Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti ṣe àwọn iṣẹ́ (aburú ọwọ́) wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, Nítorí náà, wọn yó sì máa pa rìdàrìdà.
Wọ́n fi àbòsí àti ìgbéraga takò ó, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú pé òdodo ni. Nítorí náà, wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ti rí.
A sì kó jọ fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú àlùjànnú, ènìyàn àti ẹyẹ. A sì ń kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ń bá a rìn káàkiri
Wọ́n sọ fún un pé: "Wọ inú ààfin." Nígbà tí ó rí i, ó ṣe bí ibúdò ni. Ó sì ká aṣọ kúrò ní ojúgun rẹ̀ méjèèjì. (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: "Dájúdájú ààfin tí a ṣe rigidin pẹ̀lú díńgí ni." (Bilƙīs) sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú mo ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Mo sì di mùsùlùmí pẹ̀lú (Ànábì) Sulaemọ̄n, fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá."
Rárá, ìmọ̀ wọn máa kẹ́sẹjá ní ọ̀run (orí wọn máa pé ní ọ̀run nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ (báyìí). Àní sẹ́, wọ́n fọ́jú nípa rẹ̀ ni.
Wọ́n kúkú tí ṣe àdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́."
Àti pé (rántí) ọjọ́ tí A óò kó ìjọ kan jọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan nínú àwọn tó ń pe àwọn āyah Wa ní irọ́. A ó sì kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn tí wọ́n máa tẹ̀lé ara wọn.
Títí (di) ìgbà tí wọ́n bá dé (tán), (Allāhu) yóò sọ pé: "Ṣé ẹ pe àwọn āyah Mi ní irọ́, tí ẹ̀yin kò sì ní ìmọ̀ kan nípa rẹ̀ (tí ẹ lè fi já a nírọ́)? Tàbí kí ni ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ (nílé ayé)?"
O sì máa rí àwọn àpáta, tí o lérò pé n̄ǹkan gbagidi tó dúró sojú kan náà ni, tí ó máa rin ìrìn ẹ̀ṣújò. (Ìyẹn jẹ́) iṣẹ́ Allāhu, Ẹni tí Ó ṣe gbogbo n̄ǹkan dáadáa. Dájúdájú Alámọ̀tán ni nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì dé pẹ̀lú iṣẹ́ aburú, A sì máa da ojú wọn bolẹ̀ nínú Iná. Ǹjẹ́ A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?
Ohun tí wọ́n pa mí ní àṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Olúwa Ìlú yìí, Ẹni tí Ó ṣe é ní àyè ọ̀wọ̀. TiRẹ̀ sì ni gbogbo n̄ǹkan. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí èmi wà nínú àwọn mùsùlùmí.