Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
[ Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo ]

·It's Haram To Aid, Promote Or Participate In The Oodua Nation Agitation
·Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara
·Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Aku
·Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba
·Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku
·Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
·L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo
·O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
·Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, June 18
· Ijoba Akintola din owo koko ku lojiji ni Western Region, lawon agbe onikoko ba b
Tuesday, June 02
· Lojo ti won pa Ironsi ati Adekunle Fajuyi sinu igbo Ibadan, lojo naa nijoba soja
· Remi Fani-Kayode puro mo Ladoke Akintola, sugbon iro naa fee di ooto oro, n l
· Nile ijoba niluu Ibadan, Ironsi jokoo, Danjuma duro, awon soja na orisiirisii ib
· Awolowo binu, Akintola naa binu
· Lojo buruku esu gbomi-mu, Hilary Njoku lawon soja Hausa koko
· Nibi ipade awon minisita ni Western Region, Akintola loun loga, Awolowo loun log
· Awon soja Hausa fi moto ko ibon wolu Ibadan loru, jinnijinni si mu Aguiyi Ironsi
· Lojo ti Ladoke Akintola mu Obafemi Awolowo, oga re, lojiji, o ka a mo ibi ti ko
Tuesday, April 28
· Odaju ma ni Bunmi yii o, o si da omi gbigbona somoodo e lara, o ni ko mo ile i g
· ‘Mo ti ronu piwada, mi o digunjale mo, janduku lo ku ti mo n se leyin awon olose
· Eemo l'Agege! Aafaa fi eyin adie ati iyo we fun Aanu, won lo fee fi soogun
Wednesday, June 25
· Owo Te John, Ayederu Dokita N’Ilorin, O Ti N Ka Boroboro
· Grace Ati Onobong To Gunra Won Nitori Okunrin Ti Foju Bale-ejo
Sunday, June 08
· Ogbon Nla Ni Mo Ri Ko Ninu Ija Emi Ati Lapenleke—Olu Itori
· L'Ogbomoso, Lanledi Gbe Omo Ayalegbe E Pamo, Lo Ba Ni Oore Loun Se Fun Won
· Adigunjale Loo Kawon Eeyan Mo Soosi Ti Won Ti N Se Iso-oru N'Ilesa, Ni Won
· Adeniyi Fogo Mo Egbon E Lori, Adajo Ti Ni Ko Loo Sise Sin Agbegbe Re
· Kehinde Wo Gau Leyin Toun Atawon Egbe E Na Olopaa
Sunday, March 30
· Wolii Lu Tosin Ni Jibiti Milionu Marun-un Naira, O Loun Riran Iku Si I
· Demola Ji Boosi Akero L’Abule-Egba, Ladajo Ba Ran An Lewon Osu Mefa
· N'Iloko-Ijesa, Sunday Fipa Ba Omo Iya Meji Sun, O Ti Wa Latimole Bayii
· Owo Te Wasiu Atawon Ore E Pelu Ayederu Dola Ni Saki
· Owo Olopaa Ti Te Odey To Fipa Ba Omo Odun Meje Lo Po N’Ilesa
Saturday, January 25
· Nitori Adelabu, Awon Akintola Sepade Nile Awolowo Lati Ale Titi Di Ile Mo, Won N
· Eyi Ni Itan Igbesi Aye Batili Alake, Oga Awon Oniwaka To Ku
· Itan Basorun Ogunmola Ile Ibadan, Ogunmola Ologbodo Kri Loju Ogun
· Abiru Awon Odaju Wo Ree! Sunday Atore E Pa Omo Olomo Soogun Owo N'Ilorin
· Nitori Megafoonu, Mudasiru Dana Sun Ore E L'Osogbo, O Ti Wa Logba Ewon
· Leyin Ti Won Gbowo Ati Dukia Re, Awon Adigunjale Tun Yinbon Pa Mohammed N’Ilorin

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

It's Haram To Aid, Promote Or Participate In The Oodua Nation Agitation
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara

Ninu isedale ati idasile itan ile Yoruba, okan pataki ni eya Egba je. Eya kan ni to je pe pupo ninu adamo won ko si ninu awon eya to ku nile Yoruba ti Olodumare si fi ebun ife ati isokan jiǹki won.

Yato sa asa ati ise ti a mo won mo, iwa omoluabi, irele ati ikonimora je ki eya yii di ilu-mo-o-ka kaakiri agbanla aye. A ri eleyii nibi eto isejoba, eto oro aje, eto amuluudun, eto oselu, esin ati awon asa miiran ti a fi le gbe oriyin fun omoniyan.

Nibi eto oselu, Egba lo wa loke titi di asiko yii, nitori pe awon bii Oloye Olusegun Obasanjo, Oloye Ernest Sonekan, Oloye Olusegun osoba ni ko see fowo ro ti seyin. Bakan naa nibi eto oro aje, awon bii Oloogbe Moshood Kasimaawo Abiola ni won ń wa loke.

Nibi eto amuluudun, Egba naa le maa ri niwaju nitori pe awon bii Oloogbe Akin ogungbe, Oloogbe Duro Ladiipo atawon miiran ni won so eto amuluudun dirorun. Bee nibi eto eko, ko tii si ilu kan ninu awon eya Yoruba ti won le figagbaga pelu awon omo Egba ti won ti wa loke atawon to sese ń dide bo bii, ojogbon Wole Soyinka ta gba ami eye agbaye, eyi ti enikeni ko tii gba iru e ri nile Yoruba, paapaa lorile-ede Naijiria, Omoba Bola Ajibola to je oludajo agba nile ejo agbaye ti ko tun tii si iru e dasiko yii. ojogbon Akinwunmi Isola, Debo Alebiosu, Alagba J.F Odunjo, Amofin Bola Solańke to je eni to koko gba oye imo ofin lorile-ede Naijiria, Oloogbe Titilayo Ransom Kuti to je obinrin akoko to koko wa oko nile Yoruba ati lorile-ede Naijiria lapapo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Aku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Akure

Ileewe girama ni Khadijat Oluboyo ati Adeyemi Alao ti koko bere ere-ife, sugbon won ko gburo ara won mo leyin ti Alao koja silu Abuja nibi to n gbe.

Leyin ti Khadija wo yunifasiti Adekunle Ajasin ti ilu Akungba Akoko ni oro ife won tun wo pada, ti Alao, eni ti inagije re n je QS tun bere sii wolewode pelu Khadija omo Alhaji Lasisi Oluboyo to je igbakeji gomina ipinle Ondo tele, Dokita Mimiko.

Lojo Sannde to koja la gbo pe Alao so pe ki Khadija wa ki oun nile lagbegbe Oke-Aro nilu Akure, omobinrin naa si lo sibe sugbon alo Khadija ni won ri, ko seni to ri abo re.

Lojo kefa ti Khadija di awati la gbo pe oku re dede yo si okan lara awon aburo Alao ninu ile, idi niyen ti onitohun fi bere sii wa vbogbo yara lati mo nnkan to n sele.

Iyalenu lo je faburo Alao nigba to ba oku Khadija labe beedi Alao, o pariwo sita, oro naa si di ti olopaa, bee ni won mu Alao.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Itan Bi Ladoke Akintola She Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba

Oro awon oloshelu, too too too ni. Paapaa ni ile Yoruba yii, oro awon oloshelu too too ni. Ni 1964, opolopo eeyan ko ranti oye Aare Ona Kakanfo mo rara. Elomiiran ko tile gbo o ri, won o si mo ohun ti won n pe bee. Bee agbalagba ni won, awon mi-in ninu won si ti le ni omo adorin (70) odun daadaa. Ko le she ko ma ri bee, nitori eni to je Aare Ona Kakanfo yii gbeyin ko too di 1964 yii, Momodu Obadoke Latoosa, eni ti gbogbo aye pada mo si Aare Latoosa ni. Ojo keta, oshu kewaa, odun 1871, lo di aare naa, oun si ni Aare Ona Kakanfo to je gbeyin, nitori lasiko re ni Ogun Ekiti Parapo ti won tun n pe ni Ogun Kiriji waye, ogun naa ko si pari titi ti awon oyinbo fi de. Awon oyinbo funra won ni won pari ogun naa, ti won si shofin pe ko gbodo tun si ija tabi ogun eleyameya laarin awon Yoruba, tabi ni ibi gbogbo ni Naijiria mo.

Nidii eyi, nigba to she pe o din die ni ogorun-un odun ti won ti je Aare Ona Kakanfo yii gbeyin, opo eeyan ni ko ranti mo, afi awon ti won ba n ka iwe itan ile Yoruba nikan. Sugbon ni 1964, awon oloshelu hu kinni naa yo pada, Alaafin Gbadegeshin Ladigbolu si fi Samuel Ladoke Akintola she Aare ile Yoruba ninu oshu kejo, odun naa, oro naa si mu idunnu pupo ati ironu pupo dani fawon eeyan. Bawon kan ti n dunnu pe kinni naa daa, bee lawon mi-in n ronu pe eeti je, kin nitumo oye yii, ki lo si de to je Ladoke Akintola ni won gbe e fun. Oro naa mu awuyewuye ati opolopo ariyanjiyan dani, kaluku shaa fee mo idi abajo ni. Sugbon boya eni kan fe, boya eni kan ko, Akintola ti di Aare-Ona Kakanfo fun ile Yoruba, ko si si ohun ti enikeni le she si i. Ko tie kuro lori ipo naa titi ti olojo fi de ba a ninu oshu kin-in-ni, odun 1966, o lo oye naa titi digba naa ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku

Agutan ti ko ri omo re mo, eran fohun, o ni, 'Nnkan n be!' Nnkan n be loooto fun Naijiria, nitori nigba ti iya nla ba gbe ni sanle, keekeeke a si maa gori eni. Iya nla ti gbe Naijiria sanle bayii, awon keekeeke si n gun ori Naijiria, orile-ede ti gbogbo aye n gbe gege laarin odun 1960 titi wo 1980 waa di orile-ede yeye, orile-ede ti kaluku fi n se eleya kaakiri. Igba kan ti wa to je ko si ohun ti won yoo se ni gbogbo ile Afrika pata, ti Naijiria ko ba ti da si i, ko seni ti yoo bere re, enu Naijiria nikan ni ase wa nigba yen.

Sugbon ohun to n sele ni orile-ede South Afrika bayii ti fihan pe Naijiria ati awon omo orile-ede yii ko je nnkan kan mo nibikibi, eni yeye lasan lawon eeyan orile-ede agbaye gbogbo ka wa si. Ni South Afrika lose to koja, eyin naa kuku ti ka a, e si ti ri i bi awon omo orile-ede ohun ti tu awon omo Naijiria sihooho, ti won n na won, ti won n wo won nile, ti won n dana sun won, ti won si n ko soobu ati eru won, ti won n fo moto won tuu tuu, to si je gbogbo omo Naijiria ti won ba ti ri loju ona ni won n se lese. Oro naa buru jai, koda, won o gbodo se eranko to bi won ti n se wa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Adefunke Adebiyi

Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete

Awon esun nla bii pipe ara eni lohun ti a ko je, shishe ayederu iwe ajo eleto idibo ile wa (INEC), titan araalu je ati esun merin mi-in ni Akanni Toluwalope n rojo le lori bayii nipinle Eko, leyin ti won mu un pe o she sofin ijoba.

Adugbo kan ti won n pe ni Madogun, nipinle Ogun, ni Akannni, eni ogbon odun n gbe, sugbon Ijaye Ojokoro, nipinle Eko, lo ti lu awon eeyan ni jibiti owo nla gege bi Agbefoba, Augustine Nwabuisi, she shalaye ni kootu Majisireeti to wa ni Yaba, l'Ojobo to koja yii.

O shalaye pe Akanni puro fawon eeyan ninu oshu kefa, odun yii, pe oun ti wole gege bii omo ile igbimo ashoju-shofin (House of Representatives). Koda, ki won le baa gba a gbo, iwe kan ti ibuwolu alaga INEC wa, ti won si ki i ku oriire pe o wole gege bii omo ile igbimo ashofin naa lo fi n han awon eeyan kiri. Bee ayederu niwee naa, okunrin yii lo she e funra e, ki i she INEC rara.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Florence Babashola

L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo

Awon marun-un ti igbagbo wa pe won je omo egbe okunkun toruko won n je Eiye Confraternity, Nasirudeen Jamiu, eni odun metadinlogbon, Ganiyu Saheed, eni odun meeedogbon, Adebisi Idris, eni odun merinlelogun, Adeoye Sodiq eni odun merinlelogun ati Kasali Afeez toun naa je omo odun merinlelogun ti won fesun kan pe won pa Monsuru Lawal ni won ti foju bale-ejo Majisreeti ilu Oshogbo bayii.

Esun meta otooto to ni i she pelu gbigbimo-po huwa buburu, ipaniyan ati jije omo egbe okunkun ni won fi kan awon olujejo yii.

Agbefoba, Inspekito Elisha Oluwashegun, shalaye pe awon olujejo ohun pelu awon mi-in ti owo ko ti i te ni won huwa ohun lagbegbe Isale-Oshun, lojo kesan-an, oshu keje, odun yii.

Oluwashegun so siwaju pe gbogbo esun ti won fi kan awon olujejo ni alakale ijiya won wa labala ikerinlelogota (64) ati okooleleeedegbeta o din merin (516) ofin iwa odaran ti odun 2002 tipinle Oshun n lo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin

Ileese olopaa ipinle Kwara niluu Ilorin ti kede sita pe awon n wa odomobinrin eni odun mokandinlogun kan, Sa'adat Olajumoke Bakare ti won lawon obi e ko ri lati ojo Aje Monde ose to koja yi, iyen ojo keji osu ti a wa yi.

Akekoo fasiti ipinle Kwara tiluu ilorin, iyen University of Ilorin la gbo pe Olajumoke wa ni eka ikekoo ise ile ati ounje igbalode ti Oloyinbo n pe ni Home Economics and Food Science Department.

Fun enikeni to ba kofiri Olajumoke, awon nomba yi ni ki e pe 08062623867 or 08056678859


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Baba Ti Omo Rẹ̀ Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa

Baba Ti Omo Rẹ̀ Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa

Arakunrin omo odun metalelogun, ti o n je Basty Abass, ti wa ni atimole fun ogun odun ni Nkwanta south ti Oti region, ni orile-ede Ghana, ti a gbo pe baba re ti mole nitori o ni warapa.

A gbo lati oju feresi nikan ni Abass ti ma n fi oju kan ina, o ma n se igbonse,o ma n to, o ma n jeun, o si ma n sun sinu yara naa, ti won fi agadagodo to tobi ti pa ki o ba ma le jade.

Baba re, Mallam Abass Abdulai, so fun MyJoyOnline, idi ti o se ti omo naa pa, o ni omo naa ni warapa, ko le da ronu funra re, ti e ba si salaye bi o se le toju ara re fun, ko le ye.

Mallam Abass ni omo oun ma n yagbe kaakiri ile, pe oun si ro pe nnkan to da ju lati se ni ki oun ti i pa mo yara fun ogun odun. O ni nigba ti o wa ni omo osu mejidinlogun ni iya re ti gbe sile ti ko si boju weyin lati igba naa. Iya iya re lo to ti oun naa ti je olorun nipe.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

a: a-a-lọ́-o 

B: a-a-lọ́

a: alo mi da fiiriri gbaa-gboo.

B: Ko ma gbagbo omo mi lo.

alo mi dale lori ijapa ologbon ẹ̀we pelu ikarahun e.

Lojo ti o soju ojo ko, to tutu bi aajin t'ewe si n fe lele lele, ijapa n re koja lojuna oja.

Se gbogbo wa la s'akiyẹ̀si pe ijapa feran lati maa keti. Nise ni o gbo pe atioro ati ikun n soro ohun. Ni kiakia ni o rapala wo abe tabili ti wọ́n n gbe taja.

Atioro lo n soro lowo, o ni: Nkan ti e le fira mi sipo ti ijapa wa, ki maa rababa nilẹ̀ pelu kinikan kante leyin bi igba ti wọ́n n pe ni ikarahun. Oorun ayeraye ni kinni ọ̀hun o faa pẹ̀lu ahamọ́ nla.

Ikun ni : Mama da alawada rẹ̀ lohun. Bo sẹ̀mi ni Eledua fi iru e dalola, maa ti yo kuro ninu rẹ̀ tipatipa. Ki ategun rere rohun fesi oluware leyin.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Owo Te Happiness To Ji Omo Olomo Gbe Sa Lo L'Ekoo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Owo Te Happiness To Ji Omo Olomo Gbe Sa Lo L'Ekoo

Ileese olopaa ipinle Eko ti n ba iwadii lo lori bi okunrin kan, Happiness Umah, se ji omodebinrin kekere kan lagbegbe Ijora, sugbon ti owo won te e ko too gbe e sa lo patapata.

Iwadii Iwe Iroyin Yoruba fi han pe omo osu meje pere ni omobinrin toruko re n je Favour ohun, o si ku die ki Happiness ri i gbe sa lo kowo too te e. Ohun ti a ri gbo ni pe awon olopaa ayarasise (Rapid Response Squad) to n sise lagbegbe Eric Moore lo ri okunrin naa ti won si fura si irin ese re. Nigba ti won beere bi omo se je lowo re, o ni omo oun ni, sugbon nigba ti ibeere po lo tun ni se loun ri omo naa ninu igbo nibi to ti n sunkun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Igbeyawo Odun Merinla Fori Sanpon L'Ore
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Igbeyawo Odun Merinla Fori Sanpon L'Ore

Oro beyin yo nile-ejo giga kan to fikale siluu Ore, nijoba ibile Odigbo, nipinle Ondo, l'Ojoru, Wesde, ose to koja yii, pelu bi kootu ohun se pase pe ki Ogbeni Omojeje Ajisola Victor sanwo to to egberun lona eedegbeta naira (N500,000) fun iyawo re to fee ko sile, bee lo ni odo iyawo, Folasade Omojeje, ni kawon omo mejeeji tigbeyawo naa so leso maa gbe.

Omojeje to je oko-iyawo la gbo pe o mu esun iyawo re lo sile-ejo giga pe ki won tu igbeyawo odun merinla to wa laarin awon ka, kile-ejo naa si pase fun iyawo lati yonda awon omo mejeeji to bi fun un lati maa toju won, sugbon iyalenu loro ohun je fawon ero kootu pe okunrin to pejo naa lo pada jebi bo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Oko Mi Maa n Lu Mi Ti Mo Ba Ti Ba Awon Omo Wa Wi — Mutiya
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Oko Mi Maa n Lu Mi Ti Mo Ba Ti Ba Awon Omo Wa Wi — Mutiya

Ile-ejo koko-koko kan niluu Osogbo ni arabinrin Azeez Mutiyat kegbajare lo pe bi oko oun ko se ba oun fowo sowo po lori itoju awon omo lo fa a tawon omo awon fi n jale kaakiri ile.

Obinrin yii ni nigbakigba ti eyikeyii ninu awon omo merin tawon bi ba ti jale, ti oun si ba a wi bayii, alubami loko oun yoo lu oun, ti yoo si so pe oun ko gbodo fowo kan won mo, eyi to n fa a to fi soro fawon omo ohun lati fi ole jija sile.

Bakan naa lo ni oko oun ki i sojuse re ninu ile, bee ni ko mojuto oun atawon omo rara.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Iyawo Mi n Lepa Emi Mi, E Tu Wa Ka —Alagba Oluwasesan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Iyawo Mi n Lepa Emi Mi, E Tu Wa Ka —Alagba Oluwasesan

Adajo ile-ejo koko-koko to fikale sagbegbe Oke-Eda, niluu Akure, ti fopin sigbeyawo olodun mejilelogun kan lori esun idunkooko mo emi eni ti baba eni ogota odun kan, Alagba Oluwasesan Olasehinde, fi kan iyawo re, Abileko Seri Olasehinde.

Alagba Oluwasesan to je efanjeliisi ninu ijo alaso funfun kan l'Akure lo wo iyawo re wa si kootu naa, to si n be adajo pe ko jowo ba oun fopin si ibasepo ohun nitori ti obinrin olomo meji naa n lepa emi oun, bee ni ko mo itoju ile i se.

O pari oro re pe gbogbo awon iwa buruku to kun owo obinrin yii ti je ki ife re yo lemii oun patapata, ohun toun si n fe bayii ni pe ki adajo fopin sigbeyawo naa koun le lalaafia to peye.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Odidi Odun Meta Loko Mi Fi Pa Mi Ti, Mi o Se Mo — Taiwo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Odidi Odun Meta Loko Mi Fi Pa Mi Ti, Mi o Se Mo — Taiwo

Igbeyawo ogun odun kan lo ti wa ni bebe iforisanpon bayii pelu bi iyaale ile naa se n kunle, to n rababa nile-ejo koko-koko kan to wa ni Oke-Eda, niluu Akure, pe ki won ba oun fopin si ibasepo olodun gbooro to wa laarin oun atoko oun lori esun pe okunrin naa pa oun ti bii aso to ti gbo fun odidi odun meta.

Ninu oro abileko yii to poruko ara re ni Taiwo Adebayo lo ti fidi e mule pe lilu gbogbo igba ti baale ile naa fee fi gbemi oun lo je koun koko keru kuro nile re ko too di pe iya oun pa a lase lati pada sodo e leyin to waa bebe.

Taiwo juwe okunrin ohun bii alaimoore pelu bo se loo feyawo mi-in leyin gbogbo iya to ni oun ti ba a je.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Awolowo Fi Ogbon Oselu Gbe Akintola Su
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Awolowo Fi Ogbon Oselu Gbe Akintola Subu, Sugbon Akintola Fi Ete Owo e Sare Dide

Bi won ba n wa eni to mo ogbon ati ete oselu, yoo soro ki won too ri eni to ta Obafemi Awolowo yo nile wa nibi, nitori awon ti won ni ogbon oselu ki i mo ete re, awon ti won ba si ni ete ki i mo ogbon idi re daadaa. Sugbon ni ti Awolowo, oun ni ogbon, o si tun ni ete, o si mo mejeeji bii eni mo iye owo ni. Ni ti Ladoke Akintola, ete oselu lasan loun ni, oun ko ni ogbon re, bo ba si ti lo ete re lorisiirisii ona, Awolowo yoo fi ogbon tire pa a layo, korobata ni Akintola yoo si ba ara re nile, erin ni Awolowo yoo si maa fi i rin. Gbogbo ete ti Ladoke Akintola n lo ni Awolowo ri, sugbon Akintola ko ni ogbon Awolowo, ko si mo ete re, ogbon ati ete yii si ni Awolowo lo papo to fi reyin Akintola nibere ija won. Gbogbo ohun ti Awolowo se pata lori Akintola lo ba ofin mu, bi ko si je pe awon Sardauna ti won da si i, oro naa le ma di ariwo.

Ofin egbe oselu igba naa ni pe egbe ni yoo fa eni to ba fee du ipo nla kan ninu ijoba kale, bo ba si ti je oruko egbe yii lo lo to fi wole, boya o wole sipo gomina ni o, tabi o wole si ipo olori ijoba, tabi ko je asofin, oruko egbe yii ni yoo fi wa nibe, bi ko ba ti je omo egbe naa mo, tabi ti egbe naa ba le e kuro laarin won, o di dandan ko fi ipo naa sile, ki egbe si fi elomiran to ba fe si i. Sugbon isoro wa ki egbe too le eni to wa nipo kuro legbe, nitori oun naa yoo ti ni awon eeyan tire, awon yii yoo si duro ti i, awon ti won fee le e ko si ni i le se bee, nitori bi irin ba kan irin, okan ni yoo te fun okan, sonso meji nikan ni ko le fi oju rinju.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Akeem Kole Meta N'Ibadan, O Tun Loo Renti Ile Fun Iyawo e Nita
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Akeem Kole Meta N'Ibadan, O Tun Loo Renti Ile Fun Iyawo e Nita

Opo awon abiyamo to wa ni kootu lasiko igbejo toko-taya kan ti won n je Akeem Animasahun ati Khadijat Animasahun n'Ibadan ni won n sadura pe ki Olorun ma je komo awon kagbako iru oko bii oko-iyawo yii, eni to ko odidi ile meta, to si loo renti ile fun iyawo e nita, o ni obinrin naa ko le gbe inu ile oun.

Oro Akeem tubo ya awon ero iworan kootu lenu nigba tiyawo ro ile-ejo lati fopin sigbeyawo won ti ko ti i ju odun merin pere lo (pelu omo meji), ki won si pase pe toun lawon omo mejeeji naa, ti okunrin naa si so pe oun faramo on, ati pe oun yonda awon omo to bi foun naa fun un paapaa.

Nigba to n salaye bi oko e se n fiya je e to, ati idi to se fee ko o sile ni kootu Ojaba to wa laduugbo Mapo n'Ibadan, Khadijat to n gbe ni Oju Odo Olomi, laduugbo Academy, n'Ibadan, so pe yato si bi oko oun se maa n lu oun bii igba teeyan ba n lu omo alaigboran, apo kan aabo naira (N300) lo maa n fun oun atawon omo mejeeji gege bii owo ounje fodidi osu kan.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ijoba Soja... Ijoba Soja... Ijoba Soja: 'Danfo Gedegbe, Gedegbe Lomo Wa, Da
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayiwola Alaga

Ijoba Soja... Ijoba Soja... Ijoba Soja: 'Danfo Gedegbe, Gedegbe Lomo Wa, Danfo Gedegbe'

Orin ti won n ko laye ijoba Gowon ree, nigba tawon osise gbowo Adebo, ti won fi ra moto Danfo Oro ijoba, tabi oro orile-ede, bii oro eda kookan naa lo ri o, iyato die lo kan wa nibe ni.

Bi eda kan ba wa laye ti ko si owo lowo re, oto ni iwa ti yoo maa hu, o le maa se yesa yesa kiri. Ki won too pe e ni eekan, yoo ti dahun leemeji, bee ni yoo maa sare sotun-un sare sosi.

Iru won lawon omo ode-oni maa n pe ni oko-onikanopi nile ana, to se pe bi won ba ni inawo pataki lati se, ti won ba n soro owo dida nibe, ko ni i ba won da si i, sugbon ti won ba n wa awon ti won yoo gbele, awon ti won yoo wa igi ati awon ti won yoo ta kanopi nibe, yoo so pe ki won fi kinni ohun da oun ni, gbogbo re loun yoo se. Sugbon bi owo ba wa lowo re, ko ni i se bee, koda ko ma ju janjala bayii lo, agbada nla ni yoo ko si ti yoo si jokoo sori aga feregede, ti yoo maa pase bii oba. Iyen ni pe bi enikan ba wa ti ko ba lowo lowo, iwa oniwa ni yoo maa hu.

Bo se ri fun eeyan naa lo ri fun orile-ede, eyi si ni awon orile-ede to lowo lowo fi maa n gberaga si awon ti won ko ni, ti won fi maa n di alagbara laye. Nigba ti oro owo Adebo sele ni Naijiria lawon eeyan riran wo, awon ti ko mo Naijiria tele, ti won ko mo bi awon omo Naijiria ti n huwa, won waa ri i pe iyato wa nibe, eni kan ju eni kan lo. Idi ni pe awon eeyan gba owo to po daadaa, ko si bi osise kan ti kere to ti ko gba owo to to apo kan, owo nla leleyii nigba naa, nitori ogorun-un pon-un ni won n pe ni apo kan.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Akintola n So Kiri Pe Awolowo Fee Fibo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Akintola n So Kiri Pe Awolowo Fee Fibon Gbajoba Lowo Tafawa Balewa, Sugbon Awolowo Ni Akintola Kan Fee Ba Toun Je Ni

Bi eni meji ba n se ore, ti ore naa n dun daadaa, ko si ohun to ye won ju ki won sora ki araata ma ko si aarin won lo, nitori lojo ti araata kan ba ti mo aleebu tabi abuku to wa laarin won, ookan ibe ni won yoo dojuko, ibe ni won yoo si ba fi obe ge okun ore naa ja pata, ti ko fi ni i si kinni kan laarin won mo. Bi ile kan ba n toro, ti ohun gbogbo n lo deede ninu ile naa, afi ki olori ile naa sora o, nitori bi ogiri ko ba lanu, alangba ko ni i wo ibe, bi ogiri ba ti lanu die bayii, alangba kan ni yoo koko sere lo sibe, nigba to ba si ti ri ibi farapamo si nibe, awon mi-in yoo pada loo ba a, won ko si ni i gbadura ki onile naa roju raaye di ogiri naa, bee bi ogiri ba ti n lanu si i, bee ni ile n baje si i titi ti egbe kan ile naa yoo fi wo subu. A-nju-won-lo ki i see wi lejo, ija ilara ki i tan boro, bo ba ti dara feni kan, aye yoo se ilara won.

Aye n se ilara Obafemi Awolowo nitori ipo re ati ohun to gbe dani, Awolowo mo, sugbon loju tire, ko si kinni kan ti enikeni yoo se foun, won ko si le gba ipo lowo oun. Oun ko mo pe adete ko le fun wara ni, won le da wara nu, bi wara ba si ti danu, adun inu e tan, abi ta ni yoo je wara tiyeepe tiyeepe, ko mo pe bi apa awon eeyan to n binu oun yii ko ba ka oun, ti won ko si le se oun loore kan, won le ba nnkan oun je. Bee naa lawon eeyan se ilara Ladoke Akintola nitori pe oun sunmo Awolowo, ipo to wa lo wu won, bee ni won n binu re pe ki i se oun lo ye ko wa nipo naa, ki i se oun lo ye ki Awolowo gbe e fun. Awon yii kan naa ni won si sunmo on ti won bere si i so asiri ati iwa eni to yan an sipo fun un, ati idi ti ko se gbodo gba ki Awolowo te oun mo ere, ko jewo fun Awolowo pe akoni okunrin loun naa i se.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Afi Ki Buhari Gba Wa Lowo Awon Onise-ina Yii o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Afi Ki Buhari Gba Wa Lowo Awon Onise-ina Yii o

Nigba ti Buhari de, ti awon eeyan yii bere si i fun wa ni ina ijoba, ti ina n tan yaa yoo, gbogbo ilu lo n kan saara si won o, nise ni won n so pe won ti gbe eje Buhari wonu ara won, ise won ti yato, ki kaluku maa lo ina lo lo ku. N lawon eeyan ba n gbalu ti won n jo, afi bo si se di enu ojo meta yii ti nnkan yipada, to tun pada si tatijo, to si tile tun fee buru ju ti atijo lo lawon ibomi-in. 

Bi ko ba waa si ina mo, bi awon onise monamona ba tun masinni won se tabi ti won n wa ohun to ba je lati tunse, sebi gbogbo ilu naa ni yoo fi ara mo on ti a oo si maa reti igba ti ina ohun ba de. 

Ewo waa ni eyi ti awon araabi yii tun gbe de yii o, ko ma si ina, ki gbogbo ilu wa ninu ookun, ko waa je asiko naa ni awon onina yii yoo ni ki gbogbo araalu maa waa san owo ina ti won ko lo, ti won yoo si ni awon fi owo kun owo ina sisan.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ijoba Soja... Ijoba Soja... Ijoba Soja: Owo Dowo Adebo, O n Ro Woo, Woo, Woo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayiwola Alaga

Ijoba Soja... Ijoba Soja... Ijoba Soja: Owo Dowo Adebo, O n Ro Woo, Woo, Woo

Nje e ti gbo orin yii ri nna Fun awon agbaagba to ba mo idi itan, orin naa yoo ye won yekeyeke. Fun awon omode ode oni, tabi awon agbalagba paapaa ti won bi ni bii ogoji odun seyin, itumo orin naa le ma ye won. Idi ni pe laarin odun 1970 si 1971 ni won ko orin yii, nigba ti nnkan deede yipada biri fun awon osise, ti owo ti won ko lero ya wole ti won lojiji, ti won ko si ri ohun fun ayo bi ko se ope, ni won ba senu koto, n lorin awo ba bo si won lenu, orin ti won n ko lojo naa lohun-un ni, ''Owo dowo Adebo, o n ro woo woo woo!'' Bi awon osise oba ti n korin naa ni awon iyaloja gbogbo ba won gba a, se ko si bi yoo ti se kan soju ti ko ni i ja saya, afefe owo naa fe lu awon paapaa, idunnu si subu lu ayo fun won.

Nigba aye ijoba Yakubu Gowon ni o, asiko naa ni owo di owo Adebo, to n ro woo, woo, woo.

Baba kan ti wa niluu yii ri, okan ninu awon agba to gbe oruko Naijiria ga nile ati leyin-odi ni, baba naa mo nipa ise akoso pupo, bi eto ijoba kan ba si daru nibi kan, bi won ba ti ranse si i, gege se gege niyen, onigege to loo fe asopa, gege se gege niyen o jare. Omo ilu Abeokuta ni baba naa, Simon Olaosebikan, tabi S. O. Adebo ni won n pe e. Ki baba naa too ku, o joye nla laarin awon Egba, Okanlomo Egba ni. Odun 1913 ni won bi i, okan ninu awon to si koko re ilu oyinbo loo kawe nile yii loun naa, o kawe, o si di looya nla, oga awon amofin ni. Sugbon kaka ko se looya ti yoo maa yi ile-ejo po, akoso ati abojuto ileese to ba je tijoba loun gbaju mo, okan ninu awon to maa n se agbekale eto ti ijoba yoo maa gun le ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Oro Beyin Yo - Ladoke Akintola Gba Ise
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Oro Beyin Yo - Ladoke Akintola Gba Ise Kuro Lowo Ana e, Nitori Tiyen n Gbeja Awolowo Ni

Awon kinni kan wa ti won see tunse ti won ba baje, bee ni awon nnkan mi-in ki i see tun se mo. Bi eniyan ba fi apere pon omi, ti omi naa jo danu, iru omi bee ki i see ko mo, bi eniyan si mu eyin adie dani to ba jabo, to si fo, ko seni kan ti yoo ri i ko jo. Ewon, iyen seeni (chain), ki i ja ko tun pe mo, nitori ko si bi won yoo ti se so o pada ti yoo gun to bo se wa tele mo, iyen tun di laye atunwa. Ohun to sele ninu ija ti Obafemi Awolowo, olori egbe Olope ba igbakeji re, Ladoke Akintola, Peremia fun Western Region, ja niyi o. Awon agbaagba Yoruba ti jade won pe ipade nla, won soro naa sotun-un, won so o sosi, won si ni ki Awolowo pelu Akintola jo wo moto kan naa, ki won yipo Ibadan, ki won si lo sile ara won ki won jeun, ki gbogbo aye le mo pe ija naa ti pari pata. Bee naa ni won kuku se o, sugbon ija naa ko pari pee.

Ija ko le pari bee, nitori ohun ti ko sele ri ti sele. Akintola ti gbe ina woju Awolowo, o si ti ri i pe ki i kuku se pe Awolowo lagbara to bee bi awon ti n wo o, gbogbo agbara to n lo tele, igba to wa nijoba ni, nigba ti ko si si nijoba yii, agbara owo re ko to nnkan. Ati pe Akintola woye pe agbara ti oun ni tile ju ti Awolowo lo, nitori lati igba ti Awolowo ti n sejoba re, to si n se oselu re, gbogbo agbara to n gbe kiri, agbara ile Yoruba nikan ni, ko lagbara lodo ijoba apapo, nitori ota ni oun atawon ti won jo wa nibe, won ko si feran re rara. Ni ti oun Akintola, oun mo awon eeyan ti won jo wa ninu ijoba yii, oun mo awon ti won n sejoba apapo, ore oun ni won, won si ti mura lati wa leyin oun bi wahala kan ba sele, Awolowo funra re ni yoo farapa. Ohun ti eleyii tumo si ni pe Akintola ti ri asiri Awolowo, o mo ibi ti agbara re pin si, o si ti gbominira.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ijoba Soja... Ijoba Soja... Ijoba Soja: Awon Osise Gbogun Tijoba Yakubu Gowon, W
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayiwola Alaga

Ijoba Soja... Ijoba Soja... Ijoba Soja: Awon Osise Gbogun Tijoba Yakubu Gowon, Won Ni Dandan Ni Ko Sanwo Osu Tuntun Fawon, Bi Bee Ko, Oro Naa Yoo Dariwo

Wahala omo Yunifasiti Ibadan tawon olopaa yinbon pa, Kunle Adepeju, ati bi oro naa se le awon Adeoye Lambo kuro nise yunifasiti ni ijoba Gowon fi bere odun 1971. Nigba toro naa role pata, Gowon paapaa ri aya bale, o mu omi, o si so ikeemu sile. Lesekese lohun gbogbo tun n lo deede, o kan se pe wahala mi-in ti wa nile ti ko ti i feju ni. Se ohun ti won n pe ni ijoba naa niyi, bi won ba ti n yanju wahala kan ni omiiran yoo maa yoju, bi isoro kan ba ti n lo ni omiiran yoo maa tele e. Bi eeyan ba ri ariwo ati rogbodiyan toro awon omoleewe yii mu dani, yoo ti ro pe ko tun ni i si awuyewuye mi-in ni Naijiria laarin odun kan si meji ni. Sugbon oro ilu ko ri bee, ojumo kan isoro kan ni. Bi ijoba kan ba se le sare yanju isoro to ba koju ilu si ni won se n so pe ijoba naa dara tabi ko dara, eyi ni won si fi n kan saara sawon to ba n sejoba.

Lati odun 1970, ni gere ti ogun pari ni kinni kan ti wa nile, iyen naa ni oro owo-osu awon osise ijoba gbogbo. Se teletele, ohun ti i maa a wu gbogbo awon ti won ba kawe jade ni lati ri ibi ileese ijoba kan wo, nitori owo osise ijoba ko kere nibere. Yato si ti owo ti won n gba nigba naa, awon anfaani orisiirisii lo po fun won, to fi se pe o soro ki won too ri iru awon anfaani yii ni awon ileese aladaani, afi awon ti won ba je ileese oyinbo nikan. Nigba ti odun 1970 waa de saa, nnkan ti yipada biri nitori pe bentiroolu ti mu owo repete wole fun ijoba, owo to si n wole fun ijoba Gowon, won ko ro pe awon le ri iru owo bee laye, owo naa po yanturu ni. Ase kekere lowo ti won ri ni 1970 ti won n tori e lanu, nigba ti yoo fi di odun 1971, obitibiti owo ti de, iseju iseju lowo epo naa si n ya wole bii omi.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Ija Di Tawon Obinrin - Iyawo Akintola
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ile N Jeeyan, Awon Eni Nla Ti Re Koja Lo: Ija Di Tawon Obinrin - Iyawo Akintola Pade Awolowo Lona, Imu Lo Fi Ki i

Titi di oni ti a n ko itan yii, oro kekere ti Obafemi Awolowo so lojo Eti, Fraide, ojo kesanan, osu keji, odun 1962, niwaju awon oba nla nla atawon eeyan pataki nile Yoruba ko ti i yee da ariyanjiyan sile laarin awon oloselu ati omowe pelu awon oniwadii gbogbo. Ooni Adesoji Aderemi ti i se Gomina-agba fun Western Region igba naa lo se alaga ipade naa, awon olori egbe Omo Oduduwa ti Akinola Maja si se olori won lo seto ipade-ipari-ija naa, ti won n fe ki ohun gbogbo to sele ni Jos, nibi ti Ladoke Akintola ati Ayo Rosiji ti kuro nipade, ati eyi to sele n'Ibadan, ti won ho le Awolowo funra e di ohun igbagbe, ti oro naa yoo si pari sibe nile awo. Loju gbogbo won nibe ni Awolowo ti so pe Akintola n gbe oro kan kaakiri o, oro naa si ni pe oun n mura lati fi tipa gbajoba, oun fee dite mo ijoba Tafawa Balewa, oun si ti n ko awon eeyan jo.

Olori egbe Olope naa salaye loju awon ti won duro pe ki i se pe oun n mu ase, ki i se pe oun ko si gbo oro naa daadaa nitori lenu awon toun ti gbo bee, awon ti won sunmo Akintola funra re ni, awon ni won waa gbe oro naa so foun pe ohun ti Akintola n so fawon ree o, o n so pe oun Awolowo fee fipa gbajoba, ati pe boya ni oro naa ko ti ta si eti Sardauna ni Sokoto, iyen Ahmadu Bello. Opolopo awon ti won so oro naa foun ko le ri i ti, nitori Duro Ogundiran ati Osuntokun lo soro naa, lara awon mejeeji ti won si sunmo Akintola ju naa niyen. O ni lati igba to ti soro naa loju awon meji yii ni won ti n gbe e kiri, oro naa si ti ran kale, o si da oun loju pe ijoba apapo naa yoo ti gbo, ko si sohun meji ti Akintola fee fi kinni naa se ju ko fi ko wahala boun lo, o fee ki okun soun lorun, ki ijoba le mu oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Lori Rogbodiyan Yunifasiti Ibadan Ni 1971, Gani Fawehinmi Ba Arabinrin Apampa Fa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Lori Rogbodiyan Yunifasiti Ibadan Ni 1971, Gani Fawehinmi Ba Arabinrin Apampa Fa Wahala Gidigidi

Ojo nla kan lojo naa, lojo ti obinrin ti won n pe ni Grace Apampa, alabojuto agba fun ileigbe Azikwe Hall', ninu Yunifasiti Ibadan, duro niwaju igbimo to n gbo ejo awon olopaa ti won yinbon pa Kunle Adepeju, ati ohun to fa sababi isele naa ninu yunifasiti ohun. O duro niwaju won, o si rojo, o salaye titi enu oun paapaa fere bo, bee ni awon looya ko si fi i lorun sile, paapaa Gani Fawehinmi, eni to tako obinrin ohun pe gbogbo ohun to sele nibe, owo e lo ti wa, ati bi ko ba si tire ni, ko le si ija ninu ogba yunifasiti yii debii pe awon olopaa yoo fi wa sibe, tabi ti won yoo waa maa yinbon. Se gbogbo ejo ti awon omo yunifasiti ti ro kale, ori obinrin yii ni won ro ejo naa mo, won ni oun ni ko fun won lounje, oun lo n ta ounje ati oti won fawon araata, bo si se n ta awon ohun to to sawon yii lo n febi pa awon, ohun to faja gan-an niyen.

Awon eeyan ti ro pe obinrin naa ko ni i wa ni, iyen awon looya atawon omoleewe, nitori ohun ti won gbo tele ni pe Apampa ti sa lo. Koda, awon omoleewe kan so kinni ohun di orin, ti won n korin kiri ogba pe, "Ko lee boode, ko lee boode, Apampa tilekun mori, ko le boode!(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

O Tan! Won Gbe Oku Tajudeen Raji, Oga Awon Omo Egbe Okunkun Wa S'Ogijo Waa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olowale Adejare

O Tan! Won Gbe Oku Tajudeen Raji, Oga Awon Omo Egbe Okunkun Wa S'Ogijo Waa Sin

Afi bii igba tawon eeyan ilu Ogijo, nijoba ibile Sagamu, nipinle Ogun, ti n reti iru nnkan to sele lose to koja yii, loro naa ri nigba ti won yari pe awon ko ni i je ki won sin oku okan lara oga awon omo egbe okunkun ti won pa to je omo ilu naa sinu ilu yii.

Tajudeen naa ti won lo lenu daadaa ninu awon egbe okunkun to wa nile Yoruba la gbo pe awon eeyan e pa danu lojo Eti, Fraide, ose to koja lohun-un, sugbon iyalenu lo je fawon molebi oloogbe yii nigba ti won gbe oku e wale waa sin, ti awon ara agbegbe ohun si so kinni ohun dorin mo won lowo pe ki won da oku naa pada, won ko si gbodo gbiyanju e wo lati sin in sibe, nitori tawon ti ko o gege bii omo ilu naa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Okunrin Kan Ti Bere Si i San Egberun Lona Aadota Naira Fun Agbale To Da Milionu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayinka Adedayo

Okunrin Kan Ti Bere Si i San Egberun Lona Aadota Naira Fun Agbale To Da Milionu Mejila Naira Pada Ni Papako-ofurufu Eko

Nje e ranti obinrin agbale papako-ofurufu Murtala Mohammed l'Ekoo, Arabinrin
Josephine Ugwu, to da milionu mejila naira to je owo ile okere pada feni to ni in leyin to ri
owo naa nile igbonse losu kin-in-ni, odun yii, to je pe o seun lasan lo ri gba lowo eni tolowo
ohun. Ni bayii, Olorun Oba elesan ti n san esan oore ojosi fobinrin naa.

Lojo Aje, Monde, ose to koja yii, ni okunrin kan ti ko fe ki enikeni mo oruko oun, sugbon to
pinnu lati maa san egberun lona aadota naira losoosu fodidi odun kan gbako fobinrin naa ti
bere si i san owo naa bayii.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Leyin ti won ti pa Ironsi losu keje, odun 1966, ibeere ti gbogbo ilu n beere ni
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Leyin ti won ti pa Ironsi losu keje, odun 1966, ibeere ti gbogbo ilu n beere ni pe ta ni olori ijoba Naijiria tuntun

Bi won ti ji Ironsi gbe ti won si pa a si ona inu igbo n'Ibadan, bee ni ijoba soja akoko ni Naijiria forisanpon, ijoba naa daru lojiji, o fo mole yangayanga. Sugbon kinni kan si wa nibe to le, iyen naa ni pe ta lo ku ti yoo se olori ijoba Naijiria tuntun. Ogagun Agba Aguiyi Ironsi ti so nigba ti iya dun un lara, nigba tawon ti won n mu un loo pa n lu u, ti awon soja keekeeke n fa aso re ya, ti won si n ko o ni bilala, o so fun won pe opin ti de si Naijiria, opin Naijiria ree, ko tun ni i si igbadun tabi ifokanbale kan nile yii mo. Boya epe ni boya ire ni, awon ti won kuku n mu un lo ti mu oti yo, awon ti ko si mu oti ti mu igbo koja gejia, awon ko mo kinni kan ninu gbogbo ohun to n so, won ko si setan lati mo on rara. Ise ti won ran awon lawon n je, loju tiwon, awon n gbesan lara awon ti won pa awon asaaju awon nile Hausa nijosi ni.

Oro naa daru mo awon oba alaye ti won waa se ipade n'Ibadan paapaa loju. Ati oba Ibo ati oba Yoruba, gbogbo won ni won wa ninu ookun oro, se won ko kuku ri iru e ri ni tiwon, bee lo si loju awon oba Hausa to mo ohun to n lo. Gbogbo won ni won ri Ironsi lanaa, ti won bo o lowo, ti won ba a sere, ti won ri i teruteru, ti won mo pe ko si eni to le sunmo on pelu ogunlogo soja ti won yi i ka, eni to ba dan iru re wo, lesekese naa ni ebora yoo bo o laso.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ijoba soja... Ijoba soja... Ijoba soja...
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ijoba soja... Ijoba soja... Ijoba soja...

Eyi ni bi won se fi Yakubu Gowon se olori ijoba soja keji ni Naijiria Awon araalu n beere pe ta ni olori ijoba Naijiria tuntun lojo kokandinlogbon, osu keje, odun 1966, ati titi di ogbonjo, osu naa, nitori iroyin ti won gbo ni pe won ti ji olori ijoba Naijiria gbe lo, enikan ko si mo ibi to wa, won ko si mo awon ti won ji i gbe. Se bi oro ba sele bayii, igbakeji eni to ba je olori naa ni yoo tete bo sibe ti won yoo si sebura fun un ti yoo si maa sejoba lo, nitori ofin ko faaye gba ki orile-ede kan ma ni olori laarin iseju kan, ka ma ti i so wakati kan, ka ma ti i waa so ojo kan si ojo meji. Sugbon ko seni kan ti won yoo fi se olori Naijiria lojiji bee, nitori eni to ye ki won mu lo ti na papa bora nigba to gboro iku ojiji yii, Baba Ogundipe lo ye ko gba ipo naa, oun naa si fee gba a o, sugbon nigba to ti gbo pe oro naa le ja si iku ojiji nitori awon soja Hausa to n bo waa mu un lo se yaa fipo naa sile to lo.

Ohun ti eyi tumo si ni pe Naijiria ko ni olori kan bayii, ko si olori ijoba, awon ti won si je osise ijoba paapaa ko de ibiise won, Naijiria kan wa gbuduku ni. Idi ti eleyii fi sele ni pe awon soja Hausa ti won n pa awon elegbe won lati ile Ibo yii ko mura lati gbajoba, won ko fee se olori Naijiria, won ko si fe ki enikeni ninu awon je olori ijoba won. Akoko ohun ti won fe se ni lati gbesan iku to pa Sardauna Sokoto ati awon asaaju won ninu ise ologun tawon Kaduna Nzeogwu yinbon pa. Ekeji ni pe awon asaaju won ti won je osise ijoba ti so fun won pe bi won ba ti se bee ti won si ri awon Ibo yii pa, ki won maa pada bo nile, ki won kuro ni Naijiria, ki won si so fun gbogbo eeyan pe awon ko se Naijiria mo o, awon ko si ninu ijoba Naijiria mo o, ijoba ara awon lawon fe maa se, iyen ijoba Arewa, ijoba Hausa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Awon adigunjale ma tun sose l'Owo, won gbemi olopaa mefa, bee ni won paayan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluseye Iyiade, Akure

Awon adigunjale ma tun sose l'Owo, won gbemi olopaa mefa, bee ni won paayan repete laarin ilu

Eni ori yo o dile loro ohun je niluu Owo, nijoba ibile Owo, nipinle Ondo, lasiko tawon adigunjale kan kolu awon banki bii marun-un to wa niluu naa nirole Ojobo, Tosde, ose to koja yii, ti won si se bee ran olopaa mefa sorun apapandodo leyin ti won sakolu solu ileese ajo olopaa to wa niluu yii. Eyin eyi ni won jade sigboro, nibi ti won ti tun paayan repete kawon soja to waa koju won, ti won si mu mefa bale lara awon ole ohun.

Gege bawon eeyan kan tisele yii soju won se fi to Iwe Iroyin Yoruba leti, nnkan bii aago marunun koja die nirole patapata ni won lawon a-pomo-lekun-jaye naa ya wolu, bee ni won ko besu begba ti won fi bere si i yinbon, koda won o ti i sokale ninu oko ti won gbe wa tawon eruuku ohun ti dabon bole.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: