Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
[ Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin ]

·Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awok
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Ikolu Awon South Africa Si Naijiria - Ekunrere
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbes
·Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
·Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
·Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
·Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun
·Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Sunday, March 30
· NDLEA Ya Bo Oko Igbo Laginju Aala Oyo Ati Osun, Ni Won Ba Dana Sun Gbogbo E
Saturday, January 25
· Babalawo Naa Fee Soogun Owo, Lo Ba Loo Ge Eya Ara Oku Ni Ite
· Adajo Ni Ki Won Fi Isa To Sa Usman Ladaa Pa, To Tun Dana Sun Ile E N'Ilorin
· L’Ondo, Iyabo Dana Sun Yara Awon Ayelegbe Baba Re, O Ni Won N Di Oun Lowo
· O Tan! Won Lawon To Ja Oba Sihooho Ni Ado Odo Ti N Ku Nikookan
· E Gba Ni E Laja, Baale Ile Sa Iyawo Re Ladaa N’Ile-Ife
· Nibi Ayeye Ojoobi Alake, Afoju Na Onilu Daku
· Pius Atawon Ore E Pa Abdullahi, Won Tun Ge Eya Ara E Lo Ni Kwara
· Nitori Wahala To Sele Niluu Agbonle, Akowe Ijoba Ibile Padanu Ipo Re
· Owo Ti Te Tosin To Fee Ji Omo Odun Merinla Gbe L'Ado-Ekiti
Monday, November 25
· Lati Ilu Ede Ni Najimu Ti Waa Ji Omo Gbe L’Ogbomoso, Owo Ti Te E O
· Nitori Oro Ti Ko Kan Won, Lateef Ati Ore E Lu Deborah Loja Iddo, N Lolopaa Ba Ko
Sunday, October 27
· Niluu Ilora, Tipa Te Olokada Pa, Lawon Egbe E Ba Binu Dana Sun Moto Naa
Sunday, September 08
· Oba Fatai Matanmi Pariwo: E Gba Mi O, Ojoojumo Lawon Hayakila N Lepa Mi
Thursday, June 13
· Aye Ti Baje O! Awon Omo Iya Meta Lu Oga Ileewe Won L’Akure
· L’Ondo, Awon Araalu N Binu Si Baale, Won Ni Afi Ko Fori Oye Sile
Saturday, April 13
· Ori Ko Koburu Olopaa Yo Lowo Awon Adigunjale N’Ibadan
· Abiru Omokomo Wo Ni Yemi Yii! O Si Gba Tisa To N Ko O Nileewe Lesee Loju L’Ekiti
· Wahala De! Ile-ejo Ni Ki Won Ju Onijoko Ota Satimole Osu Meji Nitori O N Pe Ara
· Won Sawari Ibi Ti Won Ti N Wa Epo Bentiroolu nN’Idi Iroko
Wednesday, March 20
· O Tan, Ile-ejo Ko-te-mi-lorun Naa Koyin Si Pasito Refurendi King, Won Ni Afi Ki
· Nitori Oro Ile, Won Fi Toogi Le Awon Ara Abule Adunbi, Ni Ewekoro, Kuro Niluu
· O Ga O! Moto Ya Lu Soobu Nusiratu, Nibi To Ti N Sa Lo Lo Ba Gbagbe Awon Omo Orog
· Ofo Emi Kan Ree O! Won Pa Eniafe Sinu Oko E N’Ilawe-Ekiti
Thursday, February 28
· Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Olopaa Pa Agbofinro Egbe E L’Ondo
· Wahala De! Won Yinbon Pa Beyioku, Igbakeji Alaga Egbe Onimoto N’Ibadan
Wednesday, February 13
· Segun Sa Ibrahim Ladaa Yannayanna L’Osogbo, Oro Obinrin Lo Fa Wahala
Wednesday, January 23
· Abiru Ki Leleyii? Nitori Ija To Wa Laarin Jelili Atawon Ore E, Won Si Fibinu Lu
· Taye To Gun Olokada Obe Lorun L’Omu-Aran Ti N Kawo Ponyin Rojo
· Pako Ni Adekola La Mo Johnson Lori Lojo Keresimesi, Niyen Ba Ku Patapata

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

EsinIslam Media: Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Iwadi Nipa Akole Yii:   
[ Pipada Si Oju Ewe Olori Ti Akoko | Sise Esayan Akole Tuntun ]

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Deji Binu Si Titi Afesona Re, Lo Ba Dana Sun Eeyan Mesan Mole L'Ondo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Deji Binu Si Titi Afesona Re, Lo Ba Dana Sun Eeyan Mesan Mole L'Ondo

Ileese olopaa ipinle Ondo ti n wa omokunrin kan, Deji Adenuga lori esun pe o dana sun awon molebi orebinrin re, Tutu Sanumi nitori pe iyen so fun un pe oun o se mo.

Deji, eni ti a gbo pe o ti sewon ri ni wahala be sile laarin oun ati Titi, eni ti won ti jo n ba ere aniyan bo lati odun merin seyin, koda, oro naa le debii wi pe won ko ara won lo si agoo olopa, sugbon pabo lo ja si.

Bi Titi se so fun Deji pe o to gee bayii la gbo pe o ti kuro niluu Ondo laije ki Deji mo. Pelu ibinu ni Deji fi lo sile awon Titi to wa loju-ona Igbokoda lojo Tusde, o gbe keegi epo petiroolu lowo, o si dogbon si windo ile naa laarin oru.

O da petiroolu sinu ile, o si ju isana si i, loju ese ni meji ninu awon molebi Titi ku, nigba tawon meje to ku dake nileewosan Trauma Center niluu Ondo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Victoria Fi Obe Gun Oko Re Pa; Ladajo Ba Ni Ki Won Loo Yegi Fun Un
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Victoria Fi Obe Gun Oko Re Pa; Ladajo Ba Ni Ki Won Loo Yegi Fun Un

Lagbala iroyin la ti gbo pe adajo ile ejo giga kan nipinle Bayelsa, Onidajo Nayai Aganaba ti pase pe ki won loo yegi fun obinrin eni ogbon odun kan, Victoria Gagariga lori esun pe o pa oko re, Henry Gagariga.

Adajo Nayai so pe gbogbo eri to wa niwaju oun lo fidii re mule pe olujejo lo gun oko re lobe pa latari owu-jije to fa wahala laarin won lojo kerin osu keji odun 2015.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Olusheye Iyiade, Akure

Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure

Ileese olopaa ipinle Ondo ni awon ti n wa gbogbo ona lati fi panpe oba gbe toko–taya kan ti won fesun kan pe won lu Testimony Tooke Babalola, omo bibi inu ara won pa l'Akure, l'Ojoruu, Wesidee, ose to koja.

Femi Joseph to je alukoro ileese ohun so lojo Aiku, Sannde, to koja yii pegbogbo igbese to ye lawon n gbe lowo lati ri i daju pe owo te Ogbeni Felix Babalola ati iyawo re laipe rara, ki won le waa so tenu won lori oro iku omobinrin eni odun merin ohun.

O ni opo igba lawon ti de ile ti won n gbe l'Akure, sugbon ti awon ko ba won, sugbon o ni awon ko ni i sinmi titi ti won yoo fi ri awon afurasi mejeeji ohun mu.

Abileko Babalola to je iya omodebinrin ohun ni won lo gbe e digbadigba lo sile-iwosan ijoba to wa l'Akure ni irole Ojoruu, Wesidee, ose to koja, kawon dokita to ba lenu ishe l'ojo naa too fidi re mule pe omo to gbe wa ti ku.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L'Abuja

Iroyin ti ko dun mo enikeni ninu bawon ajinigbe se ji okan lara awon osise telifisan African Independent Tlelevision, AIT, iyen Abayomi Adigun, ti won si pa a danu.

Eka ileese naa to wa niluu Ilorin la gbo pe won ti gbe Abayomi kuro laipe yi, lati loo darpo mo awon iko to n seto Kakaaki niluu Abuja.

Ale ojo Sande to koja yi la gbo pe Abayomi gbera nile e lati lo sibise, to si wo oko lagbegbe Kubwa-Aya, nibi to ti ko sowo awon ajinigbe ti won pe ni "One Chance" naa.

Nigba ti won ko tete ri Abayomi lati wo ise lale ojo naa la gbo pe won bere sii pe aago e, sugbon ti enikeni ko gbe e.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lorun Pa Nile Itura

Bo tile je pe a ko ti mo nnkan to shele laarin baba ati omo re, omodun meta, to mu ki baba naa daa dubule, to si ko patie bo o bii maalu to gbojo iku.

Ilu Ogbomosho nipinle Oyo nishele naa ti waye lojo Satide to koja yi.

A gbo pe baba naa ati iyawo to sheshe fe ni won jo dawo bo omodun meta naa, to si je pe awon eleyinju aanu ni won gba omo naa sile.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunkun Yinbon Pa Akekoo, Lasiko To Pari Idanwon Asekagb

She loro di boolo o yago lojo Aiku, Sande ana nigba ti won lawon Hausa ati Yoruba koju ija sira won, ti won bere sii she ara won bashubashu, ko da, ti opo dukia shofo danu, tawon eeyan si farapa yannayanna.

Agbegbe oja nla kan to wa ni Oke-Odo nipinle Eko, loju ona Ekoo si Abeokuta nija nla naa ti waye, to si je pe fun bi i wakati merin lagbegbe naa fi pa loolo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo

Baa ti n koroyin yii, atimole ileese olopaa ipinle Ondo lomokunrin kan toruko re n je Sunkanmi ti n ran awon olopaa lowo lori iku airotele to fi pa okunrin kondokito kan to n je Ojo lasiko tawon mejeeji fija peeta.

Isele naa sele ni gareeji Oloko to wa loju ona marose IlesaÍOwo, niluu Akure, nibi ti won so pe Iya Sunkanmi ti n ta ounje.

Gege bi alaye ti okan ninu awon awako to n sise ni gareeji ohun se fun wa nigba ta a sabewo sibi isele naa, iresi sise nikan ni Iya Sunkanmi n ta ninu gareeji ohun. Sugbon lojo tohun buruku yoo sele ni gareeji naa lo da bii eni pe iresi ti Iya Sunkanmi n ta ko wu Ojo i je, idi si ree to fi lo sile olounje mi-in ti ko fi bee jinna sibe.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Tope To Pa Lanloodu e L'Ondo Ti Wa Lewon
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Tope To Pa Lanloodu e L'Ondo Ti Wa Lewon

L'Ojobo, Tosde, ose to koja yii, nileese olopaa nipinle Ondo wo okunrin eni odun mejilelogun kan, Akindeji Tope, to pa lanloodu re nitori kanga lo sile-ejo majisreeti kan l'Oke-Eda, niluu Akure.

Gege bi ejo ti Inspekito Martins Olowofeso ti i se agbenuso olopaa ro lasiko ohun lese, nnkan bii aago mefa aabo aaro ojo kokanla, osu ta a wa yii, lojule kerinlelaaadorin, laduugbo Ayeferere, niluu Ondo, nijoba ibile Iwo-Oorun Ondo, ni Tope seku pa lanloodu re, Ogbeni Osunkalu Kayode.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

N'Igbokoda, Tegbon-taburo Ri Ore Meji Mole Laaye Nitori Ti Won Ji Iya Won L
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

N'Igbokoda, Tegbon-taburo Ri Ore Meji Mole Laaye Nitori Ti Won Ji Iya Won Lowo

Bi ki i baa se ori to ko awon ore meji kan, Igbekele Orisabinuole ati Ogbaro Erinbo, yo ni, o see se ki eleko orun ti polowo fun won pelu bawon okunrin meji kan ti won je omooya kan naa se ri won mole laaye lori esun pe won ji owo iya won.

Lojo Abameta, Satide, ti i se ojo kejila, osu ta a wa yii, laduugbo Omonira, niluu Igbokoda, nijoba ibile Ilaje, nipinle Ondo, nisele yii ti waye leyin towo kan to je tiya awon afurasi naa, Omoniyi Alaleran ati Oluwaseun Enikuomehin, sonu, tawon omooya yii si so pe awon ore mejeeji ohun ti won koja lagbegbe naa ni won ji i.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Owo Ileewe Di Wahala Ni Poli Oke-Ogun, Lawon Soja Ba Lu Akekoo Ati Oluko Lalubam
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Owo Ileewe Di Wahala Ni Poli Oke-Ogun, Lawon Soja Ba Lu Akekoo Ati Oluko Lalubami

Awon janduku akekoo kan ti won fura si bii omo egbe okunkun ni won darapo mo awon akekoo Poli Oke-Ogun to wa niluu Saki, nipinle Oyo, laipe yii, ti won si da omi alaafia ileewe naa ru debii pe oluko kan ati olopaa meji farapa yannayanna ninu ikolu naa.

Idanwo tawon alase ileewe naa seto re fawon akekoo onipele kin-in-ni to bere lojo kokandinlogbon, osu keji, to pari yii ni won lo fa wahala. Awon alase ti kede re tele pe eni ti ko ba sanwo ileewe ko ni i sedanwo, sugbon oro pada beyin yo lojo Isegun, ojo kin-in-ni, osu keta yii, ti i se ojo keji ti idanwo naa bere nigba tawon akekoo ti won ko ni anfaani lati jokoo sedanwo nitori pe won ko sanwo ledi apo po mo awon elegbe won lati ileewe mi-in, ti won si n gbero lati da idanwo naa ru.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

'E Gba Wa Lowo T.B Joshua Atawon Eeyan e o, Ojoojumo Ni Won n Da Wahala Sil
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johson Akinpelu, Abeokuta

'E Gba Wa Lowo T.B Joshua Atawon Eeyan e o, Ojoojumo Ni Won n Da Wahala Sile'

Lose to koja ni egbe Oodua Peoples Congress ti Otunba Gani Adams gbe atejade kan sita, eyi ti Oloye Owadokun Olufemi Lawson ati Oloye Olutayo Bode fowo si labe egbe kan ti won pe ni 'Arigidi Leaders Thought'.

Ninu atejade naa ni won ti ke si ijoba ipinle Ondo, awon eleto aabo atawon elegbejegbe lati kilo fun Pasito T.B Joshua atawon eeyan e ki won kowo omo won boso nitori bi won ko se ti i jawo lori dida alaafia ilu naa ru lati nnkan bii odun marun-un seyin.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Nnkan De! Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Gabriel Lu Henry Pa n'Idanre
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nnkan De! Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Gabriel Lu Henry Pa n'Idanre

Pako bii igba ti maalu ba robe lomokunrin eni ogun odun kan, Francis Gabriel, n wo lagoo olopaa to ti n fimu danrin lowo lori esun pe o seku pa okunrin alabaagbe e kan lasiko ti won jo n ja.

Isele naa la gbo pe o waye lose to koja nile ti okunrin afurasi yii pelu oloogbe naa toruko re n je Henry Allison n gbe to wa loju ona kan to lo si Oja Alade, niluu Idanre, nijoba ibile Idanre, nipinle Ondo.

Gege bi ohun ta a gbo nipa isele yii, oro kekere kan lo da wahala sile laarin awon mejeeji ko too di pe esu ba won lowo si i. Gabriel ni won lo loo ba Henry, o si fesun kan an latari bo se da ile sibi ti ko ye ko da a si ninu ogba ile ti won jo n gbe.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Esther Na Omo Oko Re Fo Loju, Lawon Olopaa Ba Wo o Dewaju Adajo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Esther Na Omo Oko Re Fo Loju, Lawon Olopaa Ba Wo o Dewaju Adajo

Nitori esun biba omo oko re wi lona ti ko to ni won se wo obinrin kan toruko re n je Arabinrin Esther Williams lo si kootu majisreeti to wa ni Surulere lose to koja. Obinrin yii la gbo pe o seesi fegba gun omo oko re, Boluwatife Williams to je omo odun merindinlogun loju lasiko to n ba a wi.

Okan ninu awon esun mejeeji ti won fi kan obinrin ti won so pe oun lo fo omo oko re loju ni adajo ile-ejo yii pada wogile latari bi agbejoro re, Dr. Ubiwe Eriye, se so pe ki i se eyi ti abileko naa mo-on-mo se, bi ko se pe biba to n ba omo naa wi lori iwa aigboran re legba seesi wonu oju osi e lo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Charles Na Nani Daku N'Ilorin, O Ni o N Je Komo Oun Sunkun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Charles Na Nani Daku N'Ilorin, O Ni o N Je Komo Oun Sunkun

Ileewosan 'Tobi Hospital,' to wa niluu Ilorin, lo gba arabinrin to n ba won toju omo kan, Abileko Taye Babatunde, eni odun merindinlaaadota sile nigba ti arakunrin kan, Charles Obirili, na an daku latari pe o ba omo re, omo osu mefa to n sunkun.

Isele naa waye lojo Isegun, Tusde, ose to koja si arabinrin to n toju omo ohun, eni ti opo eeyan tun mo si Mummy Tomi. A gbo pe o ti to osu meje to ti n sise naa lodo Ogbeni Charles ati iyawo re.

Nigba ti arabinrin naa n ba awon akoroyin soro, o ni banki Zenith Ilorin keji to wa ni adugbo Surulere, loun ti n sise gege bii osise oojo (contract staff), nibe si ni iya omo naa to je iyawo Charles toruko re n je Grace ti n sise.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Ore Meji Figo Gun Ara Won Sakasaka L'Ekiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Ore Meji Figo Gun Ara Won Sakasaka L'Ekiti

Nitori ede-aiyede ranpe kan to sele laarin awon ore meji ti won jo n gbe inu yara, Yetunde Kolawole, eni ogun odun ati ikeji re, Banke Alonge, toun je omo odun merindinlogbon, ileese olopaa ti wo won lo sile-ejo lori esun pe won figo gun ara won sakasaka.

Gege bi olopaa to soju ijoba, Koburu Monica Ikebuilo, se salaye nile-ejo majisreeti kan niluu Ado-Ekiti, awon olujejo mejeeji ohun koju ija sira won nita gbangba, eyi to mu won fo igo, ti won si fi gun ara won ni gbogbo ara. Isele ohun lo mu ki won da ogbe sira won lara lojo ketala, osu kewaa, odun yii, lagbegbe Irona, niluu Ado-Ekiti. O ni esun ohun tako abala kan ninu ofin to n gbogun ti iwa odaran nipinle Ekiti.

Ikebuilo waa ro ile-ejo lati sun igbejo siwaju, eyi ti yoo fun un laaye die lati mura daadaa fun ejo ohun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Iro Ni Adegboye N Pa, Won Ko Ni Ile Kankan L'Ajenisuwa — Baale Ajenisuwa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Iro Ni Adegboye N Pa, Won Ko Ni Ile Kankan L'Ajenisuwa — Baale Ajenisuwa

Baale ilu Ajenisuwa, nijoba ibile Osogbo, nipinle Osun, ti so pe ko si ooto kankan ninu oro tawon idile olomooba Lahanmi Oyipi n so pe ile awon ni ilu Ajenisuwa, ati pe ko si baale kankan nibe.

Baale naa, Enjinia Musibaudeen Olaniyi Otaoroju Oyedele, salaye pe ko seni kan ninu ile Oyipiloye to le so pe oun ko mo oun gege bii omo idile naa, ati pe ija lo de ti orin dowe, bee ni won ko ni ile kankan ni Ajenisuwa.

Gege bo se wi, ''Ko si oro ninu nnkan ti won so yen, koda won o tie ni ile ni Ajenisuwa, awon baba baba temi ti won je Otaoroju ni won te ibe do. Ti won ba tun fee gbo itan Oyipiloye daadaa, ma a so o fun won pe ile Iyadudu ni won bi emi ti mo n soro yii si niluu Osogbo, ibe ni won ti bi iya baba mi, sugbon ti oro ba ti ri bayii, awon olomooba ki i fe elomi-in. Awa meji la jo du oye Baale latile Oyipi, ko bo sowo eni keji, eyi to ba waa ni oun ko mo mi ninu won, e so fun un pe oko lo ti wa, ko si mo nnkan to n se mo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Wooli Fe Gbemi Omo Re Omo Odun Meje To Nka L'Akure, Lo Ba Ni Dandan Bi Ki W
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Wooli Fe Gbemi Omo Re Omo Odun Meje To Nka L'Akure, Lo Ba Ni Dandan Bi Ki Won Foun Lori Ewure

Oro omodebinrin omo odun meje kan, Marvelous, to ka laduugbo Oluwole, lagbegbe Olu Foam, niluu Akure, ti fee di wahala nla sawon araadugbo ohun lorun bayii pelu bi won se ni baba e, Wolii Oluwafemi Ayodele, n leri pe afi dandan koun gbemi e leyin to ti ka pe oun loun wa nidii gbogbo idaamu ti wolii naa n dojuko.

Gege bi ohun ta a fidi e mule nipa isele ohun, Baba Marvelous to je oludasile ijo kan niluu Akure ni won lo loo gbadura lodo wolii kan niluu ohun lori oro aye e to dojuru bii ese telo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Obafemi Gun Ore Re Pa Ni Yaba, Owo Lo Dija Sile
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluseye Iyiade

Obafemi Gun Ore Re Pa Ni Yaba, Owo Lo Dija Sile

Olayinka Adedayo

Awon agba lo maa n so pe owo lo n boju ore je, bee ni owo a tun maa da aarin omo iya
meji ru. Oro yii lo se mo okunrin kan to n se buredi ta, Obafemi Yunus, eni odun
merinlelogoji to n gbe lojule kokanlelogun, laduugbo Church, lagbegbe Makoko, ni Yaba,
lara lori esun pe o gun ore re, Peters Ajayi, eni odun mejidinlogoji nigo lori pa.

Okunrin naa ni adajo ile-ejo Majisireeti kan to wa l'Ebute-Meta, niluu Eko, ti pase pe ko si
wa latimole ogba ewon to wa ni Ikoyi fun iwa ti ko ba ofin mu to hu naa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Nitori jenereto, toko-tiyawo na iyawo onile daku
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori jenereto, toko-tiyawo na iyawo onile daku

Bi ki i baa se opelope awon araadugbo Ilupeju, Asero niluu Abeokuta, die lo ku ki toko- tiyawo kan lu iyawo onile won pa sinu ile. Bo tile je pe won ko pa obinrin naa, sibe won fi aburo iku han an nipa bi won se na an daku, jenereto lo fa wahala laarin won.

Nirole ojo Abameta, Satide, ni nnkan bii aago marun-un ni wahala naa be sile nigba ti oko toruko e n je James ati iyawo e, Rebecca, lu obinrin naa lasiko tiyen so pe ariwo jenereto won n da awon araale laamu.

Iwadii Iwe Iroyin Yoruba fi han pe ko ti i pe tawon toko-tiyawo naa de adugbo yii ti won si ko wahala ba awon alajogbe won.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Owo te Stella atawon egbe e pelu ohun ija oloro ni Kwara
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Owo te Stella atawon egbe e pelu ohun ija oloro ni Kwara

Obinrin afurasi eni odun metalelogoji kan, Stella Momoh, to n gbe lagbegbe ileewe awon olopaa to wa ni Kulende, pelu emewa re kan, David Ogirima Momoh, toun je eni odun mejidinlogbon to fi ojule kokanlelogoji, laduugbo Bolorunduro, lagbegbe Sango, niluu Ilorin, sebugbe lowo ileese olopaa ipinle Kwara te laipe yii pelu ohun ija oloro, won si ti foju bale-ejo.

Awon afurasi ohun ni won fesun meta otooto kan, iyen igbimo-po lati sise ibi, idunkooko mo ni ati gbigbe ohun ija oloro lona to lodi sofin.

Lara awon ohun ija oloro tileese olopaa ka mo won lowo ni ibon ilewo meji ti nomba okookan je AO70782 ati RUHMRG799ABL, ibon agbelero kan, opolopo ota ibon lorisiirisii, ewu akota-min meta, awon ohun idaabobo atawon nnkan mi-in.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

N'Ilu Itori, Christianah fee pa omo iyaale e, nise lo fi nnkan di i lenu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


N'Ilu Itori, Christianah fee pa omo iyaale e, nise lo fi nnkan di i lenu


Bi ki i baa se pe Olorun ti ni akoko iku omo odun meji kan ko ti i pe ni Itori, Ewekoro, nipinle Ogun, iyawo baba re, Christianah Faturoti ko ba ti ran an sorun airotele, sugbon Olorun ko o yo.


Eni odun mejidinlogbon ni Christianah, sadeede ni won lo mu omo iyaale e to je omo odun meji to si fi seloteepu le enu e po, o de owo e mejeeji lokun, o si tilekun mo on sinu yara.


Lojo ketadinlogun, osu keji, to koja yii nisele naa waye lojule kerinlelogoji, Agboole Ago Owu, Itori, nijoba ibile Ewekoro, nipinle Ogun.


Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba, a gbo pe Christianah toun naa n to omo odun kan lowo yii mo- on-mo le enu omo kekere ohun pa ko ma baa pariwo, leyin to si sise ibi naa tan lo gba ileepo to ti n sise lo.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Awon olopaa n wa Bidemi to dana sun Emmanuel nitori egberun kan naira n'Iba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Awon olopaa n wa Bidemi to dana sun Emmanuel nitori egberun kan naira n'Ibafo


Titi di akoko ti a n ko iroyin yii lowo lawon olopaa si n wa okunrin kan ti won n pe ni Lanre Shitu Bidemi Ibrahim lori esun pe o dana sun Emmanuel nitori egberun kan aabo naira.


Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, lojo kerindinlogun, osu to koja nisele naa waye ni oteeli ti won n pe ni Molayo, to wa niluu Ibafo, nipinle Ogun.


Bidemi ni won pe ni manija oteeli ohun, koda won ni baba e lo ni in, sugbon lojo tisele naa waye, ariyanjiyan waye lori owo ti Bidemi fun Emmanuel ti won so pe o maa n tun jenereto se.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Amidu sa egbon e ladaa, o tun fee yinbon pa awon ara abule won
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Amidu sa egbon e ladaa, o tun fee yinbon pa awon ara abule won


Opo awon ara agboole Obasa to wa labule kan ti won n pe ni Aba-Oje, nijoba ibile Lagelu, nipinle Oyo, ko foju ba oorun moju Ojobo, ti i se ojo karun-un, osu keta, iyen Tosde, ose to koja, pelu bi okunrin eni odun meeedogbon kan, Rafiu Amidu Abiodun, se gbana je, to gun egbon e, Simiyu Rafiu nigo leyin to ti koko sa a ladaa sugbon ti kinni naa ko tu irun lara e. Bee loree e to n je Owolabi naa gun alabaagbe won lobe yannayanna.


Nitori ija kan to ti waye laarin Amidu pelu okunrin kan to n je Tajudeen lati nnkan bii osu meji seyin la gbo pe o fa wahala ohun, pelu bi Amidu se be Owolabi ore e lowe lati ba oun da seria fun Taju. Nibi ti Simiyu to je egbon Amidu ti n gbiyanju lati pana wahala naa ni aburo e ti pa igo mole, to si gun un yannayanna.


Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, baba kan naa lo bi Amidu ati Simiyu, bo tile je pe iya kan ko pa won po. Inu ile won ni Simiyu n gbe, nigba ti Owolabi ni tie je omo abule kan ti won n pe ni Aba Eleran Igbe lagbegbe naa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Iya meji je Tokunbo n'Ibadan: Won ja a lole owo ati foonu, won tun fipa ba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu


Iya meji je Tokunbo n'Ibadan: Won ja a lole owo ati foonu, won tun fipa ba a lo po


Bi iya nla ba gbe ni sanle, kekere a maa gori eni, eyi lo difa fun obinrin eni odun metalelogun kan, Olatokunbo, eni ta a fi ojulowo oruko e bo lasiiri ti ole kan ja poosi owo e gba, tawon to n ba a se aajo lati mu okunrin ole naa si tun ja a lole ara. Nise ni won dogbon tan an lo soju olomo-o-to-o, won ya sikeeti to wo mo on nidii, won si fipa ba a lasepo.


Lojo Aje, Monde, ose to lo lohun-un nisele ohun waye nigba tawon olubi okunrin kan fipa ba obinrin onisowo yii lasepo laduugbo Academy, lagbegbe Iwo Road, n'Ibadan, leyin bii wakati meta tawon ole kan ti ja poosi e gba laduugbo ohun lojo kan naa.


Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ayoonu iloso ni Tokunbo kiri gba adugbo naa koja ni nnkan bii aago mefa irole to fi bere si eyin fensi ileewe girama kan laduugbo naa lati to¯. Nibi to ti n bo pata lowo lokunrin jaguda ohun to jo pe o ti n so o tele sare gba egbe e koja, o si ja poosi to n pa owo si gba lowo e. Kia ni Tokunbo sare wo pata e to si gba ya okunrin ole yii, sugbon ko sare debi kan ti a-lo-kolohun-kigbe naa fi poora mo on loju.


Egberun mewaa naira ati ero ibanisoro Nokia ti owo e to egberun merindinlogun naira la gbo pe o wa ninu poosi ohun. Ori aajo dukia ti Tokunbo padanu wonyi lo wa tawon okunrin meji kan ti won pe ara won ni ode to n so adugbo naa fi de ba a, ti won si gba lati ran an lowo lati wa ole naa, laimo pe nise lawon eeyan naa tun fee da tiwon kun iya to ti je e tele.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Owo te Akintunde atawon ore e to sa Akebisola pa l'Akure
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Owo te Akintunde atawon ore e to sa Akebisola pa l'Akure

Lose to koja lowo ileese olopaa ipinle Ondo te awon okunrin meta kan, Akintunde Babatunde, Ojo Victor ati Oyibo Ojo lori esun ipaniyan.

Olopaa kan taa foruko bo lasiiri to ba Iwe Iroyin Yoruba soro lori isele yii so pe arabinrin kan toruko re n je Akinlere Funmi to n gbe ninu Esiteeti Oba Afunbiowo, niluu Akure, lo wa sagoo olopaa ni nnkan bii aago marun-un irole ojo Abameta, Satide, ose to koja, pe oun ri oku okunrin eni ogoji odun kan toruko re n je Akebisola Adodo ninu agbara eje leyin ile akoku kan ninu esiteeti ohun.

Okunrin naa ti won lo n gbe lojule kokandinlogbon, aduugbo Awelata, Odo de Idanre, nijoba ibile Idanre, nipinle Ondo, la gbo pe won sa Adodo ladaa lori yanna-yanna nibi ti won pa a si ohun.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Ofo-emi kan re o! Won yinbon pa Jeje n'Ijoko Ota
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Ofo-emi kan re o! Won yinbon pa Jeje n'Ijoko Ota

Ariwo ikunle abiyamo o lawon eeyan to n gbe laduugbo Sawmill, n'Ijoko, niluu Ota, n pa nigba ti won ri i bi awon kan se yinbon pa okunrin eni odun mejidinlogoji kan toruko e n je Jeje Oni, ti omokunrin naa si wa ninu agbara eje titi to fi dagbere faye.

Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba, ise telo ni Jeje n se ni Ijoko, ibi ti soobu e wa ko jinna si aafin Oba Ogunseye tawon kan dana sun ni nnkan bii ose merin seyin.

Won ni o je enikan ti ko feran lati maa ra ounje je nita, eyi lo fa a to fi gbona ile lo l'Ojobo, Tosde, ti i se ojo kejo, osu yii, ni nnkan bii aago meta osan pelu awon ore e leyin tiyawo e pe e pe ounje osan ojo naa ti dele. Bi won se gbera ti won n lo sile ti Jeje n gbe ni Agoro ni won sakiyesi pe awon kan n tele awon.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Bunmi Ni Aje Lomo Lun, Lo Ba Le E Jade Nile L'Akure
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Iyiade Oluseye, Akure

Bunmi Ni Aje Lomo Lun, Lo Ba Le E Jade Nile L'Akure


Iyalenu nla loro ohun je lojo Isegun, Tusde, ose to koja, nigba ti Iwe Iroyin Yoruba ri omobinrin kan ti ko ti i ju omo odun meeedogun lo ninu ile akoku kan laduugbo Alakara, lojuna to lo s’Idanre, lagbegbe Oke-Aro, niluu Akure. Omobinrin yii pelu awon eru re bii aso atawon ohun eelo idana mi-in to n lo lo wa lodo re ninu ile ohun, bee la si ri pako gbooro kan to teso le lori to fi n sun nibe.

Leyin pe won fi paanu bo ile akoku naa lori, ko tun si aabo kankan to tun wa nibe, nitori pe ko nilekun, debii pe yoo ni ferese, gbayawu ni gbogbo re wa, eyi lo mu wa wonu ile naa lo lati foro wa omobinrin ohun lenu wo nipa boro se je gan-an.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Omo Ibo La Nnkan Mo Ore E Lori Nile Oti N'Ijesa-tedo, Lo Ba Pa A Patapata
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olayinka Adedayo

Omo Ibo La Nnkan Mo Ore E Lori Nile Oti N'Ijesa-tedo, Lo Ba Pa A Patapata

Nitori esun pe o pa Sunday to je ore e, ni aago mesan-an aabo ale ojo kokandinlogun, osu keje, lagbegbe Pako, n'Ijesa-tedo, l'Ekoo, ti ile-ejo Majisreeti to wa l’Ebute-Meta fi kan Ukpai Ama-Ukpai, eni odun merinlelogun, adajo ti pase pe ki okunrin naa si wa latimole olopaa to wa n'Ikoyi.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, isele naa waye lasiko ti Ama-Ukpai atawon meji kan ti owo awon olopaa ko ti i te bayii lo sile-afe kan lati loo muti, ko si pe rara ti ede-aiyede waye laarin won, eyi lo fa ibinu fun Ukpai to fi la nnkan mo ore re lori, teje si bere si i da lori omokunrin naa.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Ikoja Aaye Kan Ree O: Won Ni Abule Asasin Ni Won Fi Nofiu Adeyemi Joba Le Lori
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Ikoja Aaye Kan Ree O: Won Ni Abule Asasin Ni Won Fi Nofiu Adeyemi Joba Le Lori


Awon araalu Kukudi ati Obinrintin n’Ijaye ti kegbajare pe ki gbogbo agbaye gba awon lowo okunrin kan, Oba Nofiu Adeyemi Otunba, ti Alake fi joba ni abule kan ti won n pe ni Asasin, sugbon to n pe ara e ni Onijaye, eyi ti ko si ba ofin mu. Bee ni won lo tun fee maa je gaba lori awon ti won ki i sara ilu e, o fee ko won sabe e ni tipatipa.

Awon oloye ilu mejeeji ni won wa sileese Iwe Iroyin Yoruba to wa l’Abeokuta, nibi ti won ti waa fehonu han. Awon Oloye ti won wa naa ni: Oloye Rasak Adesola Obe to je Balogun Ijaye Kukudi; Oloye Adepoju Rasaki, Seriki Ijaye Kukudi; Oloye Kola Popoola, Lukotun Ijaye Kukudi ati Oloye Rasidi Ajakaye, Apagun-pote Ijaye Kukudi.

Awon oloye Ijaye Obinrintin tawon naa wa si ofiisi wa lojo naa ni: Oloye Asimiyu Ayinde Okeyale, Jagunna Ijaye Obinrintin; Oloye Musiliu Fatunbi Adeniji, Baala Ijaye Obinrintin; Oloye Sikiru Ojekunle, Seriki Ijaye Obinrintin.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Lasiko Ayeye Kanifa, Bashiru Sa Jamiu To N Lo Jeje E Ladaa Pa L'Ofa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Seyi Adeshina, Ilorin

Lasiko Ayeye Kanifa, Bashiru Sa Jamiu To N Lo Jeje E Ladaa Pa L'Ofa

Inu ogba ewon n'Ilorin ni okunrin birikila kan, Ogbeni Bashiru Abdukareem, eni to sa Ogbeni Olasunkanmi Jamiu ladaa pa lakooko ayeye awon odo kan niluu Ofa wa bayii.

Gege bi a se gbo, lakooko tawon odo ohun n se ayeye olodoodun ti won n pe ni Carnival ni won bere si i fada hale ti won si n pa igo lati je kawon araalu mo pe awon lagbara. Asiko ohun ni Jamiu n koja lo jeje e ti won si sa a ladaa pa.

Awon esun ti won fi kan Bashiru ni kootu ohun ni ipaniyan, dida alaafia ilu laamu, kiko sawon eeyan ninu lati da ilu ru ati dida egbo si eeyan lara.(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: