Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 104 from MediaYoruba
Topic: Nnkan N Be O, Niluu Aawe: Dayo Koju Ija Si Ale Oko E, N Lobinrin Naa Ba Lu U Loogun - O Sele Kunle Lu Magun!
Timeline: 2012-07-04 05:31:44


Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Nnkan N Be O, Niluu Aawe: Dayo Koju Ija Si Ale Oko E, N Lobinrin Naa Ba Lu U Loogun - O Sele Kunle Lu Magun!

INIRA kan ko tun gbodo ju bee lo fun eeyan mo. Obinrin naa n gbo diedie ninu oro teeyan ba n so loju e sugbon ko le so gbolohun gidi kan soso bayii jade lenu. Eni ba ri i bo se n lakaka lati soro yoo ro pe odi ni lati iberre aye e, idi ni pe oro to nitumo kan ki i jade lenu e, owo lo fi maa n juwe, ona to n gba bawon eeyan soro ko ju bee lo, a tun fi ko maa dun bii ojulowo odi ti ko le gbo, ti ko le so.

Bee Abileko Adedayo Ogunbode ki i se odi. Aye lo so igba dogbun, igba ko deede gbun. Ija kan to waye laarin oun pelu obinrin kan ti won pe ni ale oko e to n je Abileko Oketokun Afusa topo eeyan mo Iya Adua lo so o da bee.

Ni nnkan bii aago marun-un irole ojo Isegun, Tusde, to koja la gbo pe Abileko Dayo tawon eeyan tun mo si Iya Bolu loo ka Iya Adua mo soobu to ti n taja lagboole Lagbede Akinye, niluu Aawe, nipinle Oyo nitori o gba pe obinrin naa n yan oko oun lale, awon mejeeji si lu ara won bii ki won pa ara won ku yan-an-yan-an.

Abalo ababo ija ohun lo so Iya Adua di alaaare, o nje irora egbo nla kan to wa legbee e nibi teni to n ba ja ti deyin de e karakara. Sugbonkekere ni eyi legbee ijamba to se Iya Bolu, ese kan aye ese kan orun lobinrin naa si wa bayii nitori won ni oyun osu merin ti baje mo on lara, inu inira to si wa ko se e fenu lasan royin, nnkan ti n yiwo lo. Inu fuu aya fuu lawon ebi oko e paapaa wa bayii nitori won komo odo ti won yoo dorunla si mo lori oro naa.

Abileko Dayo ko le duro lo titi, ko le bere rara, bee ni ko le sun bii ti i wu ko mo. Bo se n kigbe ori fifo, bee lo n pariwo eyin didun ati ara riro. Bo ba si diwo mo eti e mejeeji nigba mi-in, omi gbigbona kan bayii lo n sun poroporo jade nibe bii omi seleru. Loju akoroyin wa tile ni obinrin ti won pe leni odun marunlelogbon to ti bimo marun-un yii ti daku nirole ojo to debe fun iwadii isele ohun.

Bo tile je pe Iya Adua lo loo fi ejo sun lagoo olopaa ni Durbar, niluu Oyo tawon olopaa fi mu Dayo, Ogbeni Idowu Ogunbode ti i se oko e, ohun kan naa ti Iya Bolu n tenumo ni pe aisan to se oun yii ki i se oju lasan, o ni nise niIya Adua na oun loogun ati pe inira toun n ri lowo yii koja siso.

Gege bi won se lobinrin to ti to eni odun marunlelogbon yii se so, o ni Afusa tu ibante kan nidii lasiko tawon n ja, o ka a bo oun. Bee loso pe leyin igba tobinrin ti won n pe ni Iya Adua naa da oun mole tan lo tun ro oogun kan soun lenu.

Obinrin kan toro soju e, Oloye Motunrayo Iyabo Ajeigbe to pera e ni Iyalode Afijio salaye fakoroyin wa pe obinrin yii (Adedayo) so pe o fi nnkan nu oun lara ni. O lo waa ba oun ninu ile nibi, o fi nnkan nu oun lara, o si fi nnkan soun lenu.

‘’Iya Adua ti koko lu u ninu ile e nibi, Dayo waa fejo sun mi. Nigba to setan to n lo leyinkule mi loko Iya Adua tun wa pelu e, bawon mejeeji se tun ra a mu ti won jo n lu u
niyen. Ariwo won ni mo gbo ti mo yoju si won. Igbati ma a fi debe gan-an, awon eeyan ti po nibe. Sugbon won ko saa ri won la, debii pe atoko, atiyawo, awon mejeeji ni won n lu u.

“Igba toko e gbe e soke, o la a mole, bi Dayo se daku niyen, a ba sare gbe e lo sileewosan aladaani. Won ko o, ba a se gbe e lo sileewosan Jenera niyen. Jiji to maa pada ji, ko le soro mo.”

Iyalode so siwaju pe, ‘’Iya Adua ti waa na emi naa ri, o ni mo fee fi omo mi fun ale oun. Won si bi ale, (oko Dayo) naa loooto, o ni bee lo ri, o ni koda, o la omo lo, o ni sugbon ki oko e ma tori e pokunso loun ko se gba omo oun. Bo se rojo yen fawon SARS niyen.

Lati ojo Tusde to ti sele, ko ya si i, afi bo setun waa fi olopaa SARS mu wa, sugbon awon yen ti gba beeli mi.’’ Ninu oro Abileko Ogundoyin Ogunkolade ti i se iya oko Dayo, o ni oro naa ti di ohun ti Alaawe tiluu Aawe, Oba Abiola Collenius Taiwo Oladokun Keta n da si leyin ti won ti gba beeli awon nigba ti Iya Adua folopaa mu oun atomo oun.

Gege bo se so, ‘’Lanaa ojo Eti, Fraide, to koja la lo aafin Alaawe.

Mo salaye ohun to sele, mo ni omo Tukowo niluu yiilo lu omo mi.

Iya Adua waa fi ye won pe ohun to maa mu omo gbadun, oun maa se e. O ni sugbon o di ojo meje ko too gbadun, o ni funra oun loun yoo maa toju e ti yoo fi gbadun.

‘’Leyin naa ni Alaawe atawon ijoye e pe emi ati Tukowo, iyen iya to bi Iya Adua pelu oko e ati Iya Adua funra e wole. Awon Oloye be e, won ni ka loo maa be e pe ko le tu Dayo sile.Loju Iya Adua to sise yen naa ni won ti so o o. Oun naa si seleri. “Ba a se waa wole lanaa, Iya Adua lo sile e, o loo mu ose ati kainkain pelu ororo, o waa fi we omo yii. O tun ji wa laaaro yii, o waa we fun un. Koda gan-an, o tun loun tun maa mu un lo sibi kan lola lati loo toju e.’’ Oko Dayo, Ogbeni Idowu Ogunbode tawon eeyan mo si Small lo mu ki oro naa tubo loju si i pelu bo se jewo pe loooto loun pelu Iya Adua yan ara awon lale ri bo tile je pe ko si ohun to jo bee laarin awon mo.

Nigba to n salaye ohun to mo nipa ija iyawo e peluale e ohun, Small so pe, “Emi o si nile lojo yen, mo lo soko. Bi mo se de ni mo gbo pe wonja. Mo sare wo aarin won lo, mo la won.

Igba ti mo la won tawon mejeeji subu lule loko Iya Adua ni ki n waa gbe oku ti mo pa sile, mo ni oku wo lo wa nile, sebi mo la won ni. Igba tima a fi ni ki n gbe iyawo mi, won ti loo mu olopaa waa mu wa.

“Ara bere si i ni iyawo mi lodo awon olopaa, o daku nibe, awon olopaa so pe ka waa gbe e, a gbe e lo si Jenera Osibitu pelu oko obinrin yen naa. A se ayewo fun un nitori o wa ninu oyun.

Sugbon o da bii eni pe oyun yen ti baje mo on lara,oyun to ti to osu merin. “Igba ta a dele ni Iya Adua tun mu awon Civil Defence wa, won tun waa mu mi. Mo tun salaye oro fun won, won tun fi mi sile, won ni ki n loo toju eni ti kogbadun naa ka too le maa se ohunkohun.

‘’Sugbon ohun to fa oro yii ni pe emi ati Iya Adua ti mora tipe, orebinrin mi nigba kan ni.

Sugbon nigba to ya, mo ni mi o se mo nigba ti irin e ko ba temi mu, ati pe o ti wa nile oko, sugbon o ni rara oun ko gba.

“Ti mo ba ti wa n ba obinrin kan soro, yoo maa daamumi. Bee ko si nnkan kan laarin emi pelu e mo tipe tipe. Ohun to fa idi oro niyen. Nnkan bii odun meje la fi jo je ore. O ti to ogun odun ti mo ti feyawo mi, o si ti bimo mefa, okunrinati obinrin.’’

Ni ibamu pelu ibeere akoroyin wa, Ogbeni Idowu so pe, ‘’O ti to odun merin aabo ti emi pelu Iya Adua ko ti jo se mo. Emi pelu e si jo n se po ko too di pe mi o ba a se po mo.’’

Nje se Iya Adua bimo fun e, o dahun, o ni, Obinrin lo lomo, oun lo maa mo eni to fun oun loyun ati eni to lomo. Ki lo ro pe o fa ija laarin iyawo ati ale e, okunrin to pera e leni odun mejidinlogoji yii fesi, o ni, “Ohun ti Iya Adua so fun iyawo ile mi ni pe nitori pe mo n ri ese fi rin lemi se n fe iyawo, ti mo n ba awon obinrin soro, ti mo se n se gbogbo ako yii. Ohun tiyawo ile mi gbo niyen to fi yari, to fi loo ba a ja.

‘’Ile mi nibi ni Iya Adua ti waa soro yen, bi iyawo ile mi se loo binu ba a niyen ti won tun fi bere si i ja lagbo ile Oosa, lagbo ile Iya Adua. Igba ti mo ti oko de ni mi o ba iyawo mi nile ti mo gbo pe won n ja nile Iya Adua.”

Sugbon loju ese ni Dayo ti ja oro gba mo oko e lenu to si ja lati tan imole soro naa pelu bo se n fowo atawon eya ara e mi-in soro. Gege bawon ara ile won toro obinrin alaisan yii ye se tumo e fakoroyin wa, Iya Bolu salaye pe, “O·ko mi ti ni omo lodo Iya Adua. Omo yen ni irun daadaa lori nigba kan, sugbon o ti ge irun yen bayii, obinrin lomo yen, o jo Small gan-an te e ba wo o daadaa.

O naka si omobinrin won toun atoko e bi sikerin ti won n pe ni Feyintola, o ni, o jo omo to duro yen, o jo omo yen”. O fo igba yanga siwaju, o ni, “Nigba ti Iya Adua waa toju mi laaaro yii, o ba emi ati oko Abileko Adedayo mi ninu ile, o wa n fi ara ro o, awon mejeeji jo n fi ara ro ara won bayii.”

O jo pe Small ni eje Dada lara daadaa. Gege b’Iwe Iroyin Yoruba se gbo, dada ni akobi okunrin naa, bee Dada naa niyawo e so pe obinrin ti won pe ni ale e ohun bi fun un. Sugbon Abileko Oketokun Afusa ti won n pe ni Iya Adua ta ko gbogbooro ti won so yii. O ni Iya Bolu, iyen Abileko Dayo ati oko e pelu Oloye Motunrayo gan-an leeyan buburu, won kan fee so oun loruko ti ki i se toun lasan ni.

Gege bo se so, “Lati bii ijerin loro yen ti sele, ko too digba yen,iyawo e (Dayo) waa ba mi pe se mi o ri oko oun, mo ni mi o ri oko re ni soobu mi o. O ti na mi ri, eyi lo siketa to maa na mi.

“Nigba to wa nijerin yen, ni nnkan bi aago marun-un,o roso mo idi bayii. O loun gbo pe Fulani kan so pe oko oun wa si agboole wa nibi, pe o wa leyin odo wa nibe yen to n je eran adie, mo ni ko kan mi. Ohun to si sele ni pe Small n fe omo iyakan to n ta oti nibe (Oloye Motunrayo).

Iyen ni Iya Bolu wa n bi mi pe se mi o ri oko oun nibe, mo si ni ko si eyi to kan emi nibe.

Bi mo se gbe tiree suuti kale niyi to bere si i ko suuti mi sinu aso. Mo ni se ki i se pe e muti yo.

Mo ba tu iro nidii e, suuti da sile. Bo se loo mu oko e wa nile niyen, oun ati oko e ba n na mi.

Won ge mi je, won bu mi leyin lejika. Igba ti mo n sa lo, won tun le mi. Bi iyawo e se fa leesi ti mo wo lati eyin niyen. Bo tun se deyin de mi lowo niyen.

Won na mi subu sibi saaree nibe yen. Bo se di pe a n kaakiri niyen. Bi mo se daku niyen. Bi oko mi se de lo so fun Small pe, Eran to o pa, wa maa je e o. Nigba ta a si fi n ja niyen to lo sile, sokoto lo loo wo. Bi oun ati oko e saa se lu mi daku niyen.

“Awon araadugbo ati oko mi ba gbe mi. Didide ti mo dide, aago olopaa ni mo n sare lo. Won beere oko mi, mo ni won ti yaso mo awon naa lorun, won si ge awon naa je. Bi a se loo pe awon olopaa niyen. Oloye kan waa ba mi be awon olopaa pe ki won je ka yanju e nitori mo so fun un pe N80,000 (egberun lona ogorin naira) mi tisonu nitori mi o fi enikan kan so igba nigba yen.

Ninu oro tie pelu Iwe Iroyin Yoruba, Alagba Oketokun Akano tii se oko Iya Adua so pe, Inu agboole lemi wa lojo yen, mo kan n gbo ariwo ni pe eni te e ma n na lo ti daku yii, lemi se jade. Mo ba iyawo mi nibi to ti daku sile ninu ogba wa legbee saaree. Small ti n sa lo, mo ni eran to o pa, wa a gbe e’’.

Omo bibi inu baba yii kan to n je Kafayat Oketokun so fakoroyin wa pe, Nitori oro yii ni mo se wa lati Eko nigba ti mo gbo pe won lu baba mi. A jo lo si aafin lanaa ni.

Won ti ni ki Iya Adua sadua fun obinrin yen, o si ti sadua. Awon kan ti waa so fun wa nibi pe obinrin yen n dibon ni.

Nigba ti won de SARS ti won ni ki won maa rojo lo bere si i se bii odi. Iya Adua si ni ki won je koun gbe e lo si Osogbo fun itoju, won ko dahun.

“Small funra e so fun mi lanaa pe ise esu ni. O loun ati Iya Adua ki i ja. Awon ni won waa na Iya Adua mo soobu pelu baba mi. Ka pe mo wa nile ni, iba ju bayii lo nitori mi o ba ba won fa a gidigidi’’.

Sugbon ohun to je iya oko Dayo atawon ebi oun funrae pelu awon ore ati ololufe e logun bayii ni bi arewa obinrin naa yoo se gbadun, ti yoo si bo ninu inira nla naa.

O Sele! Kunle Lu Magun Lara Iyawo Babalawo: Iya Laide Da Omi Efo Gbigbona Le Ale Oko E Lori -- Lati Owo Idris Alooma, Ilorin

Titi di bi a se n koroyin yii, awon molebi Kunle Semiu to lu magun lara iyawo Babalawo kan niluu Ofa si n toju e, bi ki i baa sawon eeyan to tete fun un lero ni, i ba ti j O·lorun nipe.

Gege bi a se gbo, o pe toko obinrin ti a foruko bo lasiiri yii ti n kilo fun un pe ko fiyawo oun lorun sile nitori oun naa niyawo tie. Oko obinrin naa la gbo pe o n sise babalawo ati sikioriti nileewe kan l’Ofa. Won lo ti figba kan ran ore Kunle si i pe ko fiyawo oun sile, aije bee, yoo kan idin ninu iyo.

Sugbon gbogbo bi won se n ba Kunle so o to, nise lo ko eti ikun si won, ko da won lohun rara. Won ni nnkan to n so ni pe iro ni won n pa mo oun, o ni lojo kojo to ba ri kinni oun ninu kinni iyawo e, nise ni ko fobe ge e.

Eyi la gbo pe o mu ki okunrin Babalawo to je oko obinrin yii dake, to si n wo awon mejeeji niran lai mo pe nnkan to fee se wa ninu e.

Leyin bii osu meta lobinrin yii yo wa sile Kunle gege bii ise e, tiyen si ba a lasepo, sugbon nise lokunrin yii takiti lori e. Eyi to mu kobinrin yii pariwo sita.

Nise lo bere si i bi, ti ko si le soro mo, n larabinrin Bola ba fee sa lo, sugbon awon to wa nibe ko je ko lo, won lawon yoo pa a danu to ba gbiyanju e. Eyi lo mu ki won sare pe awon agbaagba to wa nitosi, ti won si bere si i lo orisiirisii ero ati epa fun un kara e too bere si i wale.

Se ni Bola soju furu nigba to dele oko e pada, sugbon nigba ti yoo fi to ale, okiki ti kan de odo oko e paapaa. Awon eeyan ti ro pe okunrin naa yoo le iyawo e danu ni, sugbon nise lo rerinin muse, to se bii eni pe oro naa ko ka a lara, eyi to mu kawon eeyan so pe o see se ki nnkan miin tun wa lokan e to fee se.

Titi di bi a se n soro yii, Kunle si n gbatoju.


**{Legacy activities, comments etc counter: 1260; topic series: 6; forum: MediaYoruba; associated: 6- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Nnkan N Be O, Niluu Aawe: Dayo Koju Ija Si Ale Oko E, N Lobinrin Naa Ba Lu U Loogun - O Sele Kunle Lu Magun!



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn