Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara
[ Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara ]

·Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
·Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo — Abigail
·Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina
·Emi Atoko Mi Ko Ja, Nitori Omo Lawon Ebi Re Se Fee Le Mi Jade - Rafia
·Latodun Merin Seyin Loko Mi Ko Ti Ba Mi Lasepo, Mi o Se Mo - Folasade
·Odo Ni Wolii Moses Ti Ni Ki David Loo We Iwe Isegun, Lo Ba Fogbon Ji Moto Re Gbe
·Oro Buruku Toun Terin: Awon Omo Poli Ojere Mefa Daku Lakooko Ti Won Fee Sedanwo
·O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta
·Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Tuesday, April 28
· Ladoke Akintola fee di oga ara re, bee ni Obafemi Awolowo n so pe omoose oun ni,
· Oru ojo kokandinlogbon, osu keje, odun 1966, ki i se ojo daadaa kan niluu Ibadan
· Nibi ipade awon lobaloba gbogbo Naijiria, nibe ni won ti pa Ogagun Agba Aguiyi I
Thursday, June 26
· Ohun Tawon Oloselu Wa Se N Pa Ara Won Nitori Ipo Ree O
Wednesday, June 25
· Bawo Ni Jonathan Se N Se Bayii
Sunday, June 08
· Ta Lo Gba Yin Lamoran Bayii? Eleyii Ko Daa O
· Igbimo Agbaagba L'Ekiti Kilo Fawon Egbe Oselu Lati Yago Fun Iwa Jagidijagan
Sunday, March 30
· Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi?
· Olorun Ma Fiku Bo Sani Abacha Lasiiri o
· Ija PDP: Awon Olori Ile Igbimo Asofin Koyin Si Jonathan
· Igbakeji Gomina Fabuku Kan Oludamoran Re Lode Inawo Ni Saki
Saturday, January 25
· Ija PDP Bureke: Obasanjo, Babangida, Anenih Ati Jonathan Dota Ara Won
· Iyen Lawon Yii Naa Se N So Kantan-kantan
· Iyen Lawon Yii Naa Se N So Kantan-kantan
Monday, November 25
· Loooto Ni Mo Wi Fun Yin, Adelabu Ko Girigiri Ba Awon Awolowo Pelu Akintola
· Ki La Tun N Duro De
Sunday, October 27
· Adelabu Fesun Kan Awolowo Pe O Fee Ro Olubadan Loye, Lawon Ladoke Akintola Ba N
Sunday, September 08
· A Tie Gbo Tawon Ti Won N Gbera Won Lenu Jo Lasan: Ta Ni Yoo Mu Awon Eleyii So Bi
· Ki Lo Maa N Se Awon Oloselu Yii Gan-an?
· ...Sugbon Awon Alagbara Ko Mo Pe Wahala N Be Ni Tiwon O
Thursday, June 13
· Awon Odaran Lo Ku Ti Yoo Maa Sejoba: Atiku, Iru Oro Wo Niyen?
· Wahala Wa O: Gomina Fowo Awon Araalu Ra Eronpileeni
· Bee Ko Ni Won Se N Se: Enika Oke Oun Bee Kirikiri Lo Wa Bayii
· E Je Ki Won Maa Sunkun
· Kin Ni Ka Ti Pe Iru Eleyii Si
Saturday, April 13
· Abi Ki Lo N Seyawo Jonathan Yii: Kin Ni Won N Wa Kiri - Oun Atawon Minisita Oko
Wednesday, March 20
· Ija Yii Ko Ti I Tan O: Awon Omo Obasanjo So Pe Apa Paraku Ni Jonathan
· Nitori Oro iIle, Kabiyesi Ati Akowe Re Foju Bale-ejo L’Osogbo
· Kin Ni Jonathan N Wa Kiri O: Are Oni-rin-Aare-Lese - Apa Paraku
· Awon Oloselu Te E Fee Tori Won Para Yin Ree O: Ebele Jonathan, Olusegun Obasanjo

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O

Alaigboran ni wa. Tabi ki n so pe alaigboran ti po ju ninu iran awa Yoruba. A feran abamo pupo. Bi enikan ba roye kan, tabi to ba soye lori ohun kan, tabi to ba ni iriri kan to fi to awa to ku sona, kaka ka gbo, yeye la oo fi i she, tabi ka maa bu u, awon mi-in aa tie mura lati she e leshe ti won ba le sun mo on. Nigba ti oro naa ba waa shele, to ba je bi eni naa ti wi lo pada ja si, awon yii kan naa ni yoo dide, won yoo ni awon ko mo ni, abamo yoo si dun lenu won bii nnkan. Ko dun mo mi ninu lati maa wi pe oro ti mo wi she tabi ko she, sugbon nigba to waa she pe opo awon to wa nile yii, aletilapa ni won nko! Ki a too dibo odun 2015, mo pariwo to, mo pariwo gan-an, tawon kan si mu mi lotaa, tawon mi-in n shepe le ara won lori ti won ro pe emi ni. Sugbon bi a ti dibo tan lawon ohun ti mo ri ti mo fi soro bere si i she, gbogbo wa si foju ri i.

Nigba naa lawon eeyan bere si i ke abamo, 'baba, a o mo ni, baba, oro ti e wi lo ti n she yii o, baba, e ma binu.' Sugbon anfaani wo lo wa ninu abamo? Oore kin ni abamo yoo she feni to ba she e? Sugbon oore kan wa nibe o, oore naa ni ka lo o lati fi gbaradi fojo iwaju, ka ba ara wa soro pe ti iru nnkan yii ba tun shele lojo mi-in, a oo gboran sira wa lenu. Sugbon ki lo tun shele nigba ti ibo odun yii de? Awon mi-in pe mi ni were danwo, awon mi-in ni ki lo de ti mo koriira Fulani to bee, awon mi-in si so pe Buhari ni mo koriira. Loju awon dindinrin mi-in, won n gbeja APC, egbe oshelu won niyen o, won si ti ri emi gege bii omo PDP. N ko mo ibi ti won ti pade ti won ni won gbo oruko mi ninu egbe kankan, tabi ti mo ba n she oshelu, ko ye ki won ti fi emi naa si ipo nla ni. Ti pe n ko mowe to ni tabi ti pe n ko dagba to, nigba ti won n mu baba odun marundinlaaadorun-un (85) ninu wa lati gbe ile ijoba le won lowo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe

Bi eeyan ba ri ohun to n sele ni awon ile ijoba wa lasiko yii, okan onitohun yoo maa bale pe o da bii pe awon ijoba yii fee to ona to dara, awon oloselu kookan ti won ko moyato laarin oselu ati ijoba sise yoo yose to ba ya.

Sugbon awon ohun to n sele, ati bi awon eeyan naa se n seto ijoba won fihan pe nnkan yoo dara fun wa bo ba n ba bayii lo. Sanwo-Olu, gomina ipinle Eko, ra moto marundinlaaadoje (125), o fi okada marundinlogoji (35) ti i nidii, o ko o fawon olopaa ati awon agbofinro to ku, o ni ki won pin kinni naa laarin ara won, fun eto aabo to peye ni gbogbo ipinle re.

Bi oun ti n ko tire fun won, bee naa ni Dapo Abiodun ti ipinle Ogun naa ko ogorun-un moto, ati ogorun-un meji okada nla fawon olopaa odo tire naa, o ni ki awon naa fi maa seto aabo to peye. Ko si ohun ti eeyan le se ju ka ki awon gomina wonyi lo, paapaa lasiko ti ko sowo lowo ijoba pupo, to si je won sese tun de ile ijoba ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Bi Iro Ba Lo Logun Odun...
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Bi Iro Ba Lo Logun Odun...

Awon eeyan wa ni ko gbon, bee ni, opolopo ninu awon eeyan wa ko gbon rara. Eni ti a ba tan je leekin-in-ni, iyen see pe ni asise, tabi misiteeki.

Sugbon ti eni to tan-an-yan leekin-in-ni ba tun waa pada tan an je leekeji, iyen ki i se misiteeki mo, eni ti won n tan je ni ko logbon.

Nigba ti won fee dibo to koja yii, ibo aare ti a di ninu osu keji odun,okunrin kan ti won n pe ni Rotimi Amaechi jade, se oun ni minisita fun eto igbokegbodo oko, o ni ki gbogbo aye le mo pe ijoba Buhari n se bebe, awon ti pari oju-ona reluwee Eko si Abeokuta, ki gbogbo aye maa rin in bayii lo ku, oro wahala irinna lati Abeokuta si Eko ti di ohun igbagbe pata, o ni idi ti awon ara Abeokuta ati awon eeyan Eko se gbodo dibo fun Buhari niyen.

Awon ti won mo oro naa so pe irolokunrin yii n pa, ati pe baba nla opuro ni. Won ni ona reluwee yii ko ti i pari, ati pe won ko ra oko oju-irin tuntun kankan, awon aloku, oko ti aye ko lo mo, ni won loo ko wa lati ibi kan ti won si kun loda tuntun. Kia ni Amaechi ati awon Lai Muhammed ti sare jade, won ni oro lati enu awon alatako ti ko feran Buhari ni, awon ole ti won n ji owo ilu ko lo n so bee. Loro kan, nigba to di ojo kejo, osu keji, odun yii, nigba ti ibo didi ku bii ose meji pere, Amaechi gbe Ibikunle Amosun leyin, won ti Alake Egba si aarin, won ni awon ti pari ona reluwee Abeokuta s'Ekoo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi

O fere je pe ko si kinni kan ti awon oloselu Naijiria ko ni i fi owo ibaje kan. Eyi to si buru to je yoo pada waa kan gbogbo eeyan ile yii naa ni ti etoidajo. Won ti so awon adajo wa di nnkan mi-in, iba die, iyen to ba tilewa rara, lo ku to n dajo ododo.

Bee ni orile-ede ti ko ba ti si idajo ododo, ibe yoo segbe, ki Olorun ma je ki Naijiria segbe ni. Ohun to ba foju han, ti gbogbo aye ri, ti won si mo pe eleyii ni ododo, awon adajo wa yoo jokoo, leyin tiwon ba ti gbowo lowo awon oloselu tan, tabi ti awon ti won n sejoba ba ti hale mo won, won yoo ni kinni naa ki i se ododo, nitori lasiko to sele, elerii to soro yen ko letoo lati soro.

Ki i se pe won ni elerii yen ko so ododo o,sugbon pe ko letoo lati soro ni. Iyen ni won yoo se pale ododo mo, ti won yoo si fi iro ropo re. Ibo ti gbogbo awon ara Kogi ri, ti won si fi tokan-tara won dibo fun Dino Melaye, awon igbimo ti won gbe dide nibe lati sedajo ni ibo naa ni ko daa, Dino ko lo wole.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia

Ale ojo Eti, Fraide, ose to koja, ti i se ojo keeedogun, osu yii, niroyin gbale pe alaga fegbe oselu PDP nijoba ibile Ipokia, nipinle Ogun, Alaaji Saruku Suraju, tawon eeyan mo si Aro meta ku. Iku naa ko ba si ma mu kayeefi dani ju bee lo ka ni ki i se pe oteeli ni baba eni odun mejidinlaaadorin naa ku si, won ni asewo ni alaga naa ba se sunle-sunle to fi gbona orun lo.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, nnkan bii aago mesan-an ale ojo naa ni gudugbe ja ni oteeli kan ti won n pe ni 'De Lover Hotel' to wa laduugbo Aseko, Ibatefin, ni Ipokia, nibi ti won ni okunrin to je alaga egbe PDP titi di akoko iku ojiji naa dagbere faye si. Ohun tawon tisele naa soju won salaye fun wa ni pe ipade kan ni Suraju n lo lojo naa tobinrin kan ti won pe ni orebinrin re fi pe e lori aago pe ko yoju soun ni oteeli De Lover, won ni bo si se gba ipe naa tan lo yipada ti ko lo sipade ohun mo, odo obinrin to pe e naa lo gba lo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa

Latari ijamba oko to n fopo emi sofo ati bi orisiirisii ajalu mi-in bee se maa n waye loju ona marose Osodi-Apapa, ile igbimo asofin Eko ti ke sijoba apapo lati pese afara elese soju ona naa.

Oro yii lo je yo latenu omo egbe oselu alatako, Onarebu Jude Idimogwu, pe asiko ree fun ile naa lati ta ijoba apapo ji lori pipese afara elese, eyi to ni yoo sadinku sun-kere-fa-kere oko ati ijamba moto nibe. Bee ni Onarebu Sola Giwa ni kijoba koko sewadii na ko too di pe won gbe igbese kankan lori pipese afara sagbegbe ohun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?

Orisiirisii leeyan yoo maa ri, beeyan si n wa olori awon alawada bi ko ba ri i, bo ba ti ri Gomina Ekiti, Ayodele Fayose, ko sinmi a n rin igboro kiri mo, oga awon alawada patapata lo ti ri yen. Ni gbogbo ose bii meji meta seyin, nise ni Fayose n soro to n laagun, to n kuru to n ga, to n bu eebu to n fepe bonu, inu e ko dun rara pe Aare Muhammadu Buhari fee lo si China. 

O ni ki lo n wa lo, oun gbo pe o fee loo yawo, ko jokoo sile ko ma yawo kankan, ati pe nigba ti Naijiria ko fararo, ko si onisowo ile China kan ti yoo wa si Naijiria lati waa fi owo re da ise sile, nigba to ti mo pe oun ko le ri ere kankan je.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare

Ohun ti yoo dara ju ni ki won gbe oga awon looya ti EFCC mu timole lojosi wa sile-ejo, ko waa salaye, ko si waa so tenu re, idi to fi n fun adajo lowo. Oro kan lokunrin naa ti won n pe ni Riki Tarfa ti gbe kale. O so pe owo toun fun adajo naa, oun fun un lowo naa ko fi se oku iya re ni. Bo tile je pe eeyan ki i se adajo, ti ki i se looya, eeyan yoo sa mo ohun ti laakaye ba so. 

Ejo wa niwaju adajo kan, looya to wa n gba ejo odaran ti won fesun kan ro lo waa n fun adajo lowo, to ni ko fi soku baba e, owo ti ki i si i se owo kekere. Lara ohun to n ba wa laye je ni Naijiria niyi. 

Olopaa ko see gbojule, looya ko see fokan tan, iwa ibaje, owo kikoje, agbara nilokulo ti ba aye gbogbo won je, o fo won lori, o si da opolopo won lori ru patapata.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Bee Ni Buhari Ko Wi Nnkan Kan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Bee Ni Buhari Ko Wi Nnkan Kan

Bi awon ti won n sejoba yoo ba soro, won yoo ni isokan Naijiria lawon n wa, awon n fe ki gbogbo wa da bii omooya. Sugbon awon yii kan naa ni won yoo mu eni kan lowo dani, won yoo de owo re seyin, won yoo waa ni ki awon mi-in maa gba a loju, ki won maa gba a nimu mo igi. Bee omo iya kan naa ni won o.

Bi iya ba n je iran kan nile Naijiria, kaka kawon ti won wa nijoba sare, ki won gba awon ti iya n je yii, won yoo yi oju segbee kan ni, afi bii igba pe won n fe ki won pa wa run. 

Bi oro ba ri bayii, paapaa nigba ti Buhari ti i solori Naijiria bayii mo pe awon eya oun ni won wa nidii iwa aburu yii, oun lo ye ko koko soro, ko pe awon oba atawon ijoye won, ko si ran won sawon eeyan yii ki won kilo fun ara won, ko ba won soro lori redio nibi ti won ti n gbo, ko si je ki gbogbo ilu gbohun re pe oun ko faramo ohun ti awon eeyan oun n se.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

E Woju Won o: Awon Ti Won Ko Owo Naijiria Je Ree o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

E Woju Won o: Awon Ti Won Ko Owo Naijiria Je Ree o

Nigba ti oro naa koko bere, ohun tawon eeyan ro ni pe ijoba Muhammadu Buhari n wa gbogbo ona lati mu awon ti won ba Aare ana, Goodluck Jonathan, sise ni. Sugbon nigba ti asiri nla naa bere si i tu sita, kaluku loro naa ya lenu. Nipari osu kejo, odun yii, ni ijoba Buhari gbe igbimo kan dide, igbimo oniwadii ni, ohun ti won si fe ki igbimo yii wadii ni bi awon ti won n seto aabo ile yii lati odun 2007 se na awon owo ti won ko fun won. Ohun to fa eyi ni pe laarin odun naa, ileese to n mojuto eka eto aabo fun ijoba apapo pese owo lati ri i pe won ra irinse to po, won ra eelo ogun jija, won ra ibon atawon eronpileeni repete, paapaa nitori ogun awon Boko Haram to gba gbogbo ilu kan. Sugbon bi won ti n gba owo to, bee lawon soja n pariwo pe awon ko nirinse, ti won si n sa loju ogun fun awon Boko Haram, oro naa si di nnkan abuku fun ijoba apapo, nigba tawon soja won ki ere mole ti won sa lo.

Bi e ko ba gbagbe, laye ijoba Jonathan, awon soja bii ogota kan wa ti won dajo iku fun, esun ti won fi kan won ni pe won sa loju ogun niwaju awon Boko Haram, won sa lo pata ti enikan ko ri won. Die lo ku ki won pa won, afi nigba ti Buhari gbajoba to da won sile. Esun ti won fi kan won ni pe won ko duro jagun, nigba ti won ti foju gan-an-ni awon omo Boko Haram yii, nise ni won ki ere mole ti won n sa lo. Sugbon awon soja ti won mu nigba naa soro, won ni ko si bi awon se le koju awon Boko Haram, nitori irinse ti won n lo lagbara, o si po ju tawon lo gan-an. Nidii eyi, won ni bi awon pe egberun ti awon dojuko awon omo Boko Haram ti ko ju mewaa lo, bii eni to mu adie ni won yoo mu awon, nitori awon irinse ti won n lo, irinse igbalode to lagbara ni, eni kookan won si le pa bii ogun eeyan laarin iseju meji pere. Nise lo da bii pe owo lasan lawon fi n ja ni tawon, eni ti ko ba nirinse ogun ko si le koju ogun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Se Ka Kuku Loo Be Obasanjo Ko Waa Se Asaaju Awa Yoruba?
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Se Ka Kuku Loo Be Obasanjo Ko Waa Se Asaaju Awa Yoruba?

Bo ba je irin ti egbon wa, Egbon Segun, (Obasanjo) rin lo si Ileefe lose to koja yii ti okan e wa, to si je lori ododo, a je pe isokan ti a n wa nile Yoruba ti bere naa niyen. Lojo ti Omooba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Yoruba tuntun, wo ilu naa wa, lojo naa ni Egbon Segun ti lo sodo re lati ki i, o mu awon eeyan mi-in dani ti won je agba nile Yoruba yii naa, won si se odomode ti yoo di baba gbogbo wa naa ni maa wole maraba. Ka sa so pe yato si awon agbaagba Ife, Egbon yii lo tun koko ki oba tuntun naa kaabo. Bi ile Yoruba ba dara, ti ko ba si iyapa, ti ohun gbogbo ba si n lo bo se ye ko ri, bi nnkan se gbodo sele lo sele yii. Bi won ba yan Ooni tuntun, eni to ba je asaaju Yoruba nigba naa gbodo ko awon agbaagba ilu lo si Ife lojo ti oba naa yoo koko de, awon ni won yoo loo pade re, ti won yoo si fi i wo sibi to ba dara, awon ni yoo koko maa ri bi gbogbo etutu ilu to ku ba ti n lo.

Idi ti eyi fi gbodo ri bee ni pe Ooni ki i se oba Ileefe nikan, Oba Yoruba ni. Gbogbo itan yoowu ka pa funra wa, gbogbo ona yoowu ka gba, gbogbo ohun yoowu ki oselu so wa da laarin ara wa, Yoruba gba pe Ileefe lawon ti wa, tabi pe Ife ni orirun gbogbo wa. Niwon igba ti Ileefe ko si ti i parun, ti oba si wa nibe to n dade, ti ase Oduduwa gbogbo si wa lowo re, oun naa ni oba gbogbo wa, iyen ti Yoruba ba fe ki nnkan roju, ti a ko si fe ki aye maa fi wa seleya, ki won maa pe wa ni alaimokan ti ko le to ile ara re, awon oniyeye ti won ko ni orirun. Okun kan ko ni i gun titi ko ma ni ibi ti won ti fa a wa, tabi ibi to ti n gun bo, Yoruba ni orirun, Ileefe si ni orirun wa. Bo ti wu ki omo lowo to, bo ti wu ki omo dagba to, baba re ko sa ni i dobale fun un ko ni oun lo bi baba oun, omo re naa ni won yoo maa pe e. Gbogbo eni yoowu to ba ti Ileefe lo, omo Yooba naa ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

O Tan! Wahala Egbe Afenifere N Po Si Lehin Ti Fasoranti Kowe Fipo Asaaju Sile
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

O Tan! Wahala Egbe Afenifere N Po Si Lehin Ti Fasoranti Kowe Fipo Asaaju Sile

Wahala sese bere ni lehin ti Asaaju egbe Afenifere, Alagba Reuben Fasoranti, ti kowe fipo e sile gege bii asaaju egbe naa. Lasiko to n soro nipa ohun to mu un gbe igbese ohun, baba eni ogorin odun naa so pe nitori irepo ti ko si ninu egbe naa mo lo je koun fipo ohun sile.

Gege bi o ti jeyo ninu leta ifiposile ti baba yii ko sawon agba egbe lo ti so pe ohun ibanuje lo je foun bi awon omo egbe ko se wa ni irepo, ti won ko si tele ilana ti Oloogbe Obafemi Awolowo la kale lati je ki isokan wa laarin awon omo Oodua. Baba yii so pe ohun ti ko bojumu to ni bi iyapa se wa ninu egbe Afenifere.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Buhari, Die Die: Oun To Yeni L'oyeni...Beeni Alaseju Tite Ni i Te...
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Buhari, Die Die: Oun To Yeni L'oyeni...Beeni Alaseju Tite Ni i Te...

Awon kinni kan wa ti ko dara fun olori lati maa se, eleyii si ti di asa fun olori orile-ede yii, Aare Muhammadu Buhari. Ni gbogbo igba to ba ti lo si ile okeere, eebu ati oro ibaje ni yoo maa so nipa Naijiria, oro naa si buru debii pe Buhari ko lo sibi kan ri ko so pe awon omo Naijiria le se kinni kan yanju, tabi pe eeyan daadaa ni won, tabi pe won tile wulo nibi kan.

Ohun meji ni Buhari maa n so nipa Naijiria, ati awon eeyan re. Akoko ni pe awon omo Naijiria ti baje ju, won baje gan-an, won ko si wulo fun kinni kan rara. Bawo ni olori orile- ede kan yoo se maa so bee nipa awon eeyan re leyin odi. O ti so o ni Amerika, o so o ni Jamani, ko si ibi to lo ti ki ti i so o, eyi to si so ni India bayii lo bi opolopo eeyan ninu to fi di pe won n soro, won n pariwo pe ki lo de gan-an, se aare tiwa ko mo ju ko maa bu wa lo ni, nibi ti awon to ku ti n soro orile-ede won daadaa! Oro keji ti Buhari tun feran lati maa so naa ni pe iwa ibaje owo-kiko-je ti ba wa je, o ti wo gbogbo omo Naijiria lewu debii pe ko si ibi kan ti won ki i ti se bee, ati awon ti won n sise ijoba ati awon ti won n se ise adani, gbogbo won ni ole, gbogbo won ni akowoje.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Lori Bi Aare Muhammadu Buhari Ti Yan Awon Minisita Re Tuntun, Oun Taye N Wi Ree
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Lori Bi Aare Muhammadu Buhari Ti Yan Awon Minisita Re Tuntun, Oun Taye N Wi Ree o (Apa Kinni)

Ko seni ti aya re ko ko soke lojo Isegun, Tusde to koja lohun-un tawon asofin agba orile- ede yii foro wa awon minisita ti Aare Muhammadu Buhari fi sowo si won lenu wo. Bi ojo naa se lagbara fawon minisita yii, bee lo ri fawon omo egbe oselu won, kinni ohun ko si yo awon molebi won paapaa sile. Beeyan ba ri bi oyinbo se n bo lenu Dokita Kayode Fayemi, ti Ogbeni Babatunde Fasola naa n feebo bii opeere, ti Dokita Ngige naa duro wamuwamu niwaju awon asofin, tawon asofin naa n ju awon ibeere kabiti-kabiti sawon minisita tuntun yii, yoo mo pe ojo nla lojo naa o jare. 

Leyin opolopo ibeere ati idahun to yanranti ni olori ile igbimo asofin agba, Dokita Bukola Saraki atawon asofin yooku fowo sawon minisita tuntun ti yoo ba Buhari sise yii. Ireti awon araalu ni pe didun losan yoo so fawon omo Naijiria lasiko Buhari, ti ayipada gidi ti egbe APC so pe awon mu wa yoo si je ti gbogbo wa.

Babatunde Raji Fasola Babatunde 

Raji Fasola Ojo kejidinlogbon, osu kefa, odun 1963, ni won bi Amofin Babatunde Raji Fasola si 'Island Maternity Hospital', n'Isale-Eko. O bere ileewe alakoobere re ni 'Sunny Field Primary School', to wa l'Adelabu, ni Surulere, ko too tesiwaju sileewe girama 'Birch Freeman High school', sugbon Igbobi College lo ti pari eko re.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Buhari Ja Fun Fulani Ri, Lojo Wo Lawon Oloselu Tiwa Fee Ja Fun Wa?
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Buhari Ja Fun Fulani Ri, Lojo Wo Lawon Oloselu Tiwa Fee Ja Fun Wa?

Lori oro awon Fulani ti won ji Olu Falae gbe ni mo si wa, n ko ti i le menu kuro nibe nitori awon ohun to tun n sele si i. E wo o, oro to wa nile yii ki i se oro esin o, n ko si fe ka gba a si oro esin rara. Fulani yato si musulumi, bee ni ki i se gbogbo eni ti won bi si ile Larubawa lo n se Islaamu, oto ni esin, oto ni iran eni. Bakan naa ni oro yii ki i se oro oselu.

O n dun mi gan-an fun awon eeyan ti won n fi oro awon Fulani to fee fi ogun di wa mo inu ile tiwa yii se oro oselu, nitori bi oselu ba fo won loju loni-in, bi wahala oro naa ba sele, won ko ni i wa laye lati se oselu, iru awon ti won ba si n dite mo eya won bayii ni yoo koko ba ogun naa lo. Bi kinni ohun ba sele loooto, ko ni i si oselu kan ti yoo see se nile yii, bee ni enikan ko ni roju raaye se musulumi tabi kristeni paapaa, sebi ibi ti alaafia ba wa ni won ti n fokanbale se esin, awon ti ogun n le ki i raaye duro ko ijo jo.

Awon ohun meji ti awon alagbara aye fi n mu awa mekunnu, ti won si fi n koyin ara wa si ara wa loro oselu ati oro esin, iyen leyin ti won ba ti fi ise ati osi ta wa tan, ti won si ri i pe a ko ri ounje je, a ko rowo fi ra aso tabi to awon omo wa debi to ye. Igba yii ni won yoo fi oro esin si i, e oo ri enikan ti yoo pe ara re ni musulumi, ti yoo ni ija Anobi tabi ija Olorun loun n gbe, ti yoo yo obe, ti yoo maa fi dunbu eda egbe re, bi won ba si dunbu won tan, won yoo ji eru won ko lo. Se esin Olorun kan le mu eeyan se iru iyen ni. Tabi ki won gba ibi oro oselu, eleyii naa buru gidi. Aanu awon odo ati awon omode oni si se mi nidii eyi gan-an.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori N'Ibadan, Nitori Ija Oun Ati Akintola Ni

Won ti pari ipade Egbe Olope, Action Group, (AG) niluu Jos, Ladoke Akintola ati Ayo Rosiji pelu awon minisita merin ti won si kuro nipade naa ko pada sibe, bo tile je pe awon agbaagba egbe won parowa fun un lati lo, ki won jo ri Obafemi Awolowo, ki won le yanju ede-aiyede nla to be sile ninu egbe won. Awon eeyan Akintola ni ko je ko lo sipade ohun, won ni anfaani to wa ninu ko ma lo sibe po fun un ju ko lo lo.

Won tile ni ko si anfaani kan fun un bo ba lo sibe, yoo kan tun pada si oko aaro re ni. Oun naa si gbo, ko yaa lo mo. Pelu bi ko se lo nni, awon omo re ko je ki nnkan sinmi niluu Ibadan ati ile Yoruba lapapo, won n rin kaakiri, ipade n lo lorisiirisii, ohun ti won si n wa naa ni bi won yoo ti se fi ese ominira ti Akintola gba lowo Awolowo yii rinle, ti SLA yoo gba agbara kun agbara, ti won ko si ni i so pe Olorun lo mu un.

Awon omo-eyin Awolowo paapaa ko mu nnkan rogbo nibi ipade won ni Jos. Won ti fibinu yo Ayo Rosiji kuro nipo akowe agba egbe ohun, won si ti fi Sam Ikoku si i. Bee ni won ti fun Bola Ige ni oye kan pataki ninu egbe AG, oun ni alukoro pataki bayii, Publicity Secretary' lapapo, gbogbo oro to ba si jade ninu iwe iroyin, tabi to ba jade lori redio, to ba ti je oro egbe won, ki e ti mo pe lati enu Bola Ige lo ti jade.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Nnkan De! Oro Awon Minisita Buhari Ti Da Wahala Sile Ninu APC
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olowale Adejare

Nnkan De! Oro Awon Minisita Buhari Ti Da Wahala Sile Ninu APC

Ni gbara ti oruko awon ti Aare Muhammadu Buhari fee fi se minisita re ti jade lawon ti won mo nipa oselu ti mo pe wahala loro naa ba de, sugbon awon asaaju egbe naa gbogbo n pa kinni ohun mora, won ko fee so o sita. Inu awon kan dun pe ibi ti oro ohun yoo yori si ree, sugbon inu awon kan baje patapata.

Oro naa ko le se ko ma ri bee, nitori ninu gbogbo awon ti Buhari mu, ko senikan to lenu ninu awon asaaju APC, Buhari lo yan won funra re, awon to fe lo pe mora, ko si fi tawon olori egbe naa se. Ninu gbogbo awon gomina APC paapaa, Gomina Ibikunle Amosun nikan ni Buhari je ko fa eeyan kale, ko faaye gba gomina mi-in mo rara, eyi si fa ibinu ati ikunsinu repete. Eyi to tile waa mu wahala ati ede-aiyede to si le pada waa bi Ige ko bi Adubi lowo bayii ni pe gbogbo awon ti Buhari yan yii, paapaa awon to yan lati ile Yoruba, awon tawon olori egbe APC lagbegbe naa ko faramo rara ni.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Olorun O, Waa Gba Awa Omo Yoruba Lowo Ogun Ainisokan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Olorun O, Waa Gba Awa Omo Yoruba Lowo Ogun Ainisokan

Olorun o, n ko mo ibi ti oju re wa, Oba nla. Sugbon nibikibi ti oju re ba wa, mo gbadura si o ni kutukutu owuro yii, waa gba awa omo Yoruba la, waa ko wa yo lowo ota ile, waa ko wa yo lowo ota awa ara wa. Olorun, gba wa ka le ni isokan laarin ara wa, ki oro ara wa ye ara wa, ki o ma si se so wa di alatako ara wa. Ma je ka fi owo ara wa se ara wa paapaa, ma je ki oro wa ti baje koja atunse ko too ye wa. Amin.

Bi mo ti se fee soro to, n oo tun senupo die. Bi mo ti se fee binu to, n ko ni i binu bee, nitori ki n ma fun awon abuni loro so. Loooto, mo mo pe gbogbo wa ko ni i sun ka kori si ibi kan naa, bee ni ironu wa ko ni i je eyo kan gege bii iran, sugbon awon oro kan wa to ye ko maa dun wa bakan naa, awon ohun kan wa to ye ko maa ye wa bi a ba se n so o, paapaa oro to ba le ko iran Yoruba si iyonu lojo iwaju, ti yoo si maa fa wa seyin ninu ajose orile-ede wa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Sugbon Iro Gidi Niyen O: Enu Won Wo Wowo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluseye Iyiade

Sugbon Iro Gidi Niyen O: Enu Won Wo Wowo

Enu awon oloselu dun, ko si si ohun ti won ko le se lati ba ara awon je, ati lati ba tara won paapaa je. Won yoo puro, won yoo soro didun, won yoo si maa fi gbogbo awon nnkan wonyi tan araalu je ni. El-Rufai yii naa tun ni o, gomina Kaduna.

Ariwo to pa nijerin ni pe inu oun dun si kinni kan, nje kin ni? O ni owo ti Buhari na ti won fi sayeye ayajo odun ominira to koja yii je milionu lona aadorin pere, iyen seminti milionu.

Sugbon El-Rufai fi kun un pe nigba aye Jonathan, oun ko fi milionu sise re, bilionu ni i fi i sayeye, o ni apapo bilionu to si lo je ogojo bilionu, nitori awon kan n nawo lo ni. Eleyii ki i se bee, oro awon oloselu lasan ni. Ohun ti i ba dara ni ki Rufai ko awon eri ati iwe owo ti won na naa kale, nidii eyi leeyan yoo ti mo pe ododo ni okunrin oloselu to koriira Jonathan naa n so.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Asegbe Kan Ko Si Nile Yii Mo: Oro Buhari Ati Diezani Allison-Madueke
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Asegbe Kan Ko Si Nile Yii Mo: Oro Buhari Ati Diezani Allison-Madueke

Bi ijoba Buhari ko tile ti i bere ise won loju mejeeji, awon ohun to n sele bayii ti fihan pe nigba ti ise ohun ba bere perewu, nnkan yoo kan nile wa yii naa ni. Okan ninu awon alagbara ana, Diezani Allison-Madueke, lowo awon olopaa ilu oyinbo ti to yen.

O ti farapamo sodo won lohun-un to fee maa gbadun awon owo to ti ri lasiko to fi n ba won sejoba nibi, se bi gbogbo won ti n se tele niyi, nigba ti won ba ko owo mi nibi tan, tabi ti won ba fi ijoba ba aye awon mekunnu ilu je tan, won yoo yaa ta koso seyin odi, won yoo sa lo bamubamu.

Buhari to gbajoba yii ti soro kan, bee ni opo awon alase orile-ede agbaye to mo ohun to n sele ni Naijiria naa ti so bee ri, ohun ti won wi ni pe awon owo ti won n ji ni Naijiria, bi awon ti won n sejoba ba ti le ri ona di awon iho ti won fi n ji owo yii ko, ko le pe ko le jinna ti Naijiria yoo fi di ilu nla ati ilu ti ko ni i see fowo ro seyin nibi kan.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Lojo Ti Won Sinku Kunle Adepeju, Omo Yunifasiti Ti Won Yinbon Pa N'Ibadan,
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Lojo Ti Won Sinku Kunle Adepeju, Omo Yunifasiti Ti Won Yinbon Pa N'Ibadan, Awon Olopaa Tilekun Mori, Won Ko Le Jade

Loooto, ijoba Yakubu Gowon lawon omo Yunifasiti gbogbo n fee ba fa wahala, sugbon
Adeyinka Adebayo ti i se gomina ni Western State' ni wahala naa wo lorun julo, nitori ni
Yunifasiti Ibadan, ni olu ilu ijoba re gan-an ni daru-dapo naa ti koko seyo. Nitori bee, oun
naa lo kede, to si so fun gbogbo eeyan pe iwadii ti ijoba apapo fee se yii, iyen lori ohun to fa
a tawon olopaa fi yinbon pa akekoo yunifasiti ninu ogba won, gbangba lawon yoo ti se e,
awon ko si ni i fi igba kan bo okan ninu, gbogbo eni ti oro ba soju re, tabi ti inu ba n bi nitori
idi kan tabi omiiran, gbogbo won ni yoo letoo lati wa si gbangba lati waa so tenu won. Se ki
i se Adebayo nikan lo n soro naa, ijoba apapo labe Gowon ti so pe ko si ohun ti awon fee
gbo ju ohun to fa idi oro naa ati bi oro naa kuku se le to bee, ki awon le mo awon to wa nidii
e gan-an.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Se won ro pe won yoo wole ni, abi ewo ni ija: Ajimobi, ma ma ba won ja...
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Se won ro pe won yoo wole ni, abi ewo ni ija: Ajimobi, ma ma ba won ja...

Awon oloselu, won ki i gba, bi won gba won lesee nimu, ti won se won nigbo ti gbogbo agbari won n seje suuru, won yoo si tun maa lewo ese ni, won yoo so pe awon yoo ja titi ti iku yoo fi mu awon lo ni, sakara lasan ni. Ariwo ti awon PDP Ogun n pa ko ye enikan, ati ipade a-a-ni-i-gba tawon ati SDP n se. Ohun to n yaayan lenu ni bi won se ro pe awon yoo se bee yen mu Amosun mole, ti awon yoo si gba ijoba lowo re, nigba ti awon eeyan ti won po n so pe ijoba re te awon lorun. Ohun ti awon eeyan ko mo ni pe nigba ti awon araalu ba wo eyin oloselu kan wo, awon ti won ba ri leyin re nigba mi-in a maa je ki won dibo fun iru eni bee tabi ki won ma dibo fun un. Oro Gbenga Daniel ko ti i tan ni okan opolopo awon eeyan, bee ni won ko ti i ri aburu ti Amosun se ti won yoo fi so pe awon ko fe e mo, bee egbe PDP ko ni awon asaaju mi-in ju awon ti oruko won ko fi bee dara niwaju awon araalu yii lo, nitori bee, yoo soro fun won lati wole. Ohun ti iba tun mu ki Gboyega Isiaka ribi ba wo o ni ti pe omo Yewa loun, omo Yewa ko si ti i se gomina ri, o ye ki awon ara Yewa fi eyi dibo fun un. 


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Nile Yoruba, ko gbodo sogun, ko gbodo sija o
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nile Yoruba, ko gbodo sogun, ko gbodo sija o

Olorun Oba mo bo se maa n se oro awa omo Naijiria, nitori e lo se je ni gbogbo ibi ti a ba wa, afi ka ki ara wa ku oriire pelu ibo ta a di koja yii. Awon ara Amerika kan ni won ti koko so o ni odun mewaa seyin, won ni bo ba di odun yii geere ni Naijiria yoo pin si wewe, ti a oo fo si opolopo ona, ti a ko si ni i je orile-ede kan mo. Nigba ti ibo yii si ku bii ojo die, opolopo awon ariran bere si i so orisiirisii, won ni eje yoo san ni Naijiria, awon mi-in si so pe oku repete la oo maa ri kaakiri. Sugbon boya aawe ati adura to po ni, ibo ti wa, o ti lo, ko si ti i si wahala kan to ju emi enikeni lo. Iyen lo se je pe oro ti n oo so lose yii, ebe ni yoo po fun gbogbo omo Yoruba pe nibi ti oro ibo ti waa de yii o, ko gbodo si ogun, ko gbodo si ija, iwonba ni ki ote si mo laarin ara wa. Gege bi mo ti se maa n so o, oro oselu ko ri bi opo eeyan ti n mu un, bi a ba si ti mu kinni ohun le koko ju, igbeyin re ki i dara fun enikeni.

Ni gbogbo igba ni mo maa n so o fun wa, pe oro oselu ko ri bi awa mekunnu se maa n se e, ohun ti a si se maa n pa ara wa lara niyi. Ipalara to ba ba wa, awa la maa n wa a. Ko dara ki a maa ro pe egbe oselu kan naa ni gbogbo wa yoo se, iyen ni pe bi a ba fee se PDP, ki gbogbo wa se e, bi a ba si fee se APC, ki gbogbo wa rori sibe leekan. Iyen ko ni i see se laelae, koda ko je inu ile kan naa, tabi ninu iya kan naa ni gbogbo wa ti jade. A ko le sun ka kori si ibi kan naa, ironu wa ko si ni i sokan lae. Bi eeyan naa ba si wo ibo to lo yii, ati bi awon eeyan ti di i to, e oo ri ohun ti mo n so. E wo Ekiti, awon omo PDP ti won dibo nibe ju awon omo APC lo. E wo Ondo, e wo iye awon omo PDP ti won dibo nibe, e wo Osun naa, ki e si wo Oyo ati Eko gan-an alara. Awon ogunlogo eeyan ti won dibo fun PDP yii, won ki i se iran mi-in, Yoruba naa ni won, o kan je pe egbe to wu won ni won se yii ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Asiko ree fun Buruji Kasamu lati de Amerika ki won: Omo egbe PDP gbe Kashamu lo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Asiko ree fun Buruji Kasamu lati de Amerika ki won: Omo egbe PDP gbe Kashamu lo sile-ejo l'Ogun, o ni ko niwee-eri

Gbogbo awon ti won gbe enu won ni igbekugbee, ti won n so pe Buruji Kasamu ko ni i fese ara re te Amerika laelae, asiko ree fun Kasamu lati jewo fun won pe ore loun ati Obama, ko si si ohun to sele ti oun ko le de ile ore oun ki i. Okunrin naa ti di okan ninu awon omo ile igbimo asofin bayii, bee ni ki i se ile igbimo asofin kekere ni, ile igbimo asofin agba, o si daju pe bi eeyan ba de ibi ti Olusegun Obasanjo ba wa bayii, ara baba naa yoo maa gbona ti oju re yoo ma pon kankan ni, abi sebi nitori eni ti baba se so pe oun ko le se egbe PDP mo ree, pe oun ko le je ki omo kan ti won n wa l'Amerika koba oun. Omo ti won n wa l'Amerika naa lo ti di Seneto yii o, kin ni baba yoo waa se. Oloun kuku si se e, baba paapaa ti rin siwaju, ohun ti ko sele ri lo sele lojo idibo, gbogbo ibo ti won di lodo Obasanjo, APC lo ni in, Buhari ni baba ba lo. Eeyan ti Baba wole laduugbo baba, Kasamu naa si wole laduugbo tire, ko sija kan mo niyen. Sugbon bo ba se pe Kasamu yoo yanju oro yii, ti gbogbo ohun to n run nile yoo si tan yanga, ti oniyeye gbogbo yoo si tenu yeye bapo, ki okunrin naa yaa tete ra tikeeti bayii bayii, ko sare lo si Amerika paa, bi ko ba ba Obama nile, ko de odo awon asofin egbe re, ko sa kan so poun waa woran bi won ti n sofin won nitori asofin Naijiria tuntun loun. Bo ba ti le se bee, ati Obasanjo o, ati gbogbo awon ti won n bu u o, kaluku yoo sinmi iregbe ni. Buruji Kasamu, Seneto tuntun fun Naijiria, asiko ree lati de Amerika ki won!

Omo egbe PDP gbe Kashamu lo sile-ejo l'Ogun, o ni ko niwee-eri Johnson Akinpelu, Abeokuta Oro ti n beyin yo fun oludije ipo seneto labe egbe oselu PDP ni ekun Ila-Oorun Ogun (Ijebu), Omooba Buruji Kashamu, nigba ti okan ninu awon omo egbe naa to n gbe ni Ago- Iwoye, Mogaji Dele Ajayi, gbe e lo sile-ejo giga ijoba apapo to wa niluu Abeokuta, nibi ti won ti ni ki okunrin naa ko iwe-eri awon ileewe to lo sita.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Se dandan ni ki Obanikoro tun se minisita ni ! E ma puro tan araalu je mo, ko da
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Se dandan ni ki Obanikoro tun se minisita ni ! E ma puro tan araalu je mo, ko daa o


Oro awon oloselu yii ki i ye enikan, ko si ohun ti won ko le se bi won ba ti ha tan pata. Abi e ko ri Jonathan ti ko ri elomiran mu ni gbogbo Eko ju Musiliu Obanikoro to ti se minisita to ti se seneto lo. Iru iwa ibaje ati iwa ailero wo niyi jare. Eeyan n se minisita lowo, o fi ipo re sile, o ni oun ko se mo, oun fee loo du ipo gomina nipinle oun. Sebi o te e lorun ni, tete kuku loro ile aye, bo ba wole, deede, bi ko ba si wole, ko maa wa nnkan mi-in se. Sugbon okunrin yii lo lati du ipo naa, ko wole, kaka ki Jonathan si je ko maa lo, won ni ko tun maa bo waa se minisita. Iyen ni pe nigba ti Obanikoro fi n se minisita re, o kuku se awon ise agbayanu kan to fi je pe bi iru re ko ba si ninu ijoba, Naijiria yoo daru pata ni. Bo ba je pe Obanikoro se ise nla kan gege bii minisita ni Jonathan se da a pada, awa araalu ko mo, a ko gbo nnkan kan, ko ye wa paapaa. Sugbon awon ti won gbon modi oro, nitori alakatanpo lo se bi obo ko gbon, obo si logbon lori, tinu obo lobo n se ni. Ki i se pe Jonathan feran awon ara Eko, ki i se pe o feran Obanikoro, ko si nigbagbo pe Obanikoro ni ise ribiribi kan ti yoo se fun aabo oun, sugbon ko fe ki okunrin naa da ibo to n bo yii ru, iyen lo se fi ipo minisita tu u loju.


Nibi ti won ba ti wa n se iru iyen, ti won n fi ipo gidi tu oloselu loju, boya o mose tabi ko mose, boya o wulo tabi ko wulo, iru ijoba bee ki i se aseyori, lara ohun to si ko ifaseyin ati aseeri ba ijoba ti Jonathan n se niyen. Abiru kin ni gbogbo eleyii, bawo lawon eeyan wonyi kuku se ya alaimokan bii eyi. O ma se o, o tan lara omo to n je eeru!(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Ni Jonathan ba di metalokan Alaaji Pasito Oluwo Nitori atiwole: Iyen lo je ki Bu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ni Jonathan ba di metalokan Alaaji Pasito Oluwo Nitori atiwole: Iyen lo je ki Buhari sare wale

Ti Jonathan ba mo wipe gbogbo asarekir oun lasiko ibo pabo ni yio jasi bo ya ki ba ti kuku gba kamu. Sugbon eni ti yio kuku sofo owo ati ti ibo bi won ba ka egberun Psam fun un ko kuku ni je.  Beeyan ba n wo orisiirisii foto Aare Jonahan to n jade lojoojumo, oluware yoo mo pe okunrin naa ti di ohun tawon eeyan n pe ni metalokan. Ki i se metalokan tawon onikristeni o, metalokan tawon abalaye ni, beeyan si pe e ni Alaaji Pasito Oluwo, oluware ko jayopa.

Oun nikan le o ri ti yoo maa kunle niwaju Baba Adeboye, bo si kuro nibe yoo kunle lodo Oyedepo, tabi ko je oun ati Oritsajefor ni won yoo jo maa fa ara won lowo kaakiri. Bi eeyan ba wa n wo awon foto naa to n so lokan ara re pe ara meriiri ree, nibi to ti n so naa ni yoo ti tun ri Jonathan laarin awon asaaju Musulumi ti yoo ko saarin awon onilawani ti yoo si maa sadura kikankikan, awon ti won si ri i ni Ileefe lose to koja nibi ti awon oba alaye ti na opa ase bii ogorun-un sori oun nikan mo pe oro to wa nile yii ki i se kekere, gbogbo ona ti Jonathan ba le gba ni yoo gba ko le wole ibo won. Jonathan nikan naa ni ni soosi, oun nikan naa ni ni mosalasi, oun naa tun ni lodo awon elesin-kan-abalaye, se nitori oro ibo yii naa ni!

Ohun ti a n wi niyen pe eletan lawon oloselu, ko si iyato kan bayii laarin won. Se awon oba sese wa niluu ni abi awon onisoosi ni won sese wa nibe, abi won sese da mosalasi sile ni!


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Se loooto ni, ko gbodo je bee: Jonathan ha owo nla fun awon pasito
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Se loooto ni, ko gbodo je bee: Jonathan ha owo nla fun awon pasito


Lasiko idibo ti o koja yi aare orile ede wa tele ri ti o okogba wole se gbogbo akitiyan lati se owo ilu balublu nitori ati wole, iroyin to n lo nigboro nigba yii ko daa rara o. Eeyan iba fi eti ko oro naa danu, tabi pe ki eeyan tile se bii eni pe oro ti ko wulo ni, iyen bi ki i baa se pe awon ti won n soro naa ki i se egbe alatako nikan. Loooto gomina ipinle Rivers, Rotimi Amaechi, lo koko so o jade, sugbon oro naa ko ti enu awon APC nikan jade, oro to kan awon olori soosi ni, odo won naa lo si ti n jade julo. Pasito Kallamu Musa Dikwa lo fesun kan gbogbo awon oga re, iyen awon olori egbe Omoleyin Kristi lapapo, egbe ti won n pe ni CAN, o ni won gba bilionu meje owo naira lowo awon Jonathan ki won le lo o lati je ki gbogbo Kristeni dibo fun won. (Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Nigba wo ni Obasanjo yoo fi oju ogun sile fawon omode
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin OlootuNigba wo ni Obasanjo yoo fi oju ogun sile fawon omodeE je ka foro sile soro o, nitori bi a ba sorosoro, ka ma gbagbe eni a de lokun, enikeni ti a ba de lokun ko ni i kuro ninu inira. Bee irorun igi ni irorun eye o, bi adie ba ba lokun, ara ko le ro okun, ara ko le ro adie. Bi a ko ba yanju oro idibo to wa lona yii, ara ko le ro enikeni, afi ka yanju re, ki Olorun si ba wa gbe e ka ibi to dara, ibi ti yoo ti ro wa lorun, ti a oo si le je gbogbo anfaani to ye ka je. Mo ri awon atejise yin, mo si mo pe ohun ti yoo wa lokan yin bayii ni eni ti emi funra mi yoo dibo fun, niwon igba to ti di dandan fun mi lati dibo, nitori bi enikeni ba n pariwo pe oun fe ilosiwaju fun Naijiria, ko si ohun meji to le fi fi eyi han lasiko ta a wa yii ju ki tohun dibo lo. Eniyan kan ko le so pe egbe kan ko dara, tabi ko ni awon oloselu ko sunwon, ko waa tori e so pe oun ko ni i dibo feni kan, tohun ko tun nnkan se, o n ba nnkan je si i ni.

Se e ri i, asiko ta a wa yii, asiko to le gan-an fun wa ni Naijiria ni, eni ti ko ba si mo bi oro ti je ko ni i mo bo ti lewu to. Nibi ti Naijiria ti ba oro ara re de, ko ye ki a tun wa ninu isoro ti a wa yii, nitori pe a ti ni awon agbalagba to ye ki won to wa sona, ko ye ka le sina rara, bo ba se pe ohun gbogbo lo bo se ye ko lo. Sugbon ohun gbogbo ko lo bo se ye ko lo, kaka ko lo deede, o tubo n daru si i ni. Lose to koja yii, Egbon Segun (Obasanjo) se ohun to ya mi lenu, koda bi mo se so pe mo rile mo rode to yii, oro naa jo mi loju, o ya mi lenu koja afenuso. Pe Obasanjo lo si gbangba, o mu kaadi egbe oselu re, iyen PDP, o mu un fun alaga egbe re laduugbo won, o ni ki iyen ya a perepere bii aso loju awon onitelifisan, awon oniredio, ati awon oniwee iroyin gbogbo. O ya mi lenu.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Nibi tawon oga soja Ibo ti n muti lawon soja Hausa ti gbebon fun won l'Abeo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nibi tawon oga soja Ibo ti n muti lawon soja Hausa ti gbebon fun won l'Abeokuta, won pa won bii ejo aije

Se aago mejila ni Ogagun-Agba, Aguiyi Ironsi, olori ijoba Naijiria ninu osu keje, odun 1966, gbera kuro ninu yara alejo toun ati Ogagun Francis Adekunle Fajuyi ti i se gomina Western Region igba naa ti n sepade, to kede fun gbogbo awon oga soja to ku nibe pe oun n loo sun ni toun. Aago mejila loru ni, ohun gbogbo ti pa kanrin kese nile ijoba niluu Ibadan, osupa to n ran nigba naa paapaa ko ti i di aranmoju, bee ni ina ijoba ko ti i di yebeyebe, nitori bee, ayika ile ijoba yii paapaa sookun, awon igi ti won si gbin saarin ogba naa je ki ibi gbogbo dudu birimu-birimu, ohun gbogbo dudu kiriji. Lati kutukutu owuro ni Ironsi ti n lo to n bo, o ti ba awon oba nla nla to wa lati ibi gbogbo ni Naijiria soro, bee lo ti lo sileewe Mayflower, nibi ti Tai Solarin ti gba a lelejo, leyin naa ni oun ati Adekunle Fajuyi tun ro gbogbo ejo won.

Eyin ti won ti rojo tan yii ni Ironsi dide, o ti re ara loooto, eru ilu soro o ru, lati aaro titi tile fi su, olori ilu ki i ni isinmi, eni to ru eru ilu, eru agba lo ru, tijoba Ironsi yii tile tun lekenka, ijoba ti ko rese mule ni, ijoba ti okan awon to n se e ko bale, eyi gan-an lo si je ki oro Ironsi olori ijoba ohun mu wahala gidi dani. Awewu-sun ko ti i dopin ise, afapoti-rori kan ko gbadun oorun; ohun ti a ko si mo la o mo o, eni to n singba kan ko lowo lowo, nnkan ko rogbo fun ijoba Ironsi.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Sebi e gbo ti ariwo awon ti won so pe won ri soja nile Tinubu: Olorun ni yoo gba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Sebi e gbo ti ariwo awon ti won so pe won ri soja nile Tinubu: Olorun ni yoo gba Jega

Bi eniyaan ba n tele ariwo awon oloselu, tohun-un yoo siwa-hu, bi eeyan si n tele opo ohun to ba ka ninu awon iwe iroyin, tabi lori awon ero ayelujara, oluware yoo maa wo inu igbo lo ni. Gbogbo awon nnkan wonyi lawon oloselu ti baje, won ko si fe ki enikeni mo nipa ododo ohun to n lo.

Lose to koja ni ariwo gbale, ariwo gba oko, iroyin naa si kaakiri agbaye, won ni awon ogunlogo soja ni won ri nile Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, okan ninu awon olori egbe APC. Awon iwe iroyin nla nla to je awon ti egbe APC n lo lo fo kinni naa loju, won fi iroyin naa se akole gadagba, won si gbe e jade pe awon soja ti ya bo ile Tinubu o, won fee pa Tinubu ni, won fee ji i gbe ni ati bee bee lo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: