Topic: Kayeefi Nla Kan Ma Leleyii n’Ile-Ife: Ruth Bimo Meta, Lo Ba Ni Eyo Kan Soso Ni Toko Oun Ninu Won
Timeline: 2012-07-04 06:01:44
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo
Kayeefi Nla Kan Ma Leleyii n’Ile-Ife: Ruth Bimo Meta, Lo Ba Ni Eyo Kan Soso Ni Toko Oun Ninu Won
BII fiimu loro naa jo loju Ogbeni Depo Aderekun, nigba tiyawo to fe nisuu-loka so fun un pe akobi awon nikan lo je tie ninu gbogbo omo meta toun bi fun un.
Ohun to je koro naa ya okunrin yii lenu julo ni pe beeyan ba bu omi siyawo re, Rutu Aderekun lenu, ibe naa lo maa ba a, oko ko si fura pe o le hu iru iwa bee.
Awon molebi okunrin yii so fun Iwe Iroyin Yoruba pe lodun meeedogun seyin ni Depo Aderekun to je omo Ile Olodo, ni Ilare, Ile-Ife fe Rutu tounje omo ile Akeran, lagbegbe Enuwa, n’Ife kan naa.
Leyin igbeyawo, Rutu to je telo yii finu soyun, o si bi omokunrin lanti lanti kan to ti to omo odun metala bayii fun Depo. Leyin odun die, Rutu tun bi omokunrin kan toun ti n lo bii omo odun mejo bayii, leyin naa lo si tun bi omobinrin kan to ti le lomo odun meji bayii. Depo to ti le die lomo ogoji odun bayii n gbe igbe aye alaafia pelu iyawo re, koda gbogbo eeyan lo da won mo ninu ijo kan ti won n lo lagbegbe Oke-Atan ti won jo n gbe niluu naa nitori pe eeyan takuntakun ni Rutu ninu soosi won.
Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, Ogbeni Depo to n sise agbe,to si tun n wa oko-ero lo sirin ajo kan lose to koja lohun-un, nigba to di ojo Eti, Fraide, ojo kerindinlogbon, osu karun-un, odun yii, Rutu mura, o lo sodo egbon oko re kan toruko re n je Dupe Oladosu, o si salaye fun un pe oun loro kan lati ba a so.
Nigba ti won jokoo, Rutu salaye fun Arabinrin Dupe pe asiri kan wa toko oun ko mo nipa oro awon omo toun bi fun un. O ni akobi nikan lo je toko oun ninu awon omo naa, ati pe oto lawon toun bi awon meji to ku fun.
O salaye siwaju fun egbon oko re pe leyin toun bi akobi tan to si se die kawon too bi omo keji loun jade soro ara oun laiso fun oko oun, nibe ni won si ti so foun pe nnkan omokunrin oko oun ko le di omo mo.
Rutu so fun Arabinrin Dupe pe idi niyi toun fi pinnu lati ni oju sita. O leni toun bi omo keji fun si wa laye, bo tile je pe awon ti rira tipe sugbon o mo pe oun loyun fun un.
O lohun to waa di wahala sorun oun bayii ni eniketatoun bi omo keta fun, o ni agbegbe Lokore ti soobu oun wa ni soobu okunrin ti a foruko bo lasiiri naa wa.
Rutu ni ojoojumo lomokunrin naa n yo oun lenu pe oun fee gba omo oun, niwon igba toun si mo daju pe oun loun loyun fun, idi niyi toun fi tete waa jewo ara oun ki asiri naa too tu lati ita.
Leyin gbogbo alaye re la gbo pe egbon oko so fun Rutu pe toko re ba ti de lati irinajo, ko so fun un pe awon molebi fee ri i. Nigba toko Rutu pada de lopin ose yen, Rutu so foko re pe awon molebi fee ri i, oko beere pe se ko si wahala, Rutu si ni oun ko mo.
Nigba tawon mejeeji de odo molebi oko, awon agbaagba ti won jokoo so pe Rutu lo waa ju bombu oro kan sile, idi si niyi tawon fi ranse pe e, bayii ni won so fun Rutu pe ko fenu ara re salaye oro to waa so fun egbon oko re. Bi Rutu se pari atotonu re bayii, se ni oko bu sekun nitori pe oro naa ba a lojiji, ninu ipade naa si lawon molebi ti so fun Rutu pe se ni ko yaa ko eru re kuro ninu ile omo awon koro naa ma loo yorisi nnkan mi-in.
Nigba to di ojo kokanlelogbon, osu karun-un to koja yii ni Iwe Iroyin Yoruba gbo pe Rutu ati aburo re kan mu moto nla kan lo sile oko re, to siko gbogbo eru re patapata pelu awon omo mejeeji to je ti ale. Akobi to pe ni ti oko nikan lo fi sile fun un. Nigba ti Iwe Iroyin Yoruba pe Rutu lori ero ibanisoro re, o koko so fun wa pe awon molebi oko oun ni won so pe oun ko gbodo duro ninu ile omo awon mo leyin toun salaye oro funwon. Sugbon nigba ti akoroyin wa beere bi oro se je gan-an, obinrin yii n soro lowo ni okunrin kan lara awon molebi re so pe ko Saaye lati soro mo.
Okunrin yii so pe ohun tawon molebi oko Rutu ti wonpe wa soro naa ba ti so naa ni ka ko.
Igbeyawo osu mefa daru, oko ni: Iyawo mi n toole, otun n se nnkan osu lojoojumo, e tu wa ka -- Bisi Adesoye, Ilesa
IGBEYAWO bonkele to waye laarin Ogbeni Abayomi Adegoke ati iyawo re, Omowumi ni nnkan bii osu mefa seyin ti ja si pentuka bayii. Esun ti oko fi kan iyawo e ni pe o maa n to sile ati pe ojoojumo lo maa n see nnkan osuu.
Nigba ti Iwe Iroyin Yoruba n ba Adegoke soro lopin ose to koja ni adugbo Oke Omiru, n’Ilesa, baale ile yii ni oun ti sa kaakiri ile babalawo atialadura fun Omowumi, sugbon pabo ni gbogbo e ja si. Okunrin naa loun ti na egbelegbe owo lori aisan to n se Omowumi yii, o si po debii pe gbogbo owo ti awon iba maa fi jeun loun tina lori iyawo oun yii.
O lasiko kan wa toun gba owo ajo bii egberun marun-un naira, ori Omowumi lowo naa pari si, ko si si ayipada kankan. O loun fi oro naa to awon eeyan oun leti, won si ti gba oun nimoran pe koun ko obinrin naa sile ti oun ba fee gbe igbesi aye alaafia.
Iperindo, nibi ti Adegoke ti n sise lo loun ti padee, tawon mejeeji si jo fera won. Adegoke fi kun oro re pe Omowumi ko ni iya tabi baba mo. O ni lasiko toun ri i, awon aisedeede re mejeeji naa ko ti i bere, oun si gba lati fi i seiyawo, sugbon leyin osu meji tawon segbeyawo palo onibonkele ni wahala naa bere si Omowumi.
Nigba ti Omowumi n mura lati rin irinajo lo s’Ibadan, nibi ti egbon baba re wa ni akoroyin wa pade re niwaju ile won, o si so pe oun yoo loo farapamo lodo egbon baba oun, nibi ti oun yoo ti sunkun si Olorun lorun lori aisan to n se oun yii. O ni iya ati baba oun ko bi arun naa mo oun, sugbon leyin igbeyawo naa lo bere si i se oun.
Omowumi ni pelu aawe ati adura loun yoo fi koju wahala aye oun, ti oun si mo pe ti gbogbo oke isoro aye oun ba kuro, oun yoo gbe igba ope niwaju Oluwa. Pelu omi loju lomobinrin naa fi n ba akoroyin wa soro.
**{Legacy activities, comments etc counter: 635; topic series: 10; forum: MediaYoruba; associated: 10- /*}