Prev  

99. Surah Az-Zalzalah سورة الزلزلة

  Next  




Ayah  99:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
إِذَا زُلْزِلَتِ الْأَرْضُ زِلْزَالَهَا
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀,

Ayah  99:2  الأية
    +/- -/+  
وَأَخْرَجَتِ الْأَرْضُ أَثْقَالَهَا
Yoruba
 
Àti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù tó wúwo nínú rẹ̀ jáde,

Ayah  99:3  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ الْإِنسَانُ مَا لَهَا
Yoruba
 
Ènìyàn yó sì wí pé: "Kí l'ó mú un?"

Ayah  99:4  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَئِذٍ تُحَدِّثُ أَخْبَارَهَا
Yoruba
 
Ní ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe).

Ayah  99:5  الأية
    +/- -/+  
بِأَنَّ رَبَّكَ أَوْحَىٰ لَهَا
Yoruba
 
Nítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l'Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀).

Ayah  99:6  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَئِذٍ يَصْدُرُ النَّاسُ أَشْتَاتًا لِّيُرَوْا أَعْمَالَهُمْ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n.

Ayah  99:7  الأية
    +/- -/+  
فَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًا يَرَهُ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.

Ayah  99:8  الأية
    +/- -/+  
وَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ شَرًّا يَرَهُ
Yoruba
 
Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us