Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 102 from MediaYoruba
Topic: Kayeefi Kan Ma Tun Ree Ni Badagry Rahimant Bi Omokunrin Leyin Odun Meeedogun To Ti Wa Nile Oko
Timeline: 2012-07-04 05:28:09


Lati Owo Taofik Afolabi

Kayeefi Kan Ma Tun Ree Ni Badagry Rahimant Bi Omokunrin Leyin Odun Meeedogun To Ti Wa Nile Oko

Ki i se nnkan tuntun pe ti obinrin ba bimo sile aye, tomo naa ba je okunrin, o di dandan ki won dabe tabi kola fun un.

Itumo eyi ni pe won yoo ja nnkan jolojolo to bo nnkan omokunrin e, leyin eyi ni won too ka a si omokunrin nitori ko ni i le ba obinrin se afi ti won ba ge kinni yii kuro.

Laye atijo, omo maa n dagba daadaa ki won too ge e. Elomi-in a tie ti dagba debii pe yoo mo daadaa bi won ba fee dabe fun un, awon agbalagba to ba si wa nitosi ni won yoo di iru eni bee mu nitori yoo ti di gende.

Sugbon laye ode oni, bomo ba ti pe ojo mejo ni won yoo gbe e lo si osibitu lati dabe fun un. Idi ti won fi n tete se eleyii lode oni ni pe won gbagbo pe yoo din irora omo naa ku nitori bo ba se n dagba si ni irora naa yoo maa po si. Kayeefi ti Iwe Iroyin Yoruba ri lose to koja yato si gbogbo eyi ti a ka kale yii, ohun ti a ko gbo ri lo waye.

Omokunrin kan ni won bi, sugbon dipo ki awon obi re maa duro de ojo kejo tabi igba to ba ro won lorun lati dabe fun un,won ti da abe omo yii lati orun, bee lo si se gbe e wa sile aye. N lawon eeyan ba n pe wo omo naa pelu nnkan iyanu to sele si i.

Ojoru,Wesde, to koja lohun-un nisele kayeefi ohunsele si awon tokotaya kan niluu kekere kan ti won n pe ni Shito, nijoba ibile Badagry, nipinle Eko. Arabinrin Rahiman Joke Mafus lo bimo tuntun, ti inu baba olomo ati iya si n dun pe oore ayo sele nile awon.

Ojo yii gan-an niya olomo tuntun ati omo e kuro lodo noosi to bimo si ni Ara Adagun, nito si Badagiri. Se omobinrin to bimo yii ko kuku mo pe nnkan abami kan wa lara omo oun, ohun to saa mo ni pe omokunrin loun bi, bee si ree, noosi to gbebi fun un ti ri kinni ohun, obinrin noosi naa ti ri nnkan iyalenu to sele somo tuntun jojolo yii, sugbon se lo pa a mora, to fi oro naa se awo sikun ara re.

Pelu idunnu ati ayo lawon olomo fi gbe omo won lo sile lale ojo naa, bi won se dele ni ore iya olomo we omo, ti won si wo aso mi-in fun un. Se okunkun kuku ti bole, obinrin to we omo yii ko ri kinni kan to se ajeji lara ikoko yii.Sugbon nigba tile ojo keji mo ti won fee we omo tuntun yii ni ore iya olomo sakiyesi pe omo tuntun yii ti da oko; wa lati orun.

Ariwo ni obinrin yii pa, o pe baba olomo, iyen Alaaji Mafos pe ko waa wo nnkan iyanu toun ri lara omo won. Sugbon dipo ki baba ikoko loo wo ohun ti obinrin yii ri, nise lo so fun un pe eru n ba oun lati waa wo ohun ti arabinrin naa n so.

Loooto won we fun omo yii, won si wo aso fun un, sugbon obinrin to we omo naa ko yee pariwo fun awon olomo pe oun ri nnkan abami lara omo won. Ojo keji lawon to lomo yii too gbo oro si obinrin yii lenu ti won si gba lati wo ohun to n se e ni kayeefi ohun, asiko yii lawon naa too ri pe omo won ti dako wa lati orun. Se lawon eeyan naa n fowo luwo, ti won si n woju ara won pe iru ki leleyii Eledumare o.

Loju ese lobinrin to bimo yii ki foonu e mole, noosi to gbebi fun un lo pe, ohun to bi obinrin naa ni pe boya oun lo dako fun omo oun. Asiko yii lobinrin agbebi yii too so fun w on pe lojo ti won bi omo yii loun ti ri i pe o ti dako wa lati orun, sugbon oun ko mo pe iya olomo ko gbo nigba toun n so fuu un pe omo re ti dabe wa latorun. Ohun to je kayeefi nla lori oro yii ni pe ko si oju apa pe won sese dabe fun omo yii lara nnkan omokunrin e, se ni gbogbo e gbe furufuru, afi bii omo ti won ti dabe fun lati bii odun meji seyin.

Lesekese tiIwe Iroyin Yorubagbo nipa isele abami yii la te oko leti, o di ilu Shito lohun-un, a fee loo fidi isele yii mule. Oro yii la ba lenu awon eeyan to waa ki awon olomo tuntun yii lojo ti a debe. Ohun iyanu ti awa naa koko ri ni pe se ni omo naa n pa itan e mo nnkan omokunrin e nigba ti a fee ya foto e, bee lo teju mo eni to fee ya aworan e yii bii eni pe omo ohun ti a waa se. Lati tubo fidi isele yii mule daadaa, akoroyin wa ba awon olomo yii soro, bee la ba obinrin to koko we omo yii ni gbolohun, ti a si tun fese kan de odo obinrin noosito gbegbi fun un niluu Araadagun. E wa nnkan fidi le tabi ki e fidi le nnkan ki e gbadun ohun ti a mu wa fun yin lati ilu Shito, nitosi booda Seme.

áArabinrin Rahimat Joke, Mama to bi omo yiiâ Iwe Iroyin Yoruba> E daruko yin fun wa lekun-un-rere Arabinrin Rahimmat Mafos Emi ni Rahimat Joke Mafus
Iwe Iroyin YorubaBawo loro omo yin ti e sese bi yii se je@ Arabinrin Rahimat Mafos> Mo koko fee fi oro mi dupe lowo Olorun, nitori pe,áo bu sekunâki i se baba omo yii ni mo koko fe, eni ti mokoko fe laye mi ni eni akoko to ba mi lajosepo ri laye, ere ti a si se lojo naa di oyun,sugbon omo naa pada ku. Lati igba naa ni mo ti n wa omo, mi o si oyun lati aaro dale. Ko sibi ti mi o de, mo kan n saajo kiri, enu e ni mo wa titi di odun meeedogun nile oko lai bimo.

Lojo kan ni oko mi lo siluu won tawon obi e si gbaa nimoran pe ko wa iyawo mi-in fe. Bo se de lati ilu won lo so fun mi pe ki n wa oko temisiwaju. Bi mo se kuro nibe ni mo pada sodo baba mi, mo so fun won pe mi o setan lati fe oko miin mo nitori pe wahala awon okunrin po, sugbon baba mi ko gba, ko pe ni mo tun pade okunrin kan ladugbo wa toun naa so pe oun yoo fe mi. Koo naa lo tun ja si. Ori irina n wa omo yii naa ni mo wa ti mama mi fi kuáo tun bu sekunâsugbon ki won too ku, won so fun mi pe lagbara Olorun,momaa bimo.

Asiko naa ni mo tun pade aafaa kan to n se aajo funmi, aafaa yii lo je ki n mo pe obinrin ni eni to wa nidii oro mi, sugbon won so pe awon ko ni i so eni naa fun mi, won ni ti mo ba mu awon de odo baba mi awon yoo foju kan eni naa. Enu e la wa ti baba mi pe mi pe ki n wa pe awon fee fi aafaa kan to wa lati ile hausa han mi.

Nigba ti mo debe lo di awon aafaa Mafos ti mo padafe yii. Loooto mo ti mo won tele, ko si eni ti awon naa ko mo ninu ebi mi. Saaju ki won toowa ni aafaa ti mo so pe o n se aajo fun mi ti so pe eni ti mo maa fe yoo je eni to maa n paowo da, ti o si maa n gbadura daadaa, won ni eni naa le je musulumi, kristeni tabi babalawo, sugbon eni to maa n sise igbala awon eeyan ni yoo je, ati pe mo gbodo kuro nile wa.Se ni mo so fun won pe nibo ni mo ti fee ri eni yii, igbagbo ti mo ni ni pe oba afinimona ni Olorun, yoo to mi sona lati ri eni naa, yoo gbe mi pade e.

Bi a se de odo awon aafaa Mafos ni oteeli ti won de si, won se awon ise kan fun mi, sugbon lojo naa ni baba mi so fun mi pe awon lalaa ri baba awon, won si so fawon pe Aafaa Mafos ni oko mi, se nimoso fun won pe se won fee fi mi loko ni, sugbon won taku pe nnkan tawon fe niyen. Ohun ti mo so fun won lojo naa ni pe ki won je ki n loo ro o, bi mose kuro lodo won nimoloo ba aafaa to n saajo fun mi, mo salaye ohun ti mo ba bo lodo baba mi fun won, won beere oruko okunrin naa, ohun ti won so ni pe dajudaju oko mi niyen, sugbon ki n fara bale fun un. Oorun akoko ti emi ati Aafaa Mafos sun lo di oyun omo yii.

Iwe Iroyin Yoruba>Kin ni iriri yin nigba ti e wa ninu oyun omo yii@ Arabinrin Rahimat Mafos> Lara ohun ti mo sakiyesi ni pe ti mo ba jokoo, imole yoo tan si ara mi bii ina NEPA, se ni mo maa n so pe iru ki lele yii. Ohun ti aafaa mi yen so ni pe omo ti mo fee bi yii, omo nla ni< o ni ki n ma ra aso awin tabi awon nnkan ti yoo lo lawin fun un rara.Oku ojo meje timo fee bimo, se ni oju n yo mi lenu, ti omi yoo maa jade nibe burukuburuku, bee ni mi o ki n roorun sun loru. Ohun to jo mi loju ni pe lesekese ti mo bimo ni oju to n yo mi lenu lo. E wo o, ope nla ni oro mi gba.

Iwe Iroyin Yoruba>Ta lo koko we fun un@ Arabirin Rahimat Mafos> Ore mi ti a jo n gbele lo koko we fun un, ile ti su lojo ti a koko dele lati odo noosi, won kan we fun un die lale ojo naa ni. Nigba ti won fee we fun un

laaaro ni won ri oko yen daadaa pe won ti da a latiorun, nise ni won pe oko mi pe ko waa wo nnkan tawon ri, se ni eru n ba baale mi, won kole sun mo ibi ti won ti we omo naa.

Emi gan-gan ko ka oro naa kun rara, sugbon nigba todi irole ti won tun fee we fun un ni won tun so pe ka wo ohun tawon ri, awa molebi wa nibe nigba naa, emi tie n ba won se yeye pe se oko omo mi ni won n pe wo bee. Nigba to di ojo keji ni mo wo daadaa, ti mo ri i pe won ti da oko fun un, loju ese ni mo pe noosi.

Mo beere lowo won pe boya awon ni won da oko fun omo, ohun ti won so ni pe awon naa ti ri i bee, ki n too gbe e kuro lodo awon. Awon egbon mi ni won je ki baba mi mo ohun to sele. Iwe Iroyin Yoruba>Awon alawo le maa n la nigba ti e wa ninu oyun e@ Arabinrin Rahimat Mafos> Mama mi ni mo maa n ri lopo igba, lara e ni lojo kan ti mo ri awon omo to po niwaju mi, sugbon se ni mama mi toka si omo kan ninu awon omo naa pe omo ti mo maa bi niyen.

Alaaji MafosáBaba ommoââ Iwe Iroyin Yoruba> E daruko yin fun wa Alaaji Mafos>Oruko mi ni Mafos, omo bibi ilu Katsina ni mi.

Iwe Iroyin Yoruba> Bawo loro omo yin seee je@ Alaaji Mafos> Se e ri ohun to sele yii ko jo mi loju, idi ni pe lati odun kokandinlogbon ni mo ti ngbadura si Olorun pe ko fun mi ni waliyi lomo, aago meta oru ni mo maa gbadura yii lati odunkokandinlogun seyin. Mo si dupe lowo Olorun pe o gba adura mi. Aafaa kan ti rina simi tele pe omo nla ni mo maa bi. Iwe Iroyin Yoruba> Bawo le see pade iyawo yin@ Alaaji Mafos>Eeyan mi daadaa ni baba e, ki i se ajoji si mi rara, sugbon oko meta lo ti fe ko too de odo mi ti ko si romo bi nibe, eekan soso ti mo ba a lajosepo ni Olorun gba adura e. E je ki n so kinni kan fun yin, lati inu oyun ni mo ti mo pe omo nla ni omo yii, idi ni pe nibi ti mama e ba jokoo si, se ni imole yoo wa nibe, ti yoo tan sibe.

Ni ijeta ti a sun, iru e tun sele. Se ni kinni ohuntan sibi ti a gbe e si, emi tie ro pe awon aje lo wa. Nise ni mo so fun iyawo mi pe ko ba mi mu obe mi lati fi gun aje naa, laimo pe ara omo ni imole naa wa.

Bee si lo je pe ki i fe ki eeyan fowo kan nnkan omokunrin e. Ki n ma paro fun yin, emi o koko kobi ara si i nigba ti eni to n we fun un so pe won ti da oko fun un lati orun, leyin ojo keta ni mo too wo o. Adura ti mo gba si Olorun ni pe ko fun mi lomo olokiki, ti gbogbo aye yoo mo. Loju ese ni mo pe aafaa mi, ohun ti aafaa mi so ni pe sebi oun ti so fun mi pe omo nla ni mo maa bi. Se ni omo naa maa n rerin-in to ba ti ri mi, ti yoo maa wo mi. Ki i se pe mo ni i lokan lati fe iya re, baba e lo so pe oun lalaa pe emi ni yoo fe.

Iwe Iroyin Yoruba> Seee eyin ko i ti i fe iyawo ri tele ni@ Alaaji Mafos>Mo ti fe iyawo tele, to si bi omo kan fun mi, sugbon o ti ku bayii. Ilu Meka lo ku si. (Obinrin to koko we fun omo naa) Iwe Iroyin Yoruba> E daruko yin fun wa lekkun-un-rerre Arabinrin Atiku Naimot Iwe Iroyin Yoruba> A gbo pe eyin le koko we omo yii, ki lo sele gan-an@ Arabinrin Atiku Naimot> Ore mi ni mama e, a jo n gbe ni, omo naa da a laamu pupo ninu oyun. Lojo ti omo mu un, o so fun mi pe oun n lo si osibitu, mo si fi adura sin in. Leyin wakati meji lo pe mi pe oun ti bimo, loju ese ni molo sibe, emi ni mo so fun noosi pe ki won je ki a maa lo sile lojo naa niwongba ti ko ti si ohun to se iya atomo. Aago meje abo ale la de ile lojo naa, iyen ni ko je ki n we fun un daadaa.

Sugbon nigba ti ile ojo keji mo ti mo tun fee we fun un ni mo sakiyesi pe won ti da oko fun un, se leru ba mi, ti mo pariwo pe, “Ki ree”, se ni mo n saa n wo o, nigba ti ko ye mi ni mo pe baba e pe ko waa wo ohun ti mo ri, se ni ko da mi lohun. Nigba to di irole ti mo tun we fun un ni mo tun so fun awon molebi iya omo, lasiko naa la tun wo o daadaa ti a ri i pe won ti da oko fun un.

áNoosi to gbebi fun omo naaâ Iwe Iroyin Yoruba> E daruko yin fun wa. Arabinrin Oluwayemi Obalola Iwe Iroyin Yoruba> A gbo pe ey in le gbebi fun won, ki lo sele gan-an@ Arabinrin Oluwayemi Obalola> Ohun to se l e ni pe won ti da abe fun omo naa lati orun, bi mo se ri i pe okunrin ni ni mo so fun mama e pe okunrin ni, bee ni mo so fun eni ti a jo gbebi fun un pe omo naa ti dabe wa lati orun.

Ohun ti mo ro ni pe ami igba ikeyin lo sele yii. Nigba ti won pe mi lojo keji pe awon ri i pe won ti dabe fun un, mo so fun won pe emi naa ti ri i bee tele. Ju gbogbo e lo, kayeefi nla si loro yii je fun gbogbo awon to ti gbo nipa e.


**{Legacy activities, comments etc counter: 2014; topic series: 6; forum: MediaYoruba; associated: 6- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Kayeefi Kan Ma Tun Ree Ni Badagry Rahimant Bi Omokunrin Leyin Odun Meeedogun To Ti Wa Nile Oko



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn