Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 117 from MediaYoruba
Topic: Odun Kan Ijoba Jonathan, Afi Ki Nnkan Yipada O: Nijo Wo Le Fee Se Ona Marose Ibadan Yii, Abi O Digba Ti E Ba Pa Wa Tan Ni
Timeline: 2012-07-04 05:52:15


Lati Owo Ademola Adejare

Odun Kan Ijoba Jonathan, Afi Ki Nnkan Yipada O: Nijo Wo Le Fee Se Ona Marose Ibadan Yii, Abi O Digba Ti E Ba Pa Wa Tan Ni

Agba ki iwa loja kori omo tuntun wo lawon Yoruba nwi o, sugbon opo awon agbalagba ti a ni nile yii, loju won bayii ni gbogbo nnkan se n wo, awon gan-an ni won si wa nidii bo ba le baje ko baje to n sele kaakiri.

O ya mi lenu nigba ti mo ri awon agbalagba kan ti won kora won jo, ti won si n so pe boya awon kan fe boya won ko, Jonathan gbodo pada waa sejoba Naijiria lodun 2015 ni.

Awon agbalagba wonyi ko ralaye kan se, bee ni won ko le so idi ti won fi fe ki Jonathan maa sejoba lo ju pe eemeji ni won dibo yan Alaaji Shehu Shagari lodun 1979 ati 1983, eemeji ni won si dibo yan Olusegun Obasanjo naa lodun 1999 ati 2003. Nitori pe awon wonyi ti sejoba leemeji meji yii, Jonathan naa gbodo se tire dandan ni. Lara ohun to n ba Naijiriaje niyi, lara ohun ti ko je ki ilosiwaju kankan ba wa niyen.

A ki i gbeeyan sipo lorileede yii, nitori pe iru eni bee mose ti a fe ko se, tabi nitori teni naa kun oju osunwon, to si pegede, to fi gbooro jeka nidii ise ti a fee fun un se. Ohun meji ni a maa n wo ki a too feeyan sise, tabi ki won too dibofenikan nile yii, iyen naa ni pe omo eni ti tohun n se, boya omo Oba ni, tabi omo ijoye, tabi omo oloselu to lagbara; baba re saa gbodo je enikan to lagbara laarin ilu, bi bee ko, ko senikan ti yoo fun un nise se.

Ohun keji tawon eeyan tun nwo ni ibi teni naa ti wa, boya Hausa ni, tabi Ibo, tabi Yoruba.

Iru awon iwa bayii lo ba awon ileese ijoba bii NITEL, NEPA, Nigerian Airways atawon ileese mi-in to ti denu-kole nile yii je. Sebi ohun ti won n se nigba naa ni pe bi Hausa kan ba ti le je oga nileese ijoba, won yoo maa fiwe ranse si i lasan lati gba opolopo awon eya re sise ni, nigba tawon eeyan yoo ba si fi mo ohun to n sele, ileese naa yoo ti kun fun kidaa awon omo Hausa. Ko ba ti sohun to buru ninu eleyii bo base pe awon eeyan ti won n ko wa wonyi mose ti won waa se.

Sugbon won ko mose, bee ni won ko ni iriri, won yoo kan ko won wa nitori pe won je Hausa nikan ni. Bi won ba ti gba ise naa tan, nitori pe won ko mo ohun ti won yoo se nibe, kia nileese naa yoo daru, kia nileese naa yoo baje,nigbeyin, ibe ko ni i wulo fenikan mo.

Iyen lawon eeyan se n gbogun ti awon Hausa wonyi nigba naa, ti won n so pe ki won yee fi tipatipa sejoba, ki won yee fi tipatipa fi ara won si awon ileese to ba ti je tijoba, ki won si yee lo awon eya to ku gege bii omoose tabi eru won. Ohun tawon eeyan yii maa n se da bii igba teeyan ba mu omoose mekaniiki wa lati ibi kan, to si waa fi solori soobu tawon oga mekaniiki wa, o daju pe iru soobu naa ko ni i toro,ibe yoo baje gbeyin ni. Ohun to sele si Naijiria gan-an ree, oun naa lo si ba wa debi ti a de yii, tohun gbogbo fi ri rudurudu.

Bi gbogbo wa ba wa n panupo ti a n bu awon olori Hausa wonyi, ti ki i se pe nitori pe a koriira won to je nitori pe won ba Naijiria je ni, ko ye ki awon agbalagba mi-in tun waa kora won jo ki won maa se ohun ti a n so pe awon kan se ti ko dara.

Ko senikan ti yoo ta ko Jonathan bo ba fee sejoba leekeji, niwon igba to ba se pe eyi to n se lowo, o se e daadaa. Sugbon ki wahala po to bayii niluu, ka ma mobi ti a n lo, ki iwaju maa see lo, keyin ma see pada si, ogun bombu loni-in, ogun bombu lola, awon ti won n ji owo ko ko dinku, ojoojumo lawon adigunjale n po si i, odunkan ijoba Jonathan ko lori, ko nidii. Ki waa lenikan yoo jokoo sibi kan ti yoo so pe dandan ni ki Jonathan sejoba ni 2015 si. Haa, seyin eeyan yii ko si fe k Olounmuyin ’ bayii!

Nijo wo le fee se ona marose Ibadan yii, abi o digba ti e ba pa wa tan ni

Awon ti won n pariwo pe Jonathan ni yoo se Aare wa lodun 2015, ko le pe ko le jinna ti awon araalu yoo fi maa le won nibikibi ti won ba tin so iru oro were bee jade lenu. O daju pe nigba ti yoo ba fi di odun to n bo, awon alainise, ole ati arijenimadaru ti won ba n daruko Jonathan atodun 2015, won yoo maa gba won nikumo leyin orun ni.

Oponu ni opolopo awon eeyan, won maa n lero pe ariwo lasan ni yoo gbe enikan de ori aleefa, tabi ojoro ti won maa n se lojo idibo. Bi omo Naijiria ba fee fe Jonathan lodun 2015, ohun to ba gbe se lasiko yii ni yoo je ki awon eeyan fokan tan an, ki won si fa a kale pe ko maa sejoba re lo. Okan ninu ohun to si yara ba oruko okunrin naa je julo ni ona marose Ibadan si Eko ti won ko ti won ko tun se.

Bi Jonathan ba se ona yii, ibi tokiki oun paapaa yoo kan de, ko ni i le fenu ara re so, bee lawon eeyan yoo si maa so fun un pe bi ko tie dibo,o ti wole. Sugbon oju ona to n paayan lojoojumo yii, to si han gbangba pe yato si ekun wuruwuru ti ko jinna soju Aare wa, ki i se pe o fi taratara feran omo Naijiria tabi ko kuku je pe ko mo ohun to fee se, ojoojumo loruko re n baje si i, bo si dibo paapaa, boya ni yoo wole.

Ona yii lawon moto n rin julo ni gbogbo ile adulawo, ko tun si titi ti moto n gba bee yen mo l’Afrika. Bo ba waa ri bee, bi titi naa ba dara, sebiojoojumo lawon eeayn yoo maa gbabe, ti won yoo si maa kan saara sijoba to ba se e. Sugbon ka fi odun meeedogun pile were bii tawon ogbeni wa yii, o waa di ojo wo ki were naa too ja wo oja. Lodoodun ni won n pariwo pe ise wa lowo awon kan, awon ti won gbase ko si yee ko irinse etan jo soju ona naa lodoodun, won yoo si tun ko won kuro bo ba ya, bo ba se pe nibi tijoba gidi wa ni, ise naa yoo ti bo lowo awon alapaarutu ti won ko nikan i se. E maa tan Jonathan je ke e maa gbowo e, o dojo idibo ki gbogbo yin too foju ri i.


**{Legacy activities, comments etc counter: 529; topic series: 7; forum: MediaYoruba; associated: 7- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Odun Kan Ijoba Jonathan, Afi Ki Nnkan Yipada O: Nijo Wo Le Fee Se Ona Marose Ibadan Yii, Abi O Digba Ti E Ba Pa Wa Tan N



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn