Ni Badagry, Lanloodu Pa Alaga Egbe Won Nitori Oro Owo Ina
 
Abala Yi Wa Lati
EsinIslam Media :: http://esinislam.com/MediaYoruba
 
URL Fun Itan Yi Ni:
http://esinislam.com/MediaYoruba/modules.php?name=News&file=article&sid=855

 
Lati Owo Olayinka Adedayo

Ni Badagry, Lanloodu Pa Alaga Egbe Won Nitori Oro Owo Ina

Lori esun pe o pa alaga egbe won, ile-ejo Majisreeti kan l'Ebute-Meta ti ni ki Micheal Igbonoba si wa lewon na. Oro owo ina monamona ni Micheal tori e pa Femi Fajuhami eni aadota odun yii.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe deede aago mokanla osan ojo kokanla, osu kejo, odun yii, nisele naa waye lagbegbe Ipara Village, Morogbo, Badagry, l'Ekoo. Lasiko ti awon mejeeji ti won jo je lanloodu laduugbo naa woya ija, ti Oloogbe Femi to je alaga egbe awon lanloodu, Progressive Development Association, si fesun kan Micheal to n gbowo lowo awon araadugbo naa pe ko sanwo, bee ni ko si so bo se n se owo naa nitori awon araadugbo so pe awon ti sanwo fun un ni wahala be sile.


Eyi lo fa ija, tawon agbalagba meji naa si yowo ese sira won, eyi to mu mu ki alaga naa farapa gan-an ninu ija ohun.
Leyin tawon eeyan la won tan, ko pe rara ti Ogbeni Femi fi gbemi mi-in, eyi to si je ki awon molebi e loo fi olopaa gbe Micheal pe o ti fi ese pa eeyan won.

Koburu Onaiwu Iyobosa so fun ile-ejo pe esun apaniyan ni won fi kan olujejo ohun, eyi to tako ofin iwa odaran ipinle Eko, o si tun ni ijiya to lagbara labe ofin orile-ede yii. O so siwaju si i pe oun ti fi eda iwe esun naa sowo si eka to n ri soro idajo nipinle Eko fun imoran to peye.

Agbejoro afurasi odaran yii, Spurgeon Ataene tako aba naa. O salaye pe ki i se ija ti onibaara oun ba Oloogbe Femi ja lo pa a, bi ko se arun eje-riru, eyi ti abewo ileewosan so di mimo pe ohun lo seku pa a.

Lasiko to n gbe ipinnu re kale, Adajo O.A Komolafe pase pe ki won fi olujejo ohun pamo sogba ewon Ikoyi titi tile-ejo yoo fi gbo imoran lati ofiisi eka to n ri si eto idajo nipinle Eko.

O sun igbejo si ojo keeedogbon, osu kesan-an, odun yii.




 

Koko: Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise


Comments 💬 التعليقات