Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
[ Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo ]

·It's Haram To Aid, Promote Or Participate In The Oodua Nation Agitation
·Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara
·Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Aku
·Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba
·Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku
·Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
·L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo
·O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
·Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Wednesday, June 25
· E Gba Mi O, Iyawo Mi Ti So Yara Wa Dile Alawo, Oogun Lo Fi N Won Ile—Aminu
Sunday, June 08
· O Tan Abi Ko Tan?: Taiwo Para Re Nitori Gbese Owo Ele
· Leyin Awuyewuye To Ti Waye Ijoba Ipinle Ogun Fun Oba Omosanya Akinyemi Lopa Ase
· N'Ilorin, Wasiu Atore E Ja Soobu Onisoobu, Won Ti Wa Logba Ewon
· Nitori Atunto Eto Eko L’Osun, Awon Obi Ati Akekoo N Binu Si Aregbesola
Sunday, March 30
· Lori Esun Pe Won Tapa Si Ase Ile-ejo, Babalawo Meji Rewon He L'Osogbo
· N’Igbo Oloyin, Won Ba Ori Oku Lowo Seyi, Lo Ba Loogun Ayeta Loun Fee Fi Se
Saturday, January 25
· Bee Naa Lawon Minisita Ti Won N Sunkun
· Oogun Ni Baba Mi Fi Fa Mi Wa Sile Lati Ilu Eko, Ise Awo Lo Fe Ki N Se—Elemure
· Igbejo Ti Bere Lori Pasito To Fipa Ba Omo Ijo E Sun Nibi To Ti N We Iwe Isegun L
· Adajo Da Oluwole Tawon Olopaa Bariga Fesun Kan Pe O Fee Gbemi Ara E Sinu Tubu Si
Monday, November 25
· Ile-ejo So Obinna Sewon Odun Kan, Moto Onimoto Lo Loo Gbe Ta
· N’Ilorin, Awon Sifu Difensi Ti Won Fi So Opa Epo Loo Ji Bentiroolu Nibe
Sunday, October 27
· Okelola, Olopaa Ti Won Le Lenu Ise Ni Ki Oga Awon Agba Patapata Da Soro Oun
· Awon Odo To Ba Dukia Je Laafin Oba Fatai Aromire Ti Foju Bale-ejo
Sunday, September 08
· Iyawo Ni Kile-ejo Pase Ki Oko Oun Maa Foun Lowo Losoosu
· Nitori Pe Won Tapa Sofin Ile-ejo, Iya Atomo Dero Ewon L’Ondo
· Sina Tale Onile Pelu Ayederu Iwe, O Ti Foju Bale-ejo L’Abeokuta
Thursday, June 13
· N’Ikire, Nurudeen Fipa Ba Omo Odun Mokanla Lo Po, L’Adajo Ba Ju U Sewon Odun Mew
· L’Osogbo, Adajo Ju Eni To Ji Foonu Aregbesola Sewon Odun Marundinlaaadota, Bee O
Saturday, April 13
· Abe E O Rise Oluwa, Were Bimo Sile Iwosan Ijoba Leyin Ti Won Mu Un Kuro Loju Tit
· Awon Olopaa Ti Gbe Jegede To Pa Iyawo Atomo E Lo Sile-ejo
· Oko Mi Ki I Toju Ile Atawon Omo, Mi O Fe E Mo — Mariam
Wednesday, March 20
· N’Ijebu-Jesa, Pasito Gbe Majele Je, O Ni Ile Aye Ti Su Oun
· Ajimobi, O Seun Seun: Lori Siso Eko Ede Yoruba Di Dandan N'ile Iwe
· Eemo Ree O! Abiyamo Somo Nu Sile Akoku, Lawon Kan Ba Fa Oju Ara Re Lo
Wednesday, February 13
· Iku Olori Awon Egbe Ogboni Egbeda To Pokunso Di Eru Jeje Sawon Alabaagbe E Lorun
· Kayeefi Kan Ree Nipinle Kogi: Folorunso Pa Omo Bibi Inu E, O Fi Eya Ara E Setutu
Wednesday, January 23
· O Ga O! Nibi Ayeye Odun Awon Tilu Sao, Omoge Ogorun-un Lo Sile Oko Leekan Naa
· E Gba Wa Lowo Awon Olopaa O, Se Ni Won N Fi Wa Jeun — Egbe Awon Agbebi Ibile Ke

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Abala Ti Akojopo

Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)

Eko ni soki
Kosi isinmi beeni kosi ifayabale fun eru ayafi ki o ni igbagbo si ebubu Olohun ati kadara re, eleyi ni ki o gbagbo wipe ohun ti Olohun ba fe ki o se, ni yio se,ohun ti ko baa fe ki o se,ki yio se,atiwipe, dajudaju, ti gbogbo aye yii ba parapo lori atifi inira kan-an, won ko lee se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile le lori, ni idakeji, ti won baa korajo lati se e ni anfaani, won ko le se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile fun-un.

Oripa (Koko Alaiye):

Alayẹ lori paapaa igbagbọ ninu kadara atipe orígun kan lo jẹ ninu awọn orígun igbọlọhun gbọ.
Alayẹ nipa pe kadara kose fise ikẹwọ lọri ẹsẹ dida.
Ojuse ẹniti ohunti ko tẹẹ lọrun ba sẹlẹ sii ninu kadara.
Awọn oore to mbẹ nibi inigbagbọ ninu kadara.
Isọra kuro nibi ìròrí awọn ẹni anù nibi kadara.


