Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) tó wà nítòsí ara wọn àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù tó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fún wọn ní omi ẹyọ kan mu. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi àwọn èso wọn. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
Tí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): "Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?" Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
TiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.
(Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù láti fi wá Ojú rere Olúwa wọn. Wọ́n ń kírun. Wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Wọ́n sì ń fi rere dènà aburú. Àwọn wọ̀nyẹn ni àtubọ̀tán Ilé rere ń bẹ fún.
Àwọn tó ń tú àdéhùn Allāhu lẹ́yìn tí wọ́n ti gba àdéhùn Rẹ̀, tí wọ́n ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀; àwọn wọ̀nyẹn ni ègún wà fún. Àti pé Ilé (Iná) burúkú wà fún wọn.
Báyẹn ni A ṣe rán ọ níṣẹ́ sí ìjọ kan, - àwọn ìjọ kan kúkú ti ré kọjá lọ ṣíwájú wọn -, nítorí kí o lè máa ka n̄ǹkan tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ní ìmísí fún wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé. Sọ pé: "Òun ni Olúwa mi. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi."
Dájúdájú wọn ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ. Mo sì lọ́ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ. Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ló ní àkọsílẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kí Á fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí Á ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ, ìṣírò-iṣẹ́ sì ni tiWa.