Topic: Simon Atawon Ore Re Fipa Ba Queen Lo Po, Ni Won Badero Ewon
Timeline: 2012-07-04 05:49:40
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo ati Sam Akinrole
Simon Atawon Ore Re Fipa Ba Queen Lo Po, Ni Won Badero Ewon
GBOGBO awon abiyamo ti won wa ni Kootu Majisreeti kan niluu Osogbo laipe yii ni won n see pe fawon odomokunrin marun-un kan ti won fipa ba omo odun merindinlogun lo po ninu saaalanga.
Niluu Gbongan, nipinle Osun la gbo pe Amosan Simon, omo odun mokanlelogun, Dele Oripe, omo ogun odun, Akorede Tunde, omo odun mokandinlogun, Joseph Omolara, omo odun mokandinlogun ati Agboola Wale, omo ogun odun ti fipa ba odomobinrin naa ti won pe oruko re ni Queen lo po.
Gege bi agbejoro fun ileese olopaa, Elisha Olusegun se wi, logunjo, osu karun-un, odun yii lawon omokunrin naa sise ibi owo won ni nnkan bii aago mejo aabo ale.
Se la gbo pe ara Baba Queen ko ya, to si ran omo re pe ko loo ba oun ra oogun toun yoo lo wa, sugbon loju ona lawon odomokunrin maraarun yii ti ragabu Queen, ti won si fi tipatipa wo o lo sinu salanga kan to wa lagbegbe naa.
Nigba ti won mu un de inu salanga naa, won fa awotele re ya, leyin naa lawon maraarun fipa ba a lo po. Gbogbo ariwo ti Queen n pa la gbo pe koseso rere nitori ko si eeyan kankan lagbegbe naa to le gba a sile lowo awon omokunrin naa.
Nigba ti asiri oro naa tu, awon maraarun to sise buruku naa sa kuro ni Gbongan. Leyin ojo kerin tawon olopaa ti n sise takuntakun lati ri wonmu lowo too te won, ti won si gbabe dero ile-ejo.
Olusegun ni iwa tawon omo naa hu lodi sofin, bee losi ni ijiya nla labe ofin iwa odaran ipinle Osun. Nigba ti akowe kootu ka esun maraarun ti won fi kan awon olujejo si won leti, won so pe awon ko jebi awon esun naa.
Agbejoro won, Olayiwola Adeniyi ro ile-ejo lati faaye beeli sile fawon olujejo naa pelu ileri pe won ko ni i sa lo nigbakuugba tile-ejo ba n wa won.
Sugbon agbejoro fun ileese olopaa tako arowa agbejoro awon olujejo, o salaye pe se lawon omo naa maa sa lo ti ile-ejo ba le faaye beeli sile fun won.
Adajo kootu naa, Adewumi Makanjuola pase pe kawon olopaa loo fi awon olujejo naa pamo sogba ewon ilu Ilesa.
Leyin eyi lo sun igbejo siwaju di ojo kefa, osu keje, odun yii.
Olopaa Fipa Bayawo E Lo Po Tan, Lo Ba Tun Gun un Pa: Nitori Eedegbeta Naira, Baba Ramota Foruka Aluwo Lu Iyawo E -- Lati Owo Sam Akinrole
Oru Ojoru, Tosde, ose to koja lohun-un moju Fraide nisele yii sele, lojo naa lokunrin olopa a kan to n sise pelu ileese olopaa ko-gberegbe, iyen Mopol, to wa n Ikeja ti won n pe oruko re ni Sunday Iluegbe gun iyawo re, Caroline, pa mole, leyin to ba a sun tan. Bo si se huwa laabi yii tan lo ti na papa bora, koda titi di bi a ti n ko iroyin yii, ko ti i seni to mo ibi to gba lo.
Awon kan ni eedi lo mu olopaa yii, bee mi-in n so pe asiko esan ise ibi toun atawon olopaa egbe e maa n se fawon araalu lo de. Sugbon awon ti won jo n gbe ninu baraaki olopaa to wa ni Olosan, ni Musin, l Ekoo, atawon molebi re ko ri i bee o, oro naa n dun won gidigidi. Idi ni pe eeyan kan tiwa e dara ni won pe oloogbe naa, won lo jafafa ninu ise aranso, iyen telo to n se, eyi lo si mu ki die ninu awon eeyan naa gba lati ba akoroyin wa soro, bo tile je pe won lora lati se eyi.
Eni odun mejidinlogoji ni won pe eni to payawo e yii, sugbon iyawo e ko ti i ju eni odun mejilelogbon lo. Obinrin naa tete bimo, omo marun-un leso abemi to ni fokunrin ohun< okunrin meta, obinrin meji, akobi e si ti fee pe ogun odun.
Iwe Iroyin Yoruba gbo pe o pe tija ti maa n waye laarin awon toko-tiyawo yii, ti won maa lu ara won bii eni maa ku, gbogbo igba ti won ba si ja bayii lobinrin naa maa binu ko kuro nile. Awon kan tie so pe oloogbe naa ti fee lo tipe, sugbon oko e ko je ko ko awon omo e lo, oun naa ko si fee fi awon omo e sile, eyi lo se je pe ti won ba ja to ba lo o tun maa n waa wo awon omo yii leekookan.
Ija to sele keyin laarin won lo mu ki Caroline binu pada siluu won, osu mesan-an la gbo pe o lo nibe ko too pada wale. Omo ilu Benin, nipinle Edo, lawon mejeeji, ilu Benin yii naa lo lo sugbon oru ojo to pada de s Ekoo sodo oko e yii naa lo pade iku ojiji. Ko ba oko e nile nigba to de, awon omo e nikan lo ba.
Nigba tokunrin yii de lati ibi ise lale ojo naa, o ba iyawo e nile, awon mejeeji si bara won soro gege bi awon omo oloogbe naa se salaye fun alakooso awon obinrin to wa ninu ogba baraaki ohun to ni ka ma daruko oun sinu iwe iroyin.
Yara lawon omo sun si, sugbon palo ni olopaa atiyawo e sun. Ibe lo maa n saaba sun si nitori oru. O maa n gbe ibusun to fi n sun si yara igbalejo-si yii, ibe naa lo si maa sun si. Ori foomu yii lawon mejeeji wa, sugbon ko sedaa Olorun kan to le salaye ohun to sele laarin won laarin oru tisele buruku naa sele, nise ni olopaa yii pa iyawo re leyin to ba a sun karakara tan.
Nigba tawon omo ji laaaro ti won fee loo ki awon obi won ni won ba iya won ninu agbara eje, won ti fi aso di i lenu, Eyi lo mu ki akobi obinrin naa ti won pe oruko e ni Becky figbe ta, sugbon awon eeyan ko tete sunmo won, won ro pe iru ariwo to maa n sele naa lo tun sele, sugbon nigba tariwo omo naa po ju bo se ye lo lobinrin ti i se alakooso awon obinrin olopaa naa to ba akoroyin wa so ro sare lo sibe. Egbe ile won nibe loun n gbe. Obinrin yii so fun wa pe boun se debe, oun ba Carolina ninu agbara eje nihooho, won fi nnkan gun un lorun, ibe leje naa n gba jade, bee ni won tun fi pilo ati aso di i lenu. O lohun to ya oun lenu ni pe a¯to¯ okunrin si wa loju ara e, eyi to tumo si pe won sese bara won sere ife tan ni tabi ko je pe nigba to fipa ba a lo po tan lo gun un pa. Esekese lo loun ti ranse pe oga olopaa tesan Olosan, o ni won ti bere iwadii, bee ni won si ti gbe obinrin ohun lo si mosuari Osibitu Isolo.
Ko seni to mo nnkan pupo nipa obinrin yii atawon molebi e, ohun ti won kan mo ni pe ise telo lo n se, oun lo si maa n ba opo awon obinrin to wa ninu baraaki naa ranso.
Okunrin olopaa tesan Olosan kan to ba akoroyin wa soro so bayii pe, Awon mejeeji ki i gbe papo, won maa n ja lojoojumo ni, ko tile too di pe isele laabi yii sele.
Sugbon Caroline maa n be awon omo re wo loorekoore, nigba mi-in, to ba wa bee yen, o maa sun ni baraaki lodo oko e.
‘’Lojo tisele yen sele gan-an, omo e so fun wa pe mama awon wa bo ti maa n se leekookan. Sugbon lojo Tosde moju Fraide to wa yii, odo dadi awon lo sun ni palo, nibi ti baba awon maa n sun, tawon si maa sun si yara. Aago marunun aabo lo lo maa n ji, nitori aago meje lo maa n lo sibi ise. Omo yii so fun wa pe nigba ti oun de yara igbalejo, oun ri mama oun ninu eje, won fi sikaafu di i lenu, won so pilo le e lori, won si ti gun un lorun.”
Okunrin naa tun so fun wa pe nigba tawon olopaa maa debe, o si n mi, n lawon ba sare gbe e lo si Osibitu LUTH, sugbon ni nnkan bii aago meji osan ojo Fraide lo gbemii min. Latigba naa loko ti sa lo, ko tile yoju sibi ise e to wa n’Ikeja rara. O lokunrin naa n pe awon omo e lori foonu lati beere boya ara mama won ti ya, sugbon ko so ibi to wa.
Nigba keji ti akoroyin wa de ile oloogbe, a pade okunrin oga olopaa kan, oun naa sapejuwe oloogbe naa gege bii eeyan daadaa, o ni loooto Hausa loun, Benin lawon, sibe iyawo oun maa n se pelu e. O lohun tawon maa n kiyesi ni pe ojoojumo nija maa n waye laarin oun atoko e. O te siwaju pe tawon ba fee ran awon omo won lowo, nise ni won maa n so pe baba awon ti ni kawon ma gba nnkan kan lowo enikeni, o ni baba won ki i je kawon omo naa se pelu eni kankan ninu ogba.
Nibi toro naa ka enikan to tun ba wa soro lara de, obinrin ohun so pelu omije loju pe ka loun mo pe ibi toro naa yoo ja si niyen, oun i ba ti tu asiri okunrin olopaa yii tipe, nitori gbogbo eeyan lo mo pe bo ti n se siyawo e niyen. Obinrin to ni ka foruko bo oun lasiiri yii so pe lojo kan niyawo Baale Olosan bimo, ti gbogbo awon iyawo olopaa si lo sibe, se ni Sunday yii waa bayawo e nibe, to si bere si i fi beliiti awon Mopol onirin lu u. O ni boya ka lawon ti pariwo e sita tipe ni, Caro i ba ma ku. O waa ro ileese olopaa lati dide soro awon osise won nitori ohun ti opo won n foju awon iyawo won ri ko daa rara.
Agbenuso ileese olopaa nipinle Eko, Ogbeni Joseph Jaiyeoba, ti fidi isele naa mule, o ni loooto ni, sugbon iwadii si n te siwaju. Jayeoba ni ileese olopaa gba pe okunrin naa si wa lenu ise, bo tile je pe ko yoju latigba tisele naa ti sele.
**{Legacy activities, comments etc counter: 844; topic series: 8; forum: MediaYoruba; associated: 8- /*}