1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ
Alif-lam-ra tilka ayatualkitabi almubeen
Yoruba
'Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.) Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
|
Ayah 12:2 الأية
إِنَّا أَنزَلْنَاهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لَّعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Inna anzalnahu qur-ananAAarabiyyan laAAallakum taAAqiloon
Yoruba
Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
|
Ayah 12:3 الأية
نَحْنُ نَقُصُّ عَلَيْكَ أَحْسَنَ الْقَصَصِ بِمَا أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ هَٰذَا
الْقُرْآنَ وَإِن كُنتَ مِن قَبْلِهِ لَمِنَ الْغَافِلِينَ
Nahnu naqussu AAalayka ahsanaalqasasi bima awhayna ilayka hathaalqur-ana wa-in
kunta min qablihi lamina alghafileen
Yoruba
Àwa ń sọ ìtàn tó dára jùlọ fún ọ pẹ̀lú ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (nínú ìmísí) al-Ƙur'ān yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú ìmísí náà ìwọ wà lára àwọn tí kò nímọ̀ (nípa rẹ̀).
|
Ayah 12:4 الأية
إِذْ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَا أَبَتِ إِنِّي رَأَيْتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوْكَبًا
وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ رَأَيْتُهُمْ لِي سَاجِدِينَ
Ith qala yoosufu li-abeehi yaabati innee raaytu ahada AAashara kawkaban
washshamsawalqamara raaytuhum lee sajideen
Yoruba
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi."
|
Ayah 12:5 الأية
قَالَ يَا بُنَيَّ لَا تَقْصُصْ رُؤْيَاكَ عَلَىٰ إِخْوَتِكَ فَيَكِيدُوا لَكَ
كَيْدًا ۖ إِنَّ الشَّيْطَانَ لِلْإِنسَانِ عَدُوٌّ مُّبِينٌ
Qala ya bunayya la taqsusru/yaka AAala ikhwatika fayakeedoo laka kaydan
innaashshaytana lil-insani AAaduwwun mubeen
Yoruba
Ó sọ pé: "Ọmọ mi, má ṣe rọ́ àlá rẹ fún àwọn ọbàkan rẹ kí wọ́n má baà déte sí ọ. Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn.
|
Ayah 12:6 الأية
وَكَذَٰلِكَ يَجْتَبِيكَ رَبُّكَ وَيُعَلِّمُكَ مِن تَأْوِيلِ الْأَحَادِيثِ
وَيُتِمُّ نِعْمَتَهُ عَلَيْكَ وَعَلَىٰ آلِ يَعْقُوبَ كَمَا أَتَمَّهَا عَلَىٰ
أَبَوَيْكَ مِن قَبْلُ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْحَاقَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Wakathalika yajtabeeka rabbukawayuAAallimuka min ta/weeli al-ahadeethi
wayutimmuniAAmatahu AAalayka waAAala ali yaAAqooba kamaatammaha AAala abawayka
min qablu ibraheemawa-ishaqa inna rabbaka AAaleemun hakeem
Yoruba
Báyẹn ni Olúwa rẹ yóò ṣe ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó máa fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́. Ó sì máa pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún ìwọ àti àwọn ẹbí Ya‘ƙūb, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe pé e ṣíwájú fún àwọn bàbá rẹ méjèèjì, (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm àti 'Ishāƙ. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n."
|
Ayah 12:7 الأية
لَّقَدْ كَانَ فِي يُوسُفَ وَإِخْوَتِهِ آيَاتٌ لِّلسَّائِلِينَ
Laqad kana fee yoosufa wa-ikhwatihi ayatunlissa-ileen
Yoruba
Dájúdájú àwọn àmì (àríwòye) ń bẹ fún àwọn oníbèéèrè nípa (ìtàn Ànábì) Yūsuf àti àwọn ọbàkan rẹ̀.
|
Ayah 12:8 الأية
إِذْ قَالُوا لَيُوسُفُ وَأَخُوهُ أَحَبُّ إِلَىٰ أَبِينَا مِنَّا وَنَحْنُ
عُصْبَةٌ إِنَّ أَبَانَا لَفِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Ith qaloo layoosufu waakhoohu ahabbuila abeena minna wanahnu AAusbatuninna abana
lafee dalalin mubeen
Yoruba
(Rántí) nígbà tí wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ ni bàbá wa nífẹ̀ẹ́ sí ju àwa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni àwa. Dájúdájú bàbá wa mà ti wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.
|
Ayah 12:9 الأية
اقْتُلُوا يُوسُفَ أَوِ اطْرَحُوهُ أَرْضًا يَخْلُ لَكُمْ وَجْهُ أَبِيكُمْ
وَتَكُونُوا مِن بَعْدِهِ قَوْمًا صَالِحِينَ
Oqtuloo yoosufa awi itrahoohuardan yakhlu lakum wajhu abeekum watakoonoo min
baAAdihiqawman saliheen
Yoruba
Ẹ pa Yūsuf tàbí kí ẹ lọ gbé e jùnù sí ilẹ̀ kan nítorí kí bàbá yín lè rójú gbọ́ tiyín. Ẹ sì máa di ènìyàn rere lẹ́yìn rẹ̀."
|
Ayah 12:10 الأية
قَالَ قَائِلٌ مِّنْهُمْ لَا تَقْتُلُوا يُوسُفَ وَأَلْقُوهُ فِي غَيَابَتِ
الْجُبِّ يَلْتَقِطْهُ بَعْضُ السَّيَّارَةِ إِن كُنتُمْ فَاعِلِينَ
Qala qa-ilun minhum lataqtuloo yoosufa waalqoohu fee ghayabati aljubbi
yaltaqithubaAAdu assayyarati in kuntum faAAileen
Yoruba
Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: "Ẹ má ṣe pa Yūsuf. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ṣá fẹ́ wá n̄ǹkan ṣe (sí ọ̀rọ̀ rẹ̀), ẹ gbé e jù sínú ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga nítorí kí apá kan nínú àwọn onírìn-àjò lè he é lọ."
|
Ayah 12:11 الأية
قَالُوا يَا أَبَانَا مَا لَكَ لَا تَأْمَنَّا عَلَىٰ يُوسُفَ وَإِنَّا لَهُ
لَنَاصِحُونَ
Qaloo ya abana malaka la ta/manna AAala yoosufa wa-innalahu lanasihoon
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Bàbá wa, kí ni kò mú ọ fi ọkàn tán wa lórí Yūsuf. Dájúdájú àwa yóò máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa.
|
Ayah 12:12 الأية
أَرْسِلْهُ مَعَنَا غَدًا يَرْتَعْ وَيَلْعَبْ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ
Arsilhu maAAana ghadan yartaAAwayalAAab wa-inna lahu lahafithoon
Yoruba
Jẹ́ kí ó bá wa lọ ní ọ̀la kí ó lè dára yá, kí ó sì lè ṣeré. Àti pé dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ."
|
Ayah 12:13 الأية
قَالَ إِنِّي لَيَحْزُنُنِي أَن تَذْهَبُوا بِهِ وَأَخَافُ أَن يَأْكُلَهُ
الذِّئْبُ وَأَنتُمْ عَنْهُ غَافِلُونَ
Qala innee layahzununee an thathhaboobihi waakhafu an ya/kulahu aththi/buwaantum
AAanhu ghafiloon
Yoruba
Ó sọ pé: "Dájúdájú ó máa bà mí nínú jẹ́ pé kí ẹ mú u lọ. Mo sì ń páyà kí ìkokò má lọ pa á jẹ nígbà tí ẹ̀yin bá gbàgbé rẹ̀ (síbì kan)."
|
Ayah 12:14 الأية
قَالُوا لَئِنْ أَكَلَهُ الذِّئْبُ وَنَحْنُ عُصْبَةٌ إِنَّا إِذًا لَّخَاسِرُونَ
Qaloo la-in akalahu aththi/buwanahnu AAusbatun inna ithan lakhasiroon
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Tí ìkokò bá fi pa á jẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni wá, dájúdájú àwa nígbà náà ni ẹni òfò."
|
Ayah 12:15 الأية
فَلَمَّا ذَهَبُوا بِهِ وَأَجْمَعُوا أَن يَجْعَلُوهُ فِي غَيَابَتِ الْجُبِّ ۚ
وَأَوْحَيْنَا إِلَيْهِ لَتُنَبِّئَنَّهُم بِأَمْرِهِمْ هَٰذَا وَهُمْ لَا
يَشْعُرُونَ
Falamma thahaboo bihiwaajmaAAoo an yajAAaloohu fee ghayabati aljubbi
waawhaynailayhi latunabi-annahum bi-amrihim hatha wahum layashAAuroon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n mú un lọ tán, wọ́n panupọ̀ pé kí àwọn jù ú sí ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga. À si fí ìmísí ránṣẹ́ sí Yūsuf (níbẹ̀) pé: "Dájúdájú ìwọ yóò fún wọn ní ìró nípa ọ̀rọ̀ wọn yìí nígbà tí wọn kò níí fura."
|
Ayah 12:16 الأية
وَجَاءُوا أَبَاهُمْ عِشَاءً يَبْكُونَ
Wajaoo abahum AAishaanyabkoon
Yoruba
Wọ́n dé bá bàbá wọn ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń sunkún.
|
Ayah 12:17 الأية
قَالُوا يَا أَبَانَا إِنَّا ذَهَبْنَا نَسْتَبِقُ وَتَرَكْنَا يُوسُفَ عِندَ
مَتَاعِنَا فَأَكَلَهُ الذِّئْبُ ۖ وَمَا أَنتَ بِمُؤْمِنٍ لَّنَا وَلَوْ كُنَّا
صَادِقِينَ
Qaloo ya abanainna thahabna nastabiqu wataraknayoosufa AAinda mataAAina
faakalahu aththi/buwama anta bimu/minin lana walaw kunna sadiqeen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Bàbá wa, àwa lọ díje eré sísá. A sì fi Yūsuf sílẹ̀ síbi àwọn ẹrù wa. Nígbà náà ni ìkokò pa á jẹ. Ìwọ kò sì níí gbà wá gbọ́, àwa ìbáà jẹ́ olódodo."
|
Ayah 12:18 الأية
وَجَاءُوا عَلَىٰ قَمِيصِهِ بِدَمٍ كَذِبٍ ۚ قَالَ بَلْ سَوَّلَتْ لَكُمْ
أَنفُسُكُمْ أَمْرًا ۖ فَصَبْرٌ جَمِيلٌ ۖ وَاللهُ الْمُسْتَعَانُ عَلَىٰ مَا
تَصِفُونَ
Wajaoo AAala qameesihibidamin kathibin qala bal sawwalat lakum anfusukumamran
fasabrun jameelun wallahu almustaAAanuAAala ma tasifoon
Yoruba
Wọ́n dé pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ irọ́ lára ẹ̀wù rẹ̀. (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: "Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù abiyì (lọ̀rọ̀ mi kàn). Allāhu sì ni Ẹni tí à ń wá àánú Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń ròyìn (yìí)."
|
Ayah 12:19 الأية
وَجَاءَتْ سَيَّارَةٌ فَأَرْسَلُوا وَارِدَهُمْ فَأَدْلَىٰ دَلْوَهُ ۖ قَالَ يَا
بُشْرَىٰ هَٰذَا غُلَامٌ ۚ وَأَسَرُّوهُ بِضَاعَةً ۚ وَاللهُ عَلِيمٌ بِمَا
يَعْمَلُونَ
Wajaat sayyaratun faarsaloo waridahumfaadla dalwahu qala ya bushra hathaghulamun
waasarroohu bidaAAatan wallahuAAaleemun bima yaAAmaloon
Yoruba
Àwọn onírìn-àjò kan sì dé. Wọ́n rán apọnmi wọn (ní omi). Ó sì ju doro rẹ̀ sínú kànǹga. (Yūsuf sì dìrọ̀ mọ́ okùn doro bọ́ síta. Apọnmi sì) sọ pé: "Ire ìdùnnú rè é! Èyí ni ọmọdékùnrin." Wọ́n sì fi pamọ́ fún títà (bí ọjà). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 12:20 الأية
وَشَرَوْهُ بِثَمَنٍ بَخْسٍ دَرَاهِمَ مَعْدُودَةٍ وَكَانُوا فِيهِ مِنَ
الزَّاهِدِينَ
Washarawhu bithamanin bakhsin darahimamaAAdoodatin wakanoo feehi mina azzahideen
Yoruba
Wọ́n tà á ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú owó diriham tó níye. Wọ́n kò sì wowọ́ mọ́ ọn.
|
Ayah 12:21 الأية
وَقَالَ الَّذِي اشْتَرَاهُ مِن مِّصْرَ لِامْرَأَتِهِ أَكْرِمِي مَثْوَاهُ عَسَىٰ
أَن يَنفَعَنَا أَوْ نَتَّخِذَهُ وَلَدًا ۚ وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي
الْأَرْضِ وَلِنُعَلِّمَهُ مِن تَأْوِيلِ الْأَحَادِيثِ ۚ وَاللهُ غَالِبٌ عَلَىٰ
أَمْرِهِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Waqala allathee ishtarahumin misra limraatihi akrimee mathwahu AAasaan
yanfaAAana aw nattakhithahu waladan wakathalikamakkanna liyoosufa fee al-ardi
walinuAAallimahu minta/weeli al-ahadeethi wallahu ghalibunAAala amrihi walakinna
akthara annasila yaAAlamoon
Yoruba
Ẹni tí ó rà á ní (ìlú) Misrọ sọ fún aya rẹ̀ pé: "Ṣàpọ́nlé ibùgbé rẹ̀. Ó súnmọ́ kí ó wúlò fún wa tàbí kí á fi ṣọmọ." Báyẹn ni A ṣe fi àyè gba Yūsuf lórí ilẹ̀. Àti pé kí Á tún lè fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́n. Allāhu ni Olùborí lórí àṣẹ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.
|
Ayah 12:22 الأية
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُ آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي
الْمُحْسِنِينَ
Walamma balagha ashuddahu ataynahuhukman waAAilman wakathalika najzee
almuhsineen
Yoruba
Nígbà tí ó sì dàgbà dáadáa, A fún un ní ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san rere.
|
Ayah 12:23 الأية
وَرَاوَدَتْهُ الَّتِي هُوَ فِي بَيْتِهَا عَن نَّفْسِهِ وَغَلَّقَتِ الْأَبْوَابَ
وَقَالَتْ هَيْتَ لَكَ ۚ قَالَ مَعَاذَ اللهِ ۖ إِنَّهُ رَبِّي أَحْسَنَ
مَثْوَايَ ۖ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ
Warawadat-hu allatee huwa fee baytihaAAan nafsihi waghallaqati al-abwaba waqalat
haytalaka qala maAAatha Allahi innahu rabbee ahsanamathwaya innahu la yuflihu
aththalimoon
Yoruba
Obìnrin tí Yūsuf wà nínú ilé rẹ̀ sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì ti àwọn ìlẹ̀kùn pa. Ó sọ pé: "Súnmọ́ mi." (Yūsuf) sọ pé: "Mo sádi Allāhu. Dájúdájú ọkọ rẹ ni ọ̀gá mi. Ó sì ṣe ibùgbé mi dáadáa. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè."
|
Ayah 12:24 الأية
وَلَقَدْ هَمَّتْ بِهِ ۖ وَهَمَّ بِهَا لَوْلَا أَن رَّأَىٰ بُرْهَانَ رَبِّهِ ۚ
كَذَٰلِكَ لِنَصْرِفَ عَنْهُ السُّوءَ وَالْفَحْشَاءَ ۚ إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا
الْمُخْلَصِينَ
Walaqad hammat bihi wahamma biha lawlaan raa burhana rabbihi kathalika
linasrifaAAanhu assoo-a walfahshaa innahumin AAibadina almukhlaseen
Yoruba
(Obìnrin náà) kúkú gbèrò eré ìfẹ́ sí i. Òun náà gbèrò rẹ̀. Tí kò bá jẹ́ pé ó rí ẹ̀rí Olúwa rẹ̀ (pé harāmu ni sìná, ìbá súnmọ́ ọn). Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ náà rí) nítorí kí Á lè ṣẹ́rí aburú àti sìná ṣíṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ipò ànábì)."
|
Ayah 12:25 الأية
وَاسْتَبَقَا الْبَابَ وَقَدَّتْ قَمِيصَهُ مِن دُبُرٍ وَأَلْفَيَا سَيِّدَهَا
لَدَى الْبَابِ ۚ قَالَتْ مَا جَزَاءُ مَنْ أَرَادَ بِأَهْلِكَ سُوءًا إِلَّا أَن
يُسْجَنَ أَوْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Wastabaqa albabawaqaddat qameesahu min duburin waalfaya sayyidahalada albabi
qalat ma jazao manarada bi-ahlika soo-an illa an yusjana aw AAathabunaleem
Yoruba
Àwọn méjèèjì sáré lọ síbi ìlẹ̀kùn. (Obìnrin yìí) sì fa ẹ̀wù (Yūsuf) ya lẹ́yìn. Àwọn méjèèjì sì bá ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. (Obìnrin yìí) sì sọ pé: "Kí ni ẹ̀san fún ẹni tí ó gbèrò aburú sí ará ilé rẹ bí kò ṣe pé kí wọ́n sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí ìyà ẹlẹ́ta-eléro."
|
Ayah 12:26 الأية
قَالَ هِيَ رَاوَدَتْنِي عَن نَّفْسِي ۚ وَشَهِدَ شَاهِدٌ مِّنْ أَهْلِهَا إِن
كَانَ قَمِيصُهُ قُدَّ مِن قُبُلٍ فَصَدَقَتْ وَهُوَ مِنَ الْكَاذِبِينَ
Qala hiya rawadatnee AAannafsee washahida shahidun min ahliha in kanaqameesuhu
qudda min qubulin fasadaqat wahuwa minaalkathibeen
Yoruba
(Yūsuf) sọ pé: "Òun ló jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ mi." Ẹlẹ́rìí kan nínú ará ile (obìnrin náà) sì jẹ́rìí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya níwájú, (obìnrin yìí) ló sọ òdodo, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn òpùrọ́.
|
Ayah 12:27 الأية
وَإِن كَانَ قَمِيصُهُ قُدَّ مِن دُبُرٍ فَكَذَبَتْ وَهُوَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Wa-in kana qameesuhu qudda minduburin fakathabat wahuwa mina assadiqeen
Yoruba
Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya lẹ́yìn, (obìnrin yìí) ló parọ́, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn olódodo."
|
Ayah 12:28 الأية
فَلَمَّا رَأَىٰ قَمِيصَهُ قُدَّ مِن دُبُرٍ قَالَ إِنَّهُ مِن كَيْدِكُنَّ ۖ إِنَّ
كَيْدَكُنَّ عَظِيمٌ
Falamma raa qameesahuqudda min duburin qala innahu min kaydikunna innakaydakunna
AAatheem
Yoruba
Nígbà tí (ọkọ) rí ẹ̀wù rẹ̀ tí wọ́n ti fà á ya lẹ́yìn, ó sọ pé: "Dájúdájú nínú ète ẹ̀yin obìnrin ni (èyí). Dájúdájú ète yín tóbi.
|
Ayah 12:29 الأية
يُوسُفُ أَعْرِضْ عَنْ هَٰذَا ۚ وَاسْتَغْفِرِي لِذَنبِكِ ۖ إِنَّكِ كُنتِ مِنَ
الْخَاطِئِينَ
Yoosufu aAArid AAan hatha wastaghfireelithanbiki innaki kunti mina alkhati-een
Yoruba
Yūsuf, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Kí ìwọ (obìnrin yìí) sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn aláṣìṣe."
|
Ayah 12:30 الأية
وَقَالَ نِسْوَةٌ فِي الْمَدِينَةِ امْرَأَتُ الْعَزِيزِ تُرَاوِدُ فَتَاهَا عَن
نَّفْسِهِ ۖ قَدْ شَغَفَهَا حُبًّا ۖ إِنَّا لَنَرَاهَا فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Waqala niswatun fee almadeenatiimraatu alAAazeezi turawidu fataha AAannafsihi
qad shaghafaha hubban inna lanarahafee dalalin mubeen
Yoruba
Àwọn obìnrin kan nínú ìlú sọ pé: "Ayaba ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀; ìfẹ́ kúkú ti kó sí i lọ́kàn. Dájúdájú àwa ń rí òun pé ó wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé."
|
Ayah 12:31 الأية
فَلَمَّا سَمِعَتْ بِمَكْرِهِنَّ أَرْسَلَتْ إِلَيْهِنَّ وَأَعْتَدَتْ لَهُنَّ
مُتَّكَأً وَآتَتْ كُلَّ وَاحِدَةٍ مِّنْهُنَّ سِكِّينًا وَقَالَتِ اخْرُجْ
عَلَيْهِنَّ ۖ فَلَمَّا رَأَيْنَهُ أَكْبَرْنَهُ وَقَطَّعْنَ أَيْدِيَهُنَّ
وَقُلْنَ حَاشَ لِلَّهِ مَا هَٰذَا بَشَرًا إِنْ هَٰذَا إِلَّا مَلَكٌ كَرِيمٌ
Falamma samiAAat bimakrihinna arsalatilayhinna waaAAtadat lahunna muttakaan
waatat kulla wahidatinminhunna sikkeenan waqalati okhruj AAalayhinna
falammaraaynahu akbarnahu waqattaAAna aydiyahunna waqulna hashalillahi ma hatha
basharan in hathailla malakun kareem
Yoruba
Nígbà tí (ayaba) gbọ́ ète (ọ̀rọ̀) wọn (tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀), ó ránṣẹ́ sí wọn. Ó sì pèsè ohun jíjẹ tí wọ́n máa rọ̀gbọ̀kú jẹ lórí tìmùtìmù àti ìrọ̀rí sílẹ̀ fún wọn. Ó fún ìkọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀bẹ (tí ó máa fi jẹun). Ó sì sọ pé: "Jáde sí wọn, (Yūsuf)." Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n gbé e tóbi (fún ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì rẹ́ra wọn lọ́wọ́ (fún ìyanu ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì wí pé: "Mímọ́ ni fún Allāhu! Èyí kì í ṣe abara. Kí ni èyí bí kò ṣe mọlāika alápọ̀n-ọ́nlé."
|
Ayah 12:32 الأية
قَالَتْ فَذَٰلِكُنَّ الَّذِي لُمْتُنَّنِي فِيهِ ۖ وَلَقَدْ رَاوَدتُّهُ عَن
نَّفْسِهِ فَاسْتَعْصَمَ ۖ وَلَئِن لَّمْ يَفْعَلْ مَا آمُرُهُ لَيُسْجَنَنَّ
وَلَيَكُونًا مِّنَ الصَّاغِرِينَ
Qalat fathalikunna allatheelumtunnanee feehi walaqad rawadtuhu AAan nafsihi
fastAAsamawala-in lam yafAAal ma amuruhu layusjanannawalayakoonan mina
assaghireen
Yoruba
(Ayaba) sọ pé: "Ìyẹn ni ẹni tí ẹ bú mi fún. Dájúdájú mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó́sì wá ìṣọ́ra. Dájúdájú tí kò bá ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún un, wọ́n kúkú máa fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni. Dájúdájú ó sì máa wà nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ."
|
Ayah 12:33 الأية
قَالَ رَبِّ السِّجْنُ أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا يَدْعُونَنِي إِلَيْهِ ۖ وَإِلَّا
تَصْرِفْ عَنِّي كَيْدَهُنَّ أَصْبُ إِلَيْهِنَّ وَأَكُن مِّنَ الْجَاهِلِينَ
Qala rabbi assijnu ahabbuilayya mimma yadAAoonanee ilayhi wa-illa tasrifAAannee
kaydahunna asbu ilayhinna waakun mina aljahileen
Yoruba
(Yūsuf) sọ pé: "Olúwa (Ẹlẹ́dàá) mi, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo nífẹ̀ẹ́ sí ju ohun tí wọ́n ń pè mí sí. Tí O ò bá sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò kó sínú ète wọn, èmi yó sì wà lára àwọn aláìmọ̀kan."
|
Ayah 12:34 الأية
فَاسْتَجَابَ لَهُ رَبُّهُ فَصَرَفَ عَنْهُ كَيْدَهُنَّ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ
الْعَلِيمُ
Fastajaba lahu rabbuhu fasarafaAAanhu kaydahunna innahu huwa assameeAAu
alAAaleem
Yoruba
Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ jẹ́pè rẹ̀. Ó sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
|
Ayah 12:35 الأية
ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّن بَعْدِ مَا رَأَوُا الْآيَاتِ لَيَسْجُنُنَّهُ حَتَّىٰ
حِينٍ
Thumma bada lahum min baAAdi maraawoo al-ayati layasjununnahu hatta heen
Yoruba
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti rí àwọn àmì (pé Yūsuf kò jẹ̀bi ẹ̀sùn), lẹ́yìn náà, ó hàn sí wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di àsìkò kan ná.
|
Ayah 12:36 الأية
وَدَخَلَ مَعَهُ السِّجْنَ فَتَيَانِ ۖ قَالَ أَحَدُهُمَا إِنِّي أَرَانِي أَعْصِرُ
خَمْرًا ۖ وَقَالَ الْآخَرُ إِنِّي أَرَانِي أَحْمِلُ فَوْقَ رَأْسِي خُبْزًا
تَأْكُلُ الطَّيْرُ مِنْهُ ۖ نَبِّئْنَا بِتَأْوِيلِهِ ۖ إِنَّا نَرَاكَ مِنَ
الْمُحْسِنِينَ
Wadakhala maAAahu assijna fatayaniqala ahaduhuma innee aranee aAAsirukhamran
waqala al-akharu innee aranee ahmilufawqa ra/see khubzan ta/kulu attayru minhu
nabbi/nabita/weelihi inna naraka mina almuhsineen
Yoruba
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì sọ pé: "Èmi lálàá rí ara mi pé mò ń fún ọtí." Ẹnì kejì sọ pé: "Dájúdájú èmi lálàá rí ara mi pé mo gbé búrẹ́dì rù sórí mi, ẹyẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀." Sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú àwọn ẹni rere.
|
Ayah 12:37 الأية
قَالَ لَا يَأْتِيكُمَا طَعَامٌ تُرْزَقَانِهِ إِلَّا نَبَّأْتُكُمَا بِتَأْوِيلِهِ
قَبْلَ أَن يَأْتِيَكُمَا ۚ ذَٰلِكُمَا مِمَّا عَلَّمَنِي رَبِّي ۚ إِنِّي تَرَكْتُ
مِلَّةَ قَوْمٍ لَّا يُؤْمِنُونَ بِاللهِ وَهُم بِالْآخِرَةِ هُمْ كَافِرُونَ
Qala la ya/teekuma taAAamunturzaqanihi illa nabba/tukuma bita/weelihiqabla an
ya/tiyakuma thalikuma mimmaAAallamanee rabbee innee taraktu millata qawmin
layu/minoona billahi wahum bil-akhiratihum kafiroon
Yoruba
Ó sọ pé: "Oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè fún ẹ̀yin méjèèjì kò ní tí ì dé ba yín, àfi kí èmi ti sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ẹ̀yin méjèèjì ṣíwájú kí ó tó dé ba yín. Ìyẹn wà nínú n̄ǹkan tí Olúwa mi fi mọ̀ mí. Dájúdájú èmi fi ẹ̀sìn àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu sílẹ̀. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
|
Ayah 12:38 الأية
وَاتَّبَعْتُ مِلَّةَ آبَائِي إِبْرَاهِيمَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ ۚ مَا كَانَ
لَنَا أَن نُّشْرِكَ بِاللهِ مِن شَيْءٍ ۚ ذَٰلِكَ مِن فَضْلِ اللهِ عَلَيْنَا
وَعَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ
WattabaAAtu millata aba-eeibraheema wa-ishaqa wayaAAqooba ma kanalana an
nushrika billahi min shay-in thalikamin fadli Allahi AAalayna waAAala
annasiwalakinna akthara annasi layashkuroon
Yoruba
Mo sì tẹ̀lé ẹ̀sìn àwọn bàbá mi, (àwọn Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, 'Ishāƙ àti Ya‘ƙūb. Kò tọ́ sí wa pé kí á sọ n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu. Ìyẹn wà nínú oore àjùlọ Allāhu lórí àwa àti lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Allāhu).
|
Ayah 12:39 الأية
يَا صَاحِبَيِ السِّجْنِ أَأَرْبَابٌ مُّتَفَرِّقُونَ خَيْرٌ أَمِ اللهُ
الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ
Ya sahibayi assijniaarbabun mutafarriqoona khayrun ami Allahu alwahidualqahhar
Yoruba
Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ṣé àwọn olúwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló lóore jùlọ (láti jọ́sìn fún) tàbí Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí?
|
Ayah 12:40 الأية
مَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِهِ إِلَّا أَسْمَاءً سَمَّيْتُمُوهَا أَنتُمْ وَآبَاؤُكُم
مَّا أَنزَلَ اللهُ بِهَا مِن سُلْطَانٍ ۚ إِنِ الْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۚ
أَمَرَ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا إِيَّاهُ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ
وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Ma taAAbudoona min doonihi illaasmaan sammaytumooha antum waabaokumma anzala
Allahu biha min sultaninini alhukmu illa lillahi amara allataAAbudoo illa iyyahu
thalika addeenualqayyimu walakinna akthara annasi layaAAlamoon
Yoruba
Kò sí ohun kan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ sọ wọ́n - ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín - Allāhu kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un. Ìdájọ́ (ta ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo) kò sí fún ẹnì kan àyàfi Allāhu. Ó sì ti pàṣẹ pé ẹ má ṣe jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Òun nìkan. Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
|
Ayah 12:41 الأية
يَا صَاحِبَيِ السِّجْنِ أَمَّا أَحَدُكُمَا فَيَسْقِي رَبَّهُ خَمْرًا ۖ وَأَمَّا
الْآخَرُ فَيُصْلَبُ فَتَأْكُلُ الطَّيْرُ مِن رَّأْسِهِ ۚ قُضِيَ الْأَمْرُ
الَّذِي فِيهِ تَسْتَفْتِيَانِ
Ya sahibayi assijniamma ahadukuma fayasqee rabbahu khamranwaamma al-akharu
fayuslabu fata/kulu attayrumin ra/sihi qudiya al-amru allathee feehi tastaftiyan
Yoruba
Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ní ti ẹnì kan nínú yín, ó máa fún ọ̀gá rẹ̀ ní ọtí mu. Ní ti ẹnì kejì, wọn yóò kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ẹyẹ yó sì máa jẹ nínú orí rẹ̀. Wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀."
|
Ayah 12:42 الأية
وَقَالَ لِلَّذِي ظَنَّ أَنَّهُ نَاجٍ مِّنْهُمَا اذْكُرْنِي عِندَ رَبِّكَ
فَأَنسَاهُ الشَّيْطَانُ ذِكْرَ رَبِّهِ فَلَبِثَ فِي السِّجْنِ بِضْعَ سِنِينَ
Waqala lillathee thannaannahu najin minhuma othkurnee AAindarabbika faansahu
ashshaytanu thikrarabbihi falabitha fee assijni bidAAa sineen
Yoruba
Ó sì sọ fún ẹni tí ó rò pé ó máa là nínú àwọn méjèèjì pé: "Rántí mi lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ." Èṣù sì mú (Yūsuf) gbàgbé ìrántí Olúwa rẹ̀ (nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀). Nítorí náà, ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n fún àwọn ọdún díẹ̀.
|
Ayah 12:43 الأية
وَقَالَ الْمَلِكُ إِنِّي أَرَىٰ سَبْعَ بَقَرَاتٍ سِمَانٍ يَأْكُلُهُنَّ سَبْعٌ
عِجَافٌ وَسَبْعَ سُنبُلَاتٍ خُضْرٍ وَأُخَرَ يَابِسَاتٍ ۖ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ
أَفْتُونِي فِي رُؤْيَايَ إِن كُنتُمْ لِلرُّؤْيَا تَعْبُرُونَ
Waqala almaliku innee arasabAAa baqaratin simanin ya/kuluhunna sabAAun
AAijafunwasabAAa sunbulatin khudrin waokhara yabisatinya ayyuha almalao aftoonee
fee ru/yaya inkuntum lirru/ya taAAburoon
Yoruba
Ọbá sọ pé: "Dájúdájú èmi lálàá rí màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. (Mo tún lálàá rí) ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fún mi ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá mi tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó máa ń túmọ̀ àlá."
|
Ayah 12:44 الأية
قَالُوا أَضْغَاثُ أَحْلَامٍ ۖ وَمَا نَحْنُ بِتَأْوِيلِ الْأَحْلَامِ بِعَالِمِينَ
Qaloo adghathu ahlaminwama nahnu bita/weeli al-ahlami biAAalimeen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ (nìyí). Àti pé àwa kì í ṣe onímọ̀ nípa ìtúmọ̀ àwọn àlá."
|
Ayah 12:45 الأية
وَقَالَ الَّذِي نَجَا مِنْهُمَا وَادَّكَرَ بَعْدَ أُمَّةٍ أَنَا أُنَبِّئُكُم
بِتَأْوِيلِهِ فَأَرْسِلُونِ
Waqala allathee najaminhuma waddakara baAAda ommatin anaonabbi-okum bita/weelihi
faarsiloon
Yoruba
Ẹni tí ó là nínú àwọn (ẹlẹ́wọ̀n) méjèèjì sọ pé, - ó rántí (Yūsuf) lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ -: "Èmi yóò fún yín ní ìró nípa ìtúmọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fi iṣẹ́ rán mi ná (kí n̄g lọ ṣe ìwádìí rẹ̀)."
|
Ayah 12:46 الأية
يُوسُفُ أَيُّهَا الصِّدِّيقُ أَفْتِنَا فِي سَبْعِ بَقَرَاتٍ سِمَانٍ
يَأْكُلُهُنَّ سَبْعٌ عِجَافٌ وَسَبْعِ سُنبُلَاتٍ خُضْرٍ وَأُخَرَ يَابِسَاتٍ
لَّعَلِّي أَرْجِعُ إِلَى النَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَعْلَمُونَ
Yoosufu ayyuha assiddeequaftina fee sabAAi baqaratin simaninya/kuluhunna sabAAun
AAijafun wasabAAi sunbulatinkhudrin waokhara yabisatin laAAallee arjiAAuila
annasi laAAallahum yaAAlamoon
Yoruba
Yūsuf, ìwọ olódodo, fún wa ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá (yìí): màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. Àti ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. (Kí ni ìtúmọ̀ rẹ̀) nítorí kí n̄g lè fi àbọ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn àti nítorí kí wọ́n lè mọ (ìtúmọ̀ rẹ̀).
|
Ayah 12:47 الأية
قَالَ تَزْرَعُونَ سَبْعَ سِنِينَ دَأَبًا فَمَا حَصَدتُّمْ فَذَرُوهُ فِي
سُنبُلِهِ إِلَّا قَلِيلًا مِّمَّا تَأْكُلُونَ
Qala tazraAAoona sabAAa sineenadaaban fama hasadtum fatharoohu feesunbulihi illa
qaleelan mimma ta/kuloon
Yoruba
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin yóò gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn fún ọdún méje gbáko (gẹ́gẹ́ bí) ìṣe (yín). Ohunkòhun tí ẹ bá kó lérè̀oko, kí ẹ fi sílẹ̀ sínú ṣiri rẹ̀ àfi díẹ̀ tí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀.
|
Ayah 12:48 الأية
ثُمَّ يَأْتِي مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ سَبْعٌ شِدَادٌ يَأْكُلْنَ مَا قَدَّمْتُمْ
لَهُنَّ إِلَّا قَلِيلًا مِّمَّا تُحْصِنُونَ
Thumma ya/tee min baAAdi thalikasabAAun shidadun ya/kulna ma qaddamtum lahunna
illaqaleelan mimma tuhsinoon
Yoruba
Lẹ́yìn náà, ọdún méje tó le (fún ọ̀dá òjò) yóò dé lẹ́yìn ìyẹn, (àwọn ará ìlú) yó sì lè jẹ ohun tí ẹ ti (kó lérè oko) ṣíwájú àfi díẹ̀ tí ẹ máa fi pamọ́ (fún gbígbìn).
|
Ayah 12:49 الأية
ثُمَّ يَأْتِي مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ عَامٌ فِيهِ يُغَاثُ النَّاسُ وَفِيهِ
يَعْصِرُونَ
Thumma ya/tee min baAAdi thalika AAamunfeehi yughathu annasu wafeehi yaAAsiroon
Yoruba
Lẹ́yìn náà, ọdún kan tí Wọn yóò rọ̀jò fún àwọn ènìyàn yóò dé lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn ènìyàn yó sì máa fún èso àti wàrà mu nínú ọdún náà.
|
Ayah 12:50 الأية
وَقَالَ الْمَلِكُ ائْتُونِي بِهِ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُ الرَّسُولُ قَالَ ارْجِعْ
إِلَىٰ رَبِّكَ فَاسْأَلْهُ مَا بَالُ النِّسْوَةِ اللَّاتِي قَطَّعْنَ
أَيْدِيَهُنَّ ۚ إِنَّ رَبِّي بِكَيْدِهِنَّ عَلِيمٌ
Waqala almaliku i/toonee bihi falammajaahu arrasoolu qala irjiAA ilarabbika
fas-alhu ma balu anniswatiallatee qattaAAna aydiyahunna inna rabbeebikaydihinna
AAaleem
Yoruba
Ọba sọ pé: "Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi." Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ. (Yūsuf) sọ pé: "Padà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o bi í léèrè pé, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin tí wọ́n rẹ́ ọwọ́ ara wọn. Dájúdájú Olúwa mi ni Onímọ̀ nípa ète wọn."
|
Ayah 12:51 الأية
قَالَ مَا خَطْبُكُنَّ إِذْ رَاوَدتُّنَّ يُوسُفَ عَن نَّفْسِهِ ۚ قُلْنَ حَاشَ
لِلَّهِ مَا عَلِمْنَا عَلَيْهِ مِن سُوءٍ ۚ قَالَتِ امْرَأَتُ الْعَزِيزِ الْآنَ
حَصْحَصَ الْحَقُّ أَنَا رَاوَدتُّهُ عَن نَّفْسِهِ وَإِنَّهُ لَمِنَ الصَّادِقِينَ
Qala ma khatbukunna ithrawadtunna yoosufa AAan nafsihi qulna hasha lillahima
AAalimna AAalayhi min soo-in qalatiimraatu alAAazeezi al-ana hashasa alhaqquana
rawadtuhu AAan nafsihi wa-innahu lamina assadiqeen
Yoruba
(Ọba) sọ pé: "Kí ni ọ̀rọ̀ tiyín ti jẹ́ tí ẹ fi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ Yūsuf?" Wọ́n sọ pé: "Mímọ́ ni fún Allāhu. àwa kò mọ aburú kan mọ Yūsuf." Ayaba sọ pé: "Nísinsìn yìí ni òdodo fojú hàn. Èmi ni mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn olódodo."
|
Ayah 12:52 الأية
ذَٰلِكَ لِيَعْلَمَ أَنِّي لَمْ أَخُنْهُ بِالْغَيْبِ وَأَنَّ اللهَ لَا يَهْدِي
كَيْدَ الْخَائِنِينَ
Thalika liyaAAlama annee lam akhunhubilghaybi waanna Allaha la yahdee
kaydaalkha-ineen
Yoruba
(Yūsuf sọ pé): "Ìyẹn nítorí kí ọba lè mọ̀ pé dájúdájú èmi kò jàǹbá rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ìmọ̀nà síbi ète àwọn oníjàǹbá.
|
Ayah 12:53 الأية
وَمَا أُبَرِّئُ نَفْسِي ۚ إِنَّ النَّفْسَ لَأَمَّارَةٌ بِالسُّوءِ إِلَّا مَا
رَحِمَ رَبِّي ۚ إِنَّ رَبِّي غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Wama obarri-o nafsee inna annafsalaammaratun bissoo-i illa ma rahimarabbee inna
rabbee ghafoorun raheem
Yoruba
Èmi kò sì fọra mi mọ́ (níbi èròkérò); dájúdájú ẹ̀mí kúkú ń pàṣẹ èròkérò (fún ẹ̀dá) ni àfi ẹni tí Olúwa mi bá kẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
|
Ayah 12:54 الأية
وَقَالَ الْمَلِكُ ائْتُونِي بِهِ أَسْتَخْلِصْهُ لِنَفْسِي ۖ فَلَمَّا كَلَّمَهُ
قَالَ إِنَّكَ الْيَوْمَ لَدَيْنَا مَكِينٌ أَمِينٌ
Waqala almaliku i/toonee bihiastakhlishu linafsee falamma kallamahu qalainnaka
alyawma ladayna makeenun ameen
Yoruba
Ọba sọ pé: "Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi. Èmi yóò ṣe é ní ẹni ẹ̀ṣà lọ́dọ̀ mi." Nígbà tí ọba bá a sọ̀rọ̀ tán, ó sọ pé: "Lọ́dọ̀ wa ní òní dájúdájú ìwọ ni ẹni pàtàkì, olùfọkàntán."
|
Ayah 12:55 الأية
قَالَ اجْعَلْنِي عَلَىٰ خَزَائِنِ الْأَرْضِ ۖ إِنِّي حَفِيظٌ عَلِيمٌ
Qala ijAAalnee AAala khaza-inial-ardi innee hafeethun AAaleem
Yoruba
(Yūsuf) sọ pé: "Fi mí ṣe aláṣẹ lórí àwọn ọrọ̀ ìlú, dájúdájú alámòjúútó onímọ̀ ni mí."
|
Ayah 12:56 الأية
وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي الْأَرْضِ يَتَبَوَّأُ مِنْهَا حَيْثُ يَشَاءُ
ۚ نُصِيبُ بِرَحْمَتِنَا مَن نَّشَاءُ ۖ وَلَا نُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ
Wakathalika makanna liyoosufafee al-ardi yatabawwao minha haythu yashaonuseebu
birahmatina man nashao walanudeeAAu ajra almuhsineen
Yoruba
Báyẹn ni A ṣe fún Yūsuf ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. Ó sì ń gbé ní ibi tí ó bá fẹ́. Àwa ń mú ìkẹ́ Wa bá ẹnikẹ́ni tí A bá fẹ́. A ò sì níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
|
Ayah 12:57 الأية
وَلَأَجْرُ الْآخِرَةِ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ
Walaajru al-akhirati khayrun lillatheenaamanoo wakanoo yattaqoon
Yoruba
Dájúdájú ẹ̀san ti ọ̀run lóore jùlọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).
|
Ayah 12:58 الأية
وَجَاءَ إِخْوَةُ يُوسُفَ فَدَخَلُوا عَلَيْهِ فَعَرَفَهُمْ وَهُمْ لَهُ مُنكِرُونَ
Wajaa ikhwatu yoosufa fadakhalooAAalayhi faAAarafahum wahum lahu munkiroon
Yoruba
Àwọn ọbàkan (Ànábì) Yūsuf dé, wọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́. Ó dá wọn mọ̀. Àwọn kò sì mọ̀ ọ́n mọ́.
|
Ayah 12:59 الأية
وَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمْ قَالَ ائْتُونِي بِأَخٍ لَّكُم مِّنْ أَبِيكُمْ
ۚ أَلَا تَرَوْنَ أَنِّي أُوفِي الْكَيْلَ وَأَنَا خَيْرُ الْمُنزِلِينَ
Walamma jahhazahum bijahazihimqala i/toonee bi-akhin lakum min abeekum
alatarawna annee oofee alkayla waana khayru almunzileen
Yoruba
Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù oúnjẹ wọn tán, ó sọ pé: "Ẹ lọ mú ọbàkan yín wá láti ọ̀dọ̀ bàbá yín. Ṣé ẹ kò rí i pé dájúdájú mò ń wọn kóńgò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni? Èmi sì dára jùlọ nínú àwọn olùgbàlejò.
|
Ayah 12:60 الأية
فَإِن لَّمْ تَأْتُونِي بِهِ فَلَا كَيْلَ لَكُمْ عِندِي وَلَا تَقْرَبُونِ
Fa-in lam ta/toonee bihi fala kaylalakum AAindee wala taqraboon
Yoruba
Tí ẹ ò bá sì mú un wá, kò sí (ẹrù oúnjẹ) wíwọ̀n fún yín lọ́dọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ mi."
|
Ayah 12:61 الأية
قَالُوا سَنُرَاوِدُ عَنْهُ أَبَاهُ وَإِنَّا لَفَاعِلُونَ
Qaloo sanurawidu AAanhu abahuwa-inna lafaAAiloon
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "A máa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún un lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Dájúdájú àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀."
|
Ayah 12:62 الأية
وَقَالَ لِفِتْيَانِهِ اجْعَلُوا بِضَاعَتَهُمْ فِي رِحَالِهِمْ لَعَلَّهُمْ
يَعْرِفُونَهَا إِذَا انقَلَبُوا إِلَىٰ أَهْلِهِمْ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Waqala lifityanihi ijAAaloo bidaAAatahumfee rihalihim laAAallahum yaAArifoonaha
ithainqalaboo ila ahlihim laAAallahum yarjiAAoon
Yoruba
Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Ẹ fi owó-ọjà wọn sínú ẹrù (oúnjẹ) wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ nígbà tí wọ́n bá padà dé ọ̀dọ̀ ará ilé wọ́n (pé a ti dá a padà fún wọn), wọn yó sì lè padà wá."
|
Ayah 12:63 الأية
فَلَمَّا رَجَعُوا إِلَىٰ أَبِيهِمْ قَالُوا يَا أَبَانَا مُنِعَ مِنَّا الْكَيْلُ
فَأَرْسِلْ مَعَنَا أَخَانَا نَكْتَلْ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ
Falamma rajaAAoo ila abeehim qalooya abana muniAAa minna alkaylufaarsil maAAana
akhana naktal wa-innalahu lahafithoon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ bàbá wọn, wọ́n sọ pé: "Bàbá wa, wọ́n kọ̀ láti wọn oúnjẹ fún wa. Nítorí náà, jẹ́ kí ọbàkan wa bá wa lọ nítorí kí á lè rí oúnjẹ wọ̀n (wálé). Dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ."
|
Ayah 12:64 الأية
قَالَ هَلْ آمَنُكُمْ عَلَيْهِ إِلَّا كَمَا أَمِنتُكُمْ عَلَىٰ أَخِيهِ مِن قَبْلُ
ۖ فَاللهُ خَيْرٌ حَافِظًا ۖ وَهُوَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ
Qala hal amanukum AAalayhi illakama amintukum AAala akheehi min qablu
fallahukhayrun hafithan wahuwa arhamu arrahimeen
Yoruba
Ó sọ pé: "Ṣé kí n̄g gbà yín gbọ́ lórí rẹ̀ bí kò ṣe bí mó ṣe gbà yín gbọ́ ní ìṣaájú lórí ọmọ-ìyá rẹ̀? Nítorí náà, Allāhu lóore jùlọ ní Olùṣọ́. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú."
|
Ayah 12:65 الأية
وَلَمَّا فَتَحُوا مَتَاعَهُمْ وَجَدُوا بِضَاعَتَهُمْ رُدَّتْ إِلَيْهِمْ ۖ
قَالُوا يَا أَبَانَا مَا نَبْغِي ۖ هَٰذِهِ بِضَاعَتُنَا رُدَّتْ إِلَيْنَا ۖ
وَنَمِيرُ أَهْلَنَا وَنَحْفَظُ أَخَانَا وَنَزْدَادُ كَيْلَ بَعِيرٍ ۖ ذَٰلِكَ
كَيْلٌ يَسِيرٌ
Walamma fatahoo mataAAahumwajadoo bidaAAatahum ruddat ilayhim qaloo yaabana ma
nabghee hathihi bidaAAatunaruddat ilayna wanameeru ahlana wanahfathuakhana
wanazdadu kayla baAAeerin thalikakaylun yaseer
Yoruba
Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí owó-ọjà wọn tí wọ́n dá padà fún wọn (nínú rẹ̀). Wọ́n sọ pé: "Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba)."
|
Ayah 12:66 الأية
قَالَ لَنْ أُرْسِلَهُ مَعَكُمْ حَتَّىٰ تُؤْتُونِ مَوْثِقًا مِّنَ اللهِ
لَتَأْتُنَّنِي بِهِ إِلَّا أَن يُحَاطَ بِكُمْ ۖ فَلَمَّا آتَوْهُ مَوْثِقَهُمْ
قَالَ اللهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ
Qala lan orsilahu maAAakum hattatu/tooni mawthiqan mina Allahi lata/tunnanee
bihi illaan yuhata bikum falamma atawhu mawthiqahum qalaAllahu AAala ma naqoolu
wakeel
Yoruba
Ó sọ pé: "Èmi kò níí jẹ́ kí ó ba yín lọ títí ẹ máa fi ṣe àdéhùn fún mi ní (orúkọ) Allāhu pé dájúdájú ẹ máa mú un padà wá bá mi àfi tí (àwọn ọ̀tá) bá ka yín mọ́." Nígbà tí wọ́n fún un ní àdéhùn wọn tán, ó sọ pé: "Allāhu ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí)."
|
Ayah 12:67 الأية
وَقَالَ يَا بَنِيَّ لَا تَدْخُلُوا مِن بَابٍ وَاحِدٍ وَادْخُلُوا مِنْ أَبْوَابٍ
مُّتَفَرِّقَةٍ ۖ وَمَا أُغْنِي عَنكُم مِّنَ اللهِ مِن شَيْءٍ ۖ إِنِ الْحُكْمُ
إِلَّا لِلَّهِ ۖ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ ۖ وَعَلَيْهِ فَلْيَتَوَكَّلِ
الْمُتَوَكِّلُونَ
Waqala ya baniyya latadkhuloo min babin wahidin wadkhuloo minabwabin
mutafarriqatin wama oghnee AAankum mina Allahimin shay-in ini alhukmu illa
lillahiAAalayhi tawakkaltu waAAalayhi falyatawakkali almutawakkiloon
Yoruba
Ó tún sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe gba ẹnu ọ̀nà ẹyọ kan wọlé. Ẹ gba ẹnu ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọlé. Èmi kò lè fí n̄ǹkan kan rọ̀ yín lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sí ìdájọ́ (kan) àfi ti Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé."
|
Ayah 12:68 الأية
وَلَمَّا دَخَلُوا مِنْ حَيْثُ أَمَرَهُمْ أَبُوهُم مَّا كَانَ يُغْنِي عَنْهُم
مِّنَ اللهِ مِن شَيْءٍ إِلَّا حَاجَةً فِي نَفْسِ يَعْقُوبَ قَضَاهَا ۚ
وَإِنَّهُ لَذُو عِلْمٍ لِّمَا عَلَّمْنَاهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا
يَعْلَمُونَ
Walamma dakhaloo min haythuamarahum aboohum ma kana yughnee AAanhum mina
Allahimin shay-in illa hajatan fee nafsi yaAAqooba qadahawa-innahu lathoo
AAilmin lima AAallamnahuwalakinna akthara annasi layaAAlamoon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
|
Ayah 12:69 الأية
وَلَمَّا دَخَلُوا عَلَىٰ يُوسُفَ آوَىٰ إِلَيْهِ أَخَاهُ ۖ قَالَ إِنِّي أَنَا
أَخُوكَ فَلَا تَبْتَئِسْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Walamma dakhaloo AAala yoosufaawa ilayhi akhahu qala innee anaakhooka fala
tabta-is bima kanoo yaAAmaloon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n wọlé ti (Ànábì) Yūsuf, ó mú ọmọ-ìyá rẹ̀ mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ni ọmọ-ìyá rẹ. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́."
|
Ayah 12:70 الأية
فَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمْ جَعَلَ السِّقَايَةَ فِي رَحْلِ أَخِيهِ ثُمَّ
أَذَّنَ مُؤَذِّنٌ أَيَّتُهَا الْعِيرُ إِنَّكُمْ لَسَارِقُونَ
Falamma jahhazahum bijahazihimjaAAala assiqayata fee rahli akheehi
thummaaththana mu-aththinun ayyatuha alAAeeruinnakum lasariqoon
Yoruba
Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù wọn tán, ó fi ife-ìmumi sínú ẹrù ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan kéde pé: "Ẹ̀yin èrò-ràkúnmí, dájúdájú olè mà ni yín."
|
Ayah 12:71 الأية
قَالُوا وَأَقْبَلُوا عَلَيْهِم مَّاذَا تَفْقِدُونَ
Qaloo waaqbaloo AAalayhim mathatafqidoon
Yoruba
Wọ́n dojú kọ wọ́n, wọ́n sọ pé: "Kí l'ẹ ṣàfẹ́kù?"
|
Ayah 12:72 الأية
قَالُوا نَفْقِدُ صُوَاعَ الْمَلِكِ وَلِمَن جَاءَ بِهِ حِمْلُ بَعِيرٍ وَأَنَا
بِهِ زَعِيمٌ
Qaloo nafqidu suwaAAaalmaliki waliman jaa bihi himlu baAAeerin waanabihi zaAAeem
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "A ṣàfẹ́kù ife ọba ni. Ẹni tí ó bá sì mú un wá yóò rí ẹrù oúnjẹ ràkúnmí kan gbà. Èmi sì ni onídùróó fún ẹ̀bùn náà."
|
Ayah 12:73 الأية
قَالُوا تَاللهِ لَقَدْ عَلِمْتُم مَّا جِئْنَا لِنُفْسِدَ فِي الْأَرْضِ وَمَا
كُنَّا سَارِقِينَ
Qaloo tallahi laqadAAalimtum ma ji/na linufsida fee al-ardi wamakunna sariqeen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "A fi Allāhu búra, dájúdájú ẹ mọ̀ pé a kò wá láti ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Àti pé àwa kì í ṣe olè."
|
Ayah 12:74 الأية
قَالُوا فَمَا جَزَاؤُهُ إِن كُنتُمْ كَاذِبِينَ
Qaloo fama jazaohu inkuntum kathibeen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Kí ni ẹ̀san (fún ẹni tí) ó jí i, tí (ó bá hàn pé) ẹ̀yin jẹ́ òpùrọ́?"
|
Ayah 12:75 الأية
قَالُوا جَزَاؤُهُ مَن وُجِدَ فِي رَحْلِهِ فَهُوَ جَزَاؤُهُ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي
الظَّالِمِينَ
Qaloo jazaohu man wujida feerahlihi fahuwa jazaohu kathalika najzee aththalimeen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Ẹ̀san rẹ̀; ẹni tí wọ́n bá bá a nínú ẹrù rẹ̀, òun náà ni ẹ̀san rẹ̀. Báyẹn ni àwa ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san (ní ọ̀dọ̀ tiwa)."
|
Ayah 12:76 الأية
فَبَدَأَ بِأَوْعِيَتِهِمْ قَبْلَ وِعَاءِ أَخِيهِ ثُمَّ اسْتَخْرَجَهَا مِن
وِعَاءِ أَخِيهِ ۚ كَذَٰلِكَ كِدْنَا لِيُوسُفَ ۖ مَا كَانَ لِيَأْخُذَ أَخَاهُ فِي
دِينِ الْمَلِكِ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللهُ ۚ نَرْفَعُ دَرَجَاتٍ مَّن نَّشَاءُ ۗ
وَفَوْقَ كُلِّ ذِي عِلْمٍ عَلِيمٌ
Fabadaa bi-awAAiyatihim qabla wiAAa-iakheehi thumma istakhrajaha min wiAAa-i
akheehi kathalikakidna liyoosufa ma kana liya/khuthaakhahu fee deeni almaliki
illa an yashaa AllahunarfaAAu darajatin man nashao wafawqa kulli theeAAilmin
AAaleem
Yoruba
Ó sì bẹ̀rẹ̀ (àyẹ̀wò) pẹ̀lú àpò wọn ṣíwájú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú un jáde láti inú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Báyẹn ní A ṣe fún (Ànábì) Yūsuf ní ète dá. Kò lè fi òfin ọba mú ọmọ-ìyá rẹ̀ àfi tí Allāhu bá fẹ́. À ń ṣàgbéga àwọn ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Onímọ̀ wà lókè gbogbo onímọ̀.
|
Ayah 12:77 الأية
قَالُوا إِن يَسْرِقْ فَقَدْ سَرَقَ أَخٌ لَّهُ مِن قَبْلُ ۚ فَأَسَرَّهَا يُوسُفُ
فِي نَفْسِهِ وَلَمْ يُبْدِهَا لَهُمْ ۚ قَالَ أَنتُمْ شَرٌّ مَّكَانًا ۖ وَاللهُ
أَعْلَمُ بِمَا تَصِفُونَ
Qaloo in yasriq faqad saraqa akhunlahu min qablu faasarraha yoosufu fee nafsihi
walam yubdihalahum qala antum sharrun makanan wallahuaAAlamu bima tasifoon
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Tí ó bá jalè, dájúdájú ọmọ-ìyá rẹ̀ kan ti jalè ṣíwájú." (Ànábì) Yūsuf sì fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀, kò sì fi hàn sí wọn pé (kò rí bẹ́ẹ̀). Ó (sì) sọ pé: "Ẹ̀yin lẹ burú jùlọ ní ipò. Allāhu l'Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ròyìn rẹ̀."
|
Ayah 12:78 الأية
قَالُوا يَا أَيُّهَا الْعَزِيزُ إِنَّ لَهُ أَبًا شَيْخًا كَبِيرًا فَخُذْ
أَحَدَنَا مَكَانَهُ ۖ إِنَّا نَرَاكَ مِنَ الْمُحْسِنِينَ
Qaloo ya ayyuhaalAAazeezu inna lahu aban shaykhan kabeeran fakhuth
ahadanamakanahu inna naraka mina almuhsineen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Ìwọ ọba, dájúdájú ó ní bàbá arúgbó àgbàlágbà kan. Nítorí náà, mú ẹnì kan nínú wa dípò rẹ̀. Dájúdájú àwa ń rí ìwọ pé o wà nínú àwọn ẹni-rere."
|
Ayah 12:79 الأية
قَالَ مَعَاذَ اللهِ أَن نَّأْخُذَ إِلَّا مَن وَجَدْنَا مَتَاعَنَا عِندَهُ
إِنَّا إِذًا لَّظَالِمُونَ
Qala maAAatha Allahi anna/khutha illa man wajadna mataAAanaAAindahu inna ithan
lathalimoon
Yoruba
Ó sọ pé: "Mo sádi Allāhu pé kí á mú ẹnì kan àfi ẹni tí a bá ẹrù wa lọ́dọ̀ rẹ. (Tí a bá mú ẹlòmíìràn) dájúdájú nígbà náà alábòsí ni wá."
|
Ayah 12:80 الأية
فَلَمَّا اسْتَيْأَسُوا مِنْهُ خَلَصُوا نَجِيًّا ۖ قَالَ كَبِيرُهُمْ أَلَمْ
تَعْلَمُوا أَنَّ أَبَاكُمْ قَدْ أَخَذَ عَلَيْكُم مَّوْثِقًا مِّنَ اللهِ وَمِن
قَبْلُ مَا فَرَّطتُمْ فِي يُوسُفَ ۖ فَلَنْ أَبْرَحَ الْأَرْضَ حَتَّىٰ يَأْذَنَ
لِي أَبِي أَوْ يَحْكُمَ اللهُ لِي ۖ وَهُوَ خَيْرُ الْحَاكِمِينَ
Falamma istay-asoo minhu khalasoonajiyyan qala kabeeruhum alam taAAlamoo anna
abakumqad akhatha AAalaykum mawthiqan mina Allahi waminqablu ma farrattum fee
yoosufa falan abrahaal-arda hatta ya/thana lee abee aw yahkumaAllahu lee wahuwa
khayru alhakimeen
Yoruba
Nígbà tí wọ́n sọ̀rètí nù lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n tẹ̀ sọ̀rọ̀. Àgbà (nínú) wọn sọ pé: "Ṣé ẹ kò mọ̀ pé dájúdájú bàbá yín ti gba àdéhùn yín tí (ẹ ṣe ní orúkọ) Allāhu. Àti pé ṣíwájú (èyí, ohun tí ẹ ṣe ní) àṣeètó lórí ọ̀rọ̀ (Ànábì) Yūsuf. Nítorí náà, èmi kò níí fi ilẹ̀ (Misrọ) sílẹ̀ títí bàbá mi yóò fi yọ̀ǹda fún mi tàbí (títí) Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ fún mi. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.
|
Ayah 12:81 الأية
ارْجِعُوا إِلَىٰ أَبِيكُمْ فَقُولُوا يَا أَبَانَا إِنَّ ابْنَكَ سَرَقَ وَمَا
شَهِدْنَا إِلَّا بِمَا عَلِمْنَا وَمَا كُنَّا لِلْغَيْبِ حَافِظِينَ
IrjiAAoo ila abeekum faqooloo yaabana inna ibnaka saraqa wama shahidnailla bima
AAalimna wama kunnalilghaybi hafitheen
Yoruba
Ẹ padà sọ́dọ̀ bàbá yín, kí ẹ sì sọ pé: "Bàbá wa, dájúdájú ọmọ rẹ jalè. A kò sì lè jẹ́rìí (sí kiní kan) àfi ohun tí a bá nímọ̀ (nípa) rẹ̀. Àwa sì kọ́ ni à ń ṣọ ìkọ̀kọ̀ (ẹ̀dá).
|
Ayah 12:82 الأية
وَاسْأَلِ الْقَرْيَةَ الَّتِي كُنَّا فِيهَا وَالْعِيرَ الَّتِي أَقْبَلْنَا
فِيهَا ۖ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ
Was-ali alqaryata allatee kunnafeeha walAAeera allatee aqbalna feehawa-inna
lasadiqoon
Yoruba
Kí o sì bi àwọn ará ìlú tí a wà nínú rẹ̀ àti èrò-ràkúnmí tí a jọ darí dé léèrè wò. Dájúdájú olódodo ni wá."
|
Ayah 12:83 الأية
قَالَ بَلْ سَوَّلَتْ لَكُمْ أَنفُسُكُمْ أَمْرًا ۖ فَصَبْرٌ جَمِيلٌ ۖ عَسَى
اللهُ أَن يَأْتِيَنِي بِهِمْ جَمِيعًا ۚ إِنَّهُ هُوَ الْعَلِيمُ الْحَكِيمُ
Qala bal sawwalat lakum anfusukumamran fasabrun jameelun AAasa Allahu
anya/tiyanee bihim jameeAAan innahu huwa alAAaleemu alhakeem
Yoruba
(Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: "Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù tó rẹwà (lọ̀rọ̀ mi kàn báyìí). Ó ṣeé ṣe kí Allāhu bá mi mú gbogbo wọn wá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n."
|
Ayah 12:84 الأية
وَتَوَلَّىٰ عَنْهُمْ وَقَالَ يَا أَسَفَىٰ عَلَىٰ يُوسُفَ وَابْيَضَّتْ عَيْنَاهُ
مِنَ الْحُزْنِ فَهُوَ كَظِيمٌ
Watawalla AAanhum waqala yaasafa AAala yoosufa wabyaddat AAaynahumina alhuzni
fahuwa katheem
Yoruba
Ó pa wọ́n tì, ó sì sọ pé: "Ìbànújẹ́ ń bẹ fún mi lórí Yūsuf!" Ojú rẹ̀ méjèèjì sì funfun wá (kò ríran mọ́) látara ìbànújẹ́ náà; ó sì pa á mọ́ra.
|
Ayah 12:85 الأية
قَالُوا تَاللهِ تَفْتَأُ تَذْكُرُ يُوسُفَ حَتَّىٰ تَكُونَ حَرَضًا أَوْ تَكُونَ
مِنَ الْهَالِكِينَ
Qaloo tallahi taftaotathkuru yoosufa hatta takoona haradanaw takoona mina
alhalikeen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "A fi Allāhu búra, ìwọ kò yé rántí Yūsuf títí o máa fi di yánnayànna tàbí (títí) o máa fi di ara àwọn òkú."
|
Ayah 12:86 الأية
قَالَ إِنَّمَا أَشْكُو بَثِّي وَحُزْنِي إِلَى اللهِ وَأَعْلَمُ مِنَ اللهِ
مَا لَا تَعْلَمُونَ
Qala innama ashkoo baththee wahuzneeila Allahi waaAAlamu mina Allahi ma
lataAAlamoon
Yoruba
Ó sọ pé: "Allāhu mà ni èmi ń ro ẹ̀dùn ọkàn mi àti ìbànújẹ́ mi fún. Mo sì mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.
|
Ayah 12:87 الأية
يَا بَنِيَّ اذْهَبُوا فَتَحَسَّسُوا مِن يُوسُفَ وَأَخِيهِ وَلَا تَيْأَسُوا مِن
رَّوْحِ اللهِ ۖ إِنَّهُ لَا يَيْأَسُ مِن رَّوْحِ اللهِ إِلَّا الْقَوْمُ
الْكَافِرُونَ
Ya baniyya ithhaboo fatahassasoomin yoosufa waakheehi wala tay-asoo min rawhi
Allahiinnahu la yay-asu min rawhi Allahi illaalqawmu alkafiroon
Yoruba
Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ lọ wádìí nípa Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀. Ẹ sì má ṣe sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu àfi ìjọ aláìgbàgbọ́."
|
Ayah 12:88 الأية
فَلَمَّا دَخَلُوا عَلَيْهِ قَالُوا يَا أَيُّهَا الْعَزِيزُ مَسَّنَا وَأَهْلَنَا
الضُّرُّ وَجِئْنَا بِبِضَاعَةٍ مُّزْجَاةٍ فَأَوْفِ لَنَا الْكَيْلَ وَتَصَدَّقْ
عَلَيْنَا ۖ إِنَّ اللهَ يَجْزِي الْمُتَصَدِّقِينَ
Falamma dakhaloo AAalayhi qalooya ayyuha alAAazeezu massana waahlanaaddurru
waji/na bibidaAAatin muzjatinfaawfi lana alkayla watasaddaq AAalayna innaAllaha
yajzee almutasaddiqeen
Yoruba
Nìgbà tí wọ́n wọlé tọ Yūsuf, wọ́n sọ pé: "Ìwọ ọba, ìnira (ebi) ti mú àwa àti ará ilé wa. A sì mú owó kan tí ẹ máa ta dànù lọ́wọ́. Nítorí náà, wọn kóńgò (oúnjẹ) náà kún fún wa, kí ó sì ta wá lọ́rẹ. Dájúdájú Allāhu yóò san àwọn olùtọrẹ ní ẹ̀san rere."
|
Ayah 12:89 الأية
قَالَ هَلْ عَلِمْتُم مَّا فَعَلْتُم بِيُوسُفَ وَأَخِيهِ إِذْ أَنتُمْ جَاهِلُونَ
Qala hal AAalimtum mafaAAaltum biyoosufa waakheehi ith antum jahiloon
Yoruba
Ó sọ pé: "Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ẹ ṣe fún Yūsuf àti ọmọ ìyá rẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìmọ̀kan?"
|
Ayah 12:90 الأية
قَالُوا أَإِنَّكَ لَأَنتَ يُوسُفُ ۖ قَالَ أَنَا يُوسُفُ وَهَٰذَا أَخِي ۖ قَدْ
مَنَّ اللهُ عَلَيْنَا ۖ إِنَّهُ مَن يَتَّقِ وَيَصْبِرْ فَإِنَّ اللهَ لَا
يُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ
Qaloo a-innaka laanta yoosufa qalaana yoosufu wahatha akhee qad manna
AllahuAAalayna innahu man yattaqi wayasbir fa-inna Allahala yudeeAAu ajra
almuhsineen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Ṣé dájúdájú ìwọ ni Yūsuf?" Ó sọ pé: "Èmi ni Yūsuf. Ọmọ ìyá mi sì nìyí. Dájúdájú Allāhu ti ṣe ìdẹ̀ra fún wa. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu), tí ó sì ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre."
|
Ayah 12:91 الأية
قَالُوا تَاللهِ لَقَدْ آثَرَكَ اللهُ عَلَيْنَا وَإِن كُنَّا لَخَاطِئِينَ
Qaloo tallahi laqad atharakaAllahu AAalayna wa-in kunna lakhati-een
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "A fi Allāhu búra! Dájúdájú Allāhu ti gbọ́lá fún ọ jù wá lọ. Àti pé dájúdájú àwa ni aláṣìṣe."
|
Ayah 12:92 الأية
قَالَ لَا تَثْرِيبَ عَلَيْكُمُ الْيَوْمَ ۖ يَغْفِرُ اللهُ لَكُمْ ۖ وَهُوَ
أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ
Qala la tathreeba AAalaykumualyawma yaghfiru Allahu lakum wahuwa arhamu
arrahimeen
Yoruba
Ó sọ pé: "Kò sí ìbáwí fún yín ní òní. Allāhu yóò foríjìn yín. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.
|
Ayah 12:93 الأية
اذْهَبُوا بِقَمِيصِي هَٰذَا فَأَلْقُوهُ عَلَىٰ وَجْهِ أَبِي يَأْتِ بَصِيرًا
وَأْتُونِي بِأَهْلِكُمْ أَجْمَعِينَ
Ithhaboo biqameesee hathafaalqoohu AAala wajhi abee ya/ti baseeran
wa/tooneebi-ahlikum ajmaAAeen
Yoruba
Ẹ mú ẹ̀wù mi yìí lọ, kí ẹ fi lé iwájú bàbá mi, ó máa padà di olùríran. Kí ẹ sì kó gbogbo ẹbí yín wá bá mi."
|
Ayah 12:94 الأية
وَلَمَّا فَصَلَتِ الْعِيرُ قَالَ أَبُوهُمْ إِنِّي لَأَجِدُ رِيحَ يُوسُفَ ۖ
لَوْلَا أَن تُفَنِّدُونِ
Walamma fasalati alAAeeru qalaaboohum innee laajidu reeha yoosufa lawla
antufannidoon
Yoruba
Nígbà tí èrò-ràkúnmí náà sí pínyà (kúrò lọ́dọ̀ Ànábì Yūsuf), bàbá wọn sọ pé: "Dájúdájú èmi ń gbọ́ òórùn Yūsuf tí ẹ kò bá níí sọ pé mò ń jarán."
|
Ayah 12:95 الأية
قَالُوا تَاللهِ إِنَّكَ لَفِي ضَلَالِكَ الْقَدِيمِ
Qaloo tallahi innakalafee dalalika alqadeem
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "A fi Allāhu búra! Dájúdájú ìwọ sì wà nínú àṣìṣe rẹ ti àtijọ́ (nípa ìfẹ́ Yūsuf)."
|
Ayah 12:96 الأية
فَلَمَّا أَن جَاءَ الْبَشِيرُ أَلْقَاهُ عَلَىٰ وَجْهِهِ فَارْتَدَّ بَصِيرًا ۖ
قَالَ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ إِنِّي أَعْلَمُ مِنَ اللهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ
Falamma an jaa albasheeru alqahuAAala wajhihi fartadda baseeran qalaalam aqul
lakum innee aAAlamu mina Allahi ma lataAAlamoon
Yoruba
Nígbà tí oníròó-ìdùnnú dé, ó ju (ẹ̀wù náà) lé e níwájú, ó sì ríran padà. Ó sọ pé: "Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú mo mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu."
|
Ayah 12:97 الأية
قَالُوا يَا أَبَانَا اسْتَغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا إِنَّا كُنَّا خَاطِئِينَ
Qaloo ya abanaistaghfir lana thunoobana inna kunnakhati-een
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "Bàbá wa, tọrọ àforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa, dájúdájú àwa jẹ́ aláṣìṣe."
|
Ayah 12:98 الأية
قَالَ سَوْفَ أَسْتَغْفِرُ لَكُمْ رَبِّي ۖ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Qala sawfa astaghfiru lakum rabbeeinnahu huwa alghafooru arraheem
Yoruba
Ó sọ pé: "Láìpẹ́ mo máa tọrọ àforíjìn fún yín lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
|
Ayah 12:99 الأية
فَلَمَّا دَخَلُوا عَلَىٰ يُوسُفَ آوَىٰ إِلَيْهِ أَبَوَيْهِ وَقَالَ ادْخُلُوا
مِصْرَ إِن شَاءَ اللهُ آمِنِينَ
Falamma dakhaloo AAala yoosufaawa ilayhi abawayhi waqala odkhuloo misrain shaa
Allahu amineen
Yoruba
Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Yūsuf, ó kó àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ pé: "Ẹ wọ ìlú Misrọ ní olùfàyàbalẹ̀ - tí Allāhu bá fẹ́ -."
|
Ayah 12:100 الأية
وَرَفَعَ أَبَوَيْهِ عَلَى الْعَرْشِ وَخَرُّوا لَهُ سُجَّدًا ۖ وَقَالَ يَا أَبَتِ
هَٰذَا تَأْوِيلُ رُؤْيَايَ مِن قَبْلُ قَدْ جَعَلَهَا رَبِّي حَقًّا ۖ وَقَدْ
أَحْسَنَ بِي إِذْ أَخْرَجَنِي مِنَ السِّجْنِ وَجَاءَ بِكُم مِّنَ الْبَدْوِ مِن
بَعْدِ أَن نَّزَغَ الشَّيْطَانُ بَيْنِي وَبَيْنَ إِخْوَتِي ۚ إِنَّ رَبِّي
لَطِيفٌ لِّمَا يَشَاءُ ۚ إِنَّهُ هُوَ الْعَلِيمُ الْحَكِيمُ
WarafaAAa abawayhi AAala alAAarshiwakharroo lahu sujjadan waqala ya abati
hathata/weelu ru/yaya min qablu qad jaAAalaha rabbee haqqanwaqad ahsana bee ith
akhrajanee mina assijniwajaa bikum mina albadwi min baAAdi an nazagha
ashshaytanubaynee wabayna ikhwatee inna rabbee lateefun limayashao innahu huwa
alAAaleemu alhakeem
Yoruba
Ó gbé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì sórí ìtẹ́. Wọ́n sì wó lulẹ̀ fún un, tí wọ́n forí kanlẹ̀ kí i. Ó sọ pé: "Bàbá mi, èyí ni ìtúmọ̀ àlá mi (tí mo lá) ṣíwájú. Dájúdájú Olúwa mi ti sọ ọ́ di òdodo. Ó sì ṣe dáadáa fún mi nígbà tí Ó mú mi jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó tún mu yín wá (bá mi) láti inú oko lẹ́yìn tí Èṣù ti saburú sáààrin èmi àti àwọn ọbà-kan mi. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú fún ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 12:101 الأية
رَبِّ قَدْ آتَيْتَنِي مِنَ الْمُلْكِ وَعَلَّمْتَنِي مِن تَأْوِيلِ الْأَحَادِيثِ
ۚ فَاطِرَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ أَنتَ وَلِيِّي فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۖ
تَوَفَّنِي مُسْلِمًا وَأَلْحِقْنِي بِالصَّالِحِينَ
Rabbi qad ataytanee mina almulkiwaAAallamtanee min ta/weeli al-ahadeethi fatira
assamawatiwal-ardi anta waliyyee fee addunyawal-akhirati tawaffanee musliman
waalhiqneebissaliheen
Yoruba
Olúwa mi, dájúdájú O ti fún mi nínú ìjọba. O tún fún mi nínú ìmọ̀ ìtúmọ̀ àlá. Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Ìwọ ni Alátìlẹ́yìn mi ní ayé àti ní ọ̀run, pa mí sípò mùsùlùmí. Kí O sì fi mí pẹ̀lú àwọn ẹni rere."
|
Ayah 12:102 الأية
ذَٰلِكَ مِنْ أَنبَاءِ الْغَيْبِ نُوحِيهِ إِلَيْكَ ۖ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ
أَجْمَعُوا أَمْرَهُمْ وَهُمْ يَمْكُرُونَ
Thalika min anba-i alghaybinooheehi ilayka wama kunta ladayhim ithajmaAAoo
amrahum wahum yamkuroon
Yoruba
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí A fi ìmísí (rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Àti pé ìwọ kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ wọn, tí wọ́n ń déte.
|
Ayah 12:103 الأية
وَمَا أَكْثَرُ النَّاسِ وَلَوْ حَرَصْتَ بِمُؤْمِنِينَ
Wama aktharu annasiwalaw harasta bimu/mineen
Yoruba
Ìwọ ìbáà ṣojú kòkòrò (ìgbàlà wọn), ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò níí gbàgbọ́.
|
Ayah 12:104 الأية
وَمَا تَسْأَلُهُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ
لِّلْعَالَمِينَ
Wama tas-aluhum AAalayhi min ajrinin huwa illa thikrun lilAAalameen
Yoruba
Ìwọ kò sì bi wọ́n léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 12:105 الأية
وَكَأَيِّن مِّنْ آيَةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ يَمُرُّونَ عَلَيْهَا وَهُمْ
عَنْهَا مُعْرِضُونَ
Wakaayyin min ayatin fee assamawatiwal-ardi yamurroona AAalayha wahum
AAanhamuAAridoon
Yoruba
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn àmì tí ń bẹ ní sánmọ̀ àti ní orí ilẹ̀ tí wọ́n ń ré kọjá lórí rẹ̀, tí wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.
|
Ayah 12:106 الأية
وَمَا يُؤْمِنُ أَكْثَرُهُم بِاللهِ إِلَّا وَهُم مُّشْرِكُونَ
Wama yu/minu aktharuhum billahiilla wahum mushrikoon
Yoruba
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni kò níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àfi kí wọ́n tún máa ṣẹbọ.
|
Ayah 12:107 الأية
أَفَأَمِنُوا أَن تَأْتِيَهُمْ غَاشِيَةٌ مِّنْ عَذَابِ اللهِ أَوْ تَأْتِيَهُمُ
السَّاعَةُ بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Afaaminoo an ta/tiyahum ghashiyatunmin AAathabi Allahi aw ta/tiyahumu
assaAAatubaghtatan wahum la yashAAuroon
Yoruba
Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ pé ohun tí ń bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ nínú ìyà Allāhu kò lè dé bá àwọn ni tàbí pé Àkókò náà kò lè kò lé àwọn lórí ní òjijì, tí wọn kò sì níí fura?
|
Ayah 12:108 الأية
قُلْ هَٰذِهِ سَبِيلِي أَدْعُو إِلَى اللهِ ۚ عَلَىٰ بَصِيرَةٍ أَنَا وَمَنِ
اتَّبَعَنِي ۖ وَسُبْحَانَ اللهِ وَمَا أَنَا مِنَ الْمُشْرِكِينَ
Qul hathihi sabeelee adAAoo ilaAllahi AAala baseeratin ana wamaniittabaAAanee
wasubhana Allahi wama anamina almushrikeen
Yoruba
Sọ pé: "Èyí ni ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) mi, èmi àti àwọn tó tẹ̀lé mi sì ń pèpè sí (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Mímọ́ ni fún Allāhu. Èmi kò sì sí lára àwọn ọ̀ṣẹbọ."
|
Ayah 12:109 الأية
وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ إِلَّا رِجَالًا نُّوحِي إِلَيْهِم مِّنْ أَهْلِ
الْقُرَىٰ ۗ أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ
الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۗ وَلَدَارُ الْآخِرَةِ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ اتَّقَوْا ۗ
أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Wama arsalna min qablika illarijalan noohee ilayhim min ahli alquraafalam
yaseeroo fee al-ardi fayanthurookayfa kana AAaqibatu allatheena min
qablihimwaladaru al-akhirati khayrun lillatheenaittaqaw afala taAAqiloon
Yoruba
A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí nínú àwọn ará ìlú. Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Dájúdájú Ilé ìkẹ́yìn lóore jùlọ fún àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?
|
Ayah 12:110 الأية
حَتَّىٰ إِذَا اسْتَيْأَسَ الرُّسُلُ وَظَنُّوا أَنَّهُمْ قَدْ كُذِبُوا جَاءَهُمْ
نَصْرُنَا فَنُجِّيَ مَن نَّشَاءُ ۖ وَلَا يُرَدُّ بَأْسُنَا عَنِ الْقَوْمِ
الْمُجْرِمِينَ
Hatta itha istay-asa arrusuluwathannoo annahum qad kuthiboo jaahumnasruna
fanujjiya man nashao walayuraddu ba/suna AAani alqawmi almujrimeen
Yoruba
(A kì í jẹ àwọn ènìyàn níyà) títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ bá tó sọ̀rètí nù (nípa ìgbàgbọ́ wọn), tí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n ti pe àwọn ní òpùrọ́. Àrànṣe Wa yó sì dé bá wọn. A sì máa gba ẹni tí A bá fẹ́ là. Wọn kò lè dá ìyà Wa padà lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
|
Ayah 12:111 الأية
لَقَدْ كَانَ فِي قَصَصِهِمْ عِبْرَةٌ لِّأُولِي الْأَلْبَابِ ۗ مَا كَانَ حَدِيثًا
يُفْتَرَىٰ وَلَٰكِن تَصْدِيقَ الَّذِي بَيْنَ يَدَيْهِ وَتَفْصِيلَ كُلِّ شَيْءٍ
وَهُدًى وَرَحْمَةً لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Laqad kana fee qasasihimAAibratun li-olee al-albabi ma kana hadeethanyuftara
walakin tasdeeqa allatheebayna yadayhi watafseela kulli shay-in wahudan
warahmatanliqawmin yu/minoon
Yoruba
Dájúdájú àríwòye wà nínú ìtàn wọn fún àwọn onílàákàyè. (Al-Ƙur'ān) kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń hun, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣàlàyé gbogbo n̄ǹkan; ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|