Olopaa Ba Ibon Lowo Chioma Atawon Mi-in, Esun Idigunjale Ni Won Fi Kan Won Nile-
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=847

 
Lati Owo Oluyinka Soyemi

Olopaa Ba Ibon Lowo Chioma Atawon Mi-in, Esun Idigunjale Ni Won Fi Kan Won Nile-ejo

Ile-ejo Majisreeti Ikeja, niluu Eko, ti ni ki obinrin kan, Chioma Ezekwesiri, atawon marun-un mi-in si wa lewon lori esun pe won ba ibon lowo won ti won fee fi jale. Awon marun-un to ku ni Raymond Chukwuka, eni odun merinlelogun, Amadi Igwe, eni odun mokanlelogoji; Okechukwu Jerome, eni odun mejidinlogbon, Michael Madu, eni odun mejilelaaadota; ati Ignatius Okeredi, eni odun metadinlogbon.

Esun meta ti won fi kan won ni igbimopo lati sise ibi, idigunjale ati nini ohun ija oloro lona aito.


Nigba ti won ka awon esun ohun si won lese tan, Adajo A. O Komolafe pase pe ki won loo ti awon eeyan naa mo ogba ewon di ojo ti igbejo yoo tun waye.
Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ileetura Bolatito to wa n'Ijaye, niluu Eko ni awon olopaa ti mu won lasiko ti won fee ja okunrin kan to n se o¯wo¯ ajile lole owo to to milionu mejo. Osise ileetura yii kan lo pe awon olopaa, nigba ti won si de ni won ko awon eeyan naa ni papamora. Ibon meji ati ota mejila ni won ba ninu moto Chioma, eyi lo je ki won ko gbogbo awon afurasi-adigunjale ohun.

Ninu oro tie, Chioma to je obinrin laarin awon eeyan ohun so pe awon ki i se adigunjale, oro ile lo fa wahala tawon fi ya wa si agbegbe naa. O salaye pe Raymond lo seto awon ibon ti won ba lowo awon, sugbon ki i se lati ja enikeni lole. Obinrin ohun so pe odun 1999 loun jade ni Fasiti ipinle Eko, iyen UNILAG, oun si darapo mo egbe awon amofin lodun 2001.

Sugbon ohun ti a gbo ni pe ko si ooto ninu oro naa, ati pe ko si oruko re ninu akosile oruko awon agbejoro to wa lorile-ede yii. Pelu gbogbo nnkan ti obinrin naa ti so ati eyi to se, o da bii eni pe wahala nla lo wa lorun oun atawon to ku re, awon esun ti won si fi kan won le ran won lewon ojo pipe.




 

Koko: Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue


Comments 💬 التعليقات