Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 100 from MediaYoruba
Topic: Ajike Ki Oko E Mole, Lo Ba Lu Bii Eni Maa Ku: E Gbo N Je O Seese Bi? Abileko Sope Iya-oko Oun Atomo E N Bara Won Sun
Timeline: 2012-07-04 05:24:01


Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Ajike Ki Oko E Mole, Lo Ba Lu Bii Eni Maa Ku: E Gbo N Je O Seese Bi? Abileko Sope Iya-oko Oun Atomo E N Bara Won Sun

AFI bii igba teeyan n wo fiimu agbelewo ni nigba ti okunrin kan, Ogbeni Ajayi Olakunle, to n gbe opopo Asa-Dam, n’Ilorin sadeede sa kuro nile fun iyawo e, Ajike Olakunle nitori pe o n lu u bii aso ofi. Eyi lo mu kawon eeyan maa so pe itiju lo mu un sa lo.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe nise lobinrin naa maa n lu oko e biibaara, bee ni ki i dana ounje fun un. Gege bi iwadii wa, ninu osu karun-un, odun to koja lawon mejeeji segbeyawo, sugbon nise lobinrin naa so pe omuti paraku loko oun, o loro e ti su oun, nitori naa, oun ko fe e mo.

Gege bi a se gbo lenu Arabinrin Ajike Olakunle, o ni eeyan yepere loko oun, dipo ko maa se itoju oun, nise lo maa n fowo muti kiri, ti yoosi maa nawo fawon ale atore e. Iyaale ile yii ni gbogbo igba to ba ti muti yo lawon eeyan maan yo owo lapo e.

A gbo pe lojo buruku yii, okunrin naa pe iyawo e, iyen leyin igba to de lati ibi to ti loo muti e pe ko ko jade nile foun, o ni awon ko le gbepo mo, bi iyawo e ti gboro to tenu e jade yii lo ba so fun un pe ko ba oun mu owo to ji lati lo muti.

Sugbon nise l’okunrin naa n se bii eni pe oun ko gbo ohun to n so rara. Eyi lo mu ki Ajike so pe dandan ni ko ba oun mu owo oun, o ni bi bee ko, wahala yoo sele laarin awon. Nigba tokunrin naa ko da a lohun lo ba fa a laso, ibinu eyi ni oko e fi fo o leti leemeji lera. Niyawo naa ba lo aso mo on lorun, o si ti i lule, lo ba bere si i ko iya fun un.

Ariwo tokunrin omuti yii pa lo mu kawon araadugbo pe le won lori. Ohun itiju to sele si baale ile yii ati bi iyawo e se maa n na an tele lomu un sa kuro nile fun un. Bee la gbo pe seeti meji ati sokoto meji lo mu dani nigba to n lo.

Nigba ti oniroyin wa beere nipa isele ohun lowo obinrin naa, o ni loooto loko oun sa kuro nile, sugbon ki i se nitori ija aarin oun ati e lo se sa jade. O ni ale e lo sa loo ba.

Ni bayii, awon agbaagba to n gbe agbegbe awon toko-tiyawo yii ti n gbe igbese lati pari ija naa, sugbon won ni baale ile naa ko, o loun ko nifee Ajike mo, o loun ko fe ko fi ogun ekute sounje foun.

E Gbo N Je O Seese Bi? Abileko Sope Iya-oko Oun atomo e n bara won sun

ARIWO e gba mi o, iya oko mi ti n gba ise mi se niyawo ile kan, Arabinrin Solifo n pa laipe yii n’Ilorin, o loun ti setan lati ko oko oun sile nitorioun n fura pe oun atiya e n bara won lasepo.

Iyawo ile naa so pe nibi toro iya oko oun buru de, oun lo n dana ounje foko to si n fo aso e to fi dori pata ataso awotele e . O ni o buru debii pe ti iya oko oun ko ba so pe ko fowo obe sile, ko ni i se be e< o si see se ki iya naa fun oun loogun je nitori ko nifee oun rara.

Solifo ni oloogun buruku ni iya oko oun, oun naa lole iyawo akoko ti omo e fe jade nile tiyen ko si ranti keru e yooku. O ni opo igba niya oun maa n so pe iyawo ti ko ba fi toun se, yoo ko jade nile omo oun losan gangan ni, nigbatoun ba fina mo on.

Nigba ti a beere oro lowo iya oko, eni tawon eeyanmo si Iya Ibadan, o so pe ara omo oun ni ko ya tiyawo e ko si dana fun un nitori ija ti won n ja. O ni iwa yii ti mo obinrin naa lara. Iya agba yii ni loooto loun ba a fo pata ati awotele, nigba tiyawo e ko bikita fun un.

O ni oloorun ati alagidi ni Solifo, idi niyi tomo oun fi fee ko o sile niyen, bo tile je pe oun ni ko ro tomo to bi fun un.

O·gbeni Aderemi loun ko loro kankan lati so, o ni akeregbe ni yoo juwe ibi tawon yoo ti okun bo lara e. O ni o di ile keta toun yoo gbe bayii nitori ija ojoojumo pelu araadugbo to wo iyawo oun lewu. Alaye re ni pe aipe yii lawon tun ko de agbegbe Stadium Road, tawon n gbe yii nitori oun ko fe wahala rara. O ni ko fee ri iya oun soju, eyi ti ko si see se.


**{Legacy activities, comments etc counter: 607; topic series: 8; forum: MediaYoruba; associated: 8- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Ajike Ki Oko E Mole, Lo Ba Lu Bii Eni Maa Ku: E Gbo N Je O Seese Bi? Abileko Sope Iya-oko Oun Atomo E N Bara Won Sun



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn