Prev  

21. Surah Al-Anbiyâ' سورة الأنبياء

  Next  



Ayah  21:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
اقْتَرَبَ لِلنَّاسِ حِسَابُهُمْ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ مُّعْرِضُونَ
Yoruba
 
Ìṣírò-iṣẹ́ súnmọ́ fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì wà nínú ìfọ́núfọ́ra, tí wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo).

Ayah  21:2  الأية
    +/- -/+  
مَا يَأْتِيهِم مِّن ذِكْرٍ مِّن رَّبِّهِم مُّحْدَثٍ إِلَّا اسْتَمَعُوهُ وَهُمْ يَلْعَبُونَ
Yoruba
 
Kò sí ìrántí titun kan tí ó máa dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àfi kí wọ́n gbọ́ ọ lẹ́ni tí yóò máa (fi) ṣeré.

Ayah  21:3  الأية
    +/- -/+  
لَاهِيَةً قُلُوبُهُمْ ۗ وَأَسَرُّوا النَّجْوَى الَّذِينَ ظَلَمُوا هَلْ هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ ۖ أَفَتَأْتُونَ السِّحْرَ وَأَنتُمْ تُبْصِرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n fọ́núfọ́ra ni. Àwọn tó ṣàbòsí sì fi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (ààrin ara wọn) pamọ́ pé: "Ṣé èyí tayọ abara bí irú yín ni? Ṣé ẹ máa tẹ̀lé idán ni, nígbà tí ẹ̀yin náà ríran?"

Ayah  21:4  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّي يَعْلَمُ الْقَوْلَ فِي السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi mọ ọ̀rọ̀ tó ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀."

Ayah  21:5  الأية
    +/- -/+  
بَلْ قَالُوا أَضْغَاثُ أَحْلَامٍ بَلِ افْتَرَاهُ بَلْ هُوَ شَاعِرٌ فَلْيَأْتِنَا بِآيَةٍ كَمَا أُرْسِلَ الْأَوَّلُونَ
Yoruba
 
Rárá, wọ́n tún wí pé: "Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ ni (al-Ƙur'ān." Wọ́n tún wí pé): "Rárá, ó hun ún ni." (Wọ́n tún wí pé): "Rárá, eléwì ni. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) kí ó mú àmì kan wá fún wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi rán àwọn ẹni àkọ́kọ́."

Ayah  21:6  الأية
    +/- -/+  
مَا آمَنَتْ قَبْلَهُم مِّن قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا ۖ أَفَهُمْ يُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Kò sí àwọn tó gbàgbọ́ ṣíwájú wọn nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́ (lẹ́yìn ìsọ̀kalẹ̀ àmì). Ṣé àwọn sì máa gbàgbọ́ (nígbà tí àmì bá dé)?

Ayah  21:7  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَرْسَلْنَا قَبْلَكَ إِلَّا رِجَالًا نُّوحِي إِلَيْهِمْ ۖ فَاسْأَلُوا أَهْلَ الذِّكْرِ إِن كُنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.

Ayah  21:8  الأية
    +/- -/+  
وَمَا جَعَلْنَاهُمْ جَسَدًا لَّا يَأْكُلُونَ الطَّعَامَ وَمَا كَانُوا خَالِدِينَ
Yoruba
 
A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kì í jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé).

Ayah  21:9  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ صَدَقْنَاهُمُ الْوَعْدَ فَأَنجَيْنَاهُمْ وَمَن نَّشَاءُ وَأَهْلَكْنَا الْمُسْرِفِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A mú àdéhùn Wa ṣẹ fún wọn. A sì gba àwọn Òjíṣẹ́ àti àwọn tí A bá fẹ́ là. A sì pa àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà run.

Ayah  21:10  الأية
    +/- -/+  
لَقَدْ أَنزَلْنَا إِلَيْكُمْ كِتَابًا فِيهِ ذِكْرُكُمْ ۖ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú A ti sọ tírà kan kalẹ̀ fún yín, tí ìrántí nípa ọ̀rọ̀ ara yín wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?

Ayah  21:11  الأية
    +/- -/+  
وَكَمْ قَصَمْنَا مِن قَرْيَةٍ كَانَتْ ظَالِمَةً وَأَنشَأْنَا بَعْدَهَا قَوْمًا آخَرِينَ
Yoruba
 
Mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́, tí ó jẹ́ alábòsí! A sì gbé àwọn ìjọ mìíràn dìde lẹ́yìn wọn.

Ayah  21:12  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا أَحَسُّوا بَأْسَنَا إِذَا هُم مِّنْهَا يَرْكُضُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa (tó ń bọ̀), wọ́n sì ń sá lọ fún un.

Ayah  21:13  الأية
    +/- -/+  
لَا تَرْكُضُوا وَارْجِعُوا إِلَىٰ مَا أُتْرِفْتُمْ فِيهِ وَمَسَاكِنِكُمْ لَعَلَّكُمْ تُسْأَلُونَ
Yoruba
 
Ẹ má ṣe sá lọ. Ẹ padà síbi n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún yín àti àwọn ibùgbé yín nítorí kí A lè bi yín ní ìbéèrè.

Ayah  21:14  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا يَا وَيْلَنَا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí."

Ayah  21:15  الأية
    +/- -/+  
فَمَا زَالَت تِّلْكَ دَعْوَاهُمْ حَتَّىٰ جَعَلْنَاهُمْ حَصِيدًا خَامِدِينَ
Yoruba
 
Igbe wọn yìí kò dúró títí A fi sọ wọ́n di koríko tí wọ́n gé, wọ́n sì dòkú kalẹ̀.

Ayah  21:16  الأية
    +/- -/+  
وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاءَ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَاعِبِينَ
Yoruba
 
Àwa kò dá sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.

Ayah  21:17  الأية
    +/- -/+  
لَوْ أَرَدْنَا أَن نَّتَّخِذَ لَهْوًا لَّاتَّخَذْنَاهُ مِن لَّدُنَّا إِن كُنَّا فَاعِلِينَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé A gbèrò láti ṣèré ni, ọ̀dọ̀ Wa ni A kúkú tí máa ṣe é tí A bá jẹ́ olùṣe-(eré).

Ayah  21:18  الأية
    +/- -/+  
بَلْ نَقْذِفُ بِالْحَقِّ عَلَى الْبَاطِلِ فَيَدْمَغُهُ فَإِذَا هُوَ زَاهِقٌ ۚ وَلَكُمُ الْوَيْلُ مِمَّا تَصِفُونَ
Yoruba
 
Rárá o! À ń sọ òdodo lu irọ́ (mọ́lẹ̀ ni). Òdodo sì máa fọ́ agbárí irọ́. Irọ́ sì máa pòórá. Ègbé sì ni fún yín nípa ohun tí ẹ ń fi ròyìn (Rẹ̀ ní ti irọ́).

Ayah  21:19  الأية
    +/- -/+  
وَلَهُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَمَنْ عِندَهُ لَا يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِهِ وَلَا يَسْتَحْسِرُونَ
Yoruba
 
TiRẹ̀ ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé àwọn tó ń bẹ lọ́dọ̀ Rẹ̀, wọn kì í ṣègbéraga níbi ìjọ́sìn Rẹ̀. Kò sì rẹ̀ wọ́n.

Ayah  21:20  الأية
    +/- -/+  
يُسَبِّحُونَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ لَا يَفْتُرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ ní òru àti ní ọ̀sán; wọn kò sì sinmi.

Ayah  21:21  الأية
    +/- -/+  
أَمِ اتَّخَذُوا آلِهَةً مِّنَ الْأَرْضِ هُمْ يُنشِرُونَ
Yoruba
 
Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tí wọ́n mú jáde láti ara ilẹ̀, tí wọ́n ń jí òkú dìde ni?

Ayah  21:22  الأية
    +/- -/+  
لَوْ كَانَ فِيهِمَا آلِهَةٌ إِلَّا اللهُ لَفَسَدَتَا ۚ فَسُبْحَانَ اللهِ رَبِّ الْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).

Ayah  21:23  الأية
    +/- -/+  
لَا يُسْأَلُ عَمَّا يَفْعَلُ وَهُمْ يُسْأَلُونَ
Yoruba
 
Wọn kò níí bi (Allāhu) ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan tí Ó ń ṣe. Àwọn ni wọ́n máa bi ní ìbéèrè (nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn).

Ayah  21:24  الأية
    +/- -/+  
أَمِ اتَّخَذُوا مِن دُونِهِ آلِهَةً ۖ قُلْ هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ ۖ هَٰذَا ذِكْرُ مَن مَّعِيَ وَذِكْرُ مَن قَبْلِي ۗ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ الْحَقَّ ۖ فَهُم مُّعْرِضُونَ
Yoruba
 
Tàbí wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: "Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wa." (Al-Ƙur'ān) yìí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà pẹ̀lú mi àti ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣíwájú mi. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ òdodo; wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.

Ayah  21:25  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلَّا نُوحِي إِلَيْهِ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدُونِ
Yoruba
 
A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: "Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi."

Ayah  21:26  الأية
    +/- -/+  
وَقَالُوا اتَّخَذَ الرَّحْمَٰنُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۚ بَلْ عِبَادٌ مُّكْرَمُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Àjọkẹ́-ayé sọ ẹnì kan di ọmọ (nínú àwọn mọlāikah Rẹ̀)." Mímọ́ ni fún Un - Kò rí bẹ́ẹ̀; ẹrúsìn alápọ̀n-ọ́nlé ni wọ́n.

Ayah  21:27  الأية
    +/- -/+  
لَا يَسْبِقُونَهُ بِالْقَوْلِ وَهُم بِأَمْرِهِ يَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Wọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ ọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀.

Ayah  21:28  الأية
    +/- -/+  
يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يَشْفَعُونَ إِلَّا لِمَنِ ارْتَضَىٰ وَهُم مِّنْ خَشْيَتِهِ مُشْفِقُونَ
Yoruba
 
(Allāhu) mọ ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀.

Ayah  21:29  الأية
    +/- -/+  
وَمَن يَقُلْ مِنْهُمْ إِنِّي إِلَٰهٌ مِّن دُونِهِ فَذَٰلِكَ نَجْزِيهِ جَهَنَّمَ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Àti pé ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá wí pé: "Dájúdájú èmi ni ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀." Nítorí ìyẹn sì ni A óò fi san án ní ẹ̀san iná Jahanamọ. Báyẹn sì ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.

