Prev  

51. Surah Az-Zâriyât سورة الذاريات

  Next  




Ayah  51:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
وَالذَّارِيَاتِ ذَرْوًا
Yoruba
 
Allāhu fi atẹ́gùn tó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ ní títu-jáde tààrà búra.

Ayah  51:2  الأية
    +/- -/+  
فَالْحَامِلَاتِ وِقْرًا
Yoruba
 
Allāhu fi àwọn ẹ̀ṣújò tó ru òjò tó wúwo búra.

Ayah  51:3  الأية
    +/- -/+  
فَالْجَارِيَاتِ يُسْرًا
Yoruba
 
Allāhu fi àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn búra.

Ayah  51:4  الأية
    +/- -/+  
فَالْمُقَسِّمَاتِ أَمْرًا
Yoruba
 
Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń pín n̄ǹkan tí Ó ti pín fún ẹ̀dá búra.

Ayah  51:5  الأية
    +/- -/+  
إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَصَادِقٌ
Yoruba
 
Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.

Ayah  51:6  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ الدِّينَ لَوَاقِعٌ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ẹ̀san iṣẹ́ máa ṣẹlẹ̀.

Ayah  51:7  الأية
    +/- -/+  
وَالسَّمَاءِ ذَاتِ الْحُبُكِ
Yoruba
 
Allāhu tún fi sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́ tó gún régé búra.

Ayah  51:8  الأية
    +/- -/+  
إِنَّكُمْ لَفِي قَوْلٍ مُّخْتَلِفٍ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ tó ń takora wọn (nípa al-Ƙur'ān).

Ayah  51:9  الأية
    +/- -/+  
يُؤْفَكُ عَنْهُ مَنْ أُفِكَ
Yoruba
 
Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur'ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ).


Ayah  51:11  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ هُمْ فِي غَمْرَةٍ سَاهُونَ
Yoruba
 
Àwọn tí wọ́n wà nínú àìmọ̀kan tó gbópọn tí wọ́n ti gbàgbéra.

Ayah  51:12  الأية
    +/- -/+  
يَسْأَلُونَ أَيَّانَ يَوْمُ الدِّينِ
Yoruba
 
Tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.

Ayah  51:13  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَ هُمْ عَلَى النَّارِ يُفْتَنُونَ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà.

Ayah  51:14  الأية
    +/- -/+  
ذُوقُوا فِتْنَتَكُمْ هَٰذَا الَّذِي كُنتُم بِهِ تَسْتَعْجِلُونَ
Yoruba
 
Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú.

Ayah  51:15  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).

Ayah  51:16  الأية
    +/- -/+  
آخِذِينَ مَا آتَاهُمْ رَبُّهُمْ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَبْلَ ذَٰلِكَ مُحْسِنِينَ
Yoruba
 
Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn.

Ayah  51:17  الأية
    +/- -/+  
كَانُوا قَلِيلًا مِّنَ اللَّيْلِ مَا يَهْجَعُونَ
Yoruba
 
Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru.

Ayah  51:18  الأية
    +/- -/+  
وَبِالْأَسْحَارِ هُمْ يَسْتَغْفِرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.

Ayah  51:19  الأية
    +/- -/+  
وَفِي أَمْوَالِهِمْ حَقٌّ لِّلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ
Yoruba
 
Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún.

Ayah  51:20  الأية
    +/- -/+  
وَفِي الْأَرْضِ آيَاتٌ لِّلْمُوقِنِينَ
Yoruba
 
Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú.

Ayah  51:21  الأية
    +/- -/+  
وَفِي أَنفُسِكُمْ ۚ أَفَلَا تُبْصِرُونَ
Yoruba
 
Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ kò ríran ni?

Ayah  51:22  الأية
    +/- -/+  
وَفِي السَّمَاءِ رِزْقُكُمْ وَمَا تُوعَدُونَ
Yoruba
 
Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín wà nínú sánmọ̀.

Ayah  51:23  الأية
    +/- -/+  
فَوَرَبِّ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ إِنَّهُ لَحَقٌّ مِّثْلَ مَا أَنَّكُمْ تَنطِقُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀.

Ayah  51:24  الأية
    +/- -/+  
هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ ضَيْفِ إِبْرَاهِيمَ الْمُكْرَمِينَ
Yoruba
 
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

Ayah  51:25  الأية
    +/- -/+  
إِذْ دَخَلُوا عَلَيْهِ فَقَالُوا سَلَامًا ۖ قَالَ سَلَامٌ قَوْمٌ مُّنكَرُونَ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: "Àlàáfíà (fún ọ)." Òun náà sọ pé: "Àlàáfíà (fún yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn."

Ayah  51:26  الأية
    +/- -/+  
فَرَاغَ إِلَىٰ أَهْلِهِ فَجَاءَ بِعِجْلٍ سَمِينٍ
Yoruba
 
Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù tó ní ọ̀rá (tí wọ́n ti yangbẹ).

Ayah  51:27  الأية
    +/- -/+  
فَقَرَّبَهُ إِلَيْهِمْ قَالَ أَلَا تَأْكُلُونَ
Yoruba
 
Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?"

Ayah  51:28  الأية
    +/- -/+  
فَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً ۖ قَالُوا لَا تَخَفْ ۖ وَبَشَّرُوهُ بِغُلَامٍ عَلِيمٍ
Yoruba
 
Nígbà náà, ìbẹ̀rù wọn sì mú un.. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe páyà." Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.

Ayah  51:29  الأية
    +/- -/+  
فَأَقْبَلَتِ امْرَأَتُهُ فِي صَرَّةٍ فَصَكَّتْ وَجْهَهَا وَقَالَتْ عَجُوزٌ عَقِيمٌ
Yoruba
 
Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ wọlé pẹ̀lú igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: "Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!"

Ayah  51:30  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ ۖ إِنَّهُ هُوَ الْحَكِيمُ الْعَلِيمُ
Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀."

Ayah  51:31  الأية
    +/- -/+  
قَالَ فَمَا خَطْبُكُمْ أَيُّهَا الْمُرْسَلُونَ
Yoruba
 
(Ànábì 'Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?"

Ayah  51:32  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمٍ مُّجْرِمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni

Ayah  51:33  الأية
    +/- -/+  
لِنُرْسِلَ عَلَيْهِمْ حِجَارَةً مِّن طِينٍ
Yoruba
 
Nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn.

Ayah  51:34  الأية
    +/- -/+  
مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَ لِلْمُسْرِفِينَ
Yoruba
 
Wọ́n ti fi àmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ."

Ayah  51:35  الأية
    +/- -/+  
فَأَخْرَجْنَا مَن كَانَ فِيهَا مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, A mú àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà).

Ayah  51:36  الأية
    +/- -/+  
فَمَا وَجَدْنَا فِيهَا غَيْرَ بَيْتٍ مِّنَ الْمُسْلِمِينَ
Yoruba
 
A kò sì rí nínú (ìlú náà) yàtọ̀ sí ilé kan tó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí.

Ayah  51:37  الأية
    +/- -/+  
وَتَرَكْنَا فِيهَا آيَةً لِّلَّذِينَ يَخَافُونَ الْعَذَابَ الْأَلِيمَ
Yoruba
 
A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn tó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Ayah  51:38  الأية
    +/- -/+  
وَفِي مُوسَىٰ إِذْ أَرْسَلْنَاهُ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ بِسُلْطَانٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon.

Ayah  51:39  الأية
    +/- -/+  
فَتَوَلَّىٰ بِرُكْنِهِ وَقَالَ سَاحِرٌ أَوْ مَجْنُونٌ
Yoruba
 
Ṣùgbọ́n ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti kẹ̀yìn sí òdodo. Ó sì wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí)."

Ayah  51:40  الأية
    +/- -/+  
فَأَخَذْنَاهُ وَجُنُودَهُ فَنَبَذْنَاهُمْ فِي الْيَمِّ وَهُوَ مُلِيمٌ
Yoruba
 
Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù.

Ayah  51:41  الأية
    +/- -/+  
وَفِي عَادٍ إِذْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمُ الرِّيحَ الْعَقِيمَ
Yoruba
 
(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn.

Ayah  51:42  الأية
    +/- -/+  
مَا تَذَرُ مِن شَيْءٍ أَتَتْ عَلَيْهِ إِلَّا جَعَلَتْهُ كَالرَّمِيمِ
Yoruba
 
Kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kí ó sọ ọ́ di n̄ǹkan tó kẹfun.

Ayah  51:43  الأية
    +/- -/+  
وَفِي ثَمُودَ إِذْ قِيلَ لَهُمْ تَمَتَّعُوا حَتَّىٰ حِينٍ
Yoruba
 
(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: "Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná."

Ayah  51:44  الأية
    +/- -/+  
فَعَتَوْا عَنْ أَمْرِ رَبِّهِمْ فَأَخَذَتْهُمُ الصَّاعِقَةُ وَهُمْ يَنظُرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀.

Ayah  51:45  الأية
    +/- -/+  
فَمَا اسْتَطَاعُوا مِن قِيَامٍ وَمَا كَانُوا مُنتَصِرِينَ
Yoruba
 
Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́.

Ayah  51:46  الأية
    +/- -/+  
وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ
Yoruba
 
Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ arúfin.

Ayah  51:47  الأية
    +/- -/+  
وَالسَّمَاءَ بَنَيْنَاهَا بِأَيْدٍ وَإِنَّا لَمُوسِعُونَ
Yoruba
 
Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni Alágbára (tí a mú un tóbi).

Ayah  51:48  الأية
    +/- -/+  
وَالْأَرْضَ فَرَشْنَاهَا فَنِعْمَ الْمَاهِدُونَ
Yoruba
 
Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. (Àwa sì ni) olùtẹ́-ilẹ̀ sílẹ̀ tó dára.

Ayah  51:49  الأية
    +/- -/+  
وَمِن كُلِّ شَيْءٍ خَلَقْنَا زَوْجَيْنِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ
Yoruba
 
Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.

Ayah  51:50  الأية
    +/- -/+  
فَفِرُّوا إِلَى اللهِ ۖ إِنِّي لَكُم مِّنْهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ayah  51:51  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَجْعَلُوا مَعَ اللهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۖ إِنِّي لَكُم مِّنْهُ نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ayah  51:52  الأية
    +/- -/+  
كَذَٰلِكَ مَا أَتَى الَّذِينَ مِن قَبْلِهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا قَالُوا سَاحِرٌ أَوْ مَجْنُونٌ
Yoruba
 
Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn tó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè ni."

Ayah  51:53  الأية
    +/- -/+  
أَتَوَاصَوْا بِهِ ۚ بَلْ هُمْ قَوْمٌ طَاغُونَ
Yoruba
 
Ṣé́wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-ààlà ni wọ́n ni.

Ayah  51:54  الأية
    +/- -/+  
فَتَوَلَّ عَنْهُمْ فَمَا أَنتَ بِمَلُومٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe ẹni tí A máa bá wí.

Ayah  51:55  الأية
    +/- -/+  
وَذَكِّرْ فَإِنَّ الذِّكْرَىٰ تَنفَعُ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  51:56  الأية
    +/- -/+  
وَمَا خَلَقْتُ الْجِنَّ وَالْإِنسَ إِلَّا لِيَعْبُدُونِ
Yoruba
 
Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi.

Ayah  51:57  الأية
    +/- -/+  
مَا أُرِيدُ مِنْهُم مِّن رِّزْقٍ وَمَا أُرِيدُ أَن يُطْعِمُونِ
Yoruba
 
Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi.

Ayah  51:58  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ اللهَ هُوَ الرَّزَّاقُ ذُو الْقُوَّةِ الْمَتِينُ
Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle.

Ayah  51:59  الأية
    +/- -/+  
فَإِنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا ذَنُوبًا مِّثْلَ ذَنُوبِ أَصْحَابِهِمْ فَلَا يَسْتَعْجِلُونِ
Yoruba
 
Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn tó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn).

Ayah  51:60  الأية
    +/- -/+  
فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا مِن يَوْمِهِمُ الَّذِي يُوعَدُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us