Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
[ Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo ]

·E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o
·Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku
·Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
·Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
·O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
·Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
·Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja
·Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure N
·O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

E Gba Mi Lowo Iyawo Mi o, O Fee So Mi Di Dindinrin — Rafiu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

E Gba Mi Lowo Iyawo Mi o, O Fee So Mi Di Dindinrin — Rafiu

Se ni gbogbo awon ti won wa ni kootu ibile keji niluu Osogbo n woju ara won lasiko ti okunrin kan, Bakare Rafiu, n so niwaju awon adajo pe ki won tete ba oun tu igbeyawo oun pelu Bakare Kehinde ka ko too di pe obinrin naa yoo so oun di dindinrin gege bo se n leri.

Ogbeni Rafiu ni alaafia ti ko si ninu ile loun koko n dojuko latodo iyawo toun fe lodun mesan-an seyin ko too di pe o tun bere si i leri kiri pe oun yoo so oun di dindinrin patapata.

O ni yato si eleyii, alaarifin niyawo oun, ko niteriba fun enikeni, koda, ki i fojuure wo awon obi oun, epe lo fi maa n ranse si won ni gbogbo igba.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Nibo Ni Isokan Yoruba Yoo Ti Wa?
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nibo Ni Isokan Yoruba Yoo Ti Wa?

Okan ninu awon aburo wa soro kan lose to koja lo yii. Aburo wa naa, Seneto loun tele, Femi Ojudu, lati Ekiti. Amerika lo ti soro ti mo fee so yii o, ohun to si so ni pe lasiko ijoba Buhari yii, bi Yoruba ko ba wa nisokan, won ko ni i ri kinni kan gba kuro ninu ijoba naa.

Iyen tumo si pe gbogbo wahala tawon oloselu Yoruba se leyin Buhari lati je ko de ipo to wa yii, ofo ni yoo ja si. Aburo wa ko le soro naa nile, Amerika lo ti loo so o. Nigba ti awon oniroyin si gbe ohun to so jade, o ni bi oun ti so o ko niyen. Sugbon nigba toun naa ko ohun to so pe oun so jade, oro kan naa ni, ko siyato nibe. Koko ohun ti Femi so ni pe nnkan ti bo mo Yoruba lowo ninu ijoba yii. Femi so nibi ipade naa pe lasiko ti won n mu awon ti won fee se minisita, won ti fi oruko Femi Falana si i tele, sugbon won ni bo ba fe ki oro naa see se foun, ko koko lo si Kaduna lodo enikan to le ba a se e. Ni Falana ba ko, ko lo.

Ta lo waa wa ni Kaduna ti Femi Falana yoo loo ba lati se minista? El Rufai ni. El Rufai to n se gomina ibe lowo bayii, okunrin to fee di ana Buhari bi ohun gbogbo ba lo deede, to si ri omo re fe, oun lo ku ti won n ni kawon bii Falana loo ri ko le ba a soro lodo Buhari atawon ti won jo n sejoba ki won fi i se minisita. Bee, awon El Rufai yii ni ki i won nile Yoruba tele.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

TITUBA KURO NIBI ESE (AT-TAWBAH MIN AL-MA'ASIY)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Ori Minbari Yoruba

TITUBA KURO NIBI ẸSẸ (AT-TAWBAH MIN AL-MA'ASIY)

Awọn erongba khutuba
- Sisẹri pada lọ ọdọ Ọdọ Ọlọhun
- Rire awọn eniyan lori bi wọn yoo se se atunse aarin wọn ati Ọlọhun
- Jijinna si ijakan ninu ikẹ Ọlọhun
Akoko Khutuba mejeeji: Isẹju marundinlogoji

Khutuba Alakọkọ

الحمد لله القائل في كتابه المبين : "وتوبوا إلى الله جميعا أيها المؤمنون لعلكم تفلحون" (النور 31) أحمده إذ فتح لعباده باب التوبة . ودعاهم إليها , ووعدهم أن يتقبلها منهم ويمحو بها سيئاتهم . واشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له ولا نعبد إلا إيّاه . وأشهد أن محمدا عبده ورسوله صلّ الله عليه وأصحابه وبعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun to sọ ninu tira Rẹ pe: "Nitorinaa, ẹ ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun, gbogbo nyin patapata, ẹyin onigbagbọ ododo ki ẹ le baa la. (Suratul Nuru 31). Mo jẹri pe ko si ẹniti isin ododo yẹ, ayafi Ọlọhun nikan ti ko ni orogun, bẹẹni mo si jẹri pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni Ojisẹ Rẹ si ni, ki Ọlọhun bawa kẹ Annọbi, awọn ara ile rẹ, awọn sahabe rẹ ati gbogbo ẹlẹsin isilaamu titi ọjọ ikẹyin.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Kike Alkur'an Ati Awon Eko Re: Alaye Ola (Esan) kike AlKur'an Alaponle
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Ori Minbar Yoruba

Kike Alkur'an Ati Awon Eko Re: Alaye ọla (ẹsan) kike Alkur’an, Wiwa awọn eniyan nisọra nipa kiko airoju nibi kike Alkur’an ati Yiyannana awọn ẹkọ kike Alkur’an

Alukurani je tiira Olohun eleyii ti o sokale lati odo re lati maa je iwe ti yio maa dari gbogbo olugbagbo ododo nibi isemi aye ati esin won, eniti o ba gbe iwe mimo yii siwaju ti o si ntele, iwe yi yio fa iru enibee wo Alijannah Onidera.Nida miran, eniti o ba ju iwe mimo yi seyin ti ko tele, iwe yii yio ti iru eniti bee woo ina, latiara idieyi, eniti o ba nwa oore aye ati orun, ki o ya gba iwe mimo yii mu ki o si maa ka ni oore koore.

- Alaye ọla (ẹsan) kike Alkur’an
- Wiwa awọn eniyan nisọra nipa kiko airoju nibi kike Alkur’an
- Yiyannana awọn ẹkọ kike Alkur’an

Akoko kutuba: Isẹju marundinlogoji

الحمد لله الكريم المنّان الذي أكرمنا بالقرآن , وجعله ربيعا لقلوب أهل البصائر والعرفان , ويسّره للذكر حتى استظهره صغار الولدان وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لاشريك له شهدة تنال بها الغفران وأشهد أن محمدا عبده ورسوله حثّ على تعلم القرآن وتعليمه والتفكر فيه وتفهيمه والعمل بأحكامه , والوقوف عند حدوده, صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا وبعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun to pawa lasẹ ninu tira Rẹ Alapọnle pe: Ẹnyin ti ẹ gbagbọ ni ododo ẹ maa ranti Ọlọhun ni iranti ti o pọ ki ẹ si ma se afọmọ Rẹ ni arọ ati ni irọlẹ”.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Kamalat, Omo Odun Mefa To Laisan Okan Ma N Pariwo, O Ni Kawon Omo Naijiria Ran
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Kamalat, Omo Odun Mefa  To Laisan Okan Ma N Pariwo, O Ni Kawon Omo Naijiria Ran Oun Lowo

Lati gba ti Kamalat Balogun ti wa lomo odun meji lawon dokita ti sakiyesi pe iho wa ninu okan re, eyi to maa n mu un saisan ti won si ti n toju e latigba naa. Ni bayii, o ti to omo odun mefa, sugbon sibe ko ti i ri itoju to peye.

Omodebinrin ohun to wa nipele keji (KG 2) nileewe alakoobere Al-Alim Nursery and Primary School, n'Ilorin, ni aisan okan to n da a laamu ohun ti wo o lara bayii, to si nilo ise-abe ni kiakia lati pada sipo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

IGBEYAWO NINU ISLAM: Itumo Igbeyawo; Kinni Erogba Igbeyawo Ninu Islam?
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
IGBEYAWO NINU ISLAM

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

الزواج في الإسلام

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

IGBEYAWO NINU ISLAM

Itumo Igbeyawo:

Igbeyawo ninu Islam je asopo ti o ni alubarika laarin okunrin kan ati obinrin kan, eyi ti yoo so enikookan ninu awon mejeeji di eleto enikeji re, ti won yoo si bere irin-ajo olojo gbooro ni ile aye yii. Won yoo wa bayi pelu ife ati ifowosowopo, enikan ninu won yoo maa ri ifokanbale lodo enikeji re, ti ibagbepo won yoo si maa fun awon mejeeji ni alaafia ati igbadun aye.

Kinni Erogba Igbeyawo Ninu Islam?

Erongba igbeyawo ninu Islam ni lati pile idile Musulumi. Idile Musulumi ni opomulero fun awujo Islam ti o dara, eyi ti awon eniyan re yoo je awon eniti won ni oripa rere ni ile aye, ti won yoo maa fi owo sowopo lori daadaa ati iberu Olohun, ti won yoo si maa sare alapantete lo sibi awon ise oloore.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Awon ipile meta Esin Islam ati awon Eri won Lati owo Shaikh Muhammad Ibn sulaima
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Awọn ipilẹ mẹta ẹsin islam ati awọn ẹri wọn

Lati ọwọ
Shaikh Muhammad Ibn sulaiman At-Tameemi - Ki Ọlọhun O kẹ ẹ-

Ẹni ti o tumọ ri si ede Yoruba ni: Sharafuddeen Gbadebọ Raji

الأصول الثلاثة وأدلتها

تأليف

الشيخ محمد بن سليمان التميمي

ترجمه إلى اليوربا

شرف الدين باديبو راجي

بسم الله الرحمن الرحيم

Mo bẹrẹ ni orukọ Ọlọhun Ọba Alaanujulọ Aladipele-ẹsan-rere

[IPILẸ ALAKỌKỌ: MIMỌ ỌLỌHUN ỌBA]
Mọ daju “Ọlọhun ki O kẹ ọ” pe ọranyan l’o jẹ lori wa pe ki a kọ nipa awọn ohun ayẹwo mẹrin kan:-

Alakọkọ ni imọ; Oun ni pe ki a mọ Ọlọhun, ki a si mọ anabi Rẹ, ki a si mọ nipa ẹsin Islam pẹlu awọn ẹri rẹ.

Ẹlẹẹkeji ni ki a maa fi imọ naa sisẹ.

Ẹlẹẹkẹta ni ipepe lọ sidi rẹ.

Ẹlẹẹkẹrin ni sise suuru lori inira ti n bẹ ninu rẹ.

Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} والعصر . إن الإنسان لفي خسر. إلا الذين آمنوا وعملوا الصالحات وتواصوا بالحق وتواصوا بالصبر {.

« Mo fi igba bura* Dajudaju awọn eniyan n bẹ ninu ofo* Afi awọn ti wọn ni igbagbọ-ododo, ti wọn si n se daadaa, ti wọn si n gba ara wọn niyanju lati maa sọ otitọ, ti wọn si n gba ara wọn niyanju lati maa se suuru ».

Imam Shaafi’i “ki Ọlọhun t’O ga O kẹ ẹ” sọ pe: « Iba se pe Ọlọhun kò sọ awijare kankan kalẹ le awọn ẹda Rẹ lori yatọ si Suura yii nikan ni, dajudaju ko ba to wọn ».

Imam Bukhari naa “ki Ọlọhun t’O ga O kẹ ẹ” sọ pe: Akọle ẹkọ kan -pe-: Ọranyan ni ki imọ o siwaju ọrọ ati isẹ. Ẹri eleyii ni ọrọ Ọlọhun t’O ga t’o ni:

} فاعلم أنه لا إله إلا الله واستغفر لذنبك {. [سورة محمد، آية:
(19)].

« Nitori naa mọ daju pe kò si ọba kan ti o tọ lati fi ododo jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ki o si maa tọrọ aforijin ẹsẹ rẹ …» . [Qur’aan, Suuratu Muhammad: 19]. Imọ l’O fi bẹrẹ siwaju ọrọ ati isẹ.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

AKASO ODODO (Al- WASEELAH) - Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi -- Atunyewo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
AKASO ODODO (Al- WASEELAH)

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi

Atunyewo: Rafiu Adisa Bello

التوسل المشروع

« بلغة اليوربا »

إسحاق بن أحمد الإلالوي

مراجعة: رفيع أديسا بلو

AKASO ODODO (AL WASEELAH)

Al –waseelah ni gbolohun ede Arab ti o tumo si akaso tabi ona isunmo. Gbolohun naa waye ni ona meji pere ninu al Qur’aan Abiyi; suurah Maaidah, aayah 35 ati Suurah Israa’, aayah 57.

Ninu Suurah Maaidah, Olohun so pe:

﴿ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱبۡتَغُوٓاْ إِلَيۡهِ ٱلۡوَسِيلَةَ وَجَٰهِدُواْ فِي سَبِيلِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ ٣٥ ﴾ [المائ‍دة: ٣٥]

“ Mo pe eyin onigbagbo ododo, e beru Olohun, e wa akaso si odo Re ki e si jagun si oju ona Re nitori ki e le jere.” Ese ketedinlogota ninu Suuratil Israa’ lo bayi pe: “ –awon alujonu ti awon alaigbagbo nkee pe- nwa ona lati sunmo odo Oluwa won…”

Ibeere ti o n fe idahun ni pe:

1- Kini a le fi se akaso si odo Olohun?

2- Akaso wo ni Olohun pase pe ki a wa?

Akaso ti Olohun pe wa si ni ki a sunmo odo Re. Ohun ti a si le fi sunmo Olohun ni itele ase Re ati itakete si aigboran ati iwa ese gege bi itoka awon onimo Tafseer. Ninu ohun ti o je ki itumo won yii fidi munle ni itan ti Ojisenla Muhammad- Alaafia ati ike Olohun fun un- pa fun awon omo leyi re nipa awon ijo isaaju. Itan naa ni kukuru lo bayi pe:

Ona di mo awon eniyan meta kan ti won wa ni ori irin-ajo, won sa si inu apata kan, apata naa si panude mo won ti won ko lee jade.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Alaye lori Aayah (23) ninu Suuratu Furkooni
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Alaye lori Aayah (23) ninu Suuratu Furkooni

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

تفسير الآية (23) من سورة الفرقان

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

ALAYE LORI AAYAH (23) NINU SUURATU FURKOONI

Olohun- ti ola Re ga- so wipe: (Dajudaju A o siju wo ohun ti won se ni ise, A o wa so o di eruku ti a ku danu) [Suuratu Furkooni: 23].

Alaye Lori Aayah Yi:

Olohun- Oba mimo Oba ti o ga- nso ninu aayah yi nipa awon osebo, awon ti won n da nkan miran po mo Olohun nibi ijosin wipe Oun Olohun yoo mu ise awon osebo naa, awon ise ti won nlero wipe ise daradara ni won, ti won si se wahala lori won, Olohun yoo so ise naa di ohun ti yoo ku danu bii eruku, awon osebo yi yoo wa di eniti won pofo ti won ko si ni esan kankan lori ohun ti won gbe ile aye se.

Ohun ti yoo se okunfa ki Olohun se ise won bayi ni wipe won ko ni igbagbo si Olohun, won si je eniti won maa npe Olohun ati awon ojise Re ni opuro. Ise ti Olohun yoo maa gba ni odo erusin Re naa ni eyi ti o ba je wipe onigbagbo ododo ni o se e, eniti o gba Olohun ati awon ojise Re ni ododo, ti o ntele won, ti o si nse afomo ise naa fun Olohun Allah nikan.

Ohun ti Olohun so ninu aayah yi yoo sele ni ojo ajinde nigbati Olohun ba nse isiro ise awon eda Re ti won se ni ile aye, eyi ti o dara ninu awon ise naa ati eyi ti o je aburu. Olohun nso fun awa eru Re ninu aayah yi wipe awon ise ti awon osebo lero wipe awon se ni ile aye ti won si ni agbiyele wipe won yoo gba esan lori won, ti yoo si je ohun ti yoo se okunfa lila kuro ninu iya Olohun fun won, won ko ni ri nkan kan ninu ohun ti won ni agbiyele re, ohun ti o si se okunfa eleyi ni wipe ise won naa ti padanu awon majemu ti o ye ki o wa nibi ise erusin Olohun, awon majemu naa ni ki erusin se afomo ise fun Olohun nikan, ki o fi wa oju rere Re nikan, bakannaa ki ise naa wa ni ibamu bi ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ti se e.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Oorun didun igi ododo ti orewa nipa ajulo awon iya awon olugbagbo ododo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
OOrun didun igi ododo ti orewa nipa ajulo awon iya awon olugbagbo ododo
Lati owo

Ibudo iwadi nipa awon eko esin Eyi T o je aketun fun Ibuseni ni oore nipa awon ara ile (Anabi) ati awon Saabe re

ترجمة: مؤسسة القلم الخيرية العالمية للبحوث والترجمة والتعريب (السودان)

Ni oruko Olohun ajoke aiye aske orun

"النَّبِيُّ أَوْلَى بِالْمُؤْمِنِينَ مِنْ أَنفُسِهِمْ وَأَزْوَاجُهُ أُمَّهَاتُهُمْ"

(الأحزاب 6)

OOrun didun igi ododo ti orewa nipa ajulo awon iya awon olugbagbo ododo

Anabi ni eto si awon oni gbagbo ododo ju ara won lo, atipe awon iyawo re ni awon iya won (Suratul- Ahzaab: 6)

Oro isiwaju

Alaye soki nipa, awon iya awon olugbagbo ododo

Ibuseni ni oore fun awon ara ile (Anabi) ati awon Saabe re: Ipele itan nipa awon ara ile (Anabi) ati awon Saabe re

Ope ni fun Olohun, ike ati ola fun eni ti oje opin awon ojise Olohun, ati awon ara ile re, ati awon ijo re, ati awon ti won ba tele won, titi di ojo esan. Leyin naa:(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

GBIGBA AAWE NINU GBOGBO AWON OJO OSU RAJAB ATI SHA'BAAN
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
GBIGBA AAWE NINU GBOGBO AWON OJO OSU RAJAB ATI SHA'BAAN

Ibeere:

Mo ri awon eniyan kan ti won n gba aawe ninu osu Rajab ati Sha'baan ki won to gba awe osu Ramadan, lai je wipe won yoo sinu rara ni gbogbo asiko yii, ejowo nje hadiisi kan wa ti o toka si ohun ti won n se yii, ti o ba si ri bee kinni hadiisi naa?(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

NJE A LE RI ANABI MUHAMMAD NI OJU ALA
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi

Atunyewo: Rafiu Adisa Bello

رؤية النبي ﷺ في المنام

« بلغة اليوربا »

إسحاق بن أحمد الإلالوي

مراجعة: رفيع أديسا بلو

NJE A LE RI ANABI MUHAMMAD NI OJU ALA?

Ni otito, eniyan le ri anabi Muhammad-alaafia Olohun fun un - ni oju oorun. Sugbon Shatani le pe ara re ni anabi gege bi ero okan wa se le yipada si ohunkohun nigbati a ba ti sun. Nipase bee, riri anabi loju oorun lee je iro idunnu, o lee je alakala lati owo esu, o si lee je abayori ife okan wa.

Ronu si awon ala yii:

Akoko: Onimo hadiisi agba, Bukhaari - aanu Olohun fun un, nigbati o wa ni kekere o lala pe oun nfi abebe le esinsin kuro ni oju anabi [1] - alaafia Olohun fun un.

Ikeji: Enikan so pe oun ri anabi loju oorun ti o we lawani funfun laini irugbon, o si so bayi pe: baba agba ni mo je fun o, eje mi si ni iwo nse; nitorinaa, asegbe ni ohunkohun ti o ba se, mo si ti fun o ni ase ‘wi bee je bee’.

Iketa: Muhammad Al- Buusoyr [2] so pe: Nigbati arun ‘ro lapa ro lese’ mu mi, ti ko si gbo itoju, mo ko orin eyin anabi ti opa orin naa to ogun mejo (160) ni oju oorun mi, mo ri anabi Muhammad, o fi owo pa owo ati ese mi o si wi fun mi pe ki n ko orin eyin naa. Anabi fi idunnu re han si mi nigbati o gbo orin eyin naa. Nigbati mo dide ni ori oorun naa, mo gbe apa o see gbe, mo si gbe ese naa ni irorun [3].(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Àwon Origun Esin Islãm Itunmo si Ede Yoruba
(Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Àwọn Origun Ẹsin Islãm

أركان الإسلام بلغة اليوروبا

Itunmọ si Ede Yoruba

Lati ọwọ:

AbdulWahab Muhammad Jãmiu Ẹlẹsin

Ilẹ Saudi Arabia, Ilé isẹ - Minisiri - ẹkọ giga - Ilé-ẹkọ giga Islãm ni Mọdinat

Àyè iwadii-Imọijinlẹ - Ẹka títúmọ ede si omiran

Àwọn Origun Ẹsin Islãm

Ọrọ Isãju

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, ikẹ ati ọla ki o maa ba igbẹyin awọn annabi, Annabi wa Muhammad ọmọ 'Abdullahi r. Lẹhin na:

Dajudaju titan awọn imọ ẹsin Islam ka o ni ipa kan ti o tobi l'ori sise alaye papa ẹsin Islam, ati fifi idi awọn opo ẹsin rinlẹ, ati mimu ilọsiwaju ba ijọ (Musulumi). Eleyi jẹ ero ngba nla, ohun naa ni ile ẹkọ giga ti Islam (Islamic University) n sapa lati se pẹlu ipepe ati ikọnilẹkọ.

Ni ifọwọsowọpọ l'ori eyi ni ile isẹ ti n se amojuto iwadi imọ-ijinlẹ ni ile ẹkọ yii fi dide lati se ọna ati igbesẹ kalẹ l'ori ọpọlọpọ ninu awọn isẹ adawọle ti o jẹ ti imọ, ninu rẹ ni sise iwadi ti o jinlẹ nipa Islam ati awọn daada ti o gbe wa, ati sise afọnka rẹ, lati le fun awọn ọmọ Musulumi ni imọ ti o peye nipa ẹsin wọn, adisọkan rẹ, pẹlu awon ofin rẹ.

Iwadi yi ti o da le ori (Awọn Origun Islam) jẹ ọkan ninu awọn igbesẹ ile işẹ yi, nitori naa ni o fi pe apakan ara awọn olukọ ni ile ẹkọ giga yi ki wọn kọ nkankan nipa origun Islam, lẹyin naa ni o tun wa gbe awọn ikọ kan dide ni ile işẹ naa lati se ayẹwo nkan ti wọn kọ, ki wọn si se atunse ti o yẹ l'ori rẹ ki wọn si gbee jade, ki wọn si gbiyanju lati maa mu ẹri wa lati inu Al-Qur'an ati Sunna (Ilana Annabi) l'ori gbogbo ọrọ imọ ti wọn ba mu ẹnu ba.(Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Awon Origun Igbagbo-ododo “Al-’Iimaan”
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Awọn origun igbagbọ-ododo“Al-Iimaan

Eyi ti a tumọ si Yoruba lati ọwọ:

Sharafuddeen Gbadebọ Raji

Ilẹ Saudi Arabia, Ilé-isẹ -Ministiri- ẹkọ giga - Ilé-ẹkọ giga ti Islam ni ilu Madina

Aaye iwadii-ijinlẹ - Ẹka yiyi ọrọ pada lati ede kan si omíran

بسم الله الرحمن الرحيم

Mo bẹrẹ ni orukọ Ọlọhun Alaanujulọ Aladipele-ẹsan-rere

Gbogbo ọpẹ ti Ọlọhun ni i se, ikẹ ati ọla Ọlọhun k’o maa ba ẹni ti kò si anabi kan mọ lẹyin rẹ, Anabi wa, Muhammad ọmọ Abdullaah, “ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a”; lẹyin naa:

Dajudaju titan imọ Islam ka ni oripa nla nipa sise alaye paapaa Islam, ati fifi awọn opo ẹsin naa rinlẹ, ati tita awọn ijọ yii ji.

Ohun afojusi alapọnle yii si ni ohun ti ilé-ẹkọ giga ti Islam [ni ilu Madina] n gbiyanju lati fi rinlẹ gba ọna ipepe, ati ikọnilẹkọ.

Ati pe nitori atikopa ninu fifi eleyii rinlẹ ni aaye iwadii-ijinlẹ ni ilé-ẹkọ giga yii se se eto, ti o si se ipalẹmọ fun ọpọlọpọ ninu awọn adawọle ti imọ, eyi ti o ni itumọ, ninu rẹ si ni awọn iwadii ti o rinlẹ nipa Islam, ati awọn ẹwa rẹ, ati titan an ka, nitori ojukokoro rẹ lori atise ipese fun awọn ọmọ ijọ Musulumi, pẹlu eyi ti o rinlẹ ju, ti o si lagbara ju ninu awọn ẹkọ nipa Islam, ati adisọkan rẹ, ati awọn ofin rẹ.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Okunfa Ifokanbale fun Musulumi Ododo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Okunfa Ifokanbale fun Musulumi Ododo

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

من أسباب اطمئنان القلوب

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

Okunfa Ifokanbale fun Musulumi Ododo

Ifokanbale je nkan ti gbogbo eniyan ti o wa laye yii nwa, yala eniti o je Musulumi ti o gba fun Olohun, ti o si jupajuse sile fun Un, tabi keeferi ti o ko ti Olohun Oba re, ti o si se aimoore si I. Kosi eniti ko fe ifokanbale, koda ifokanbale ni ohun ti o ga julo ti eniyan maa nwa ni aye yii, bi o tise je wipe ki eniyan jere pelu ogba idera (Al-Janna) ni ohun ti o ga julo ti eniyan maa ngbero ki oun ri ni orun.

Nigbati oro wa ri bayi, o ye ki a bi ara wa ni ibeere wipe: kinni o nse okunfa ifokanbale fun eniyan?

Ni idahun si ibeere yii, e je ki a gbo oro Olohun Oba wa ninu Al-Qur'aan. Olohun so wipe: (Je ki nso fun o, pelu iranti Olohun ni awon okan fi nbale) [Q: 13,28].(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

AWON LETA TI O WAFUN AWON ALHAJI ATI AWON ONI UMRA
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
AWON LETA TI O WAFUN AWON ALHAJI ATI AWON ONI UMRA -- Lati Owo DR. SHEIK YAHYA BIN IBRAHIM ALYAHYA

Lati owo

DR. SHEIK YAHYA BIN IBRAHIM ALYAHYA

Olutumo re si ede Yoruba ni:Abu Maalik N. Alimaam

بسم الله الرحمن الرحيم

NI ORUKO OLOHUN ALANU JULO OBA ONI IKE.

Ope ni fun Olohun Oba gbogbo aye,mo njeri pe kosi eniti oye ki a josin fun ni toto ayafi oun, ore awon eni rere, mosi tun jeri wipe Anabi Muhamad eru Olohun ni ojise re si ni, asiwaju (ALGURRUL MUAJJALIIN) awon ti gbogbo orike ara won yo maa tan imole ni ojo Al qiyamo, O jise tiwon ran,osi pe adehun pelu,koda ose waasi ati ikilo fun ijore,o si fiwa sile lo lori imole gbo,ti oru re da bi osan re,enikankan kowa le sonu mo ayafi olori kunkun(eni iparun).ki Olohun se ike fun ati ara ile re pelu awon Sabe re lapapo,bakanaa ki ikeyi tun lo ba gbogbo eniti o ba pepe si oju ona re,ti o si ntele ilana re,titi di ojo esan,lehin naa:

Omo iyami Alhaji,iwo ti Olohun sa lesa lati wasi ile Olohun laarin ogunlogo awon musulumi,mo nbe Olohun ti o ga pe ki o duro ti o ni aye ati ni orun,ki o si se o ni alalubarika nibi yowu ti o bawa.

Omo iya mi alaponle:se bi iwo naa ni o farada opolopo wahala,ati isoro pelu inawo ,ti o si tun fi ile ati ara ati omo sile, o se gbogbo eleyi titori ki o le se ise Haji Oranyan ni,mo wa nbe Olohun ki o se Haji re ni atewogba,ki o si se aforiji ese re,ki o si bo asiri asise re.

Omo iyami Alhaji alaponle: ife ti moni si o,ati idunu mi si didere ni alaafia ni o mu mi ko awon leta yii si o,ati lati se die ninu ojuse mi si o,leyiti o je oranyan,bakanaa ni itele ase Olohun ti o sope:

(وتـواصـوا بالـحـق وتـواصــوا بـالصــبر) العـصـر /3

(Won si ma nso asotele ododo ati suru sise) Al-asr /3.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

OJUSE ENIYAN NI ILE AYE
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
OJUSE ENIYAN NI ILE AYE

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

مسؤولية الإنسان في الحياة

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

OJUSE ENIYAN NI ILE AYE

Oro Irori:

Ninu ohun ti ko ba laakaye mu ni ki eniyan se ise kan, ki o se igbiyanju pupo ki o to pari re, sugbon ni ipari ki o je wipe kosi erongba kankan ti o fi se ise naa. Fun apejuwe eniti o se oko ofurufu (baaluu), ti o se wahala pupo lori re ki o to pari, ki o to di ohun ti yoo maa fo ni oju ofurufu, leyinnaa ki awon eniyan wa bii leere wipe: kinni idi ti o fi se oko ofurufu naa? Ki o wa da won lohun wipe: Oun kan se e lasan ni, kosi idi Kankan fun sise re, oun ko ni nkankan ti oun fee fi se. A o ri pe gbogbo onilaakaye olopolo pipe ni oro yii yoo tako laakaye won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

IPO IRUN NINU ISLAM: Pataki Irun, Ninu Awon Idi ti yoo Je Ki A Mo Pataki Irun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Itumo ati Pataki Ijeri Mejeeji

IPO IRUN NINU ISLAM

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

مكانة الصلاة في الإسلام

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

IPO IRUN NINU ISLAM

Pataki Irun:

Awon iko Banu Thaqeef wa si odo ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- lati gba esin Islam ki won si pada si odo awon ijo won ti won yoo maa fi esin Olohun mo won. Leyin ti won gba lati se esin Islam tan won beere awon nkan kookan ni odo ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- ninu awon nkan naa ni wipe: Awon fe ki ojise Olohun se amojukuro fun awon nibi irun kiki eyi ti o tumo si pe awon ko fe lati maa ki irun, ojise Olohun si da won lohun wipe: "Kosi oore kankan nibi esin ti ko ni irun ninu" [Zaadul Ma'aad: 3/437].

Irun je origun ti o se pataki julo ninu awon origun esin Islam leyin awon ijeri mejeeji: Ijeri pe kosi olohun kan ti ijosin to si ni otito ati ni ododo ayafi Olohun Allah atipe anabi Muhammad ojise Olohun ni. Olohun Allah se ni oranyan fun anabi Re ati gbogbo awa ijo anabi ninu oru ojo ti O mu un se irin-ajo lo si sanma, ohun si ni origun eleekeji ninu awon origun esin Islam maraarun.

Irun maraarun ojumo je dandan fun gbogbo Musulumi l'okunrin ati Musulumi l'obinrin ni aaye-kaaye ti won ba wa: ni ile tabi ni ori irin-ajo, nigbati won ba wa ni alaafia tabi won ba n se aisan, nigbati won wa ninu ifokanbale tabi ifoya, gbogbo isesi kookan ni o si ni bi Musulumi yoo se ki irun nibe.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Itumo ati Pataki Ijeri Mejeeji: (LA ILAHA ILLA ALLAH, MUHAMMADU ROSUULU LLAH)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
 
(LA ILAHA ILLA ALLAH, MUHAMMADU ROSUULU LLAH)

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

معنى الشهادتين وأهميتها

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

Itumo ati Pataki Ijeri Mejeeji: (LA ILAHA ILLA ALLAH, MUHAMMADU ROSUULU LLAH)

Alakoko: Itumo (LA ILAHA ILLA ALLAH):

Itumo ijeri yi ni ki eniyan gba pelu okan re pe kosi eni kankan ti o leto si ijosin ni ti ododo ayafi Olohun Allah nikan soso, kosi orogun fun Un ninu awon ijosin ti a nse fun Un, beeni kosi orogun fun Un ninu ola Re.

Olohun- Mimo fun Un- so wipe: (Atipe Emi ko se eda alijonu ati eniyan lasan ayafi ki won le maa sin Mi) [Q:51, 56].

Olohun- ti Ola Re ga- tun so wipe: (Atipe Oluwa re pase pe: E ko gbodo sin nkan kan ayafi Oun nikan) [Q: 17,23].

O je dandan fun Musulumi ki o ni adisokan ti o fi ese rinle fun itumo gbolohun yii gege bi o se je dandan ki o maa wi i pelu enu re.

Ijeri pe kosi elomiran ti ijosin to si ni ti ododo ayafi Olohun Allah, ohun naa ni a npe ni sise afomo ise ijosin fun Olohun Allah, eyi tii se majemu alakoko ti yoo maa je ki ise Musulumi je atewogba ni odo Olohun Allah.

Olohun- Mimo fun Un- so wipe: (A ko pa won lase ayafi pe ki wo josin fun Olohun, ki won se afomo esin fun Un) [Q: 98,5].(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Idajo Wiwa Iranlowo Ni Odo Awon Anabi Olohun Ati Awon Ore Olohun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Idajo Wiwa Iranlowo Ni Odo Awon Anabi Olohun Ati Awon Ore Olohun

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia

Eni ti o tumo re ni: Rafiu Adisa Bello

حكم الاستعانة بالأنبياء والأولياء

« بلغة اليوربا »

الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء

في المملكة العربية السعودية

ترجمة: رفيع أديسا بلو

IDAJO WIWA IRANLOWO NI ODO AWON

ANABI OLOHUN ATI AWON ORE OLOHUN

Ibeere:

Awon iko meji kan wa: Iko alakoko nso wipe: Ebo sise ni ki eniyan maa wa iranlowo pelu awon anabi Olohun ati awon ore Olohun, won sin mu eri wa lati inu al-Kurani ati Sunna ojise Olohun. Iko eleekeji nso wipe: O leto ki eniyan maa wa iranlowo pelu awon anabi Olohun ati awon ore Olohun; nitoripe ayanfe Olohun ni won je, erusin Re ti O sa lesa si ni won. Ejowo, ewo ninu awon iko mejeeji yi ni o wa ni ori ododo?(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

SISO AHON ATI AWON OHUN TI O LE RAN MUSULUMI LOWO LORI RE
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
SISO AHON ATI AWON OHUN TI O LE RAN MUSULUMI LOWO LORI RE

[ Yorùbá - يوربا ]

ABDUR RASHEED ADENIYI ABDUR RAHUF

حفظ اللسان والوسائل المعينة عليه

« بلغة اليوربا »

عبد الرشيد أدينيي عبد الرؤوف

SISO AHON ATI AWON OHUN TI O LE RAN MUSULUMI LOWO LORI RE

Ope ni fun Olohun Oba Alagbara ti O fi ogo Re ati agbara Re da aye ati orun, ti O si fi omo eda eniyan se oludari ati arole lori ile aye, ti O si da awon eda eniyan dara ju gbogbo ohun miran ti O da lo, O da aworan won ti o dun n wo pelu opolo pipe ti O tun fi ke won, O si fun won ni ofin ati ilana ti won yoo maa fi lo eya ara won, ni ona ti yoo ba iyonu Oun Olohun Allah mu, O si fi awon Malaaika ti won lati maa so isesi ati isoro si won. Olohun so ni aaye kan ninu awon ese wura Al-qur'an bayi pe: ([Enikan] ko ni so gbolohun oro kan ayafi ki oluso kan ti wa pelu re) [Suuratu Koof: 18].

