Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.
Onka Ni Oju-Agbo
Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi
E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi
Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran
E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:
Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.
Ona Igba Wole Si Agbo
Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.
Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awokose Igbeaye Ojise-Olorun
Pelu bi awon musulumi jakejado orileede yii se n se ayeye odun Ileya loni, Omooba Dotun Babayemi ti ro won lati ri igbesi aye irele, ife ati ibagbepo alaafia to farahan lara ojise-Olorun, Ibrahim, gege bii awokose.
Ninu oro ikini ku odun re si awon musulumi nipinle Osun, paapaa, niha ekun Iwo-Oorun Osun lo ti parowa yii.
Babayemi, oloselu lati ilu Gbongan ohun woye pe ilana eko Id-el-Adha eleyii to da lorii nini igbagbo ninu Olorun ati gbigbekele ife Re gbodo maa jeyo ni gbogbo igba ninu aye awon elesin Islam.
O ran won leti pe ki i se agbo ti won pa lojo odun tabi eran ti won je lo ni nnkan se pelu Olorun bikose atunhu iwa ati titun igbeaye won yewo.
Babayemi ro won lati mu ife si Allah ati igbagbo ninu Re lokunkundun, ki won si nawo ife yii kan naa sawon alajogbe won nipase eyi ti idagbasoke yoo fi wa nipinle Osun.
Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Ikolu Awon South Africa Si Naijiria - Ekunrere
Okun kii ho ruru ka wa ruru! Bayii ni ijoba apapo se n parowa fawon omo Naijiria pe ki won ye kolu awon ileese to je ti orilede South Africa to wa ni Naijiria lati gbesan isekupani awon omo Naijiria lorilede naa.
Ijoba ni kikolu awon ileese orileede South Africa ni Naijiria yoo ni ipa ti ko dara lara omo Naijiria ju South Africa lo.
Minisita fun iroyin ati asa, Alhaji Lai Mohammed so ninu atejade kan pe bawon omo Naijiria kan ti fi ibinu kolu awon ileese to je ti orileede South Africa lojo Isegun ku die kaato.
Lai Mohammed ni awon omo Naijiria ni oludokowo lawon ileese orileede South Africa, nitorinaa fifi owo ara eni sera eni ni kawon omo Nigeria maa ba iru awon ileese bee je.
Bakan naa ni minisita eto iroyin ati asa ni omo Naijiria lo poju ninu awon osise ileese South Africa to wa ni Naijiria.
Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbesan L'ara South Africa
awon omo Naìjíría ní ìpínle Eko ti gba ìgboro láti koju ìkora eya miran ti awon South Africa ń se fún awon omo Naìjíría.
Ile ìtaja ìgbalóde Shoprite tí agbegbe Lekki ní omobinrin kan ti gbe ìwe ilewo láti bu enu ate lu ìwá akolu ti awon South Africa n se si awon omo Naìjíría.
awon míran tíll ń kigbe pe ki won dáná sun ile itaja náa lójùna ati ranse pada sí awon enìyan South Africa gege bi esan.
Tí e o bá gbagbe awon omo oríle-ede South Africa tí ń ko soobu ti won sì ń pa awon omo Naìjíría ni orile-ede won.
Ìroyìn so pe opo awon tó ń gba ìgboro ló ti padánù awon ebí won nínú wahalá tí awon ará South Africa ń dásíle.
Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N Royin Dasiko Yi
Ese ko gba ero niluu Ekoo lopin ose to koja yi nigba ti Omidan Kanyinsola Fagbayi to je amugbalegbe igbakeji Gomina ipinle Ogun, Onimo-ero Noimot Salako Oyedele se igbeyawo alarinrin, to si je pe gbogbo agbaye lo peju sibe.
Gbongan ayeye M2 Arena to gbajumo daadaa niluu Ekoo ni ayeye naa ti waye, nibi ti molebi, ara, ore, ojulumo atawon ololufe Kanyinsola Fagbayi ati oko re, Oladoye Odunsi ko gba gbogbo agbegbe naa, to si je pe haha ni agbegbe naa di pa.
Lara awon ti won wa nibi ayeye naa ni: Igbakeji Gomina ipinle Ogun funra re, Onimo-ero Noimot Salako Oyedele ati oko re, Alaaji Bode Oyedele; Iyawo Gomina ipinle Ogun, Arabinrin Bamidele Abiodun; Olori awon osise Gomina ipinle Ogun, Alaaji Shuaib Salisu; Onorebu Jimoh Ojugbele to n soju agbegbe Ado-Odo Ota.
Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-Ede South Africa Sile
Awon omo Naijiria ti ko din ni irinwo la gbo pe won ti foruko sile lati fi orile-ede South Afrika sile latari bawon omo orile-ede naa se doju ija ko won, ti won si n pa won nipakupa bi adie irana.
Ajo kan ti won pe ni Nigerian Mission lorile-ede South Afrika ni won fidi oro naa mule laipe yi pe awon ti setan lati ko awon eeyan naa pada si orile-ede won, lati le gba won lowo iku ojiji to n doju ko won.
A gbo pe oko baalu ofe ile ise Air Peace lo gbe eto naa kale lati ko awon eeyan naa kuro.
Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijiria Pelu Awon Omo Re To N Sun Segbe Opopona Niluu Oyinbo
Bi e she n ka iroyin yi, awon omo Naijiria ti ko din ni metalelogun lo ti wa lorile-ede yi bayii latari esun gbigbe kokeeni ti won fi kan won lorile-ede Saudi Arabia.
Adeniyi Adebayo Zikri, Tunde Ibrahim, Jimoh Idhola Lawal, Lolo Babatunde, Sulaiman Tunde, Idris Adewunmi Adepoju, Abdul-Raimi Awela Ajibola, Yusuf Makeen Ajiboye, Adam Idris Abubakar, Saka Zakaria, Biola Lawal, Isa Abubakar Adam, Ibrahim Chiroma, Hafis Amosu ati Aliu Muhammad.
Awon to ku ni: Funmilayo Omoyemi Bishi, Mistura Yekini, Amina Ajoke Alobi, Kuburat Ibrahim, Alaja Olufunke Alalaoe Abdulqadir, Fawsat Balogun Alabi, Aisha Muhammad Amira ati Adebayo Zakariya.
Be o ba gbagbe, lai pe yi ni won dajo fun omo Naijiria kan, Kudirat Afolabi lori esun gbigbe kokeeni, to si tun je pe ko pe lowo tun te Saheed Shobade peluu kokeeni ti ko din ni iwon egberun kan (1,183) giraamu niluu Jeddah.
Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
Lasiko tawon eeyan kaakiri agbaye, paapaa lorile-ede Naijiria ti n shajoyo ayeye odun Ileya lojo Aiku Sande ana, edun okan lo je fawon Fijilante ijoba apapo, Vigilante Group of Nigeria nipinle Ogun fun bi won she padanu okan lara won, Idowu Aderibigbe laipe yi.
Aderibigbe la gbo pe won padanu lasiko tawon olopaa atawon Fijilante loo koju ija sawon ajinigbe ti won ji awon Pasito shooshi Ridiimu, iyen The Redeemed Christian Church of God marun un gbe, to si je pe won pada ri awon eeyan naa gba sile lojo Satide, ojo keta oshu yi.
Won ni Aderibigbe lo fi emi re lele lagbegbe J3 to wa nijoba ibile Ila-Oorun Ijebu, ipinle Ogun peluu ibon tawon ajinigbe naa yin fun un lojiji, to si je pe ki won to o gbero lati du emi e, o ti ta teru nipa.
Ojoru Weside ose to koja yi la gbo pe won sin Aderibigbe siluu Igbotako to wa nipinle Ondo, to si je pe awon Fijilante lo shagbateru isinku naa.
Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun
Leyin orisiirisii awuyewuye, ile-ejo giga ipinle Eko to wa ni Igbosere ti dajo iku fun ogbologboo omo egbe okunkun kan, Adigun Oriyomi, lori esun ipaniyan ti won fi kan an.
Ose to koja nidajo naa waye latenu Onidaajo Oluwatosin Taiwo pe ki won loo yegi fun Oriyomi titi ti emi yoo fi bo lara re nitori pe o jebi esun pe o pa Oluwafemi Adekeye to je ore re lodun 2014.
Iwe Iroyin Yoruba gbo pe o pe ti Oriyomi ti maa n paayan, to si maa n mu un je, sugbon aago re to kun a-kun-wo-sile ni ko se mori bo nigba towo te e pe o gbemii ore re.
Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku
Ibi toro aafaa kan, Olayinka Olawale Abdulateef, to n gbe niluu Ijare, nijoba ibile Ifedore, nipinle Ondo, yoo ja si ni ko ti i seni to le so pelu esun ti won fi kan ojise Olorun naa pe o seyun osu mefa fun orebinrin re, Oyewumi Agbeluyi, eyi to sokunfa iku aitojo fun un lojo Aiku, Sannde, ose to koja.
Gege bi Abileko Funke Isaac, egbon oloogbe yii to fisele naa to Iwe Iroyin Yoruba leti se salaye, ile loun wa lojo ti enikan toruko re n je Omolola fi pe oun pe koun waa wo aburo oun nileewosan ijoba niluu Akure to ti n gba itoju. O ni gbogbo itoju tawon dokita fun Oyewumi ni ko jo pe o sise lara re, nitori igbe inu rirun lo n pa loore-koore, to si n lonu mole bii eni tifun re ti ja si meji.
Funke ni ariwo ti oloogbe naa n pa ni pe ki awon sekilo fawon dokita ki won ma se fa omi soun lara, bee lo be awon eeyan e to duro ti i pe ki won ba oun pe Aafaa Yinka pe ko waa gbe oun lo siluu Ijare, nitori pe oun lo mo agbo ti yoo lo foun tara oun yoo fi ya.
Oro awon oloselu, keeyan fi senu ko dake ni, tabi ki eeyan saa maa woran won ni. Gomina ti won yan ni Kogi yii, Yahaya Bello, yoo si ma dunnu bayii o, koda yoo maa yo. Awon onilu yoo maa lu ilu, awon onijo yoo si maa jo, won yoo so pe awon ti ni gomina tuntun. Ko si ohun to buru ninu ki eeyan se oriire ko dunnu, ko si si ohun ti ko dara ninu ki eniyan ba alayo yo ayo.
Sugbon nibo ni inu eeyan yoo ti maa dun pe oun feru gbabukun. Tabi ta ni yoo so pe oun ko mo pe Yahaya Bello feru gbabukun ni, nibi ti ko ti se lo ti fee je. Ohun ti ko da si ni won pin kan an, ise tawon elomiran se lo di ounje fun un.
Owo olowo leegun n na, aso alaso loga n da bora, ki eeyan sora lati se ami iru adura bee, nitori oba ilu esan. Ki Oluwa ko ma je ka sowo fun omo elomiran je, sugbon eni to ba fee je ise awon mi-in, ise ti oun naa ko se nibe, ki tohun sora o, nitori ifa a maa fa ni lapo ya.
Waheed Ni Ismaila N Ba Iyawo Oun Sun, Lo Ba Sa a Pa N'Ilorin
Gbogbo eeyan to wa ni kootu majisreeti to wa niluu Ilorin l'Ojoru, Wesde, ose to koja lo n beere kelekele lowo ara won iru ife tabi owu jije ti ogbeni eni ogbon odun kan,Waheed Suleiman, ni to bee to fi wo sunsun, to si fi pa eni to ni o n ba oun du obinrin.
Nigba to n safihan re fun ile-ejo, agbenuso ijoba, Inspekito Mojisola Olamokun, fi esun kan afurasi naa pe se lo se iku pa eeyan, eyi to tako abala kan ninu ti iwe ofin to de iwa odaran lorile-ede yii.
Ojo Ileya Ni Shehu Ati Hussein Pa Muhammadu, Ni Won Ba Ge Ori e Fi Soogun N'Ilorin
Ileese olopaa ipinle Kwara ti nawo gan awon afurasi odaran meji kan, Shehu Usman ati Hussein Mohammadu, tawon mejeeji je omo ogun odun latari pe won seku pa Muhammadu Dogo.
Gege bi alaye ti a gbo ni tesan olopaa ti won wo won lo niluu Ilorin, won ni isele naa sele lojo Ileya, nigba tawon Fulani kan ni gbolohun aso laarin ara won, ti won si sa Mohammadu Dogo pa. Leyin eyi ni won gbe saare kekere kan ti won si sin in. Nigba ti ileese olopaa bere iwadii ni won nawo gan awon afurasi mejeeji nitori pe awon ni won ri keyin pelu oloogbe ohun.
Awon Minisita Buhari Tuntun - Awon Eeyan Orisiirisii Aare Muhammadu Buhari Yii
Gbogbo awon omo Naijiria ni won n wo awon asofin wa, iyen awon seneto, pelu awon eeyan orisiirisii ti Aare Muhammadu Buhari fee yan sipo minisita re, won n wo won bi kaluku won se n soro, won n wo awon ti won logbon ninu won, awon ti oro enu won dara, awon ti won mo ohun ti won fee se, ati awon ti won mo ogbon ayinike ati ayinipada. Bo ba je nibi ta a ti fee se nnkan wa bo se to ni, bo ba je bi won ti n se nnkan lorile-aye to ku ni, ko daa rara ko je gbogbo eni ti aare ba fakale pata naa lawon seneto yoo fowo si, gbogbo won naa ko ni won yoo daa, gbogbo won naa ko ni ko ni i labuku.
Eleyii tile le see se lawon orile-ede mi-in, ki i se ni iru Naijiria tiwa yii ni. Awon ti won fesun ole kan wa ninu won, awon ti won kowe wa lati ipinle won wa nibe, awon ti won fi eri ranse pe owo ti won ko je ko see fenu so wa ninu awon ti aare fi oruko won ranse yii o, sugbon awon asofin tiwa ko ri eni kan yo ninu won. Gbogbo won pata ni won dara bii omo oyinbo. Igba to se pe owo awon naa ko mo, won ko le se ise won bii ise.
Iberu owo tawon naa ti ko mi ati iwa ibaje ti won ti hu wa lara awon seneto yii funra won, se awon ni won yoo waa yo enikan danu pe won fesun ole kan an, sebi ole naa ni yoo mo ese ole i to lori apata.
Oga Olopaa Wo Segun To Fipa Ba Alaaja Lasepo N'Ibadan Lo Si Kootu
Fun bo se fi tulaasi ba iya kan to n je Alaaja Serifat Isola, lasepo, to si tun ja a lole owo, ero ibanisoro atawon dukia mi-in, oga agba olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade, ti pe okunrin eni odun mejidinlogoji kan, Segun Muyiwa lejo si kootu.
Ni nnkan bii aago mejila osan Ojoru, Wesde, ojo ketalelogun, osu kesan-an, odun yii, ni Segun ka Alaaja Serifat eni ti a fi ojulowo oruko e bo lasiiri mo oju-olomo-ko-to-o laduugbo ti won n pe ni Eyin Girama, ni agbegbe Iwo Road, n'Ibadan, to si ja a lole awon dukia re, eyi ti apapo re to egberun mejidinlogorun-un naira (N98,000).
E Wo O, Odun Kerin Ree Toko Mi Ti Sunmo Mi Gbeyin, E Tu Wa Ka - Serifat
Awon Yoruba bo, won lowo to ba n dun ni, eeyan ki i fi i sabe aso, bee ni kinni taa n so yii ko se e fi sara ku. Se bo se n sokunrin naa lo n sobinrin, abi ki lo le mu odidi iyaale ile maa rababa niwaju alaga ile-ejo koko-koko pe o to gee, alubata kan ki i darin, to ni ki won ba oun fopin sigbeyawo olodun mefa to wa laarin oun atoko oun, nitori pe o ti le lodun merin bayii tokunrin naa ti beere ohun toun n ta gbeyin.
Lose to koja yii lobinrin ohun to n je Serifat Aralepo mu esun oko re wa sile-ejo koko-koko to wa niluu Ikare-Akoko, nijoba ibile Ariwa Iwo-Oorun Akoko, nipinle Ondo, pe kile-ejo ba oun fopin sigbeyawo to wa laarin oun atoko re ti won pe ni AbdulRasheed Aralepo.
Nitori Obinrin, Awon Fulani Sara Won Pa Lojo Odun Ileya Ni Saki
Gbogboeeyan to n koja ninu oja Sango, niluu Saki, nipinle Oyo, lo n diwo mori, ti won si tun n pariwo ikunle abiyamo nigba ti omodekunrin Fulani daran-daran kan subu sinu agbara eje latari bi elegbe re kan se sa a ladaa ni gbogbo ara, to si gbabe dero orun.
Isele buruku naa waye lojo Abameta, Satide, ojo kerindinlogbon, osu kesan-an, odun yii, nigba tawon odomokunrin Fulani daran-daran kora won jo ninu oja naa lati sajoyo odun Ileya to sese kogba wole. Gege bi ise won lodoodun, awon odo Fulani naa maa n lo anfaani popo-sinsin odun yii lati wa oko tabi iyawo, won a si tun maa lo anfaani naa lati se faaji lorisiirisii.
Akanse Adura Ati Ijoko Pakati Fun Isehinde Mubasiru, Aburo MKO Abiola, To Ku Yio Waiye
Ogoji ojo m bo lona fun akanse eto adura fun Mubasiru, Aburo MKO Abiola ti o di oloogbe. Eto ti n lo lowo bayii, gbogbo awon omo atawon iyawo e pata ni won ti n mura sile fun adura ojo kejo ti won fee se fun aburo Oloogbe MKO Abiola to ku lose to koja, iyen Alaaji Mubasiru Abiola.
Iwe Irohin Yoruba gbo pe gbogbo awon omo okunrin naa pata lo peju pese sile, awon to wa loke okun naa ti n de nikookan, gbogbo won lo fee wa nibi adura ti won yoo se fun baba won yii.
Gbogbo igba ti mo ba loyun loko mi maa n ba mi ja, o digba ta a ba fee loyun mi-in kija too pari—Rukayat
Erin arin-takiti lawon ero inu kootu koko-koko kan to wa niluu Ilorin n rin lose to koja yii nigba ti iyaale ile kan, Rukayat Isa, so pe gbogbo igba toun ba ti loyun loko oun maa n ba oun ja, ija naa ko si ni i pari afi igba tawon ba fee loyun mi-in. Nigba to gbe ejo oko re, Kehinde, lo sile-ejo pe ki won tu igbeyawo won ka, o ni okunrin yii maa n ba oun fa wahala ni kete toun ba ti loyun, oro kan ti ko nidii lo fi maa n daja sile, yoo si tesiwaju digba tawon ba fee loyun omo mi-in, awon eeyan gan-an ko ni i le pari e ko too di akoko naa.
Osalaye pe omo meta loun ti bi fun un, bee loro si se ri lasiko toun loyun awon omo meteeta. Oni iyawo meta loko oun fe, ati pe oun ko ba won gbe inu ile kan naa, okunrin naa gba ile foun nita ni.
Eyi Ni Bi Imaamu Ile Ibadan Se Ku Gan-an: Ki Olohun Gba A Si Ogba Idera Alujana
Titi dasiko yii ni gbogbo musulumi ile Yoruba atawon musulumi Yoruba kaakiri orile- ede yii si n sedaro imaamu agba ile Ibadan, Sheik Suara Haruna, eni to je Oloun nipe leni odun metalelaadorun-un.
Laaaro kutu ojo Ojobo, (Tosde), to koja ni Sheik Suara, to tun je aare igbimo awon aafaa ati lemoomu ile Yoruba titi de ipinle Edo ati Delta, dagbere faye leyin aisan ti awon eeyan gba pe o ni i se pelu ogbo;.
Igbakeji aare igbimo awon lemoomu ati aafaa jakejado ile Yoruba, Sheik Bello Kewulere to tun je imaamu agba Ado-Ekiti lo saaju oke aimoye awon musulumi to kirun si oku baba naa lara ni deede aago marun-un ku iseju meeedogbon, nirole ojo Eti, (Fraide), to koja.
Awon looya kan nipinle Ondo ti won je ololufe Buhari ko ni i gbagbe Ojobo, Tosde, ose to koja yii laelae. Koda akosile isele ojo ti a n so yii yoo ti wonu iwe-isele won pelu bawon eeyan kan ti won furasi gege bii toogi oloselu se din dundu iya fun won lasiko ti won korajo lati sewode atileyin fun oludije sipo aare legbe oselu APC, Ogagun-feyinti Muhammadu Buhari ati igbakeji re, Osinbajo, ninu ibo gbogbogboo ose yii.
Gege bi won se fi iroyin ohun to Iwe Iroyin Yoruba leti, aaro kutukutu Ojobo, Tosde, lawon agbejoro to je ti egbe oselu APC nipinle Ondo kora won lo siwaju ile-ejo giga kan to wa l'Oke-Eda, niluu Akure, lerongba ati sepolongo ojule sojule lati so fawon eeyan ilu ohun pe ki won dibo fun Buhari ati Osinbajo lasiko ipolongo idibo ti o koja.
E fura! Won ti n fi taksi ja awon araalu lole n'Ilorin o
Beeyan ba ri iyaale ile kan bo se n gbe ara sanle lopopona Muritala, niluu Ilorin, laaaro ojo Aje, Monde, ose to koja lohun-un, onitohun yoo kaaanu e. Oko akero igboro taa mo si taksi ni obinrin ohun wo, laimo mo pe ole paraku ni gbogbo awon to wa nibe, egberun lona ogoji naira to fee loo fi ra oja ni won yo lara e.
Iwe Iroyin Yoruba se konge obinrin ohun nibi to ti n yiraa mole legbee titi ni nnkan bii aago mokanla aaro. Se lawon eeyan pe ti i ti won si n petu si i. Bee lobinrin ohun n pariwo, to si n foro awon onise-ibi ohun to Olorun leti. Se ni okan lara awon eeyan to ba wo oko-ero naa fi abefele ya baagi to gbe lowo toun ko mo, won si yo poosi to ko owo naa si lo.
Ohun to tun waa mu oro ohun buru ni pe inu poosi ti won ji lo yii ni gbogbo owo wa to fi mo owo oko to fee wo pada sile leyin to ba ra oja tan. Koda kokoro ile re gan-an wa nibe, agbegbe Sango lo si ti loun fee loo ra eyin.
Lati Owo Akoroyin OlootuE ma ro iku ro Buhari oNibayi ti Buhari ti di aare, ayipada kankan ko jo wipe o le ba ile Yoruba nitori iwa aburu awon omo oduduwa si ara won. Se oro oselu, paapaa nile Yoruba, bii ogun ni. Nile yii lawon oloselu ti maa n ro iku ro ara won, won a si maa ro pe bi ota tabi alatako awon ba ku lawon yoo too le wole ibo, tabi tawon yoo too le wa ni ipo awon. Idi tawon oloselu kan ninu PDP se n ro iku ro Buhari ko yeeyan, ti won n ro pe ko ku nikan lo daa, ko ku lo le mu won wole. Ayo Fayose ni gomina ipinle Ekiti, sugbon bii igba toun gan-an lo n saaju awon ti won n ro pe ki Muhammadu Buhari yii ku laipe ojo ni. Won lo ti dagba, won ni ojo-ori re ti po ju, won ni ko si bo se le sejoba pelu ojo-ori bee, won ni ara re ko tun ya. Bee, gbogbo awon eeyan yii lo mo o, won mo pe oro Olorun ko ri bee. Nigba mi-in, bi a ba gbojule e pe igi gbigbe ni yoo wo;, o le je igi tutu ni yoo wo;, Olorun nikan lo mo ojo tiku yoo pa awon eda aye. Lona keji, igba akoko ko niyi ti eni to ti le lomo aadorin odun yoo dupo aare, ni Naijiria wa yii naa si ni.
Ofo nla lo se laduugbo ti won n pe ni Idunnu, titi de ibi ti won n pe ni Alaku;ta niwaju Apete, n'Ibadan, nibi ti idile meji otooto ti padanu baba ati iya won pelu obinrin kan lati idile mi-in, bee lawon araadugbo naa padanu odidi eeyan marun-un leekan soso.
Inu e¯kun; omi to sele nibi odo Eleyele lawon eeyan naa segbe si nigba ti won n ti ibi ise won lo sile pelu oko oju omi leyin ojo nla to ro ni nnkan bii aago meje si mejo ale ojo Isegun, (Tusde), to koja.
Oruko awon to kagbako iku ojiji ohun ni Ogbeni Nafiu Tunde Yusuf ati iyawo e to n je Moriliat Alaba Yusuf, Sulaiman Ahmed ati Mulikat Ahmed, nigba ti enikarun-un won toun naa je olugbe adugbo Idunnu n je Abileko Ramotalahi Mudashiru.
Oga-agba ileewe awon afoju ni Kwara koro oju si fifi eto awon akanda dun won
Oga-agba akoko fun ileewe awon afoju nipinle Kwara, Ogbeni Sunday Adeshina, ti koro oju si bawon ileese atawon eeyan se maa n feto awon akanda, paapaa julo awon afoju, dun won nipa riri won gege bii eni ti ko ye leni ti won n gba sise tabi ipo kan.
Adeshina to feyinti laipe yii lenu ise lo je oga-agba eka awon afoju nileewe awon akanda ti won n pe ni 'Kwara State School of Special Needs' to wa niluu Ilorin, afoju si loun naa.
Gege bo se so, o ni nigba toun wa ni omo odun mejilelogun toun n gbaradi lati pari ileewe girama loun deni ti ko le foju riran mo, sugbon pelu eyi, oun tesiwaju lati loo pari eko, oun si tun lo sileewe awon olukoni to wa niluu Jos, iyen 'Gindiri Teachers College'.
Leyin osu mefa ti awuyewuye lori eto idibo gomina ti won di koja nipinle Osun ti wa nile-ejo, won ti kede Gomina Aregbesola gege bii oludije to jawe olubori ninu eto idibo ojo kesan-an, osu kejo, odun to koja.
Lojo idajo naa, aago mesan-an ku iseju marun-un lawon adajo meteeta wonu gbongan idajo to wa ninu ogba ile-ejo giga tilu Osogbo, alaga awon adajo naa, Arabinrin Ikpejime Elizabeth, si bere kika idajo re ni aago mesan-an koja iseju mewaa.
Aago merin aabo irole ni obinrin yii pari kika idajo oniwakati meje ataabo re leyin to gbon gbogbo ipejo ati eri oludije fun egbe oselu PDP, Otunba Iyiola Omisore, yebeyebe ni gbogbo awon ijoba ibile metadinlogun ti won so pe magomago ti waye lasiko idibo naa.
Bi won ti kede pe awon ko dibo lojo ti won fee di i mo, bee ni awon ijoba Amerika ti sare bo si gbangba, ijoba London naa sare wa, won si bere si i so pe bi won ti sun ojo naa siwaju ko dara.
Gbogbo ohun ti awon soja Naijiria mo lawon oyinbo yii naa mo, nitori ijoba Amerika so pe ko dara rara ki ijoba Naijiria maa lo oro aabo ilu tabi ti Boko Haram lati fi sun ojo idibo siwaju, won ni awon mo pe iro ni INEC n pa, oje ni won n yo, awon ko si gba oro ti won so gbo pe awon sun ojo idibo siwaju nitori oro Boko Haram nile Hausa.
Ko seni tinu oro naa ko bi loooto, ko si seni ti ko dun, nitori nise lawon eeyan ti won n sejoba Naijiria n fi owu le kobo loju fun wa, won n pe wa ni oponu, won si n se bii eni pe won logbon kan lori to ju tiwa lo, bee, baba nla omugo bayii ni won, ogbon arekereke ti won si n lo yii naa ni yoo pa won.
Awon isele nlaodun to koja: Awon koko inu iroyin ati isele ni odun 2014 - 2015
Ojo kin-ni-ni, osu kin-in-ni • Egberun kan ati igba omo egbe PDP nipinle Kaduna darapo mo APC.
• Onkowe agba, Odia Ofeimun, gboriyin nla fun Oloogbe Obafemi Awolowo nigba to so pe baba Ijebu naa niyi ju asiwaju ile Liberia, Oloogbe Nelson Mandela lo.
Ojo keji,osu kin-in-ni • Ijoba apapo kede pe afikun ko ni i gori owo epo bentiroolu ti awon araalu yoo maa ra.
Ojo keta, osu kin-in-ni • Awon janduku kolu olutele Muhammadu Buhari kan, Alhaji Abdulmajid Danbuiki, ninu mosalasi kan ni Kano. Won lu baba naa gidi.
Iku Ti O Pa Alaaji Azeez Arisekola Alao Aare Musulumi Ile Yoruba, Gbogbo Eniyan Ni Yio Pa! Sun Re O, Alao!
Bi ko ba se ti eja nla to lo nibu yii, ani ti Aare Musulumi ile Yoruba, Alaaji Azeez Arisekola Alao ba si wa laye, yato si pe ojoojumo lo maa n fowo ran awon eeyan lowo, bii ki awon eeyan pe eni awon kan n saisan tabi pe iya owo ileewe n je awon, lati ose ta a wa yii gan-an ni ile okunrin naa iba bere si i gba yun-un fun ogooro awon musulumi ti yoo maa waa gba nnkan aawe lojoojumo, bo tile je pe ile e ki i wule fi ojumo kan sinmi igbalejo ero tele niwon igba to ba wa nile.
Bo ba waa di ojo odun Itunu Aawe, gbogbo awon to ti n jeun ofe lojoojumo yii ni won yoo tun ba a lalejo, Arisekola ko si ni i tori e roju koko, terin tawada ni yoo fi fun won lowo leyin ti won ba je ti won mu tan. Oro yii ko yo awon kristeni paapaa sile, koda to fi mo awon eeyan pataki pataki laarin ilu, eni gbogbo to ba ti lo sile okunrin yii ni yoo dunnu pada sile nitori owo to joju lagba onisowo naa yoo fi ta won lore. Oun si lenikan soso ta a mo nile yii ti odidi gomina ipinle n loo ba sodun nile, ti okunrin alowo-lodu yii yoo si tun di owo si odidi olori lapo bamubamu. Bee naa si ni lojo Ileya odun nla.
Ko jo pe awon ti won n gbara dale fun ekun nile Arisekola lojo ti okunrin naa ku yii tile ti i ranti awon asiko odun ti a n so yii, opo ninu won lo se pe oto ni ohun ti won ba lo sile e tele ki won too se konge ipapoda oloore won. Se o to bii ose meji kan to ti lo si idale, oun funra e lo si dagbere fun won pe oun yoo de l’Ojobo, (Tosde), ojo kejidinlogun, osu kefa, odun yii, ati pe lojo naa gan-an ni ki won waa pade oun nile waa gbowo.
Adehun ti Aare Musulumi ile Yoruba se fawon eeyan yii lelomi-in tori e lo sile e, won ro pe okunrin olowo ti-i-fowo-saanu naa ti de ki won ki i ki won tun le dogbon rowo mu lo sile ni, afi bi won se debe ti won ba gbogbo ara ile lori ekun sisun. Iroyin iku Arisekola dun abiyamo mi-in koja iku omo, o si dun olulufe mi-in wora koja ka pe aya e lo fo sanle to gborun lo. Awon wonyi gba pe ko si nnkan fawon nile aye mo nitori eni to je ki aye nitumo si awon lo ti dagbere faye nni.
Oro awon Boko Haram ko le tan niluu yii bi gbogbo aye se n ro pe ko tan, bee ni a ko le ri awon omo ti won ji ko lo yii boro bo ba se pe ona ti a n gba yii naa la n gba lati wa won.
Lose to koja yii ni won ko awon Hausa bii eedegbeta ti won n fi oru rin ninu awon boosi gboorogbooro lo sipinle Abia, nibi ti won ti n lo lawon soja ti da won duro. Won da won duro, won ni ki won jokoo, won si beere ibi ti won n lo, won ko ri alaye gidi kan se. Iyen lawon yen se so pe Boko Haram ni won, ati pe won n lo lati loo sise ijamba nipinle naa ni.
Idi Ti A Fi Fowo Kun Owo Tawon Omoleewe OAU N San—Bamitale
Oga agba ileewe Obafemi Awolowo University niluu Ileefe, Ojogbon Bamitale Omole, ti so pe fun anfaani awon akekoo ni igbese fifikun owo ileewe naa tawon gbe, ati paapaa nitori ki eni iwaju ileewe naa ma baa di eni eyin lo se pon dandan.
Ose to koja ni Ojogbon Bamitale salaye oro naa latari iroyin kan ti Iwe Irohin Yoruba gbe laipe yii lori ipa ti awon akekoo so pe igbese awon alase ileewe naa yoo ni lori eto isuna won.