Fasola Seleri Lati Da Ogo Ileewe Giga Fasiti LASU Pada: Alabi Adeola, Ile Igbimo Asofin Eko
Firanṣẹ: Ajé Oṣù Kejì 09, 2026 4:33 am
*Legacy Post Number 111 from MediaYoruba
Topic: Fasola Seleri Lati Da Ogo Ileewe Giga Fasiti LASU Pada: Alabi Adeola, Ile Igbimo Asofin Eko
Timeline: 2012-07-04 05:43:43
Lati Owo Stephen Ajagbe ati Alabi Adeola, Ile Igbimo Asofin Eko
Fasola Seleri Lati Da Ogo Ileewe Giga Fasiti LASU Pada: Alabi Adeola, Ile Igbimo Asofin Eko
GOMINA ipinle Eko, Amofin agba Babatunde Raji Fasolati benu ate lu ona ti orile-ede yii n gba n fi amieye da awon eeyan lola, eyito ni ko mu ohun rere kankan jade.
Bee naa lo tun fofin de iru igbese yii nileewe gigaFasiti ijobba ipinle Eko, iyen LASU, o nijoba oun yoo ri i pe ogo ileewe naa to ti sonnu tun pada.
Gomina soro yii nibi ayeye ikeko jade eleeketadinlogun to waye ninu ogba awon omoleewe naa to wa ni Ojo, nipinle Eko. Gege bi Fasola se so, opolopo awon ami-eye ti a fi n da awon eeyan lola lode oni, paapaa julo lorile-ede Naijiria lo je pe awon ti a n da lola naa ko ye fun un rara, o ni ohun to to ni pe bi a ba fee fi ami-eye da enikan lola, onitohun gbodo ti mu ilosiwaju tabi ayipada rere ba awujo ni ipokipo to ba wa, tabi ki o ti se ohun tenikan ko se ri, eleyii gan-an lo ye ki a maa wo ni ohun amuye ni dida eeyan lola.
O ni orile-ede Naijiria to je pe a ko ri ina manna-manna lo daadaa, a o le maa fo epo wa funra wa, ile okeere la ti n fo epo, ki waa ni anfaani fifi ami-eye ti ko mu igbega kankan ba orile-ede da ni lola. Bakan naa lo tun so o di mimo pe ileewe naa yoo ni ileese redio tire laipe yii. O waa gba awon akekoogboye ohun nimoran lati gbaradi fun ipenija to wa niwaju won, o ni ko si tabi-sugbon kan nibe, awon akekoojade ohun yoo sese bere si i da opolopo nnkan se funra won ni, die si ni iranlowo tawon obi yoo maa se fun won; o ni ki won ma je eni to n wa ise alakowe kiri bii asa awon kan, sugbon ki won je eni to n dase sile dipo eni to n wase.
Awon akekoo egberun metadinlogbon le metadinlaaadorun (27, 087) lo kawe gboye nileewe ohun lodun yii.
Awon asofin ipinle Eko mu kiko ede abinibi lawon ileewe ni dandan -- Alabi Adeola, Ile Igbimo Asofin Eko
ILE-igbimo asofin ipinle Eko ti pa a lase fun ileese ijoba to n ri si oro eko nipinle naa lati ri i pe gbogbo ileewe, lati ileewe alakooberetiti de ileewe girama, ibaa je tijoba tabi ti alaadani, mu kiko eko ede abinibi wa ni pataki.
Nibi ijokoo won to waye laipe yii ni okan lara wonto n soju fun ijoba ibile Epe, Onorebu Segun Olulade, ti mu aba ohun wa. O so o di mimo peede je ohun to se pataki, ati pe kiko ede wa lawon ileewe yoo tubo gbe asa wa laruge.
Nigba ti won n da si oro ohun, awon omo ile-igbimo so pe o se ni laanu pe opolopo awon omo wa lode oni ni ko le so ede abinibi won mo nitori opolopo ileewe lo ti so kiko ede ohun nu. Bakan naa ni won tun ni opolopo awon obi naa ko ran awon omo ohun lowo nitori won ki i so ede abinibi won sawon omo nile mo, eyi to ni ko bojumu rara.
Ile-igbimo naa waa ro eka ileese ijoba to n ri soro iroyin ati ogbonisakoso lati satileyin fun ijoba nipa sise ipolongo ipa pataki ti ede abinibi n ko lawujo, ati pe kawon obi ri i pe won n so ede abinibi won loore-koore sawon omo won.
**{Legacy activities, comments etc counter: 1099; topic series: 3; forum: MediaYoruba; associated: 3- /*}