Prev  

107. Surah Al-Mâ'ûn سورة الماعون

  Next  



1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
أَرَأَيْتَ الَّذِي يُكَذِّبُ بِالدِّينِ
Araayta allathee yukaththibu biddeen

Yoruba
 
Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!

Ayah  107:2  الأية
فَذَٰلِكَ الَّذِي يَدُعُّ الْيَتِيمَ
Fathalika allathee yaduAAAAualyateem

Yoruba
 
Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.

Ayah  107:3  الأية
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ الْمِسْكِينِ
Wala yahuddu AAalataAAami almiskeen

Yoruba
 
Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.

Ayah  107:4  الأية
فَوَيْلٌ لِّلْمُصَلِّينَ
Fawaylun lilmusalleen

Yoruba
 
Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;

Ayah  107:5  الأية
الَّذِينَ هُمْ عَن صَلَاتِهِمْ سَاهُونَ
Allatheena hum AAan salatihimsahoon

Yoruba
 
Àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;

Ayah  107:6  الأية
الَّذِينَ هُمْ يُرَاءُونَ
Allatheena hum yuraoon

Yoruba
 
Àwọn tó ń ṣe ṣekárími;

Ayah  107:7  الأية
وَيَمْنَعُونَ الْمَاعُونَ
WayamnaAAoona almaAAoon

Yoruba
 
Àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).




© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us