By Adeola Olanrewaju
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ obìnrin kan tó ṣètò bí ó ṣe jí ara rẹ̀ gbé pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó sì gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀.
Orílẹ̀-èdè South Africa ni ọkọ obìnrin yìí ń gbé, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Bélú ni ó pe ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà pé wọ́n ti jí ìyàwó òun gbé, ó ní òun ti san mílíọ́nù mẹ́ta náírà owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ wọn kò fi sílẹ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá bá ta mọ́ra, wọ́n kò sí ìwádìí, ṣàdédé ni obìnrin náà dé sílé tó ní wọ́n dá òun sílẹ̀.
Obìnrin yìí ṣe àlàyé pé àwọn ajínigbé dá òun lọ́nà, mẹ́fà ni iye wọn pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́, ó ní wọ́n gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ òun olówó iyebíye iphone 12promax. Ó ní inú àpò owó òun ni ọkọ òun san owó ìtúsílẹ̀ náà sí tí òun sì tari rẹ̀ sínú àpò owó àwọn ajínigbé.
Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní àlàyé tí obìnrin yìí ṣe kò bára mu, wọ́n ṣe ìwádìí nọ́ḿbà tí wọ́n fi bá ọkọ sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì Whatsapp.
Ẹdẹ ni ẹni tó ni nọ́ḿbà náà wà, àwọn ọlọ́pàá lọ gbé e ó sì jẹ́wọ́ pé ọ̀rẹ́ òun náà tọrọ láti fi nọ́ḿbà òun ṣí ìkànnì Whatsapp òun sì fi òǹkà OTP ránṣẹ́ síi, ó ní òun kò mọ ohun tí ó fẹ́ fi ṣe.
Bákan náà ni wọ́n tọpinpin ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ iphone 12pro max dé ọwọ́ ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n kan, ó ṣe àlàyé pé òun ra ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ obìnrin náà ní ọ̀rìnlélọ́ọ̀dúnrún ẹ̀gbẹ̀rún náírà #380,000 pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé kí òun má tan ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní obìnrin náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ìwádìí bá parí. Wọ́n rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún ìwà ọ̀daràn.