Ike Olohun ati Ola Re ki o maa ba Ojise Re Anabi wa Muhammad ati awon ara ile re ati gbogbo eni ti o ba gba ise re gbo titi di ojo idajo, eniti o da majemu fun wa pe "Enikeni ti o ba le so ohun ti o wa laarin irun imu ati irun agbon re – AHON- ati ohun ti o wa laarin itan re mejeeji– ABE- emi yoo fun un ni idaniloju pe yoo wo ogba idera (Al-janna)". [Bukhari ati Muslim].(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

Ola Ti O Nbe Nibi Irun kiki Ati Awon Anfaani Re
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ola Ti O Nbe Nibi Irun kiki

Ati Awon Anfaani Re

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

فضل الصلاة وفوائدها

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

OLA TI O NBE NIBI IRUN KIKI ATI AWON ANFAANI RE

Ninu egba oro kan ti o fi ese rinle okunrin kan ti oruko re nje Robi'ah omo Ka'ab al-Aslami so wipe: Mo maa nsun pelu ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- mo wa gbe omi ti yoo fi se aluwala ati nkan kan ti o ni bukata si wa fun un, o wa so fun mi wipe: {Beere ohun ti o ba fe}, mo si so wipe: Mo fe ki emi wa pelu re ninu ogba idera (al-Jannah), ojise Olohun tun so wipe: {Iwo ko ri nkan miran ti o le beere ni?}, mo wa so wipe: Ohun kan ti mo fe niyi. Nigba naa ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- wa so wipe: {Ti o ba ri bee, se iranlowo fun mi nitori ara re pelu opolopo iforikanle} [Muslim: 489].

Lai si iruju rara, o ye wa ninu hadiisi yi wipe ki erusin Olohun maa fi ori kanle ni opolopo je ohun ti yoo se okunfa ki o wo ogba idera (al-Jannah), aaye ti erusin Olohun si ti maa nfi ori kanle naa ni ibi irun kiki, eyi ti o fi han wa pe irun kiki je ona nla kan ti o gbooro ti o maa nmu eniyan wo ogba idera (al-Jannah).(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

ORO NIPA ABOSI ATI AWON ABURU RE
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
ORO NIPA ABOSI ATI AWON ABURU RE

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

الظلم: حقيقته وأضراره

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

ORO NIPA ABOSI ATI AWON ABURU RE

Itumo Abosi:

Abosi ni ki eniyan fi nkan si ibi ti kii se aaye re tabi ibi ti ko leto si. Abosi ni yiye kuro lori deede ati kikoja enu aala ododo. Bakannaa o tun ntumo si ki eniyan kan gba ohun ti o je eto elomiran ni ona ti ko dun mo eni naa ninu.

Abosi je iwa ti o buru pupo, ti ko si dara rara, fun idi eyi ni Olohun- ti ola Re ga- fi se e ni eewo fun ara Re gege bi ojise Olohun ti so ninu hadiisi kudsi ti o gba wa lati odo Olohun. Olohun so pe: “Mo pe eyin erusin Mi, dajudaju Emi ti se abosi ni eewo fun ara Mi, Mo si se e ni eewo ni aarin yin, ki e ma se maa se abosi” [Muslim: 2577].

Olohun wa Oba mimo Oba ti o ga julo ni ikapa ki O se abosi si awa eda Re ti kosi si eda kan ti o le bi I, sugbon ki awa eda Re le mo wipe abosi je iwa buburu ati isesi ti ko dara ti kosi ni oore kankan ninu, eyi ni Olohun fi se abosi ni eewo fun ara Re; nitoripe Olohun Oba wa daradara ni gbogbo ohun ti O ba se, Oun kii se aburu rara, kosi leto ki a fi aburu ti si odo Re.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

ISE IJOSIN AFOKANSE NI IPILE ESIN
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
ISE IJOSIN AFOKANSE NI IPILE ESIN

[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

Rafiu Adisa Bello

العبادات القلبية أساس الدين

« بلغة اليوربا »

رفيع أديسا بلو

ISE IJOSIN AFOKANSE NI IPILE ESIN

Kinni Itumo Ijosin?

Ijosin a maa tumo si nkan meji:

Alakoko: Ijosin tumo si ki eniyan re ara re sile fun Olohun- Oba Abiyi, Oba ti O ga- pelu ki o maa tele awon ase Re ki o si maa jinna si awon nkan ti O ba ko, ki o maa se awon nkan wonyi ni eniti o n feran Olohun naa ti o si n gbe E tobi.

Eleekeji: Ijosin tun maa n tumo si awon ise ti eniyan n se gan-an lati wa asunmo si odo Olohun. Pelu bayi, ijosin je oruko kan ti o ko gbogbo ohun ti Olohun feran ti O si yonu si sinu, yala awon ohun ti Olohun feran ninu oro siso ni tabi ise sise, eyi ti o han tabi eyi ti o pamo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: