Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:

Irohin Nitele-N-Tele

Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara
[ Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara ]

·Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
·Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo — Abigail
·Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina
·Emi Atoko Mi Ko Ja, Nitori Omo Lawon Ebi Re Se Fee Le Mi Jade - Rafia
·Latodun Merin Seyin Loko Mi Ko Ti Ba Mi Lasepo, Mi o Se Mo - Folasade
·Odo Ni Wolii Moses Ti Ni Ki David Loo We Iwe Isegun, Lo Ba Fogbon Ji Moto Re Gbe
·Oro Buruku Toun Terin: Awon Omo Poli Ojere Mefa Daku Lakooko Ti Won Fee Sedanwo
·O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta
·Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Wednesday, January 23
· Oro Buruku Tohun-terin Sola Atawon Emewa A Foju Bale-ejo
Monday, January 21
· Oro Buruku Tohun Terin! Igbeyawo Ojo Kan Daru l’Otun Ekiti
· Oladejo Fesun Agbere Kan Iyawo E, Niyen Ba Ge Nnkan Omokunrin E Je Nibi Ti Won T
· Kayeefi Kan Ree O! Dokita Pa Omo Iyawo E, Inu Omi Lo Binu So O Si
Thursday, October 11
· Omuti Loko Mi, Mi O Fe E Mo, E Tu Wa Ka—Rasheedat: Oko Mi N Ta Tete, Bee Lo Tun
· Loooto N Mo N Gbadun Kinni Oko Mi Daadaa, Sugbon Ko Doyun, N Ko Fe E Mo —Musili
· Nitori O Paro Fun Adajo, Won Ni Ki Aminatu Maa Gba Ile-ejo Fosu Kan Gbako
Wednesday, October 10
· Aramanda Kan Ma Niyi n’Ilorin: Iyaale Ile Gbe Ale Wa Sile Oko E, Se Lo Mura Bii
Tuesday, October 09
· Bunmi Yii Ma Kuku Laya O, Gbese To Je Lawon Olopaa Tori E Mu un Lo Ba Tun Ja Awo
Wednesday, August 22
· Kayeefi Kan Ree! L’Ondo, Oko Sa Lo Lojo Igbeyawo: Lasiko Ti Eto Igbeyawo N Lo Lo
Saturday, August 18
· Ara Kan Ma Tun Ree! Lasiko Ti Eto Igbeyawo N Lo Lowo Ni Silifatu Taku, O Loun Ko
· Oko Mi Ti Pa Mi Ti, Ki I Ba Mi Sun Daadaa, N Ko Fe E Mo — Amudalat: Ale Ni Oko M
Friday, August 17
· Olopaa Gbagbe Sun Lo Sile Oniparaga, Ni Won Gbebon E Lo: N’Ibadan, Samuel Ja Olo
Wednesday, July 04
· Iya Alaso Da Omiigbona Lu Nnkan Omokunrin Oko E: Nibo La O Gbeyii Gba, Loooto Ma
· Tenanti N Gbo Iyawo Mi Nigbokugbo Ni Mo Se Le E Jade — Ogbeni Mathew: Abiru Alag
· Iyawo Kabiyesi Ja Nita Gbangba, Lo Ba Dero Kootu, Ni Won Ba Tun Fi Esun Ifipa-ba
· Nnkan N Be O, Niluu Aawe: Dayo Koju Ija Si Ale Oko E, N Lobinrin Naa Ba Lu U Loo
· Kayeefi Kan Ma Tun Ree Ni Badagry Rahimant Bi Omokunrin Leyin Odun Meeedogun To
Monday, June 18
· Wahala De! Sunday Ba Ore E Micheal Ninu Yara Pelu Iyawo E, Lo Ba Sa A Ladaa Yann
· Abeeri Tope Bo Se Koba Ra E Iso Oru Lo Dagbere Fawon Obi E, Odo Okunrin Lo Gba L
· O Doju E! Baba Agbalagba Eni Ogota Odun Mayowa Temilade t’Ondo Waa Lu Magun Lara
· Ofo Emi Ree! Baba Favour Lo Sibi Ise, Iyawo Atomo Meji Si Jona Mole Ko Too De
Sunday, May 13
· Alagba Soosi Lo N Bayawo Mi Sun— Ogbeni Michael Adebayo: Wahala Boko Haraamu Oro
· O Sele! Kunle Lu Magun Lara Iyawo Babalawo: Iya Laide Da Omi Efo Gbigbona Le Ale
· Abi Ki Lo N s’Oba Alowa Yii, O Si Tun n Daran Moran: Kayode Wo Aso Soja Daran n’
Tuesday, May 01
· Olopaa Fipa Bayawo E Lo Po Tan, Lo Ba Tun Gun un Pa: Nitori Eedegbeta Naira, Bab
· Iya Laide Da Omi Efo Gbigbona Le Ale Oko E Lori: Tobi Fee Fore E Timotimo Soogun
Monday, March 26
· O Ga O, Nijoba Ibile Ifo, Awon Toogi Le Baale Atawon Eeyan E Niluu, Won Lenikan
· Kayode Ki Iya Arugbo Mole, O Gbo O Nigbokugbo
Thursday, November 18
· Eemo Ni Ketu! Okunrin Bokunrin Egbe Re Lasepo Laarin Oja: Lawon Alase Oja Ba Bo

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Terin N'isoosi

Oro buruku toun terin, nigba ti won ka Ajihinrere kan ti won pe oruko re ni Akinjide Durojaiye mo ibi to ti n ji foonu lasiko to n waasu ihinrere Jesu pe kawon eeyan yi pada kuro ninu eshe won.

"E she mi jeje, ishe eshu ni, Emi mimo lo ran mi nishe" loro ebe to n tenu Durojaiye jade lasiko towo palaba e segi naa, pelu foonu olowo nla meji otooto to ji gbe lagbegbe Dugbe niluu Ibadan, ipinle Oyo.

Gege bi a she gbo, opin ose to koja yi la gbo pe Durojaiye ti won ni ilu Ilare-Ijesha to wa nipinle Oshun lo ti n shishe ni shooshi kan ti won pe ni Dominion Assembly gba ilu Ibadan lo, to si lo n waasu ihinrere Jesu.

Won ni bi Durojaie, omodun mokandinlaadota naa she de agbegbe Dugbe lojo naa, ni won loo bere sii waasu loirshirishi, tawon eeyan si n wo o bo she n she. Shadede ni won loo wo shoobu kan ti won pe ni Femi Johnson.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo — Abigail
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo — Abigail

"Loooto ni mo maa n mu oti, sugbon igo kan pere ni mo maa n mu loojo, ekookan ni mo maa n mugbo, sugbon oro enu iyawo mi yii ko dara rara, nitori naa ni mo se maa n lu u." Baale ile eni odun merinlelogbon kan, Ayodele lo so bee niwaju ile-ejo lasiko ti iyawo re, Abigail Ojo, wo o lo sile-ejo, to si ro adajo lati tu igbeyawo odun mejo to wa laarin won ka.

Iyaale ile eni odun metadinlogbon ohun so pe gbogbo igba loun pelu oko oun maa n ja, bee lokunrin naa maa n lu oun nilu baara, ati pe omuti paraku ni, ti ija ba si ti sele, gbogbo eru inu ile lokunrin naa maa n baje.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina

''Oko mi n soogun, o si daju pe o ti fi pata mi soogun owo nitori pe latigba ti pata mi ti di awati ni mi o ti ni ifokanbale ati alaafia mo, se ni mo maa n gbo tenikan maa n pe oruko mi ti mi o si ri onitohun, mo kan maa n gbo oruko mi saa ni.'' Iyaale ile kan, Abileko Igbolanu Philomina, lo so bee lasiko to to ile-ejo ibile kan lo, to si ro aare ile-ejo ohun lati tu igbeyawo olodun merindinlogun to wa laarin oun pelu oko re, Bonaventure, ka.

Obinrin ohun so pe gbogbo igba nija maa n waye laarin awon, bee lokunrin naa maa n se agbere kiri, omuti paraku ni, ko toju oun pelu awon omo, o si maa n se oogun pupo.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Emi Atoko Mi Ko Ja, Nitori Omo Lawon Ebi Re Se Fee Le Mi Jade - Rafia
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Emi Atoko Mi Ko Ja, Nitori Omo Lawon Ebi Re Se Fee Le Mi Jade - Rafia

 Agbalagba ni Ogbeni Musediku Salami, die ni yoo fi din ni aadorin odun, bee naa si ni iyawo re, Abileko Rafia Salami, oun naa kuro lomode agbekorun roko. Sugbon awon mejeeji ni won wa sile-ejo koko-koko to n jokoo l'Agege, nipinle Eko, laipe yii, nibi ti baba naa ti so pe oun fee ko iyawo oun nitori o maa n ba oun ja ni gbogbo igba ni.

 Baba ko rojo kan lo titi, o sa ni Rafia ko bimo foun latodun kokanla to ti wa nile oun, oun ko si bimo ri laye yii, bo tile je pe Rafia ti bi meji sile oko aaro e ko too fe oun. O wu oun naa lati lomo laye loun tun se fe iya yii, sugbon oun toun fe latodo e ko wa si imuse rara, ko somo laarin awon. Iyen lawon eeyan oun ro papo ti won ni ko maa lo lo daa toun naa si tori e wa si kootu.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Latodun Merin Seyin Loko Mi Ko Ti Ba Mi Lasepo, Mi o Se Mo - Folasade
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Latodun Merin Seyin Loko Mi Ko Ti Ba Mi Lasepo, Mi o Se Mo - Folasade

Iyaale ile eni odun mokandinlogoji kan, Folasade Adelabu lo gbejo lo si kootu ibile kan niluu Ado-Ekiti, to si ni oko oun maa n fi oorun dun oun, nitori idi eyi, oun ko le mu un mora mo, kile-ejo tu igbeyawo olodun meje to wa laarin oun pelu David Adelabu ka.

Folasade to so pe o ti to odun merin tokunrin naa ti pa oun ti ti ko si sunmo oun gege bii ise oko ati aya, bee lo ni David tun maa n mu imukumu bii siga ati igbo, o si tun je omuti paraku. O ni igbeyawo ohun ti so eso omo odun mefa kan toruko re n je Matthew Adelabu.

Obinrin ohun so pe David ki i bikita rara fun itoju oun ati omo naa, bee lo tun maa n lu oun bii bara, ti yoo si maa dunkooko lati pa oun. Bakan naa lo ni gbogbo eru oun lokunrin naa maa n baje.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Odo Ni Wolii Moses Ti Ni Ki David Loo We Iwe Isegun, Lo Ba Fogbon Ji Moto Re Gbe
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Kayode Omotosho, Ilorin

Odo Ni Wolii Moses Ti Ni Ki David Loo We Iwe Isegun, Lo Ba Fogbon Ji Moto Re Gbe N'Ilorin

Afi ki awon eeyan maa sora ni awujo wa bayii pelu bo se je pe orisiirisii awon wolii lo ti wa nita, to si je pe opo ninu won kan n je ipe ara won ni, ki i se ipe Olorun ni won n je. Abi kin ni ka ti pe ti Wolii Moses Adegbite ti owo ileese olopaa ipinle Kwara te pe o ji oko gbe sa lo nibi to ti n jise to ni Olorun ran oun.

Ojo Isegun, Tusde, ose to koja ni ileese olopaa ipinle Kwara taari alagba Moses, eni odun mejidinlogoji si kootu majisreeti to wa niluu Ilorin, niwaju Adajo F.O Olokoyo.

Nigba to n safihan afurasi odaran naa fun ile-ejo, olopaa to n soju ijoba, Inspekito Mojisola Olamokun, fesun kan Moses pe se lo lu jibiti oko, eyi to tako abala kan iwe ofin to de iwa odaran tipinle Kwara. O salaye pe ni nnkan bii aago marun-un aabo irole, ojo kejo, osu kokanla, odun yii, ni ogbeni kan toruko re n je David Awopetu mu esun wa si tesan olopaa pe Ogbeni Moses Adegbite to n kawo ponyin rojo yii waa ba oun pe wolii ijo Kerubu ati Serafu to wa ni adugbo Shao loun, ati pe lasiko tawon n se isin pataki kan ni soosi awon, Olorun fi iran han oun pe David nilo lati loo we iwe isegun kan lodo.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Oro Buruku Toun Terin: Awon Omo Poli Ojere Mefa Daku Lakooko Ti Won Fee Sedanwo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Oro Buruku Toun Terin: Awon Omo Poli Ojere Mefa Daku Lakooko Ti Won Fee Sedanwo

Beeyan ba ri i bawon omo ile-eko giga Poli ti Moshood Abiola to wa ni Ojere, niluu Abeokuta, se bere si i subu lule, ti won si n daku lojo Eti, Fraide, ose to koja lakooko ti won n sedanwo ise kan ti won pe ni EED 126, ni gbongan '800 seaters', aanu abiyamo yoo seeyan.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe awon akekoo mefa otooto lo daku lojo naa, tawon kan si subu lule, ti won bere si i bi bii oloyun. Ibi ti won duro si lati wonu gbongan ti won ti fee sedanwo ni won ti n subu lule lairotele.

Iyalenu lo je pe obinrin nikan lawon ti won n daku naa. Ohun ti a gbo ni pe wahala ti won n se lati tete wonu gbongan idanwo naa lo fa a nitori pupo ninu won ni ko jeun kuro nile nitori idanwo naa.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta

Opo awon to fee lo sibi isomoloruko kan to waye lojo Aje, Monde, ose to koja, laduugbo kan ti won n pe ni Ita-Balogun, Ago-Oko, niluu Abeokuta, ni won dogbon feyin rin pada nigba ti wahala deede bere lori omo tuntun ti won fee fun loruko lojo naa.

Ohun to fa wahala to mu ki gbogbo aga ati atibababa ti won gba lojo naa bere si i di nnkan tawon kan baje ko seyin bi won se ni okunrin meji ni iya omo naa bimo fun, tawon oko iyawo naa si n ja pe awon lawon lomo.

Seun Ojo ni won pe oruko obinrin ti won ni ko mo eni to le gbomo fun ninu awon mejeeji to n ja ohun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Oluseye Iyiade, Ondo

Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo

Boroboro bii igba ti aje iba maa ka ni onisegun ibile kan, Ogbeni Sowosoye Rufai n ka nigba tawon wolewole ijoba ibile Iwo-Oorun Ondo wo o wa sile-ejo alagbeeka kan to wa ni sekiteriati ijoba ibile naa pelu esun merin otooto ti won fi kan an.

Nigba to n ka awon esun naa si olujejo yii leti, oga awon wolewole ohun, Arabinrin Elizabeth Akinfemisoye so pe Rufai ko lati pese salanga miiran sile re nigba to han si i pe eyi ti won n lo tele ti kun, eyi to lo see se ko fa ajakale arun fawon to n gbe nile yii ati agbegbe re.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Iya Jibola fi tie koba awon ti won jo n gbe n'Ibafo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Iya Jibola fi tie koba awon ti won jo n gbe n'Ibafo

Epe lawon to n gbe niluu Ibafo n gbe obinrin kan ti won n pe ni Iya Jibola se laaaro ojo Aje, Monde, ose to koja pelu bo se fi tie koba awon ti won jo n gbele to si so won si kolobo.

Iyen nikan ko, o tun mu emi awon eeyan meji lo.

Laduugbo kan ti won n pe ni Ore merin, legbee ile Baba Dayo Ebute, nidojuko tiransifoma ilu Ibafo ni isele naa ti waye. Ohun ta a gbo ni pe laaaro kutu ojo naa ni ina deede seyo, tawon araadugbo si n wa ona lati pa a, sugbon epa ko boro mo, ina ti ba opo nnkan je jinna.

Eyi to ba ni ninu je nipa isele naa ni tomo odun kan aabo to jona mo ile naa, ti won ko si le da a mo nigba ti won gbe e jade. Iwadii fi ye wa pe o ti pe ti obinrin ti won n pe ni Iya Jibola yii ti n ta epo bentiroolu ninu ile naa, koda won lo ni yara kan leyinkule to maa n gbe epo ohun si, alagbata lo si tun je fawon to n ta oja okunkun ti won n pe ni ‘Black Market'.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Omuti paraku loko mi, ada lo fi n le mi kiri to ba ti yo—Funke
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Akoroyin Olootu

Omuti paraku loko mi, ada lo fi n le mi kiri to ba ti yo—Funke

Iyaale ile kan, Funke Ogunbayo lo kegbajare si adajo ile-ejo ibile lati tu oun pelu oko re, Olusola Folorunso, ka nitori okunrin naa fee gbemi e. O ni oko oun ko mo ju oti mimu lo, gbogbo igba lo maa n yo keri wole, to ba si ti yo bee, ada lo maa n fi le oun kiri.

Funke salaye pe gbogbo igba toko oun ba ti muti yo lo maa n siwa hu, bee ni yoo maa lu oun. O loun ti n foriti i tipe, toun si n gbadura ki Olorun ba oun yi okunrin naa pada, sugbon o tubo n buru si i ni.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

E Gbo, Amuni-kolu-ni Ni Yinka? O Ji Oko Gbe N'Ibadan, O Ba Loo Gbe E Pamo S
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

E Gbo, Amuni-kolu-ni Ni Yinka? O Ji Oko Gbe N'Ibadan, O Ba Loo Gbe E Pamo Si Soosi Ni Gbongan

Bo ba se pe loju-ese ni Olorun n dajo ni, Oloun funra e nikan lo mo iru itu ti i ba ti fi okunrin afurasi adigunjale kan, Yinka Oyeniran, pa bayii, abi nigba ti eeyan waa fibon gba oko lowo eni eleni to n ti soosi bo jeje, to si wa loo gbe e pamo sinu soosi won.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe ni nnkan bii aago mesan-an aaro ojo Isegun, Tusde, ojo kewaa, osu kesanan, odun yii, nigba tobinrin naa n dari lo sile lati ibi isin kan to waye ni soosi won bo n'Ibadan lawon adigunjale merin kan ti won dihamora pelu ibon ti n tele e leyin pelu oko Honda pupa kan ti ko ni nomba lara. Bi obinrin onigbagbo naa se dele e to wa ni Kute, laduugbo Wofun, n'Ibadan, ni won sare si i pelu ibon lowo, ti won si wo o ju sile kuro ninu oko re.Yato si ti oko Toyota Camry ohun ti nomba e je LSR 292 AT (LAGOS), owo to to egberun lona ogofa naira pelu awon ero ibanisoro atawon ohun eso ara lawon adigunjale yii gbe lo mo obinrin naa lowo patapata.Pelu ibanuje ni iya oniyaa fi loo royin ohun to kolu u fawon olopaa ni tesan won to wa ni Akobo, n'Ibadan, ti awon agbofinro si bere iwadii lori e ni warasesa ko too di pe won pada ri oko ohun gba pada.Ilu Gbongan, nipinle Osun, ni won ti ri moto yii. Bakan naa lawon olopaa ri okan ninu awon afurasi adigunjale ohun mu pelu ibon ilewo kan ti won fi n soro fawon araalu.Nigba to n fidi isele naa mule fawon oniroyin lolu ileese olopaa ipinle Oyo, l'Eleyele, n’Ibadan, alukoro fun ileese agbofinro ipinle ohun, DSP Olabisi Okuwobi-Ilobanafor so pe, “Bi won se fi isele yen to won leti lagoo olopaa to wa ni Akobo, n’Ibadan lawon olopaa ti bere ise lati ri oko naa gba pada.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Nitori Ale E To Fee Fun Lowo Inawo, Ramoni Ji Ewure Gbe N'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Seyi Adeshina, Ilorin

Nitori Ale E To Fee Fun Lowo Inawo, Ramoni Ji Ewure Gbe N'Ilorin

Afi bii igba teeyan n wo fiimu agbelewo loro ohun ri n'Ilorin laipe yii, nigba ti Ogbeni Ramoni, eni ogota odun ji ewure gbe lagbegbe Taiwo, n'Ilorin, nigba towo te e lawon eeyan ba so pe nitori owo to fee fun ale e lo se huwa ohun.Gege bi iwadii wa, a gbo pe okunrin to niyawo meji atomo mejo ohun lo sadeede loo ji ewure elewure gbe lagbegbe Taiwo, n'Ilorin.

Won ni nise lo bu iyo si eran to loyun sinu ohun lenu to si gbe e. Iyo yii ni won ni ko je ki ewure naa ke rara.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Agbaaya Ma Leleyii O: Bakare N Bomo Lanloodu E Lo Po N’Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Seyi Adeshina, Ilorin

Agbaaya Ma Leleyii O: Bakare N Bomo Lanloodu E Lo Po N’Ilorin

Asiri okunrin kan, Ogbeni Bakare, to n ba omo lanloodu e, Tosin sun ti tu bayii nitori bi won se ri i nigba to n huwa ibi naa, ti won si fi olopaa mu un.

Gege bi a se gbo, o pe ti Bakare ti n ba omobinrin ohun sun. Nibi to ko somo naa lori de, bo ba ti lo sileewe laaaro, ki i pee pada wale nigba tawon obi e ba ti lo sibi ise, odo tenanti yii ni yoo wa ti iyen yoo si maa ko ibasun fun un karakara.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Sekinat Ge Oko E Ni Kinni Je N'Ilorin, O Lo Fee Maa Ba Oun Sun Pelu Omo Osu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Sekinat Ge Oko E Ni Kinni Je N'Ilorin, O Lo Fee Maa Ba Oun Sun Pelu Omo Osu Marun-un Lowo

Gbogbo ero iworan to wa lagbegbe Gaa Akanbi, n'Ilorin, lo rerin-in arin-lami-loju nigba ti iyawo ile kan, Arabinrin Sekinat ge oko e ni kinni je nitori esun pe o n lu oun nilukulu, bee lo tun fee maa ba oun sun pelu omo osu marun-un pere toun n toju lowo.Sugbon nise loko obinrin naa, Ogbeni Ibrahim, so pe iro niyawo oun n pa.

O lomo osu mejo niyawo oun gbe lowo, ati pe alagbere paraku ni.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

"Oloogun Niyawo Mi, O Tun N Lepa Emi Ni, E Tu Wa Ka"—Olusola
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

"Oloogun Niyawo Mi, O Tun N Lepa Emi Ni, E Tu Wa Ka"—Olusola

Igbeyawo olodun mokandinlogun kan ti di tituka bayii niluu Ileefe. Ogbeni Olusola Aribaba lo gbe iyawo re, Kehinde, lo si kootu ibile pe ki won tu igbeyawo naa ka lori esun pe oogun sise ti po ju ninu igbe aye iyawo oun, ati pe se lo maa n dunkooko mo oun ninu ile.

Bakan naa lo ni ko ba oun fowo sowo po, ko si bikita kankan nipa aye oun ati tawon omo.

O tun fesun kan obinrin ohun pe onija ni, ko si fi oun lokan bale gege bii oko ninu ile nigba kookan.

Okunrin yii to ti loo feyawo mi-in so pe ko sohun to tun le mu ki ibasepo kankan waye laarin oun ati Kehinde mo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

N'llesa, Timothy Fee Koyawo E, O Lo Mu Nnkan Omokunrin Oun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Bisi Adesoye

N'llesa, Timothy Fee Koyawo E, O Lo Mu Nnkan Omokunrin Oun

Ogbeni Timothy Adekoya to gbe iyawo re, Kikelomo, lo si kootu ibile ni Ilesa ti ro ileejo pe ko tu igbeyawo olodun mewaa to wa laarin awon ka bayii lori esun pe o gbe tesoo ogun ibile kan le oun, eyi to fi mu nnkan omokunrin oun lo ti oun ko le ba obinrin mi-in sun yato si oun nikan. Esun keji ni pe iyawo oun je onigbonara, ki i fee ri obinrin mi-in pelu oun.

Ninu awijare Adekoya niwaju Adajo lo ti so pe egbelegbe owo loun ti na lati mu nnkan omokunrin oun pada bo sipo. O ro ile-ejo lati tu igbeyawo naa ka, o ni ko si ohun to le mu oun gun ori obinrin naa mo gege bii oko si aya.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Oko Mi Ki I Ba Mi Sun Daadaa, N Ko Fe E Mo, Odunayo Lo So Bee N'Ilesa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesha

Oko Mi Ki I Ba Mi Sun Daadaa, N Ko Fe E Mo, Odunayo Lo So Bee N'Ilesa

Arabinrin Odunayo, eni odun mejilelogbon ti wo oko re, Ogbeni Oloyede, lo si kootu ibile n'Ilesa lori esun pe to ba ti ba oun sun leekan, o maa n sun lo ni, eyi ti ko je koun gbadun re gege bo se ye.

Ninu awijare Odunayo niwaju Adajo lo ti so pe oko oun je onisekuse okunrin, gbogbo agbara nnkan omokunrin re lo ti maa n lo fun awon orebinrin re ko too wole, eyi ti ki i je ko ni agbara kankan lati ba oun sun, eekan lo si maa n se ni gbogbo igba.

Esun keji to fi i kan oko re ni pe omuti paraku ati arinde oru ni.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Taju Yari L'Ondo, O Ni Apaayan Niyawo Mi, Mi O Fe E Mo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Taofeek Surdiq, Ondo

Taju Yari L'Ondo, O Ni Apaayan Niyawo Mi, Mi O Fe E Mo

Baale ile kan, Ogbeni Tajudeen Akinrintoye to je awako taksi ti gbe iyawo e, Abileko Abimbola Akinrintoye, wa sile-ejo koko-koko kan to wa l'Oja Moferere, niluu Ondo, l'Ojobo,Tosde, ose to koja yii, pe ki won tu igbeyawo odun meta to wa laarin awon ka lori esun pe apaayan lobinrin naa, o lo n gbero lati gbemi oun. Bee lo tun bebe pe ki ile-ejo pa a lase fun obinrin naa lati gbe omo osu marun-un to gbe lowo foun.

Lara awon esun mi-in ti Tajudeen fi kan aya e ni pe gbogbo igba tawon ba ti ni gbolohunaso lo maa n bu awon obi oun,bee lo maa n dunkooko mo oun lati gbemi oun. Bakan naa lo ni alaigboran to maa n se ori kunkun soko ni obinrin yii. O fi kun oro re pe oun setan lati mu elerii ti yoo jerii gbe oro yii nigbakigba wa tile-ejo ba pase pe ko yoju.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

E Ba Mi Be Iyawo Mi Ko Ma Ko Jade, Mi O Ni I Pee Ku To Ba Fi Le Lo — Musediq
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilori

E Ba Mi Be Iyawo Mi Ko Ma Ko Jade, Mi O Ni I Pee Ku To Ba Fi Le Lo — Musediq

Erin arin-lami-loju lawon eeyan to wa nibi ipari ija oko atiyawo kan laduugbo Saabo Oke, n’Ilorin, n rin nigba ti baale ile kan, Ogbeni Musediq, dobale gbalaja fun iyawo e pe ko ma se ko jade, bi bee ko, oun ko ni i pee ku, nitori obinrin naa lo n bo oun. Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba, a gbo pe okunrin naa maa n ji owo iyawo re lati muti ati igbo. O ni to ba ti mu sepe e yo tan, nise lo maa n lu oun bii baara. O salaye pe oko oun ko nise gidi lowo, takisi lo n wa tele, sugbon nigba ti ko se daadaa leni to gbe moto naa fun un gba a lowo e.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Babalola Fomo Iyawo E Loyun, Ni Won Ba Wora Won lLo Sile-ejo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesha

Babalola Fomo Iyawo E Loyun, Ni Won Ba Wora Won lLo Sile-ejo

Asunke, eni ogota odun gbe oko e, Ogbeni Babalola lo sile-ejo ibile kan to wa n’Ilesa nitori to so pe oun loun ni oyun inu akobi re, Bosede, eni odun merinlelogun to bi foko aaro e.
Sugbon iyaale ile yii atomo e ni Bukola lo ni oyun ohun.

Nigba ti Abileko Asunke n soro niwaju adajo, o ni omo merin loun bi fun oko aaro oun ko too di pe oun waa fe Babalola, awon mereerin ohun< Bosede, Yinka, Ayodeji ati Mopelola lawon si jo n gbe po pelu oko oun keji naa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Iyaale Ile Fese Yo Eyin Gende, N Ladajo Ba Ni Ko Lo Sise Sin Agbegbe Fun Ojo Mar
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Olowoake Latifat

Iyaale Ile Fese Yo Eyin Gende, N Ladajo Ba Ni Ko Lo Sise Sin Agbegbe Fun Ojo Marun-un

Afi bii igba teeyan n wo fiimu agbelewo loro ri ni yara igbejo Keji nile-ejo Majisireeti to wa ni Yaba, l’Ekoo, lakooko ti Adajo S.K. Matepo fee gbe idajo re kale lori esun ti won fi kan Abileko Abiodun Olajide, eni ogbon odun pe o yo eyin Augustine Olukukoyi meji pelu igbati, to si so pe oun jebi esun naa nigba akoko ti igbejo waye ninu osu kerin, odun yii, to tun pada waa so lojo ketala, osu karun-un, yii pe oun ko jebi esun ohun mo. N ni adajo ba ni ko loo sise sin agbegbe fun ojo marun-un gbako.

(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Awon Eegun Dero Atimole L’Odo-Owa, Obinrin Kan Ni Won Lu Daku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Awon Eegun Dero Atimole L’Odo-Owa, Obinrin Kan Ni Won Lu Daku

Inu wahala nla lawon eegun meji to lu obinrin kan daku niluu Odo-Owa, nipinle Kwara, wa bayii, won si ti n kawo ponyin rojo ni kootu.
Awon eegun meji ohun ni Olasehinde Asaolu ati Kolawole Kayode ti won n gbe niluu OdoOwa, nijoba ibile Oke-Ero. Nise won so pe won ko awon nnkan ija oloro, ti won si bere si i da ilu ru, ti won se opo eeyan lese repete. Bakan naa ni won tun ba opo dukia je.

Ninu iwe ehonu ti Ogbeni Abraham Olu Aina, eni to n gbe laduugbo Eri, ko si Komisanna awon olopaa Kwara lojo kerin, osu kerin, odun yii, o so pe lojo kerinlelogun, osu keta, ni eegun merin kan, eyi ti Ogbeni Tunde Akinola saaju won lu omo aburo oun toruko e n je Kemi Alufoge daku.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Asiri Nla Alaaji Amosa So Itan Igbesi Aye Re, O ni: Anjonnu Ni Mo Fe Niyawo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Asiri Nla Alaaji Amosa So Itan Igbesi Aye Re, O ni: Anjonnu Ni Mo Fe Niyawo

Titi di bi a se n ko iroyin yii, gbogbo eni to wa nibi ti baba afoju eni ogorin odun kan, Alaaji Karimu Amosa, ti gbogbo eeyan mo si Afoju¬ma-tepa ti n so itan igbesi aye e loro naa n ya lenu. Idi ni pe bi baba naa se fo loju to, o si n lo soko ode, bee lo je pe o fe anjonnu niyawo, tiyen si bimo fun un daadaa. A gbo pe ninu igbe ode lawon anjonnu ti fibinu fo o loju.

Igbe aye iyanu ti baba yii n gbe niluu Diko, to wa nitosi ilu Molete, nijoba ibile Moro, nipinle Kwara, lo mu ki Iwe Iroyin Yoruba foro wa baba naa lenu wo, o si ba wa so opolopo oro lori itan igbesi aye e, idi tawon anjonnu se fo o loju, asiri to wa ninu bo se n de igbe ode, agbara ti Olorun fun un ati bee bee lo. Bayii ni oro baba naa se lo> Bi mo se bere Omo bibi ilu Diko, nitosi Molete, to wa nijoba ibile Moro, nipinle Kwara, ni mi.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Iyawo Mi Ti Feran Kinni Ju, Gbogbo Igba Lo Fe Ki N Maa Ba Oun Sun, N Ko Fe E Mo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Iyawo Mi Ti Feran Kinni Ju, Gbogbo Igba Lo Fe Ki N Maa Ba Oun Sun, N Ko Fe E Mo

Niluu Omu Aran ni baale ile kan, Ogbeni Dele, ti pariwo sita pe oun ko fe iyawo oun mo nitori bo se feran ibasun ju bo se ye lo, bee lo tun lo tori owu dana sun aso iyawo e, nitori naa, ko maa lo.

Nigba to n ba wa soro, o salaye pe osise ijoba loun ati pe iwa iyawo oun ti ko daa loun se loo feyawo keji. O ni latigba toun ti feyawo le e lo ti bere wahala nla. O so o di mimo pe gbogbo igba lo maa n fe koun ba a lajosepo, bee ni ki i fe koun sun ti iyawo keji rara.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
‘Okobo Loko Mi, Ko Si Mi Laso Wo Lati Bii Osu Merin Ti Mo Ti Dele Re’
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

‘Okobo Loko Mi, Ko Si Mi Laso Wo Lati Bii Osu Merin Ti Mo Ti Dele Re’

Afi bii igba teeyan n wo fiimu Baba Ijesa alawada loro ohun ri ni kootu ibile kan n’Ilorin laipe yii nigba tiyawo ile kan, Abileko Nimotalahi Saka, so pe okobo loko oun; esin inu iwe ti ko le ta putu ni, oun ko si le se koun ma se kinni ni toun. O ni lati osu kerin tawon ti fera awon, nise lo n keyin sogiri tawon ba sun, ko si oun laso soke ri.

Abileko naa fesun yii kan oko re, Ogbeni Saka Baba. O loun setan lati fi baba naa sile nitori omo kekere loun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Oro Buruku Tohun-terin! Ambali Fogo Mo Mutiu Lori Nitori Romoke
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Oro Buruku Tohun-terin! Ambali Fogo Mo Mutiu Lori Nitori Romoke

Gbogbo awon eeyan to wa nile oti kan niluu Ofa laipe yii nibi tawon Baale ile meji ti gunra won nigo nitori ale lo n so pe nnkan ti won je lo yo won.

Gege bi oniroyin wa se gbo, o pe ti Ogbeni Ambali ti n fe obinrin kan to n je Romoke to n ba iya oloti kan ta oti nibe, ti won si n baara won sun. Sugbon sadeede nija de laarin won, ti won ko si da sira won mo. Laarin akoko yii ni Ogbeni Mutiu n se kuru-kere lodo omobinrin yii, ko too di pe awon mejeeji bere si i ba ara won lasepo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Oko Mi Fee Fi Mi Soogun Owo, N Ko Fe E Mo — Abibat
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Oko Mi Fee Fi Mi Soogun Owo, N Ko Fe E Mo — Abibat

Afi bii igba teeyan n wo fiimu agbelewo Baba Latin loro ohun ri ni kootu ibile kan to wa n’Ilorin laipe yii, nigba tiyawo ile kan, Arabinrin Abibat, la a mole pe oun fee ko oko oun, Godwin Nduka, sile nitori pe o fee foun soogun owo, bee osu kefa pere tawon fera awon niyi. O ni oju oko oun le ju nipa oro owo, o si ti pinnu lati foun seso.

Lakooko tobinrin ohun n salaye oro naa ni kootu ibile kan n’Ilorin laipe yii, o so pe bi ki i baa se asiri oko oun to tu soun lowo, okunrin naa iba ti foun seso. Obinrin yii loun ti pinnu lati ko o sile nitori pe oun si lemii oun i lo. O ni okunrin naa ko feran oun rara, nise lo maa n se oun basubasu.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Alaigboran Niyawo Mi, Nise Lo Maa N Fo Mi Leti Ti Mo Ba Ba A Soro — Zakariyau
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Alaigboran Niyawo Mi, Nise Lo Maa N Fo Mi Leti Ti Mo Ba Ba A Soro — Zakariyau

Pelu omi loju ni baale ile kan, Ogbeni Bello Zakariyau, fi n soro ni kootu ibile niluu Ilorin laipe yii nigba to so pe nise niyawo oun maa n fo oun leti ni gbogbo igba toun ba ti beere ounje lowo re, eyi lo mu koro e su oun toun si pinnu lati ko o sile. Okunrin naa so pe loooto lo ti pe odun meta bayii toun ti fe Fatimoh Zakariyau, sugbon oun ko nifee re mo rara nitori ki i bowo foun gege bii oko, bee ni ki i se ojuse e gege bii aya loode.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: