Prev  

96. Surah Al-'Alaq سورة العلق

  Next  



Ayah  96:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
اقْرَأْ بِاسْمِ رَبِّكَ الَّذِي خَلَقَ
Yoruba
 
Ké (al-Ƙur'ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

Ayah  96:2  الأية
    +/- -/+  
خَلَقَ الْإِنسَانَ مِنْ عَلَقٍ
Yoruba
 
Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

Ayah  96:3  الأية
    +/- -/+  
اقْرَأْ وَرَبُّكَ الْأَكْرَمُ
Yoruba
 
Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

Ayah  96:4  الأية
    +/- -/+  
الَّذِي عَلَّمَ بِالْقَلَمِ
Yoruba
 
Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

Ayah  96:5  الأية
    +/- -/+  
عَلَّمَ الْإِنسَانَ مَا لَمْ يَعْلَمْ
Yoruba
 
Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

Ayah  96:6  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا إِنَّ الْإِنسَانَ لَيَطْغَىٰ
Yoruba
 
Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

Ayah  96:7  الأية
    +/- -/+  

Ayah  96:8  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ الرُّجْعَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  96:9  الأية
    +/- -/+  

Ayah  96:10  الأية
    +/- -/+  
عَبْدًا إِذَا صَلَّىٰ
Yoruba
 
Fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

Ayah  96:11  الأية
    +/- -/+  
أَرَأَيْتَ إِن كَانَ عَلَى الْهُدَىٰ
Yoruba
 
Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà ('Islām)

Ayah  96:12  الأية
    +/- -/+  

Ayah  96:13  الأية
    +/- -/+  
أَرَأَيْتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ
Yoruba
 
Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

Ayah  96:14  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ يَعْلَم بِأَنَّ اللهَ يَرَىٰ
Yoruba
 
Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

Ayah  96:15  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا لَئِن لَّمْ يَنتَهِ لَنَسْفَعًا بِالنَّاصِيَةِ
Yoruba
 
Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);

Ayah  96:16  الأية
    +/- -/+  
نَاصِيَةٍ كَاذِبَةٍ خَاطِئَةٍ
Yoruba
 
Àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ayah  96:17  الأية
    +/- -/+  
فَلْيَدْعُ نَادِيَهُ
Yoruba
 
Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

Ayah  96:18  الأية
    +/- -/+  

Ayah  96:19  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا لَا تُطِعْهُ وَاسْجُدْ وَاقْتَرِب ۩
Yoruba
 
Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us