Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

EsinIslam Media: Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o

Medinat Adesoye

Ile ejo majisreeti ti o tedo si ilu Osogbo ti ni ki arabinrin kan ti oruko re n je Jimoh simiat lo ma gba afefe logba ewon lori esun pe o pa Mama Friday ti won ri oku re ni Oke Osun nilu Osogbo.

Inspekito Mustapha Tajudeen to soju ileese olopa salaye pe lojo kewa osu keji, odun yii ni deede ago meje abo owuro ni agbegbe ile iwe giga Fountain university, ni ilu osogbo ni Simiatu ba Esther Oga to je ore re ja titi ti emi fi bo lenu e.

Inspekito naa so pe afurasi naa ti se lodi si abala 316, ti o si le fi iya je ni abala 319(1), ofin iwa odaran ipinle osun ti odun 2002.

Nigba ti adajo kootu beere oro lowoo Simiatu, o lojo kesan osu keji odun yii ni oun loo ba ologbe naa ni ile lati beere pe se loooto lo so fun oko re, iyen Baba Friday pe olosho ni oun, ti Baba Friday naa si tun so oro naa fun oko toun.

Simiatu ni oro naa lawon loo yanju nidi ogede lojo naa, tawon si tuka.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku

Se loro di boolo o yago laaro ojo Aiku Sande oni nigba ti won lawon baale ile meji kan ti won yan ise agbase se laayo nipinle Ekiti ko sinu konga lasiko ti won n gbiyanju lati yo foonu to jabo sinu konga naa.

Abule kan ti won pe Anaye to wa nijoba ibile Emure la gbo pe isele naa ti waye. Foluso Ajayi ti won tun n pe ni Vosco ati okunrin kan topo awon eeyan n pe ni Alaaji, eni ti won lomo Ebira nipinle Kogi ni lawon meji naa ti a gbo pe foonu lo ran won lo sorun alakeji.

Ohun ti a gbo ni pe okan lara awon meji lo n gbiyanju lati pon omi to fee lo lati dana, asiko naa la gbo pe eni kan pe e lori foonu e, bo si se n gbiyanju lati yo o ni foonu naa jabo sinu konga ti won loo jinna gan an.

Bi foonu naa se jabo la gbo pe o gbiyanju lati yo o, sugbon se ni won so pe ese yo geerege to si fee jabo sinu konga naa, eyi lo mu ki ekeji e naa sare debe lati doola e, to si je iyalenu pe se lawon mejeeji jo jabo leekan-naa.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re

Senken bayii lowo olopaa ipinle Akwa Ibom te Baale ile kan, Idorenyin Essien, eni odun marundinlogoji ti won loo dana sun omo re latari esun to fi kan omo naa pe o ji owo oun, eedegbeta naira gbe.

Bo tile je pe "ise esu ni" loro ebe to n tenu Essien jade, sugbon sibe, epe rabande lawon eeyan n gbe okunrin naa se lori iwa odaju to hu naa, ti won si n be awon olopaa pe ki won rii daju pe won ran an lo sewon gbere.

Agbegbe Afia Nsit to wa nijoba ibile Eket nisele naa ti waye lojo Fraide ose to koja yi, sugbon to je pe ana Tuside lawon olopaa fidi isele naa mule leyin towo palaba Essien segi.

Alukoro ileese olopaa ipinle naa, Odiko Macdon nigba to n fidi oro naa mule bu enu ate lu iwa ti Essien hu naa, to si lawon ko ni i foju aanu wo rara, ati pe gbogbo ona ti ile ejo yoo fi gbe idajo ododo kale lawon yoo gba nitori pe elese kan ko nii lo lai jiya.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya

Titi dasiko ta a shakojopo iroyin yi tan niku odomokunrin eni odun metadinlogbon kan, Ismaila Ogunshola shi n je kayeefi fawon eeyan, paapaa awon araalu Owode Egba, nijoba ibile Obafemi/Owode, ipinle Ogun lori bi won she so pe ojo idun Ileya to koja yi ni won pe e, to si je pe nigba ti won maa pada ri, oku e ni won ri.

Ki i she pe bi Ismaila ti won loo fi odun meje gbako ko ishe telo she ku lo n je kayeefi fun gbogbo eeyan, paapaa awon ara agbegbe Owode, bi ko she bi won she ba oku e lori igi Mango, ti won tun de e lapa ati ese, ti won si tun sokun mon on lorun gan an lo n je edun okan fawon araalu, paapaa awon ebi re.

Gege bi a she gbo, won ni odun meji seyin ni won so pe Ismaila gba aaye lodo oga re to ko o nishe telo, iyen Ogbeni Sulaimon Abisoye niluu Owode Egba lati fi wa owo ti yoo fi she firidoomu, idi ni yii ti won loo fi wa ibi to ti n shishe logba osin (poultry) kan to wa lagbegbe Malaaka, opopona Adejoin, Owode kan ni nnkan bi oshu mesan seyin.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle Ogun Teleri Ku Lokiji

Titi dasiko ti a ko iroyin yi tan, lawon eeyan shi n fi oro ibanikedun ranshe si Komishana foro epo robi ati idagbasoke, iyen Oil Producing Area Development Commission (ASOPADEC) nipinle Abia, Onorebu Adeile Ekeke.

Ojo Sannde to koja ni Onorebu Ekeke padanu iyawo e ati omo meji sinu ijamba moto lopopona Enugu-Okigwe, lasiko ti won n rin irin ajo, ko too di pe ijamba naa waye lojiji.

Loju ese ni gbogbo won ti dagbere faye, to si mu kawon eeyan kawo mori.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewande To Gun Oko Re Pa Sile L'ewon

Ko seni to tete gbagbo nigba tiroyin kan jade sita pe omodebinrin omodun merinla kan, Favour gba emi ara re, nipa bo she pokunso, to si n jekayeefi nipa nnkan to ro debe.

Ipele kerin (SS1) la gbo pe Favour wa nileewe girama Kess College to wa ladugbo Ekredjebor lagbegbe Ughelli, to wa nijoba ibile Ariwa Ughelli, ipinle Delta.

Ohun ta a gbo ni pe orekunrin Favour lo ja a ju sile lojiji pe oun ko she mo, to si je pe gbogbo akitiyan ati igbese ti won ni favour gbe lati je ki ololufe re naa gba a pada lo ja si pabo, eyi lo fa a ti won loo fi pinu lati wo o pe iku ya ju esin lo.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja

Ko seni to le so pato ohun ti Lucky Bassey, eni odun mokandinlaaadota se fun iyawo re Grace, eni odun mokanlelogbon, ti ko se ro nnkan kan mi-in ro o ju pe ko da emi re legbodo lo pelu bo se fi obe idana dunbu re. Eyi lo mu kadajo ile-ejo majisireeti kan to wa l'EbuteMeta pase pe koun ati orekunrin re ti won jo gbimo-po seku pa oko re ohun si wa latimole ogba ewon to wa ni Ikoyi.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ni nnkan bii aago merin oru ojo keeedogbon, osu kin-in-ni, odun yii, nisele naa waye ni ojule ketalelogun, laduugbo Abari, n'Iyana-Ipaja, niluu Eko, iyen nigba ti Grace gbimo-po pelu orekunrin re to n je Benjamin Otu lati pa oko re ti won jo wa lati Akwa Ibom pelu obe idana. Ohun to si buru ju ninu oro naa ni pe oju oorun ni oko omobinrin yii wa tawon mejeeji fi pitu owo won.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure N
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure Ni Moto Te e Pa Si

Surusuru lomije n da loju awon eeyan to wa nibi toko akero kan ti te omokunrin eni odun meeedogbon kan pa l'Akure laaaro Ojobo, Tosde, ose to koja yii.

Gege bi alaye ti okunrin kan tisele naa soju re se fun wa nigba ta a sabewo si geeti ogba Fasiti Imo Ero (FUTA) to wa l'Akure leyin isele naa, o ni jeeje lokunrin toko te pa ti won poruko re ni Johnson Ogah n ta ipekere re nigba ti moto ohun sadeede loo ya ba a nibi to duro si, to si te e pa.

Oko boosi akero naa ti nomba idanimo re je Oyo XC 247 YYY to n bo lati Ileefe lo deede ya kuro loju ona tire nigba to de iwaju geeti Fasiti Imo Ero naa, to si se bee loo kolu awon moto mi-in to n lo ni tiwon, ko too waa te Johnson pa nibi to wa. Loju-ese lo ni omokunrin yii ti ku, bee ni ipekere to n ta fon soju titi nibe kaakiri.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Florence Babasola,Osogbo

O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo

Pelu iyanu lawon eeyan agbegbe Odeyemi, ni Kolawole, niluu Osogbo, n wo lose to koja nigba ti omokunrin kan deede dake lori opo ina to ti n so waya papo, sugbon nigba to di pe ko mira mo ni won figbe ta.

Redio la gbo pe Ismaheel Dauda n tun se lagbegbe naa, sugbon igbakigba ti ina ijoba ba ti yonu lori opo ni won maa n ranse si i ni soobu re to si maa n ba won se e.

Bii eni pe ara ti n ro ajalu fun un lojo naa ni nitori nigba ti ore re kan koko loo pe e pe ko waa ba won so ina awon IBEDC, a gbo pe se ni Dauda koko yari pe oun ko se. Sugbon nigba ti ebe po, o gba lati ba won se e, bee la gbo pe o loo wa akaba onirin kan to fi gun opo ina ohun.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Ofo Emi Kan Ree! Eefin Jenereto Pa Segun Alawaye Sinu Yara Ni Sagamu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Ofo Emi Kan Ree! Eefin Jenereto Pa Segun Alawaye Sinu Yara Ni Sagamu

Eefin jenereto la gbo pe o ti seku pa okunrin dereba kan toruko e n je Segun sugbon tawon eeyan mo si Alawaye niluu Sagamu.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, laaaro Ojoru, Wesde, to koja yii nisele naa waye laduugbo Oju;mele, niluu Sagamu, bee niyawo atawon omo e si n gba itoju lowo latari ijamba kan naa titi di akoko ti a n ko iroyin yii lowo.

Ohun ta a gbo ni pe okan lara awon ayalegbe ni Segun pelu iyawo atawon omo e nile alaja meta ti won n gbe, won lo ti pe ti okunrin naa ti maa n gbe jenereto e wole sibi ti ko si ategun ni egbe yara e, awon ayalegbe yooku si ti kilo fun un titi sugbon ko da won lohun.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

O Ma Se o: Ile Wo Pa Kafaya Arowosere l'Abeokuta, Bee Obinrin Naa Wa Ninu O
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

O Ma Se o: Ile Wo Pa Kafaya Arowosere l'Abeokuta, Bee Obinrin Naa Wa Ninu Oyun

Boya ka ni obinrin kan, Kafaya Arowosere, reni so fun un pe ile alapa kan to ti di egeremiti yoo wo pa a l'Ojobo, Tosde, ose to koja tomo-tomo ni, o see se ki obinrin olomo meji to ni oyun eketa sinu naa ma gba egbe ibe koja, sugbon ko seni to mo pe iru ajalu bee yoo sele, bo se di pe olojo de were to mu un lo pelu omo re, Ganiya, ati oyun ikun re niyen nigba tile naa deede da wo lojiji lagboole Onifufu, ni Ijeun Titun, niluu Abeokuta.

Eni odun metadinlogbon ni Kafaya Arowosere, Ganiya to n mu lo sileewe ti wahala naa fi sele ko ju omo odun marun- un lo.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ni nnkan bii aago mejo aaro nisele naa waye, ojo ti won lo ro moju ojo naa ni won lo sokunfa ogiri to wo yii nitori ile naa ti san sara tele, awon ile to si ti di egeremiti bee po laduugbo yii gan-an.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Bi Minisita Buhari Atiyawo Pelu Omo e Se Ku Sinu Ijamba Moto Ree
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Bi Minisita Buhari Atiyawo Pelu Omo e Se Ku Sinu Ijamba Moto Ree

A-gbo-sogba-nu niroyin iku ojiji to pa minisita abele foro awon osise lorile-ede yii, Ogbeni James Ocholi, iyawo ati akobi re lokunrin sinu ijamba moto to sele si won loju ona Kaduna si Abuja, lojo Aiku, Sannde, ijeta.

Lojiji ni Iwe Iroyin Yoruba gbo pe taya moto jiipu okunrin naa fo yo lori ere, ti oko naa si gbokiti leralera, leyii to sokunfa bi minisita ohun atomo e se padanu emi won lesekese.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Ija Ni Baba Joke La L'Orile-Iganmu, Lo Ba Gbabe Ku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Ija Ni Baba Joke La L'Orile-Iganmu, Lo Ba Gbabe Ku

Ogbeni Oladiran ti pade iku ojiji lasiko to n pari ija to waye laarin omo re, Olajoke Oladiran pelu Stanley Okere to je araadugbo won.

Nigba tomo baba naa n ba akoroyin wa soro leka to n topinpin esun ipaniyan nileese olopaa to wa ni Panti nipa iku baba e, Joke to je eni odun metadinlogbon so pe, ''Idi omi taapu to wa laduugbo wa ni Adisatu, l'Orile-Iganmu, ni mo lo laaaro ojo Isegun, Tusde, ojo kin-inni, osu keta, yii, lati loo ba aburo mi gbe omi wale. Bi mo se debe, mo ba awon omobinrin meji kan ati omo kekere kan pelu aburo mi nibe, lobinrin to n ta omi ba so fun awa ta a duro pe ka pon omi wa, ka ma duro de awon ti garawa omi won wa saaju tiwa lori ila.'' Leyin tawon omobinrin mejeeji pon omi won tan ti Joke ni koun gbe garawa omi ti aburo re gbe sori ila ni omo kekere kan to ni ko ju omo odun mejila lo so pe ko ma gbero lati se bee nitori boun se wa yii, oun lagidi gan-an, bee lomo naa beere pe se ko ya were?

Oro tomo naa so si Joke lo se so fun un pe boun ba ki i mole toun n na an, awon eeyan a so pe oun ri i lomode loun se n fiya je e. Oro yii ni Joke atomo ohun n fa lowo ti egbon re, Stanley Okere fi sunmo won lati da si i, to si gba Joke leti lori oro ti ko to nnkan

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori Owo Eja To Sonu, Kunle Gbe Ayoonu Gbigbona Le Omo Iyawo e Leyin N'Ib
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Nitori Owo Eja To Sonu, Kunle Gbe Ayoonu Gbigbona Le Omo Iyawo e Leyin N'Ibadan

Ko si eni ti yoo ri omokunrin eni odun mejila kan, Azeez Yusuf, lati ojo Aiku, (Sannde), ojo kejilelogun, osu kokanla, odun yii, ati leyin bii ose meji si asiko naa ti aanu e ko ni i se e pelu bi egbo nla nla se kun gbogbo eyin ati ejika re, ti inira si han loju omo naa gidigidi.

A®pa; to kun gbogbo ara omo yii ki i se ti pe o subu tabi pe o farapa nibi kan, apa ayoonu gbigbona ni, oko iya e to n je Kunle Anisere lo si han an leemo bee nitori pe o so egberun kan naira nu ninu owo eja yiyan to ba iya re kiri lo.

Leyin to ti koko lu u sugbon ti iyen ko te e lorun lo loo ki ayoonu bo ina, to si da a de Azeez leyin nigba ti kinni ohun ti gbona daadaa.

Amumora bii iso inu eku ni Azeez fi oro naa se titi di ojo keta tisele ohun han sita faye, nigba ti okan ninu awon ore e nileewe, iyen 'IDC Primary School', to n lo ni Gbagi, n'Ibadan sakiyesi pe ara re ko ya, to si bi i leere ohun to se e. Bo se jewo fun ore e yii niyen ti loo fi isele naa to oluko won leti, oluko naa ko si fi oro ohun bo to fi royin fun oga-agba ileewe naa.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Ibon Onike Ni Biola Atawon Ore e Fi Deruba Obinrin Ti Won Fipa Ba Lo Po n'I
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Ibon Onike Ni Biola Atawon Ore e Fi Deruba Obinrin Ti Won Fipa Ba Lo Po n'Ileefe

Adajo kootu majisreeti kan niluu Ileefe ti pase pe ki awon omokunrin meta kan loo se faaji odun Keresimesi won logba ewon latari esun pe won fipa ba omo odun metadinlogun lo po.

Awon omokunrin meteeta ti won fesun kan ohun ni Biola Akinwande, omo odun mejidinlogun Ayoola Awodile, eni odun meeedogbon< ati Sodiq Oyedele to pe ara re lomo odun mokandinlogun.

Gege bi agbejoro fun ileese olopaa lori esun yii, Koburu Ronke Badmus, se salaye fun ileejo, o ni ojo kejilelogun, osu kokanla, odun yii, lawon afurasi naa huwa ohun ni nnkan bii aago meji osan.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Kayeefi N'Ilorin: Baba Atawon Omo Meta Ku Sinu Ile, Won Ni Ege To Ni Majele
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Kayeefi N'Ilorin: Baba Atawon Omo Meta Ku Sinu Ile, Won Ni Ege To Ni Majele Ni Won Je

Nise ni adugbo kan ti won n pe ni Ogbondoko, to wa ni ona Afon, nijoba ibile Asa, niluu Ilorin, nipinle Kwara, kan gogo, tawon eeyan si n duro ni meji-meta lati jiroro lori nnkan to le fa sababi iku ojiji to deede pa odidi molebi kan run ninu ilu naa. Iwe Iroyin Yoruba sabewo si ilu ohun lati sewadii bi isele naa se sele.

Oru ojo Eti, Fraide, moju ojo Abameta, Satide ose to koja lohun-un nisele naa sele si idile okunrin kan ti won pe oruko re ni Baba Mokudi. Iwadii akoroyin wa fi han pe baba yii lo bi awon omo meta (okunrin kan ati obinrin meji) ti won ku pelu re ninu ile yii lojo naa. Gege bi a se gbo lenu awon eeyan ti a foro wa lenu wo laduugbo naa, sugbon ti won ko lati daruko won, won so pe se ni iya awon omo wonyi sadeede gbo ti won sunkun wa lati oju oorun loru ojo isele naa, eyi to mu un ji Baba Mokudi.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

O Ma Se o, Omo Iya Meji Jona Mole n'Ilesa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesa

O Ma Se o, Omo Iya Meji Jona Mole n'Ilesa

Igbe oro o, ikunle abiyamo lo gbenu awon to gbo nipa isele aburu to sele sobinrin kan tawon eeyan mo si Iya Victor to n gbe lopopona Fagbola, lagbegbe Isale Jenera, nijoba ibile Iwo-Oorun Ilesa, nipinle Osun, awon omo re mejeeji, Victor ati Williams lo sagbako iku ojiji lojo Aje, Monde, ose to lo lohun-un nigba tina jo won pa mole.

Iwadii Iwe Iroyin Yoruba fidi e mule pe Iya Victor tilekun mo awon omo e yii lateyin pelu agadagodo ni deede aago mejo ale ojo naa, o si jade lo sibi ti a ko mo lasiko ti a n ko iroyin yii jo.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori Indomie, Oluwaseun Gun Ore Re Pa l'Ondo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Indomie, Oluwaseun Gun Ore Re Pa l'Ondo

Se lawon oluworan ile-ejo majisreeti to fikale sagbegbe Oke-Eda, niluu Akure, lanu sile ti won ko le pa a de nigba ti won wo omokunrin kan toruko re n je Oluwaseun Ojo wa si kootu naa lori esun pe o gun ore ko-ri-ko-sun e pa lasiko ti won n ja si Indomie.

Isele naa la gbo pe o waye ninu osu kesan-an, odun ta a wa yii, laduugbo Familusi, lagbegbe Oke-Aro, l'Akure, iyen lasiko ti Seun gun ore re, Sola Omotayo, nigo pa nitori Indomie ti won n jiyan le lori.

Losan-an ojo buruku esu gbomi mu yii ni Sola ati Seun ti won jo n gbe inu yara kan naa se Indomie je.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Waya Ina Pa Iya Olomo Meji Ati Alabaagbe E L'Ekoo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Waya Ina Pa Iya Olomo Meji Ati Alabaagbe E L'Ekoo

Waya ina ti ja pa awon alabaagbe meji kan, Bashirat Rauf, eni to je iya olomo meji ati Sodiq Saka to n sowo igi tita, tawon mejeeji n gbe ni Araromi Quarters, ni Ketu, nipinle Eko. Awon alabaagbe mejeeji yii la gbo pe won gan pa leyin ti waya ina NEPA kan to wa leba ile won ninu ileewe kan nibe gbina, to si ran mo ile won.

Gege bi akoroyin wa se gbo, se ni Bashirat Rauf, eni ti won lo n dana ounje irole ojo naa lowo sare jade lati inu yara re lati gbe awon omo re mejeeji to n sere niwaju ile won leyin to ri ina to n jo lati ara waya ohun, sugbon oro naa beyin yo nigba tina gbe e, to si gan pa.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Noosi Abele Bbebi Daran N'Ilorin, Ibi Omo Kate Ni Ko Jade, Lo Ba Gbabe Ku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Noosi Abele Bbebi Daran N'Ilorin, Ibi Omo Kate Ni Ko Jade, Lo Ba Gbabe Ku

Iya eni aadota odun kan, Adelodun Oyenike, to n sise noosi lo fika abamo bo enu lose to
koja nigba ti ileese olopaa ipinle Kwara wo oun ati Oladoye Oluwasogo, eni odun
marundinlogoji lo sile-ejo majisreeti to n jokoo ni Sango, niluu Ilorin, lati lo so tenu won
lori ohun ti won mo nipa obinrin to ku sodo won ti won n pe ni Kate.

Nigba to n rojo tako won nile-ejo, olopaa to n soju ijoba, Koburu Olajide Emmanuel, so pe
awon mejeeji naa ni won gbimo-po huwa odaran, ti won si seku pa omobinrin kan toruko re
n je Kate. Esun naa lo so pe o tako abala kan ninu iwe ofin to de iwa odaran tipinle Kwara.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

O Ma Se O: Won Ba Oku Omo Ghana Legbee Soobu Kan Ni Ago-Oko
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

O Ma Se O: Won Ba Oku Omo Ghana Legbee Soobu Kan Ni Ago-Oko

Fun bii wakati mefa lawon to ni soobu laduugbo ti won n pe ni Ago-Oko, niluu Abeokuta,
ko fi le si i nitori bi won se deede ri oku gende kan ti won gbe segbee okan lara awon soobu
naa, ti won ko si mo awon to sise ibi ohun.

Gege bi Iwe Irohin Yoruba se gbo, laaaro Ojoru, Wesde, ose to koja, tawon to ni soobu de sibe lati
taja won ni won ri oku naa, ero-okan won ni pe boya okunrin naa ti muti yo lo se dogbon
sun sibe, sugbon nigba ti won sunmo on ni won too ri i pe ki i se pe o sun, bi ko se pe o ti
ku.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori siga, Alli pa Idowu ni Ikotun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Olayinka Adedayo

Nitori siga, Alli pa Idowu ni Ikotun

Ileese olopaa ti wo okunrin omo ipinle Niger kan, Alli Mustapha, eni odun mejilelogoji lo sile-ejo Majisreeti to wa ni Ebute-Meta lori esun ti won fi kan an pe o seku pa onibaara re kan, Idowu Maliki, pelu bo se fo igi mo on lori.

Gege bi olopaa to wa nidii ejo naa, Sajenti Olaniyan Rasak, se salaye fun ile-ejo, isele naa waye lojo keje, osu keta, odun yii, ninu ogba Imope, n'Ikotun, niluu Eko, iyen nigba ti Idowu loo ra siga lowo Alli to n ta worobo ninu ogba naa, sugbon to ko lati sanwo fun un.

Ko pe toloogbe naa fi pada wa si soobu olujejo, sugbon iyen ko je ko wole lati mu ohunkohun mo, eyi lo si fa ede-aiyede laarin won.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori owo ina: Iya Olope fun iya onile e lorun pa ni Mowe
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Nitori owo ina: Iya Olope fun iya onile e lorun pa ni Mowe

Ariwo e gba wa ni awon omo iya onile kan ni Mowe, nijoba ibile Obafemi Owode, nipinle Ogun n ke lojo Abameta, Satide, ose to koja nigba ti okan lara awon ayalegbe iya naa fun un lorun pa nitori pe won ja ina e.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, obinrin eni odun metalelogbon kan toruko e n je Saki, tawon eeyan adugbo naa mo si Iya Olope, la gbo pe o loo ka iya onile e mole lale ojo naa to si seku pa a.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Isiaka to lu orebinrin re pa l'Ajegunle ti dero ile-ejo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Isiaka to lu orebinrin re pa l'Ajegunle ti dero ile-ejo

Nitori tokunrin aafaa kan, Isiaka Akanbi, eni odun marundinlogota to n gbe lojule karundinlogbon, laduugbo Salubi, l'Ajegunle, niluu Eko, lu orebinrin re, Raliatu Kareem, eni odun mejilelogota pa, ile-ejo majisreeti Ebute-Meta ti ni ko si maa gbategun logba ewon Ikoyi na.

Gege bi agbejoro ijoba, ASP Elizabeth Ekuma, se salaye fun ile-ejo, isele ohun waye ni nnkan bii aago meje ale ojo karundinlogbon, osu kewaa, odun to koja ni oteeli kan lagbegbe Olodi Apapa, nigba ti Raliatu kuro nile re l'Agbado lati loo ki egbon e tomo e bimo. Nigba to debe to ba awon olomo sere die lo so pe oun fee sare loo ki ore oun kan l'Ajegunle.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo

Kayeefi ni iku to pa pasito kan toruko re n je Bright Daniel to je alakooso ijo isembaye kan niluu Okeigbo, nipinle Ondo, si n je fawon eeyan latari bi agbonrin abami kan se deede ran an lo sorun ojiji l'Ojobo, Tosde, ose to koja yii.

Gege bawon ti iroyin buruku naa soju won se so, okan lara awon omo ijo pasito yii lo waa fi alupupu okada gbe e nirole ojo yii lati loo sise itusile lori oke kan ti won n pe ni Pele, nipinle Ondo, iyen ni won se kuro ni soosi won to wa laduugbo Oke-Jege nibe, ti won si kori sori oke ohun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Eemo! omo odun mejila pokunso l'Oko-Oba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Eemo! omo odun mejila pokunso l'Oko-Oba

Kayeefi niku omokunrin omo odun mejila kan toruko re n je Hassan to n kose kapinta laduugbo Funmilola Judge Crescent, niluu Oko-Oba, nipinle Eko, si n je fun gbogbo awon to ri oku e nibi to pokunso si.

Ni nnkan bii aago mokanla aaro ojo Eti, Fraide, to koja yii ni won deede ri oku omokunrin yii ninu soobu oga e, Taofik. Enikan to gbese fun okunrin naa la gbo pe o ri oku Hassan nibi to ku si, oun lo si ke sawon araadugbo. Iyalenu nla lo je fawon eeyan yii nigba ti won ri oku omodekunrin naa lori iso.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe saaju asiko yii loga e, iyen oko egbon e ti won n pe ni Iya Hikimat ti koko ba omo to ku yii wi. Asise kan ni won so pe o se lara aga ti enikan gbe fun won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Iku afurasi da wahala sile n'Ilorin, ileese olopaa loun ko mo nipa e
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Iku afurasi da wahala sile n'Ilorin, ileese olopaa loun ko mo nipa e

Oro odomokunrin kan to padanu emi e lasiko tawon soja ati otelemuye ya bo ibugbe e laduugbo Anifowose, lagbegbe Pakata, niluu Ilorin, ti da awuyewuye sile o. Bawon kan se n so pe afurasi ohun je okan lara awon a-femi-diku, Boko Haram, bee lawon mi-in n so pe janduku to n fooro emi awon eeyan lasan ni.

Isele to waye lose to koja lo da iberu-bojo sile lagbegbe naa nitori bawon agbofinro pelu afurasi odaran ohun ti ko seni to mo oruko e titi di bi a ti n soro yii, tabi iru ese to se gan-an ti won fi seku pa a dana ibon bo ara won.

Iwe Iroyin Yorubagbo pe afi bii igba ti won wa loju ogun loro ohun ri lasiko tawon agbofinro to ya bo ile ti afurasi ohun pelu iya re ati iyawo re kan n gbe doju ibon ko ara won. Lasiko yii lawon omo-ogun ti fi ota ibon re e bale, toun naa si yin okan lara awon agbofinro to wa sibe nibon lapa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

O d'oju e! Aisan-okan kolu Kate pelu oyun osu meje ninu, milionu mewaa lo n
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

O d'oju e o! Aisan-okan kolu Kate pelu oyun osu meje ninu, milionu mewaa lo nilo fun ise-abe

Stephen Ajagbe, Ilorin Lati igba ti Abileko Kate Onimisi ti wa ninu oyun osu mefa lo ti n ba wahala ohun finra, aisan to lagbara kan lo kolu u to fi dero ileewosan ekose Fasiti Ilorin, UITH. Nigba tawon dokita se ayewo fun un, won sakiyesi pe aisan-okan lo n se obinrin alaboyun naa, latigba naa lo si ti wa lori akete aisan.

Ipo ti Kate wa yii lawon dokita so pe o lewu fun omo inu re, nitori ohun to daju ni pe ko ni i le bi omo naa to ba fi le wo osu mesan-an, idi niyi ti won fi sise-abe fun un ti won si gbe omo osu mefa ohun jade ninu re. Won setoju omo naa sinu igo ti won maa n gbe awon omo ikoko ti osu won ko pe si nileewosan, o si ye.

Loooto lomo naa n se daadaa, sugbon ipo ti iya re wa bayii buru jai, o si n kigbe fun iranlowo awon eleyinju-aanu ati ijoba lorile-ede Naijiria lati saaanu re ko ma je pe aisan yii lo maa mu emi re lo. Se lobinrin ohun ti ru ku eegun, beeyan ba si ri asiko to segbeyawo nibi toju re ti gun rege si ipo to wa bayii, onitohun yoo kaaanu re.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Rilwan gun Suraju nigo pa, o tun gbe telifisan ore e lo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin OlootuRilwan gun Suraju nigo pa, o tun gbe telifisan ore e loBeeyan ba gbo bi awon araadugbo omodekunrin eni odun mokandinlogun kan to n je Saludeen Rilwan se n royin e gege bii ipanle omo ti ko ko ki ile su ninu oorun osan gangan, bi eni naa ba fi oju gan-an-ni Rilwan, yoo soro fun un lati gba iroyin ohun gbo nitori apeere esin Islam han lara e daadaa, o si jo pe irun kiki ti mo on lara gidi pelu bi iwaju ori e se dapaadi, to si dudu fafa fun irun kiki. Sugbon ba a se n ko iroyin yii, omokunrin naa ti gba oye kun oye, oju ipanle lawon araadugbo fi n wo o, o ti di apaayan, o si ti di jaguda-paalibaba-ole.

Lojo Eti (Fraide), ogbonjo, osu kin-ni-ni, odun yii, la gbo pe Rilwan wo ile ore e kan to n je Olayiwola Femi laduugbo ti won n pe ni Oke-Oloro, lagbegbe Omi-Adio, n'Ibadan, to si ji telifisan re gbe lo leyin to ti gun omo lanloodu okunrin naa to ba ninu ile ohun nigo pa.

Gege b'Iwe Iroyin Yorubase gbo, nigba ti Rilwan de ile Femi ni nnkan bii aago kan osan ojo naa, omo lanloodu e ta a wi yii to n je Kareem Alaba Suraju lo ba ninu yara e. Leyin to beere Femi tiyen ni ko si nile ni Rilwan lo si idi telifisan pelebe ti won maa n de mo ara ogiri ninu ile (Plasma) to si bere si i tu u lai se pe o gba iyonda lowo oni-nnkan tabi eni to ba nibe. Eyi lo mu ki Suraju pe e nija, sugbon Rilwan taku pe oun yoo saa gbe telifisan naa lo dandan ni.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori eefin jenereto, Ibrahim sa Bashorun pa l'Ajah
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori eefin jenereto, Ibrahim sa Bashorun pa l'Ajah

Okunrin eni odun mokandinlogbon kan ti won pe oruko re ni Ibrahim Tijani ti wa ni akolo awon olopaa ni Panti, Yaba, nipinle Eko, bayii latari esun ti won fi kan an pe o pa okunrin kan ti won jo n gbe pelu ada nigba tiyen kilo fun un pe eefin jenereto re n di oun lowo ninu yara.

Bashorun Okanla ni won pe oruko okunrin to doloogbe yii, ile akoku kan ti eni to ni in wa niluu oyinbo ni Iwe Iroyin Yoruba gbo pe awon mejeeji jo n gbe ti kaluku won si mu yara nibe lagbegbe Ogombo, Okun Ajah, nipinle Eko. Sugbon lojo Aiku, Sannde, ojo kejo, osu yii, ni wahala sele nigba ti Ibrahim to n sise birikila tan ero amunawa ti a mo si jenereto re ni nnkan bii aago mokanla aaro. Bo se n jaye ori e ni Bashorun, eni odun metadinlogota jade ninu yara to si so fun un pe ko pa jenereto ohun nitori eefin e n wo yara oun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: