Prev  

82. Surah Al-Infitâr سورة الإنفطار

  Next  




Ayah  82:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
إِذَا السَّمَاءُ انفَطَرَتْ
Yoruba
 
Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,

Ayah  82:2  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْكَوَاكِبُ انتَثَرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

Ayah  82:3  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْبِحَارُ فُجِّرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,

Ayah  82:4  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْقُبُورُ بُعْثِرَتْ
Yoruba
 
Àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,

Ayah  82:5  الأية
    +/- -/+  
عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّا قَدَّمَتْ وَأَخَّرَتْ
Yoruba
 
(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

Ayah  82:6  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الْإِنسَانُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ الْكَرِيمِ
Yoruba
 
Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,

Ayah  82:7  الأية
    +/- -/+  
الَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّاكَ فَعَدَلَكَ
Yoruba
 
Ẹni t'Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.

Ayah  82:8  الأية
    +/- -/+  
فِي أَيِّ صُورَةٍ مَّا شَاءَ رَكَّبَكَ
Yoruba
 
Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.

Ayah  82:9  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا بَلْ تُكَذِّبُونَ بِالدِّينِ
Yoruba
 
Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

Ayah  82:10  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَافِظِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.

Ayah  82:11  الأية
    +/- -/+  
كِرَامًا كَاتِبِينَ
Yoruba
 
(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.

Ayah  82:12  الأية
    +/- -/+  

Ayah  82:13  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الْأَبْرَارَ لَفِي نَعِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.

Ayah  82:14  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ الْفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.

Ayah  82:15  الأية
    +/- -/+  
يَصْلَوْنَهَا يَوْمَ الدِّينِ
Yoruba
 
Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.

Ayah  82:16  الأية
    +/- -/+  
وَمَا هُمْ عَنْهَا بِغَائِبِينَ
Yoruba
 
Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.

Ayah  82:17  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ
Yoruba
 
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

Ayah  82:18  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ مَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

Ayah  82:19  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَ لَا تَمْلِكُ نَفْسٌ لِّنَفْسٍ شَيْئًا ۖ وَالْأَمْرُ يَوْمَئِذٍ لِّلَّهِ
Yoruba
 
(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us