Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan tó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.
Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: "Kí ó sì jẹ́ pé àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?" Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún wọn mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé ṣe sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n wí pé: "Nūh, o mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo."
Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí."
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé, dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni tó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí. Dájúdájú wọ́n máa tẹ̀ wọ́n rì ni.
Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Ìgbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: "Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.
A kò níí sọ n̄ǹkan kan (sí ọ) bí kò ṣe pé, àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (ló fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn)." Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ
Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fún yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan tó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ kò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan."
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà tó nípọn.
Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ náà, ó pajú dà sí wọn (ó f'ojú òdì wo àìjẹun wọn). Ìbẹ̀rù wọn sì mú un. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí."
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ sísun lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.
A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú.
Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin.
Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí dín in kù.
Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.