Prev  

23. Surah Al-Mu'minûn سورة المؤمنون

  Next  



Ayah  23:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
قَدْ أَفْلَحَ الْمُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè.

Ayah  23:2  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ هُمْ فِي صَلَاتِهِمْ خَاشِعُونَ
Yoruba
 
Àwọn tó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn,

Ayah  23:3  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ هُمْ عَنِ اللَّغْوِ مُعْرِضُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ,

Ayah  23:4  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ هُمْ لِلزَّكَاةِ فَاعِلُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tó ń ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí àti ara) wọn.

Ayah  23:5  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ هُمْ لِفُرُوجِهِمْ حَافِظُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,

Ayah  23:6  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِينَ
Yoruba
 
Àfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn),

Ayah  23:7  الأية
    +/- -/+  
فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà,

Ayah  23:8  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ هُمْ لِأَمَانَاتِهِمْ وَعَهْدِهِمْ رَاعُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn,

Ayah  23:9  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَوَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tó ń ṣọ́ ìrun wọn;

Ayah  23:10  الأية
    +/- -/+  

Ayah  23:11  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ يَرِثُونَ الْفِرْدَوْسَ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Yoruba
 
Àwọn tó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

Ayah  23:12  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ مِن سُلَالَةٍ مِّن طِينٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú ẹrẹ̀.

Ayah  23:13  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ جَعَلْنَاهُ نُطْفَةً فِي قَرَارٍ مَّكِينٍ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ìrọ̀rùn kan (ìyẹn, ilé-ọmọ).

Ayah  23:14  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ خَلَقْنَا النُّطْفَةَ عَلَقَةً فَخَلَقْنَا الْعَلَقَةَ مُضْغَةً فَخَلَقْنَا الْمُضْغَةَ عِظَامًا فَكَسَوْنَا الْعِظَامَ لَحْمًا ثُمَّ أَنشَأْنَاهُ خَلْقًا آخَرَ ۚ فَتَبَارَكَ اللهُ أَحْسَنُ الْخَالِقِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn. Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).

Ayah  23:15  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ إِنَّكُم بَعْدَ ذَٰلِكَ لَمَيِّتُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yóò di òkú.

Ayah  23:16  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ تُبْعَثُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde wọ́n máa gbe yín dìde.

Ayah  23:17  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ خَلَقْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعَ طَرَائِقَ وَمَا كُنَّا عَنِ الْخَلْقِ غَافِلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá.

Ayah  23:18  الأية
    +/- -/+  
وَأَنزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً بِقَدَرٍ فَأَسْكَنَّاهُ فِي الْأَرْضِ ۖ وَإِنَّا عَلَىٰ ذَهَابٍ بِهِ لَقَادِرُونَ
Yoruba
 
À ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n níwọ̀n. Lẹ́yìn náà, À ń mú un dúró sínú ilẹ̀. Dájúdájú Àwa kúkú lágbára láti mú un lọ.

Ayah  23:19  الأية
    +/- -/+  
فَأَنشَأْنَا لَكُم بِهِ جَنَّاتٍ مِّن نَّخِيلٍ وَأَعْنَابٍ لَّكُمْ فِيهَا فَوَاكِهُ كَثِيرَةٌ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A fi dá àwọn ọgbà oko dàbínù àti àjàrà fún yín; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso wà nínú rẹ̀ fún yín, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.

Ayah  23:20  الأية
    +/- -/+  
وَشَجَرَةً تَخْرُجُ مِن طُورِ سَيْنَاءَ تَنبُتُ بِالدُّهْنِ وَصِبْغٍ لِّلْآكِلِينَ
Yoruba
 
Àti igi kan tó ń hù jáde níbi àpáta Sīnā'; ó ń mú epo àti n̄ǹkan ìṣebẹ̀ jáde fún àwọn tó ń jẹ ẹ́.

Ayah  23:21  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ لَكُمْ فِي الْأَنْعَامِ لَعِبْرَةً ۖ نُّسْقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهَا وَلَكُمْ فِيهَا مَنَافِعُ كَثِيرَةٌ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn; À ń fún yín mu nínú ohun tí ó wà nínú ikùn wọn. Àwọn àǹfààní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (mìíràn) tún wà fún yín lára wọn, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.

Ayah  23:22  الأية
    +/- -/+  
وَعَلَيْهَا وَعَلَى الْفُلْكِ تُحْمَلُونَ
Yoruba
 
Ẹ sì ń kó ẹrù sí orí àwọn ẹran ọ̀sìn àti ọkọ̀ ojú-omi.

Ayah  23:23  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ أَفَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?"

Ayah  23:24  الأية
    +/- -/+  
فَقَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن قَوْمِهِ مَا هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يُرِيدُ أَن يَتَفَضَّلَ عَلَيْكُمْ وَلَوْ شَاءَ اللهُ لَأَنزَلَ مَلَائِكَةً مَّا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي آبَائِنَا الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Àwọn olórí tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín, tí ó fẹ́ gbé àjùlọ fún ara rẹ̀ lórí yín. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ránṣẹ́ sí wa ni), ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ ni. A kò sì gbọ́ èyí rí lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.

Ayah  23:25  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ بِهِ جِنَّةٌ فَتَرَبَّصُوا بِهِ حَتَّىٰ حِينٍ
Yoruba
 
Kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí (ìkángun) rẹ̀ títí di ìgbà kan ná."

Ayah  23:26  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّ انصُرْنِي بِمَا كَذَّبُونِ
Yoruba
 
(Ànábì) Nūh sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́."

Ayah  23:27  الأية
    +/- -/+  
فَأَوْحَيْنَا إِلَيْهِ أَنِ اصْنَعِ الْفُلْكَ بِأَعْيُنِنَا وَوَحْيِنَا فَإِذَا جَاءَ أَمْرُنَا وَفَارَ التَّنُّورُ ۙ فَاسْلُكْ فِيهَا مِن كُلٍّ زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ وَأَهْلَكَ إِلَّا مَن سَبَقَ عَلَيْهِ الْقَوْلُ مِنْهُمْ ۖ وَلَا تُخَاطِبْنِي فِي الَّذِينَ ظَلَمُوا ۖ إِنَّهُم مُّغْرَقُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: "Ṣe ọkọ̀ ojú-omi ní ojú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Nígbà tí àṣẹ Wa bá dé, tí omi bá ṣẹ́ yọ ní ojú àrò, nígbà náà ni kí o kó sínú ọkọ̀ ojú-omi gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ, àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí nínú wọn (fún ìparun). Má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí; dájúdájú A óò tẹ̀ wọ́n rì sínú omi ni.

Ayah  23:28  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا اسْتَوَيْتَ أَنتَ وَمَن مَّعَكَ عَلَى الْفُلْكِ فَقُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي نَجَّانَا مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí o bá jókòó sínú ọkọ̀ ojú-omi náà, ìwọ àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ, sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó gbà wá là lọ́wọ́ ijọ alábòsí."

Ayah  23:29  الأية
    +/- -/+  
وَقُل رَّبِّ أَنزِلْنِي مُنزَلًا مُّبَارَكًا وَأَنتَ خَيْرُ الْمُنزِلِينَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Olúwa mi, sọ̀ mí kalẹ̀ sí ibùsọ̀ ìbùkún. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn amúnigúnlẹ̀."

Ayah  23:30  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ وَإِن كُنَّا لَمُبْتَلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Àwa sì ni À ń dán ẹ̀dá wò.

Ayah  23:31  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَنشَأْنَا مِن بَعْدِهِمْ قَرْنًا آخَرِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.

Ayah  23:32  الأية
    +/- -/+  
فَأَرْسَلْنَا فِيهِمْ رَسُولًا مِّنْهُمْ أَنِ اعْبُدُوا اللهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ أَفَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
A tún rán Òjíṣẹ́ kan sí wọn láààrin ara wọn (láti jíṣẹ́) pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?"

Ayah  23:33  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ الْمَلَأُ مِن قَوْمِهِ الَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِلِقَاءِ الْآخِرَةِ وَأَتْرَفْنَاهُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا مَا هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يَأْكُلُ مِمَّا تَأْكُلُونَ مِنْهُ وَيَشْرَبُ مِمَّا تَشْرَبُونَ
Yoruba
 
Àwọn olórí tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀, àwọn tó pe ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn tí A ṣe gbẹdẹmukẹ fún nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, wọ́n wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín; ó ń jẹ nínú ohun tí ẹ̀ ń jẹ, ó sì ń mu nínú ohun tí ẹ̀ ń mu.

Ayah  23:34  الأية
    +/- -/+  
وَلَئِنْ أَطَعْتُم بَشَرًا مِّثْلَكُمْ إِنَّكُمْ إِذًا لَّخَاسِرُونَ
Yoruba
 
Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé abara kan bí irú yín, dájúdájú ẹ mà ti di ẹni òfò nìyẹn.

Ayah  23:35  الأية
    +/- -/+  
أَيَعِدُكُمْ أَنَّكُمْ إِذَا مِتُّمْ وَكُنتُمْ تُرَابًا وَعِظَامًا أَنَّكُم مُّخْرَجُونَ
Yoruba
 
Ṣé ó ń ṣe àdéhùn fún yín pé nígbà tí ẹ bá kú, tí ẹ sì di erùpẹ̀ àti egungun tán, dájúdájú wọn yóò mu yín jáde (ní alààyè)?

Ayah  23:36  الأية
    +/- -/+  
هَيْهَاتَ هَيْهَاتَ لِمَا تُوعَدُونَ
Yoruba
 
Ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín (yìí) jìnnà tefétefé (sí òdodo).

Ayah  23:37  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ
Yoruba
 
Kò sí ìṣẹ̀mí ayé kan mọ́ àyàfi èyí tí à ń lò yìí; àwa kan ń kú, àwa kan ń wáyé. Àti pé wọn kò níí gbé wa dìde mọ́.

Ayah  23:38  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ افْتَرَىٰ عَلَى اللهِ كَذِبًا وَمَا نَحْنُ لَهُ بِمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
(Òjíṣẹ́ náà) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Àwa kò sì níí gbà á gbọ́."

Ayah  23:39  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّ انصُرْنِي بِمَا كَذَّبُونِ
Yoruba
 
(Òjíṣẹ́ náà) sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́."

Ayah  23:40  الأية
    +/- -/+  
قَالَ عَمَّا قَلِيلٍ لَّيُصْبِحُنَّ نَادِمِينَ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Láìpẹ́ ńṣe ni wọn yóò di alábàámọ̀."

Ayah  23:41  الأية
    +/- -/+  
فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ بِالْحَقِّ فَجَعَلْنَاهُمْ غُثَاءً ۚ فَبُعْدًا لِّلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. A sì sọ wọ́n di pàǹtí. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ alábòsí.

Ayah  23:42  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَنشَأْنَا مِن بَعْدِهِمْ قُرُونًا آخَرِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A tún mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.

Ayah  23:43  الأية
    +/- -/+  
مَا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ
Yoruba
 
Ìjọ kan kò níí lọ ṣíwájú àkókò (ìparun) rẹ̀, wọn kò sì níí sún (ìparun wọn) síwájú.

Ayah  23:44  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَرْسَلْنَا رُسُلَنَا تَتْرَىٰ ۖ كُلَّ مَا جَاءَ أُمَّةً رَّسُولُهَا كَذَّبُوهُ ۚ فَأَتْبَعْنَا بَعْضَهُم بَعْضًا وَجَعَلْنَاهُمْ أَحَادِيثَ ۚ فَبُعْدًا لِّقَوْمٍ لَّا يُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n á pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ ní òdodo.

Ayah  23:45  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ وَأَخَاهُ هَارُونَ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A rán (Ànábì) Mūsā àti ọmọ-ìyá rẹ̀ (Ànábì) Hārūn níṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé.

Ayah  23:46  الأية
    +/- -/+  
إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَاسْتَكْبَرُوا وَكَانُوا قَوْمًا عَالِينَ
Yoruba
 
(A rán wọn níṣẹ́) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣègbéraga, wọ́n sì jẹ́ ìjọ olùjẹgàba.

Ayah  23:47  الأية
    +/- -/+  
فَقَالُوا أَنُؤْمِنُ لِبَشَرَيْنِ مِثْلِنَا وَقَوْمُهُمَا لَنَا عَابِدُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣé kí á gba abara méjì bí irú wa gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹrú wa ni àwọn ènìyàn wọn?"

Ayah  23:48  الأية
    +/- -/+  
فَكَذَّبُوهُمَا فَكَانُوا مِنَ الْمُهْلَكِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. Wọ́n sì wà nínú àwọn olùparun.

Ayah  23:49  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.

Ayah  23:50  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلْنَا ابْنَ مَرْيَمَ وَأُمَّهُ آيَةً وَآوَيْنَاهُمَا إِلَىٰ رَبْوَةٍ ذَاتِ قَرَارٍ وَمَعِينٍ
Yoruba
 
A ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, tó ní ibùgbé, tó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú.

Ayah  23:51  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الرُّسُلُ كُلُوا مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَاعْمَلُوا صَالِحًا ۖ إِنِّي بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ
Yoruba
 
Ẹ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  23:52  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ هَٰذِهِ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَأَنَا رَبُّكُمْ فَاتَّقُونِ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ('Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.

Ayah  23:53  الأية
    +/- -/+  
فَتَقَطَّعُوا أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ زُبُرًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ
Yoruba
 
Ṣùgbọ́n wọ́n gé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn láààrin ara wọn sí kélekèle. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tó ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wọn.

Ayah  23:54  الأية
    +/- -/+  
فَذَرْهُمْ فِي غَمْرَتِهِمْ حَتَّىٰ حِينٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìṣìnà wọn títí di ìgbà kan ná.

Ayah  23:55  الأية
    +/- -/+  
أَيَحْسَبُونَ أَنَّمَا نُمِدُّهُم بِهِ مِن مَّالٍ وَبَنِينَ
Yoruba
 
Ṣé wọ́n ń lérò pé (bí) A ṣe ń fi dúkìá àti ọmọ nìkan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn,

Ayah  23:56  الأية
    +/- -/+  
نُسَارِعُ لَهُمْ فِي الْخَيْرَاتِ ۚ بَل لَّا يَشْعُرُونَ
Yoruba
 
Ni A óò ṣe máa yára ti àwọn oore sí ọ̀dọ̀ wọn lọ (títí láéláé). Rárá, wọn kò fura ni!

Ayah  23:57  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الَّذِينَ هُم مِّنْ خَشْيَةِ رَبِّهِم مُّشْفِقُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tó ń páyà (ìṣírò-iṣẹ́) nípa ìpáyà wọn nínú Olúwa wọn;

Ayah  23:58  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ هُم بِآيَاتِ رَبِّهِمْ يُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tó ń gba àwọn āyah Olúwa wọn gbọ́;

Ayah  23:59  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ هُم بِرَبِّهِمْ لَا يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tí kì í ṣẹbọ sí Olúwa wọn,

Ayah  23:60  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ يُؤْتُونَ مَا آتَوا وَّقُلُوبُهُمْ وَجِلَةٌ أَنَّهُمْ إِلَىٰ رَبِّهِمْ رَاجِعُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn tí wọ́n ń ṣe ohun wọ́n ń ṣe (nínú àwọn iṣẹ́ rere) pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn;

Ayah  23:61  الأية
    +/- -/+  
أُولَٰئِكَ يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَهُمْ لَهَا سَابِقُونَ
Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ń yára ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn sì ni aṣíwájú nínú (àwọn ẹ̀san) iṣẹ́ náà.

Ayah  23:62  الأية
    +/- -/+  
وَلَا نُكَلِّفُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا ۖ وَلَدَيْنَا كِتَابٌ يَنطِقُ بِالْحَقِّ ۚ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Yoruba
 
Àti pé A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tírà kan tó ń sọ òdodo (nípa iṣẹ́ ẹ̀dá) ń bẹ lọ́dọ̀ Wa. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

Ayah  23:63  الأية
    +/- -/+  
بَلْ قُلُوبُهُمْ فِي غَمْرَةٍ مِّنْ هَٰذَا وَلَهُمْ أَعْمَالٌ مِّن دُونِ ذَٰلِكَ هُمْ لَهَا عَامِلُونَ
Yoruba
 
Àmọ́ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wà nínú ìfọ́núfọ́ra nípa (al-Ƙur'ān) yìí. Àti pé wọ́n ní àwọn iṣẹ́ kan lọ́wọ́, tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ rere yẹn. Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ náà

Ayah  23:64  الأية
    +/- -/+  
حَتَّىٰ إِذَا أَخَذْنَا مُتْرَفِيهِم بِالْعَذَابِ إِذَا هُمْ يَجْأَرُونَ
Yoruba
 
Títí di ìgbà tí A máa gbá àwọn onígbẹdẹmukẹ nínú wọn mú pẹ̀lú ìyà. Nígbà náà ni wọ́n máa kígbe (fún ìrànlọ́wọ́).

Ayah  23:65  الأية
    +/- -/+  
لَا تَجْأَرُوا الْيَوْمَ ۖ إِنَّكُم مِّنَّا لَا تُنصَرُونَ
Yoruba
 
Ẹ má ṣe kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) ní òní. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Wa.

Ayah  23:66  الأية
    +/- -/+  
قَدْ كَانَتْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنتُمْ عَلَىٰ أَعْقَابِكُمْ تَنكِصُونَ
Yoruba
 
Wọ́n kúkú ń ka àwọn āyah Mi fún yín. Àmọ́ ńṣe ni ẹ̀ ń fà sẹ́yìn (níbi òdodo).

Ayah  23:67  الأية
    +/- -/+  
مُسْتَكْبِرِينَ بِهِ سَامِرًا تَهْجُرُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀ sì ń fi (Kaaba) ṣègbéraga, ẹ tún sọ ìsọkúsọ (nípa al-Ƙur'ān) ní alẹ́!

Ayah  23:68  الأية
    +/- -/+  
أَفَلَمْ يَدَّبَّرُوا الْقَوْلَ أَمْ جَاءَهُم مَّا لَمْ يَأْتِ آبَاءَهُمُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Ṣé wọn kò ronú sí ọ̀rọ̀ náà ni? Tàbí ohun tó dé bá wọn jẹ́ ohun tí kò dé bá àwọn bàbá wọn àkọ́kọ́ rí ni?

Ayah  23:69  الأية
    +/- -/+  
أَمْ لَمْ يَعْرِفُوا رَسُولَهُمْ فَهُمْ لَهُ مُنكِرُونَ
Yoruba
 
Tàbí wọn kò mọ Òjíṣẹ́ wọn mọ́ ni wọ́n fi di alátakò rẹ̀?

Ayah  23:70  الأية
    +/- -/+  
أَمْ يَقُولُونَ بِهِ جِنَّةٌ ۚ بَلْ جَاءَهُم بِالْحَقِّ وَأَكْثَرُهُمْ لِلْحَقِّ كَارِهُونَ
Yoruba
 
Tàbí wọn ń wí pé àlùjànnú kan ń bẹ lára rẹ̀ ni? Rárá o. Ó mú òdodo wá bá wọn ni. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì jẹ́ olùkórira òdodo.

Ayah  23:71  الأية
    +/- -/+  
وَلَوِ اتَّبَعَ الْحَقُّ أَهْوَاءَهُمْ لَفَسَدَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ وَمَن فِيهِنَّ ۚ بَلْ أَتَيْنَاهُم بِذِكْرِهِمْ فَهُمْ عَن ذِكْرِهِم مُّعْرِضُونَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn tó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn.

Ayah  23:72  الأية
    +/- -/+  
أَمْ تَسْأَلُهُمْ خَرْجًا فَخَرَاجُ رَبِّكَ خَيْرٌ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ
Yoruba
 
Tàbí ò ń béèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn ni? Owó-ọ̀yà Olúwa rẹ̀ lóore jùlọ. Àti pé Òun l'óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.

Ayah  23:73  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّكَ لَتَدْعُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ò ń pè wọ́n sójú ọ̀nà tààrà ni.

Ayah  23:74  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ عَنِ الصِّرَاطِ لَنَاكِبُونَ
Yoruba
 
Àwọn tí kò sì gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò lójú ọ̀nà náà.

Ayah  23:75  الأية
    +/- -/+  
وَلَوْ رَحِمْنَاهُمْ وَكَشَفْنَا مَا بِهِم مِّن ضُرٍّ لَّلَجُّوا فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé́gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-ààlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà).

Ayah  23:76  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَخَذْنَاهُم بِالْعَذَابِ فَمَا اسْتَكَانُوا لِرَبِّهِمْ وَمَا يَتَضَرَّعُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú A fi ìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọn kò tẹríba fún Olúwa wọn, wọn kò sì rawọ́ rasẹ̀ sí I

Ayah  23:77  الأية
    +/- -/+  
حَتَّىٰ إِذَا فَتَحْنَا عَلَيْهِم بَابًا ذَا عَذَابٍ شَدِيدٍ إِذَا هُمْ فِيهِ مُبْلِسُونَ
Yoruba
 
Títí di ìgbà tí A fi ṣílẹ̀kùn ìyà líle fún wọn; nígbà náà ni wọ́n sọ̀rètí nù.

Ayah  23:78  الأية
    +/- -/+  
وَهُوَ الَّذِي أَنشَأَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۚ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ
Yoruba
 
(Allāhu), Òun ni Ẹni tí Ó ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.

Ayah  23:79  الأية
    +/- -/+  
وَهُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
Yoruba
 
Òun ni Ẹni tí Ó da yín sórí ilẹ̀, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n yóò ko yín jọ sí.

Ayah  23:80  الأية
    +/- -/+  
وَهُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ وَلَهُ اخْتِلَافُ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Yoruba
 
Òun ni Ẹni tó ń sọ ẹ̀dá di alààyè, Ó ń sọ ẹ̀dá di òkú, tiRẹ̀ sì ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

Ayah  23:81  الأية
    +/- -/+  
بَلْ قَالُوا مِثْلَ مَا قَالَ الْأَوَّلُونَ
Yoruba
 
Rárá (wọn kò níí ṣe làákàyè, ṣebí) irú ohun tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wí ni àwọn náà wí.

Ayah  23:82  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé wọn yóò gbé wa dìde ni?

Ayah  23:83  الأية
    +/- -/+  
لَقَدْ وُعِدْنَا نَحْنُ وَآبَاؤُنَا هَٰذَا مِن قَبْلُ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Wọ́n kúkú ti ṣàdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́."

Ayah  23:84  الأية
    +/- -/+  
قُل لِّمَنِ الْأَرْضُ وَمَن فِيهَا إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?"

Ayah  23:85  الأية
    +/- -/+  
سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n á wí pé: "Ti Allāhu ni." Sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?"

Ayah  23:86  الأية
    +/- -/+  
قُلْ مَن رَّبُّ السَّمَاوَاتِ السَّبْعِ وَرَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?"

Ayah  23:87  الأية
    +/- -/+  
سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ أَفَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
Wọ́n á wí pé: "Ti Allāhu ni." Sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?"

Ayah  23:88  الأية
    +/- -/+  
قُلْ مَن بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ يُجِيرُ وَلَا يُجَارُ عَلَيْهِ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?"

Ayah  23:89  الأية
    +/- -/+  
سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ فَأَنَّىٰ تُسْحَرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n á wí pé: "Ti Allāhu ni." Sọ pé: "Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?"

Ayah  23:90  الأية
    +/- -/+  
بَلْ أَتَيْنَاهُم بِالْحَقِّ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Yoruba
 
Àmọ́ sá, òdodo ni A mú wá ba wọn. Dájúdájú àwọn sì ni òpùrọ́.

Ayah  23:91  الأية
    +/- -/+  
مَا اتَّخَذَ اللهُ مِن وَلَدٍ وَمَا كَانَ مَعَهُ مِنْ إِلَٰهٍ ۚ إِذًا لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَٰهٍ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلَا بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ سُبْحَانَ اللهِ عَمَّا يَصِفُونَ
Yoruba
 
Allāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá tó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí).

Ayah  23:92  الأية
    +/- -/+  
عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
(Allāhu) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nítorí náà, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.

Ayah  23:93  الأية
    +/- -/+  
قُل رَّبِّ إِمَّا تُرِيَنِّي مَا يُوعَدُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Olúwa mi, Ó ṣeé ṣe kí Ó fi ohun tí wọ́n ń ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn mí,

Ayah  23:94  الأية
    +/- -/+  
رَبِّ فَلَا تَجْعَلْنِي فِي الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Olúwa mi, má ṣe fi mí sínú ìjọ alábòsí."

Ayah  23:95  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّا عَلَىٰ أَن نُّرِيَكَ مَا نَعِدُهُمْ لَقَادِرُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa lágbára láti fi ohun tí A ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn ọ́.

Ayah  23:96  الأية
    +/- -/+  
ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ السَّيِّئَةَ ۚ نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَصِفُونَ
Yoruba
 
Fi èyí tó dára tí àìdára dànù. Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n fi ń ròyìn (Wa).

Ayah  23:97  الأية
    +/- -/+  
وَقُل رَّبِّ أَعُوذُ بِكَ مِنْ هَمَزَاتِ الشَّيَاطِينِ
Yoruba
 
Sọ pé: "Olúwa mi, mò ń sádi Ọ́ níbi ròyíròyí t'àwọn èṣù.

Ayah  23:98  الأية
    +/- -/+  
وَأَعُوذُ بِكَ رَبِّ أَن يَحْضُرُونِ
Yoruba
 
Mò ń sádi Ọ́, Olúwa mi, níbi kí wọ́n wá bá mi."

Ayah  23:99  الأية
    +/- -/+  
حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ رَبِّ ارْجِعُونِ
Yoruba
 
(Wọ́n ń ṣẹ̀mí lọ) títí di ìgbà tí ikú fi máa dé bá ọ̀kan nínú wọn. Ó sì máa wí pé: "Olúwa mi, Ẹ dá mi padà (sílé ayé)

Ayah  23:100  الأية
    +/- -/+  
لَعَلِّي أَعْمَلُ صَالِحًا فِيمَا تَرَكْتُ ۚ كَلَّا ۚ إِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَائِلُهَا ۖ وَمِن وَرَائِهِم بَرْزَخٌ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ
Yoruba
 
Nítorí kí èmi lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde.

Ayah  23:101  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا نُفِخَ فِي الصُّورِ فَلَا أَنسَابَ بَيْنَهُمْ يَوْمَئِذٍ وَلَا يَتَسَاءَلُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, kò níí sí ìbátan láààrin wọn ní ọjọ́ yẹn, wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.

Ayah  23:102  الأية
    +/- -/+  
فَمَن ثَقُلَتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè.

Ayah  23:103  الأية
    +/- -/+  
وَمَنْ خَفَّتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ فِي جَهَنَّمَ خَالِدُونَ
Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú iná Jahanamọ.

Ayah  23:104  الأية
    +/- -/+  
تَلْفَحُ وُجُوهَهُمُ النَّارُ وَهُمْ فِيهَا كَالِحُونَ
Yoruba
 
Iná yóò máa jó wọn lójú. Wọn yó sì wà nínú rẹ̀, tí Iná yóò ti bà wọ́n lójú jẹ́.

Ayah  23:105  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ تَكُنْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ
Yoruba
 
Ṣé wọ́n kì í ka àwọn āyah Mi fún yín ni, àmọ́ tí ẹ̀ ń pè é ní irọ́?

Ayah  23:106  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا رَبَّنَا غَلَبَتْ عَلَيْنَا شِقْوَتُنَا وَكُنَّا قَوْمًا ضَالِّينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, orí burúkú ló kọlù wá; àwa sì jẹ́ ìjọ olùṣìnà.

Ayah  23:107  الأية
    +/- -/+  
رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْهَا فَإِنْ عُدْنَا فَإِنَّا ظَالِمُونَ
Yoruba
 
Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú Iná. Tí a bá fi lè padà (síbi iṣẹ́ ibi nílé ayé), dájúdájú nígbà náà alábòsí ni àwa."

Ayah  23:108  الأية
    +/- -/+  
قَالَ اخْسَئُوا فِيهَا وَلَا تُكَلِّمُونِ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Ẹ tẹ̀rì sínú rẹ̀. Ẹ má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀."

Ayah  23:109  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ كَانَ فَرِيقٌ مِّنْ عِبَادِي يَقُولُونَ رَبَّنَا آمَنَّا فَاغْفِرْ لَنَا وَارْحَمْنَا وَأَنتَ خَيْرُ الرَّاحِمِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú igun kan wà nínú àwọn ẹrúsìn Mi, tí wọ́n ń sọ pé: "Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì l'óore jùlọ nínú àwọn aláàánú."

Ayah  23:110  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّخَذْتُمُوهُمْ سِخْرِيًّا حَتَّىٰ أَنسَوْكُمْ ذِكْرِي وَكُنتُم مِّنْهُمْ تَضْحَكُونَ
Yoruba
 
Ṣùgbọ́n ẹ sọ wọ́n di oníyẹ̀yẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn yẹ̀yẹ́ (yín) fi mu yín gbàgbé ìrántí Mi. Ẹ̀yin sì ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín.

Ayah  23:111  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي جَزَيْتُهُمُ الْيَوْمَ بِمَا صَبَرُوا أَنَّهُمْ هُمُ الْفَائِزُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú Mo san wọ́n ní ẹ̀san ní òní nítorí sùúrù wọn; dájúdájú àwọn, àwọn ni olùjèrè.

Ayah  23:112  الأية
    +/- -/+  
قَالَ كَمْ لَبِثْتُمْ فِي الْأَرْضِ عَدَدَ سِنِينَ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Ọdún mélòó ni ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) lò lórí ilẹ̀ ayé?"

Ayah  23:113  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا لَبِثْنَا يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ فَاسْأَلِ الْعَادِّينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "A lo ọjọ́ kan tàbí abala ọjọ́ kan, bi àwọn olùṣírò-ọjọ́ léèrè wò."

Ayah  23:114  الأية
    +/- -/+  
قَالَ إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا قَلِيلًا ۖ لَّوْ أَنَّكُمْ كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀."

Ayah  23:115  الأية
    +/- -/+  
أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ
Yoruba
 
Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?"

Ayah  23:116  الأية
    +/- -/+  
فَتَعَالَى اللهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ
Yoruba
 
Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé.

Ayah  23:117  الأية
    +/- -/+  
وَمَن يَدْعُ مَعَ اللهِ إِلَٰهًا آخَرَ لَا بُرْهَانَ لَهُ بِهِ فَإِنَّمَا حِسَابُهُ عِندَ رَبِّهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُونَ
Yoruba
 
Ẹni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí rẹ̀. Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè.

Ayah  23:118  الأية
    +/- -/+  
وَقُل رَّبِّ اغْفِرْ وَارْحَمْ وَأَنتَ خَيْرُ الرَّاحِمِينَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Olúwa mi, ṣàforíjìn, kí O sì kẹ́ (mi). Ìwọ sì l'óore jùlọ nínú àwọn aláàánú."
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us