Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 121 from MediaYoruba
Topic: Ise Esu Gidi Ree o, Musa Ati Ore E N Ja Lo Ba Fowo Ti I, Ori Waya Ina Ni Omokunrin Naa Bale Si: N’Ibadan, Damilola Lu Ore Omo E Pa
Timeline: 2012-07-04 05:58:16


Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan ati Olawale Ajao, Ibadan

Ise Esu Gidi Ree o, Musa Ati Ore E N Ja Lo Ba Fowo Ti I, Ori Waya Ina Ni Omokunrin Naa Bale Si: N’Ibadan, Damilola Lu Ore Omo E Pa

Bo ba se pe enikan so fun Musa Abdullahi pe oro gbolohun aso kekere to waye laarin oun ati Wasiu yoo ja si iku fun ore e yii ni, gbogbo iya yoowu ti iyen ba fi je e ni iba farada, tabi ko tile sa lo fun un, ko yago fun esu patapata.

Bo tile je pe Wasiu ni won lo koko fun un nikuuku, Musa ko na suuru si oro naa to, titaari to si taari Wasiu lo sokunfa iku e, n ni won ba loun lo pa ore e. S·e ona esu ti yoo ba seeyan ki i jin, gongori ookan aya eni ni i duro le.

Oro ti ko to nnkan lo si daja sile o. Tori e ni Wasiu se fun Musa ni ifoti, niyen naa ba fibinu taari e subu. S·ugbon ibinu ko mo pe olowo oun ko lese nile. E·yin ti Wasiu yoo mu lo sile bayii, waya ina lo subu le, lo ba gan pa.

Bee ore ni won, inu yara kan naa ni won si jo n sun. Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba, omo bibi abule kan ti won n pe ni Yakira, ni Ilesa Ibariba, nipinle Kwara ni Musa. Wasiu je omo ilu S·aki, nipinle O·yo. S·ugbon ise aje lo gbe awon mejeeji de Ibadan, inu yara kan naa ni won jo n gbe laduugbo Sango, niluu naa gege bii aburo ati egbon ati gege bii ore.

Bo tile je pe Wasiu ju Musa lo daadaa, nitori omo ogbon odun loun, Musa ko si ju omo ogun odun pere lo, sibe bii ore ni won jo maa n se,paapaa nigba to se pe ibi kan naa ni won ti jo n sise. O·ko ikeru nla to je ti ileese aladaani kan to wa ninu ogba ile igbafe ijoba, iyen Trans Amusement Park, ni Sango, n Ibadan ni ’ won n tele loo ko eru, ati lati ja eru.

Bi won se jo n sise ti won si jo n gbe ree ki iku too pin won niya lojo Aiku, Sande, ojo ketadinlogun, osu kefa, odun yii. O·na kekere bayiini iku si ba wole, isele ohun ya Musa lenu, o se awon to soju won paapaa ni kayeefi.

Gege b Iwe Iroyin Yorubase gbo, oko ileese ti won n ba sise lo baje lojo naa ti Musa si ri i pe ko koja nnkan ti oun le se. Ibi to ti n ye ogangan ibi ti oko naa ti baje wo lo ran Wasiu pe ko mu skurudirefa kan wa foun ninu apoti ti won n ko awon irin-ise ti won fin n tun oko se si ti okunrin eni ogbon odun naa si mu un fun un. S·ugbon o jo pe kinni ohun ko sise daadaa, ni Musa ba tun ni ko mu omin-in wa. Igba yii ni Wasiu gbina je, ti oro si dija laarin won.

Inu bi okunrin eni ogbon odun naa pe eni ti ko to egbe abile keta oun n ran oun nise, o si n da oun laamu. N lo ba n bu Musa, nigba ti iyen naa fun un lesi ni inu bi i, o fo o leti, Musa si taari Wasiu subu.

Waya ina kan ja lati ori igi kan ti won fi gbe e ro, ori paanu ile naa lo ja le ti gbogbo egbe kan ile ohun si ti gba ina sara; paanu ohun paapaa ti wa sile, sugbon awon to n ja niwaju ile yii ko mo nnkan kan, awon onile paapaa ko si mo. Niwaju ile yii kan naa ni gota ti won la si egbe titi gba koja. Inu gota yii ni Wasiu fee subu si nigba ti Musa ti i, n lo ba dura ki oun ma subu sinu erofo.

S·ugbon fifo to fo gota ohun bayii, eyin lo mu lo sile, ara ogiri ile to ti gbana sara lo subu le.

Wasiu ke irora Yeee! Ijamba se ole, onile taji. Igbe yii lawon araadugbo gbo ti won fi sare debe, won ba a nibi to ti n po eje lenu goorogo. S·ugbon ko seni to le sunmo on. Ta lo fee ku? Tabi iku to toju elewure pa aladiye tun ye ko pa elewure bi? O se die ti won ti n ronu bi won se le doola emi omo bibi ilu S·aki naa ki ero gidi too so si won lokan. Won fi igi gbigbe taari e lule, won si sare gbe e lo sileewosan fun itoju. S·ugbon pabo ni gbogbo aajo won ja si nitori awon dokita fidi e mule pe omokunrin ti lo.

O tile ti gbemi-in mi ki won to gbe e debe. Agbo pe lati igba ti Wasiu ti gan mona ni eru ti n ba Musa paapaa.

Won ni bo se n kawo leri lo n sunkun, to n kigbe pe oun ko ba a ja o, nise loun kan rota taari e lasan o.

S·ugbon lojo naa ni won folopaa mu un. Ago olopaa San go lo si gba de Iyaganku, nibi tawon olofin-toto olopaa ti n fi ibeere po o nifun lati ri fin-in idi koko lori iku to pa Wasiu lasiko ti won jo n ja.

O·ro Musa ko yi pada, nnkan to n tenumo naa ni pe owo oun ko ni iku Wasiu ti wa nitori oun ko ba a ja bo tile je pe okunrin naa gba oun leti. Gege bo se so, Lojo yen, moto wa lo baje. Mo waa ri i pe nnkan ti mo le se naa ni. Mo ni ko ba mi mu skurudirefa wa ki n gbiyanju e wo na. S·ugbon enu skurudirefa yen ti te, mo waa ni ko ba mi mu omi-in, n lo ba ni, Ori e yi, ta lo o maa ran nise.

Moni sebi oko taa ti jo n je naa ni mo fee fi se. Bo se bere si i bu mi niyen. Nigba ti oro kobakungbe yii po lemi naa fun un lesi. Bo se da igbaju bo mi niyen. N ni mo ba taari e danu pe ko fi mi sile. Ibi to ti n ja raburabu pe ki oun ma subu sinu gota lo ti lo subu lu ina Inu ile kan naa la jo n gbe. Awon obi e si mo mi daadaa. Mi o mo pe waya ina wa nibe ni. Mi o ba a ja gan-an, mo kan taari e pe ko fi mi sile lasan nigba to fun mi ni ifoti ni.

Nigba to n fidi isele yii mule, agbenuso ileese olopaa ipinle O·yo, DSP O·labisi Clet Ilobanafor so pe awon olopaa SCID n Iyaganku n se iwadii lori e lowo. O ni leyin iwadii ohun ni won yoo gbe Musa lo si kootu lati jejo esun ipaniyan.

N’Ibadan, Damilola Lu Ore Omo E Pa, O Lo Ji Redio Oun Bee Won Lomo Naa Ko Mo Nnkan Kan Nipa E -- Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Baba olowo kan, Ogbeni Damilola ti di eni atimole awon olopaa ti won n se ofintoto isele isekupani n Iyaganku, n Ibadan, lori iku oro to pa omodekunrin eni odun meeedogun kan to n je Korede Raji.

Ke e si maa wo o, okunrin to n ta moto niwaju ileewe awon to n sewadii ijinle nipa ohun ogbin l Apata, n Ibadan, yii ni olufisun o, oun lo loo fejo Korede sun gege bii afurasi, o lokunrin naa gbe ero redio amohunbu-gbamu ti won n pe ni Home Theatre omo oun to n je Michael lo. Damilola to loo fejo eni to ro pe o ja oun lole sun ni ago olopaa lo waa pada deni ti won n mu ti mole nitori omokunrin afurasi ohun.

Ni Fraide, ojo kerin, osu yii, loro ohun bere, lasiko ti Damilola si n gbe laduugbo Adifase, lagbegbe Apata, n Ibadan, o ko oke aimoye awon odo leyin lati loo lu Korede mo ile e. Igo, irin atawon ohun ija oloro mi-in ni won ko lowo lo.

Olorun lo moru ile to mo okunrin naa lojo yii paapaa, nitori lataaro kutu ni nnkan ko ti wu u se ju pe ko wo fidio lo. Agbo pe ko ju nnkan bii aago mesan-an aaro lo tomokunrin naa ti loo ba okan ninu awon obinrin ti won jo n gbe ninu ile pe ki won fi fiimu agbelewo kan sinu fidio won kawon wo o, sugbon tiyen le e danu, o ni ko le wo nnkan kan lodo oun, nitori oko oun, aafaa ko gbodo de ba oun pelu e ninu ile.

Leyin naa lo loo ba obinrin mi-in ti won tun jo n gbe, niyen naa ba so fun un pe oun ko ni fiimu kankan tawon le jo wo, lo ba tun ni ko je koun wa a lo. Korede gba ile ore e kan to n je Michael lo lati loo ya fiimu agbelewo. Ile to la ile Korede ati ti Michael yii laarin ko ju marun-un lo, adugbo kan naa ni won jo n gbe. Nigba to de odo ore re yii, ko ba a nile, ko si ri elomi-in nile ju iya arugbo eni odun mokanlelaaadorun-un kan ti ko riran mo lo. N lo ba sinmi lori oro fiimu wiwo o jare.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe wakati bii meji leyin ti Korede ti kuro nile awon ore e l Ogbeni Damilola ti i se Baba Michael de, to si sakiyesi pe ko si ero Home Theatre re nibi to maa n gbe si i. Niwon igba ti ko ba elomi-in ninu ile ohun ju iya agba nikan lo, o beere lowo e pe alejo wo lo mo to wole lasiko toun ko si nile, iya arugbo naa ni ko salejo to wole ju Korede to beere Michael ore e lo. Loju ese ni baba onimoto naa ti ran ni loo pe ore e wa.

Oju oorun ni won ni onise baba olowo naa ba omokunrin ohun ti won fi ji i, to si tele won loo ba baba ore e ti won lo n pe e. Ibeere ti baba naa gbe ko o loju ni pe se oun lo ji oun leru ko lo nitori won ti so foun pe oun nikan lalejo to wole lasiko tile da. Korede dahun pe loooto loun wole sugbon oun ko mu nnkan kan jade nitori kaseeti ere agbelewo lasan loun waa ya.

A gbo pe loooto ni mo wole ti Korede so nikan ni Damilola ri di mu ninu gbogbo alaye to se fun un. Ko wule duro gbo awijare kankan mo to fi ko osuka igbaju ru omo ore e yii, to tun deru iyale e lori.

Leyin naa lo pinnu lati mu omodekunrin naa lo si ago olopaa to wa l’Apata, n’Ibadan, ko si sinmi igbaju ati igbarun to n ko bo o bo se n mu un lo.
Ohun to tubo mu kiya ti won fi je omo naa lojo yii po ni pe Damilola je eni to yawo nipa a n gbaayan leti, bee si ree, bi awon omo toogi adugbo ti baba olowo naa maa n ra oti fun ti ri i nigba to n mu Korede lo ni won ti gba a lowo e, tawon naa si bere si i koya fun un, ti won si n kigbe ole le e lori.

Okan ninu awon araadugbo ohun toro naa soju e lo salaye f’akoroyin wa pe nibi ti won ti n lu omodekunrin naa ni Michael ti de ba won, toun naa si la irin to mu bo lati ibi ise mo ore e lori (irin ti won fi n kole ni won n ta nibi ise awon Micheal). Leyin naa lo tun pa igo mole, to si bere si i gun ore e yii kaakiri.
Iwadii Akoroyin wa fi han pe i¯ya¯ ti won fi je okunrin omoodun meeedogun naa ko mo niwon. O jo pe gbogbo eegun owo e mejeeji ni won ti firin ati apola igi run, nitori nise lawon apa ohun n mi jolojolo, bee lo tun wu gelete, ko too di pe won gbe e de ago olopaa.

Gege b’Iwe Iroyin Yoruba se gbo, DPO tesan Apata, n’Ibadan, ti won mu Korede lo, Ogbeni Ganiyu Alli, lo pa awon omo e lase pe ki won koko loo toju e.Ileewosan aladaani kan to wa l’Ago Tailor, laduugbo Apata nibe naa ni won lawon olopaa koko gbe Korede lo, sugbon leyin ti won fa omi si i lara, ti won tun fun un nitoju lorisiirisii ti ko si ayipada lo mu ki dokita ibe gba won nimoran pe ki won gbe e lo UCH.
O seni laaanu pe lojo keji, iyen ojo Abameta, Satide, ojo karun-un, osu karun-un yii ni Korede dake nibi ti won ti n toju e lowo. Egberun lona aadojo naira (N150,000) ni Damilola na lati fi ra emi Korede pada leyin to kabaamo lori iwa arufin to ti hu saaju.

Nigba to n ba akoroyin wa soro lori isele naa, Baba Korede, Ogbeni Bolaji Raji ni nitori pe omo oun n gbe adugbo naa lai si oun atiya e nibe ni won se ro pe omo orukan ni, ti won fi fowo ola gba a loju.

Gege bo se so, ‘Irin ati igo ni mo gbo pe won fi lu omo mi lori oro ti ko mowo, ti ko mese.
Ilu Akure ni mo wa ti won fi ranse pe mi pe won fesun ole kan omo mi, pe o wa lagoo olopaa l’Apata, n’Ibadan.

‘Nigba ti mo debe ni mo gbo pe nise l’Ogbeni Damilola atawon omo e ja omo mi sihooho omoluabi, ti won si ti i mole. Igo atirin ni won fi lu u ni gbogbo orikerike ara, tomo mi ko si le dide nile mo.

‘Won ja a sihooho, ihooho naa ni won gbe e lo si ago olopaa. Ohun to dun mi ju ni pe nigba ti won debe, togaa olopaa ni ki won gbe e lo si ileewosan kawon too le gba oro sile lenu Damilola, awon eeyan, awon alaisan ti mo ba nileewosan aladaani ti won gbe e lo ni won so fun mi pe se lawon olopaa fi sekeseke de e mo ori beedi lai se odaran.’

Okunrin naa fi kun un pe omo oun ki i somo orukan gege bi won se n so kiri. O lomo osu meta ni Korede wa tiyaa e ti gbe e sile, to loo fe oko mi-in. Won ro pe omo orukan ti ko lebi ti ko lara lomo naa ni won se fiya je e. Mo ro awon to wa nipo ase pe ki won gba mi, ki won ma je kiya yii je mi gbe o.’ Egbe ajafetoo kan ti won pe oruko won ni Peace Movement of Nigeria ti ke si ile igbimo asofin ipinle Oyo lati tanna iwadii soro naa, ki won si fiya to to je awon to pa omolomo laise.
Nigba to n ba awon oniroyin soro ni tesan olopaa to wa l’Apata, n’Ibadan, ati nileewosan UCH, n’Ibadan, nibi tomo naa ku si, oludari egbe ohun, Ogbeni Ayoola Olawale Joseph bu enu ate lu iwa tawon to lu Korede pa hu, pelu bi won se mu ofin lowo ara won. Bakan naa lo ro ileese olopaa ati ileese eto-idajo nipinle Oyo lati ri i daju pe won fofin gbe Damilola atawon omo e ti won jo huwa ibi yii.
Omokunrin toun pelu Korede jo n gbe inu ile kan naa to pera e ni Joshua so pe okunrin ti won fesun kan ohun atiyawo e ko huwa gege bii abiyamo gidi rara, nipa bi won ko se ro o pe ore omo won ni oloogbe naa je.

‘Won ti i mole lori esun ti ko mowo, won si lu u pa. Nigba ti a lo sagoo olopaa lati loo be Baba naa pe ko tu Korede sile, ko so fun wa pe won ti gbe e lo sileewosan, nise lo n leri pe oun yoo ri i pe oun sin in dewon. Sugbon iyalenu nla lo je fun wa pe lojo Monde to koja ta a fee loo gba beeli e ni won bere si i parowa fun wa pe ohun to sele ti sele o, Korede ti ku o.
Igbiyanju akoroyin wa lati fidii isele yii mule lati enu DSP, Olabisi Okuwobi, ti i se alukoro ileese olopaa nipinle Oyo lo ja si pabo, pelu bawon ipe ori ero ibanisoro ta a pe e ko se wole.

Iwadii Iwe Iroyin Yoruba ti fidi e mule pe iku Korede mu ayipada ba isele naa lodo awon olopaa, nitori bi omo naa se dagbere faye ni won ti loo mu Damilola.

Inu ahamo lo si wa titi ti a fi pari akojopo iroyin yii.


**{Legacy activities, comments etc counter: 743; topic series: 4; forum: MediaYoruba; associated: 4- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Ise Esu Gidi Ree o, Musa Ati Ore E N Ja Lo Ba Fowo Ti I, Ori Waya Ina Ni Omokunrin Naa Bale Si: N’Ibadan, Damilola Lu Or



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn