Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
[ Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere ]

·Ijoba Ipinle Osun Ti Ki Oselu Bo Eto-eko O - Awon Eeyan Iwo-Oorun Osun Ke Gbajar
·Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So
·Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
·Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
·O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
·Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
·Nitori Bi Won Ko Se Rowo Osu Gba, Awon Osise Di Onibaara Nipinle Oyo
·Nitori Owo Osu, , Edet Be Ori Omo Oga e N'Ijebu Ife
·Ipo Adele Oba Saki: Awon Afobaje Atawon Odo Yari Mo Ijoba Lowo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Sunday, March 30
· Iru Gift Wo Leyi? Oga Re Ni O Lu Ni Jibiti, O Loo Fi Kaadi Re Gbowo Ni Banki L&#
· Owo Te Biodun, Ogbologboo Adigunjale N’Ibadan, Oko Olowo Nla Lawon Maa N Ja Gba
· Awon Adigunjale Ya Bo Banki Moniya
· E Gba Wa O, Awon Olokada Ogbomoso N Ja Wa Lole Awon Ara Ilu
· Lati Idanre Lawon Omo Odun Metala Ti Waa Ji Eeyan Gbe L’Ondo, Won Ni Jasper Lo R
Saturday, January 25
· Peter Loo Ji Aso Ti Oloriegbe Fee Fi Segbeyawo N'Ilorin, Owo Ti Te E
· Lateef Lu Ileese E Ni Jibiti Milionu Mewaa Naira, Ni Won Ba Wo O Lo Sile-ejo
· Olopaa Ba Ibon Lowo Chioma Atawon Mi-in, Esun Idigunjale Ni Won Fi Kan Won Nile-
· Awako Takisi Rewon He L'Ondo, Esun Idigunjale Ni Won Fi Kan An
· Won Ni Babalawo Ji Olokada Gbe Ni Badagry, O Ti Dero Ile-ejo
· Oga Banki Atawon Egbe E To Kowo Je Ti Wa Logba Ewon Oke-Kura, N'Ilorin
· Tosin Yii Ma Laya O! O Wo Soobu Onisoobu N’Ibadan, Lo Ba Gbomo Lowo Iya E
· Nitori Esun Idigunjale, Ile-ejo Pase Ki Won Yegi Fun Taiwo Atawon Egbe E
Monday, November 25
· N'Ilorin, Owo Te Adigunjale Ogbon, Lawon Araalu Ba Dana Sun Meta
· Owo Te Ola, Omo Seneto Femi Kila To Jale L’Abuja
· Baagi Funmilayo Ni Seun Ja Gba Nitosi Marwa Garden, N Ladajo Ba Ni Ko Loo Sewon
· Asiri Ajao To Ji Moto Gbe L’Ekoo Tu, Lo Ba Loo Pokunso Ni Saki
· Abudu Fi Kaadi ATM Gbowo Olowo Jade L'Olowora, Ni Won Ba Gba A Mu
Sunday, October 27
· Awon Ore Meta Ti N Sere Logba Ewon N'Ilesa, Ole Lo Sun Won Debe
Sunday, September 08
· Adigunjale Ni Olopaa Fee Yinbon Fun L’Oko-Baba, Muyideen Lo Loo Pa
· Paul Atawon Egbe E Fibon Jale, Oun Nikan Lowo Te
Thursday, June 13
· Segun Ati Ore E Ti Jewo Fawon Olopaa, Won Ni: Nitori Olokada Yen Je Omode La Fi
· Nitori Esun Ole Jija, Adajo Ni Ki Won Yegi Fawon Ore Meta L’Akure
· O Ma Se O, Won Lu Igbakeji Gomina Kwara Tele Ni Jibiti Owo Nla
Saturday, April 13
· L’Ekoo, Joshua Atawon Ore O Fo Soobu Iyaloja Ebute-Ero, N Ladajo Ba So Won Sewon
· Adajo Ti Ju Hannah To Ji Omo Osu Meta Gbe L’Ore Sogba Ewon
· Owo Te Opeyemi,Omo Odun Mokandinlogun To N Jale L’Ekiti
Wednesday, March 20
· Awon Adigunjale Ya Wo Banki Kan L’Osun
· E Woju Won O, Awon Odaran To N Sayederu Owo
Thursday, February 28
· N’Ibadan, Owo OPC Te Ganiyu To Maa N Mura Bii Omobinrin To Ba Fee Loo Jale

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Afise Loroo Benjamen Yi O, Leyin To Jade Lewon Lo Tun Loo Ji Telifisan Pasito
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Afise Loroo Benjamen Yi O, Leyin To Jade Lewon Lo Tun Loo Ji Telifisan Pasito

Lagbala iroyin la ti gbo pe adajo majisreeti kan nipinle Eko ti pase pe ki omokunrin eni odun meedogbon kan, Benjamin Akegh loo faso penpe roko oba fun odun kan gbako lori esun ole jija.

Lasiko ti isin irole n lo lowo ninu ijo Redeemed Christian Church of God, Tabernacle of Peace lagbegbe Oluwole Baker, Thomas Estate, Ajiwe, lojo ketadinlogbon osu kinni odun yii la gbo pe olujejo huwa naa.

Benjamen, eni to sese ti ewon de lori esun ole jija kannaa la gbo pe o ti tu telifisan alademogiri ti owo re je egberun lona ogoji naira to si je ti Pasito Ayodeji Adeniyi ni nnkan aago mejo ale ojo naa ko too di pe ara ijo kan ka a mobe.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti

Osu meta gbako ni odomokunrin eni odun mejilelogun kan, Ojo Ayomide yoo lo lewon, latari esun jibiti ti ajo to n gbogun ti iwa ajebanu lorile-ede Naijiria, iyen Economic and Financial Crime Commission, EFCC fi kan an.

Ojoru tii se Weside la gbo pe ile ejo giga to fikale siluu Abuja, eyi ti Onidajo N.E. Maha je oludari e gbe idajo naa kale, to si ni esun ti won fi kan Ayomide fidi mule, ati pe ojulowo ni.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe oruko Onimo-ero kan ni United States, eni to fi Miami, Florida sebugbe ni Ayomide fi n lu awon eeyan ni jibiti lori ayelujara, fun idi eyi, o ni lati jiya ese re labe ofin.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Idaraya

Bi ki i ba a she opelope awon eleyinju aanu kan ni, boya won ki ba ti dana sun odomobinrin arewa kan, ti won pe oruko re ni Laurenta, eni ti won loo wo oteeli lo, to si lo o ji okan lara awon amohunmaworan, iyen telifishan ti won lo n lo nibe.

Oteeli kan ti won pe ni Kevleyn, eyi to wa nipinle Delta la gbo pe Laurenta loo ji gbe, ati pe oun peluu orekunrin re kan, tiyen ti na papa bora ni won jo gbimo papo ji telifishan naa gbe.

Iwe Irohin Yoruba gbo pe ose kan gbako ni Laurenta ati orekunrin re fi n gbe ni oteeli naa, latari owo ti won san sibe, ti won si n gbadun ara won daadaa.

Won ni inu baagi nla kan ti won n pe ni ''Ghana Must Go'' ni Laurenta gbe telifishan naa pamo si, asiko to si n gbe e jade ni lawon esho daa duro lati beere nnkan to wa ninu baagi naa, to si lawon eru tawon gbe debe ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti L'edo

She lopo awon eeyan kawo mori nipinle Edo laipe yi nigba ti ileeshe aabo ti otelemuye (DSS) foju awon gendekunrin meji kan ti won ni won ko nishe meji ju jibiti ori ayelujara, iyen Yahoo-Yahoo lo, to si je pe oruko Iyawo Aare orileede yi, Aishat Buhari ati gbakeji Aare, Ojogbon Yemi Oshinbajo ni won fi n lu awon eeyan ni jibiti owo lori ayeluajra.

Awon mejeeji ni Amos Ehis Asuelimen ti won lomo ogbon odun ni, to si tun je akekoo fasiti Ambrose Alli leka eto okoowo (Business Administration ati Kelvin Godwin Ogashi toun je omodun mejidinlogun.

Igbakeji oga agba, Galadima Byange lo foju awon odaran yi han fawon oniroyin l'Ojobo ana nipinle Edo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein

Ojo gbogbo ni tole, ojo kan ni tolohun. Owe yii lo se mo awon afurasi odaran merin kan towo ileese olopaa ipinle Kwara te pe won maa n gba ogunlogo owo lowo awon araalu pe awon yoo ba won wa ise ijoba nipinle naa, to si je pe ogbon ati ete lati lu won ni jibiti ni.

Ojo Isegun, Tusde, ose to koja ni ileese olopaa ipinle Kwara safihan awon afurasi odaran mereerin naa fawon akoroyin pelu esun pe nise ni won ka awon ayederu leta igbanisise awon ileese ijoba apapo ati tipinle Kwara mo won lowo.

Lara awon leta naa ni ti ajo to n ri si irin-ajo Hajj lorile-ede yii (Nigeria Hajj Commision), ileese 'Nigeria Port Authority', ileese 'Kwara State Teaching Service Commission', 'Kwara State Universal Basic Education Board', ajo SUBEB atawon mi-in.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Friday Paro Pe Won Ja Tanka Epo Gba Lowo Oun, Lo Ba Loo Ta a Sona Jebba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Kayode Omotosho, Ilorin

Friday Paro Pe Won Ja Tanka Epo Gba Lowo Oun, Lo Ba Loo Ta a Sona Jebba

Pelu bi ori se n ta awon omo orile-ede Naijiria fun bi epo bentiroolu se won bii imi eegun, ileese olopaa ipinle Kwara ti mu awako tanka epo kan ti oruko re n je Friday Joseph, eni odun metadinlogbon lori esun pe o paro, o si tun lu jibiti.

Ojo Isegun, Tusde, ose to koja ni ileese olopaa ipinle Kwara wo Friday lo siwaju Adajo K.A Yahaya. Esun ti olopaa to n soju ijoba nile-ejo, Inspekito Matthew Ologbonsaye, fi kan Friday ni pe nise ni okunrin yii fi ese ara re rin wa si tesan olopaa to wa ni Omu-Aran, lojo kerindinlogbon, osu keta, odun yii, ni nnkan bii aago mokanla oru pe awon adigunjale merin kan da oko tanka epo Mack toun n wa, eyi ti nomba re je AKD 518 XL ti epo bentiroolu egberun metalelogbon lita wa ninu re, eyi ti owo re le ni milionu merin ati aabo naira(#4,587,000.00) duro, ti won si ja a gba lowo oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Tunmise Ji Kaadi ATM Ore e Ni Saki, Owo Nla Lo Fi Wo Jade
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Tunmise Ji Kaadi ATM Ore e Ni Saki, Owo Nla Lo Fi Wo Jade

Loooto lowo ti te omobinrin akekoo ileewe gbogbonise Poli Oke-Ogun to wa nipinle Oyo, Tunmise Isola, lori esun pe o ji kaadi ATM omobinrin kan ti won jo n gbe, Suleman Nafisat Oluwatoyin, sugbon oju boro ko gba omo lowo ekuro loro naa komobinrin ohun too pada jewo nigba ti won wo o de odo awon agbofinro.

Omo orukan ni Oluwatoyin ti Tunmise ji kaadi re yii, ko si ti i ju ojo merin lo ti won mora won ti Tunmise fi se bee gba egberun marundinlogota (55,000) ninu egberun lona igba o le die tomobinrin naa ni ninu asuwon re. Alaye ti Nafisat se fakoroyin wa ni pe oun ko ni oluranlowo kankan latigba ti awon obi oun ti ku, kaadi ipe loun n ta toun fi ran ara oun nileewe girama, kaadi ohun loun si ta titi toun fi ni egberun lona igba naira nipamo. O ni owo naa loun lero lati fi pari iwe oun nileewe ti won sese ti mu oun yii.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Olusiro-owo Gbe Owo Awon Osise Sa Lo L'Akoko
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Olusiro-owo Gbe Owo Awon Osise Sa Lo L'Akoko

Nnkan ko fararo rara niluu Ikare-Akoko lose to koja lo lohun-un pelu bawon osise eleto ilera niluu naa se fehonu han lori bi won ko se rowo osu kokanla gba leyin ti won nijoba ti sanwo ohun sinu asuwon banki tawon osise naa n lo.

Gege bi ohun ta a gbo, eni ti won lo je olusiro-owo-agba nileewosan ijoba ipinle Ondo to wa niluu Ikare-Akoko, Ogbeni Aminu Kamilu, ni won fesun kan pe o ledi apo po pelu enikan, ti won si jo gbowo ti won lo to bii milionu meje lara owo to ye ki won fi sanwo osu kokanla awon osise eleto ilera nileewosan ohun.

Awon osise ileewosan naa la gbo pe ara n fu, eyi to mu ki won bere si i yo olusiro-owo ohun lenu nipa bi won yoo se rowo osu kokanla gba, sugbon o saa n fi won lokan bale pe ki won ni suuru, laipe lowo won yoo te won lowo. Bee lawon osise ohun ko kuku mo pe ijoba ti sanwo won, sugbon to je pe olusiro-owo naa lo n lo agbara tire le won lori.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Dereba Bisoobu Fipa Ba Eni To Ja Lole Lo Po, Ladajo Ba Ran an Lewon N'Ilori
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Dereba Bisoobu Fipa Ba Eni To Ja Lole Lo Po, Ladajo Ba Ran an Lewon N'Ilorin

Ile-ejo majisreeti to wa niluu Ilorin nileese olopaa ipinle Kwara wo okunrin eni odun metalelogoji kan, Moses Atile James, to tun je dereba Bisoobu ijo kan to wa ni Oro lo lori esun pe o fo ile onile wole ni nnkan bii aago kan oru, o si tun ba obinrin to ja lole lo po pelu ipa lojo kerinla, osu keta, odun yii.

Nigba to n soro, agbenuso olopaa, Koburu Gbenga Ayeni, so pe awon esun meteeta (fifo ile, ifipa-ba ni lopo ati idigunjale) ti won fi kan afurasi naa lojo Isegun, Tusde, ose to koja, tako abala kan ninu ofin to de iwa odaran nipinle Kwara.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Owo Te Oladele To N Ta Ori Eeyan N'Ibadan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Owo Te Oladele To N Ta Ori Eeyan N'Ibadan

Pelu bi baba eni odun mejilelaaadota kan, Kamoru Oladele, atawon afurasi odaran egbe e ko se ri okoowo gidi mi-in se ju ki won maa ta ori eeyan atawon eya ara to je ti eeyan eleran ara bii tiwon, nigba ti won ba wa eya ara ajeji titi ti won ko ri i boro, boya omo ebi, ara tabi alabaagbe won ni won yoo pada maa lo lojo iwaju bi ko ba se opelope awon olopaa to tete fi panpe oba gbe won.

Niwon igba ti eya ara eeyan ko ti da bii eya ara moto tenikan le maa so pe oun fee ra tabi ta feeyan, A®gbon ni adape oruko ti Oladele ati okunrin kan to n je Mudashiru Adedokun pelu awon afurasi odaran egbe won to ku maa n pe ori eeyan. Bi ki i baa si i se pe eeyan je ara won, ti won yoo fi dunaadura odidi ori eeyan meeedogbon legbee re, ''agbon, agbon≈ naa ni won yoo maa daruko ti tohun ko si ni i mo pe emi odidi eeyan ti won daruko nni lo gbodo segbe; ki won too le ri iye iru agbon ti won n so naa, abi alaaye eeyan wo lo je gbe ori tie sile fawon adahunse.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Ile-ejo Pase Ki Won Yegi Fun David Fesun Idigunjale L'Ekiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ado-Ekiti

Ile-ejo Pase Ki Won Yegi Fun David Fesun Idigunjale L'Ekiti

Fun esun idigunjale ati bo se jewo pe loooto loun ti kopa ninu orisiirisii idigunjale, ile-ejo giga to wa niluu Ado-Ekiti ti pase ki won loo yegi fun David Olugboyega ti won fesun kan pe o ji owo to le die ni egberun merinla (14, 570).

Lasiko ti okunrin ohun foju bale-ejo, olopaa to soju ijoba, Alaba Adeyemi, salaye pe odaran naa se ese ohun logunjo, osu keta, odun 2013, lopopona Araromi, niluu Ikere-Ekiti. O ni odaran naa gbe awon ohun ija oloro bii ibon ati ada lati loo ja awon araalu kan lole owo won.

Gege bi alaye re, o gba egberun mejo naira lowo enikan toruko re n je Kola Owolabi, o gba egberun marun-un naira lowo Arabinrin Beatrice Olawumi, o si tun gba egberun kan naira le die lowo Idowu Abiodun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Baba Atomo Ji Yusuf Gbe l'Ajase-Ipo, Nigba Ti Won Ko Rowo Gba Lowo e Ni Won
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Baba Atomo Ji Yusuf Gbe l'Ajase-Ipo, Nigba Ti Won Ko Rowo Gba Lowo e Ni Won Pa a

Ileese olopaa ipinle Kwara ti taari awon afurasi odaran meta kan, Dore Mohammadu, eni odun marundinlaaadorun-un (65) atawon omo re meji, Shehu Mohammadu to je eni ogun odun ati Mohammadu Bello, eni odun marunlelogun ti gbogbo won n se ise daran-daran lo si kootu lori esun pe won ji eeyan gbe, won si tun seku pa onitohun.

Gege bi agbefoba to n soju ijoba ni kootu, iyen Inspekito Isaac Yakub, se so niwaju Adajo T. Osuolale Ajayi, o ni okunrin kan toruko re n je Shehu Madaki to n gbe ni ago awon Fulani, ni Ajase-Ipo, lo mu esun lo si tesan olopaa pe lojo karundinlogbon, osu kesan-an, odun yii, se ni omo oun toruko re n je Yusuf Chede lo si oja Kara to wa ni Ajase-Ipo, ti ko si pada wale mo. Baba naa salaye pe gbogbo akitiyan oun lati pe omo naa lori foonu lo ja si pabo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Olumide Lu Egbon Iyawo Re Ni Jibiti Milionu Mesan-an l'Agbado
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayinka Adedayo

Olumide Lu Egbon Iyawo Re Ni Jibiti Milionu Mesan-an l'Agbado

Nitori ti Olumide Ogunbolude lu ana re, Ogbeni Taiwo Elegbede, ni jibiti owo to le ni milionu mesan-an naira (N9.105m) lo se n kawo ponyin rojo nile-ejo majisreeti to wa l'Ebute-Meta, niluu Eko.

Gege bi akosile ile-ejo, inu osu kewaa, odun 2013, nisele naa waye laduugbo Ogo-Oluwa, lagbegbe Alagbado, niluu Eko, nigba ti egbon iyawo olujejo so o leti re pe oun fee ra moto, niyawo to n wa rere foko re ba ni Olumide n ta moto. Kia ni Ogbeni Taiwo ti ko egberun mokandinlogoji ati eedegbeta owo dola ($39,500) fun un lati ba a ra oko Range Rover, ko si pe to tun fi milionu kan ati eedegbeta naira (1.6m) kun owo naa, ti apapo re fi le milionu mesan-an (N9.105m).


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Won Ji Aso Ati Owo Awon Omolooku n'Ilesa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesa

Won Ji Aso Ati Owo Awon Omolooku n'Ilesa

Titi di asiko yii lo si n se awon ebi Oloogbe Oladipupo atawon ti won waa ba won sayeye ni kayeefi pelu bawon eeyan kan se wole, ti won si ji egberun lona ogun naira awon omo olokuu lojo ti won n sinku baba won nijoba ibile Oriade, niluu Iwoye, n'Ilesa, l'Ojobo, Tosde, to koja.

Yato si owo yii, awon nnkan ini awon omo olokuu la tun gbo pe awon ole naa gbe lo lai bikita pe awon eeyan naa n sofo eni won to ku lowo.

Iwadii akoroyin wa niluu naa fidi e mule pe ilu Eko ni Oloogbe Oladipupo ku si leyin aisan ranpe, ko too di pe won gbe e wa siluu won lati waa sin.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Iwaju Soosi Ni Wanger Ti Ji Oko Gbe Lojo Sannde N'Ilorin, Lo Ba Ta a Siluu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Kayode Omotosho, Ilorin

Iwaju Soosi Ni Wanger Ti Ji Oko Gbe Lojo Sannde N'Ilorin, Lo Ba Ta a Siluu Benue

Awon agba bo, won ni Olorun atijo lo maa n pe e mu eeyan, sugbon tode oni, kiakia ni.

Bee gele loro ri fawon afurasi odaran meji kan,Tehemba Wanger ati ore re, Olusegun Babatunde ti inagije re n je German, eni ti won jo gbimo-po ji oko oloko to je Toyota camry ti nomba re je Kwara AG 708 ARP gbe sa lo niwaju soosi 'St.James Catholic,' to wa laduugbo Taiwo Isale, niluu Ilorin, ti oni nnkan gbe e si.

Nigba to n safihan won nile-ejo, agbefoba to gbenuso fun ileese olopaa, Inspekito Hassan Jubril, salaye pe okunrin kan toruko re n je Michael Chukwu lo mu esun to ileese olopaa wa pe won ji oun loko O ni okunrin naa so pe leyin tawon se oore-ofe tan ni nnkan bii aago mefa irole ojo kokandinlogun, osu kin-in-ni, odun 2014, toun bo sita pe koun loo gbe moto nibi toun paaki e si loun ri i pe won ti ji oko tiye owo re to milionu kan naira ohun gbe sa lo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Owo Olopaa Te Awon Omo Ibo To n Jale N'Ibadan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Owo Olopaa Te Awon Omo Ibo To n Jale N'Ibadan

Owo palaba awon omo Ibo ti won maa n dena de awon to ba loo gba owo nla ni banki n'Ibadan ti segi. Nibi ti won ti n gbiyanju lati fi ibon gba egberun lona eedegbeta naira (N500,000) ti okunrin kan to n je Ambali Lawal sese gba nileefowopamo lowo awon agbofinro ti to won.

Bo tile je pe ohun ti eeyan ko le so pe ki enikeni maa se ni Lawal se lojo naa, igboya ti okunrin naa ni lo ran an lowo pelu bo se je pe ariwo ole to pa le won lori lo koba awon afurasi adigunjale naa pelu bi awon olopaa se sare debe, ti won si mu meji ninu won lai je pe won ri erongba won muse.

Awon afurasi adigunjale ohun, Ebere Akanya ati Akpan Eyinnaya pelu eni keta won ti won n pe ni Spido, eni tawon olopaa si n wa lowo ni won loo da okunrin kan to n je Ambali Lawal, eni to sese gba owo nileefowopamo lona adugbo Academy, Iwo Road, n'Ibadan, lona lati gba owo naa lowo e, sugbon ti oro naa ko bo si i fun won.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Ise Ode Ni Won Gba Sunday Fun, Lo Ba N Sagbodegba Fole
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Ise Ode Ni Won Gba Sunday Fun, Lo Ba N Sagbodegba Fole

Owo awon olopaa ilu Abeokuta ti te okunrin eni odun mejidinlogoji kan, Sunday Uche, to n sise ode atawon merin mi-in lori esun pe won ji moto gbe, bee ni won tun fee fipa ba obinrin to ni moto naa lo po.

Awon yooku towo te pelu Sunday ni Mohammed Aliu, Odeh Benedict, Akinniyi Ademola ati Sikirulai Ojulari. Agbo pe awon adigunjale naa wa lara awon to n yo awon eeyan agbegbe Ijaba, Iyesi Ota, Itele ati gbogbo Ado-Odo lapapo lenu.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Nibi Ti Oni Atawon Egbe E Ti Fee Ta Eru Ti Won Ji Lowo Ti Te Won N'Ibadan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq

Nibi Ti Oni Atawon Egbe E Ti Fee Ta Eru Ti Won Ji Lowo Ti Te Won N'Ibadan

Olawale Ajao, Ibadan Adanu ti iba se obinrin ontaja kan loja Sango, n'Ibadan, ti pada sori awon obayeje eeyan to fee ba a laye je pelu bi awon odomokunrin merin kan ti won ti so ole jija di ise se ja ilekun soobu re wole, ti won si ko gbogbo oja to wa nibe pata, sugbon towo awon olopaa pada te won, ti won si da gbogbo dukia obinrin onisowo naa pada fun un.

Laaaro ojo Aiku (Sannde), ojo ketadinlogbon, osu kesan-an, odun yii, nigba ti onikaluku awon ontaja ti gbe ilekun soobu won ti pa fun ijosin ojo naa tabi isinmi opin ose ni okunrin eni odun merindinlogbon kan, Godbless Oni, ko awon emewa e meta ti won n je Alaka Babatunde (eni odun metalelogun), Jamiu Alabi (eni odun mejidinlogbon) ati Benjamin Segun, eni ti ko ju omo odun mejidinlogun pere lo, ti won si loo ja ilekun awon soobu ti won ti n ta awon ohun eso ara, ni won ba ko gbogbo oja ti won ba nibe lo pata.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Iru onijibiti wo waa ni Lola yii, awon onisowo meta lo lu jibiti owo nla
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Iru onijibiti wo waa ni Lola yii, awon onisowo meta lo lu jibiti owo nla

Okunrin onisowo kan, Lola Anjorin, eni odun mejilelogoji ti n kawo ponyin rojo nile-ejo majisreeti Ebute-Meta bayii pelu bi aago re se kun lori esun ti won fi kan an pe o lu awon alaabasisepo e ni jibiti owo goboi.

Gege bi a ti gbo, loju ona Ogudu, l'Ojota, ninu osu karun-un, odun 2012, ni Lola ti koko bere jibiti re pelu bo se foruko ileese re, 'Bonvic Gold Oil Limited', gba okunrin kan to n je Kenneth Eromosele to je asoju ileese 'Minel Petroleum and Gas Ltd' nigba tiyen ja disu milionu mokanlelogun naira (N20, 920,000) fun un. O fun olupejo ni sowedowe oja to ra, sugbon iyalenu lo je fun iyen pe ko rowo ohun gba, bee ni ko ri olujejo debi ti yoo ri oja re to ta fun un gba.

Boya bi Lola se ri i pe oun ti mu iyen je lo je kile ta si i dojo kewaa, osu kefa, odun to koja, to si tun se iru e fun Basil Ogoha to je alaga 'Starby International Nigeria Limited' pelu bo se gba disu milionu mesan-an (8.9m) naira, to si tun gbe sowedowe ti ko sowo ninu akaunti e le e lowo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Titilayo foju bale-ejo nitori esun ole
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olowoake LatifTitilayo foju bale-ejo nitori esun oleObinrin onisowo eni odun mokandinlogoji kan, Titilayo Ilesanmi, ti n kawo ponyin rojo nile-ejo majisreeti to wa ni Surulere lori esun pipe ara e ni ohun ti ko je lati ya owo to to milionu kan ataabo naira nileefowopamo 'ACCION Microfinance Bank Ltd', pelu ileri lati da a pada fun won, sugbon to ko lati se bee.

Obinrin naa to n gbe lojule kokanlelogorin, laduugbo Akerele, ni Surulere, l'Ekoo ni won wo lo sile-ejo lori esun meta otooto, iyen ole jija, fifipa gba nnkan lowo eni ati fifi iwe sowedowo ti ko wulo kale fun ileefowopamo to yawo lowo e.

Agbenuso ijoba, Koburu Jimah Iseghede, ni isele ohun waye lojo ketadinlogun, osu kokanla, odun to koja, lojule ketadinlogorin, loju ona Ojuelegba, Surulere. Nise ni afurasi naa lo si ofiisi 'ACCION Microfinance Bank Ltd' lati ya milionu kan ataabo naira (N1.5m) pelu ipinnu lati sanwo naa pada fun won lojo kejidinlogun, osu kejila, odun to lo, sugbon to ko lati se bee.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Leyin ti Sunday sa kuro lewon lo tun loo jale l'Ekiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Solomon Adewoye, Ado-EkitiLeyin ti Sunday sa kuro lewon lo tun loo jale l'EkitOwo ileese olopaa ipinle Ekiti ti te Sunday Adegboye, ogboju ole to wa logba ewon, sugbon to sa lo to tun pada loo jale, afaimo si ni ko ma pada sewon naa bayii.

Esun idigunjale ni won tori e ju Sunday sewon sugbon o sa kuro nibe lodun to koja, iyen lakooko tawon kan loo fo ogba ewon naa. Leyin ojo karun-un to sa jade lo tun bere ise idigunjale re, sugbon owo pada te e.

Gege bi komisanna awon olopaa nipinle Ekiti, Ogbeni Taiwo Lakanu, se so, nise ni Sunday loo ja Ogbeni Akingbinsola Feyi to n gbe lagbegbe Ori Apata, Adebayo, l'Ado-Ekiti, lole lojo karun-un, osu kejila, odun to koja, ni nnkan bii aago mewaa aabo ale, eyi to mu kawon eeyan kan ta awon olopaa lolobo, owo si pada te e.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Owo te omo igbakeji komisanna olopaa pelu opolopo ohun ija oloro ni Kwara
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Iroyin Yoruba

Leyin wakati merinlelogun ti ileese olopaa ipinle Kwara sawari oko tirela kan to ko awon ohun ija oloro lose to koja lagbegbe Kosubosu, nijoba ibile Baruten, nipinle Kwara, panpe won tun ti mu odomokunrin akekoo-jade ‘Ajayi Crowther University' tilu Oyo kan, Momoh Ogirimah pelu opolopo ohun ija oloro.

Odomokunrin ohun to n kekoo nipa imo-ero (Industrial Engineering) nileewe giga naa salaye pe baba oun to je igbakeji komisanna olopaa to ko iko sodi loo koju awon egbe okunkun ‘Ombatse' ti won n da wahala sile nipinle Nasarawa ni nnkan bii odun meji seyin, sugbon to ba ogun lo, lo ni gbogbo awon ohun ija oloro ti won ba lakata oun naa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Leyin ti won ja iyawo re lole, awon ole yinbon pa Baba Zainab l'Ogbomoso
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Leyin ti won ja iyawo re lole, awon ole yinbon pa Baba Zainab l'Ogbomoso

Nise ni ariwo ekun so nile enikan ti won n pe ni Azeez, ti opo eeyan tun mo si Baba Zainab laduugbo BB, Stadium, niluu Ogbomoso lojo Satide ose to koja nigba tawon adigunjale yinbon pa a.

Gege bi iwadii akoroyin wa niluu Ogbomoso, eedu ni iyawo Azeez n ta, bee toro-kobo ti won n ri ni oun ati oko re fi n gbo bukaata. Nise lawon adigunjale yii ba awon ara adugbo lalejo oran lati oru ojo Eti, Fraide, moju Satide, ose to koja, bee ni won de ile Baba Zainab.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

L'Ekoo, awon ole koju olopaa obinrin, niyen ba gbabon lowo won
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

L'Ekoo, awon ole koju olopaa obinrin, niyen ba gbabon lowo won

Nnkanko senuure fawon afurasi adigunjale kan l'Ojoru, Wesde, ose to koja yii nigba ti won kolu obinrin olopaa kan ati elomi-in laduugbo Tawakalitu, Orisunmibare, Egbeda, niluu Eko.

Ni nnkan bii aago mefa aaro lawon afurasi ohun deede yo si Sajenti Mercy John ati eni keji pelu okada, won si ni ki won doju bole ti won ba ni emi won i lo.

Nigba tawon eeyan ohun ni ki Mercy gbe baagi owo re wa, o ko jale, sugbon eni keji gbe tie sile pelu iberu. Asiko yii ni okan ninu awon afurasi ohun yo ibon ilewo kan jade.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Kabiru dero ogba ewon, omo odun mokanla lo fipa ba lo po
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Kabiru dero ogba ewon, omo odun mokanla lo fipa ba lo po

Bi won se n ge awon afipa-bani-lo-po lowo ni won n bo oruka, iyen loro to gba enu awon ero kootu majisreeti karun-un to n jokoo l'Abule–Egba, nipinle Eko, nigba tawon okunrin agbalagba n se bee ba aye awon omo kekere je, paapaa awon omo ti ojo ori won ko ti i ju mokanla lo.

Kabiru Ibrahim, okunrin eni odun mokandinlogoji lo tun n kawo ponyin rojo ni kootu naa l'Ojobo, ojo karun-un, osu yii, lori esun pe o fipa ba omobinrin eni odun mokanla kan sun nile re to wa lojule ketalelogun, opopona Jinadu, l'Agege, to si se bee gba ibale omo naa pelu ipa. Esun to n jejo re ohun lo mu ki adajo pase pe ki won loo fi i pamo si ogba ewon Kirikiri di ojo keeedogbon, osu yii, nigba ti igbejo yoo maa tesiwaju. Gege bi alaye ti olopaa naa, Abileko Rachael Williams, se ni kootu, ojo kerindinlogbon, osu kin-in-ni ni, ni omodebinrin ti won ko daruko re naa atawon ore re kan loo sere nile awon Kabiru, bi won si ti n sere ohun ni okunrin yii pe omodebinrin naa, o si mu un wo yara re lo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Ayederu Owo Dola Ati Naira Nileese Olopaa Ka Mo Haruna Atawon Emewa E Lowo N
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Ayederu Owo Dola Ati Naira Nileese Olopaa Ka Mo Haruna Atawon Emewa E Lowo N'Ilorin

Owo palaba awon afurasi meta kan, Mohammed Haruna, Kayode Abdulrauf ati Oladele Olaniyi, segi laarin ose to koja yii, nigba tileese olopaa ipinle Kwara ba ayederu owo dola ati naira tabua lowo won, lojo kerindinlogun, osu kefa, odun yii, eyi ti won n lo lati maa fi lu awon araalu ni jibiti.

Gege bi komisanna ileese olopaa nipinle Kwara, Ambrose Aisabor, se so lasiko to n safihan awon afurasi ohun, o salaye pe awon olopaa to n so opopona Jebba atijo lo da oko Toyota akero kan tawon afurasi ohun wa duro lati sayewo gege bii ise won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Leyin Odun Kan To Tewon De, Owo Tun Te Musa Nibi Idigunjale
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluyinka Soyemi

Leyin Odun Kan To Tewon De, Owo Tun Te Musa Nibi Idigunjale


Nnkan ko senuure fun omokunrin eni odun mejilelogun kan, Musa Ojo, nitori bi owo awon olopaa se tun te e fun esun idigunjale leyin odun kan to jade lewon. Nibi toun atawon mi-in ti won ti sa lo bayii ti ji oko Toyota Corolla to ni nomba LSR 587 AR gbe lomi ti teyin wo igbin lenu fun un.

Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba, Musa ti awon to mo on maa n pe ni 'Agba Musa' wa lara awon igba o le metalelogbon (233) elewon ti Adajo-agba ipinle Eko, Onidaajo Ayodele Philips, tu sile logba ewon Kirikiri ni osu kesan-an, odun to koja. Odun kan aabo lo ti lo lewon ki won too dariji i, sugbon nise lo pada si ise laabi re yii.

Ojo kerinla, osu kesan-an, to koja yii loun atawon meji ti won jo n jale gba Toyota Corolla kan, nigba ti won si de agbegbe Ijesha, lona Apapa si Oshodi lawon olopaa to n gbogun ti idigunjale ri won, bee ni won bere si i le won. Nigba ti oro fee yiwo ni won be sile, ti won sa lo, sugbon owo te Musa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Owo Olopaa Te Dimeji To N Ji Okada
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Owo Olopaa Te Dimeji To N Ji Okada

Nnkan ko senuure fun omokunrin eni odun mokandinlogbon kan, Oladimeji, towo awon olopaa te lori esun idigunjale, oro to si n ti enu e jade n se awon eeyan ni kayeefi.

Dimeji ni nitori enikan ti ja oun lole ri loun naa se gbodo di adigunjale ki oun le gbesan oro ti won da oun, sugbon o gbagbe asayan oro awon agba pe oro to o da mi ni mo da o ni ki i je ki oro tan nile. O ni iru iwaasu bee ko si ninu iwe owe toun, owe kan soso toun mo ni pe bi adie da oun loogun nu, oun yoo fo o leyin, bi adie ohun ko ba ye eyin, oun yoo fo ti adie mi-in di i lai mo pe atimole olopaa ni ero buruku bee yoo gbe e de.Ise okada ni Oladimeji n se nigba kan ri, sugbon lojo kan lole da a lona to si ji okada naa gbe mo on lowo.

Lati ojo naa ni jagunlabi ti pinnu pe oun ko ni i sise mi-in mo laye oun, afi ise ole, ko si si nnkan mi-in ti oun yoo maa fipa gba lowo awon eeyan ju okada.Yoruba bo, won ni eni ti yoo ba sowo ale, dandan ni ko ra eni atin-in. Ko pe ti okunrin to pera e lomo bibi ilu Ogbomoso yii bere ole jija lo wa ibon ilewo kan, n lo ba kuku sora e di adigunjale loju paali nitori bi ibon se te e lowo lo tun mu awon ole peepeepe mi-in mo on, bii ko deede ja wo ibi ti awon omo ileewe LAUTECH l'Ogbomoso ba po si, ko si fibon gba ero ibanisoro won pata.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Tirela To Ko Opolopo Miliiki Ni Won Da Lona L'Ekoo, Nibi Tawon Ajayi Ti N J
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Tirela To Ko Opolopo Miliiki Ni Won Da Lona L'Ekoo, Nibi Tawon Ajayi Ti N Ja A Sile N'Ibadan Lowo Ti Te Won

Leyin ti won ti fipa gba oko tirela kan to kun fun miliiki iyefun lagbegbe Berger, l'Ekoo, owo awon agbofinro ijoba ipinle Oyo ti won n pe ni Operation Burst ti te Yemi Ajayi, okan ninu awon adigunjale ohun ti won maa n fipa ja awon oko tirela gba kiri.

Oko eru nla to ni nomba KRD 343 KD to je tileese akeru KK Global Nigeria Limited lo n ko miliiki kurugbe to to egberun meta o le metalelogosan-an lati Eko lo si Ibadan, ti awon obayeje eeyan naa si gba eru towo e to milionu lona ogun naira ohun. Ati eru, ati tirela to gbe e lawon eruuku fibon gba ni nnkan bii aago mesan-an ale Ojobo, Tosde, ojo kokanlelogun, osu kesan-an, odun yii.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, mefa lawon adigunjale naa. Aso soja ati aso olopaa ni won wo ti won si duro si oju titi ona Eko s'Ibadan lati le fi tan awon awako ti irin-ajo won je mo ona naa. Bi awako eru yii se de odo won ni won wo o ju sile ti won si gbe oko re sa lo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Ori Ko Fijilante Yo Lowo Awon Adigunjale L'Ajaawa, O Ni Opelope Ajesara
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Abayomi Akanni, Ogbomoso

Ori Ko Fijilante Yo Lowo Awon Adigunjale L'Ajaawa, O Ni Opelope Ajesara

Kaka ki ewe agbon iwa idigunjale ro nile wa, nise lo tun n le koko si i, bee si ni pe eni ti Olorun ko pa kan ko ni i ku. Oro yii lo se regi lojuna bi ori se ko okunrin kan toruko re n je Simon Oyeleke to je okan ninu awon egbe fijilante eka tijoba ibile Guusu Ogbomoso yo lowo eleko orun ti i ba polowo iku fun un latowo awon adigunjale mejo kan to yin in nibon, sugbon ti ko ran an lojo Abameta, ojo kokanlelogun, osu kesan-an, odun yii. Agbegbe Ayegun Ikolaba, lopopona Ajaawa, nijoba ibile Ogo Oluwa nisele naa ti sele.

Ninu oro Ogbeni Simon Oyeleke to ba Iwe Iroyin Yoruba so lofiisi won to wa lagbegbe Kolara, nijoba ibile Guusu Ogbomoso, o salaye pe ko salagbara kan ayaafi Olorun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: