Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
[ Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo ]

·It's Haram To Aid, Promote Or Participate In The Oodua Nation Agitation
·Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara
·Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Aku
·Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba
·Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku
·Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
·L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo
·O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
·Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Wednesday, June 25
· Igbeyawo Odun Mewaa Tuka N’Ileefe Nitori Esun Ija Ojoojumo
· Kehinde Gbe Oga E Lo Si Soosi, Lo Ba Gbabe Gbe Moto E Sa Lo L’Ondo
Sunday, June 08
· Ileese Ayani-lowo -sowo Se Gbaju E Fawon Eeyan N'Ilorin, Won Ti Wo Won Lo S
Sunday, March 30
· Aini-asaaju Lo N Fiya Je Yoruba O — Oga OPC Ni Kwara
· Owo Te Pasito To Fee Lu Oga Olopaa Ni Jibiti L'Ekoo
· Akekoo Poli Iree Meji Foju Bale-ejo, Obe Ati Oogun Ni Won Ba Lowo Won
Saturday, January 25
· Se Awon Baba Yii Ko Ni I Loo Sinmi Ni
· Sebi E Ri Eyi Ti Won Se l’Ekiti Lodo Tiwa Nibi Naa...
· Loooto Ni, Ko See Se Ki Yoruba Maa Da Nikan Se Tie Loto, Sugbon...
· Awon Ayederu Babalawo Meta Ti Foju Bale-ejo L'Abeokuta
· Adebayo N Gun Awon Eeyan Labere Losibitu E N'Ilorin, Ase Ayederu Dokita Ni
· Ni Badagry, Lanloodu Pa Alaga Egbe Won Nitori Oro Owo Ina
· Awon Idile Sefunmi To Ku l'Akure Yari, Won Ni Won Pa A Ni
· ‘Ise Jibiti Yii Ko Wu Mi Mo, Ori Mi Gan-an Ko Ro Mo On Rara’
Monday, November 25
· Won Si N Sewadii Ohun To Mu Dokita Kan Pokunso Ni Ketu, L'Ekoo
Sunday, October 27
· Yinusa Ran Awon Agbanipa Si Baba Iyawo Re, Ni Won Ba Sa Okunrin Naa Pa
· Oogun Ki Awon Onile Sun Fonfon Ti Won Ba Fee Wole Won Ni Saliu Atore E Fi N Jale
· Asasi Abi Eedi! Fijilante Yinbon Pa Wale N'Iperu
Sunday, September 08
· Awon Ohun Ti Oju Eni To Ba Fee Sise Fun Yoruba Maa N Ri Ree
· E Gba Mi O, Aje Ni Iya Mi, Oogun Lo Fi Pe Mi Wa Lati Eko To Fi Fi Mi Loko
· L’Akure, Joseph Lu Iya Re Lalubami, O Ni Ko Je Kawon Pin Ogun Baba Oun
· N’Ilorin, Owo Te Wasiu Atore E Ti Won Foruko Akowe Ijoba Lu Jibiti
· Awon Adigunjale Di Eru Jeje Siluu Ondo, Bi Won Ti N Fo Soobu Ni Won N Ja Okada G
Thursday, June 13
· Eni Kan Ko Le Da Yan Asaaju Fun Yoruba O
· Ileese Island Finance Kowo Awon Onibaara Won Lo N’Ilesa, Ni Won Ba Sa Lo Patapat
· Owo Olopaa Te Ramoni Atawon Emewa re, Eyederu Owo Ile Okeere Ni Won N Se Fawon A
· N’Ilorin, Awon Omo Ka Oogun Mo Iyawo Baba Won Lowo, Ni Won Ba Ni Afi Ko Ko Jade
Saturday, April 13
· Kayeefi Ma Loro Adeola Yii O, Omo To Bi Ninu Ara Re Lo Ri Mole Laaye L’Osogbo
· Lojo Ti Won Ko Awon Omo Eyin Eegun Wa Si Kootu, Won Ni Eegun Ti Won Fesun Ipaniy
· Raymond Gbe Omo Alabaagbe Re Pamo Sodo Orebinrin E, Lo bBa Ni Ki Baba Omo Mu Mil

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo

Latigba ti mo ti n soro ashaaju Yoruba, igba kan ma fere koja ti n ko ni i gba atejishe lori awon oba ile wa, paapaa awon ashaaju oba meji ta a ni, Ooni ati Alaafin, pelu Aare Ona Kakanfo. Atejishe ti mo n gba naa ni pe iru awon to ye ko she ashaaju fun Yoruba ti mo n wi niyi, iru awon oba to ye ko ko Yoruba lo sibi ti mo fe niyen, awon oba to lashe lenu. Loooto ni. Ko si ohun ti iba wu mi bi ki eni kan ninu awon meteeta yii je ashaaju fun Yoruba. Idi ni pe awon meteeta ni won ti di ipo naa mu ri, ti won si ko Yoruba debi to dara. Ni ibere pepe, Oduduwa ni olori gbogbo wa, ashe ti Oduduwa ba pa ni gbogbo Yoruba to ku yoo tele nibikibi ti won ba wa, bo ba ti pashe bayii, ashe naa yoo mule ni. Eni to ba si fee mo bi agbara yii ti po to ko ranti igba tawon ilu Ibinni (Benin) n wa olori, to je Oduduwa ni won waa ba ko fun won loba.

Tabi ta ni yoo so pe oun ko mo agbara Alaafin nile Yoruba wa yii. Igba kan ti wa to je o fere ma si ibi kan ni ile Yoruba ti agbara oba nla yii ko de, koda awon ti won ko si labe re gan-an, bo ba pashe, won ko to eni ti i da a koja. Alaafin lo nile, oun ni oba, oun naa si ni olori ilu, ohun gbogbo to ba so, ashe ni. Asiko tire ni ile Yoruba ran kaakiri, ti ijoba re bere lati ile awon Tapa, titi to fi de orile-ede Ghana, ti awon ti won ko si sun mo ilu Oyo rara n fi oruko Alaafin she ohun gbogbo ti won ba fee she. Bo tile je pe nigba ti Alaafin yoo fi maa she olori ile Yoruba yii, awon omo Oduduwa ti fonka, sibe, oba yii fi agbara re ko gbogbo won si abe ara e, o si n she akoso ile naa, ti ko si seni to le beere pe bawo lo she she e, tabi ti yoo so pe oun o ni i tele ashe to ba pa. Eyi ni pe bi Alaafin she olori ile Yoruba lasiko ta a wa yii, ko sohun to buru nibe.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Sugbon Ta La Ri Ba Wi, Bi Ko Je Baba To Fi Omo Re Foko L'oru
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Sugbon Ta La Ri Ba Wi, Bi Ko Je Baba To Fi Omo Re Foko L'oru

Baba kan wa nigba kan, o gba alejo kan sile re, lowo ale ni alejo naa de, bee lo ko opolopo eru ati iwofa dani. O ni oun n lo si irin-ajo kan ni, sugbon ile ti su awon sona bayii, ki baale je ki awon sun moju. Inu baale dun, o ni oun gba alejo pataki, n lo ba bere si i fi ile ponti lo n fi ona roka, se o si ti ri i pe okunrin to de naa, apo nla nla bii marun-un ti won ko kale nibe, owo lo kun inu re fofo.

Nibi ti won ti n salejo ni okunrin olola naa ti taju kan-an to ri arewa omo baba to gba won sile, n lo ba ni oun yoo fe e, bo ba se towo, oun yoo fe e, ale ojo naa loun yoo si fe e.

Ninu apo owo meje o ko marun-un kale, loru ojo naa lo si feyawo re, n lo ba mu un lo. Ase oko ole ni okunrin ti won ro pe olowo ni yii ti n bo, ni feere to si jana lati maa pada lo pelu awon ero, peki–n-reki lo se pelu awon ode nla nla lati agbegbe ti won ti loo ja won lole, ni won ba fija peeta.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Ni 1978, Emo N Lo, Afe N Lo, Azikiwe Nikan Ni Ko Ti i Mo Ibi To Fee Gba Lo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ni 1978, Emo N Lo, Afe N Lo, Azikiwe Nikan Ni Ko Ti i Mo Ibi To Fee Gba Lo

Titi di ipari osu kewaa, odun 1978, egbe oselu kan soso to wa ti ko loluwa ni egbe NPP. Ki i se pe ko loluwa bee naa, ko kan ni asaaju kan ti gbogbo won jo fowo si ni. Ati nitori eyi, isoro inu egbe naa ju ti egbe yoowu lo. Gbogbo eeyan lo ti gbo oruko egbe Unity Party of Nigerian (UPN), ti won si mo asaaju won pe Obafemi Awolowo ni. Bakan naa ni won mo oruko egbe National Party of Nigeria (NPN), ti won si mo alaga egbe naa pe Alaaji Aliyu Makama Bida ni. Bakan naa ni won mo oruko egbe Movement of the People (MOP), ti won si mo pe Fela Anikulapo Kuti ni olori egbe naa. Won tun mo egbe National Advance Party (NAP), ati pe Tunji Braithwaite lolori won nibe. Bee naa ni won si mo People Redemption Party ati pe olori won ni Aminu Kano. Koda, awon egbe keekeeke to ku paapaa ni olori won, gbogbo aye lo si mo won.

Sugbon ko seni to mo olori egbe NPN tabi eni ti yoo du ipo aare loruko won, bo tile je pe awon oloselu nla nla ni won wa nibe, awon oloselu gidi, awon olowo ati awon eni ti won mo lawujo. Awon bii Adeniran Ogunsanya, Kola Balogun, ati opolopo awon ti won je omoleyin Azikiwe ninu egbe NCNC lasiko ijoba awon oloselu atijo. Eyi ni awon eeyan kan se n so pe Azikiwe lolori egbe naa, ti won si ni oun naa ni won fee lo lati du ipo aare loruko egbe won. Awon oloselu inu egbe naa ti won mo eyi ko sise feni meji ju Azikiwe lo, bo tile je pe eni kan ti wa ninu egbe naa to n nawo gidi ju awon to ku lo. Okunrin oloselu kan toun naa ti se oselu daadaa, to si se minisita laye awon oloselu akoko ni, leyin to si kuro nidii oselu, ibon lo n ta, bee lo n ta etu, ati awon ota ibon, eyi si je ki owo re ya mura lasiko ogun abele. Waziri Ibrahim loruko re. Alaaji ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Leyin Odun Mokanla, Bose Fee Ko Oko Re Sile l'Abeokuta: Nitori Orekunrin Re
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Kayode Omotosho, Abeokuta

Leyin Odun Mokanla, Bose Fee Ko Oko Re Sile l'Abeokuta: Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunsoo

Abileko Bose Oladapo lo ti wo oko re, Oladepo Oladapo, lo si kootu koko-koko to wa ni Agbeloba, niluu Abeokuta, o ni oun fee ko o sile latari pe o ti n hale pe oun yoo jogun ile ti oun ko, bee Oladepo ko tun san owo-ori oun. Obinrin naa ni fun odidi odun mokanla ni oko oun fi n foni-donii, fola-dola lori oro sisan owo-ori oun, idi niyen ti oun si she fee ko o.

Esun meta to ka si oko re lese ni pe oun ko nifee re mo nitori ko nifee oun pelu awon omo oun mejeeji, idunkooko mo emi oun pelu awon omo oun ati ifiya-jeni.

Bose ni opo igba loun ti mu ejo oko oun lo si odo awon ebi re, sugbon ko tori re yiwa pada rara.

Nigba to n fesi, Oladapo ni iro niyawo oun n pa mo oun. O ni oniwahala ni obinrin naa, idi niyen ti awon fi maa n ja.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Aafaa Abdulraham Ma N Shere Ni Bebe Ewon, Omo Ile-keu Re Fipa Ba Lo Po L'Ed
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Florence Babashola

Aafaa Abdulraham Ma N Shere Ni Bebe Ewon, Omo Ile-keu Re Fipa Ba Lo Po L'Ede

Won n pe oro ohun lowe, o da bii eni pe o fee maa laro ninu bayii pelu bi omo odun merindinlogun to so pe aafaa kan fipa ba oun lo po she so ni kootu pe ti awon molebi oun ba le gba lati fowo ile to oro naa, she loun yoo pa ara oun si won lorun.

Loshu to koja ni won wo aafaa kan niluu Ede, Habeebullah Abdulraham lo sile-ejo Majisreeti ilu naa lori esun meta otooto. Agbefoba so pe aafaa yii gbe omodebinrin naa pamo, o fipa ba a lajoshepo, o si she e bashubashu.

O shalaye nigba naa pe okan lara awon omo keu aafaa Abdulraham ni omobinrin ti won foruko bo lashiiri ohun, won ni okunrin naa tan an lo sibi eto kan niluu Ilaro, nigba akoko to fipa ba a lashepo.

Nigba ti won beere bi oro she je lowo aafaa, she lo so funle-ejo pe iyawo oun ni omodebinrin to wa ni ipele keta akoko nile-eko girama (JSS 3) ati pe oun ti toro re lowo awon molebi e. Sugbon iya omo yii ati egbon re okunrin to pejo so pe iro pata ni aafaa naa n pa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Arabinrin Ti Fi Iya Jẹ́ Omo ọ̀dọ̀ Rẹ̀ Nitori O Ke Pe Iranlọ́Wọ́

Laaarin awuyewuye ti n lo lowo nipa ifipabalopo, orisirisi obinrin lo ti n so awon nnkan ti oju won ti ri seyin nipa ifipabalopo. Bee ni a si ri awon obinrin miiran ti won ko ni aanu obinrin bi egebe won.

Arabinrin kan, Agatha Ayerite, ti so lori Facebook bi anti omo obinrin kan se fi iya je omo naa nitori egbon okunrin anti naa gbiyanju lati fi ipa ba omo naa lopo ti omo naa si ke sita fun iranlowo.

Agatha ni: ''ejowo olori mo fe ki gbogbo aye ri aworan yii, eyi ninnnkan ti anti se fun omo ti n gbe ni odo re. Egbon okunrin anti naa ti o ba won lalejo gbiyanju lati fi ipa ba omo naa lopo, nitori omo naa ke sita fun iranlowo ni anti naa se lu omo naa bi i ilu bara.''

Iroyin ni, Lagos Island ni isele naa ti waye, ile iwe Lifiaji High School si ni omo naa n lo.

Ọ̀muti ti fi okọ̀ pa awon omo meji: iya ti fi oogun p'ẹ̀fon(sniper) pa omo rẹ̀


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Iyaale Ile To Fi Kokeeni Soyun Ti n Ka Boroboro
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Iyaale Ile To Fi Kokeeni Soyun Ti n Ka Boroboro

Owo ileese to n ri soogun oloro gbigbe lorile-ede yii, NDLEA, ti te obinrin kan toruko re n je Dorothy Onyekas to fi kokeeni soyun. Nise ni obinrin to ti bimo meta naa to n bo lati orileede Dubai fee gbe kinni ohun wole lati papako ofurufu ile wa to wa n'Ikeja. Lasiko tawon ileese to n gbogun ti oogun oloro n sayewo re ni akara tu sepo.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, isesi obinrin yii ati irisi re jo ti alaboyun, sugbon nigba ti won sayewo re lori ero to maa n -ihan ara eeyan bi ohunkohun ba wa nibe ni won ri i pe ki i se oyun lo wa nibe bi ko se idi kokeeni to fee to giraamu meji.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin

Afaimo kawon okunrin meta kan, Wasiu Alayande, to je eni odun mejidinlogbon, Fayose Ebenezer to je eni odun mokandinlogun ati Adeleke Adewale, eni odun mejilelogun ti won filu Ekiti sebugbe ma faso penpe roko oba niluu Ilorin pelu bi ileese olopaa ipinle Kwara se wo won lo sile-ejo lori esun igbimo-po lati sise ibi ati nina owo ayederu.

Nigba to n rojo tako won lojo Isegun, Tusde, ose to koja, Inspekito James Wodi to gbenuso fun ileese olopaa so pe arabinrin olutaja kan toruko re n je Funke lo mu esun to ileese olopaa wa pe soobu oun to wa ni Erin-Ile loun wa ti Ebenezer ati Wasiu ti won wa lati ipinle Ekiti fi waa ra miliiki ati ose iwe tiye owo re je igba naira. O ni obinrin naa se e lalaye pe egberun kan naira (N1000) lawon afurasi naa gbe le oun lowo, toun si fun won ni senji egberin naira (N800.00).


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Onisowo Ibadan Bo Lowo Awon Ajinigbe Leyin Ojo Marun-un Ninu Ahamo Won
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Onisowo Ibadan Bo Lowo Awon Ajinigbe Leyin Ojo Marun-un Ninu Ahamo Won

Ori ti ko obinrin onisowo Ibadan kan, Risikat Badiru, yo lowo iku ojiji pelu bo se ko sowo awon agbenisowo ti won mura lati pa a danu, sugbon ti won pada fi i sile leyin to lo odidi ojo marun-un ninu ahamo won.

Obinrin onisowo yii siwo ise fojo naa, iyen lale ojo Aje, Monde, ti i se ojo kerinla, osu keta, odun yii. Funra re lo si wa oko ayokele e lati ibi to ti n taja dele. Sugbon bo se de enu ona ile lawon eruuku ti won gun okada be gija siwaju e pelu ibon. Oko ayokele Honda re ohun naa ni won si fi waa lo sona jinjin rere.

Gege bi oga-agba olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade, se fidi e mule, inu ile nla kan nitosi ilu Imodi, nipinle Ogun, lawon ajinigbe ohun loo gbe Abileko Risikat pamo si. Leyin naa ni won pe awon ebi e lori ero ibanisoro pe owo awon ti ba iya naa, pipa lawon yoo si pa a bi won ko ba tete wa ogun milionu naira wa, bo tile je pe won pada din owo ohun ku si egberun lona eedegbeta naira (N500,000).


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Nitori Airomobi, Toko-tiyawo Padanu Milionu Merinlelogun Naira Sowo Ayederu Doki
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Airomobi, Toko-tiyawo Padanu Milionu Merinlelogun Naira Sowo Ayederu Dokita Ati Aafaa N'Ibadan

Bi iya nla ba gbe ni sanle, kekere a maa gori eni, adia fokunrin onisowo kan, Ogbeni Caleb, atiyawo e to n je Funke ti won n sunkun airomobi, won mu ookan kun eeji, won gba ile onisegun oyinbo lo nitori aajo ati dolomo laye, laimo pe owo ayederu dokita lawon ko si.

Nigba toju won yoo si fi la, won ti padanu owo bii milionu merinlelogun naira sowo ayederu dokita naa.

O jo pe ayederu obinrin dokita ohun, Damilola Ojo, eni topo awon to mo on saaba maa n pe ni Dokita Dammy ti mo iru isoro tawon toko-tiyawo yii ni. Isoro ohun lo fi wole si won lara pelu bo se so fun Abileko Funke pe ogboju dokita to mo nipa itoju awon aisan to n fa airomobi loun i se, oun si setan lati ran won lowo ninu isoro naa pelu itoju to peye.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Mi o Le Dariji Falilat Lori Eedegberin Naira Mi To Ji, Afi Kile-ejo Tu Wa Ka - A
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu
Mi o Le Dariji Falilat Lori Eedegberin Naira Mi To Ji, Afi Kile-ejo Tu Wa Ka - Alabi
''Oluwami, inu mi ki i dun siyawo mi nigbakigba ti mo ba ti n ranti bo se ji mi ni eedegberin naira (N700) nibi ti mo kowo ohun pamo si. Bee nisele naa ki i sohun ti mo le gbagbe boro laye, ohun ti mo n fe bayii ni pe ki e tu wa ka.'' Eyi lawon oro to ti enu okunrin eni odun mokandinlogbon kan, Muyideen Alabi, to wo iyawo re, Falilat Muyideen, wa si kootu koko-koko kan niluu Akure lori esun pe obinrin naa ji oun ni eedegberin naira jade.

Oro naa ni awon igbimo onidaajo kootu ro pe yoo niyanju, sugbon nigba ti won gbiyanju e titi ti toko-taya ohun taku pe afi dandan ki won fopin sigbeyawo naa lo sokunfa bi alaga igbimo naa se tu igbeyawo olodun mefa naa ka lose to koja.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Awon Ebi Oko Mi Maa n Da Soro Wa Ju, O Ti Su Mi — Fatimo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Awon Ebi Oko Mi Maa n Da Soro Wa Ju, O Ti Su Mi — Fatimo

Omobinrin kelebe ti ojo ori re ko ti i to meeedogbon ni Fatimo Lawal, sugbon ile oko lo wa ko too keru jade laipe yii, koda o ti bimo okunrin kan foko re naa toruko re n je Rasak Lawal.

Ose to koja ni Fatimo wa si kootu koko-koko to wa l'Agege pelu alaye pe oun fe ki kootu ya oun ya Rasak, ki i toju oun latigba toun ti loyun titi toun fi bimo. Ile awon obi re lawon n gbe, iyen lo se je pe gbogbo oro awon pata ni won maa n da si ni gbogbo igba, oun ko si nifee siru e.

O tun salaye pe Rasak maa n lu oun, oun ko si le gbagbe pe baba oun lo sanwo itoju toun gba ninu oyun ati leyin ibimo, okan oun ko bale nile oko, iyen loun se keru jade toun si gba kootu wa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Iyawo Mi Maa n Lu Mama mi, O Tun n Pe Won Lajee — Morufu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Iyawo Mi Maa n Lu Mama mi, O Tun n Pe Won Lajee — Morufu

Babalawo ni Ogbeni Morufu Ajah, ise naa lo n se niluu Eko to n gbe. Ose to koja yii ni baale ile naa mu ejo iyawo re, Deborah Ajah, to fe lodun keta seyin wa si kootu ibile to wa ni Igando, nipinle Eko, pe oun fee ko o sile nitori apa oun ko ka a.

Morufu so fun kootu pe Deborah buru pupo, o maa n lu mama oun sere ni, bee lo maa n pe e lajee. O ni oun funra oun ko bo lowo iya latowo obinrin yii, o maa n lu oun naa nigba tapa oun ko ka a.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Owo Te Baba Agbalagba Pelu Ori Eeyan N'Iloro-Ekiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Owo Te Baba Agbalagba Pelu Ori Eeyan N'Iloro-Ekiti

Okunrin afurasi eni odun marundinlogorin kan, James Adeniran atawon afurasi meta miin nileese olopaa ti wo lo sile-ejo majisireeti agba to wa niluu Ado-Ekiti lori esun pe won ba ori eeyan lowo won.

Awon afurasi ohun, Tope Omoleye to je eni odun mokandinlogun; Femi Ajayi, omo ogun odun; ati Dada Owoeye toun je eni odun marundinlaaadota ni won fesun kan pe won gbimo- po lati hu oku okunrin kan, Peter Ajayi, niluu Iloro-Ekiti, ti won si ge ori re lo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Bee Gbogbo Wa Naa Lole N'ile Yii...
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Bee Gbogbo Wa Naa Lole N'ile Yii...

Bee ni Naijiria yii, ko seni kan ti yoo maa sejoba e ti yoo so pe ara oun mo o, tabi ti yoo so pe owo oun mo, gbogbo wa naa lole, eni ti ile ba mo ba ni barawo ni. Ki i se owo-kiko-je nikan ni iwa ibaje, orisiirisii ni ona ti iwa ibaje fi n wole, ibi to ba ti kan kaluku ni. A-kowoebo ni ki i mo pe ole ni, bee ni awon a-keyin-je ni won ki i mo pe idi n ro adie. Tabi iwa ibaje wo lo ju ka feyin pon ole nitori pe oun je omo egbe oselu wa lo.

Iwa ibaje wo lo ju ka fi eeyan kan si ipo olori ileese ijoba nitori pe o je omo adugbo wa tabi o je ore eni lo, lara awon iwa ibaje naa niyen. Ose to koja ni asiri tu pe ajo EFCC kilo gidi fun ijoba apapo lati ma je ki Abubakar Audu ti i se gomina ipinle Kogi tele du ipo kankan mo nipinle naa nitori ejo ikowoje to n je lowo, nibi ti won ti so pe bilionu kan naira loun nikan ji ko, ati pe owo naa lo na to fi n se oselu kaakiri yii. Sebi ijoba apapo lo ni EFCC, sebi Buhari ni olori ijoba naa, bi oun naa yoo ba fi apeere pe ki enikeni ma huwa ibaje lele, nise lo ye ko so pe Audu yii ko gbodo dije lati du gomina Kogi, ki egbe APC wa eeyan gidi mi-in gbe kale fun awon ara ipinle naa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Aliu Je Kunbi Lowo, Lo Ba Tun Seku Pa a
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Aliu Je Kunbi Lowo, Lo Ba Tun Seku Pa a

Inu ofo nla lawon ara adugbo Olorunfunmi, l'Oworo, niluu Eko, wa bayii latari isele aburu to sele lojo Eti, Fraide, to koja nigba tawon kan deede pa okunrin eni odun mejilelogbon kan, Lawal Afolabi Kunbi, lairotele. Ohun to mu oro naa lagbara ni pe osu meji si asiko yii lo ye ki oloogbe segbeyawo, sugbon awon eni ibi naa da emi re legbodo nitori owo.

Ohun ti Iwe Iroyin Yoruba gbo ni pe l'Ojobo, Tosde, ni okunrin eso alaabo kan to n je Aliu pe Kunbi to ni soobu, to si tun je akekoo eka-eko eto okoowo ni ileewe Lagos State Polytechnic sori aago pe ko waa gba egberun mejilelogbon naira toun je e. Pelu idunnu si niyen fi sare lo sodo re, sugbon ko pada de mo. Nigba tawon eeyan re ko ri i ni won bere si i wa gbogbo agbegbe naa, ojo keji ni won si too ri oku re nibi ti won so o si pelu ora ti won fi we e.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Lori Oro Ipo Gomina: Isiaka, Ma Da Won Lohun, Won Fee Ba e Nawo Ni o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Lori Oro Ipo Gomina: Isiaka, Ma Da Won Lohun, Won Fee Ba e Nawo Ni o

Bo tile je pe opo eeyan lo mo pe ko si giri kan fun Ibikunle Amosun lori oro ibo ti won di koja yii, sibe ariwo ti awon alukoro fun egbe PDP ipinle Ogun ati akede fun ondupo gomina ibe, Gbenga Nasir, n pa lori oro ibo naa ti mu ki aya awon ti eru ko ba tele paapaa maa ja, won n fee mo ibi ti awon adajo to n dajo eto idibo naa yoo da ejo ti won pe Amosun si. PDP so pe ko wole, won ni eru lo se. Bi ko ba je pe awon oloselu feran lati maa da ara won ninu dun, ki won si maa ko awon to n tele won lokan soke pelu oro idaniloju ti won maa n so, bee won mo pe iro lawon n pa o, ko seni ti yoo ro pe won yoo yo Amosun nipo l'Ogun, ni bi nnkan se wa ni Naijiria loni-in yii, ti won yoo waa gbe ipo naa fun Nasir, omo PDP. 

Sugbon awon eeyan naa ko gba, koda lojo ti won loo dajo yii, ohun ti won n ko sori intaneeti kiri ni pe Amosun ti keru e kuro nile ijoba, o ti mo pe loni-in loun se gomina mo, ti won si ya aworan awon kan ti won gbalu ti won n jo sibe.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

E Je Ka Pada Sidii Ise Agbe — Audu Ogbeh
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Akole Iroyin Yii

Pelu bi owo epo se n fojoojumo wale loja agbaye, oloye kan pataki ninu egbe oselu APC, Audu Ogbeh, ti gba ijoba apapo nimoran lati si oju awon araalu pada sidii ise agbe ko too di pe ohun gbogbo ti a n pe ni oro-aje yoo denukole patapata.

O so eyi di mimo lasiko to n soro nibi ipade kan to wa fun ipalemo eto igbelaruge awon nnkan t'Olorun fi jinki ile Afrika, paapaa obi (kolanut), orogbo, ataare, moringa ati bee bee lo. Ijoba ipinle Osun ni yoo gbalejo eleekerin iru ipade ohun ti won pe ni 'Africa's Indigenous Stimulant' (ICAIS-4) lose to n bo.

Audu Ogbeh ni awon adari to ti koja lorile-ede Naijiria kuna lati wa ona miiran towo to n wole labenu yoo fi gbenu soke si i, won gbaju mo oro epo nibi ti won mo pe awon ti le lanfaani lati se owo to n rejo sinu asunwon basubasu.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Leyin Ti Biodun Muti Yo Lo Ba Dukia Olowo Iyebiye Je N'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Kayode Omotosho, Ilorin

Leyin Ti Biodun Muti Yo Lo Ba Dukia Olowo Iyebiye Je N'Ilorin

Afaimo ni okunrin eni odun merindinlogoji kan, Abiodun Balogun, ko ni i sewon bayii pelu bi ileese olopaa ipinle Kwara ti se wo o lo sile-ejo majisreeti kan lati loo salaye nnkan to ri lobe to fi waro pelu dukia olowo iyebiye to baje.

Gege bi iwadii akoroyin wa, isele naa waye lojo kokanla, osu kewaa, odun yii, nigba ti Biodun sadeede pada sile leyin to ti muti yo bamu nita, to si lo taara si yara Oloye James Adeoti ti won jo n gbe ile kan naa loju ona Amadu, niluu Ilorin, to bere si i ba awon dukia baba naa je lai se pe won nija kan ti tele.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Alaigboran Niyawo Mi, O Tun N Soogun, Mi O Se Mo - Otedola
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Alaigboran Niyawo Mi, O Tun N Soogun, Mi O Se Mo - Otedola

Ile-ejo ibile to wa ni Igando, nipinle Eko, ni baale ile kan, Ogbeni Adedola Odetola, gba lo ninu osu kesan-an to pari yii, o ni ki won ba oun fagile igbeyawo odun marun-un to wa laarin oun atiyawo oun, Regina, nitori ko gboran soun lenu. O ni ohun ti iya re ati Anti re ba so fun un lo fi n huwa soun ninu ile, ara oun ko si gba kobinrin ma tele ase oko, kawon si tun jo maa gbe.

Odetola so pe osu mokanla leyin igbeyawo awon ni Regina bere si i se bakan bakan ninu ile, igba naa lo di pe ko maa ko ounje toun ba ra lo sodo mama ati anti re. O ni Regina so pe awon eeyan meji yii lo se pataki ju nigbesi aye oun, ohun ti won ba si so foun loun yoo maa tele, oun ki i se eru oko ti yoo maa sa kubekube labe ase okunrin.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Nnkan Omokunrin Oko Mi Ko Le Domo, E Tu Wa Ka - Abike
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesa

Nnkan Omokunrin Oko Mi Ko Le Domo, E Tu Wa Ka�Abike

Nitori to ni nnkan omokunrin oko re ko le domo, Arabinrin Abike, eni ogoji odun ti wo oko re, Ogbeni Odetola, lo sile-ejo ibile kan n'Ilesa pe ki won tu igbeyawo olodun mewaa to wa laarin awon ka.

Ninu awijare Abike niwaju adajo lo ti salaye pe oko oun dara ninu iwa ati isesi, sugbon lati odun mewaa toun ti wa loode e, oun ko loyun aaro dale ri.

Obinrin naa ni gbogbo awon aburo oun ti won segbeyawo leyin oun ni won ti bi omo meji si meta foko won, eyi toun ri bii ipenija nla toun si gbodo wa ona abayo si pelu adura.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Nwon Ni Oku Orun Gba Tope Loju N'Ifaki-Ekiti, Lo Ba Bere Si i Ka Boroboro
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Taofeek Surdiq

Nwon Ni Oku Orun Gba Tope Loju N'Ifaki-Ekiti, Lo Ba Bere Si i Ka Boroboro

Kayeefi loro okunrin kan, Tope Adigun Omotayo, si n je fawon to gbo nipa isele to sele
si i, nise ni won ni oku okunrin kan, Suraju Fadahunsi, gba a loju, lo ba n ka boroboro pe
oun lowo ninu iku okunrin eni odun metadinlogoji naa.

Isele ohun waye lojo Eti, Fraide, ose to lo lohun-un, nigba ti Omotayo bere si i sa kiri le
yin ti won sin Suraju tan, to si n pariwo pe oku re ko je koun sinmi, to ni gbogbo igba loun
n ri i.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Awon akekoo ileewe olukoni Oro dero ogba ewon fesun sise egbe okunkun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Awon akekoo ileewe olukoni Oro dero ogba ewon fesun sise egbe okunkun

Fun esun sise egbe okunkun ati idunkooko mo awon akekoo egbe won yooku, ile-ejo majisreeti kan to wa niluu Ilorin ti pase pe ki won loo fi awon akekoo marun-un ileewe olukoni tilu Oro, nipinle Kwara, sahaamo ogba ewon.

Awon afurasi ohun ni Suleiman Bolakale, Adebayo Femi, Tajudeen Ridiwa, Olasunkanmi Quadri ati Ambali Lukman.

Ejo awon olujejo maraarun-un ohun ni won gbe wa si eka to n sewadii iwa odaran nileese olopaa ilu Ilorin lati eka ilu Oro nibi towo ti te won lasiko ti won n sose.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

E Gbo Se Sango Leejaq Abi Iro Ni Nwon Fipa Pe Aara San Pa Omoleewe l'Ogijo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

E Gbo Se Sango Leejaq Abi Iro Ni Nwon Fipa Pe Aara San Pa Omoleewe l'Ogijo

Ajalu nla kan sele lojo Aje, Monde, ose to koja nileewe alakoobere 'Local Government', to wa ni Aregun, labule Ilara, Ogijo, nijoba ibile Sagamu, nipinle Ogun. A®a¯ra; lo deede san, to si pa omoleewe obinrin kan toruko e n je Fabian Lawal, bee lawon tisa farapa yannayanna.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, sadeede lategun bere si i fe, to si n ka awon paanu yara ikawe awon akekoo.

Iji lile ti ojo naa mu dani ni won so pe o mu kawon tisa atawon omoleewe naa bere si i sa asala femii won. Nibi ti won sa si ni nnkan tun ti yiwo, pelu bi aara se san, to si pa akekoo kan, eyi to mu kawon tisa naa farapa. Awon to ba akoroyin wa soro so pe ko tile too di pe iji naa n mu owo lile wa lawon tisa ti ko awon omo naa jade pelu ero pe ko ni i sewu nibi ti won sa si.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Awon obinrin rinhooho losan-an gangan l'Emure Ekiti, won ni afi ki Kabiyesi
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Awon obinrin rinhooho losan-an gangan l'Emure Ekiti, won ni afi ki Kabiyesi tu awon odo to ti mole sile


Nise niluu Emure-Ekiti, nijoba ibile Emure, nipinle Ekiti, gbona girigiri lojo kokanla, osu yii, ti i se Ojoru, Wesde, ose to koja nitori bi awon obinrin ilu naa tinu n bi se fehonu han lori bi Kabiyesi ilu ohun, Oba Emmanuel Adebayo, se n fowo ola gba awon mekunnu ilu loju, to si n lo ipo naa ni ilokulo.


Nise lawon obinrin ti won rinhooho pelu ewe lowo yii n ko orisiirisii orin, ti won si n te e mo Kabiyesi naa leti pe dandan ni ko wa ona tawon odokunrin to to ogbon niye tawon olopaa ti mole lojo kesan-an, osu yii, latari pe won n fehonu han lori aini nnkan amayederun yoo fi ri itusile.


Oba Emmanuel Adebayo, eni to ti je igbakeji oga-agba olopaa ri nipinle Eko ati Abuja ko too joba lawon obinrin naa so pe inu awon ko dun si bo se n tuko ilu naa.


Akoroyin Iwe Iroyin Yoruba sabewo siluu Emure, nibe la si ti ri i gbo pe wahala naa bere lojo Aje, Monde, ojo kesan-an, osu keta, nigba tawon odo tinu n bi lori aisi ina ati bi banki kankan ko se sise lati bii osu meje seyin n fehonu han.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Omo Benin ti won mu fun esun ole koba alaga egbe Akoodu n'Ibadan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Omo Benin ti won mu fun esun ole koba alaga egbe Akoodu n'Ibadan


Leyin ose meta ti Iwe Iroyin Yoruba ti gbe iroyin jade nipa okunrin omo orile-ede Benin kan to n je Umoru, titi di asiko yii lawon oloselu si n fi okunrin onisowo kan, Alaaji Mukaila Bolarinwa Olabiyi, sesin nitori ti oruko e jo ti afurasi ole to n ji okada gbe ohun.


Ta o ba gbagbe, ninu iwe iroyin wa to jade lose meta seyin la ti ko nipa bi asiri okunrin kan ti won lo n ra okada tawon ole ba ji to si n tun un ta se tu. Alaaji Mukaila ni won pe okunrin naa, sugbon omoose e to n je Umoru ni won ri mu, oun naa lo si fidi e mule pe Alaaji Mukaila lo ni ofiisi ti won ti n ta okada ohun ninu garaaji oko to wa ni Sango, n'Ibadan.


Bo tile je pe Hausa ni afurasi onisowo oja okunkun ohun, sugbon lati igba naa lawon kan ti n foju ole wo okunrin Yoruba onisowo eja tutu kan toun naa n je Alaaji Mukaila laduugbo Elewure, ni Sango kan naa, bo tile je pe ibi tawon mejeeji ti n se okoowo won jinna sira won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Kayeefi nla kan ree o! Taiwo bimo ti ko lapa ni Ilogbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Kayeefi nla kan ree o! Taiwo bimo ti ko lapa ni Ilogbo


Ero okan idile Mudasiru Sherif ni pe ti Olorun ba so iyawo e to wa nipo oyun layo ati alaafia, tawon si gbohun iya atomo, ojo ti won yoo ba se ikomo, aye yoo gbo, orun yoo mo.


Sugbon ohun ti i ba je ayo fun idile Mudasiru naa lo pada di nnkan mi-in mo won lowo lojo Isegun, Tusde, ose to koja, iyen nigba ti iyawo okunrin naa to n je Taiwo bimo, ti omo naa ko si lapa.


Kayeefi loro naa n je titi di akoko yii fawon to n gbe laduugbo Bosun, Ilogbo, nijoba ibile Ifo, nipinle Ogun, nigba ti won gbo pe arabinrin naa bi aramanda omo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Leyin towo te Kehinde to digunjale niluu Ore, o ni kawon olopaa pa oun ti won ba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Leyin towo te Kehinde to digunjale niluu Ore, o ni kawon olopaa pa oun ti won ba tun mu oun

E jowo, e saanu mi. Be e ba tun ri mi ti mo tun loo jale, se ni ke e pa mi, e ma wule saanu mi mo bowo ba tun te mi. Ki i se pe mo deede n jale o, ebi-o¯ga¯ja¯-fowo;-me;ke; lo sun mi si i, e joo, mi o tun je se bee mo." Eyi nigbe tokunrin eni odun mokanlelogun kan, Kehinde Abiodun, fi bonu latimole olu ileese olopaa to wa l'Akure, nipinle Ondo, lasiko t'Iwe Iroyin Yoruba sabewo sibe l'Ojoru, Wesde, ose to koja.

Kehinde atawon emewa re, Akeem Gbenga, eni odun marundinlogbon ati Henry Obu to je eni odun metadinlogbon lowo awon olode to n so adugbo Kiwi, niluu Ore, nijoba ibile Odigbo, nipinle Ondo, te ni nnkan bii aago meta oru ojo ketadinlogbon, osu to koja, lasiko ti won loo ka awon eeyan kan mole, ti won si ja won lole owo ati ohun-ini bii ero ibanisoro.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Jinnijinni mu Aguiyi Ironsi atawon ti won jo n sejoba re, nigba tawon oba ile Ha
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Jinnijinni mu Aguiyi Ironsi atawon ti won jo n sejoba re, nigba tawon oba ile Hausa ko hilahilo ba a

Gege bi a ti n ba kinni ohun bo, awon kinni kan ti wa nile to n bi awon Hausa gbogbo ninu, atawon soja, atawon oloselu, atawon araalu paapaa, iyen ko too di ojo kerindinlogbon, osu karun-un, odun 1966, ti wahala bere fun ijoba soja Ogagun Agba Aguiyi Ironsi. Awon kinni kan wa to n bi awon Hausa yii ninu, nitori awon naa ti ri i, tabi won ro o lokan, won si gbagbo pe awon Ibo ko wa lati tun aye awon tawon je Hausa se, won fee ba a je pata ni. Eni to ba fee pa ni, a ki i sun asunpara ninu ile e, iyen lawon Hausa yii ti se n se awon eto gbogbo labele, ti won si ti n ba ara won soro ko too di ojo ti won bere ija yii. Ki i se ojo ti kinni yii bu gbamu lo bere, awon kinni kan ti wa nile tele, igba ti Ironsi ko si ri ona yanju awon nnkan wonyi, toun naa ko si huwa bii eni pe ki i se awon Ibo lo n ti i lo je kawon Hausa binu.

Ninu ijoba Ironsi, afi bii eni pe awon Ibo lo n se e ni, nitori awon Ibo lo fi yi ara re ka.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Azeez Yii Ma Buru O: O Pa Iya Ati Omo Leyin To Ta Ile Re Ni Milionu Lona Irinwo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Soyemi Oluyinka ati Adeola Alabi-Oloye

Azeez Yii Ma Buru O: O Pa Iya Ati Omo Leyin To Ta Ile Re Ni Milionu Lona Irinwo Naira

Iroyin kan lo gba ilu Eko kan lojo Abameta, Satide, to koja yii pe won tun ti ri ajaale lagbegbe Ajuwon, won si ti n ri orisiirisii oku nibe, eyi to fa ipaya fawon eeyan. Eyi lo mu Iwe Iroyin Yoruba gba adugbo ohun lo, nibe si lasiiri ohun to sele gan-an ti tu si wa lowo. Awon olopaa to n gbogun ti iwa idigunjale (SARS) n’Ikeja, niluu Eko, lo sawari oku arabinrin eni odun merinlelogota to je oga asobode (Custom) nigba kan, Angela Uzo Kery, ati omo re to je omo odun mewaa, Obiagulum, ti aafaa kan pa laipe yii nibe nitori to ta awon nnkan ini re.

Gege bi iroyin to te Iwe Iroyin Yoruba lowo se fi han, okunrin afurasi onijibiti kan, Alaaji Olatunji Azeez, lo pa obinrin oga asobode ohun atomo e leyin to ta awon ile re ni iye to le daadaa ni milionu lona oodunrun naira. Ile ti okunrin naa sese ra lojule keje, lagbegbe Wadoye, Pipeline, l’Ajuwon, lo sin awon eeyan naa si, bee ni awon olopaa ti ti i pa, ti won si ko ‘Ile adigunjale ati apaayan’ sara re lati fi le awon eeyan sa nibe, bee ni won ko fi adugbo naa sile rara.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: