Prev  

54. Surah Al-Qamar سورة القمر

  Next  




Ayah  54:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
اقْتَرَبَتِ السَّاعَةُ وَانشَقَّ الْقَمَرُ
Yoruba
 
Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).

Ayah  54:2  الأية
    +/- -/+  
وَإِن يَرَوْا آيَةً يُعْرِضُوا وَيَقُولُوا سِحْرٌ مُّسْتَمِرٌّ
Yoruba
 
Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: "Idán kan tó máa parẹ́ (ni èyí)."

Ayah  54:3  الأية
    +/- -/+  
وَكَذَّبُوا وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ ۚ وَكُلُّ أَمْرٍ مُّسْتَقِرٌّ
Yoruba
 
Wọ́n pè é ní irọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn.

Ayah  54:4  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ جَاءَهُم مِّنَ الْأَنبَاءِ مَا فِيهِ مُزْدَجَرٌ
Yoruba
 
Dájúdájú wáàsí tí ó ń kọ aburú wà nínú àwọn ìró tó dé bá wọn.

Ayah  54:5  الأية
    +/- -/+  
حِكْمَةٌ بَالِغَةٌ ۖ فَمَا تُغْنِ النُّذُرُ
Yoruba
 
(al-Ƙur'ān sì ni) ọgbọ́n tó péye pátápátá; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

Ayah  54:6  الأية
    +/- -/+  
فَتَوَلَّ عَنْهُمْ ۘ يَوْمَ يَدْعُ الدَّاعِ إِلَىٰ شَيْءٍ نُّكُرٍ
Yoruba
 
Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),

Ayah  54:7  الأية
    +/- -/+  
خُشَّعًا أَبْصَارُهُمْ يَخْرُجُونَ مِنَ الْأَجْدَاثِ كَأَنَّهُمْ جَرَادٌ مُّنتَشِرٌ
Yoruba
 
Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.

Ayah  54:8  الأية
    +/- -/+  
مُّهْطِعِينَ إِلَى الدَّاعِ ۖ يَقُولُ الْكَافِرُونَ هَٰذَا يَوْمٌ عَسِرٌ
Yoruba
 
Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Èyí ni ọjọ́ ìṣòro."

Ayah  54:9  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ فَكَذَّبُوا عَبْدَنَا وَقَالُوا مَجْنُونٌ وَازْدُجِرَ
Yoruba
 
Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: "Wèrè ni." Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.

Ayah  54:10  الأية
    +/- -/+  
فَدَعَا رَبَّهُ أَنِّي مَغْلُوبٌ فَانتَصِرْ
Yoruba
 
Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san."

Ayah  54:11  الأية
    +/- -/+  
فَفَتَحْنَا أَبْوَابَ السَّمَاءِ بِمَاءٍ مُّنْهَمِرٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára.

Ayah  54:12  الأية
    +/- -/+  
وَفَجَّرْنَا الْأَرْضَ عُيُونًا فَالْتَقَى الْمَاءُ عَلَىٰ أَمْرٍ قَدْ قُدِرَ
Yoruba
 
A tún mú àwọn odò ṣàn jáde láti inú ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).

Ayah  54:13  الأية
    +/- -/+  
وَحَمَلْنَاهُ عَلَىٰ ذَاتِ أَلْوَاحٍ وَدُسُرٍ
Yoruba
 
A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,

Ayah  54:14  الأية
    +/- -/+  
تَجْرِي بِأَعْيُنِنَا جَزَاءً لِّمَن كَانَ كُفِرَ
Yoruba
 
Tí ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ẹni tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.

Ayah  54:15  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَد تَّرَكْنَاهَا آيَةً فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣẹ́ ẹ kù (tí A fi ṣe) àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

Ayah  54:16  الأية
    +/- -/+  
فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ
Yoruba
 
Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

Ayah  54:17  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur'ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

Ayah  54:18  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ عَادٌ فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ
Yoruba
 
Ìran ‘Ād pé òdodo ní irọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

Ayah  54:19  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا صَرْصَرًا فِي يَوْمِ نَحْسٍ مُّسْتَمِرٍّ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.

Ayah  54:20  الأية
    +/- -/+  
تَنزِعُ النَّاسَ كَأَنَّهُمْ أَعْجَازُ نَخْلٍ مُّنقَعِرٍ
Yoruba
 
Ó ń fa àwọn ènìyàn tu bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.

Ayah  54:21  الأية
    +/- -/+  
فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ
Yoruba
 
Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

Ayah  54:22  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur'ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

Ayah  54:23  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ ثَمُودُ بِالنُّذُرِ
Yoruba
 
Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.

Ayah  54:24  الأية
    +/- -/+  
فَقَالُوا أَبَشَرًا مِّنَّا وَاحِدًا نَّتَّبِعُهُ إِنَّا إِذًا لَّفِي ضَلَالٍ وَسُعُرٍ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.

Ayah  54:25  الأية
    +/- -/+  
أَأُلْقِيَ الذِّكْرُ عَلَيْهِ مِن بَيْنِنَا بَلْ هُوَ كَذَّابٌ أَشِرٌ
Yoruba
 
Ṣé òun ni wọ́n sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni."

Ayah  54:26  الأية
    +/- -/+  
سَيَعْلَمُونَ غَدًا مَّنِ الْكَذَّابُ الْأَشِرُ
Yoruba
 
Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.

Ayah  54:27  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا مُرْسِلُو النَّاقَةِ فِتْنَةً لَّهُمْ فَارْتَقِبْهُمْ وَاصْطَبِرْ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.

Ayah  54:28  الأية
    +/- -/+  
وَنَبِّئْهُمْ أَنَّ الْمَاءَ قِسْمَةٌ بَيْنَهُمْ ۖ كُلُّ شِرْبٍ مُّحْتَضَرٌ
Yoruba
 
Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.

Ayah  54:29  الأية
    +/- -/+  
فَنَادَوْا صَاحِبَهُمْ فَتَعَاطَىٰ فَعَقَرَ
Yoruba
 
Wọ́n pe ẹni wọn. Ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nawọ́ mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.

Ayah  54:30  الأية
    +/- -/+  
فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ
Yoruba
 
Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?

Ayah  54:31  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ صَيْحَةً وَاحِدَةً فَكَانُوا كَهَشِيمِ الْمُحْتَظِرِ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí koríko gbígbẹ tí àgbẹ̀ dáná sun.

Ayah  54:32  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur'ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

Ayah  54:33  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ بِالنُّذُرِ
Yoruba
 
Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.

Ayah  54:34  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ حَاصِبًا إِلَّا آلَ لُوطٍ ۖ نَّجَّيْنَاهُم بِسَحَرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.

Ayah  54:35  الأية
    +/- -/+  
نِّعْمَةً مِّنْ عِندِنَا ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي مَن شَكَرَ
Yoruba
 
(Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni tó bá dúpẹ́ (fún Wa).

Ayah  54:36  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَنذَرَهُم بَطْشَتَنَا فَتَمَارَوْا بِالنُّذُرِ
Yoruba
 
Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.

Ayah  54:37  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ رَاوَدُوهُ عَن ضَيْفِهِ فَطَمَسْنَا أَعْيُنَهُمْ فَذُوقُوا عَذَابِي وَنُذُرِ
Yoruba
 
Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.

Ayah  54:38  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ صَبَّحَهُم بُكْرَةً عَذَابٌ مُّسْتَقِرٌّ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.

Ayah  54:39  الأية
    +/- -/+  
فَذُوقُوا عَذَابِي وَنُذُرِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.

Ayah  54:40  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur'ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

Ayah  54:41  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ جَاءَ آلَ فِرْعَوْنَ النُّذُرُ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.

Ayah  54:42  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا كُلِّهَا فَأَخَذْنَاهُمْ أَخْذَ عَزِيزٍ مُّقْتَدِرٍ
Yoruba
 
Wọ́n pe gbogbo àwọn āyah Wa ní irọ́ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (máa ń gbá ẹ̀dá mú).

Ayah  54:43  الأية
    +/- -/+  
أَكُفَّارُكُمْ خَيْرٌ مِّنْ أُولَٰئِكُمْ أَمْ لَكُم بَرَاءَةٌ فِي الزُّبُرِ
Yoruba
 
Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l'ó lóore ju àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?

Ayah  54:44  الأية
    +/- -/+  
أَمْ يَقُولُونَ نَحْنُ جَمِيعٌ مُّنتَصِرٌ
Yoruba
 
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Àwa wà papọ̀ tí a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)"

Ayah  54:45  الأية
    +/- -/+  
سَيُهْزَمُ الْجَمْعُ وَيُوَلُّونَ الدُّبُرَ
Yoruba
 
A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.

Ayah  54:46  الأية
    +/- -/+  
بَلِ السَّاعَةُ مَوْعِدُهُمْ وَالسَّاعَةُ أَدْهَىٰ وَأَمَرُّ
Yoruba
 
Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.

Ayah  54:47  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الْمُجْرِمِينَ فِي ضَلَالٍ وَسُعُرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.

Ayah  54:48  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَ يُسْحَبُونَ فِي النَّارِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمْ ذُوقُوا مَسَّ سَقَرَ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn bolẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.

Ayah  54:49  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا كُلَّ شَيْءٍ خَلَقْنَاهُ بِقَدَرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.

Ayah  54:50  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَمْرُنَا إِلَّا وَاحِدَةٌ كَلَمْحٍ بِالْبَصَرِ
Yoruba
 
Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.

Ayah  54:51  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا أَشْيَاعَكُمْ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?

Ayah  54:52  الأية
    +/- -/+  
وَكُلُّ شَيْءٍ فَعَلُوهُ فِي الزُّبُرِ
Yoruba
 
Gbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.

Ayah  54:53  الأية
    +/- -/+  
وَكُلُّ صَغِيرٍ وَكَبِيرٍ مُّسْتَطَرٌ
Yoruba
 
Àti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.

Ayah  54:54  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَنَهَرٍ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).

Ayah  54:55  الأية
    +/- -/+  
فِي مَقْعَدِ صِدْقٍ عِندَ مَلِيكٍ مُّقْتَدِرٍ
Yoruba
 
Ní ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us