Ojúewé 1ti 1

Baba Arugbo Fipa Ba Omo Odun Mewaa Lo Po, Lo Ba Tunloun Ko Jebi: Baba Agbalagba Eni Ogota Odun t’Ondo Waa Lu Magun

Firanṣẹ: Ajé Oṣù Kejì 09, 2026 3:48 am
nipasẹ MediaYoruba
*Legacy Post Number 99 from MediaYoruba
Topic: Baba Arugbo Fipa Ba Omo Odun Mewaa Lo Po, Lo Ba Tunloun Ko Jebi: Baba Agbalagba Eni Ogota Odun t’Ondo Waa Lu Magun
Timeline: 2012-07-04 05:23:13


Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Baba Arugbo Fipa Ba Omo Odun Mewaa Lo Po, Lo Ba Tunloun Ko Jebi: Baba Agbalagba Eni Ogota Odun t’Ondo Waa Lu Magun

S›E lawon eeyan n rojo epe le Baba agbalagba kan, Al agba John Osunade, eni odun mejilelogota (62yrs) lori nileejo Majisreeti niluuOsogbo laipe yii, nigba ti won gbo pe se lo fipa ba omodebinrin kan, Bosede, eni odun mewaa lo po. A gbo pe se ni baba naa fogbon tan omo yii wonu ile re, to si fipa ja ibalee.

Abule kan ti won n pe ni Tonkere, nijoba ibile Ayedaade, nipinle Osun, nisele naa ti sele.

Ohun tawon eeyan n beere lowo ara won nigba ti Babanaa foju baleejo ni pe igbadun wo ni Baba arugbo yii fee je lara Bose, abi ki lo wa lokan re to fi hu iru iwa bee.

Ni nnkan bii aago marun-un irole ojo ketadinlogbon, osu karun-un, odun yii, la gbo pe Alagba Osunade tan Bose wole, to si ba a se nnkan ti ko se ri. Ni kete tawon obi Bose gbo soro yii ni won fori le ago olopaa to wa lagbegbe Gbongan, kia lawon naa si bere iwadii lati mo nnkan ti Baba Osunade ri lobe to fi waro owo. Leyin iwadii lawon olopaa gbe Baba agbalagba yii lo sileejo niluu Osogbo, nibi ti won ti fesun ifipa-ba-ni-lopo kan an.

Nigba ti won ka esun naa seti John, o loun ko jebi.Agbejoro fun ileese olopaa, Elisha Olusegun salaye pe iwa ti okunrin yii hu lodi sofinile wa, bee lo ni ijiya nla wa fun iru
ese bee labe ofin iwa odaran ipinle Osun.

Bakan naa, Agbejoro fun olujejo, Reginald Ngwu ro ile-ejo lati faaye beeli sile fun onibaara re, o ni ko ni i sa lo.

Leyin naa ni Adajo Majisreeti ohun, Olusola Aluko so fun Agbejoro olujejo naa pe ko loo ko arowa beeli re sinu iwe, yato senu to fi n so o.Aluko waa pase pe ki awon agbofinro loo fi olujejo pamo sogba ewon ilu Ilesa. O sun igbejo siwaju di ojo kerin, osu keje, odun yii.

O Doju E! Baba Agbalagba Eni Ogota Odun Mayowa Temilade t’Ondo Waa Lu Magun Lara Ololufe E Alice Titilola n’Ilesa -- Lati Bisi Adesoye, Ilesa

BABA agbalagba eni ogota odun to n sise oluko lOndo, Ogbeni Mayowa Temilade, ti lu magun lara ololufe re, Arabinrin Alice Titilola, oju ese lo si ti gbemi mi. Agbo wipe aweon mejeeji yi je omo ijosin soosi kanna ni ilu Eko ati ni Ilesha ti nwon ti mdijo ba er ife nwon bo.
Agbegbe Ilaje, nijoba ibile Iwo-Oorun Ilesa, lokunrin naa ti pade iku ojiji lojo Aiku, Sannde, tokojalohun-un. Kayeefi nisele ohun je fun gbogbo awon to gbo o.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe ojo Eti, Fraide, to saaju isele naa ni Alagba Temilade de s’Ilesa lati Ondo nitori ololufe e, lati le bara won sere ife lopin ose naa, lai mo pe ohun ti yoo pa a lo waa ba.
Won ni Titilola ti kuro lodo oko re to bi omo mefa fun, o n da gbe n’Ilaje ni. Alagba yii ni gbogbo eeyan mo gege bii oko obinrin naa, paapaa bo ti maa n wa s’Ilesa lodo re, isele yii lo je kawon eeyan mo pe ki i se oun loko re.Ileewe alakoobere kan la gbo pe awon mejeeji ti pade ara won ni bii ogun odun seyin, nibe ni won ti mu ara won loree titi di asiko ti Alice fe oko re. Leyin to ko oko re sile lawon mejeeji tun pade ara won n

’Ilesa, ti won si tun bere ere aniyan ti won ti pa ti tele.
Ohun ti akoroyin wa gbo lati odo awon olopaa ni pe leyin ti oloogbe yii lu magun lara obinrin naa, awon agbofinro to n sewadii oro ohun lawon ri ami to fihan pe se lokunrin naa n japoro lori ibusun Alice, ko too di pe o pada gbemii mi. Sugbon ki awon olopaa too gbo nipa iku baba yii, Alice ti juba ehoro loru pelu awon eru re, o sa lo patapata.

Won ti gbe oku e lo sile igbokuu-si to wa ni nileewosan Ilesa fun ayewo siwaju.


**{Legacy activities, comments etc counter: 1295; topic series: 10; forum: MediaYoruba; associated: 10- /*}