Prev  

38. Surah Sâd. سورة ص

  Next  



1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
ص ۚ وَالْقُرْآنِ ذِي الذِّكْرِ
Sad walqur-ani theeaththikr

Yoruba
 
Sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.) Allāhu fi al-Ƙur'ān tí ó kún fún ìrántí bura.

Ayah  38:2  الأية
بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي عِزَّةٍ وَشِقَاقٍ
Bali allatheena kafaroo fee AAizzatinwashiqaq

Yoruba
 
Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wà nínú ìgbéraga àti ìyapa (òdodo).

Ayah  38:3  الأية
كَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَبْلِهِم مِّن قَرْنٍ فَنَادَوا وَّلَاتَ حِينَ مَنَاصٍ
Kam ahlakna min qablihim min qarninfanadaw walata heena manas

Yoruba
 
Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) nígbà tí kò sí ibùsásí kan.

Ayah  38:4  الأية
وَعَجِبُوا أَن جَاءَهُم مُّنذِرٌ مِّنْهُمْ ۖ وَقَالَ الْكَافِرُونَ هَٰذَا سَاحِرٌ كَذَّابٌ
WaAAajiboo an jaahum munthirunminhum waqala alkafiroona hatha sahirunkaththab

Yoruba
 
Wọ́n ṣèèmọ̀ pé olùkìlọ̀ kan nínú wọn wá bá wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: "Èyí ni òpìdán, òpùrọ́."

Ayah  38:5  الأية
أَجَعَلَ الْآلِهَةَ إِلَٰهًا وَاحِدًا ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ عُجَابٌ
AjaAAala al-alihata ilahan wahidaninna hatha lashay-on AAujab

Yoruba
 
Ṣé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu.

Ayah  38:6  الأية
وَانطَلَقَ الْمَلَأُ مِنْهُمْ أَنِ امْشُوا وَاصْبِرُوا عَلَىٰ آلِهَتِكُمْ ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ يُرَادُ
Wantalaqa almalao minhum aniimshoo wasbiroo AAala alihatikuminna hatha lashay-on yurad

Yoruba
 
Àwọn aṣíwájú nínú wọn sì lọ (káà kiri láti wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn wọn) pé: "Ẹ máa bá (ìbọ̀rìṣà) lọ, kí ẹ sì dúró ṣinṣin ti àwọn òrìṣà yín. Dájúdájú èyí (jíjẹ́ ọ̀kan ṣoṣo Allāhu) ni n̄ǹkan tí wọ́n ń gbàlérò (láti fi pa àwọn òrìṣà yín run).

Ayah  38:7  الأية
مَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي الْمِلَّةِ الْآخِرَةِ إِنْ هَٰذَا إِلَّا اخْتِلَاقٌ
Ma samiAAna bihatha feealmillati al-akhirati in hatha illa ikhtilaq

Yoruba
 
Àwa kò gbọ́ èyí nínú ẹ̀sìn ìkẹ́yìn (ìyẹn, ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄). Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àdápa irọ́.

Ayah  38:8  الأية
أَأُنزِلَ عَلَيْهِ الذِّكْرُ مِن بَيْنِنَا ۚ بَلْ هُمْ فِي شَكٍّ مِّن ذِكْرِي ۖ بَل لَّمَّا يَذُوقُوا عَذَابِ
Aonzila AAalayhi aththikru minbaynina bal hum fee shakkin min thikree bal lammayathooqoo AAathab

Yoruba
 
Ṣé Wọ́n sọ (tírà) Ìrántí kalẹ̀ fún un láààrin wa ni?" Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa (tírà) Ìrántí Mi (tí Mo sọ̀kalẹ̀ ni). Rárá, wọn kò tí ì tọ́ ìyà Mi wò ni.

Ayah  38:9  الأية
أَمْ عِندَهُمْ خَزَائِنُ رَحْمَةِ رَبِّكَ الْعَزِيزِ الْوَهَّابِ
Am AAindahum khaza-inu rahmatirabbika alAAazeezi alwahhab

Yoruba
 
Tàbí tiwọn ni àwọn ilé ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ, Alágbára, Ọlọ́rẹ?

Ayah  38:10  الأية
أَمْ لَهُم مُّلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ فَلْيَرْتَقُوا فِي الْأَسْبَابِ
Am lahum mulku assamawatiwal-ardi wama baynahuma falyartaqoofee al-asbab

Yoruba
 
Tàbí tiwọn ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin méjèèjì? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wọn wá àwọn ọ̀nà láti fi gùnkè wá (bá Wa).

Ayah  38:11  الأية
جُندٌ مَّا هُنَالِكَ مَهْزُومٌ مِّنَ الْأَحْزَابِ
Jundun ma hunalika mahzoomunmina al-ahzab

Yoruba
 
A máa ṣẹ́gun ọmọ ogun tó wà níbẹ̀ yẹn nínú ọmọ ogun oníjọ.

Ayah  38:12  الأية
كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَعَادٌ وَفِرْعَوْنُ ذُو الْأَوْتَادِ
Kaththabat qablahum qawmu noohinwaAAadun wafirAAawnu thoo al-awtad

Yoruba
 
Àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti Fir‘aon, eléèkàn, wọ́n pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn.

Ayah  38:13  الأية
وَثَمُودُ وَقَوْمُ لُوطٍ وَأَصْحَابُ الْأَيْكَةِ ۚ أُولَٰئِكَ الْأَحْزَابُ
Wathamoodu waqawmu lootin waas-habual-aykati ola-ika al-ahzab

Yoruba
 
Ìjọ Thamūd, ìjọ Lūt àti àwọn ará 'Aekah, àwọn wọ̀nyẹn (tún ni) àwọn ìjọ (tó pe òdodo ní irọ́).

Ayah  38:14  الأية
إِن كُلٌّ إِلَّا كَذَّبَ الرُّسُلَ فَحَقَّ عِقَابِ
In kullun illa kaththaba arrusulafahaqqa AAiqab

Yoruba
 
Kò sí ẹnì kan nínú wọn tí kò pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà Mi sì kò lé wọn lórí.

Ayah  38:15  الأية
وَمَا يَنظُرُ هَٰؤُلَاءِ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً مَّا لَهَا مِن فَوَاقٍ
Wama yanthuru haola-iilla sayhatan wahidatan ma lahamin fawaq

Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyí kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan, tí kò níí ní ìdádúró.

Ayah  38:16  الأية
وَقَالُوا رَبَّنَا عَجِّل لَّنَا قِطَّنَا قَبْلَ يَوْمِ الْحِسَابِ
Waqaloo rabbana AAajjil lanaqittana qabla yawmi alhisab

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, yára fi ìwé iṣẹ́ wa (àti ìpín ẹ̀san wa) lé wa lọ́wọ́ ṣíwájú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́."

Ayah  38:17  الأية
اصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَاذْكُرْ عَبْدَنَا دَاوُودَ ذَا الْأَيْدِ ۖ إِنَّهُ أَوَّابٌ
Isbir AAala mayaqooloona wathkur AAabdana dawooda thaal-aydi innahu awwab

Yoruba
 
Ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ. Kí o sì ṣèrántí ìtàn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) Dāwūd, alágbára. Dájúdájú ó jẹ́ olùronúpìwàdà.

Ayah  38:18  الأية
إِنَّا سَخَّرْنَا الْجِبَالَ مَعَهُ يُسَبِّحْنَ بِالْعَشِيِّ وَالْإِشْرَاقِ
Inna sakhkharna aljibalamaAAahu yusabbihna bilAAashiyyi wal-ishraq

Yoruba
 
Dájúdájú Àwa tẹ àwọn àpáta lórí ba tí wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ (fún Allāhu) ní ìrọ̀lẹ́ àti nígbà tí òòrùn bá yọ (ní òwúrọ̀).

Ayah  38:19  الأية
وَالطَّيْرَ مَحْشُورَةً ۖ كُلٌّ لَّهُ أَوَّابٌ
Wattayra mahshooratankullun lahu awwab

Yoruba
 
Àti àwọn ẹyẹ náà, A kó wọn jọ fún un. Ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ (láti ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu).

Ayah  38:20  الأية
وَشَدَدْنَا مُلْكَهُ وَآتَيْنَاهُ الْحِكْمَةَ وَفَصْلَ الْخِطَابِ
Washadadna mulkahu waataynahualhikmata wafasla alkhitab

Yoruba
 
Àti pé A fún ìjọba rẹ̀ ní agbára. A sì fún un ní ipò Ànábì àti ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ àti ìdájọ́.

Ayah  38:21  الأية
وَهَلْ أَتَاكَ نَبَأُ الْخَصْمِ إِذْ تَسَوَّرُوا الْمِحْرَابَ
Wahal ataka nabao alkhasmi ithtasawwaroo almihrab

Yoruba
 
Ǹjẹ́ ìró àwọn oníjà ti dé ọ̀dọ̀ rẹ; nígbà tí wọ́n pọ́n ògiri ilé ìjọ́sìn?

Ayah  38:22  الأية
إِذْ دَخَلُوا عَلَىٰ دَاوُودَ فَفَزِعَ مِنْهُمْ ۖ قَالُوا لَا تَخَفْ ۖ خَصْمَانِ بَغَىٰ بَعْضُنَا عَلَىٰ بَعْضٍ فَاحْكُم بَيْنَنَا بِالْحَقِّ وَلَا تُشْطِطْ وَاهْدِنَا إِلَىٰ سَوَاءِ الصِّرَاطِ
Ith dakhaloo AAala dawoodafafaziAAa minhum qaloo la takhaf khasmanibagha baAAduna AAala baAAdinfahkum baynana bilhaqqi walatushtit wahdina ila sawa-iassirat

Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Dāwūd, ẹ̀rù wọn bà á. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Oníjà méjì (ni wá). Apá kan wa tayọ ẹnu-ààlà sí apá kan. Nítorí náà, fi òdodo dájọ́ láààrin wa. Má ṣàbòsí. Kí o sì tọ́ wa sí ọ̀nà tààrà.

Ayah  38:23  الأية
إِنَّ هَٰذَا أَخِي لَهُ تِسْعٌ وَتِسْعُونَ نَعْجَةً وَلِيَ نَعْجَةٌ وَاحِدَةٌ فَقَالَ أَكْفِلْنِيهَا وَعَزَّنِي فِي الْخِطَابِ
Inna hatha akhee lahu tisAAunwatisAAoona naAAjatan waliya naAAjatun wahidatun faqalaakfilneeha waAAazzanee fee alkhitab

Yoruba
 
Dájúdájú èyí ni arákùnrin mi. Ó ní abo ewúrẹ́ mọ́kàndín-lọ́gọ́rùn-ún. Èmi sì ní abo ewúrẹ́ ẹyọ kan. Ó sì sọ pé: "Fà á lé mi lọ́wọ́ (Fi mí ṣe alámòójútó rẹ̀). Ó sì borí mi nínú ọ̀rọ̀." (Ó fi ọ̀rọ̀ tirẹ̀ borí ọ̀rọ̀ tèmi.)

Ayah  38:24  الأية
قَالَ لَقَدْ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعْجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِ ۖ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ الْخُلَطَاءِ لَيَبْغِي بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَقَلِيلٌ مَّا هُمْ ۗ وَظَنَّ دَاوُودُ أَنَّمَا فَتَنَّاهُ فَاسْتَغْفَرَ رَبَّهُ وَخَرَّ رَاكِعًا وَأَنَابَ ۩
Qala laqad thalamakabisu-ali naAAjatika ila niAAajihi wa-innakatheeran mina alkhulata-i layabghee baAAduhum AAalabaAAdin illa allatheena amanoowaAAamiloo assalihati waqaleelun mahum wathanna dawoodu annama fatannahufastaghfara rabbahu wakharra rakiAAan waanab

Yoruba
 
(Ànábì Dāwūd) sọ pé: "Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-ààlà lórí apá kan àfi àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n." (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu).

Ayah  38:25  الأية
فَغَفَرْنَا لَهُ ذَٰلِكَ ۖ وَإِنَّ لَهُ عِندَنَا لَزُلْفَىٰ وَحُسْنَ مَآبٍ
Faghafarna lahu thalikawa-inna lahu AAindana lazulfa wahusna maab

Yoruba
 
Nítorí náà, A ṣàforíjìn ìyẹn fún un. Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un lọ́dọ̀ Wa.

Ayah  38:26  الأية
يَا دَاوُودُ إِنَّا جَعَلْنَاكَ خَلِيفَةً فِي الْأَرْضِ فَاحْكُم بَيْنَ النَّاسِ بِالْحَقِّ وَلَا تَتَّبِعِ الْهَوَىٰ فَيُضِلَّكَ عَن سَبِيلِ اللهِ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَضِلُّونَ عَن سَبِيلِ اللهِ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ بِمَا نَسُوا يَوْمَ الْحِسَابِ
Ya dawoodu inna jaAAalnakakhaleefatan fee al-ardi fahkum bayna annasibilhaqqi wala tattabiAAi alhawa fayudillakaAAan sabeeli Allahi inna allatheena yadilloonaAAan sabeeli Allahi lahum AAathabun shadeedun bimanasoo yawma alhisab

Yoruba
 
(Ànábì) Dāwūd, dájúdájú Àwa ṣe ọ́ ní àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, fi òdodo dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú nítorí kí ó má baà ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Dájúdájú àwọn tó ń sọnù kúrò nínú ẹ̀sìn Allāhu, ìyà líle wà fún wọn nítorí pé, wọ́n gbàgbé Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.

Ayah  38:27  الأية
وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاءَ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا بَاطِلًا ۚ ذَٰلِكَ ظَنُّ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا مِنَ النَّارِ
Wama khalaqna assamaawal-arda wama baynahuma batilanthalika thannu allatheena kafaroofawaylun lillatheena kafaroo mina annar

Yoruba
 
A kò fi irọ́ ṣẹ̀dá sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì. (Irọ́), ìyẹn ni èrò ọkàn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (sí Wa). Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Iná.

Ayah  38:28  الأية
أَمْ نَجْعَلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ كَالْمُفْسِدِينَ فِي الْأَرْضِ أَمْ نَجْعَلُ الْمُتَّقِينَ كَالْفُجَّارِ
Am najAAalu allatheena amanoowaAAamiloo assalihati kalmufsideenafee al-ardi am najAAalu almuttaqeena kalfujjar

Yoruba
 
Ṣé kí Á ṣe àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere bí (A ó ti ṣe) àwọn òbìlẹ̀jẹ́ lórí ilẹ̀? Tàbí ṣé kí Á ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Mi bí A ó ti ṣe) àwọn aṣebi?

Ayah  38:29  الأية
كِتَابٌ أَنزَلْنَاهُ إِلَيْكَ مُبَارَكٌ لِّيَدَّبَّرُوا آيَاتِهِ وَلِيَتَذَكَّرَ أُولُو الْأَلْبَابِ
Kitabun anzalnahu ilayka mubarakunliyaddabbaroo ayatihi waliyatathakkara olooal-albab

Yoruba
 
(Èyí ni) Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa àwọn āyah rẹ̀ àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí.

Ayah  38:30  الأية
وَوَهَبْنَا لِدَاوُودَ سُلَيْمَانَ ۚ نِعْمَ الْعَبْدُ ۖ إِنَّهُ أَوَّابٌ
Wawahabna lidawooda sulaymananiAAma alAAabdu innahu awwab

Yoruba
 
A fi (Ànábì) Sulaemọ̄n ta (Ànábì) Dāwūd lọ́rẹ. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sọ́dọ̀ (Allāhu) ni (nípa ìronúpìwàdà).

Ayah  38:31  الأية
إِذْ عُرِضَ عَلَيْهِ بِالْعَشِيِّ الصَّافِنَاتُ الْجِيَادُ
Ith AAurida AAalayhi bilAAashiyyiassafinatu aljiyad

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹṣin akáwọ́ọ̀jà-lérí asárétete wá bá a ní ìrọ̀lẹ́,

Ayah  38:32  الأية
فَقَالَ إِنِّي أَحْبَبْتُ حُبَّ الْخَيْرِ عَن ذِكْرِ رَبِّي حَتَّىٰ تَوَارَتْ بِالْحِجَابِ
Faqala innee ahbabtu hubbaalkhayri AAan thikri rabbee hatta tawaratbilhijab

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi fẹ́ràn ìfẹ́ ohun rere (ìyẹn, àwọn ẹṣin náà) dípò ìrántí Olúwa Mi (ìyẹn, ìrun ‘Asr) títí òòrùn fi wọ̀.

Ayah  38:33  الأية
رُدُّوهَا عَلَيَّ ۖ فَطَفِقَ مَسْحًا بِالسُّوقِ وَالْأَعْنَاقِ
Ruddooha AAalayya fatafiqa mashanbissooqi wal-aAAnaq

Yoruba
 
Ẹ dá wọn padà sọ́dọ̀ mi." Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi idà gé wọn ní ẹsẹ̀ àti ní ọrùn.

Ayah  38:34  الأية
وَلَقَدْ فَتَنَّا سُلَيْمَانَ وَأَلْقَيْنَا عَلَىٰ كُرْسِيِّهِ جَسَدًا ثُمَّ أَنَابَ
Walaqad fatanna sulaymanawaalqayna AAala kursiyyihi jasadan thumma anab

Yoruba
 
Dájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà).

Ayah  38:35  الأية
قَالَ رَبِّ اغْفِرْ لِي وَهَبْ لِي مُلْكًا لَّا يَنبَغِي لِأَحَدٍ مِّن بَعْدِي ۖ إِنَّكَ أَنتَ الْوَهَّابُ
Qala rabbi ighfir lee wahab leemulkan la yanbaghee li-ahadin min baAAdee innakaanta alwahhab

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi, forí jìn mí. Kí O sì ta mí ní ọrẹ ìjọba kan èyí tí kò níí tọ́ sí ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn mi. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Ọlọ́rẹ."

Ayah  38:36  الأية
فَسَخَّرْنَا لَهُ الرِّيحَ تَجْرِي بِأَمْرِهِ رُخَاءً حَيْثُ أَصَابَ
Fasakhkharna lahu arreehatajree bi-amrihi rukhaan haythu asab

Yoruba
 
Nítorí náà, A tẹ atẹ́gùn ba fún un. Ó ń fẹ́ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn síbi tí ó bá fẹ́.

Ayah  38:37  الأية
وَالشَّيَاطِينَ كُلَّ بَنَّاءٍ وَغَوَّاصٍ
Washshayateena kulla banna-inwaghawwas

Yoruba
 
Àti àwọn èṣù àlùjànnú; gbogbo àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn awakùsà (ni A tẹ̀ ba fún un).

Ayah  38:38  الأية
وَآخَرِينَ مُقَرَّنِينَ فِي الْأَصْفَادِ
Waakhareena muqarraneena fee al-asfad

Yoruba
 
Àti àwọn (àlùjànnú) mìíràn tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mọ́lẹ̀ (A tẹ̀ wọ́n ba fún un).

Ayah  38:39  الأية
هَٰذَا عَطَاؤُنَا فَامْنُنْ أَوْ أَمْسِكْ بِغَيْرِ حِسَابٍ
Hatha AAataona famnunaw amsik bighayri hisab

Yoruba
 
Èyí ni ọrẹ Wa. Nítorí náà, fi tọrẹ tàbí kí ó mú un dání láì níí ní ìṣírò.

Ayah  38:40  الأية
وَإِنَّ لَهُ عِندَنَا لَزُلْفَىٰ وَحُسْنَ مَآبٍ
Wa-inna lahu AAindana lazulfawahusna maab

Yoruba
 
Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un ní ọ̀dọ̀ Wa.

Ayah  38:41  الأية
وَاذْكُرْ عَبْدَنَا أَيُّوبَ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ أَنِّي مَسَّنِيَ الشَّيْطَانُ بِنُصْبٍ وَعَذَابٍ
Wathkur AAabdanaayyooba ith nada rabbahu annee massaniya ashshaytanubinusbin waAAathab

Yoruba
 
Ṣèrántí ẹrúsìn Wa, (Ànábì)'Ayyūb. Nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ (pé): "Dájúdájú Èṣù ti kó ìnira (àìsàn) àti ìyà bá mi."

Ayah  38:42  الأية
ارْكُضْ بِرِجْلِكَ ۖ هَٰذَا مُغْتَسَلٌ بَارِدٌ وَشَرَابٌ
Orkud birijlika hathamughtasalun baridun washarab

Yoruba
 
(Mọlāika sọ fún un pé): "Fi ẹsẹ̀ rẹ janlẹ̀. Èyí ni omi ìwẹ̀ tútù àti omi mímu (fún ìwòsàn rẹ)."

Ayah  38:43  الأية
وَوَهَبْنَا لَهُ أَهْلَهُ وَمِثْلَهُم مَّعَهُمْ رَحْمَةً مِّنَّا وَذِكْرَىٰ لِأُولِي الْأَلْبَابِ
Wawahabna lahu ahlahu wamithlahummaAAahum rahmatan minna wathikrali-olee al-albab

Yoruba
 
A sì ta á lọ́rẹ àwọn ará ilé rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn. (Ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.

Ayah  38:44  الأية
وَخُذْ بِيَدِكَ ضِغْثًا فَاضْرِب بِّهِ وَلَا تَحْنَثْ ۗ إِنَّا وَجَدْنَاهُ صَابِرًا ۚ نِّعْمَ الْعَبْدُ ۖ إِنَّهُ أَوَّابٌ
Wakhuth biyadika dighthan fadribbihi wala tahnath inna wajadnahu sabiranniAAma alAAabdu innahu awwab

Yoruba
 
Fi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ. Dájúdájú Àwa rí ('Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà).

Ayah  38:45  الأية
وَاذْكُرْ عِبَادَنَا إِبْرَاهِيمَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ أُولِي الْأَيْدِي وَالْأَبْصَارِ
Wathkur AAibadanaibraheema wa-ishaqa wayaAAqooba olee al-aydee wal-absar

Yoruba
 
Ṣèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, 'Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára àti olùríran (nípa ẹ̀sìn).

Ayah  38:46  الأية
إِنَّا أَخْلَصْنَاهُم بِخَالِصَةٍ ذِكْرَى الدَّارِ
Inna akhlasnahum bikhalisatinthikra addar

Yoruba
 
Dájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan, (òhun ni) ìrántí Ilé náà (ilé Ìkẹ́yìn).

Ayah  38:47  الأية
وَإِنَّهُمْ عِندَنَا لَمِنَ الْمُصْطَفَيْنَ الْأَخْيَارِ
Wa-innahum AAindana lamina almustafaynaal-akhyar

Yoruba
 
Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa.

Ayah  38:48  الأية
وَاذْكُرْ إِسْمَاعِيلَ وَالْيَسَعَ وَذَا الْكِفْلِ ۖ وَكُلٌّ مِّنَ الْأَخْيَارِ
Wathkur ismaAAeelawa-ilyasaAAa watha alkifli wakullun mina al-akhyar

Yoruba
 
Ṣèrántí (àwọn Ànábì) 'Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘ àti Thul-Kifl. Ìkọ̀ọ̀kan wọn wà nínú àwọn ẹni rere jùlọ.

Ayah  38:49  الأية
هَٰذَا ذِكْرٌ ۚ وَإِنَّ لِلْمُتَّقِينَ لَحُسْنَ مَآبٍ
Hatha thikrun wa-innalilmuttaqeena lahusna maab

Yoruba
 
Èyí ni ìrántí. Àti pé dájúdájú àbọ̀ rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  38:50  الأية
جَنَّاتِ عَدْنٍ مُّفَتَّحَةً لَّهُمُ الْأَبْوَابُ
Jannati AAadnin mufattahatanlahumu al-abwab

Yoruba
 
Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére (ni). Wọ́n sì máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.

Ayah  38:51  الأية
مُتَّكِئِينَ فِيهَا يَدْعُونَ فِيهَا بِفَاكِهَةٍ كَثِيرَةٍ وَشَرَابٍ
Muttaki-eena feeha yadAAoona feehabifakihatin katheeratin washarab

Yoruba
 
Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú nínú rẹ̀. Wọn yóò máa bèèrè fún àwọn èso púpọ̀ àti ohun mímu nínú rẹ̀.

Ayah  38:52  الأية
وَعِندَهُمْ قَاصِرَاتُ الطَّرْفِ أَتْرَابٌ
WaAAindahum qasiratu attarfiatrab

Yoruba
 
Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, tí ọjọ́ orí wọn kò jura wọn lọ yó sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn.

Ayah  38:53  الأية
هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِيَوْمِ الْحِسَابِ
Hatha ma tooAAadoona liyawmialhisab

Yoruba
 
Èyí ni ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín fún Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.

Ayah  38:54  الأية
إِنَّ هَٰذَا لَرِزْقُنَا مَا لَهُ مِن نَّفَادٍ
Inna hatha larizquna malahu min nafad

Yoruba
 
Dájúdájú èyí ni arísìkí Wa. Kò sì níí tán.

Ayah  38:55  الأية
هَٰذَا ۚ وَإِنَّ لِلطَّاغِينَ لَشَرَّ مَآبٍ
Hatha wa-inna littagheenalasharra maab

Yoruba
 
Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Àti pé dájúdájú àbọ̀ burúkú ni ti àwọn alágbèéré (sí Allāhu).

Ayah  38:56  الأية
جَهَنَّمَ يَصْلَوْنَهَا فَبِئْسَ الْمِهَادُ
Jahannama yaslawnaha fabi/saalmihad

Yoruba
 
Iná Jahanamọ ni wọn yó wọ̀. Ó sì burú ní ibùgbé.

Ayah  38:57  الأية
هَٰذَا فَلْيَذُوقُوهُ حَمِيمٌ وَغَسَّاقٌ
Hatha falyathooqoohu hameemunwaghassaq

Yoruba
 
Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, kí wọ́n tọ́ ọ wò; omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.

Ayah  38:58  الأية
وَآخَرُ مِن شَكْلِهِ أَزْوَاجٌ
Waakharu min shaklihi azwaj

Yoruba
 
Oríṣiríṣi (ìyà) mìíràn bí irú rẹ̀ (tún wà fún wọn).

Ayah  38:59  الأية
هَٰذَا فَوْجٌ مُّقْتَحِمٌ مَّعَكُمْ ۖ لَا مَرْحَبًا بِهِمْ ۚ إِنَّهُمْ صَالُو النَّارِ
Hatha fawjun muqtahimunmaAAakum la marhaban bihim innahum saloo annar

Yoruba
 
Èyí ni ìjọ kan tó máa wọ inú Iná pẹ̀lú yín. (Àwọn aṣíwájú nínú Iná sì máa wí pé:) "Kò sí máawolẹ̀-máarọra fún wọn." Dájúdájú wọn yóò wọ inú Iná ni.

Ayah  38:60  الأية
قَالُوا بَلْ أَنتُمْ لَا مَرْحَبًا بِكُمْ ۖ أَنتُمْ قَدَّمْتُمُوهُ لَنَا ۖ فَبِئْسَ الْقَرَارُ
Qaloo bal antum la marhabanbikum antum qaddamtumoohu lana fabi/sa alqarar

Yoruba
 
(Àwọn ọmọlẹ́yìn nínú Iná) máa wí pé: "Rárá, ẹ̀yin náà kò sí máawolẹ̀-máarọra fún yín. Ẹ̀yin l'ẹ pè wá síbi èyí (tó bí Iná)." Ó sì burú ní ibùgbé.

Ayah  38:61  الأية
قَالُوا رَبَّنَا مَن قَدَّمَ لَنَا هَٰذَا فَزِدْهُ عَذَابًا ضِعْفًا فِي النَّارِ
Qaloo rabbana man qaddama lanahatha fazidhu AAathaban diAAfan fee annar

Yoruba
 
Wọ́n (tún) wí pé: "Olúwa wa, ẹni tí ó pè wá (síbi ìyà) yìí, ṣe àlékún àdìpèlé ìyà fún un nínú Iná."

Ayah  38:62  الأية
وَقَالُوا مَا لَنَا لَا نَرَىٰ رِجَالًا كُنَّا نَعُدُّهُم مِّنَ الْأَشْرَارِ
Waqaloo ma lana lanara rijalan kunna naAAudduhum mina al-ashrar

Yoruba
 
Wọ́n tún wí pé: "Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wa tí a kò rí àwọn ọkùnrin kan, àwọn tí à ń kà mọ́ àwọn ẹni burúkú.

Ayah  38:63  الأية
أَتَّخَذْنَاهُمْ سِخْرِيًّا أَمْ زَاغَتْ عَنْهُمُ الْأَبْصَارُ
Attakhathnahum sikhriyyan am zaghatAAanhumu al-absar

Yoruba
 
Ṣèbí a fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí àwọn ojú ti fò wọ́n ni (l'a ò fi rí wọn nínú Iná)?"

Ayah  38:64  الأية
إِنَّ ذَٰلِكَ لَحَقٌّ تَخَاصُمُ أَهْلِ النَّارِ
Inna thalika lahaqqun takhasumuahli annar

Yoruba
 
Dájúdájú ìyẹn, àríyànjiyàn àwọn èrò inú Iná, òdodo mà ni.

Ayah  38:65  الأية
قُلْ إِنَّمَا أَنَا مُنذِرٌ ۖ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا اللهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ
Qul innama ana munthirunwama min ilahin illa Allahu alwahidualqahhar

Yoruba
 
Sọ pé: "Èmi ni olùkìlọ̀. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

Ayah  38:66  الأية
رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا الْعَزِيزُ الْغَفَّارُ
Rabbu assamawati wal-ardiwama baynahuma alAAazeezu alghaffar

Yoruba
 
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì, Alágbára, Aláforíjìn."

Ayah  38:67  الأية
قُلْ هُوَ نَبَأٌ عَظِيمٌ
Qul huwa nabaon AAatheem

Yoruba
 
Sọ pé: "(al-Ƙur'ān) ni ìró ńlá.

Ayah  38:68  الأية
أَنتُمْ عَنْهُ مُعْرِضُونَ
Antum AAanhu muAAridoon

Yoruba
 
Èmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé.

Ayah  38:69  الأية
مَا كَانَ لِيَ مِنْ عِلْمٍ بِالْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ إِذْ يَخْتَصِمُونَ
Ma kana liya min AAilmin bilmala-ial-aAAla ith yakhtasimoon

Yoruba
 
Èmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé.

Ayah  38:70  الأية
إِن يُوحَىٰ إِلَيَّ إِلَّا أَنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ
In yooha ilayya illa annamaana natheerun mubeen

Yoruba
 
Kí ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi bí kò ṣe pé èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé."

Ayah  38:71  الأية
إِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِّن طِينٍ
Ith qala rabbuka lilmala-ikatiinnee khaliqun basharan min teen

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: "Dájúdájú Èmi yóò dá abara kan láti inú ẹrẹ̀.

Ayah  38:72  الأية
فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ
Fa-itha sawwaytuhu wanafakhtu feehimin roohee faqaAAoo lahu sajideen

Yoruba
 
Nígbà tí Mo bá ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ tán, tí Mo sì fẹ́ nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí Mo dá sínú rẹ̀, nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un, kí ẹ forí kanlẹ̀ kí i."

Ayah  38:73  الأية
فَسَجَدَ الْمَلَائِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ
Fasajada almala-ikatu kulluhumajmaAAoon

Yoruba
 
Gbogbo àwọn mọlāika pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.

Ayah  38:74  الأية
إِلَّا إِبْلِيسَ اسْتَكْبَرَ وَكَانَ مِنَ الْكَافِرِينَ
Illa ibleesa istakbara wakanamina alkafireen

Yoruba
 
Àyàfi 'Iblīs, tí ó ṣègbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.

Ayah  38:75  الأية
قَالَ يَا إِبْلِيسُ مَا مَنَعَكَ أَن تَسْجُدَ لِمَا خَلَقْتُ بِيَدَيَّ ۖ أَسْتَكْبَرْتَ أَمْ كُنتَ مِنَ الْعَالِينَ
Qala ya ibleesu mamanaAAaka an tasjuda lima khalaqtu biyadayya astakbarta amkunta mina alAAaleen

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "'Iblīs, kí l'ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí ohun tí Mo fi ọwọ́ Mi méjèèjì dá? Ṣé o ṣègbéraga ni tàbí o wà nínú àwọn ẹni gíga?"

Ayah  38:76  الأية
قَالَ أَنَا خَيْرٌ مِّنْهُ ۖ خَلَقْتَنِي مِن نَّارٍ وَخَلَقْتَهُ مِن طِينٍ
Qala ana khayrun minhukhalaqtanee min narin wakhalaqtahu min teen

Yoruba
 
Ó wí pé: "Èmi lóore jù ú lọ; O dá èmi láti ara iná. O sì dá òun láti ara ẹrẹ̀."

Ayah  38:77  الأية
قَالَ فَاخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ
Qala fakhruj minhafa-innaka rajeem

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Jáde kúrò nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) nítorí pé, dájúdájú ìwọ ni ẹni ẹ̀kọ̀.

Ayah  38:78  الأية
وَإِنَّ عَلَيْكَ لَعْنَتِي إِلَىٰ يَوْمِ الدِّينِ
Wa-inna AAalayka laAAnatee ila yawmiaddeen

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ègún Mi yóò wà lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san."

Ayah  38:79  الأية
قَالَ رَبِّ فَأَنظِرْنِي إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ
Qala rabbi faanthirneeila yawmi yubAAathoon

Yoruba
 
(Èṣù) wí pé: "Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí Wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde."

Ayah  38:80  الأية
قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ الْمُنظَرِينَ
Qala fa-innaka mina almunthareen

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn tí wọ́n máa lọ́ lára

Ayah  38:81  الأية
إِلَىٰ يَوْمِ الْوَقْتِ الْمَعْلُومِ
Ila yawmi alwaqti almaAAloom

Yoruba
 
Títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ̀."

Ayah  38:82  الأية
قَالَ فَبِعِزَّتِكَ لَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ
Qala fabiAAizzatika laoghwiyannahumajmaAAeen

Yoruba
 
(Èṣù) wí pé: "Mo fi agbára Rẹ búra, dájúdájú èmi yóò kó gbogbo wọn sínú ìṣìnà

Ayah  38:83  الأية
إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ الْمُخْلَصِينَ
Illa AAibadaka minhumualmukhlaseen

Yoruba
 
Àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo) nínú wọn."

Ayah  38:84  الأية
قَالَ فَالْحَقُّ وَالْحَقَّ أَقُولُ
Qala falhaqqu walhaqqaaqool

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Òdodo (ni ìbúra Mi), òdodo sì ni Èmi ń sọ, (pé)

Ayah  38:85  الأية
لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنْهُمْ أَجْمَعِينَ
Laamlaanna jahannama minka wamimmantabiAAaka minhum ajmaAAeen

Yoruba
 
Dájúdájú Mo máa fi ìwọ àti gbogbo àwọn tó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn kún inú iná Jahanamọ."

Ayah  38:86  الأية
قُلْ مَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ وَمَا أَنَا مِنَ الْمُتَكَلِّفِينَ
Qul ma as-alukum AAalayhi min ajrinwama ana mina almutakallifeen

Yoruba
 
Sọ pé: "Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Èmi kò sì sí nínú àwọn onítàn-àròsọ."

Ayah  38:87  الأية
إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَالَمِينَ
In huwa illa thikrun lilAAalameen

Yoruba
 
Kí ni al-Ƙur'ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  38:88  الأية
وَلَتَعْلَمُنَّ نَبَأَهُ بَعْدَ حِينٍ
WalataAAlamunna nabaahu baAAda heen

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ẹ máa mọ ìró rẹ̀ (sí òdodo) láìpẹ́.




© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us