Awọn Iroyin ati Ero
Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ
MediaYoruba
Site Admin
Awọn ifiweranṣẹ: 133
Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am
Olubasọrọ:

     MediaYoruba Site Admin    Awọn ifiweranṣẹ: 133    Ẹ darapọ̀: Isegun Oṣu Kẹwa 21, 2025 9:44 am    Olubasọrọ:   


Firanṣẹ nipasẹ MediaYoruba »

Esin127 *Legacy Post Number 122 from MediaYoruba
Topic: Awon Araadugbo To Fiya Je Osise PHCN To Ja Ina Won, Ti Won Tun Pe E Lole: Nitori Ina Manna-manna, Awon Araalu Ba Tesan Olopaa Je
Timeline: 2012-07-04 06:00:15


Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Awon Araadugbo To Fiya Je Osise PHCN To Ja Ina Won, Ti Won Tun Pe E Lole: Nitori Ina Manna-manna, Awon Araalu Ba Tesan Olopaa Je

E›RIN arintakiti lawon eeyan ti won wa nile-ejo Majisireeti kan niluu Osogbo n rin laipe yii lakooko ti agbejoro ileese olopaa safihan awon eeyan meji kan ti won fesun kan pe won sina iya fun osise ajo Power Holding Company of Nigeria (PHCN) kan, Oyeyemi Musbau.

Yato si pe awon olujejo naa, Adegoke Olasupo, eni ogoji odun ati Ahmed Ibrahim to je omo ogbon odun na osise ajo PHCN yii, won tun loo so fawon olopaa pe awon ti mu enikan to waa jale ninu ile awon.

Se la gbo pe awon olopaa mura bii eni to fee lo koju awon adigunjale ni tooto, ti won si fi pampe oba gbe osise PHCN naa, Oyeyemi Musbau.

Oju otooto lawon ti won wa ni kootu lojo naa fi wooro ohun, bawon kan se so pe o ti le mo awon PHCN ju pelu owo goboi ti won maa n mu kaakiri nipari osu laise pe ina maa n wa deede, lawon kan tun n so pe labe bo-ti-wu-ko-ri, ko ye kawon olujejo fiya je osise naa nitori pe awon oga re ni won ran an nise.

Leyin iwadii lawon olopaa ri i pe se ni Musbau n sise re lojo naa, iyen lojo kerindinlogbon, osu kerin, odun yii, ni nnkan bii aago mewaa owuro, nigba to si fee ja ina ile awon olujejo naa nitori pe won ko sanwo to ye ki won san fun ajo PHCN lawon olujejo dawojo lu u.

Leyin ti won na an daadaa tan ni won tun lo si aago olopaa to wa nitosi ibe pe awon ti mu ole. Gege bi agbejoro fun ileese olopaa, I n s pe k i t o F a g b o y i n b o Abiodun se wi, se lawon olujejo dagi bo Musbau lakooko to n se ojuse re gege bii osise ajo PHCN. Won tun fesun kan awon olujejo pe lakooko ti won n na Musbau, won tun ba ilekun enikan ti won pe ni Pasito Amos Oluwaniran je, eleyii ti owo re to egberun lona ogun naira.

Awon esun ti won fi kan won yii ni Fagboyinbo ni o lodi sofin, o si ni ijiya nla labe ofin iwa odaran tipinle O·sun.

Agbejoro fawon olujejo, Arabinrin B.O. Akande ro ileejo lati gba beeli awon onibaara oun ati pe o see se ki won yanju oro naa nitubi-inubi. Adajo Olusola Aluko gba beeli enikookan awon olujejo pelu egberun lona aadota naira ati elerii meji-meji ni iye kan naa.

Olusola waa sun igbejo naa siwaju di ojo ketadinlogbon, osu kefa, odun yii.

Nitori ina manna-manna, awon araalu ba tesan olopaaje -- Idris Alooma, Ilorin

WAHALA nla ti be sile bayii lagbegbeElekoyangan ati Apata Yakuba, n’Ilorin, nitori bi won see n ja lori aifun won nina ati omi, eyi to mu ki won ba tesan olopaa ati ofiisi awon eso VIO je.

Gege bi iwadii oniroyin wa, a gbo pe lati bii osu mefa lawon eeyan agbegbe naa ti n gbe ninu okunkun ti won ko si rina lo. Bakan naa ni wontun n binu pe awon ko romi lo pelu. Nitori eyi la gbo pe awon eeyan ohun se loo ba awonti oro ina ati omi kan lati ba won wa nnkan se si i.

Sugbon dipo ki won ri ayipada, nnkan ko ri bi won se fe. Eyi lo mu ki won jade sita laaaro ojo Jimo to koja yii lati fehonu han si ajo ina mannamanna ati olomi ero ni Kwara. Sugbon dipo bi awon eeyan ohun se lero ati sewode woorowo, nise la gbo pe awon olopaa n yinbon tajutaju ta a mo si tia gaasi si won, eyi lo mu kinu bi won, ti won si loo ba tesan olopaa to wa lagbegbe naa ati ofiisi awon VIO je, nise ni agbegbe naa gbona girigiri bii aaro oniburedi.

Ninu oro Ogbeni Tunde to ba wa soro, o so pe aika nnkan si ajo to n pese ina ijoba, PHCN, ti won ko fun won ni ero amunawa, tiransifoma, tawon eeyan naa beere fun lo mu ki iwode naa waye. O tun so pe bawon olopaa se mu oro naa lo fa a tawon eeyan agbegbe naa se ba awon nnkan je, paapaa ofiisi awon olopaa to wa lagbegbe naa.

Ninu oro alukoro ileewe Poli Kwara, Ogbeni Yunus Abdulquadri, o so pe ki i sawon omoleewe awon lo n sewode, o ni awon eeyan agbegbe Yakuba ati Elekoyangan ni. O ni awon olopaa ti kapa wahala naa.

Gbogbo akitiyan wa lati ba alukoro awon olopaa Kwara, Ogbeni Dabo Ezekiel, soro lori isele naa lo ja si pabo nitori nise ni foonu e ko lo rara.


**{Legacy activities, comments etc counter: 464; topic series: 9; forum: MediaYoruba; associated: 9- /*}

Fi èsì kan ranṣẹ

Awon Araadugbo To Fiya Je Osise PHCN To Ja Ina Won, Ti Won Tun Pe E Lole: Nitori Ina Manna-manna, Awon Araalu Ba Tesan O



Fún Ìdáhùn

Pada si "Àwọn Àpilẹ̀kọ, Àwọn Àròkọ àti Àwọn Èrò Àkosílẹ"

Fún Ìdáhùn