Topic: Nitori Owo Ile, Awon Omoota Paayan Marunun Ni Ilaje-Bariga: Nitori Ihale Awon Adigunjale, Awon Banki Tilekun Won Pa n’Ilesa
Timeline: 2012-07-04 05:53:51
Lati Owo Bisi Adesoye
Nitori Owo Ile, Awon Omoota Paayan Marunun Ni Ilaje-Bariga: Nitori Ihale Awon Adigunjale, Awon Banki Tilekun Won Pa n’Ilesa
Titi di ba a ti n ko iroyin yii ni awon olopaa ipinle Eko si n wa omokunrin kan toruko re n je Ibrahim, sugbon ti inagije re n je Small Jaypron. Eleyii waye nitori bi won se ni o wa lara awon to da wahala sile ni adugbo Bariga lose to koja, nibi ti eeyan marunun ti padanu emi won.
Laarin ose to koja yii nikan, eeyan marun-un lo kuninu wahala to waye ohun. Ohun ta a gbo pe o fa a ni ede aiyede to wa laarin Baale Ilaje, Kayode Aiyetiwa ati omo Baale to ti figba kan je niluu naa, Segun O·pere ti inagije re n je Shaggy.
Oro eni to lase lati maa ta yeepe laduugbo ohun atieni to lase lati maa gba owo ile lori oko oju omi to n na adugbo naa lo fa wahala. Bi awon omo eyin Baale to wa nibe bayii ti n so pe awon lawon letoo si i, bee ni awon omo eyinomo Baale to ti wa nibe tele naa n so pe awon lo ye kawon maa gba a.
Eyi lo fa yanpon-yanrin lose to koja nigba ti awonomoleyin won ohun, ti Shaggy ati Small Jaypron dari bere ija, ki awon araadugbo si too mo ohun to n sele, eeyan meta ti padanu emi won. Iwe Iroyin Yoruba gbo pe awon ohun ija oloro lorisiirisii bii ada, ibon obe, aake ati bee bee lo ni won yo sira won.
A gbo pe awon omoleyin Baale to wa nibe bayii ni iya oro naa je ju, awon ni won fara gba julo ni Ojobo, Tosde, ose to koja ti ija naa koko waye. Eyi lo mu ki won tun ara mu, ti won si pada si ibi ija naa ni Sannde, ojo Aiku,ijeta leyii ti eeyan meji mi-in tun padanu emi won.
Opelope awon olopaa to tete de sibi isele naa ni koje ki o buru ju bee lo. Latigba naa lawon olopaa ti n so adugbo naa lati le fopin si wahala ohun. Bee ni won ti kede pe awon n wa Ibrahim ti won gbagbo pe o da wahala naa sile.
Nitori ihale awon adigunjale, awon banki tilekun won pa n’Ilesa -- Bisi Adesoye, Ilesa
O›JO›BO›, Tosde, to koja yii, niseee ni awon ile ifowopamo mewaa to wa n’Ilesaa ti ilekun won pinpin mo gbogbo awon ti won feeee gbowo tabi fowo pamo.. Eleyii ko yo awon banki keekeekee bii OSCOTEC Finance Bank to wani Adeti, n’Ilesaa.
Ohun to si fa a ni ti ariwo awon adigunjale ti won ya bo ilu naa. Iwadii fihan pe nise lawon eeyan bii ogorun-un ti won duro lenu geeti First Bank wa nibe fun bii wakati marun-un si mewaa, ti won ko le wole lati gba tabi fi owo pamo nibe.
Bakan naa loro ri ni ile-ifowopamo WEMA, gboin-gboin nilekun won wa ni titi, ti awon eeyan bii aadota pada sile lai ri owo gba tabi fi pamo.
Awon ile epo to wa ni agbegbe Ilesa naa ko gbeyin ninu oro yii, won ni oju ni alakan fi n sori.
Lasiko ti a lo kaakiri Ilesa ati agbegbe re, niseni igbokegbodo eeyan dinku, awon olopaa gbe moto won si gbagede Ilesa, won si loo fara sokofun awon adigunjale naa pelu
erongba lati dana si won lara ti won ba le mu ileriwon se lati wo Ilesa.
Oga agba banki kan to ni ka foruko bo oun lasiiri so pe afaimo ki ile-ifowopamo oun ma kogba won kuro niluu Ilesa nitori wahala awon adigunjale naa.
**{Legacy activities, comments etc counter: 831; topic series: 8; forum: MediaYoruba; associated: 8- /*}