Gbagede Yoruba
 



Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo

Latigba ti mo ti n soro ashaaju Yoruba, igba kan ma fere koja ti n ko ni i gba atejishe lori awon oba ile wa, paapaa awon ashaaju oba meji ta a ni, Ooni ati Alaafin, pelu Aare Ona Kakanfo. Atejishe ti mo n gba naa ni pe iru awon to ye ko she ashaaju fun Yoruba ti mo n wi niyi, iru awon oba to ye ko ko Yoruba lo sibi ti mo fe niyen, awon oba to lashe lenu. Loooto ni. Ko si ohun ti iba wu mi bi ki eni kan ninu awon meteeta yii je ashaaju fun Yoruba. Idi ni pe awon meteeta ni won ti di ipo naa mu ri, ti won si ko Yoruba debi to dara. Ni ibere pepe, Oduduwa ni olori gbogbo wa, ashe ti Oduduwa ba pa ni gbogbo Yoruba to ku yoo tele nibikibi ti won ba wa, bo ba ti pashe bayii, ashe naa yoo mule ni. Eni to ba si fee mo bi agbara yii ti po to ko ranti igba tawon ilu Ibinni (Benin) n wa olori, to je Oduduwa ni won waa ba ko fun won loba.

Tabi ta ni yoo so pe oun ko mo agbara Alaafin nile Yoruba wa yii. Igba kan ti wa to je o fere ma si ibi kan ni ile Yoruba ti agbara oba nla yii ko de, koda awon ti won ko si labe re gan-an, bo ba pashe, won ko to eni ti i da a koja. Alaafin lo nile, oun ni oba, oun naa si ni olori ilu, ohun gbogbo to ba so, ashe ni. Asiko tire ni ile Yoruba ran kaakiri, ti ijoba re bere lati ile awon Tapa, titi to fi de orile-ede Ghana, ti awon ti won ko si sun mo ilu Oyo rara n fi oruko Alaafin she ohun gbogbo ti won ba fee she. Bo tile je pe nigba ti Alaafin yoo fi maa she olori ile Yoruba yii, awon omo Oduduwa ti fonka, sibe, oba yii fi agbara re ko gbogbo won si abe ara e, o si n she akoso ile naa, ti ko si seni to le beere pe bawo lo she she e, tabi ti yoo so pe oun o ni i tele ashe to ba pa. Eyi ni pe bi Alaafin she olori ile Yoruba lasiko ta a wa yii, ko sohun to buru nibe.

Tabi ti Aare Ona Kakanfo la fee so ni. Bi enikan ba wa ti Alaafin funra re maa n beru ni koro, Aare ni. Idi ni pe ko si oba, bi ko ba si jagunjagun laye igba naa: bi awon jagunjagun ba ti to naa ni agbara ati iyi oba kan n to, oba ti ko ba le jagun ki i she eni ti won yoo beru nibi kan. Bi won o ba si beru oba, ko si iyi ti won yoo fun un. Alaafin funra re ko ni i lo soju ogun, Alaafin yoo shigun ni, eni ti yoo si pashe yii fun naa l'Aare Ona Kakanfo, tori o ti mo pe yoo lo soju ogun naa, yoo si shegun. Bi agbara Aare kan ba ti to ni iyi ati iberu oun naa n to, nitori e lo she je eni ti o ba loogun, ti ko si le jagun, ko ni i je aare ona kakanfo igba naa, ipo awon alagbara ni. Ko si aare igba naa kan ti won fi je ti ki i she alagbara, ajagun-shegun ni won. Bo ba si je bi nnkan she wa nigba naa lo shi wa lasiko yii ni, Aare to lati ko omo Yoruba je, o too she olori wa daadaa.

Sugbon nnkan ti yato pata, aye ti kuro lowo awon wonyi, awon mi-in ti n gba ishe won she. Lati igba ti iyapa ti de ba awon omo Yoruba ni iyi ti Ooni ni ko ti to ti tele mo, nigba ti gbogbo won ti kuro ni ile baba won. Kaluku n she tire loto ni, agbara naa si po de gongo, agaga nigba ti Oduduwa funra re dagbere faye. Awon omo re ko ri ara won bii omo baba kan naa mo, kaluku n she ohun to ba fe ni adugbo tire ni. Bi iran kan ba wa, tabi tawon eeyan kan ba wa, tabi orile-ede kan lo wa, nibi ti onikaluku ti n she tie loto, ishokan yoo jinna si won, bi ishokan ba si ti jinna si won, ko le shoro kapa awon ota too ka won. Nigba ti ishoro ti wa lati shakoso Yoruba lati Ile-Ife ti i she orirun gbogbo wa, igba naa ni ko ti si enu kan lati fi soro mo: iyapa enu wa ninu iwa ati ishe wa. Ooni ko lagbara bii tatijo mo, awon oloshelu ti gba ishe e she.

Nigba tawon oyinbo de, owo eni ti won ba agbara ni Alaafin, bo tile je pe awon ile Yoruba mi-in, paapaa Ibadan, ti dide gege bii alagbara lagbegbe won, iwonba agbara to ku lowo Alaafin lo fi n pashe. Nitori e lo she je pe nigba ti won ti gba Eko, ti won kapa Ijebu, Oyo ni won lo taara lati kori Alaafin sabe. Won ba Alaafin igba naa ja, won si te ori e ba ti ko fi le she ohunkohun yato seyii tawon oyinbo ba fe. Agbara ibon ati ka so oba to ba shagidi sewon, ka ro o loye, ka le e kuro niluu, lawon oyinbo yii fi sheruba awon oba wa, ati oba gbogbo ni Naijiria paapaa, eyi o si je kenikeni ninu won laya lati dojuko won. Ohun tawon oyinbo yii foju Adeyemi akoko ri lo n lo yii, ko si seni ti ko gbo itan pe ijoba awon Awolowo lo yo Adeyemi Keji kuro lori oye, ohun toju Alaafin Keta to wa lori oye yii naa si ti ri lowo awon oloshelu, oun nikan lo le so.

Ni ti Aare Ona kakanfo, agbara awon naa ti di otubante nigba ti ko ti sagbara lowo Alaafin mo. Tabi ogun wo ni Aare kan ja ni ko-pe-ko-pe yii, awon wo lo si ba jagun. Lati aye Akintola, nigba ti Alaafin Gbadegeshin Ladigbolu fi i je Aare, ko si kinni kan to le she, ohun to tie je ki agbara re han saye die ni pe olori ijoba ile Yoruba (Western Region), loun nigba naa, oshelu lo fi i she olori ijoba. Nigba toro naa kan Moshood Abiola, loooto olowo nla loun, sibe, ko ni agbara kan lati fi she akoso ile Yoruba, nitori nigba ti oun naa n joye yii, opo awon gomina ologun ile Yoruba igba naa ko debi ti won ti fi i je. Oro naa dun Abiola, o si so o moro pe ki odidi Aare Ona Kakanfo maa je nile Yoruba kawon gomina ibe ma wa, ohun ti ko daa ni. Lati fi han Abiola pe awon ko mo agbara Aare, awon shoja kan ya lo sile re ni bii oshu keji to je Aare.

Won ni Kola omo re ri awon fin, won lu gbogbo awon ara ile e ni ilukulu ni o, won da Abiola funra e jokoo sileele, arifin naa si ba awon eeyan leru, nitori olowo l'Abiola, ore Babangida to n shejoba si ni. Sugbon won ko ri awon shoja ti won kolu u yii mu, won ni awon shoja ti won ko mo ni (Unknown Soldiers). Oro naa di awada laarin Abiola atawon ijoye Oyo ti won loo ki i nigba ti won so fun un pe Aare ki i sa fun ogun o! Abiola ni ko si Aare kankan loju ibon shoja o, afi ti a ba n tan ara wa je. Ohun naa lo shele nigba ti won n fi Gani Adams je Aare yii. Gomina meloo lo wa nibe, bee gbogbo won lo to oruko won sinu iwe-ipe, Siaka kan shosho to wa nibe binu kuro ni, o ni Olubadan roun fin. Omo Ibadan si ni o, bo ba si l'Olubadan roun fin, o ye ki kaluku ti mo pe nnkan ti shele si Yoruba. Awon oba wa o je kinni kan loju awon oloshelu yii rara.

Bo tile je pe awon oba ile Hausa niyi daadaa loju awon eeyan won, ati loju eni yoowu to n shejoba, oro awon oba ti Yoruba ko ri bee rara. Igba kan wa to je Sultan ile Sokoto lo da bii olori ijoba Naijiria, nitori igbakigba to ba yoju si awon olori ijoba, won yoo dide fun un ni, titi de ori awon Babangida yii nigba ti Dasuki fi n she Emir, ko too di pe Abacha kan iye olori awon oba ile Hausa naa. Koko ohun ti mo n so ni pe ishoro ni fun wa lati reti ashaaju Yoruba lodo Ooni tabi Alaafin, ka ma ti i so Aare Ona Kakanfo, nitori awon oloshelu ti gba agbara won lowo won. Bi ofin ti she eto naa loni-in niyi, alaga ijoba ibile ti oba kan ba wa lagbara ju u lo. Alaga ibile ni olori oba, ko si ti i kan komisanna fun eto oro oye, ka ma ti i so alashe pata, iyen gomina ipinle won. Bi gomina kan ba bu ramuramu, ko si oba kan to gbodo duro.

O jo pe ohun to n je kawon kan ronu pe ka mu oloshelu she ashaaju Yoruba niyi, iwe awon naa po lodo mi repete. Sugbon a ko le mu oloshelu she ashaaju, nitori agbara tawon ni ko lo titi, bi oloshelu kan ba wa nipo agbara loni-in ti a ba mu un, ta lo mo oloshelu mi-in ti yoo debe lola. Paapaa julo, awon oshelu ko tie shee fi iru oye bee fun, won yoo fi ko gbogbo eeyan adugbo naa si abe won ni, iyen ko si so pe ki won tori e she ashaaju naa daadaa, won yoo kan maa fi oruko Yoruba lu jibiti bi won ti n she loni-in yii naa ni. Iyen la o she le mu oloshelu. Bee, a gbodo leni ti yoo to wa sona, ti yoo shaaju wa, awon oba wa lo si ti ha sabe ofin oshelu yii. Boya bi ore mi purofeso ojosi she wi naa la o she, funra wa la oo fa ashaaju jade. Amo bawo la oo wa she she e!

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:30:18 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise



"Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com