Gbagede Yoruba
 



Blessing Gun Orekunrin Re Pa Ni Lekki
 
Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose Lati Owo Akoroyin Olootu

Blessing Gun Orekunrin Re Pa Ni Lekki

Boya ka ni Blessing Edet to je omo odun merinlelogun mo pe ile orekunrin re, Edet Ebong, to je eni odun metalelogun toun fee loo sun lojo naa yoo ko ibanuje ayeraye ba oun atawon ebi oun ni, o see se ko ma lo sile orekunrin re to pada seku pa, eyi to mu un dewaju adajo nile-ejo majisireeti to wa l'Ebute-Meta, niluu Eko.

Gege bi agbenuso ijoba, Sajenti Maria Dauda, se salaye, oru ojo kejidinlogun, osu kejo, odun to koja, nisele ohun waye lojule kin-in-ni, laduugbo Falana, lagbegbe Ogombo, ni Lekki, niluu Eko. Wahala kan lo sele laarin awon olulufe mejeeji yii. Koloju si too se e, Blessing ti gun orekunrin re lobe idana nikun.

Gbogbo akitiyan re atawon araale lati doola emi Edet lo ja si pabo pelu bo se jepe orun. Kia lawon eeyan ti fa olujejo le olopaa lowo, leyin iwadii ni won taari e lo sile-ejo.

Esun kan soso to da lori ipaniyan ni agbenuso ijoba nile-ejo fi kan olujejo, eyi lo si lodi sofin ipinle Eko, bee nijiya wa fun un labe ofin. O so siwaju pe oun ti fi eda iwe esun ohun sowo si eka to n ri soro idajo fun amoran to peye.

Ninu idajo re, Adajo B.O Folarin-Williams pase pe ki won si loo fi Blessing pamo satimole ogba ewon olopaa titi ti won yoo fi gbo amoran latodo oludari oro igbejo nipinle Eko. O waa sun igbejo mi-in si osu to n bo.

Ile-ejo koko-koko to wa niluu Ilesa ni Ogbeni Olusola Onifade gbe iyawo re, Arabinrin Simbiatu, to fesun agbere kan lo, nibi to ti rawo ebe sadajo lati tu igbeyawo odun mewaa to wa laarin won ka.

Nigba to n wi awijare re niwaju adajo, Onifade pe Oluso-agutan Femi Olayinka tijo 'Christ Miracle', Orisun-iye, to fikale sagbegbe Powerline Ajebandele, niluu Ile-Ife, ti fun iyawo oun loyun, tobinrin ti ko nitiju ohun ko si fi bo rara.

Okunrin naa ni Simbiatu lo figba kan ro oun pe koun gba idile awon laaye lati maa loo josin ninu ijo naa laimo pe oluso-agutan naa yoo pada fun iyawo oun loyun.

Onifade tesiwaju pe Olorun fi asepo Simbiatu ati Pasito Femi Olayinka han oun ni oju ala, nibi toun ati okunrin naa ti n fa nnkan mo ara won lowo. O ni leyin toun la ala naa loun lo sodo pasito ohun lati fidi aala naa mule, sugbon iyalenu lo je foun nigba ti Olayinka so pe loooto loun ti fun iyawo oun loyun, bee lo ni koun jowo iyawo oun toun ba nifee ara oun pelu awon omo meji to wa ninu igbeyawo naa.

Nigba ti Ogbeni Azeez Kareem n jerii nile-ejo, o fidi e mule pe loooto ni Simbiatu je aburo oun, ati pe oun ati Pasito Olayinka ti ba agbere won debi to lapeere pelu bi won se ti n se bii toko-taya, ti aburo oun si ti loyun fun un. O ni bo tile je pe gbogbo ebi ti dide soro naa, sugbon nise lo da bii pe Pasito ti fun obinrin naa ni oogun ife pelu bo se faso ya mo iya re lara, ti ko si fee gbo imoran eni kankan.

Ninu oro elerii keji to je aburo olupejo, Arabinrin Elizabeth Oyeyemi, o salaye pe Pasito Femi ti n wa ona lati pa egbon oun nitori oro obinrin. O waa ro ile-ejo naa lati tu igbeyawo naa ka ni kiakia.

Ninu oro Simbiatu nile-ejo, o fidi e mule pe Pasito Femi ni okan oun n fe bayii, ati pe ko seni kankan to le ye ese oun kuro nibe.

Leyin atotonu awon mejeeji, Adajo Bunmi Adegoke tu igbeyawo naa ka, bee lo pase pe kawon omo meji to wa ninu igbeyawo naa maa gbe lodo baba won.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 19:53:45 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose:
Iru Pasito Radarada Wo Waa Ni Oluso-Aguntan Oyelami Yii Gbogbo Awon Omobinrin Ij


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose



"Blessing Gun Orekunrin Re Pa Ni Lekki" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com