Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
Lẹ́yìn náà, A dá ìṣẹ́gun lórí wọn padà fún yín. A sì fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ ṣèrànwọ́ fún yín. A sì ṣe yín ní ìjọ tó pọ̀ jùlọ.
Tí ẹ bá ṣe rere, ẹ ṣe rere fún ẹ̀mí ara yín. Tí ẹ bá sì ṣe aburú, fún ẹ̀mí ara yín ni. Nígbà tí àdéhùn ìkẹ́yìn bá dé, (A óò gbé ọmọ ogun mìíràn dìde) nítorí kí wọ́n lè kó ìbànújẹ́ ba yín àti nítorí kí wọ́n lè wọ inú Mọ́sálásí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wọ̀ ọ́ nígbà àkọ́kọ́ àti nítorí kí wọ́n lè pa ohun tí (àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl) jọba lórí rẹ̀ run pátápátá.
A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (àwọn ọjọ́). Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́.
Ènìyàn kọ̀ọ̀kan, A ti so iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ọn lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀.
Nígbà tí A bá sì gbèrò láti pa ìlú kan run, A máa pa àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà láṣẹ (rere). Àmọ́ wọ́n máa ṣèbàjẹ́ sínú ìlú. Ọ̀rọ̀ náà yó sì kò lé wọn lórí. A ó sì pa wọ́n rẹ́ pátápátá.
Wo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ.
Dájúdájú A ti ṣe àlàyé sínú al- Ƙur'ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìṣítí. Síbẹ̀síbẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún ìrántí).
Sọ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni."
A fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Nígbà tí o bá sì dárúkọ Olúwa rẹ nìkan ṣoṣo nínú al-Ƙur'ān, wọ́n máa pẹ̀yìndà tí wọn yóò máa sá lọ.
Tàbí (kí ẹ di) ẹ̀dá kan nínú ohun tí ó tóbi nínú ọkàn yín." Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò wí pé: "Ta ni Ó máa dá wa padà (fún àjíǹde)?" Sọ pé: "Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá yín ní ìgbà àkọ́kọ́ ni." Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò mi orí wọn sí ọ (ní ti àbùkù). Nígbà náà, wọn yóò wí pé: "Ìgbà wo ni?" Sọ pé: "Ó lè jẹ́ pé ó ti súnmọ́."
Àti pé kò sí ohun tí ó dí Wa lọ́wọ́ láti fi àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) ránṣẹ́ bí kò ṣe pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti pè é nírọ́. A fún ìjọ Thamūd ní abo ràkúnmí; (àmì) tó fojú hàn kedere ni. Àmọ́ wọ́n ṣàbòsí sí i. A ò sì níí fi àwọn àmì ránṣẹ́ bí kò ṣe fún ìdẹ́rùbà.
Fi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Kí o sì ṣe àdéhùn fún wọn." Èṣù kò sì níí ṣe àdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn.
Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A dá.
Ní ọjọ́ tí A óò máa pe gbogbo ènìyàn pẹ̀lú aṣíwájú wọn. Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ìwé (iṣẹ́) rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò máa ka ìwé (iṣẹ́) wọn. A ò sì níí fi ìbójú kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn.
Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá ọ nípa n̄ǹkan tí A mú wá fún ọ ní ìmísí nítorí kí o lè hun n̄ǹkan mìíràn nípa Wa. Nígbà náà, wọn ìbá mú ọ ní ọ̀rẹ́ àyò.