Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 107 from MediaYoruba
Topic: Awon Oloselu Ile Yoruba Ati June 12: Oloun Nikan Ni Ko Ko Wa Yo
Timeline: 2012-07-04 05:36:05


Lati Owo Ademola Adejare

Awon Oloselu Ile Yoruba Ati June 12: Oloun Nikan Ni Ko Ko Wa Yo

Ko siru ayeye teeyan kan tabi ijoba kan se fun Abiola to po ju fun un lasiko eto oselu ti a n ba lo yii, nitori bi ko ba si oun ni, boya ni a oo ni demokiresi ti a ni yii, o see se ki Abacha ma ti i ku, ko ti di anjannu si wa lorun, o si see se ko je awon ologun naa ni won yoo maa se ijoba won lo.

Sugbon Abiola fi emi re lele, ona si si fun awon oloselu gbogbo. Loooto ni awon ti won n sejoba ti n se kinni kan tabi nnkan meji lati fi seranti okunrin onisowo to di oloselu naa, sugbon awon Yoruba ko gba pe won ti se e to. Nigba ti awon n se ayeye iranti re lose to koja yii, awon kan so pe ki won fi oruko re si ipoawon olori orile-ede yii latijo, ki won maa pe e ni Aare ti won dibo yan, bo tile je pe ko raaye sejoba titi to fi ku. Awon mi-in so pe oruko ile ijoba ni Abuja gan-an tabi ile igbimo awon asofin ni ki won maa fi oruko Abiola pe, iyen yoo je ki gbogbo eeyan mo bo se je pataki to nidii oselu tiwa-n-tiwa.

Gbogbo ohun ti won beere fun un yii lo daa, gbogbo e naa lo si le to won lowo bi won ba gbe e gba ona to ye ki won gba. Sugbon awon ona ti awon oloselu Yoruba n gba yii, a oo pe tope ka too ri ohun ti a ba fe fun Abiola gba.

Nigba ti awon oniroyin yoo gbe iroyin jade nipa gbogbo ayeye ti won se fun Abiola, won ko so pe ile Yoruba lo sayeye fun un, ohun ti won nwi ni pe awon gomina egbe ACN lo se ayeye fun un. Abuku to wa nidii eyi ni pe ki i se Yoruba lo n sayeye fun un ni won n so yen, awon oloselu ACN ni, won si n royin naa bii eni pe ki i se Abiola lawon eeyan naa se ohun ti won se fun, won kan fee fi gbayi oselu lasan ni. Bee kinni kan lo ba eto naa je o, ka so pe ipinle Ondo wa ninu won ni, ko senikanti yoo so pe ACN ni, gbogbo eeyan yoo maa so pe ile Yoruba ni. Sugbon awon oloselu tiwa nibi ko le se bee, oro oselu tiwon bii iku bii iku ni, bi o ko ba ti si ninu egbe won,o ti di ota won niyen.

Nigba ti awon PDP naa ni ipinle marun-un ninu mefa nile yii, bi won ba se kinni kan ti ko si Eko nibe, won yoo so pe awon gomina PDP lo n see ni. Bee Eko ko ni i ba won se nigba naa, awon alase Eko yoo so pe Eko da duro ni, Eko ko si lara ile Yoruba to ku. Ni bayii ti ijoba wa lowo won, Eko ko da duro mo, asaaju ile Yoruba ni. Awon ohun ti a n se ti nnkan gidi ki i fi i te Yoruba lowo ree, o digbati gbogbo e ba bo rale ka to maa pariwo.

Oloun nikan ni ko ko wa yo

Awon ti n sewadii idi ti arun kansa, iyen jejere, fi n po ni Naijiria lojoojumo, to si je ti arun naa ba ti ko luuyan, ki i gboogun, afi to ba mu eni to kolu naa lo so pe eefin epo diisu ti a n fa simu lo tubo je ki arun naa po, nitori ko seni ti yoo fa epo diisu yii simu ju ti kinni naa ko ni i mu un.

Kin ni a waa fee se bayii o. Ara ilu wo lo lagbaralori oro yii ju ijoba lo. Ni asiko ti a wa yii, ile wo, tabi ileese wo ni eeyan yoo de ti ko ni i ba jenereto to n lo epo diisu nibe. O·polopo awon epo ti awon jenereto yii n fonjade lo dudu bii nnkan mi-in, bi ategun ba si ti gbe e bayii, inu awon omo eeyan lo n bo, ihoimu won ni yoo gba wole.

Kekere tun lawon eleyii o, ojoojumo ni egbaagbeje awon oko tirela n gbera lati Eko ti won yoo si la ile Yoruba koja lo sile Hausa ati ile Ibo, gbogbo bi won si ti n rin yii naa ni won n fe ategun iku kiri, nigba to se pe diisu ni epo ti won n lo, diisu naa yoo si dudu rara nigba ti eefin re ba n jade bi moto naa ba ti n lo.

Ohun to ye kijoba se ree o, bi O·loun ba ti fi ota eni han ni, ko ye ko tun le pa ni mo.

Ijoba ni ki won mo ohun ti won yoo se si oro ina elentiriiki, o ti han pe bi ina ba wa deede bayii, eefin diisu yoo dinku, arun kansa ko si ni i maa kolu araalu lojoojumo.

Bee ni ki ijoba tun ona reluwee se, ki reluwee maa ko eru nla tawon tirela n ko, ki won si ri i pe tirela to ba ti gbo ko si loju titi,ki emi awon omo Naijiria yee fojoojumo pare nitori arun jejere ti won n pe ni kansa. Eyinti e n sejoba ni Naijiria, e e si tori Oùloun ke e saanu wa!

Won tun daruko Adajo Salami si i

O·loun nikan lo mo boya awon kan wa ti won kan fee ba oruko Adajo ile-ejo Ko-te-mi-lorun, Ayo Salami je ni o, tabi ko je oun funrare lo n hu awon iwa kan ti won fi n soro e. Abi iru iroyin wo ni won gbe jade lose to koja yii, ti won so pe Salami lo ba awon da si i ki awon agbaagba ACN too gba lati mu Akeredolu l’Ondo.

Iwe iroyin Thisday lo gbe e jade nigba to n salaye bi won se mu okunrin looya naa lati je oludije loruko egbe won. Ki la waa ba lo, ki laba bo, ki lawon eeyan yoo maa so siru oro yii o. Gbogbo wahala to ba Salami nidii ise idajo to ti n se lati bii odun marundinlogoji seyin, ohun tawon eeyan n so ni pe egbe ACN yii gan-an lo ko ba a.

Bee, ni tododo, lati igba ti wahala naa ti bere, awon asaaju ati omo egbe ACN paapaa ko pada leyin re, awon ni won n pariwo oro naa, ti won si n wa awon eeyan lati sewode ati lati soro lori oro Salami yii, ti won saa n so pe ki won da a pada si ile-ejo Ko-temi- lorun ti won ti yo o. \\ Ohun to n bi awon PDP ninu niyen, ti won n so pe ACN ni baba naa n sise fun, idi to si fi da gbogbo ejo awon nu niyen. Bo ba waa je asiko ti won n so iyen lowo, ti baba naa n so pe oun ki i se omo egbe naa, ti awon ti won si mo on daadaa n so pe ki i se oloselu ni iru iroyin buruku yii tun waa jade pe oun lo n ba won da si eni ti ACN yoo fa kale lati du ipo gomina, a je pe afi ki babayii sora. Bi koko ba n fe ni lefee, eeyan ki i je ori imado, bo ba si je ori imado, ki i lo si awujo kumo, bo ba de awujo kumo lojiji, iya egbe won ni ko gbodo bu, bo ba si bu iya egbe won, koun naa ti mura lati sa ere asalaagun ni.

Ki Ayo Salami rin jinna si awon oloselu, nitori alaso-aala ni, ko jinna si awon elepo o.

Nitori Akeredolu tawon agbaagba egbe fa kale, wahala nla bere ninu egbe oselu ACN l’Ondo -- Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta S·E·E tele, ohun ti opo eniyan mo ni pe isokan lawon oludije sipo gomina labe egbe oselu ACN l’Ondo wa, ti gbogbo won si n sise papo lati ri i pe egbe naa wole ninu eto idibo to n bo nipinle naa losu kewaa, odun yii,sugbon ni bayii, wahala nla ti de ba egbe naa, to si je peiyapa nla ti bere lori bi won se so pe awon agbaagba egbe yii nipinle Eko ti fa Rotimi Akeredolu, okan ninu awon oludije naa sile lati je oludije won.

Ni ojo Aje, Monde to koja niroyin gbale pe alagatele ri fun egbe agbejoro lorile-ede yii, Oùgbeni Oluwarotimi Akeredolu, ni awon igbimo egbe naa fa kale lati gbeasia
won ninu eto idibo to n bo. Bo tile je pe awon adari egbe naa ko ti i kede omo bibi ilu O·wo· yii sita faraye gbo, sibe gbogbo awon to gbo nipa igbese naa lo tako arakunrin naa, paapaa julo awon oludije to ku.

Lowolowo bayii, awon oludije pataki mejila ninu ogbon to n dije si ipo naa lo ti fariga pe laelae, awon ko ni i gba, won tun so pe ti egbe naako ba tete yi ipinnu re pada, a je pe egbe miiran lawon n lo niyen. Ninu ipade kan tawon oludije mejila ti gbogbo won wa lati Akoko naa se ni won ti salaye pe awon asiwaju egbe naa ko gba ona to to lati fa oludije kan soso kale, won ni Akeredolu ko le jawe olubori laelae ninu eto idibo naa nitori ko seni to mo on, bee lo je pe ko gbe ile rara, ko si mo ohun to n lo ninu eto oselu ipinle naa.

O·kan ninu awon oludije naa to ba akoroyin wa soro,Seneto Ajayi Boroffice so pe ona ti awon adari egbe gba lati mu Akeredolu ko to, o ni oyato si ileri ti won se tele pe gbogbo awon oludije yoo ni anfaani lati so eni ti won ba fe pelu awon adari egbe nipinle naa.

‘’O ya opolopo wa lenu gidi nitori ohun ti a n ro ko la ba pade, awon adari egbe nipinle yii gan-an ko mo nnkan kan ninu yiyan ti won yan Akeredolu niluu Eko, eni ti ko le bori rara. Ki i se iru re lo le koju Mimiko, ko mo nnkankan nipa oselu ipinle Ondo rara, bee si ni ko gbele; ko seni to mo on ni ilu ti won ti bi i,iyen O·wo, nitori naa, a ko fara mo on.’’

Ni bayii, awon oludije mejila naa ti waa ko leta sialaga egbe naa lorileede yii, Oloye Bisi Akande lati ri si oro ohun ki won si wa woroko fi sada, bee lawon oludije naa so pe awon ko setan lati kuro ninu egbe naa ti awon adari egbe ba ti se ohun to to ati ohun to ye.

Yato si eyi, awon egbe kan to n ja fun ominira ipinle Ondo, iyen Sunshine Liberation Forum (SLF) ti ta ko mimu ti awon adari egbe naa muAkeredolu gege bii oludije sipo gomina labe egbe ACN. E·gbe naa to je pe lojoojumo ni won n kede imurasile won lati ti egbe selu ACN leyin ninu eto idibo to n bo salaye pe yiyan ti won yan Akeredolu ba awon lojiji nitori awon ko tile ro pe won le yan iru eniyan bee.

Nibi ipade oniroyin kan ti won pe, adari egbe ohun,O·gbeni Sùegun Odidi, so pe nise lawon n fokan si Seneto Ajayi Boroffice, Olu Agunloye ati Saka Lawal gege bii awon to le koju Mimiko ninu eto idibo to n bo, ki i se Akeredolu tenikeni ko mo rara. O waa salaye pe awon ko faramo oludije naa rara, awon si n seto lowo lati mo ohun to ba kan nitori awon ko le polongo ibo fun eni ti ko le wole.

S·e egbe naa lo je pe lojoojumo ni won n se eto lori redio lati ta ko isejoba Olusegun Mimiko, to si je pe opo awon omo egbe naa lo wa lati inu egbe oselu PDP ati Labour ti won si da duro, sugbon egbe oselu ACN ni won n sise fun.

Titi di akoko yii, egbe oselu ACN ko ti i so farayerara lori eni ti won fa kale lati dije nitori awon adari won ko ti i mo ona ti won yoo gba lati yanju e, sugbon arigbamu iroyin fidi e mule pe o see se kawon oludije meji ninu egbe naa, iyen Seneto Ajayi Boroffice ati Oloye Olu Agunloye lo sinu egbe miiran lati dije sipo gomina ninu eto idibo to n bo naa.


**{Legacy activities, comments etc counter: 626; topic series: 7; forum: MediaYoruba; associated: 7- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Awon Oloselu Ile Yoruba Ati June 12: Oloun Nikan Ni Ko Ko Wa Yo



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn