Baba Kafinta Si Dana Sun Ara E Mole
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=843

 
Lati Owo Olawale Alao, Ibadan

Baba Kafinta Si Dana Sun Ara E Mole

Boya awon eeyan iba tete doola emi okunrin aloku soja kan ti won n pe ni Alhaji Liadi bo ba se pe ni ojumomo lo gbe igbese buruku ohun, sugbon lasiko ti gbogbo araadugbo ti wole sun ni baba naa deede dana sun ara e monu ile. Eefin ina lo pe akiyesi awon eeyan si ohun ti baba naa n danwo, sugbon nigba ti won yoo fi rona debe, nnkan ti baje koja atunse.Lale Ojobo (Tosde) to koja, iyen ojo karun-un, osu kesan-an, odun yii ni baba naa wo yara e lo ninu ile e to wa ni adojuko NEPA, laduugbo Olorunsogo, n'Ibadan. Bo se tilekun mora e lo fi epo bentiroolu para, to si sana si i. Leyin ti eefin ina ti ta awon ara inu ile atawon aladuugbo lolobo ohun to n sele ninu yara Alhaji Liadi, won gbiyanju lati silekun wole, sugbon igbiyanju ohun ko seso rere nitori baba naa ti tilekun pa lati eyin.


Iwe Irohin Yoruba gbo pe ipa ni won fi ja ilekun wole loo ba okunrin ajagun-feyinti ti won lo ti to eni aadorin odun yii nigba ti nnkan ti fee bo sori tan. Boya gbogbo ile nla ohun ni iba segbe sinu isele yii bi ko se pe awon ara ile atawon aladuugbo naa ti won ko je kina ohun raaye jo ran awon yara yooku pelu bi won se sare ro omi pa a. Won ni logan ni won sare gbe oloogbe lo sileewosan aladaani kan laduugbo naa, sugbon ko ru u la. Lale ojo naa gan-an lo mi kanle to jade laye.
Atawon to foju kan oku baba naa atawon to kan feti gbo iroyin ohun lasan, efun tabi eedi ni won pe ohun to sele yii, won ni oju lasan ko leeyan yoo se deede tu epo bentiroolu da sira e lara ti yoo si se bee dana sun ara e mole. Sugbon awon to sunmo Oloogbe Liadi so pe nitori bi nnkan se denu kole fun un leyin ti ijakule ba a nidii okoowo kan to se lo mu ko fopin si gbogbo irinajo ara e lode aye. Gege bi ara adugbo ohun kan se so fakoroyin wa, Alhaji Liadi ti won tun pe ni kafinta nigba aye e yii lo ni ileetura kan ti won n pe ni Headmaster Hotel nigba ti nnkan si n lo deede fun un ko too di pe o ta a. Iwe Irohin Yoruba gbo pe owo to ri nibi ileetura to ta ohun lo fi ra oja kan to fi bere si i se owo mi-in l'Ekoo. Sugbon lojiji ni ona ti owo n gba wole fun un pin nigba tijoba Gomina Babatunde Raji Fasola wo ileetaja re mo ara awon ile ati ileetaja ti atunse oju ona ipinle Eko kan. "Baba yen renti ile to fi n se oteeli ni, sugbon eyin e lo ko ile to n gbe si, to da bii ogba nla kan ti won ko awon ileetaja igbalode si.

Gbogbo ile-igbafe ohun ni baba yen si ti ta fun elomi-in, ti eni to ra a naa si ti n lo o fun nnkan mi-in, sugbon ko ta ile. Ile yen naa lo n gbe ti isele ohun fi sele lojo Tosde." A ko lanfaani lati gbo tenu iyawo, omo tabi ebi ti okunrin kafinta naa fi saye lo nitori ko si eyi to gba lati ba wa soro nigba ti akoroyin wa dele won.Ni nnkan bii aago mewaa aaro ojo Eti, (Fraide) to koja ni won sinku baba yii nilana esin Islam. Bo si tile je pe awon ebi oloogbe naa si n sofo titi asiko ta a pari akojo iroyin yii, sibe won ko fi bee baraje, won ni awon ti gba isele ohun gege bii amuwa Olorun.




 

Koko: Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo


Comments 💬 التعليقات