Ayah  21:30  الأية
    +/- -/+  
أَوَلَمْ يَرَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ كَانَتَا رَتْقًا فَفَتَقْنَاهُمَا ۖ وَجَعَلْنَا مِنَ الْمَاءِ كُلَّ شَيْءٍ حَيٍّ ۖ أَفَلَا يُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Ṣé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò wòye pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti inú omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni?

Ayah  21:31  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلْنَا فِي الْأَرْضِ رَوَاسِيَ أَن تَمِيدَ بِهِمْ وَجَعَلْنَا فِيهَا فِجَاجًا سُبُلًا لَّعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ
Yoruba
 
A sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. A sì fi àwọn ọ̀nà fífẹ̀ sáààrin àwọn àpáta nítorí kí wọ́n lè rí ọ̀nà tọ̀.

Ayah  21:32  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلْنَا السَّمَاءَ سَقْفًا مَّحْفُوظًا ۖ وَهُمْ عَنْ آيَاتِهَا مُعْرِضُونَ
Yoruba
 
A tún ṣe sánmọ̀ ní àjà tí wọ́n ń ṣọ́ (níbi jíjábọ́). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi àwọn àmì rẹ̀.

Ayah  21:33  الأية
    +/- -/+  
وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ
Yoruba
 
Òun ni Ẹni tí Ó dá òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òṣùpá. Ìkọ̀ọ̀kan (òòrùn àti òṣùpá) wà ní òpópónà roboto tó ń tọ̀.

Ayah  21:34  الأية
    +/- -/+  
وَمَا جَعَلْنَا لِبَشَرٍ مِّن قَبْلِكَ الْخُلْدَ ۖ أَفَإِن مِّتَّ فَهُمُ الْخَالِدُونَ
Yoruba
 
A kò ṣe bíbẹ gbére fún abara kan ṣíwájú rẹ. Ǹjẹ́ tí o bá kú, àwọn sì ni olùṣegbére bí?

Ayah  21:35  الأية
    +/- -/+  
كُلُّ نَفْسٍ ذَائِقَةُ الْمَوْتِ ۗ وَنَبْلُوكُم بِالشَّرِّ وَالْخَيْرِ فِتْنَةً ۖ وَإِلَيْنَا تُرْجَعُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A sì máa fi aburú àti rere ṣàdánwò fún yín. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.

Ayah  21:36  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا رَآكَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِن يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَٰذَا الَّذِي يَذْكُرُ آلِهَتَكُمْ وَهُم بِذِكْرِ الرَّحْمَٰنِ هُمْ كَافِرُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ bá rí ọ, wọn kò sì níí kà ọ́ kún kiní kan bí kò ṣe oníyẹ̀yẹ́ pé: "Ṣé èyí ni ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́hun yín?" Aláìgbàgbọ́ sì ni àwọn náà nípa ìrántí Àjọkẹ́-ayé.

Ayah  21:37  الأية
    +/- -/+  
خُلِقَ الْإِنسَانُ مِنْ عَجَلٍ ۚ سَأُرِيكُمْ آيَاتِي فَلَا تَسْتَعْجِلُونِ
Yoruba
 
Wọ́n fi ìkánjú sínú àdámọ́ ènìyàn. Mo máa fi àwọn àmì Mi hàn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe kán Mi lójú.

Ayah  21:38  الأية
    +/- -/+  
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Yoruba
 
Wọ́n ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?"

Ayah  21:39  الأية
    +/- -/+  
لَوْ يَعْلَمُ الَّذِينَ كَفَرُوا حِينَ لَا يَكُفُّونَ عَن وُجُوهِهِمُ النَّارَ وَلَا عَن ظُهُورِهِمْ وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mọ ìgbà tí wọn kò níí dá Iná dúró níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn, tí A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́, (wọn ìbá tí wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú).

Ayah  21:40  الأية
    +/- -/+  
بَلْ تَأْتِيهِم بَغْتَةً فَتَبْهَتُهُمْ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ رَدَّهَا وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ
Yoruba
 
Ṣùgbọ́n (ìyà Iná) yóò bá wọn ní òjijì, nígbà náà ó máa kó ìdààmú bá wọn; wọn kò sì níí lè dá a padà. A kò sì níí sún (ìyà náà) síwájú fún wọn.

Ayah  21:41  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدِ اسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِّن قَبْلِكَ فَحَاقَ بِالَّذِينَ سَخِرُوا مِنْهُم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Yoruba
 
Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí àwọn tó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.

Ayah  21:42  الأية
    +/- -/+  
قُلْ مَن يَكْلَؤُكُم بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ مِنَ الرَّحْمَٰنِ ۗ بَلْ هُمْ عَن ذِكْرِ رَبِّهِم مُّعْرِضُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ta ni ẹni tí ó ń ṣọ yín ní òru àti ní ọ̀sán níbi ìyà Àjọkẹ́-ayé?" Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọkẹ́-ayé.

Ayah  21:43  الأية
    +/- -/+  
أَمْ لَهُمْ آلِهَةٌ تَمْنَعُهُم مِّن دُونِنَا ۚ لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَ أَنفُسِهِمْ وَلَا هُم مِّنَّا يُصْحَبُونَ
Yoruba
 
Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn Wa ni? Wọn kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Wọn kò sì lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́dọ̀ Wa.

Ayah  21:44  الأية
    +/- -/+  
بَلْ مَتَّعْنَا هَٰؤُلَاءِ وَآبَاءَهُمْ حَتَّىٰ طَالَ عَلَيْهِمُ الْعُمُرُ ۗ أَفَلَا يَرَوْنَ أَنَّا نَأْتِي الْأَرْضَ نَنقُصُهَا مِنْ أَطْرَافِهَا ۚ أَفَهُمُ الْغَالِبُونَ
Yoruba
 
Síbẹ̀síbẹ̀ A fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn títí ìṣẹ̀mí ayé wọn fi gùn. Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l'À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọnú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn). Nítorí náà, ṣé àwọn ni wọ́n máa borí ni?

Ayah  21:45  الأية
    +/- -/+  
قُلْ إِنَّمَا أُنذِرُكُم بِالْوَحْيِ ۚ وَلَا يَسْمَعُ الصُّمُّ الدُّعَاءَ إِذَا مَا يُنذَرُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ìmísí ni mo fi ń kìlọ̀ fún yín. Àwọn adití kò sì níí gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fún wọn."

Ayah  21:46  الأية
    +/- -/+  
وَلَئِن مَّسَّتْهُمْ نَفْحَةٌ مِّنْ عَذَابِ رَبِّكَ لَيَقُولُنَّ يَا وَيْلَنَا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú tí abala kan nínú ìyà Olúwa rẹ bá fọwọ́ bà wọ́n, dájúdájú wọ́n á wí pé: "Ègbé wa ò; dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí."

Ayah  21:47  الأية
    +/- -/+  
وَنَضَعُ الْمَوَازِينَ الْقِسْطَ لِيَوْمِ الْقِيَامَةِ فَلَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا ۖ وَإِن كَانَ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِّنْ خَرْدَلٍ أَتَيْنَا بِهَا ۗ وَكَفَىٰ بِنَا حَاسِبِينَ
Yoruba
 
A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò.

Ayah  21:48  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَىٰ وَهَارُونَ الْفُرْقَانَ وَضِيَاءً وَذِكْرًا لِّلْمُتَّقِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  21:49  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِالْغَيْبِ وَهُم مِّنَ السَّاعَةِ مُشْفِقُونَ
Yoruba
 
(Àwọn ni) àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀. Olùpáyà sì ni wọ́n nípa Àkókò náà.

Ayah  21:50  الأية
    +/- -/+  
وَهَٰذَا ذِكْرٌ مُّبَارَكٌ أَنزَلْنَاهُ ۚ أَفَأَنتُمْ لَهُ مُنكِرُونَ
Yoruba
 
Èyí sì ni ìrántí oníbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Ṣé ẹ̀yin yóò takò ó ni?

Ayah  21:51  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ آتَيْنَا إِبْرَاهِيمَ رُشْدَهُ مِن قَبْلُ وَكُنَّا بِهِ عَالِمِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm ní ìmọ̀nà tirẹ̀ ṣíwájú (kí ó tó dàgbà). Àwa sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.

Ayah  21:52  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا هَٰذِهِ التَّمَاثِيلُ الَّتِي أَنتُمْ لَهَا عَاكِفُونَ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ pé: "Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì, tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ṣe jẹ́ ná?"

Ayah  21:53  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا وَجَدْنَا آبَاءَنَا لَهَا عَابِدِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni."

Ayah  21:54  الأية
    +/- -/+  
قَالَ لَقَدْ كُنتُمْ أَنتُمْ وَآبَاؤُكُمْ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Dájúdájú ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé."

Ayah  21:55  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا أَجِئْتَنَا بِالْحَقِّ أَمْ أَنتَ مِنَ اللَّاعِبِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣé o mú òdodo wá fún wa ni tàbí ìwọ wà nínú àwọn ẹlẹ́fẹ̀."

Ayah  21:56  الأية
    +/- -/+  
قَالَ بَل رَّبُّكُمْ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ الَّذِي فَطَرَهُنَّ وَأَنَا عَلَىٰ ذَٰلِكُم مِّنَ الشَّاهِدِينَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Rárá. Olúwa yin ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; Ẹni tí Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èmi sì wà nínú àwọn ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.

Ayah  21:57  الأية
    +/- -/+  
وَتَاللهِ لَأَكِيدَنَّ أَصْنَامَكُم بَعْدَ أَن تُوَلُّوا مُدْبِرِينَ
Yoruba
 
Àti pé mo fi Allāhu búra, dájúdájú mo máa dète sí àwọn òrìṣà yín lẹ́yìn tí ẹ bá pẹ̀yìn dà, tí ẹ lọ."

Ayah  21:58  الأية
    +/- -/+  
فَجَعَلَهُمْ جُذَاذًا إِلَّا كَبِيرًا لَّهُمْ لَعَلَّهُمْ إِلَيْهِ يَرْجِعُونَ
Yoruba
 
Ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ àfi àgbà (òrìṣà) wọn nítorí kí wọ́n lè padà dé bá a.

Ayah  21:59  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا مَن فَعَلَ هَٰذَا بِآلِهَتِنَا إِنَّهُ لَمِنَ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ta ni ó ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa? Dájúdájú onítọ̀un wà nínú àwọn alábòsí."

Ayah  21:60  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا سَمِعْنَا فَتًى يَذْكُرُهُمْ يُقَالُ لَهُ إِبْرَاهِيمُ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "A gbọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n. Wọ́n ń pe (ọmọ náà) ní 'Ibrọ̄hīm."

Ayah  21:61  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا فَأْتُوا بِهِ عَلَىٰ أَعْيُنِ النَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَشْهَدُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ẹ mú un wá han àwọn ènìyàn kí wọ́n lè jẹ́rìí lé e lórí."

Ayah  21:62  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا أَأَنتَ فَعَلْتَ هَٰذَا بِآلِهَتِنَا يَا إِبْرَاهِيمُ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣé ìwọ lo ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa, 'Ibrọ̄hīm?"

Ayah  21:63  الأية
    +/- -/+  
قَالَ بَلْ فَعَلَهُ كَبِيرُهُمْ هَٰذَا فَاسْأَلُوهُمْ إِن كَانُوا يَنطِقُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Rárá o, àgbà wọn yìí ló ṣe (wọ́n bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, ẹ bi wọ́n léèrè wò tí wọ́n bá máa ń sọ̀rọ̀."

Ayah  21:64  الأية
    +/- -/+  
فَرَجَعُوا إِلَىٰ أَنفُسِهِمْ فَقَالُوا إِنَّكُمْ أَنتُمُ الظَّالِمُونَ
Yoruba
 
Nígbà náà, wọ́n yíjú síra wọn, wọ́n sì wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin ni alábòsí."

Ayah  21:65  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ نُكِسُوا عَلَىٰ رُءُوسِهِمْ لَقَدْ عَلِمْتَ مَا هَٰؤُلَاءِ يَنطِقُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, wọ́n sorí kọ́ (wọ́n sì wí pé): "Ìwọ náà kúkú mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí kì í sọ̀rọ̀."

Ayah  21:66  الأية
    +/- -/+  
قَالَ أَفَتَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ مَا لَا يَنفَعُكُمْ شَيْئًا وَلَا يَضُرُّكُمْ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira ba yín lẹ́yìn Allāhu?

Ayah  21:67  الأية
    +/- -/+  
أُفٍّ لَّكُمْ وَلِمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ ۖ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Yoruba
 
Ṣíọ̀ ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, ṣé ẹ̀yin kò níí ṣe làákàyè ni?"

Ayah  21:68  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا حَرِّقُوهُ وَانصُرُوا آلِهَتَكُمْ إِن كُنتُمْ فَاعِلِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ẹ dáná sun ún; kí ẹ sì ran àwọn ọlọ́hun yín lọ́wọ́, tí ẹ̀yin bá níkan-án ṣe."

Ayah  21:69  الأية
    +/- -/+  
قُلْنَا يَا نَارُ كُونِي بَرْدًا وَسَلَامًا عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ
Yoruba
 
A sọ pé: "Iná, di tútù àti àlàáfíà lára 'Ibrọ̄hīm."

Ayah  21:70  الأية
    +/- -/+  
وَأَرَادُوا بِهِ كَيْدًا فَجَعَلْنَاهُمُ الْأَخْسَرِينَ
Yoruba
 
Wọ́n gbèrò ète sí i, ṣùgbọ́n A ṣe wọ́n ní olófò jùlọ.

Ayah  21:71  الأية
    +/- -/+  
وَنَجَّيْنَاهُ وَلُوطًا إِلَى الْأَرْضِ الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا لِلْعَالَمِينَ
Yoruba
 
A sì gba òun àti Lūt là sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí fún gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  21:72  الأية
    +/- -/+  
وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ نَافِلَةً ۖ وَكُلًّا جَعَلْنَا صَالِحِينَ
Yoruba
 
A ta á ní ọrẹ ọmọ, 'Is-hāƙ àti Ya‘ƙūb tí ó jẹ́ àlékún (ìyẹn, ọmọọmọ). Olúkùlùkù (wọn) ni A ṣe ní ẹni rere.

Ayah  21:73  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلْنَاهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا وَأَوْحَيْنَا إِلَيْهِمْ فِعْلَ الْخَيْرَاتِ وَإِقَامَ الصَّلَاةِ وَإِيتَاءَ الزَّكَاةِ ۖ وَكَانُوا لَنَا عَابِدِينَ
Yoruba
 
A ṣe wọ́n ní aṣíwájú tó ń tọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Wọ́n sì jẹ́ olùjọ́sìn fún Wa.

Ayah  21:74  الأية
    +/- -/+  
وَلُوطًا آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا وَنَجَّيْنَاهُ مِنَ الْقَرْيَةِ الَّتِي كَانَت تَّعْمَلُ الْخَبَائِثَ ۗ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمَ سَوْءٍ فَاسِقِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí Ànábì) Lūt. A fún un ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì gbà á là nínú ìlú tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú, òbìlẹ̀jẹ́.

Ayah  21:75  الأية
    +/- -/+  
وَأَدْخَلْنَاهُ فِي رَحْمَتِنَا ۖ إِنَّهُ مِنَ الصَّالِحِينَ
Yoruba
 
A sì mú un wọ inú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹni rere.

Ayah  21:76  الأية
    +/- -/+  
وَنُوحًا إِذْ نَادَىٰ مِن قَبْلُ فَاسْتَجَبْنَا لَهُ فَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
(Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú. A sì jẹ́pè rẹ̀. A sì gba òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ìbànújẹ́ ńlá.

Ayah  21:77  الأية
    +/- -/+  
وَنَصَرْنَاهُ مِنَ الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمَ سَوْءٍ فَأَغْرَقْنَاهُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
A sì ṣàrànṣe fún un lórí àwọn ènìyàn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú. A sì tẹ̀ wọ́n rì pátápátá.

Ayah  21:78  الأية
    +/- -/+  
وَدَاوُودَ وَسُلَيْمَانَ إِذْ يَحْكُمَانِ فِي الْحَرْثِ إِذْ نَفَشَتْ فِيهِ غَنَمُ الْقَوْمِ وَكُنَّا لِحُكْمِهِمْ شَاهِدِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n, (rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ń ṣe ìdájọ́ lórí (ọ̀rọ̀) oko, nígbà tí àgùtàn ìjọ kan jẹko wọ inú oko náà. Àwa sì jẹ́ Olùjẹ́rìí sí ìdájọ́ wọn.

Ayah  21:79  الأية
    +/- -/+  
فَفَهَّمْنَاهَا سُلَيْمَانَ ۚ وَكُلًّا آتَيْنَا حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَسَخَّرْنَا مَعَ دَاوُودَ الْجِبَالَ يُسَبِّحْنَ وَالطَّيْرَ ۚ وَكُنَّا فَاعِلِينَ
Yoruba
 
A sì fún (Ànábì) Sulaemọ̄n ní àgbọ́yé rẹ̀. Àti pé ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ni A fún ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì tẹ àwọn àpáta àti ẹyẹ ba; wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) pẹ̀lú (Ànábì) Dāwūd. Àwa l'A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀.

Ayah  21:80  الأية
    +/- -/+  
وَعَلَّمْنَاهُ صَنْعَةَ لَبُوسٍ لَّكُمْ لِتُحْصِنَكُم مِّن بَأْسِكُمْ ۖ فَهَلْ أَنتُمْ شَاكِرُونَ
Yoruba
 
A tún fún un ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀wù irin fún yín nítorí kí ó lè jẹ́ odi ìṣọ́ fún yín níbi ogun yín. Nítorí náà, ǹjẹ́ olùdúpẹ́ (fún Allāhu) ni ẹ̀yin bí?

Ayah  21:81  الأية
    +/- -/+  
وَلِسُلَيْمَانَ الرِّيحَ عَاصِفَةً تَجْرِي بِأَمْرِهِ إِلَى الْأَرْضِ الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا ۚ وَكُنَّا بِكُلِّ شَيْءٍ عَالِمِينَ
Yoruba
 
A sì tẹ atẹ́gùn líle lórí ba fún (Ànábì) Sulaemọ̄n. Ó ń gbé e lọ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí. A sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  21:82  الأية
    +/- -/+  
وَمِنَ الشَّيَاطِينِ مَن يَغُوصُونَ لَهُ وَيَعْمَلُونَ عَمَلًا دُونَ ذَٰلِكَ ۖ وَكُنَّا لَهُمْ حَافِظِينَ
Yoruba
 
Nínú àwọn èṣù, àwọn tó ń wa kùsà òkun tún wà fún un. Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwa sì ń jẹ́ Olùṣọ́ fún wọn.

Ayah  21:83  الأية
    +/- -/+  
وَأَيُّوبَ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ أَنِّي مَسَّنِيَ الضُّرُّ وَأَنتَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí Ànábì) 'Ayyūb, nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú ọwọ́ ìnira ti kàn mí. Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú."

Ayah  21:84  الأية
    +/- -/+  
فَاسْتَجَبْنَا لَهُ فَكَشَفْنَا مَا بِهِ مِن ضُرٍّ ۖ وَآتَيْنَاهُ أَهْلَهُ وَمِثْلَهُم مَّعَهُمْ رَحْمَةً مِّنْ عِندِنَا وَذِكْرَىٰ لِلْعَابِدِينَ
Yoruba
 
A sì jẹ́pè rẹ̀. A mú gbogbo ìnira rẹ̀ kúrò fún un. A tún fún un ní àwọn ẹbí rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn; (ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn olùjọ́sìn (fún Wa).

Ayah  21:85  الأية
    +/- -/+  
وَإِسْمَاعِيلَ وَإِدْرِيسَ وَذَا الْكِفْلِ ۖ كُلٌّ مِّنَ الصَّابِرِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí Ànábì) 'Ismọ̄‘īl àti (Ànábì) 'Idrīs àti (Ànábì) Thul-Kifl; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) wà nínú àwọn onísùúrù.

Ayah  21:86  الأية
    +/- -/+  
وَأَدْخَلْنَاهُمْ فِي رَحْمَتِنَا ۖ إِنَّهُم مِّنَ الصَّالِحِينَ
Yoruba
 
A sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni rere.

Ayah  21:87  الأية
    +/- -/+  
وَذَا النُّونِ إِذ ذَّهَبَ مُغَاضِبًا فَظَنَّ أَن لَّن نَّقْدِرَ عَلَيْهِ فَنَادَىٰ فِي الظُّلُمَاتِ أَن لَّا إِلَٰهَ إِلَّا أَنتَ سُبْحَانَكَ إِنِّي كُنتُ مِنَ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi wà nínú àwọn alábòsí."

Ayah  21:88  الأية
    +/- -/+  
فَاسْتَجَبْنَا لَهُ وَنَجَّيْنَاهُ مِنَ الْغَمِّ ۚ وَكَذَٰلِكَ نُنجِي الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
A jẹ́pè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.

Ayah  21:89  الأية
    +/- -/+  
وَزَكَرِيَّا إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ رَبِّ لَا تَذَرْنِي فَرْدًا وَأَنتَ خَيْرُ الْوَارِثِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí Ànábì) Zakariyyā nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Olúwa mi, má fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan (tí kò níí bímọ). Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùjogún."

Ayah  21:90  الأية
    +/- -/+  
فَاسْتَجَبْنَا لَهُ وَوَهَبْنَا لَهُ يَحْيَىٰ وَأَصْلَحْنَا لَهُ زَوْجَهُ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَيَدْعُونَنَا رَغَبًا وَرَهَبًا ۖ وَكَانُوا لَنَا خَاشِعِينَ
Yoruba
 
A jẹ́pè rẹ̀. A sì ta á lọ́rẹ ọmọ, (Ànábì) Yahyā. A sì ṣe àtúnṣe ìyàwó rẹ̀ fún un. Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa.

Ayah  21:91  الأية
    +/- -/+  
وَالَّتِي أَحْصَنَتْ فَرْجَهَا فَنَفَخْنَا فِيهَا مِن رُّوحِنَا وَجَعَلْنَاهَا وَابْنَهَا آيَةً لِّلْعَالَمِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  21:92  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ هَٰذِهِ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَأَنَا رَبُّكُمْ فَاعْبُدُونِ
Yoruba
 
Dájúdájú ('Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.

Ayah  21:93  الأية
    +/- -/+  
وَتَقَطَّعُوا أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ ۖ كُلٌّ إِلَيْنَا رَاجِعُونَ
Yoruba
 
(Àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄), wọ́n sì dá ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn) wọn sí kélekèle láààrin ara wọn; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) sì máa padà sí ọ̀dọ̀ Wa.

Ayah  21:94  الأية
    +/- -/+  
فَمَن يَعْمَلْ مِنَ الصَّالِحَاتِ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَا كُفْرَانَ لِسَعْيِهِ وَإِنَّا لَهُ كَاتِبُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kò sí kíkọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀. Àti pé dájúdájú Àwa máa ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún un.

Ayah  21:95  الأية
    +/- -/+  
وَحَرَامٌ عَلَىٰ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا أَنَّهُمْ لَا يَرْجِعُونَ
Yoruba
 
Èèwọ̀ ni fún ará ìlú kan tí A ti parẹ́ (pé kí ó tún padà sí ayé); dájúdájú wọn kò níí padà mọ́ (sí ilé ayé).

Ayah  21:96  الأية
    +/- -/+  
حَتَّىٰ إِذَا فُتِحَتْ يَأْجُوجُ وَمَأْجُوجُ وَهُم مِّن كُلِّ حَدَبٍ يَنسِلُونَ
Yoruba
 
(Wọn yóò wà nínú barsaku) títí A óò fi ṣí àwọn Ya'jūj àti Ma'jūj sílẹ̀. Àwọn (wọ̀nyí) yó sì máa sáré jáde láti inú gbogbo àyè gíga.

Ayah  21:97  الأية
    +/- -/+  
وَاقْتَرَبَ الْوَعْدُ الْحَقُّ فَإِذَا هِيَ شَاخِصَةٌ أَبْصَارُ الَّذِينَ كَفَرُوا يَا وَيْلَنَا قَدْ كُنَّا فِي غَفْلَةٍ مِّنْ هَٰذَا بَلْ كُنَّا ظَالِمِينَ
Yoruba
 
Àdéhùn òdodo náà súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò máa ranjú kalẹ̀ ràngàndàn, (wọ́n yó sì wí pé): "Ègbé ni fún wa! Dájúdájú àwa ti wà nínú ìgbàgbéra nípa èyí. Rárá, àwa jẹ́ alábòsí ni."

Ayah  21:98  الأية
    +/- -/+  
إِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ حَصَبُ جَهَنَّمَ أَنتُمْ لَهَا وَارِدُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni ìkoná Jahanamọ; ẹ̀yin yó sì wọ inú rẹ̀.

Ayah  21:99  الأية
    +/- -/+  
لَوْ كَانَ هَٰؤُلَاءِ آلِهَةً مَّا وَرَدُوهَا ۖ وَكُلٌّ فِيهَا خَالِدُونَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ni ọlọ́hun ni, wọn ìbá tí wọ inú Iná. Olùṣegbére sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú rẹ̀.

Ayah  21:100  الأية
    +/- -/+  
لَهُمْ فِيهَا زَفِيرٌ وَهُمْ فِيهَا لَا يَسْمَعُونَ
Yoruba
 
Iná yóò máa kùn yùn-ùn sí wọn létí; wọn kò sì níí gbọ́ (ọ̀rọ̀ mìíràn).

Ayah  21:101  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الَّذِينَ سَبَقَتْ لَهُم مِّنَّا الْحُسْنَىٰ أُولَٰئِكَ عَنْهَا مُبْعَدُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tí rere ti ṣíwájú fún láti ọ̀dọ̀ Wa, àwọn wọ̀nyẹn ni A óò gbé jìnnà sí Iná.

Ayah  21:102  الأية
    +/- -/+  
لَا يَسْمَعُونَ حَسِيسَهَا ۖ وَهُمْ فِي مَا اشْتَهَتْ أَنفُسُهُمْ خَالِدُونَ
Yoruba
 
Wọn kò sì níí gbọ́ kíkùn rẹ̀. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú ìgbádùn tí ẹ̀mí wọn ń fẹ́.

Ayah  21:103  الأية
    +/- -/+  
لَا يَحْزُنُهُمُ الْفَزَعُ الْأَكْبَرُ وَتَتَلَقَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ هَٰذَا يَوْمُكُمُ الَّذِي كُنتُمْ تُوعَدُونَ
Yoruba
 
Ìpáyà tó tóbi jùlọ kò níí bà wọ́n nínú jẹ́. Àwọn mọlāika yóò máa pàdé wọn, (wọn yóò sọ pé): "Èyí ni ọjọ́ yín tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín."

Ayah  21:104  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَ نَطْوِي السَّمَاءَ كَطَيِّ السِّجِلِّ لِلْكُتُبِ ۚ كَمَا بَدَأْنَا أَوَّلَ خَلْقٍ نُّعِيدُهُ ۚ وَعْدًا عَلَيْنَا ۚ إِنَّا كُنَّا فَاعِلِينَ
Yoruba
 
(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bíi kíká ewé tírà. Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Ayah  21:105  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ كَتَبْنَا فِي الزَّبُورِ مِن بَعْدِ الذِّكْرِ أَنَّ الْأَرْضَ يَرِثُهَا عِبَادِيَ الصَّالِحُونَ
Yoruba
 
Àti pé A ti kọ ọ́ sínú àwọn ìpín-ìpín Tírà (tí A sọ̀kalẹ̀) lẹ́yìn (èyí tí ó wà nínú) Tírà Ìpìlẹ̀ (ìyẹn, Laohul- Mahfūṭḥ) pé dájúdájú ilẹ̀ (ìyẹn ilẹ̀ Ọgbà Ìdẹ̀ra), àwọn ẹrúsìn Mi, àwọn ẹni rere, ni wọn yóò jogún rẹ̀.

Ayah  21:106  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي هَٰذَا لَبَلَاغًا لِّقَوْمٍ عَابِدِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ohun tí ó máa tó ẹ̀dá (nípa ọ̀rọ̀ ayé àti ọ̀rọ̀ ọ̀run) wà nínú (al-Ƙur'ān) yìí fún ìjọ tó ń jọ́sìn (fún Allāhu ní ọ̀nà òdodo).

Ayah  21:107  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَالَمِينَ
Yoruba
 
A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  21:108  الأية
    +/- -/+  
قُلْ إِنَّمَا يُوحَىٰ إِلَيَّ أَنَّمَا إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ فَهَلْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ohun tí Wọ́n ń fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí ni pé, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin máa di mùsùlùmí?"

Ayah  21:109  الأية
    +/- -/+  
فَإِن تَوَلَّوْا فَقُلْ آذَنتُكُمْ عَلَىٰ سَوَاءٍ ۖ وَإِنْ أَدْرِي أَقَرِيبٌ أَم بَعِيدٌ مَّا تُوعَدُونَ
Yoruba
 
Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ nígbà náà pé: "Èmi ń fi to yín létí pé èmi àti ẹ̀yin dìjọ dá dúró fún ogun ẹ̀sìn (tí ó máa ṣẹlẹ̀ láààrin wa báyìí). Èmi kò sì mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín ti súnmọ́ tàbí ó sì jìnnà.

Ayah  21:110  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ يَعْلَمُ الْجَهْرَ مِنَ الْقَوْلِ وَيَعْلَمُ مَا تَكْتُمُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú (Allāhu) mọ ohun tí ó hàn nínú ọ̀rọ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.

Ayah  21:111  الأية
    +/- -/+  
وَإِنْ أَدْرِي لَعَلَّهُ فِتْنَةٌ لَّكُمْ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ
Yoruba
 
Èmi kò sì mọ̀ bóyá (lílọ́ yín lára) máa jẹ́ àdánwò àti ìgbádùn fún yín títí di ìgbà díẹ̀."

Ayah  21:112  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّ احْكُم بِالْحَقِّ ۗ وَرَبُّنَا الرَّحْمَٰنُ الْمُسْتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi, ṣèdájọ́ pẹ̀lú òdodo. Olúwa wa ni Àjọkẹ́-ayé, Ẹni tí à ń wá àánú Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń fi ròyìn (Rẹ̀)."
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us