Apa Kini

الحمد لله رب العالمين , خلق كل شيئ فقّدره تقديرا, وقال في محكم تنزيله: " إنا خلقنا الإنسان من نطفة أمشاج نبتليه فجعلنه سميعا بصيرا (1) إنا هديناه السبيل إما شاكرا وإما كفورا" وأشهد أن لا إله ألا الله وحده لا شريك له, سبحانه وتعالى عما يقول الظالمون علوا كبيرا , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله بعثه شاهدا وبشيرا ونذيرا, وداعيا إلى الله بإذنه وسراجا منيرا, صلّ الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا – أما بعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, ọba to sẹda gbogbo agbaye. O da gbogbo nkan, O si pebubu rẹ daada , O sọ ninu tira Rẹ rẹ pe: Dajudaju Awa ni A da eniyan lati ara omi gbọlọgbọlọ ti a ropọ mọ ara wọn, ki a le baa dan an wo, nitorinaa ni A se ni olugbọrọ Oluriran. Dajudaju A ti fi mọ ọna ti o tọ taara: O le jẹ oluse ọpẹ, o si le jẹ alaimore” Suratul Insani: 2 – 3.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Umaru Gbe Oogun Wo Kootu, Ladajo Ba Da Igbejo Duro Kia
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Umaru Gbe Oogun Wo Kootu, Ladajo Ba Da Igbejo Duro Kia

Bii iran lawon ero kootu pelu Adajo Omolade Awope n wo olujejo kan, Ibrahim Umaru, nigba to n jejo ni kootu majisreeti to wa l'Ogba, nipinle Eko, pelu bi ara re ko se bale, nigba ti won si ye e wo, won ba oogun orisii meta lara re.

Umaru wo ewu le okan mole ninu awon oogun ohun, o so okan mo ese o si fi sokoto bo o, bee lo tun se okan ribiti bii oruka to si fi i sowo. Awon ohun ti akowe kootu to ye ara re wo gege bii ase adajo ba yii lo mu ki adajo pase pe ki igbejo Umaru wa sopin lesekese nitori Olorun nikan lo mo ohun to gba lero pelu oogun abenugongo to gbe sara ko too maa rojo, bee ese mi-in lo se tele ti won tori e gbe e wa si kootu naa, sugbon ti oloogun de yii tubo mu oro re dojuru si i ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Fasasi Ko Iyawo e Sile N'Ibadan, O Ni Ko Ro Amala Fun Baba Oun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Fasasi Ko Iyawo e Sile N'Ibadan, O Ni Ko Ro Amala Fun Baba Oun

Ohun to n dun ni ni i po loro eni, ologun eru ku, aso re je okan soso. Bi ki i baa se ooto lowe awon agba yii ni, ko ni i je pe nitori amala lasan lasan ni baale ile kan, Akanji Fasasi, yoo fi ko iyawo e sile ni kootu nitori to ko lati ro amala fun baba e, to ni afebipani obinrin ni i se.

Bo tile je pe iyawo Fasasi, Akanji Odunayo, gan-an lo pe ejo naa, to si ro ile-ejo lati fopin si ibasepo olodun mejo to wa laarin oun atoko e nitori awon ebi oko oun ko feran oun pelu bo se ni won ti folopaa mu oun ri, ati pe eemeji otooto ni iya oko oun binu da gbogbo eru oun sita, bee lawon ebi oko oun tun ti figba kan da eru oun atawon omo oun sita, sibe, o see se ki ile-ejo ba won pari ija naa bi ko se ti ejo toko ro, to ni iyawo oun ko ro amala fun baba oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri

Ogba ewon to wa ni Kirikiri ladajo ni ki won fi ayederu looya kan, Emmanuel Uba, to puro gba milionu mejilelogun naira (N22m) lowo okunrin onisowo kan si titi digba tigbejo mi-in yoo fi waye lori iwa arufin to hu.

Odun 2014 ni won ti koko fesun yiyi iwe ati jibiti kan okunrin naa. Igbejo ohun ni won se ti won fi fun un ni beeli idaji milionu naira (N500,000) ati oniduuro meji. Sugbon ti oro yiwo nigba tawon ibatan Emmanuel meji ti won soniduuro fun un mu esun to awon olopaa lo pe awon ko mo ibi ti afurasi yii sapamo si nitori gbogbo igba tawon ba beere e lowo iyawo atawon omo e ni won ki i le so pato ibi to wa. Eyi lo mu kawon agbofinro topinpin re, ti won si ba a nibi to lugo si labe beedi.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Alake To Fee Ko Oko Dero Ewon N'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Alake To Fee Ko Oko Dero Ewon N'Ilorin

Afi bii igba teeyan n wo sinima ofe loro naa ri ni kootu ibile to wa ni Centa-Igboro, niluu Ilorin, lose to koja nigba tobinrin kan, Adamo Alake, wo oko re, Isiaka Alao, wa si kootu pe oun fee ko o, sugbon to je pe ogba ewon Oke-Kura lo ba ara re nigba to mu adajo ile-ejo naa bu.

Adamo mu esun wa siwaju Adajo Ibrahim Abdulkadri pe latodun marunlelogun toun ti fe Isiaka ni ko ti somo laarin awon, idi niyi toun se fee ko o.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Yekeen Fee Ko Munira n'Ilorin, O Ni Latigba Tawon Ti Fera Loun Ti n Ru, Tou
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Yekeen Fee Ko Munira n'Ilorin, O Ni Latigba Tawon Ti Fera Loun Ti n Ru, Toun n Gbe

Adajo Ibrahim Abdulkadri ti kootu ibile to wa ni Centa-Igboro, niluu Ilorin, ti tu adehun ife to wa laarin baba agbalagba kan, Yekeen Oladipo atiyawo re, Munirat Oladipo, ka lori esun ti baba naa fi kan iyaale ile yii pe latigba toun ti fe e loun ko ti lalaafia mo.

Yekeen lo wo Munirat wa sile-ejo lose to koja pelu ebe pe ki kootu jowo, tu igbeyawo ohun ka nitori toun si ni emi oun i lo. O salaye pe lati osu mejo seyin toun ti fe obinrin yii loun ko ti lalaafia mo, to se pe owo oun to maa n ji si aje ko se bee mo, nnkan ko si lo deede foun mo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un

Beeyan ba gesin ninu obinrin opo; kan, Abileko Medinat Folasade Adekunle, l'Ojoru, Wesde, ose to koja yii, tohun ko ni i kose rara nibi tinu e dun de pelu bi ile-ejo giga kan l'Ore, nijoba ibile Odigbo, l'Ondo, se pase fawon ebi oko e pe ki won gbese kuro lori dukia toko re fi sile saye lo.

Saaju lobinrin naa ati agbejoro re, Amofin Anthony Oyibo, ti mori le ile-ejo giga naa, to si fesun kan awon ebi oko re meji kan, Hamzat Taofeek ati Sherifat Olabiyo, pe won gbese le gbogbo dukia toko re, Oloogbe Hamzat Adekunle, fi sile foun atawon omo re, ti won ko si je ko letoo sawon ogun naa.

Iyaale ile naa ro ile-ejo lati pase pe kawon ebi oko re ohun sanwo to to egberun lona eedegbeta naira (N500,000) fun un gege bii owo gba-ma-binu fun iya nla ti won fi je e tomotomo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Igbeyawo Ogun Odun Daru L'Osogbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Igbeyawo Ogun Odun Daru L'Osogbo

Aare kootu koko-koko kan niluu Osogbo, Oloye Popoola Bolarinwa ti tu igbeyawo Ogbeni Moruf Ademola ati Tawa Ademola ka lori esun aisi itoju to peye.

Arabinrin Tawa lo mu ejo oko re lo sile-ejo naa pe ki won tu igbeyawo ogun odun naa ka nitori pe Morufu ko bikita nipa itoju oun, ati pe bii bara lo se maa n lu oun lojoojumo, bee ni ko fi oun lokan bale lataaro dale ri.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Lori Oro Ti Ko To Nnkan, Awon Olopaa Fibon Fa Femi Lorun Ya, Ni Won Ba Sa Lo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Lori Oro Ti Ko To Nnkan, Awon Olopaa Fibon Fa Femi Lorun Ya, Ni Won Ba Sa Lo

Ori lo ko okunrin eni odun marundinlogoji kan, Femi Olajuyin, yo lowo iku airotele lose to koja pelu bi awon olopaa ti Arabinrinn Funmi Fajuyi toun pelu e jo ni aawo ko wa lati gbe okunrin naa se se e basubasu, ti okan si fi irin ara ibon fa orun Femi ya, die lo si ku ko ba isele naa lo.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe aawo kekere kan lo sele laarin Femi ati Funmi ti won jo kole ti ara won lopopona Tope Alabi, lagbegbe G.R.A, niluu Ado-Ekiti, oro ohun lo si pada waa dohun ti won fi olopaa gbe ara won. Isele naa to bere laaaro kutu ojo kokandinlogbon, osu kokanla, odun yii, lo pada waa so Femi dero eka pajawiri nileewosan ekose Fasiti ipinle Ekiti, EKSUTH, nibi ti won sare gbe e lo pelu bi eje se n da sorosoro lorun e.

Sugbon se ni awon olopaa to waa mu Femi na papa bora leyin ti won gbe e lo sileewosan tan, koda won ko duro gba iwe lati fi han pe awon lo gbe e wa si osibitu, bee ni won ko pada loo wo o lati mo boya o si wa laye tabi o ti jade laye. Yato si eyi, Funmi toun pelu Femi jo ni aawo naa fese fe e, ko si seni to mo ibi to wole si titi di bi a se n so yii.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Won Ti Yo Oga Olopaa To Lu Iyawo Oniyawo Toyun Fi Jabo Lara e Nise
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ipo Adele Oba Saki: Awon Afobaje Atawon Odo Yari Mo Ijoba Lowo

Ka ni oga olopaa kan ti won pe ni DPO toruko e n je CSP Amos Samuel mo pe inu bibi yoo ko oun si wahala nla ni, o see se ko foju fo o da, sugbon ko mo, o si inu bi titi ti won fi le e ni ofiisi e, ti won si da a pada si olu-ileese olopaa ni Eleweran, nibi ti won ti n se iwadii e bayii.

Ileese olopaa to wa ni Eleweran, niluu Abeokuta ni won ti pase fun oga olopaa naa to je DPO won ni tesan Kemta, Idi Aba, pe ko si loo rokun nile titi tawon yoo fi pari iwadii lori bi won se lo na iyawo oniyawo kan toruko e n je Risikat Abosede Bamidele, toyun osu meji si baje lara e. Komisanna awon olopaa nipinle Ogun, Abdulmajid Ali, lo pase yii leyin ti won lo gbo nipa isele to waye ohun.

Samuel la gbo pe o sinu bi lose to koja lohun-un nigba to lu obinrin naa nilukulu lori esun pe o n pe lori foonu lale tiyen sabewo sodo oko e ti won ti mole. Iwe Iroyin Yoruba gbo pe lakooko ti obinrin naa pe okan lara awon egbon oko e lori foonu lori bi won yoo se gba beeli oko e ni oga olopaa ohun rin sasiko, sugbon kaka ko fi suuru yanju e tabi ba obinrin naa soro, se ni won so pe egun aso olopaa to wo gun un, to si da ibinu bole, bee lo ju igbati ako si iyawo oniyawo yii. Leyin to lu u tan lo tun fa obinrin naa le okan lara awon omoose e lowo, tiyen naa si tun koya fun un ko too di pe won ti i mole.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Nitori Kiko Ara Bibo Iyawo, Igbeyawo Falilat Ati Rafiu Tuka N'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Kiko Ara Bibo Iyawo, Igbeyawo Falilat Ati Rafiu Tuka N'Ilorin

Adajo kootu ibile to wa ni Centre Igbooro, niluu Ilorin, ti tu igbeyawo to wa laarin Ogbeni Rafiu Sadiq ati aya re, Falilat Yusuf, ka latari pe Falilat ti so ara bibo di faaji.

Ose to koja ni Falilat wo oko re lo siwaju Adajo Y.K Kayode ti ile-ejo naa, o si ro o lati jowo, ba oun fopin si igbeyawo olomo merin naa. Nigba ti adajo n beere lowo Rafiu pe se o yonda aya re gege bo se wa ninu esin Islam pe oko gbodo yonda iyawo re ki ile-ejo too le fi ofin tu won ka, se ni Rafiu so pe ki ile-ejo dakun gba oun lowo Falilat, nitori to ba le faramo ase oun, oun si nifee re dokan.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Bilikis Sa Kuro Nileewe Nitori Tisa Fee Lu u, Ni Joe Atore e Ba Fipa Ba a Lo Po
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Kayode Omotosho, Ilorin

Bilikis Sa Kuro Nileewe Nitori Tisa Fee Lu u, Ni Joe Atore e Ba Fipa Ba a Lo Po N'Ilorin

Afi bii igba ti omodebinrin kan toruko re n je Bilikis (ta a fi oruko idile bo lasiiri) sa lati inu epo gbigbona bo sinu ina ni nigba to sa fun egba, to waa ko sowo awon afipa-bani-lo-po.

Ojo kokanlelogun, osu to koja yii, nisele naa sele ni ile-eko Queen Elizabeth, ti awon akekoo n gbebe, to wa niluu Ilorin. Gege bi iwadii akoroyin wa se fihan, iya omodebinrin yii, Amudalat Elewure, ti agboole Elewure, to wa ni Niger Road, niluu Ilorin, lo mu esun to olu-ileese olopaa, eka to n ri soro omode (Women and Children Protection Unit) lo pe oun gba ipe pajawiri lati ileewe omo oun. O ni won so pe Bilikis, omo odun metala to wa ni ipele keta (Jss3) di awati, o yo kelekele jade kuro nileewe naa logunjo, ni nnkan bii aago mokanla ale latari pe won fee fiya je e nitori o se akegbe re kan lese.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Odun Kejila Ree Ti Oko Mi Ti File Sile Fun Mi, Mi O Le Duro De e Mo — Rukayat
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Odun Kejila Ree Ti Oko Mi Ti File Sile Fun Mi, Mi O Le Duro De e Mo — Rukayat

''Nigba ti oko mi so fun mi lodun kejila seyin pe oun fee loo sise nipinle Imo, oun yoo pada wale to ba ya, mi o mo pe odidi odun mewaa leyin re ni mi o fi ni i ri i mo. O pada de leyin odun meji to ti wa nibe, sugbon ko je ki n mo ibi to wa titi dasiko yii. Mi o le duro de e mo ni mo se fe ki e tu wa ka.'' Wonyi loro Abileko Ruka Omodeni ti oko re, Nurudeen Omodeni, to n sise kapenta ko sile latodun mewaa seyin pelu omobinrin meta to bi fun un. 

Rukayat so fun ile-ejo koko-koko to wa n'Igando, nipinle Eko, lose to koja pe ise kongila kan lo yoju si oko oun lodun 2003 to fi gba ipinle Imo lo, nigba to pe odun meji lohun-un loun ati baba re loo ki i nibe, igba naa loun si ti foju kan an gbeyin nitori o kuro nibe lai so foun.

O fi kun un pe latigba naa ni foonu re ko ti lo mo, boya o tie waa ku ni tabi o si wa laaye, oun ko mo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Pasito Ni Olorun Fi Iran Han Oun Lati Koyawo Oun Sile, Niyen Ba Ni Iro Lo n Pa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq, Ondo

Pasito Ni Olorun Fi Iran Han Oun Lati Koyawo Oun Sile, Niyen Ba Ni Iro Lo n Pa

Erin arintakiti lawon ero ile-ejo ibile to wa laduugbo Ododibo, l'Ondo, n rin lojo Isegun, Tusde, ose to koja, nigba ti ojise Olorun kan toruko re n je Isaac Agbaje bere si i ka boroboro pe ori oke toun lo ni Olorun ti fi iran han oun pe ki oun ko iyawo oun, Victoria Agbaje, atawon omo maraarun-un to bi foun sile.

Okunrin yii so pe iyaale ile naa ko lemii iteriba foun, bee ni ki i gba amoran agba mo tie. O ni awon iwa palapala owo obinrin yii lo tubo je ki ife re yo lemii oun. O waa be adajo ile-ejo naa lati fopin sigbeyawo olodun meeedogun to wa laarin won.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Baba To Lu Adajo Ni Jibiti Owo Bu Sekun Ni Kootu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Baba To Lu Adajo Ni Jibiti Owo Bu Sekun Ni Kootu

Gbaragada ni baba eni aadota odun kan, Waheed Agboola, atiyawo re bu sekun nile-ejo majisreeti kan niluu Osogbo lose to koja nigba ti adajo pase pe ki baba naa loo naju logba ewon Ilesa titi di ojo kefa, osu kokanla, odun yii, tigbeejo yoo tun waye lori esun ti won fi kan an.

Oro baba yii ko deede yori si ewon nitori pe aaye wa lati gba beeli fun un, sugbon se ni igbagbe se agbejoro re lati beere lowo adajo pe ko faaye beeli sile fun onibaara re, nigba to si ranti si, aso ko ba omoye mo, adajo ti ka idajo ewon fun baba.

Bayii loro yiwo, ti omi si n kan poroporo loju baba agbalagba yii nibi to ti n rababa nile-ejo pe ki won siju aanu wo oun, bee niyawo naa n sunkun pe iriri ose bii meta lewon ki i se eyi to le rorun fun oko oun, sugbon o papa lo lojo naa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

E Gba Mi O, Babalawo Ni Mi O Gbodo Sinku Aburo Mi, O Si Ti N Jera Mole — Lawrenc
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

E Gba Mi O, Babalawo Ni Mi O Gbodo Sinku Aburo Mi, O Si Ti N Jera Mole — Lawrence

Ohun ti yoo sele leyin iku okunrin eni odun metadinlogota kan, Dahun Elerewe, ni ko ti i gba ibi kan ye enikeni pelu bi babalawo kan niluu naa se taku pe afi kawon molebi okunrin to ti doloogbe naa sanwo to le ni milionu kan naira ki won too sinku e, bee oku ti fee maa run ninu ile ti won gbe e pamo si.

Gege bi alaye ti Ogbeni Lawrence Elerewe to je egbon foloogbe naa se f'Iwe Iroyin Yoruba, baba to n gbe laduugbo Aganyan, niluu I®moru, nijoba ibile Ose, nipinle Ondo, ohun ni odun 2010 loun pada wale lati ilu Eko toun n gbe tele, leyin odun keta toun pada de, iyen lodun 2013 ni aisan buruku kan sadeede seyo lara aburo oun naa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Mo n Wa Awon Molebi Oko Mi, Omo Ipinle Kogi Ni, Ise Olopaa Lo n Se To Fi Ku — Fo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Mo n Wa Awon Molebi Oko Mi, Omo Ipinle Kogi Ni, Ise Olopaa Lo n Se To Fi Ku — Folasade

Pelu omije loju ni iyaale ile kan, Folasade Janet Oladoja, eni odun marunlelaaadota fi ba Iwe Iroyin Yoruba soro nile re to wa ni agboole Ari-kaa-koyesi, laduugbo Sando, niluu Ago-Aare, nipinle Oyo, l'Ojoru to koja nigba to n salaye oro aye re.

O salaye pe odun 1992 loun pade oko oun to je olopaa toruko re n je Mohammed Umar niluu kan ti won n pe ni Tabida, nijoba ibile Baruten, ni Kwara. O ni ise ayaworan loun n se niluu naa nigba yen ti Umar to gboye Sajenti ninu ise olopaa fi ko enu ife soun, toun si gba lati fe e nitori oko oun akoko toun bimo meta fun ti doloogbe nigba naa. Boun se fe Umar niyen tawon jo n gbe po bii toko-taya.

Folasade ni oun loyun fun olopaa naa, oun si bimo okunrin kan lojo kerin, osu kejila, odun 1994, nileewosan aladaani kan toruko re n je 'Akintunde Hospital', niluu Saki, awon si so omo naa ni Nurudeen Adeola Umar.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

WIWA MIMO ATI KI A SI LO IMO TI A BA KO
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Ori Minbari Yoruba

WIWA MIMỌ ATI KI A SI LO IMỌ TI A BA KỌ

1- Ipeni si akiyesi lati wa mimọ ti o wulo.
2- Irani leti awọn ẹkọ ti o wa fun wiwa mimọ.
3- Pipe fun sise atunse ilana ẹkọ

Wiwa mimọ jẹ ohun ti Isilaamu kakun babara fun musulumi, ni kika ati kikọ. A o ranti akọkọ ohun ti o sọ kalẹ fun Annabi Muhammad (r) ni ayah ti o sọ Pataki imọ

قوله تعالى:" اقرأ باسم ربك الذي خلق. خلق الإنسان من علق. اقرأ وربك الأكرم. الذي علم بالقلم. علم الإنسان ما لم يعلم".

" maa ka pẹlu orukọ Ọlọhun rẹ, ẹni ti o da ẹda, o fi ẹjẹ didi da eniyan. Maa ka atipe Oluwa rẹ ni Alabunkun julọ ẹni ti o fi kọlamu kọ ni lẹkọ. o kọ eniyan ni ohun ti ko mọ tẹlẹ Suratul Alak: 1-5.

Dandan ni ki Musulumi wa mimọ ki o to maa fi se isẹ. Oluwa sọ wipe(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Ile-ejo So Pasito Pelu Aafaa Sewon, Awon Agbe Ni Won Lu Ni Jibiti L'Emure-E
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Ile-ejo So Pasito Pelu Aafaa Sewon, Awon Agbe Ni Won Lu Ni Jibiti L'Emure-Ekiti

Ewon odun kan gbako nile-ejo majisreeti kan to wa niluu Ado-Ekiti pase pe ki won ju pasito ijo 'Deeper Life' kan, Anjorin Adaniki ati aafaa kan, Mallam Maliu Aliu, si nitori iwa jibiti ti won hu.

Anjorin to je eni odun mejilelogoji pelu ojugba re ni kootu so pe won jebi esun jibiti.

Gege bi olopaa to soju ijoba, Sgt. Oriyomi Akinwale se salaye fun ile-ejo, o ni laarin osu karun-un si osu kefa, odun 2013, lawon olujejo naa lu awon eeyan ni jibiti niluu Emure-Ekiti.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Losu Mefa Pere, Eedegbeta Olopaa Ti Padanu Emi Won - Arase
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olowale Adejare

Losu Mefa Pere, Eedegbeta Olopaa Ti Padanu Emi Won - Arase

O kere tan, awon olopaa bii eedegbeta ni won ti padanu emi won loniruuru ona laarin osu mefa seyin ninu odun yii nikan. Oga agba awon olopaa, Ogbeni Solomon Arase, lo soro yii lasiko to n kopa ninu eto kan tawon igbimo to n ri si ibasepo laarin olopaa atawon araalu nipinle Osun gbe kale. Arase ni nnkan ibanuje ni iku awon eeyan naa je foun, sugbon eleyii tun safihan ife ti won ni si orile-ede yii.

O ni gbogbo ipa loun gege bii oga won yoo sa lati ri i pe iku awon agbofinro naa ko ja sofo. Bakan naa lo ro awon olopaa to wa lenu ise lati mo pe ifara-eni-jin fun ise nikan lo le mu eeyan goke agba. Oga olopaa naa fi kun oro re pe ijoba to wa lode bayii ti ni opolopo nnkan iyanu nipamo to fee fun awon olopaa lati le mu igbe aye rorun fun won. Lara re ni sisan owo osu won deede ati igbega lati le je koriya fun won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Nitori Ikolu Tawon Olokada Festac Town Se Sawon Olopaa, Awon Asofin Eko Gbe Igbi
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq

Nitori Ikolu Tawon Olokada Festac Town Se Sawon Olopaa, Awon Asofin Eko Gbe Igbimo Kale

Ni bayii tile igbimo asofin Eko ti gbe igbimo eleni marun-un kale lati ri si leta ifehonu han tawon olugbe agbegbe Festac Town, nijoba ibile Amuwo Odofin, ko si won pe ki won jowo, fofin de awon olokada agbegbe yii lati yee sise nibe mo lori iwa a-lo-ni-lowo-gba ti won fi kan won ni ko ti i seni to mo ohun ti yoo tidi e yo fawon olokada naa.

Ninu leta ohun ti aare egbe awon olugbe agbegbe yii, Ogbeni Sola Fakorede, ko sile yii lo ti so pe inu-fuu-aya-fuu lawon n gbe bayii, pelu bawon olokada se n fise naa boju sise laabi, ti won n da awon eeyan lona gba nnkan-ini won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Ramdan: Aawe Gbigba Ninu Ramadan Ati Awon Eto Re: Eko ni Nipa Ramadan Ati Ipese
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Ori Minbar Yoruba

Ramdan: Aawe Gbigba Ninu Osu Ramadan Ati Awon Eto Re: Eko ni Nipa Ramadan Ati Ipese Sile Fun Osu Ramadan

Osu Ramadan, osu aponle, ni osu yi ni a maa nsi awon ilekun alijanna, a si maa nti awon ilekun ile ina, osu ti Olohun gbola fun lori gbogbo osu ti o ku, Olohun se ajulo oore fun awon eru re pelu re lati lee silekun afokante pelu ibokun ina kuro lorun, ti Olohun oba ni bibokun ina kuro ni gbogbo oru kookan ninu awon oru re, ohun ti o to fun awon onigbagbo ododo ni ipesesile fun osu alaponle yii, ati igbaradi fun-un siwaju ki o to de, osu yi je alejo abiyi ti kii wa bawa ni odun ayafi ni eekan soso. 

1. Gbigbani ni yanju fun imura silẹ de osu Rọmadan.2. Gbigbani ni iyanju nipa pataki ọla ti n bẹ fun awọn ọjọ ti o wa ninu osu Rọmadan.3. Sise alaye nipa ọla ti o wa fun awẹ ati awọn erenjẹ rẹ.

الحمد لله الذى جعل لعباده مواسم الخيرات يتسابقون فيها بأنواع الطاعات ويتوبون من السّيّئات، وأشهد أن لا إله إلاّ الله وحده لا شريك له فى ربوبيته وإلهيته، وما له من الأسماء والصفات وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله أول سابق إلى الخيرات –صلى الله عليه وسلّم- وأصحابه الذين كل أوقاتهم طاعات وسلّم تسليما كثيراز أما بعد:

A dupẹ fun Ọlọhun, Ọba ti o sẹsa awọn asiko kan ti o lore fun awọn ẹru Rẹ, ki wọn le ni anfaani lati se alapantete lọ si ibi isẹ oloore ki wọn si ronu piwada kuro nibi awọn aburu. A jẹri pe ko si ẹnikankan ti a lẹtọ lati sin niti ododo ayafi Ọlọhun nikan, ko ni orogun nibi dida, sinsin ati nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn irohin Rẹ , bẹẹni a si jẹri pe anọbi wa Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni, Ojisẹ Rẹ si ni pẹlu, asiwaju lo jẹ nibi ise rere sise, ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa baa ati awọn ara ile rẹ ati Sahabe rẹ, to se pe gbogbo asiko wọn tọlọhun ni wọn fi se.· Oluwa wa “Allah” wipe:


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Ohun tawon ariran eke woli, alufa ati oluwo so pe yoo sele lodun yii ree: Eyi ni
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Afolabi

Ohun tawon ariran eke woli, alufa ati oluwo so pe yoo sele lodun yii ree: Eyi ni die ninu ohun ti awon ariran eke wi

Bi odun yii se bere ni pereu lawon wolii, awon araye-rorun eke ninu awon woli, aafaa atawon araye-rorun ti bere si i so awon asotele eke ti nwon ni Olorun fi han awon nipa odun ti a wa yii. Lai ti pariodun opolopo awon awitel eke yii ni o ti ja si iro.

Bawon kan se so pe odun ayo, odun idunnu ni yoo je fawon mekunnu, bee lawon mi-in so pe odun ibanuje ni yoo je fawon to n ni orile-ede yii lara. Bi won se soro nipa eto oselu ni won so ohun ti Olorun fi han won nipa eto oro-aje ati ohun ti yoo sele lagbo awon osere gbogbo.

E wa nnkan fidile tabi ki e fidi le nnkan lati ka ohun tawon araye-rorun eke wonyi so pe yoo sele lodun yii.

Buhari ko le saare orile-ede yii mo, Jonathan ni yoo wole - Ariran-eke Wolii Alajagun Eyi lawon ohun ti Oluwa fi han Wolii Oluwasogo Alajagun tijo ‘Christ Faith Arena Ministry' (Agbala Adura)

Ado-Ekiti, pe yoo sele lodun yii. Eni to ba fe, ko gbo ohun ti emi n so.

“Gege bi emi Olorun alaye se ba mi soro lori awon ohun ti yoo sele lodun yii, ohun akoko to jade ni pe ki awa omo orile-ede yii kun fun adura gidi lori eto idibo to n bo. Emi Olorun so pe eto idibo naa yoo lo nirowo-rose lai ni wahala kankan ninu, bo tile je pe awon kan yoo gbogun dide, sugbon Olorun so pe oun ti pana ogun naa.

“Olorun ko fi Buhari han mi ninu iran naa gege bii aare orile-ede yii, eyi to tumo si pe ko le wole nigba igba to ba n gbegba ibo lati dije sipo aare orile-ede yii, nitori ti a ti fa ijoba re ya. Bee ni mo ri Jonathan gege bii eni t'Olorun fun lanfaani lati sin Naijiria fodun merin miiran. Oore-ofe nla ni Jonathan ri gba, bo tile je pe opo eeyan ni yoo dide ogun si i, sugbon oun ni yoo pada jawe olubori.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Sise akojo owo-ori nipa ilana ayewo ara eni (Self Assessment) (Apa Keji)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Sise akojo owo-ori nipa ilana ayewo ara eni (Self Assessment) (Apa Keji)


SISE AFIKUN OJO TO YE FUN SISAN OWO (1) Fun ti owo-ori lori owo to n wole (Income tax returns), eni to n san an letoo lati kowe si ajo FIRS lati beere fun asiko siwaju si i lati sanwo ohun.


a. Onitohun gbodo fi iwe naa ranse ko too di ojo to ye ko fi akosile owo to san han.


b. O gbodo so idi pataki toun ko fi le ri owo ohun san lasiko to ye.


(2) Ajo FIRS lase lati gba ebe onitohun wole ki won si fun un di asiko to beere fun lati se nnkan to ye ko se ti won ba ri i pe ebe re lese nile.


AWON IDI TO LE MU KI AJO FIRS FASE SI IBEERE FUN ASIKO SIWAJU SI I LATI SANWO (1) Awon idi wonyi ni ajo FIRS yoo wo lati gba ebe fun sisun ojo siwaju si i> a. Ni ti aladaani to n sanwo ori. Ti onitohun ba ti ku ko too di asiko to ye lati sanwo naa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Sise akojo owo-ori nipa ilana ayewo ara eni (Self Assessment)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Sise akojo owo-ori nipa ilana ayewo ara eni (Self Assessment)


(i) Ilana tileese to n gba owo-ori n lo lati gba owo da lori sise akojo ati akosile owo-ori atigbadegba ati sisan owo-ori lasiko ati nigba to ye.


(ii) Enikeni to n san owo-ori gbodo se akosile gbogbo owo-ori to je, ko si san owo-ori naa, leyin naa ni onitohun gbodo fi eri to daju sowo sileese to n gba owo-ori ni asiko to ye lati fi han pe loooto lo sanwo.


(iii) Ileese to letoo lati gba owo-ori, FIRS, yoo tewo gba gbogbo akosile owo-ori teni to n sanwo naa san. Bakan naa nileese ohun yoo se ayewo finnifinni lati ri i daju pe gbogbo ohun to ye ko wa ninu akosile naa ni won se yekeyeke sinu awon foomu owo-ori ohun.


(iv) Eyikeyii asanwo-ori to ba kuna lati fi awon foomu ti akosile owo-ori to san wa sowo si ajo toro kan laarin ojo tileese ohun la kale ti tapa si ilana ati ase to ro mo sisan owo-ori.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Riri i daju pe awon eeyan n finu-fedo sanwo ori (Apa Keji)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Riri i daju pe awon eeyan n finu-fedo sanwo ori (Apa Keji)


Ajo FIRS maa n gba awon olusanwo ori niyanju lati maa sanwo naa tinutinu, lati okan wa ti ko ni i si pe a n fi ipa mu won tabi lo owo ofin kankan. Ife lati sanwo ori ni i se pelu beeyan ba se n tele ofin to ro mo on niluu eni. Fun apeere, keeyan se ooto pelu iye to n wole fun un, ko san iye to ye ko san bii owo-ori lasiko re.


Ifinnu fedo sanwo ori tumo si ki enikan tabi ileese maa sanwo ori won lasiko, lai je pe ajo olowo ori fipa mu won tabi lo ofin ijoba ki won too se bee. Ifinnu fedo sanwo ori ni ki enikan soso tabi ileese ri owo-ori sisan bii ojuse re gege bii omo orile-ede kan tooto, eni ti ko tile duro de ki won ran oun leti to fi mo pe owo-ori too san to si san an.


Ona ti ajo FIRS n gba lati mu ki awon eeyan maa finnu fedo sanwo ori won ∞Nipa sise ilaniloye ati itaniji fun awon toro kan.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Isakoso owo-ori sisan mo oja lorile-ede Naijiria (VAT) (Apa Keji)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Isakoso owo-ori sisan mo oja lorile-ede Naijiria (VAT) (Apa Keji)

*Ajile, awon irinse tawon agbe n lo pelu eyi ti won fi n toju awon nnkan osin
*Awon nnkan ti a fi n ranse sawon orile-ede mi-in, yato si eroja epo robi
* Awon irinse ati ero ti won n lo lati wa epo-robi
*Awon irinse ti awon ileese ko ranse soke-okun lati Export Processing Zone (EPZ) tabi Free Trade Zone to ba je pe se ni won yoo fi gbogbo nnkan tileese naa ba se sowo sorile-ede miin, lai se bee, ori ere tileese naa ba je ni won yoo ti yo owo-ori yii.

*Awon oko irinna pelu eya ara oko.

*Awon nnkan ti ko ni i se pelu epo-robi
*Awon eru ti awon ara ile okeere ba ra*Awon oja to je pe awon ajo to n seranwo fawon eeyan ni won ra won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Isakoso owo-ori sisan mo oja lorile-ede Naijiria (VAT)
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Isakoso owo-ori sisan mo oja lorile-ede Naijiria (VAT)

Owo-ori yii je eyi ti a maa n san mo owo oja ti a ba ra, opolopo orile-ede agbaye ni won si ti fi ife han si i nitori pe o rorun lati seto e, bee ni ko rorun lati foju fo o da. O je owo-ori ti eni to se nnkan tabi to pese ohun kan maa n fi le owo to fee ta oja re. Ori eni ti oja ba gbeyin si ni won ti maa n yo owo-ori yii, eredi e si ni lati je ki owo to n wole fun ijoba labenu ru gogo si i.

Awon koko to ye ki o mo nipa owo-ori asanmoja *Eni to lo nnkan naa gbeyin ni yoo san owo to je ida marun-un ninu ogorun-un.

*Eni tijoba fowo si lo letoo lati gba a.

*O je owo-ori, o si ti wa lara owo ti eni to raja gbeyin n san.

*Ko gbodo ju ida marun-un ninu ida ogorun-un lo.
*Awon ileese ati olokoowo ti won ti forukosile pelu ileese to n pawo wole labenu fun ijoba apapo, iyen Federal Inland Revenue Services (FIRS) ni won letoo lati gba a.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Iya Oloosa ti won lo pa olokada l'Ondo ti ku o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq, Ondo

Iya Oloosa ti won lo pa olokada l'Ondo ti ku o

Yoruba bo, won ni bi a ba pe laye titi, olojo yoo de lojo kan. Oro naa lo se regi iya kan toruko re n je Romoke to n bo Osanyin niluu Ondo. Laipe yii ni Osanyin naa pa okunrin kan ti won n pe ni Abokuusoro, eni tawon eeyan gbagbo pe afojudi lo pa a.

Te o ba gbagbe, omo iya olorisa kan toruko re n je Febisola lese n dun, nitori e lo se ranse si iya e labule kan ti ko jinna siluu Ondo. Bi iya ti ri onise omo e lo gba odo e lo, o si so fun Febisola pe oun ni lati pada sile loo gbe orisa oun wa nitori ese naa lagbara die, yoo si gba koun duro ti i titi ti yoo fi san. Bayii ni Febisola pe ore re to n je Abokuusoro to ni okada pe ko waa gbe iya oun lo lati gbe Osanyin re wa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Nitori Kinni Oko Re Ti Ko Sise Mo, Mosunmola Bu Sekun Gbaragada Ni Kootu, O Ni K
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq, Ondo

Nitori Kinni Oko Re Ti Ko Sise Mo, Mosunmola Bu Sekun Gbaragada Ni Kootu, O Ni Ki Adajo Tu Awon Ka L’Ondo

Erin arin takiti lawon ero iworan kootu ibile kan to wa l’Ondo n rin lojo Isegun, Tusde, ose to koja, nigba ti won ri omobinrin eni ogbon odun kan toruko re n je Mosunmola, eni ti won so pe o yanse oluko laayo nileewe aladaani kan l’Ondo to wo yara igbejo wa pelu bo se bu sekun gbaragada lori ikunle to so pe afi dandan ki adajo ile-ejo ohun tu igbeyawo to wa laarin oun atoko e, Sileola, ka, nitori ti nnkan omokunrin baale ile naa ti dase sile, eyi to lo mu iporuru okan ba oun pupo.

Pelu bi adajo atawon osise ibe ti sa ipa won lati ri i pe obinrin naa dide lori ikunle to wa ninu apoti igbejo to, ko bo si i, eyi lo si fa a ti won fi fi i sile lati rojo e pelu ipo ohun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: