Ṣé wọ́n mú àwọn aláàbò kan lẹ́yìn Rẹ̀ ni? Allāhu, Òun sì ni Aláàbò. Òun l'Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ohunkóhun tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ọ̀run, A máa ṣe àlékún sí èso rẹ̀ fún un. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ayé, A máa fún un nínú rẹ̀. Kò sì níí sí ìpín kan kan fún un mọ́ ní ọ̀run.
(Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tó jẹ́pè ti Olúwa wọn, tí wọ́n ń kírun, ọ̀rọ̀ ara wọn sì jẹ́ ìjíròrò láààrin ara wọn, wọ́n tún ń ná nínú arísìkí tí A pèsè fún wọn.
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò tún sí aláàbò kan fún un mọ́ lẹ́yìn Rẹ̀. O sì máa rí àwọn alábòsí nígbà tí wọ́n bá rí Iná, wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ ọ̀nà kan kan wà tí a lè fi padà sí ilé ayé?"
O sì máa rí wọn tí A máa kó wọn lọ sínú Iná; wọn yóò palọ́lọ́ láti ara ìyẹpẹrẹ, wọn yó si máa wò fín-ín-fín. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ara ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde." Kíyè sí i, dájúdájú àwọn alábòsí yóò wà nínú ìyà gbére.
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, A kò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ fún wọn. Kò sí kiní kan tó di dandan fún ọ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn). Àti pé dájúdájú nígbà tí A bá fún ènìyàn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn án nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọn tì ṣíwájú (ní iṣẹ́ aburú), dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore.
Báyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà), ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà ('Islām).