Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 103 from MediaYoruba
Topic: Ofin Yoo Maa Fiya Je Eni To Ba Dale Soju Titi—Asofin Eko: Ajo NBTS So Idi Toseye Ki Awon Eeyan Maa Fi Eje Sile Lofee
Timeline: 2012-07-04 05:30:12


Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan ati Alabi Adeola, Ile Igbimo Asofin Eko

Ofin Yoo Maa Fiya Je Eni To Ba Dale Soju Titi—Asofin Eko: Ajo NBTS So Idi Toseye Ki Awon Eeyan Maa Fi Eje Sile Lofee

ALAGA igbimo to n mojuto eto ayika nile igbimo asofin Eko, Abiodun Tobun, salaye lose to koja pe awon n sise lowo lori ofin ti yoo maa fiya je awon to ba n dale¯ kiri oju titi.

Asofin yii salaye oro naa nibi ipade to se pelu awon oniroyin laipe yii. O ni, A ti n sise le e lori, a woye pe ti iya gidi ba ti wa feni to ba hu iru iwa bee, iyen ki won maa dale kiri oju titi, yoo je kawon eeyan dekun lati maa se bee.

A ti gbiyanju iru nnkan bee ri nigba ti mo wa ninu isakoso ijoba ibile, nigba tokunrin kan kuro nile e pe oun n lo si pati lakooko eto gbale-gbata. Awon agbofinro mu un, won si ri i pe won fi oko e kole fodidi ose kan gbako. To ba je pe a kan ni ko sanwo ni, i ba se e pelu irorun, sugbon iyen ko ni i ni ko jawo ninu iru iwaarufin bayii.

Asofin naa ni ki i sowo itanran tabi ewon lawon arufin yii yoo maa fi gbara, nitori pe ewon gan-an ti kun, awon ko si nifee lati maa ran awon eeyan lo sewon. Yato siyen, awon tun fee maa se idanilekoo fawon ara Eko, kiluu yii, paapaa Naijiria lapapo, le di ibi to dara.

O fi ro awon eeyan lati ma maa kole fawon akole mo,bee si lo ni ki won maa ko gota won ni gbogbo igba.

Ajo NBTS so idi toseye ki awon eeyan maa fi eje sile lofee: Ofin yoo maa fiya je eni to ba dale soju titi—Asofin Eko

S›E lawon eeyan n rojo epe le Baba agbalagba kan, Al agba John Osunade, eni odun mejilelogota (62yrs) lori nileejo Majisreeti niluuOsogbo laipe yii, nigba ti won gbo pe se lo fipa ba omodebinrin kan, Bosede, eni odun mewaa lo po. A gbo pe se ni baba naa fogbon tan omo yii wonu ile re, to si fipa ja ibalee.

Abule kan ti won n pe ni Tonkere, nijoba ibile Ayedaade, nipinle Osun, nisele naa ti sele.

Ohun tawon eeyan n beere lowo ara won nigba ti Babanaa foju baleejo ni pe igbadun wo ni Baba arugbo yii fee je lara Bose, abi ki lo wa lokan re to fi hu iru iwa bee.

Ni nnkan bii aago marun-un irole ojo ketadinlogbon, osu karun-un, odun yii, la gbo pe Alagba Osunade tan Bose wole, to si ba a se nnkan ti ko se ri. Ni kete tawon obi Bose gbo soro yii ni won fori le ago olopaa to wa lagbegbe Gbongan, kia lawon naa si bere iwadii lati mo nnkan ti Baba Osunade ri lobe to fi waro owo. Leyin iwadii lawon olopaa gbe Baba agbalagba yii lo sileejo niluu Osogbo, nibi ti won ti fesun ifipa-ba-ni-lopo kan an.

Nigba ti won ka esun naa seti John, o loun ko jebi.Agbejoro fun ileese olopaa, Elisha Olusegun salaye pe iwa ti okunrin yii hu lodi sofinile wa, bee lo ni ijiya nla wa fun iru
ese bee labe ofin iwa odaran ipinle Osun.

Bakan naa, Agbejoro fun olujejo, Reginald Ngwu ro ile-ejo lati faaye beeli sile fun onibaara re, o ni ko ni i sa lo.

Leyin naa ni Adajo Majisreeti ohun, Olusola Aluko so fun Agbejoro olujejo naa pe ko loo ko arowa beeli re sinu iwe, yato senu to fi n so o. Aluko waa pase pe ki awon agbofinro loo fi olujejo pamo sogba ewon ilu Ilesa. O sun igbejo siwaju di ojo kerin, osu keje, odun yii.


**{Legacy activities, comments etc counter: 456; topic series: 5; forum: MediaYoruba; associated: 5- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Ofin Yoo Maa Fiya Je Eni To Ba Dale Soju Titi—Asofin Eko: Ajo NBTS So Idi Toseye Ki Awon Eeyan Maa Fi Eje Sile Lofee



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn