Oku Awon To Ja Bo Ninu Eronpileeni Ti Di Wahala O
Firanṣẹ: Ajé Oṣù Kejì 09, 2026 4:11 am
*Legacy Post Number 105 from MediaYoruba
Topic: Oku Awon To Ja Bo Ninu Eronpileeni Ti Di Wahala O
Timeline: 2012-07-04 05:32:35
Lati Owo Ademola Adejare, Sam Akinrole, Taofik Afolabi ati Soyemi Oluyinka
Oku Awon To Ja Bo Ninu Eronpileeni Ti Di Wahala O
TITI di bi a seee n wi yii, ijoba ipinle Eko pelu ebi awon ti won ku sinu ijamba eronpileeni to sele lose to koja ko ti i mo bi won yoo see yanju wahala to ti wa nidii oro naa bayii o.
Bi awon olokuu ti n pariwo pe awon fee gba oku eeyan awon, awonn ko le fi won sile lai fun won letoo isinku to dara, beee nijoba n so pe ohun to dara ju ni ki won je kawon sin gbogbo oku naa papo, ki awon si fopin si gbogbo awuyewuye.
Latojo Aiku, Sannde, ojo keta, osu ta a wa yii tijamba eronpileeni DANA naa ti sele n’Iju-Isaga lawon ebi ti won ti ri oruko awon eeyan won ti n paara odo ijoba, ti won ni ki won ba awon gbe oku eeyan awon. Sugbon wahala wa nidii oro naa. Wahala to si wa nibe naa ni pe awon oku naa yato sira won.
Awon kan ti jona koja aala, to se pe ko senikan toda won mo mo rara. Eleyii lo n ba ijoba leru pe ki awon kan ma maa gbe oku feni ti ki i se tie, nitori awon ko mo bi awon se fee da won mo, tawon yoo si da won ya soto, pe oku eleyii ree, oku onitohun ree, ati bee bee lo. Won ni bi awon ba sin won papo, ko ni i senikanti yoo gbe oku olokuu lo sile won, ti won yoo si maa sayeye oku feni ti ki i sebi won rara.
Yato si pe awon oku kan ti jona debi pe won ko se e da mo, awon mi-in wa ti won ko tile ri rara, iye oku ti won ri sa jo, ko to iye awon tiwon wa ninu eronpileeni naa, titi di bi a se n wi yii, oku bii ogoji ni won ko ri rara, o jo pe awon yen ti jona gburugburu ki won too rina naa pa, won ko si ba nnkan kan mi-in nibe ju eegun lasan lo. Bawo
leeyan yoo se waa fi eegun da oku mo. Ibi ti wahala wa gan-an niyen.
Loooto nijoba n se orisiirisii ayewo, sugbon bi won yoo ba sayewo lati mo oku orisiirisii yii, oro naa ko ni i ya to bii awon kan se fe. Nibi toro naa tile le de, awon oyinbo ti won ku sinu ijamba naa paapaa, awon araalu won n beere oku won, awon naa ni awon fee gbe won dele. Ise nla ni awon dokita yoo se lati da eegun oku oyinbo mo si teeyan dudu.
Ana ode yii ni Gomina Babatunde Raji Fasola ba awon ebi oku lorisiirisii soro, koko ohun to si so naa ni bi won yoo se jo wa ojutuu si oro naa, ohun ti won ba le se, won ni awon n fe imoran awon toro kan gan-an.
Awon mi-in ninu awon ebi won yii ko ni suuru gbogbo eleyii, won ko si fee gbo pe boya oku awon ti jona koja idamo, tabi pe won ko da eegun oku eeyan won mo, ohun ti awon fe ni ki won saa gbe oku awon fawon. Ijoba ti koko fee lo agbara re lati so pe ko sohun ti awon ko le se bi oro ba ti da bayii, sugbon awon kan ti n leri ninu awon ti won fee gbaoku won pe bi awon ko ba ri eegun oku awon, tabi tenikeni ba da oku ti awon po mo oku elomiin, awon yoo ba ijoba sejo, ijoba yoo si je gbese nla. Ijoba ko fee sanwo itanran lori ohun ti won ko se, nitori bi oro naa ba di ti ileejo bi won ba jebi bo, owo nla niwon yoo san fun awon to wo won lo si kootu.
Lojoojumo lawon ebi oku wonyi n paara mosuari, oro naa si ka ijoba laya, o ka awon omo olokuu paapaa laya, sugbon ohun ti awon mejeeji jo n so naa ni pe a¯ro¯ kan ki i gbona jan-in jan-in ko ma role, bo pe bo ya, awon yoo yanju oro naa dandan ni.
**{Legacy activities, comments etc counter: 819; topic series: 1; forum: MediaYoruba; associated: 1- /*}