Ojúewé 1ti 1

Eemo Ni Ketu! Okunrin Bokunrin Egbe Re Lasepo Laarin Oja: Lawon Alase Oja Ba Bo Si Ihoho

Firanṣẹ: Wed Oṣu kejila 17, 2025 9:00 pm
nipasẹ NewsTeam
Eemo Ni Ketu! Okunrin Bokunrin Egbe Re Lasepo Laarin Oja: Lawon Alase Oja Ba Bo Si Ihoho

Ko soro meji to n ru awon oloja ati gbogbo awon olugbe Ikosi-Ketu nijoba ibile Ikosi-Ketu nijoba ipinle Eko loju lati nnkan bii ose meta seyin bayii ju isele abami kan to sele ninu oja ohun ninu eyi ti won ni okan ninu awon agba okunrin ti gbogbo eeyan n foju eni gidi ati alagbara wo hu.

Gege bi Irohin Yoruba se gbo, ni nnkan bi ose meta seyin ni asiri oro naa tu pe Baba kan ti won n pe inagije re ni BABA DUNLOP n ba awon odomokunrin ti o le ni ogbon sun ninu soobu re kan to wa ninu oja Jakande to wa ni Ikosi-Ketu. Baba Dunlop gege bi gbogbo eeyan se mo on si, ni won so pe o ni keke akeru bi ogorun meta (300 Wheel Barrows) ti o fi n renti ninu oja Jakande Ikosi Ketu beeni o si tun n ta taya  moto ati ti okada lawon soobu re kan to wa lagbegbe Ojota ati Maryland niluu Ekoo.

Iroyin to te Irohin Yoruba lowo ni pe Baba Dunlop ti oruko re nje Gebureli ko mo bi o se le ba obinrin lasepo afi ki o maa lajosepo pelu okunrin.

Won lo pe ti Baba Dunlop ti maa n ba awon okunrin sun  ninu soobu re to wa ninu oja Jakande Ikosi-Ketu sugbon ti asiri ko tu ki o to se eyii to bu u lowo ni nnkan bii ose meta seyin yii.

Okan ninu awon omokunrin to maa n renti keke akeru (Wheel Barrow)  lowo Ogbeni Gebureli Baba Dunlop ti o si je omo ilu Ogbomoso nipinle Oyo l'Irohin Yoruba gbo pe Baba Dunlop fipa ba lasepo ti o si fun-un ni egberun lona ogun naira (N20,000) sugbon ti omokunrin yii tu asiri ohun ti Baba Dunlop se fun-un nigba ti inira de ba a latari bii gbogbo ile iyagbe re se degbo.

Irohin Yoruba gbo pe bi eni ti nnkan baje mo lara ni Baba Dunlop se n wo nigba ti awon elegbe omokunrin yii so fun-un pe awon maa pariwo oro sita bi awon alase oja naa ko ba tete gbe igbese to ye leyin ti awon ti foro naa to won leti.

Irohin Yoruba tungbo pe egberun lona ogorun naira (N100,000) ni owo itanran ti Baba Dunlop san fun awon alase oja Jakande Ikosi-Ketu, o si san egberun lona ogbon naira (N30, 000) fawon omo iluu lati fi setutu ki ohun buruku ma ba a sele ninu ilu tori ohun ti Baba Dunlop se yii ko dun mo awon alale iluu Ikosi-Ketu ninu rara.

Bawon alase oja se n gbiyanju lati bo oro isele yii mole ni awon ebi omokunrin ba tun gbe e pada wa lati ilu Ogbomoso ti won ti lo toju e tori won ni babalawo to n toju re so pe o di dandan ki omo yii ati Baba Dunlop foju kanra ki ara re to ya daadaa.

Bi won se tun gba owo ti o je egberun lona ogbon naira (N30,000) mi-in lo je ki Baba Dunlop ro o ninu okan re pe o seese ki o je pe won fe maa fi oun jeun nipase isele yii idi si niyen ti o fi yera kuro ninu oja naa fun igba die.

Ninu iwadii ti Irohin Yoruba se lodo awon to n taja ninu oja Ikosi-Ketu sugbon ti won fe ka foruko bo awon lasiri ni a ti gbo pe o seese ki esun ti won fi kan Baba Dunlop yii je otito tori pe opolopo igba lawon omokunrin ti won maa renti keke akeru (Wheel Barrow) lodo re yii maa n ro tele e ninu oja ti won yoo si maa fowo pa a lara bi igba ti okunrin ati obinrin ba n tage.

Won ni nise ni Baba Dunlop maa rojo owo le awon omokunrin yii lori paapaa julo eyi ti o ba fowo pa a lara daadaa. Bakan naa ni won tun so pe ko si orebinrin kankan ti o maa n wa Baba Dunlop wa sinu oja naa bi o se gbajumo to.

Lati se iwadii isele yii daadaa ki a si fi idi ododo mule lo mu ki oniroyin Irohin Yoruba lo si odo awon alase oja  Ikosi-Ketu sugbon leyin irinajo wa si oja ohun leemeta ti a ko si reni ba wa soro ni a pe Babaloja oja Jakande Ikosi-Ketu, Oloye Alao Oluokun lori 0803945------3 o si so fun wa pe looto ni oun gbo nipa isele ohun sugbon awon agba oja lo pinnu pe ki a ma je ki oro naa da wahala sile laarin oja, a si foro naa le awon olopaa tesan Ketu lowo lati se iwadii won ohun to si je abajade iwadii won ko kan awa mo.

Ni idahun si ibeere Irohin Yoruba kan ni Babaloja Ikosi Ketu Oloye Alao Oluokun ati Iyaloja Alhaja Taiwo Balogun ti so pe awon alase oja ohun ko gbowo lowo enikeni.