Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
EsinIslam Media: Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Won Ni Akeem Pa Sajenti Opeyemi Iyawo Re, O Ti N Se Faaji Lewon Bayi
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Won Ni Akeem Pa Sajenti Opeyemi Iyawo Re, O Ti N Se Faaji Lewon Bayi

Medinat Adesoye, Osogbo

Adajo kootu kan nilu Osogbo ti pase pe ki won lo fi Abiodun Akeem Oladebo pamo sogba ewon titi ti imoran yoo fi wa lati ileese eto idajo ipinle Osun lori esun ti won fi kan an.

Se lawon olopa so pe Akeem, omo odun mokanlelogoji lo pa iyawo re, Sajenti Opeyemi Ojo lojo keedogbon osu keji odun yii.

Inspekito Tajudeen Mustapha so funle ejo pe se ni Akeem so ori obinrin olopa yi mo ogiri, eleyi to yori si iku ojiji to ku. O ni iwa naa nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun.

Mrs B Y. Dada to duro fun olujejo ro ile ejo lati je koun gba beeli re sugbon Onidajo Ajanaku ni rara, afi ki won lo fi pamo sogba ewon.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Eyi Ni Bi Pasito Se Gbe Majele Je Ni Ipinle-Ogun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Eyi Ni Bi Pasito Se Gbe Majele Je Ni Ipinle-Ogun

Bosun Olaniyi, Abeokuta Gbogbo adugbo Atala to wa niluu Mowe lo fee le daru lojo Fraide ose to koja yi nigba ti won ni Pasito kan to gbajumo daadaa lagbegbe naa, iyen Tunde gbe majele je, to si gbabe soda sorun alakeji.

A gbo pe awon kan ni won lu Tunde ti won ni okan lara awon pasito soosi Deeper Life ni jibiti owo ti ko din legberun lona egbeta (600,000) naira, to si je pe itiju gbese naa lo muu pinu lati gbemi ara re lojiji.

Iroyin to te Iwe Iroyin Yoruba lowo fi ye wa pe ajo ni Tunde n gba kaakiri leyin to padanu ise e lodun bii meji seyin, to si je pe ko seni ti mo ni gbogbo ibi to n gba ajo naa de.

Ohun to ti e n se opo eeyan ni kayeefi ni pe Tunde ti ran iyawo e jade lojo naa, sugbon nigba tiyawo naa maa fi pada wole, oko e lo ba nile nibi to ti n japoro, eyi lo muu sare pe awon ara adugbo lati ran an lowo gbe e lo si osibitu kan to wa nitosi won.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo

Lojoru Weside to koja yi ni ese ko gbero nile ejo giga kan to fikale sagbegbe Ikoyi niluu Ekoo lati wo oju baba agba kan to je Purofeso ni fasiti Obafemi Awolowo to wa n'Ile-Ife, eni ti won loo lu jibiti owo oni aimoye milionu naira.

A gbo pe ajo kan ti Purofeso naa, Charles Jide-Oni da sile, eyi ti won lo fi n gba owo lona aito lowo awon onibaara re ki asiri re too pada tu.

Lara awon ti Charles lu ni jibiti la gbo pe won gbe ejo re lo siwaju awon ajo EFCC, ko too di pe awon yen bere ise iwadii won, ti won si ri i pe loooto ni, paapaa nigba ti won tun ni ko le dahun awon ibeere kookan ti won n bii.

Yato si Jide-Oni, a gbo pe awon ajo EFCC naa tun foju awon min in naa bale ejo latari esun jibiti ti won fi kan won niwaju Onidajo Nicholas Oweibo tile ejo ekun ile Yoruba.

Awon min in ti won tun foju won bale ejo naa peluu ni; Olaleye Kolapo, Madukife Ifeanyi Azuka, Fatanmi Yinka Sunday, Adebayo Bolaji Adeyinka, Adeleke Peter ati Adebowale Fadairo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita

Gbajugbaja oshere tiata nni, Oloye Binta Ayo Mogaji Oduneye, topo awon eeyan mo si Igbanladogi ti ju bombu oro sita, o ni alashewo lo po ju ninu awon oshere tiata lorile-ede Naijiria, eyi to je ki won maa wo asho iwokuwo lori itage.

O ni bi ki i ba a she pe alashewo pombele ni won ni, ko ye ki obinrin to ba ni oko gidi nile, to bimo, to si ni ebi rere de idi ishe tiata, ko wa lo maa shi ara re sile tabi she afihan ihooho re bi Olorun she daa sita.

Ayo Mogaji soro naa lasiko to n kopa lori eto ileeshe telifisan kan ni Naijiria laipe yi, to si tu peere-peere oro nibe.

Binta Mogaji ni imura eeyan kan nigboro ni nkan she peluu idile to ti jade wa ati iwa omoluabi to ni, ti yoo si mu ko le ronu jinle pe iru oju wo ni aye fi n wo oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma Se O, Obirin Ja Ibale Omodun Mejo L'ondo

Gbogbo ilu Makurdi, nipinle Benue lo fee le daru laaro oni nigba ti won ba oku omoge arewa kan ta a ko tii mo oruko re dasiko ti a shakojopo iroyin yi tan ninu igbo kan to wa niwaju shooshi ti won pe ni Grace Tower.

Ohun ta a gbo ni pe awon gendekunrin kan ni won fipa wo odomobinrin naa, ti won si ko ibasun fun leyo-kookan, titi to fi jade laye.

Iwe Irohin Yoruba gbo pe she ni won ja omobinrin naa sihoho omolaubi, ti won si fi asho dii lenu pa, ki won too bere sii fi kinni abe won dana si omoge arewa naa labe.

Igba ti won ni agbara omobinrin yi ko fee gbe mo, leyin to ti bebe titi, sugbon ti won ko da a lohun, la gbo pe o gba ekuru je lowo ebora.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran

Gbogbo eto la gbo pe o ti to bayii fun egbe alaabo So Safe Corps nipinle Ogun, eyi ti Ogbeni Olusoji Ganzallo je Komanda won lati wo iya ija peluu awon odaran kaakiri ipinle naa, paapaa bi won tun she towo bowe adehun peluu awon ileeshe eleto aabo yooku kaakiri.

Fawon to ba mo bi nnkan she n lo, won a mo daju pe bi awon asiko ayeye gbogboogbo bayii ba ti n waye lawon odaran bii omo egbe okunkun, adigunjale maa n gbero lati shoshe won, eyi ti won loo le da alaafia ilu laamu.

Eyi gan an la gbo pe o mu egbe alaabo So Safe Corps pinu lati shishe papo peluu awon ileeshe eleto aabo yooku kaakiri ipinle Ogun, ki eto aabo le tubo kesejare lasiko ati leyin odun Ileya.

Gege bi agbenuso fun egbe naa, Ogbeni Moruf Yusuf she shalaye fun wa, o so pe bo tile je pe awon ko sheshe maa towo bowe adehun pelu awon ileeshe eleto aabo, sugbon, eyi tawon tuntun sheshe she yii yato patapata sawon eyi tawon ti n she tele, nitori pe ishe won ti yato si tigba tawon shi n je Fijilante.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibadan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibada

Die lo ku ki ori ko lagbaja yo, Oloun ko ni oluware i yo ninu ewu ni. Patapata ni ori ko omodebinrin eni odun metadinlogun kan, Adegoke Bukola, yo lowo iku ojiji leyin to ti ko sowo awon agbenisowo ti won si ti fun un loogun je.

Bukola, eni ti a fi ojulowo oruko e bo lasiiri lo ko si pampe ife etan lojo Aiku, Sannde, ojo ketadinlogbon, osu keta, odun yii, pelu bo se tele orekunrin re to n je Onuigbo Chibuike atawon ore e jade loo se faaji laimo pe ero iku lawon omokunrin naa n ro si i.

Gege bi oga-agba awon olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade se so fawon oniroyin n'Ibadan lojo Eti, Fraide, to koja, lojo odun Ajinde awon Kristeni to koja yii ni Bukola loo pade orekunrin e laduugbo Iwo Road, n'Ibadan, lasiko to ye ko wa pelu iya e ni soosi fun poposinsin odun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Nitori Wahala Ojoojumo, Igbeyawo Odun Mefa Tuka L'Osogbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Wahala Ojoojumo, Igbeyawo Odun Mefa Tuka L'Osogbo

Kootu ibile keji niluu Osogbo ti tu igbeyawo olodun mefa ka laarin Ogbeni Rasheed Olalekan atiyawo re, Mutiat Olalekan, lori esun wahala ojoojumo.

Ogbeni Rasheed lo mu ejo iyawo re lo sile-ejo, o ni onijagidijagan ati oniwahala niyawo oun to je onisowo, ati pe oun ko le farada wahala re mo lo je koun fee jawee fun un.

O ni, ''Wahala re ti po ju, ki i gbo ibawi rara, ko fi mi lokan bale ninu ile. Mo ti koko figba kan fi olopaa mu un, sugbon awon yen so pe tori pe o n gbe omo kekere lowo, ki n se suuru.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Won Ti Ran Oga Ileewe To Fipa Ba Akekoo Re Lo Po Lewon Odun Mewaa L'Ekiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Won Ti Ran Oga Ileewe To Fipa Ba Akekoo Re Lo Po Lewon Odun Mewaa L'Ekiti

Oludasile ileewe aladaani kan, Ogbeni Babatunde Ibitoye nile-ejo giga kan to wa niluu Ado-Ekiti pase ewon odun mewaa fun nitori esun fifi ipa ba akekoo ileewe re kan to je omo odun mewaa lo po niluu Ado-Ekiti.

Ibitoye to nileewe alakoobere God's Grace Nursery and Primary School to wa lagbegbe Agric Olope, ni Ajilosun, niluu Ado-Ekiti, lowo te lojo kewaa, osu kefa, odun 2013, lasiko to n ki omodebinrin ohun mole ninu oja ohun.

Gege bi idajo Adajo Toyin Abodunde, eri ti olupejo je fi lele pe lai si tabi-sugbon kan nibe, olujejo fipa ba akekoo naa lo po.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Tessy Loyun L'Ondo, Lo Ba Loo Ta Omo To Bi Si Onitsha
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Tessy Loyun L'Ondo, Lo Ba Loo Ta Omo To Bi Si Onitsha

Owo ileese olopaa ipinle Ondo ti te toko-taya kan, Ogbeni ati Abileko Sunday Kalu, lori esun pe won ra omo tuntun jojolo lowo obinrin eni odun metadinlogun kan toruko re ni Tessy Obianua.

Awon meji mi-in ti won tun fesun kan pe won sonigbowo bi Tessy se gbomo bibi inu re ta fun toko-taya naa ni Abileko Chibuzor Okoye ati Ogbeni Jude Azuka, ti gbogbo won si jo n ka boroboro lolu ileese olopaa to fikale si Igbatoro, niluu Akure.

Gege bi ohun ta a gbo lori isele to waye niluu Ogbese, nitosi Owo, nijoba ibile Owo, nipinle Ondo ohun, okunrin kan toruko re n je Sola ni won lo fun Tessy loyun lodun 2014, sugbon dipo ki Tessy gboyun feni to ni in, Jude to je alabaagbe awon obi re niluu Ogbese lo sa loo ba niluu Onitsha, ninu osu kin-in-ni, odun to koja.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Iya Omo Osu Merin Fee Ko Oko n'Ibadan, O Ni Baba Ikoko Maa n Fipa Ba Oun La
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Iya Omo Osu Merin Fee Ko Oko n'Ibadan, O Ni Baba Ikoko Maa n Fipa Ba Oun Lasepo

Bo tile je pe igbeyawo ohun ko ti i to odun kan, ti omo ti won bi si je omo osu merin pere, awon toko-taya kan, Opeyemi Adebayo ati Matthew Adebayo ti ro kootu ibile Ile Tuntun, to wa laduugbo Mapo, n'Ibadan, lati fopin si ibasepo awon gege bii toko-taya.

Ejo ohun, eyi ti Opeyemi pe l'Ojobo, Tosde, to koja lati je ki ile-ejo tu igbeyawo oun ati oko e ka ko fere yato si esun odaran nile-ejo giga pelu bi iyawo se so pe nise loko oun maa n fa pata ya mo oun nidii, to si maa fipa ba oun lasepo. Saaju lobinrin yii ti tori esun ifipabanilopo yii ti oko e mole ni tesan olopaa ko too gba kootu lo lati fopin si ibasepo oun pelu Matthew.

Loju Opeyemi, gbogbo iwa odaran ti Matthew n hu yii ki i se ebi e, ifun baba e lo ja je nitori odaju ni pupo ninu won nile won. O ni bi oko oun se maa n fi ebi pa oun lo tun maa n lu oun bii eni lu bara, ati pe baba e paapaa tun buru ju bee lo pelu bi baba naa se fi tipatipa gba omo lowo oun, to si le oun danu nigba ti omo naa si wa lomo osu meta pere.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Pasito Oluso-agutan Femi Olayinka Tijo 'Christ Miracle' Fun Iyawo Omo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Pasito Oluso-agutan Femi Olayinka Tijo 'Christ Miracle' Fun Iyawo Omo Ijo e Loyun N'Ife

Ile-ejo koko-koko to wa niluu Ilesa ni Ogbeni Olusola Onifade gbe iyawo re, Arabinrin Simbiatu, to fesun agbere kan lo, nibi to ti rawo ebe sadajo lati tu igbeyawo odun mewaa to wa laarin won ka.

Nigba to n wi awijare re niwaju adajo, Onifade pe Oluso-agutan Femi Olayinka tijo 'Christ Miracle', Orisun-iye, to fikale sagbegbe Powerline Ajebandele, niluu Ile-Ife, ti fun iyawo oun loyun, tobinrin ti ko nitiju ohun ko si fi bo rara.

Okunrin naa ni Simbiatu lo figba kan ro oun pe koun gba idile awon laaye lati maa loo josin ninu ijo naa laimo pe oluso-agutan naa yoo pada fun iyawo oun loyun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Blessing Gun Orekunrin Re Pa Ni Lekki
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Blessing Gun Orekunrin Re Pa Ni Lekki

Boya ka ni Blessing Edet to je omo odun merinlelogun mo pe ile orekunrin re, Edet Ebong, to je eni odun metalelogun toun fee loo sun lojo naa yoo ko ibanuje ayeraye ba oun atawon ebi oun ni, o see se ko ma lo sile orekunrin re to pada seku pa, eyi to mu un dewaju adajo nile-ejo majisireeti to wa l'Ebute-Meta, niluu Eko.

Gege bi agbenuso ijoba, Sajenti Maria Dauda, se salaye, oru ojo kejidinlogun, osu kejo, odun to koja, nisele ohun waye lojule kin-in-ni, laduugbo Falana, lagbegbe Ogombo, ni Lekki, niluu Eko. Wahala kan lo sele laarin awon olulufe mejeeji yii. Koloju si too se e, Blessing ti gun orekunrin re lobe idana nikun.

Gbogbo akitiyan re atawon araale lati doola emi Edet lo ja si pabo pelu bo se jepe orun. Kia lawon eeyan ti fa olujejo le olopaa lowo, leyin iwadii ni won taari e lo sile-ejo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Olopaa Lu Wolii Ijo Sele Bukky Victor Alonge Daku l'Akure, Won Lo Lu Funke
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluseye Iyiade, Akure

Olopaa Lu Wolii Ijo Sele Bukky Victor Alonge Daku l'Akure, Won Lo Lu Funke Ni Jibiti

Bii eni lu bara la gbo pe olopaa kan ti won lo n sise leka ileese olopaa to n gbogun ti ijinigbe nipinle Ondo lu baba wolii kan lori esun pe o lu omobinrin kan ni jibiti ile to ta fun un.

Oro ile lasan la gbo pe o fa wahala laarin omobinrin kan ti won pe oruko re ni Alonge Grace Funke to n gbe niluu Akure ati Wolii Bukky Victor Alonge, agba wolii ninu ijo Sele kan niluu Akure.

Gege bi alaye ti Wolii Bukky se fun wa nigba ta a sabewo si i nileewosan Jojein to wa l'Oke-Ijebu, l'Akure, o ni latodun 2013 loun ti ta ile fun Funke, toun si fun un niwee pe loooto lo ti sanwo ile to ra lowo oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Awon Omo Egbe Okunkun Yinbon Pa Baba Tee N'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Awon Omo Egbe Okunkun Yinbon Pa Baba Tee N'Ilorin

Se ni awon omo egbe okunkun gbina je niluu Ilorin l'Ojoru, Wesde, ose to koja lohun-un, ti won si seku pa ogbeni kan toruko re n je Taiye Moses Adewoye si opopona Emir's Road.

Akoroyin wa ri i gbo pe se ni awon omo egbe okunkun naa fi Taye ti opo eeyan tun mo si Baba Tee pe okan lara awon omo egbe okunkun igun miiran, ti won si seku pa a.

ASP Ajayi Okasanmi to je alukoro ileese olopaa ipinle Kwara fidi isele yii mule fun akoroyin wa. O salaye pe eeyan merin ni owo awon ti te lori isele yii, pelu alaye pe orun ni awon obayeje yii ti yinbon fun Baba Tee.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

O Do Ju e! Oogun Oloro Yi Omo Lori, Lo Ba Ti Baba e Pa Ni Abeokuta
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

O Do Ju e! Oogun Oloro Yi Omo Lori, Lo Ba Ti Baba e Pa Ni Abeokuta

Oro di bo o lo o yago fawon oniroyin l'Ojoru, Wesde, ose to koja nigba tawon ebi okunrin kan ti won n pe Baba Basira dide ogun pe won ko gbodo gbe iroyin omokunrin kan to ti baba e subu, tiyen si gbabe ku.

Lojo Isegun, Tusde, niwadii fi ye wa pe omo baba naa ti won so pe oogun oloro yi lori seku pa a lojule keeedogbon, adugbo Akintobi Badejo, Sabo, niluu Abeokuta.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, oro ti ko toro lo waye laarin baba atomo tinu fi bi omo yii, abi ka ni oogun oloro lo yi i lori, o si ti baba e subu, niyen ba daku, osibitu ni dokita ti fidi e mule pe o ti ku.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Owo Te Daniel To N Lu Awon Eeyan Ni Jibiti Lori Facebook
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluseye Iyiade, Akure

Owo Te Daniel To N Lu Awon Eeyan Ni Jibiti Lori Facebook

Awon Yoruba bo, won ni ojo gbogbo ni tole, ojo kan bayii ni tolohun. Bee gele loro ri fun ogbologboo okunrin onijibiti kan, Daniel Obasi, to je omo bibi ipinle Rivers, towo olopaa te lose to koja pe o kundun ati maa lu awon eeyan ni jibiti lori eka ayelujara ta a mo si Facebook.

Gege bi a se gbo, Daniel to n gbe lojule kin-in-ni, laduugbo Zion, niluu Port Harcourt, nipinle Rivers, lowo olopaa ipinle Ondo te lori esun pe opo awon oloselu nla lo ti lu ni jibiti lori Facebook.

Koda, igbakeji gomina ipinle Ondo, Alaaji Lasisi Oluboyo, la gbo pe oun naa fara gba ninu jibiti ti Daniel lu awon oloselu to ba ti ha si i lowo lori eka ayelujara naa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Mi o Sonu o, Iro Loko Mi n Pa Pe Oun Ko Ri Mi — Bukola
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Mi o Sonu o, Iro Loko Mi n Pa Pe Oun Ko Ri Mi — Bukola

''Bii igba teeyan dogbon soogun dudu si eeyan ni fife ti mo fe oko mi nitori enu ekose ni mo wa to fi ko enu ife si mi, nise ni mo si sa kuro nibe lai duro se firidoomu ti mo fi loo fe e.

Lati igba ti mo si ti fe e naa ni okan mi ko ti bale, eru maa n ba mi ni saa nitori opo igba ni mo maa n ba oogun labe pilo ti mo fi n rori sun.'' Iyawo ile kan, Abileko Adebukola Fatimah Bello, to deede poora loode oko e ni nnkan bii odun kan seyin lo se bayii soro nigba to n salaye idi to fi se bee fi ololufe e sile fakoroyin wa.

Ninu Iwe Iroyin Yoruba to jade ni ogbonjo, osu kefa, odun yii, la ti gbe iroyin ohun pelu akole pe, ''Iyawo ile poora loode oko e n'Ibadan'', ni ibamu pelu gbajare ti oko re, Ogbeni Bello Tajudeen Akinbami, ke wa si ofiisi ileese iweeroyin yii to wa n'Ibadan pe iyawo oun ti ko awon dukia oun sa lo, oun ko si gburoo e mo lati ojo kerinla, osu kewaa, odun 2014, to ti sa kuro nile, iyen nnkan bii osu mejo si asiko naa.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Owo Te Pasito Ati Sorosoro Ori Redio N'Ilorin, Ayederu Risiiti Ni Won Se
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Kayode Omotosho, Ilorin

Owo Te Pasito Ati Sorosoro Ori Redio N'Ilorin, Ayederu Risiiti Ni Won Se

Ileese olopaa ipinle Kwara ti wo awon afurasi odaran meta kan, Oladele Olanipekun (eni odun merindinlogoji) to tun je osise ijoba, Oladipo Oluwatosin (eni odun mokandinlogoji) to je pasito ati Talabi Olaitan, eni to je pe sorosoro ori redio ni lo si kootu majisreeti to wa niluu Ilorin niwaju Adajo A.M Ibrahim, lori esun pe won gbimo-po lati se ayederu risiiti ileeko 'Kwara State College of Education', to wa ni Oro.

Nigba to n rojo tako won ni kootu, olopaa to n soju ijoba, Inspekito Nasir, fi esun kan won pe se ni won huwa to tako ofin ipinle Kwara. Gege bo se salaye, ojo kejila, osu kewaa, odun yii ni Ogbeni Bamigbe Caleb Adesola, eni to je olori eto aabo ni ile-eko naa mu esun to ileese olopaa lo pe lojo kejidinlogbon, osu kesan-an, odun yii, ni Ibitoye Oyeniyi to n gbe laduugbo Ago Iyamu, niluu Oro, to si je akekoojade awon mu ayederu risiiti to ni nomba 12638 wa sileewe pe oun ti san owo to ye koun san, oun fee gba iwe-eri NCE oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Olorun Lo Mu un: Ete Omo Biafra N'ilu Oyinbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Olorun Lo Mu un: Ete Omo Biafra N'ilu Oyinbo

Omo kan wa ni London ti won n pe oruko re ni Kanu, omo Ibo ni, oun lo si so pe oun da egbe kan sile to pe ni egbe awon omo Biafra. Se e ri i, ohun to n fi oruko egbe yii se ni lati fi gba owo lowo awon eeyan, bo si tile je pe awon omo Ibo kan wa nibe ti won n fi gbogbo aye won ja pe awon fe ijoba Biafra tawon, Kanu yii lo jokoo siluu oyinbo toun n fi oruko Biafra jeun. 

Bo se n se ni pe o jokoo siluu oyinbo nibe, o da redio kan ti won n pe ni 'Pirate Radio' sile, iyen redio awon ti ko ni iwe-ase, redio awon arufin. 

Ori redio yii lo ti n so fun gbogbo awon omo Biafra pe awon ni egbe, awon omo egbe awon si ti le ni milionu lona ogun, ki won da owo, ki won le gba ara won kuro lowo ijoba Naijiria. 

Omode ni o, ko legbe oselu o, ko lero leyin o, ki i wale boro o, ko seni to mo on ninu awon agbaagba Ibo o, oun kan n fi oruko won jeun lo ni tire ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Olaniyi Fee Ba Iyawo Egbon e Lasepo N'Ibadan, Niyen Ba Loun Ko Fe Oko Oun M
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Olaniyi Fee Ba Iyawo Egbon e Lasepo N'Ibadan, Niyen Ba Loun Ko Fe Oko Oun Mo

Nitori bi aburo oko se yo kinni ti iyawo egbon e laarin oru, igbeyawo olodun merinla to wa laarin toko-tiyawo kan, Tunde Olaniyi ati Jumoke Olaniyi ti fori sanpon pelu bi iyaale ile naa se fariga to loun ko se mo, o loun ko le maa gbe aarin awon eeyan ti won yoo fi ibalopo ba oun laye je, abi nigba ti egbon ba n ba oun sere loko-laya, ti aburo re naa si tun n gbo oun mole ninu yara kan naa.

Inu yara kan soso ti toko-tiyawo yii n gbe pelu awon omo meta ti won bi naa ni Olaniyi kekere, iyen aburo Tunde to ti le leni ogun odun n gbe lati bii odun kan seyin, to si se bee fa ipinya sinu igbeyawo awon eni eleni.

Jumoke salaye niwaju igbimo oludajo kootu ibile Ojaba to wa laduugbo Mapo, n'Ibadan, pe oun nikan loun sun ori beedi lojo ta a wi yii gege bo se maa n sele leekookan ti okunrin to ti le leni ogun odun naa fi dide legbee awon ti won jo sun nileele, to gun ori beedi to oun wa, to si bere si i fi owo pa oun lara.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Owo Te Wolii Ijo Kerubu To N Feran Eeyan Soogun L'Ogbomoso
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayinka Adedayo

Owo Te Wolii Ijo Kerubu To N Feran Eeyan Soogun L'Ogbomoso

Nigba ti eni to n pe ara e ni wolii Olorun ba n fi eran eeyan egbe e saajo fawon odo agutan, ki waa ni iba maa fi soogun bo ba se pe ise isegun gan-an lo n se? Eyi ni ibeere ti awon eeyan n bi ara won leere ni olu ileese olopaa ipinle Oyo to wa ni Eleyele, n'Ibadan, nigba tawon agbofinro n safihan okunrin wolii kan, Oluwatosin Odetunde, to n fi eran eeyan soogun fawon eeyan pelu omokunrin re kan, Jacob Odetunde, atawon meji mi-in ti won n je Adewole Elijah ati Adeyanju Adeniyi.

Iwe Irohin Yoruba gbo pe funra okan ninu awon afurasi yii pelu afurasi odaran egbe e kan to ti je Olorun nipe bayii ni won pa okunrin kan labule ti won n pe ni Odo-Oba, nitosi ilu Ogbomoso, nipinle Oyo, laipe yii, ti won si kun oku re bii igba ti awon alapata ba ge eran maalu si bure nla nla.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Nitori Ija Gbogbo Igba Pasito, Igbeyawo Odun Meeedogun Fori Sanpon L'Ondo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluseye Iyiade, Akure

Nitori Ija Gbogbo Igba Pasito, Igbeyawo Odun Meeedogun Fori Sanpon L'Ondo

Ile-ejo koko-koko kan to fikale s'Oke-Eda, niluu Akure, ti fopin sigbeyawo olodun meeedogun to wa laarin pasito kan toruko re n je Tunde Adekunle pelu iyawo re, Abileko Agbeke Adekunle, latari esun ija ojoojumo ti eni-owo naa fi kan iyaale ile ohun.

Pasito yii to je oludasile ijo 'Christ Living Church' niluu Owo, nijoba ibile Owo, nipinle Ondo, lo mu esun iyawo re wa pe obinrin naa ki i gboran soun lenu, bee lo lo feran ija ju ka si nnkan lo.

O ni ko sibi tobinrin olomo merin yii ko ti le ja ti kinni ohun ba gun un, koda, o ni Agbeke ti ya aso mo oun lorun ri niwaju gbogbo omo ijo lasiko tawon n se isin lowo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Iya Ayo Ku Lojiji N'Ilesa, Won Ni Ale E Lo Fi Ibasun Pa A
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Iya Ayo Ku Lojiji N'Ilesa, Won Ni Ale E Lo Fi Ibasun Pa A

Tesan olopaa to wa ni Ijamo, n'Ilesa, ni okunrin kan to n sise asegita ti a ko mo oruko re lasiko ti a n ko iroyin yii jo wa lori esun pe o fi tipatipa ba orebinrin re, Iya Ayo, lo po doju iku ni Ojoru, Wesde, ose to koja, lagbegbe Oke-Eso, nijoba ibile Iwo-Oorun Ilesa.

Iwadii Iwe Irohin Yoruba lagbegbe Oke-Eso, nibi ti obinrin oloogbe naa n gbe fidi e mule pe oun ati okunrin naa ti n ba ore won bo latodun meta seyin, ti okunrin to niyawo meji sile yii si maa n wa sodo re waa sun di ojo keji lai si wahala kankan. Bee lawon eeyan si mo awon mejeeji po bii toko-tiyawo ki nnkan to sele laarin won yii too waye.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Ismaila Dero Ogba Ewon L'Ekiti, Won Loun Lo Pa Iyawo Re
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Ismaila Dero Ogba Ewon L'Ekiti, Won Loun Lo Pa Iyawo Re

Baale ile eni odun mokandinlogbon kan, Azeez Ismaila, ti wo gau nipinle Ekiti, Olorun nikan ni yoo si ko o yo. Idi ni pe ile-ejo majisreeti kan to kale siluu Ado-Ekiti ti pase pe ki won loo ju u sahaamo ogba ewon lori esun ti won fi kan an pe oun lo pa iyawo re, Odunayo Ismaila.

Gege bi olopaa to soju ijoba nile-ejo, Sajenti Bankole Olasunkanmi, se salaye, ojo keeedogbon, osu kesan-an, odun yii, ni afurasi ohun lowo ninu esun ipaniyan ti won fi kan an lagbegbe Odo-Ado, niluu Ado Ekiti.

Esun tile-ejo fi kan olujejo ni Olasunkanmi so pe o tako abala kan ninu ofin to n gbogun ti iwa odaran nipinle Ekiti, todun 2012.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Epe niyawo mi maa n se fun mi laraaro to ba n gbadura—Tunde
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Epe niyawo mi maa n se fun mi laraaro to ba n gbadura—Tunde

Baale ile kan, Ogbeni Tunde Samuel, ti gbe iyawo re, Grace, wa sile-ejo ibile kan to wa niluu Ilorin, o si ro adajo lati tu igbayawo odun merinlelogun awon ka, o ni epe niyawo oun maa n se foun laraaro to ba n gbadura.

Okunrin yii so pe iyawo oun koriira oun pupo, bee lo si tun ti koyin awon omo meteeta tawon bi soun. O ni to ba ti ji laaaro bayii, nise lo maa bere si i sepe foun to ba n gbadura fara yooku ninu ile, o si ti je kawon omo oun koriira oun gidi.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Babatunde foruko olopaa otelemuye lu jibiti n'Ilorin, lowo ba te e
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Babatunde foruko olopaa otelemuye lu jibiti n'Ilorin, lowo ba te e

Owo palaba odomokunrin eni ogbon odun kan, Kehinde Babatunde, to n fi oruko olopaa otelemuye lu awon to n wase ni jibiti segi laipe yii, ileese olopaa si ti foju e bale-ejo lose to koja.

Afurasi ohun to n gbe lojule keje, lopopona Adam, lagbegbe papa-isere ilu Ilorin, lo n fogbon jibiti so fawon to ba n wase pe eka olopaa otelemuye loun n ba sise, oun le ran won lowo lati rise sibe.

Bo tile je pe o ti n se e tipe to si ti n mu un je, lara awon to ti lu ni jibiti ni Sikurudeen Azeez atawon mi-in, sugbon eyi to yi i lagbo danu ni ti odomokunrin kan, Saidu Abdulkadir, to loun fee wase fun sugbon tiyen ko ri ise ohun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Ezekiel ki omoodo oga re mole, lo ba n wo bii maalu to robe nile-ejo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayinka Adedayo


Ezekiel ki omoodo oga re mole, lo ba n wo bii maalu to robe nile-ejo


Ikun n jepa, ikun n redii, ko mo pe ohun to dun lo n pa ni. Oro yii lo se mo omokunrin geetimaanu kan, Ezekiel Collins, eni odun meeedogbon to n jejo lowo ni kootu majisireeti Ebute-Meta lori esun ti won fi kan an pe o fi tipa ba omoodo oga re ti a foruko bo lasiiri lo po.


Nile-ejo ni agbenuso ijoba, DSP Etim Ekankuk, ti so o di mimo pe isele naa waye ni nnkan bii aago mejila koja losan ojo keji, osu keji, odun yii, lojule kokandinlogun, laduugbo Sowemimo, G. R. A Ikeja, niluu Eko, iyen lasiko ti Ezekiel ki omodebinrin to je omoodo oga re ti won jo n gbele mole, to si jabaale re. O tun fun omo naa lorun, o si fun un lesee nikun nigba tiyen n ba a sagidi.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

L'Akure, ajo to n gbogun ti oogun oloro sawari ile kan to kun fofo fun igbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Iyiade Oluseye, Akure


L'Akure, ajo to n gbogun ti oogun oloro sawari ile kan to kun fofo fun igbo


Fofoofo lawon ero to waa woran aramanda ohun kun adugbo kan ti won n pe ni Kayode Ogunleye, lagbegbe Olu Foam, l'Emure, niluu Akure ti i se olu-ilu ipinle Ondo laaaro Ojobo, Tosde, ose to koja leyin tajo to n gbogun ti lilo ati gbigbe oogun lorile-ede yii, eka tipinle Ondo, sawari ile nla kan to kun fofo fun igbo. Bee lawon eeyan to pejo sibi isele naa fi boro ohun se ya won lenu to han, won ni iru nnkan bayii le maa sele laduugbo kawon to n gbe nibe ma fura.


Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, enikan ni won lo gboorun igbo to n run lasiko ti okada gbe e koja laduugbo ohun lo loo ta ajo to n gbogun ti lilo oogun oloro lolobo, kia lawon yen si gbe igbese lati sabewo sibe.


Enikan ninu awon olugbe adugbo yii to ko lati daruko re f'Iwe Iroyin Yoruba so pe ni nnkan bii aago merin idaji Ojobo, Tosde, ni won deede gbo ti won n ja geeti ile kan laduugbo ohun. O ni ole lawon koko pe e nitori ko ti i ju bii ose meji seyin tawon ole waa yo awon lenu, leyii to mu ki onikaluku maa gbaradi di asiko tawon ole ohun yoo de odo won.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Odaran ponbele ma ni Ige yii o: O fipa ba Tomiwa lo po l'Owo, lo ba tun fi
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Odaran ponbele ma ni Ige yii o: O fipa ba Tomiwa lo po l'Owo, lo ba tun fi bairo ko oruko egbe okunkun to wa si i nitan


Ebe, “E dakun, e saanu mi, mi o mo pe ese ni pe keeyan o baayan lo po lai se pe inu onitohun o dun si i”, lomokunrin eni ogbon odun kan fi bonu leyin towo olopaa te e niluu Owo, nijoba ibile Owo, nipinle Ondo, pe o fipa ba omobinrin kan toruko re n je Tomiwa lo po, bee lo tun fi bairo ko ‘Blue Angel' si i nitan leyin to sise ibi owo e tan lojo Abameta, Satide, ojo kerinla, osu to koja yii.


Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se fidi e mule latenu olopaa kan to ko lati daruko e lojo isele buruku ohun, se omokunrin naa toruko re n je Soladoye Ige to n gbe laduugbo Enete, niluu Owo, nipinle Ondo, fogbon tan omobinrin ohun lo sile e, nibi to ti fipa ba a lo po, to si tun ko ‘Blue Angel' ti i soruko egbe okunkun to wa si i ko too yonda e.


O tesiwaju pe bi omobinrin ohun se jajabo lowo Ige lo morile ago olopaa to wa l'Owo lati fejo sun. Ige ko si ti i rona sa lo towo awon olopaa fi te e, eyi to mu kawon eeyan maa so pe boya nitori ti afurasi naa ko ro o lokan pe Tomiwa le gbori-gboya fejo sun olopaa kiakia ni ko je ko sa lo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: