Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
[ Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin ]

·Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awok
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Ikolu Awon South Africa Si Naijiria - Ekunrere
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbes
·Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
·Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
·Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
·Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun
·Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Sunday, June 08
· O N Rugbo Bo L'Osun, Awon Alase Ileewe Olukoni Fee Dase Sile
· O Ma Se O, Sanni Abacha, Agbaboolu Naijiria Tele Ku
· Iro Ni Won Pa, Ko Seni To Le Mi Laafin, Oba Ilu Tede Pariwo
· Eyi Ni Bi Won Se Sinku Agagu Atawon Ohun To Sele Ki Won Too Sin In
Sunday, March 30
· Gongo So Lojo Tawon Omo Ilu Igburowo Sajoyo Odun Kan Ti Won Le Oba Won Kuro Lori
· Wahala Olu Ifo Ti Bureke: Awon Oloye Ago-Oko Lawon Yoo Ro O Loye
Saturday, January 25
· Ija PDP N Buru Si I - Baba Iyabo, Atiku, Jonathan - Ajatu-Akata, O Doju E
· Oye Ataoja: Olote Lawon To N Tako Awa Idile Lahanmi — Omooba Rasaki Ajani
· Ki Awon Oba Yoruba Naa Kogbon Ninu Ohun To Sele Ni Warri
· Alaga Kansu Ti Ni Kawon Omoleewe Maa Wo Aso Adire L’Abeokuta
· Oro Oye Obalufon Sepeteri Di Wahala
· Ijoba Ipinle Ondo Fofin De Zaki Arigidi, Won Ni Ko Gbodo Pera E Loba Mo
· Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii
· Esun Jibiti So Igbakeji Alaga Kansu Dero Ile-ejo L'Osogbo
· Alake Tile Egba Soro: O Ni Ipo Tawon Oloselu To Awon Oba Alaye Si Ko Te Awon Lor
· Idi Tawon Omooba Ofa Fi Koju Ija Sira Won
Monday, November 25
· Idajo Ku Si Dede: Awon Olomooba Kan Ni Dandan Ni Ki Ataoja Osogbo Lo
· Onpetu Ati Onijeru Koju Ija Sira Won L'Ogbomoso
· Omo To Ko Sinu Taya Eronpileeni Lati Binni De Eko So Pe Amerika Loun N Lo
Sunday, October 27
· Ipo Oba Da Wahala Sile Niluu Irun-Akoko
· Awon Obinrin Egba Yari O! Won Lawon Yoo Rin Ihooho Loo Bawon Asofin L'Abuja
Sunday, September 08
· O Ma Se O! Odidi Molebi Kan Padanu Emi Won Sinu Ijamba Moto L’Akure
Thursday, June 13
· Ipo Oba Di Wahala L’Akure, Deji Atawon Oba Fee Gbena Woju Ara Won
· Ope O, Gomina Ipinle Oyo Fun Onibapon Ti Ibapon Lopaa Ase
· Nitori Ile Onile Ti Won Gba: Oba Joga Orile Ti N Kawon Poyin Rojo Niwaju Adajo
Saturday, April 13
· Oba Alowa Pariwo Ni Kootu: Emi O Fipa Ba Agunbaniro Lo Po, Iyawo Mi Ni, Gbogbo E
· Awon Osise PHCN Ati Onibaara Won To Ji Transfoma Ta Ni Lekki Ti Dero Ile-ejo
· Awon Odo Ya Bo Aafin, Won Ni Afi Ki Kabiyesi Fipo Sile
· O Ti Doju E! Ijoba Ipinle Ondo Ro Kabiyesi Loye Nitori Esun Tawon Araalu E Fi Ka
Wednesday, March 20
· Nitori Oro iIle, Kabiyesi Ati Akowe Re Foju Bale-ejo L’Osogbo

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ijoba Ipinle Osun Ti Ki Oselu Bo Eto-eko O - Awon Eeyan Iwo-Oorun Osun Ke Gbajar
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ijoba Ipinle Osun Ti Ki Oselu Bo Eto-eko O - Awon Eeyan Iwo-Oorun Osun Ke Gbajare

Awon olugbe agbegbe Iwo-oorun Osun ti ke si gbogbo awon abiyamo tooto ti won mo pataki eto eko gba won lori igbese tijoba ipinle Osun gbe lati da eto-eko ofe lenu isinmi tawon akekoo agbegbe naa maa n se duro.

Lati odun merin seyin ni ajo kan to n je Alaafia Dotun eleyii ti Omooba Dotun Babayemi nsagbateru re ti maa nseto eko-ofe fawon akekoo ninu olude, eleyii to mu ki ipo eko lawon agbegbe naa muna doko sii

Omooba Babayemi wa ninu egbe oselu APC ni gbogbo asiko yen, ko si si wahala kankan rara, sugbon ni kete ti okunrin naa bo sinu egbe oselu PDP ni oniruuru igbese ti n waye lati dawo ohun gbogbo to n se duro.

Okan lara awon agbenuso fawon eeyan ilu Gbongan, Alhaji Ojewale salaye pe ko si obi ti inu re ki i dun si eto naa latigba to ti bere nitori pe ajo naa ko fi ti egbe oselu kankan se rara.

O ni gbogbo eto ni won tun ti la sile fun ti olude yii, koda, eto-eko ofe naa ti bere lawon ibugbe mejidinlogbon ti won ti fee se e kaakiri ekun idibo naa ko too di pe iwe kan wa lati ileese to n ri si eto eko nipinle Osun pe ki won dawo duro.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So

Laaro kutu ojo Eti tii se Fraide ana ni iroyin naa jade sita Aare teleri l'orile-ede Zimbabwe, Robert Mugabe ti jade laye. Kayeefi, ati pe lojiji niroyin iku naa ba gbogbo agbaye.

Ohun ta a gbo ni pe osibitu kan lorile-ede Singapore ni Robert Mugabe wa lati bi osu meloo kan seyin nibi to ti n gba itoju, latari aisan ojo ogbo ti won loo koluu, to si je pe nibe lo gba jade laye leni odun marundinlogorun (95years).

Lati odun 1980 lo ti n tuko orileede Zimbabwe titi wo odun 2017 nigba ti igbakeji re ye aga mo nidi pelu atileyin ileese ologun.

Adanu nla n'iku Rubert Mugabe je, Olusegun Obasanjo

Aare orileede Naijiria nigbakan ri, Olusegun Obasanjo ti so pe, iku aare Zimbabwe ana, Robert Mugabe je adanu nla fun gbogbo ile adulawo lapapo.

O salaye pe Robert Mugabe je ajijagbara ti o mo pataki ki eeyan ja fun ominira.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!

Ohun to n sele si awon omo Naijiria ti won wa ni orile-ede South Afrika bayii ni ko sele nibi kan ri, gbogbo arinrin-ajo to je omo orile-ede Naijiria ko lo sibi kan ti won ti n pa won, ti won si n fi kumo ati ohun ija oloro mi-in le won jade. Loooto ni bii odun 1970, nigba to di pe eto oro aje won fee maa denu kole ni orile-ede Ghana, won le awon omo Naijiria ti won wa nibe, won ni ki won maa pada lo si ile won. Won le won tiletile ati teruteru won, awon miiran to si ri se daadaa nibe, won o je ki won gbe awon ileese won. Nigba naa ni kinni naa di orin bayii ni ile Yoruba pe: 'Kin ni n oo je gbagbe ile mi, kin ni n oo je gbagbe ile mi, ero Ghana ti ko mi logbon, ero Ghana ti ko mi logbon, kin ni n oo je gbagbe ile mi!' Awon ara Oke-Ogun si so orin naa di ijo, ti won n ko o pe 'Tile-tile loko ko won wa o, tile-tile loko ko won wa, ero to lo si Ghana, tile-tile loko ko won wa!'

Sugbon nibi ti oro naa mo niyi, ko senikan to pa enikan, ko si si eni to fiya je won, ijoba lo sofin pe ki onikaluku maa lo sile re. Bee naa loro si ri ni odun 1984 si 1985, nigba ti eto oro aje Naijiria funra re sese fee maa denukole, ti ijoba ologun awon Muhammadu Buhari ati Tunde Idiagbon si sofin pe ki awon omo Ghana ti won ti kun Naijiria fofo nigba naa maa waa lo sile. Ijoba Naijiria se e debii pe won wa moto ti yoo ko awon eeyan naa, koda won tun fun awon mi-in lowo ninu won. Ko senikan to lu omo Ghana kan, tabi ti won gun won lobe, ka ma ti i so pe won yoo pa won. Ohun to se n ya gbogbo aye lenu pe awon omo orile-ede South Afrika n se bayii si awon eeyan wa, ti won mura lati pa won ti won ba ri won, ti won si n fiya to ba wu won je won, latari pe won ni ki won kuro ni orile-ede awon. Iyato eyi ni pe ki i se ijoba South Afrika lo sofin.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ija ti be sile ni Nnamdi Azikiwe Airport ni Abuja

Ija Ti Waye Ni Papa Okọ̀ - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Sheshe Tewon De, Lo Ba Tun Loo Ji Ogogoro

Gege bi iroyin se so, a gbo pe iya naa waye laaatin awon ti won fe wo oro ofurufu ti Airpeace, awon ti n lo si Enugu atinawon ti n lo si Eko n ja si eni ti o ma koko wo okọ̀.

Eni ti isele naa soje re ni, awon ti won fe ba oko ofurufu Airpeace ti wa ni papa oko-ofurufu lati ago mewaa aaro ti o je igba ti o ye ki oko won gbera, ti won si da won duro titi di ago merin koja isejun ogbon irole sibe ti won o tii mo ago ti oko won ma gbera, eyi lo fa ibinu ti won ko gba ki enikeni lo wo oko.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo Egbe OOkunkun One Million Boys L'ekoo

Ofin tuntun bayii ti orile-ede South Afrika gbe jade bayii ni pe ko si omo Niajiria kan shosho ti yoo wo ilu won lai gba iwe irinna, ati pe awon omo orile-ede Ghana yoo peluu awon ti yoo maa je anfaani lati wo ilu won nigba to ba wu won lai gba iwe irinna.

Be o ba gbagbe, ati pe fawon to ba mo bi eto oro aje South Afrika she n lo, orile-ede Naijiria ni won ti n jere to poju lagbaye, to si tun je pe ko si orile-ede naa lagbaye ti won le fowo soya pe orile-ede Naijiria ko ni won ti n je ere to poju.

Orile-ede meje ni awon to n ri soro irinna lorile-ede South Afrika, iyen South Africa's Department of Home Affairs gbe jade pe awon ti fun won ni anfaani lati maa wo ilu won lai gba iwe irinna lasiko to ba wu won, to si je pe Naijiria ko si ninu won.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun

Gomina ipinle Ogun, Omoba Dapo Abiodun ti je ko di mimo pe ijoba ilu ko she e da she lai si imo ati ogbon awon agbaagba ilu nibe, nitori naa, o so pe idi ni yii toun yoo fi ya ninu imo ati ogbon awon agbaagba lati le rii pe ipinle naa gun oke ju bi enikeni she le lero lo.

Gomina Abiodun lo soro naa lonii niluu Abeokuta, lasiko to n gba egbe awon igbimo agbaagba lalejo ninu ofiisi re to wa ni Oke-Mosan. Nibe lo si ti so pe oun ko ni i koyan agba kankan, paapaa awon obinrin kere lati da si eto ishejoba oun.

Bakan naa lo tun so pe anfaani nla lo je fun ipinle Ogun lati ni awon agbaagba bi i eyi, iyen State Elders Consultative Forum, nitori pe awon gan an ni majeobaje ti won duro digbi ti ijoba, ti won ko si ni gba ki ipinle naa rele laarin awon akegbe e.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Nitori Bi Won Ko Se Rowo Osu Gba, Awon Osise Di Onibaara Nipinle Oyo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Nitori Bi Won Ko Se Rowo Osu Gba, Awon Osise Di Onibaara Nipinle Oyo

Lojo Isegun, Tusde, ose to koja, awon osise ofiisi gomina meta kan n dogbon ba iya to n ta nnkan mimu elerindodo soro nibi abe ibooji kan ninu ogba sekiteriati ijoba ipinle Oyo lati ta nnkan mimu tutu fun won lawin. Ko jo pe kinni ohun paapaa lo n wu won i mu, won fee mu un lati saa ri nnkan fi sinu ni. Sugbon gbogbo aroye awon okunrin ohun ni ko wo iya oni miniraasi leti, o ni awin toun ta ti to gee, keni kan ma da oun ni gbese ni toun.

''E saa mo pe ki i sejo tiwa naa. Gbogbo wa la mo bi ilu se ri. A ni lati jo maa wo o se funra wa naa ni. Obinrin ti mo maa n gba ounje (ounje tutu bii iresi, ewa ati bee bee lo) awin lowo e nile ti mo mi, o mo pe ti mo ba ti gbowo ni mo maa setu oun. Oloun n bo asiri ounje ati maa ri owo wo moto wa sofiisi naa nisoro.'' Oro ti okan ninu awon okunrin naa so niyi nibi ti won ti n saroye nipa owo-osu tijoba Seneto Abiola Ajimobi je won. Eyi ni ohun ti ai ri owo-osu gba so awon osise ijoba ipinle yii da. Pupo ninu won lo ti fee di ala;gbe (onibaara) tan nitori won n se fainbara lati rowo woko pada sile lati ibi ise, lati jeun ati lati gbo awon bukaata peepeepe mi-in.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Nitori Owo Osu, , Edet Be Ori Omo Oga e N'Ijebu Ife
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Owo Osu, , Edet Be Ori Omo Oga e N'Ijebu Ife

Arakunrin kan, Edet Umoren, lowo awon olopaa te l'Ojobo, Tosde, ose to koja, lori esun pe o be omobinrin omo odun mewaa kan lori sinu igbo nitori pe oga e to je baba iya omo naa toruko re n je Precious Adedeji je e lowo osu meji nileewe alakoobere 'St Favour' to ti n sise. Agbegbe kan ti won pe ni Esugbo, n'Itamerin, legbee Ijebu Ife, nijoba ibile Ila-Oorun Ife, nisele naa ti waye.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe okan lara awon tisa ileewe naa ni Edet, sugbon se lemi esu sadeede gbe e wo lojo to ku ola tomo naa yoo sojoobi odun kewaa re. Agbo pe Edet ti so omo naa daadaa, igba ti Precious ati ore re kan to n je Patricia loo ra bisikiti ti won n pada bo lo yo si won lojiji pelu ada lowo e, lo ba fa Precious dani lowo lo sinu igbo, nibi to be ori re si.

Patricia tori ko yo lo sare loo so fun oga-agba ileewe naa pe Onku Edet ti gbe Precious lo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ipo Adele Oba Saki: Awon Afobaje Atawon Odo Yari Mo Ijoba Lowo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ipo Adele Oba Saki: Awon Afobaje Atawon Odo Yari Mo Ijoba Lowo

Lowolowo bayii, awon afobaje ti won dibo yan Gasali Adegoke lojosi gege bii Bagii, iyen Adele-oba ilu Saki, ti faake kori pe awon ko ni i tele ase ijoba ipinle Oyo lati tun ibo di laaarin ojo merinla.

Lojo Aje, ogbonjo, osu kokanla, odun yii, ni ase waye lati olu-ileese to n ri soro ijoba ibile ati oye jije nipinle Oyo pe kawon afobaje mejeejo to yan Gasali Adegoke gege bii Bagii ilu Saki tun ero won pa nipa siseto idibo tuntun. Eyi waye latari iwe ehonu ti won ri gba latodo idile Kujenya to letoo lati fa omo oye kale, won ni yiyan ti won yan Gasali ko ba ilana oye jije idile naa mu.

Ninu iwe to jade lati sekiteriati ohun lojo Eti, ojo ketadinlogbon, osu kokanla, eyi ti Ogbeni Femi Akano fowo si loruko komisanna ni won ti fi ye idile Kujenya pe pelu awon iwe ehonu tawon ri gba, atundi ibo se pataki. Iwe yii lo mu ki ipade pajawiri waye ni gbongan ile asofin to wa ninu ogba ijoba ibile Iwo-Oorun Saki laarin awon idile ti oro naa kan atawon Afobaje mejeejo, awon agbofinro, awon osise ijoba ibile Iwo-Oorun Saki pelu awon oniroyin.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Wahala l'Orile Ilugun, Won Ni Ayederu Ni Yusuf To n Pera e Ni Baale
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Wahala l'Orile Ilugun, Won Ni Ayederu Ni Yusuf To n Pera e Ni Baale

Bi nnkan se n lo yii, afaimo ki wahala ma be sile niluu Orile Ilugun, nipinle Ogun, pelu bi won se ni okunrin kan toruko e n je Waheed Olatunde Yusuf, ti inagije re n je 'Olumo Record' se n pe ara e ni Baale ilu naa laije pe ilu yan an sipo.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, lojo kejilelogun, osu kewaa, odun yii, ni Baale to wa nibe tele, iyen Oloye Raheem Sule Lawal dagbere faye.

Nitori kiluu naa ma baa salai ni olori ni Oba Dokita Adedapo Adewale Tejuoso to je Osile Oke-Ona Egba se yan awon oloye mesan-an kan gege bii igbimo ti yoo maa dari ilu naa titi ti won yoo fi yan Baale tuntun.

Awon eeyan wonyi so pe Osile fowo si i pe kawon maa sakoso Orile Ilugun lo, o si fowo siwee fawon lojo kokanla, osu kokanla, odun yii.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ote Ni Yoo Ba Aye Wwon Oba Yoruba Yii Je
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ote Ni Yoo Ba Aye Wwon Oba Yoruba Yii Je

Won ni awon oba Osun kan n leri pe awon ko ni i lo sibi ti won ti fee fi Ooni joye, ati pe Owa Ilesa lo saaju won. Won ni Owa so pe won fi oun se alaga, Ataoja lo fa owo oun soke, oun si ti di alaga igbimo lobalola ipinle Osun. Ati Ataoja, ati Owa, atawon ti won wa leyin won, won mo pe ina ote lawon n da yii, won mo pe ote tuntun lawon n bere, won mo pe ina naa yoo si jo laipe, won mo pe wahala mi-in lawon tun fee da sile nile Yoruba ati laduugbo tiwon niyen. Won mo daadaa. Ohun to n fa iru eleyii nile Yoruba ko ye eni kan, ati idi ti awon to ye ko gbin igi alaafia siluu se maa je awon gan-an ni won maa n fee fa igi alaafia tu.

Owa so pe oun loun ti n se adele fun Ooni lati ojo yii wa, ti oun si n se adele alaga nigba ti Ooni ko ba ti le wa sipade. Eleyii ki i se nnkan tuntun tabi ohun to lodi sofin. Bo ba je bee ni Owa ti n je alaga yii tele, ki lo waa fa ikanju, ki lo fa ere giragira, ki lo de ti awon oba Osun ko duro ki won gbade ka Ooni lori ko si gba opa ase, ki won waa jo wa nipade, bi won ba fee fi Owa je alaga, ki won si fi i je alaga. 


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ipo Adele Oba Saki Di Wahala, Won Ti Gbera Won Lo Sile-ejo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ipo Adele Oba Saki Di Wahala, Won Ti Gbera Won Lo Sile-ejo

O see se ki erongba tomode tagba ilu Saki, nipinle Oyo, nipa yiyan oba tuntun laipe fori sanpon pelu bawon kan se n so pe yiyan ti won yan Gasali Adegoke gege bii Bagii ilu naa ko tona.

Idi abajo oro yii ni pe awon molebi Kujenya to letoo lati fa omo oye kale ninu eto idibo to waye lojo kejo, osu kewaa, odun ti a wa yii, nibi ti won ti yan Bagii tuntun naa tun ti gba ileejo lo pe yiyan ti won yan Gasali, gege bii Adele Okere tuntun naa ko ba ofin mu. Won ni amuni-muye lo mu iye awon lo lojo tawon n dibo, iyen lo fa a ti won fi yan Adegoke gege bii Bagii ilu naa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Oro Oye Iyaloja N'Ijebu: Awon Ara Oja Kan Lawon Ko Fe Wuraola Kuforiji
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Oro Oye Iyaloja N'Ijebu: Awon Ara Oja Kan Lawon Ko Fe Wuraola Kuforiji

Olorun nikan lo mo ibi ti wahala oro oye Iyaloja Oke Aje, niluu Ijebu-Ode, yoo ja si nitori won lawon kan ti yari ninu oja naa pe awon ko fe obinrin ti won fi se Iyaloja naa bayii, Oloye Wuraola Kuforiji, gege bii Iyaloja Akile Ijebu. Sugbon obinrin naa so pe ko seni to le gba oye naa lowo oun.

Gege bii leta ehonu tawon ara oja kan lati oja Oba Adetona, Oke Aje, Ijebu-Ode, ko si Oba Sikiru Adetona to je Awujale tile Ijebu, won ke si oba naa lati tete ba won gbe igbese lori bi won se ni obinrin naa n da wahala sile.

Bo tile je pe Iyaloja Wuraola naa ti so pe ko si ooto kan ninu leta ti won ko naa, nitori pe nigba ti Iyaloja gbogbogboo, iyen Elewuju, wa laye lo ti foun joye naa, ati pe titi to fi jade laye, Iyaloja lo n pe oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Obasanjo So Pe Koko Lara Oun Le o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Obasanjo So Pe Koko Lara Oun Le o

Oloye Olusegun Obasanjo ti so pe loooto loun nijamba moto lojo Abameta, Satide, ijerin, sugbon ori ko oun yo, bee lo je pe koko lara oun le, oun si wa nibi toun ti n mojuto ibo lorile-ede Cote d'Ivoire.

Nibi atejade kan ti won fi sita lojo Aiku, Sannde, ijeta loro yii ti jade nipa orisiirisii awuyewuye tawon kan n so nipa ijamba moto naa. Ohun ta a gbo ni pe sadeede ni okan lara taya moto ti aare tele naa wa ninu e fo lojiji loju-ona Ibadan s'Ekoo lakooko to n lo sibi ayeye ojoobi ogorin odun ti Kesington Adebutu se.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Nnkan De! Deji Akure Gbade Lori Ndi-Igbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluseye Iyiade, Akure

Nnkan De! Deji Akure Gbade Lori Ndi-Igbo

Ibiti wahala to n waye laarin awon omo bibi Ibo to filu Akure sebugbe ati Deji ilu naa yoo ja si bayii lenikan ko ti i le so pelu bawon eeyan naa to n taja niluu ohun se binu ti soobu won pa lose to koja leyin ti won fesun kan Deji pe o wo asaaju awon nile pelu bo se pase pe kawon odo kan gba ade lori re.

Gege bi alaye ti alaga egbe kan to n daabo bo egbe omo Ibo lorile-ede yii, Ogbeni Emma Ezema, se nigba to n ba wa soro lori isele yii, o lo ti pe die ti wahala ti n sele lori eni to ye ko je alaga awon to n ta eya ara oko loja Mojere, to wa ni gareeji Ilesa, l'Akure.

O ni awon omo Ibo lo ko ida ogorin ninu awon onisowo to n taja nibe, bee lajosepo to dan moran wa laarin awon omo Yoruba ti won je onisowo loja yii atawon akegbe won to je eya Ibo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ija Agba Ninu Egbe Eleedu Ipinle Eko, Won Lu Babaoja Nibi Iwuye
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ija Agba Ninu Egbe Eleedu Ipinle Eko, Won Lu Babaoja Nibi Iwuye

O tojo meta ti awuyewuye ti n sele ninu egbe awon to n ta eedu nipinle Eko, eyi to mu ki egbe naa pin si meji, awon kan n ba igun Iyaloja Jenera, Oloye Folasade Tinubu Ojo, se, ti awon mi-in si n tele okunrin giga kan ti won n pe ni Bola Sanusi. Okunrin pupa yii ni won pe ni aare egbe awon onise owo nipinle Eko, sugbon baba naa ko fi mo ni ti onise owo nikan, o ni oun naa tun ni aare fegbe awon eleeedu naa.

Bi Sanusi se n mu oloja mo onise owo ni ko ba awon igun ti Iyaloja Jenera lara mu, won so pe ko seni ti ko mo pe ka-ra-ka-ta ni eleedu n se. Won ni eni kan soso to letoo lati feeyan joye ni Oloye Folasade Tinubu Ojo.

Ojobo, Tosde, ose to koja lohun-un, ti i se ojo kejo, osu kewaa, ni mama naa fi Oloye Benjamin Olabode je Babaoja Jenera fun gbogbo eleeedu nipinle Eko, nigba to maa di ose to tele e ni Sanusi ko awon eleeedu kan jo, to ni oun yoo fi oye da won lola, ohun to fa wahala to sele ninu ogba ijoba ibile Oshodi Isolo niyen l'Ojobo to koja yii.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Nje Oba Ooni Lee Sun Re Bayi Ti Wahala Ti Be Sile Laarin Awon Olomooba Ile-Ife?
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq

Nje Oba Ooni Lee Sun Re Bayi Ti Wahala Ti Be Sile Laarin Awon Olomooba Ile-Ife?

Ni bayii to ku ojo merinlelogbon pere ti won yoo kede eni ti yoo je Ooni tuntun ni ilu Ileefe, o da bii eni pe awon idile to letoo soye naa ko ti i fori ikoko soodunrun, bi awon kan se n sekilo fawon afobaje lati te e jeje, lawon kan fori le ile-ejo pe dandan ni kawon fese ofin to oro naa.

Latojo kejidinlogbon, osu keje, odun yii, ti Oba Okunade Sijuwade ti waja lorisiirisii igbese ti bere lori eni ti yoo je Ooni tuntun, niwon igba to si je pe ko seni ti ipo ola ko wu, atawon to letoo si i atawon ti ko letoo si i ni won ti bere si i lo kaakiri lati fa oju awon afobaje mora.

Koda, iwadii fihan pe bawon kan se n ru owo kaakiri, lawon kan n se oniruuru ise idagbasoke sagboole won lati fi jewo pe omo ile oba tooto lawon je.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Leyin odun meta to ti n womo, iyaale ile bi omo to niwo lori n'Ilesa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Leyin odun meta to ti n womo, iyaale ile bi omo to niwo lori n'Ilesa

Nnkan idunnu ati ayo nla lomo tuntun maa n je bi obinrin ba se bee ru u daadaa, to tun so o layo, paapaa tiru obinrin bee ba ti n sunkun omo lojo to ti pe, ti Eledaa si waa saanu re to fun un lomo. Bi tebi tore ti n yo ni awon to bimo ohun gan-an yoo maa file ponti fona roka, gbogbo eni to fe ire a si maa ba awon olomo naa yo pe kulumbu yeye sole loode won.

Sugbon oro ko ri bee nile obinrin eni odun marundinlogbon kan ti a ko mo oruko re lasiko ti a n ko iroyin yii, omobinrin naa lo ti n fomije beere omo lowo Oluwa latodun keta to ti wole oko re niluu Ilesa, nipinle Osun, sugbon nigba ti yoo bi omo naa lose to koja yii, iwo meji lomo ohun gbe waye, nise lomo tuntun hu iho meji lori bii eranko, eyi to je kayeefi fun gbogbo eni to ri i, ti ko si je ki won le pariwo ayo to maa n ro mo dide omo tuntun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Owo te awon to n ta ori eeyan n'Ibadan, oko atiyawo to loyun wa ninu won
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Owo te awon to n ta ori eeyan n'Ibadan, oko atiyawo to loyun wa ninu won

Bo ba se pe lati inu oyun ni omo ti maa n jogun ba ise ti iya e yan laayo ni, bi obinrin oloyun kan n'Ibadan, Adeniran Saki, ba bi oyun inu e, Olorun lo mo iru eeyan ti omo naa iba ya, abi nigba to se pe oun ati oko e ni won jo n de isa oku kiri iboji, ti won si n hu awon oku eda eeyan egbe won ta nitori owo.

Saki, eni odun meeedogbon ati oko e, Mojeed Adeniran, pelu awon akegbe won meta mi-in lowo awon olopaa te n'Ibadan fun bi won se n ra ori eeyan gbigbe, ti won si n tun un ta, eyi to mu ki won maa loo sigun ba awon oku ti won sun jeje tiwon ninu saree ti won si n ge won lori lo feu, egberun meji si merin naira ni won si n ta odidi ori eeyan kan.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Oye Parakoyi ile Egba di wahala: Won lawon ko fe Kasimawo Laloko
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta


Oye Parakoyi ile Egba di wahala: Won lawon ko fe Kasimawo Laloko


Bi nnkan se n lo yii, afaimo ki oro oye tuntun ti won fi eni to ti figba kan je koosi egbe agbaboolu ile wa, Oloye Kasimawo Laloko, je ma di wahala nla nitori bawon kan se pe Alake ile Egba ati Gomina Ibikunle Amosun ipinle Ogun lejo.


Ose meloo kan seyin la gbo pe ijoba ipinle Ogun fowo si i pe ki won fi Laloko je Parakoyi ile Egba, ti won si ti jawe oye le e lori. Sugbon se ni igbimo Parakoyi Igbore tawon oloja lokunrin ati lobinrin wa so pe awon ko faramo eni ti won fi joye naa, eyi lo si fa a ti won fi gbe ijoba ati Alake lo sile-ejo.


Won ni igbese ti won fi yan Laloko ko bofin ati ilana ti won fi maa n yan oloye Parakoyi mu. Gege bii iwe kan tawon Parakoyi Igbore gbe sita ti akowe won, Oloye Olusegun Sokeye fowo si ni won ti so pe Laloko ki i se Olori Parakoyi Igbore tabi tile Egba, won ni bijoba ipinle Ogun se fowo si i ko ba ilana mu, o si lowo kan oselu ninu.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ki lawon oba Yoruba tun se fun yin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Ki lawon oba Yoruba tun se fun yin


Nibi ti e ba fi oro oselu yii ba aye je de, ti e fi ba ile Yoruba je de, oju gbogbo yin naa ni yoo se o. Ariwo ti awon egbe APC n pa kiri bayii ni pe awon oba ile Yoruba ti gba owo, owo dola ni won si n gba lowo Jonathan. Bi won ti wi bee, bee naa ni awon iwe iroyin won n gbe e jade. Akoko ni pe ninu gbogbo awon ti won n soro yii, titi dori Lai Muhammed, ko seni kan to ri igba ti won n ko owo dola yii fun awon oba wa, won ni, won pe, awon gbo o nibi kan, enikan ti ko loruko lo so fawon, ati bee bee lo la n gbo, enu awon eeyan yii nikan naa la si ti n gbo o.

Ibeere ti eeyan yoo beere naa ni pe ki lo de to je awa Yoruba feran lati fowo ara wa ba tara wa je bayii, a oo so awon oba wa di yeye, a oo so awon eeyan nla aarin wa di yeye, nitori oro oselu yii naa si ni. Bi awon oba kan ba wa nile yii ti won n gba owo to po ju, awon oba ile Hausa ni. Bi gomina won je, won yoo maa fun won lowo, won yoo maa ra moto tuntun fun won, bi won yoo se odun yoowu, owo ti yoo to lati fi gbo bukaata gidi fun araalu ni won yoo ko fun won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ipo oba da wahala sile n'Ido-Ani, lawon omooba ba lura won lalubami
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Ipo oba da wahala sile n'Ido-Ani, lawon omooba ba lura won lalubami


Wahala ipo oba Alani ti Ido-Ani, nijoba ibile Ose, nipinle Ondo, tun gbona mi-in yo lose to koja yii pelu bi won se ni okan ninu awon omo Oba Olufemi Olutoye, to gba opa-ase losu kewaa, odun to koja gege bii Alani ti Ido-Ani lu die ninu awon ti won je alatako baba e atawon olori kan lalubami ninu aafin.


Gege bi iwe esun ti agbejoro agbarijo awon omooba ilu Ido-Ani, Amofin C. Olufunmilola Abitoye, ko si komisanna olopaa ipinle Ondo, o ni bii ere nisele ohun bere lojo Abameta, Satide, ti i se ojo kejidinlogbon, osu to koja, lasiko ti won n sayeye isinku olori awon afobaje niluu Ido-Ani, iyen Oloye S.O.AOniye, ninu ijo ‘Anglican Holy Trinity' to wa niluu naa.


Ninu iwe esun to je oju iwe meta ohun ni won ti fidi e mule pe okan ninu awon omo oloogbe, Eni-Owo Gbenga Oniye, to je ore igba ewe Omooba Jackson Agunloye Falade (eni toun naa n dupo oba pelu Oba Olutoye) wa nileejosin lojo naa, ohun gbogbo si ti n lo letoleto ko too di pe Agbo;pa¯a; Oba, Alaaji Ibrahim Kamaru Agbede, eni ti inagije re n je Kakuleto wole, ko si ri ibomi-in jokoo si ju iwaju Omooba Jackson Falade lo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Oro oye Balogun fee da wahala sile l'Osogbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Oro oye Balogun fee da wahala sile l'Osogbo


Awon idile meta ti won n je oye Balogun niluu Osogbo tele ti wo Ataoja tile Osogbo, Oba Jimoh Olanipekun lo siwaju igbimo to n wadii jagidijagan to ba sele laarin ilu nipinle Osun lori esun pe o fee da ilana to ti wa nile nipa oye naa ru.


Sugbon Ataoja so fun igbimo naa pe ko si ooto ninu esun ohun, ati pe oye Balogun ko wa fun idile naa nikan pelu bo se je pe awon ijoye keekeeke mi-in naa lanfaani lati ni igbega de ori oye ohun.


Lati odun 2009 ni wahala yii ti bere nigba ti awon idile Balogun Kujenyo, Balogun Agoro ati Balogun Fagbemi tawon eeyan tun mo si Balogun Biiro ni awon nikan lawon letoo labe ilana ti ilu Osogbo n tele lati maa je oye Balogun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ileese olopaa Kwara sawari tirela to ko ohun ija oloro Stephen Ajagbe, Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ileese olopaa Kwara sawari tirela to ko ohun ija oloro Stephen Ajagbe, Ilorin

Lojo Eti, Fraide, ose to koja yii nileese olopaa sawari oko nla kan to ko awon ohun ija oloro lagbegbe Ko;su¯bo;su¯, nijoba ibile Baruten.

Iwe Iroyin Yoruba ri i gbo pe ale ojo Eti naa lowo te oko ohun ti nomba re je Lagos XU 110 BDG, eyi ti won nigbagbo pe lati orile-ede Burkina-Faso lo ti n bo, to si n lo siluu Ibadan.

Dereba oko naa pelu enikan ti won jo wa ninu e lowo awon olopaa to wa ni Kosubosu te pelu awon ohun ija oloro yii.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Asiri tu! Idi ti won se sun ojo idibo siwaju ree o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Asiri tu! Idi ti won se sun ojo idibo siwaju ree o

Kangun kangun, oro eto idibo to ye ko waye lopin ose yii ti kangun sibi kan bayii pelu bi alaga ajo eleto idibo lorile-ede yii, Ojogbon Attairu Jega, se kede ni ojo Abameta, Satide, ose to koja, pe eto idibo naa ko ni i waye bawon se seto e tele. Ni bayii, ojo kejidinlogbon, osu keta, odun yii, ni eto idibo aare to ye ko waye ni Satide, ose yii, yoo waye bayii, nigba ti tawon gomina ti won ti fi si ojo kejidinlogbon, osu yii, tele yoo waye lojo kokanla, osu kerin.

Lose to koja ni Iwe Iroyin Yoruba ti koko gbe e jade pe o see se ki won sun ojo idibo siwaju.

Eleyii ko seyin ariwo to ti n lo nigboro lati bii ojo die seyin lori eto idibo ohun, ko si jo pe igbese ajo eleto idibo, (INEC), ba opo eeyan lojiji rara, bo tile je pe ireti opo araalu ni pe ko si ona ti won yoo gba lati sun ojo idibo naa siwaju.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Lori oro omo ti won gbe ju si salanga, olopaa ti mu eeyan mokanlelogun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq, Ondo

Lori oro omo ti won gbe ju si salanga, olopaa ti mu eeyan mokanlelogun

Inu iberu-bojo lawon araadugbo John, l'Ondo, wa lati nnkan bii ose meji seyin ti oniseebi kan ti ko ti i seni to mo on loo gbe omo oojo ju sinu salanga to wa niwaju ita ile alaja meji kan laduugbo naa, eyi to mu kawon olopaa maa sa enikeni ti won ba fura si pe o lowo ninu iwa ohun.

Ninu awon towo ba ni pasito kan atomo re obinrin wa. Leyin ti won gbe iranse Olorun naa ju soko tan ni won nawo gan obinrin kan to n kiri eja lo ni tie jeje laaaro kutu ojo naa, bee ni won tun wonu ile kan to wa niwaju ile tisele yii ti waye loo mu obinrin kan nibe, sugbon gbogbo bi iyen ti n salaye fun won pe o se die toun ti wa nile nitori ara oun ti ko ya ni ko gba ibi kan wonu eti won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ile N Jeyan! Igbesi Aye Arisekola Alao Aare Musulumi Ile Yoruba - Igbe Aiye Rere
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Olawale Ajao, Ibadan

Ile N Jeyan! Igbesi Aye Arisekola Alao Aare Musulumi Ile Yoruba - Igbe Aiye Rere Ni

Ni aye igba kan nile yii, ero redio ko po pupo, bee ni awon iwe iroyin to wa niluu ati ti oloyinbo ati ti Yoruba ko si to nnkan. Ohun kan naa lawon eeyan fi n mo gbajumo laarin ilu, ti won yoo si tun mo awon olowo tuntun ti won ba sese de saarin ilu kaakiri. Ona kan soso ti awon araalu n gba mo awon eeyan ti owo won ba sese bureke bee ni lati odo awon olorin. Bi olorin nla kan ba ki enikan, ki ile ojo ti awo rekoodu naa ba jade too su, gbogbo ilu pata ni yoo ti mo oruko eni naa, bi awon orin naa ba si se n ta si, bee ni oruko okunrin naa yoo maa ran bii irawo owuro. Ati pelu, bi akorin to korin naa ba je elere nla, kia laye yoo ti mo pe olowo gidi ni eni ti won n ki naa.

Ohun to sele ni odun 1977 si 1978 niyen, nigba ti awon elere nla meta kan ti okiki won n kan lowo, ti irawo won si bu yo korin ki okunrin kan soso sinu awo orin won ti won se leralera, ti okiki okunrin naa si gbile bii irawo nla. Olanrewaju Adepoju, Borokinni Akewi omo Okebadan, lo koko si ode kinni ohun, oun lo koko forin ewi juwe Arisekola Alao fun gbogbo ilu, oun lo je ki Yoruba mo pe eni naa wa to n je Azeez, o pe e ni Arisekola Alao Azeez, oba kekere aarin igboro, Ikolaba Aare Ibadan to ri bii oba ibomi-in.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Bi Sanusi Lamido Sanusi Ti Papa Di Oba Ilu Kano Lehin Awuyewuye Ati Ijaagboro
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Ademola Adejare

Bi Sanusi Lamido Sanusi Ti Papa Di Oba Ilu Kano Lehin Awuyewuye Ati Ijaagboro

Bi ko ba je pe awon olopaa tete ni, ti won si ti mura sile sepesepe, ohun ti yoo baje niluu Kano ko ni i se e fenuso, nitori oba tuntun ti won je nibe. Lesekese ti won kede oruko Alaaji Sanusi Lamido Sanusi gege bii oba tuntun ti yoo je niluu naa ni nnkan ti sele, ti awon odo si gbegi, ti awon kan si bere si i ba dukia ati ohun-ini je, ti awon kan paapaa n dana soju titi kaakiri. Titi di osan ana ni awon olopaa ati soja si n yi gbogbo ilu naa po, ti won n le awon omo to n parojo ti won n fee maa ba ijaagboro naa lo danu, ti won si n kilo fun olomo pe ko toju omo won.

Se lojo Eti, ojo Jimo, ojo kefa, osu kejo odun 2014 yii ni Alaaji Ado Bayero, Oba ilu Kano tele waja, eni odun metalelogorin ni ki iku too mu un lo, nitori ni ojo keeedogbon, osu keje, odun 1930 ni won bi i. Ninu odun to lo laye yii, odun mokanlelaaadota nibe lo fi joba, osu kewaa, odun 1963 ni won ti we lawani oye fun un, omo Fulani ponbele si ni. Omo Abdullahi Bayero ni, baba re si ti joba fun odun metadinlogbon ko too ku. Bi baba re ti ku ni won mu egbon re to n je Sanusi, iyen akobi baba won, pe ko joba, odun mewaaa loun si lo ti won fi le e loye. Igba naa ni won fi Ado Bayero si i, leyin to ti se ise olopaa, to si se asoju Naijiria ni Senegal. Bayero naa lo ku yii o.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Oro Ooni Ati Alaafin (Ta Ni Yoruba Gan-an?)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Oro Ooni Ati Alaafin (Ta Ni Yoruba Gan-an?)


Ninu awon iwe ti mo gba lose to koja yii, okan wa nibe to kan mi kuu. Ohun to wa nibe niyi: “Baba, ajinde ara ko maa je. E jowo, awa merin kan wa ti a maa n jokoo po ka oro yin ninu Iwe Iroyin Yoruba losoose. Enikan ninu wa yoo ka oro naa, a oo si bere si i se atupale le e lori. Awa mereerin yii, oluko agba ni wa ni yunifasiti, awon meji ni purofeso ninu wa, awa meji to ku si powo le won. Oro Ooni ati Alaafin ti e bere yii, oro nla ni o, o see se ko je ohun ti yoo yanju wahala ile Yoruba gan-an le gbenu le yii. Sugbon e ma bere nibi ti e ti fee bere yen, ki i se ohun to fa ija Ooni ati Alaafin ni ki e fi bere. E jowo, Baba, e so fun wa, ta ni Yoruba gan-an? Nibo ni won ti wa? Ta lomo oko, ta lomo ale? Leyin eyi ni ki e too soro ija.

Bi bee ko, e o kan gbe oro naa lori ni, ko si ni i mu iyanju kankan wa. E seun sa. E jowo, e ma daruko mi ati nomba mi, nitori oro ki i ye awon eeyan wa boro, eyi ti mo ko ranse si yin lojosi ko wahala gidi ba mi.” Mo mi kanle nigba ti mo gba leta yii, nitori nigba tawon ojogbon bayii ba soro, afi keeyan tele e. Sugbon ohun ti won n beere lowo mi yii, bii igba teeyan fee so itan gbogbo Yoruba ni, ise nla si ni. Bee ni tododo, bi a ko ba tu oro naa de isale, ki kaluku mo ara re, a oo kan maa se e lasan ni. Eyi lo je ki n gba lati gbiyanju oro naa, ti mo si bere si i fi oro lo awon oniwadii, awon onkowe ati awon ore mi. Won ti da orisiirisii iwe jo fun mi, n ko si ro pe mo sise mi-in lati ojo Isegun to koja ju ise kika lo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi? (Apa Keji)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Adewale Adejare

Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi? (Apa Keji)


Lori oro ti mo bere lose to koja yii orisiirisii idasi ni mo gba, ona ti kaluku kan fi da soro naa lo yato ni. Inu mi dun fun kinni kan, iyen naa ni pe opolopo awon ti won da soro yii ni won gba pe ni tododo, awon Oba meji ti oro won se pataki ju naa ni Ooni ati Alaafin, ti won si gba pelu mi pe iti ogede lasan ni oro Awujale ati Oba Eko, ko to ohun teeyan yoo maa lo ada si rara. Bi aarin Ooni ati Alaafin ba ti gun rege, ohun to ku yoo see se, nitori awon oba to ku yoo maa tele won.

Sugbon oro naa ko ye awon mi-in, ohun ti won n so ni pe ki lawon oba wonyi le se, awon oba wonyi gan-an ni isoro wa, ki a pa won ti ki a yan asaaju, bi a ba ti yan asaaju fun Yoruba, o pari niyen. Oro ti awon wonyi naa so ye mi, nitori mo mo pe ibi ti oro ye awon paapaa de, ati bi oro naa ti ka won lara to ni won fi n soro ti won n so. Sugbon awon kinni kan wa ti a gbodo mo.

Akoko ni pe awon oba ti a ri yii ni ami-idanimo akoko fun Yoruba, bi a ba ti yowo ede ti a n so lenu. Nibi ti nnkan ba ti dara, oba to ba je lo ye ko ko asa ati imo awon eeyan re dani, oba ti ko ba ti le se eleyii ko ye ni oba rara ni. Ni ile Yoruba yii si niyi, boya a fe, boya a ko, Ooni ati Alaafin ni asaaju awon oba wa. Awon wonyi lo ye ki agbara ile Yoruba wa lowo won, nitori lati igba iwase, agbara Yoruba ti wa lowo won ri.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: